Àwọn Wo Ló Ń Gbára Dì fún Ogun Ọ̀gbálẹ̀gbáràwé?
“Fífi ogun ọ̀gbálẹ̀gbáràwé pa gbogbo èèyàn run kì í ṣe ohun tí kò lè ṣẹlẹ̀. Ó ṣì lè ṣẹlẹ̀ lónìí, . . . bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọ̀tẹ̀ Abẹ́lẹ̀ ti parí ní ohun tó ju ọdún mẹ́wàá sẹ́yìn.”—Robert S. McNamara tó jẹ́ Akọ̀wé fún Ètò Ààbò nígbà kan rí ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà àti James G. Blight tó jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ìmọ̀ nípa àjọṣe láàárín àwọn orílẹ̀-èdè ní Iléèwé Watson tí wọ́n ti ń kọ́ nípa Àjọṣe Tó Wà Láàárín Àwọn Orílẹ̀-Èdè.
NÍ ỌDÚN 1991 tí Ọ̀tẹ̀ Abẹ́lẹ̀ dópin, wọ́n yí ọwọ́ aago lílókìkí tí wọ́n fi ń díwọ̀n ọjọ́ ìparun padà sí “aago méjìlá òru” ku ìṣẹ́jú mẹ́tàdínlógún. Wọ́n yàwòrán aago yìí sẹ́yìn ìwé ìròyìn Bulletin of the Atomic Scientists, ó sì jẹ́ àmì tí ń fi bí àwọn èèyàn ṣe rò pé ayé ti sún mọ́ ogun ọ̀gbálẹ̀gbáràwé tó hàn, ìyẹn (aago méjìlá òru). Nígbà yẹn, ibi tí wọ́n yí ọwọ́ aago náà sí jìnnà gan-an sí aago méjìlá òru, ibi tó wà nígbà yẹn sì ló tíì jìnnà jù lọ látìgbà tí wọ́n ti fi lọ́lẹ̀ lọ́dún 1947. Àmọ́ ṣá o, látìgbà yẹn ni ọwọ́ aago náà ti bẹ̀rẹ̀ sí sún síwájú sí i. Bí àpẹẹrẹ, ní oṣù February ọdún 2002, wọ́n yí ọwọ́ aago náà sí aago méjìlá òru ku ìṣẹ́jú méje, èyí tó jẹ́ ìgbà kẹta tí wọ́n á yí i síwájú látìgbà tí Ọ̀tẹ̀ Abẹ́lẹ̀ ti parí.
Kí nìdí táwọn òǹṣèwé ìròyìn yẹn fi rò pé ó yẹ káwọn yí ọwọ́ aago náà síwájú? Kí ló mú kí wọ́n rò pé ogun ọ̀gbálẹ̀gbáràwé ṣì ń bọ̀ wá jà? Àwọn wo gan-an tiẹ̀ lọ̀tá àlàáfíà?
Ẹ̀tàn Tó Wà Nídìí “Dídín Ohun Ìjà Kù”
Ìwé ìròyìn Bulletin of the Atomic Scientists ṣàlàyé pé: “Ó ju ẹgbẹ̀rún mọ́kànlélọ́gbọ̀n [31,000] àwọn ohun ìjà olóró tó ṣì wà ní sẹpẹ́ fún lílò.” Ó tún fi kún un pé: “Bí a bá dá àwọn ohun ìjà olóró wọ̀nyí sí ọ̀nà ọgọ́rùn-ún, ìdá márùndínlọ́gọ́rùn-ún nínú wọn ló wà ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà àti orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà, iye tí wọ́n sì ti kẹ́ sílẹ̀ ju ẹgbẹ̀rún mẹ́rìndínlógún [16,000] lọ.” Àwọn kan lè wá máa ṣe kàyéfì nípa iye ohun ìjà olóró tó wà ní sẹpẹ́ yìí. Ṣebí àwọn orílẹ̀-èdè méjèèjì tó ń múpò iwájú nínú ṣíṣe ohun ìjà olóró yìí ti sọ pé ẹnì kọ̀ọ̀kan àwọn ti dín ohun ìjà táwọn ní kù sí ẹgbẹ̀rún mẹ́fà [6,000] ni?
Àlàyé tó wà nísàlẹ̀ yìí fi ẹ̀tàn tó wà nídìí “dídín ohun ìjà kù” hàn. Ìròyìn kan tó wá látọ̀dọ̀ Àjọ Tó Ń Rí sí Àlàáfíà Láàárín Àwọn Orílẹ̀-Èdè èyí tí Carnegie gbé kalẹ̀ ṣàlàyé pé: “Ẹgbẹ̀rún mẹ́fà [6,000] ohun ìjà tí wọ́n sọ pé àwọn ní lọ́wọ́, jẹ́ àwọn ohun ìjà tí wọ́n fohùn ṣọ̀kan lé lórí pé ó yẹ kí àwọn kà gẹ́gẹ́ bí àdéhùn tí wọ́n ṣe nígbà Ìpàdé Àpérò Lórí Dídín Àwọn Ohun Ìjà Olóró Kù. Àwọn orílẹ̀-èdè méjèèjì yìí ṣì ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún ohun ìjà ayọ́kẹ́lẹ́ṣọṣẹ́ kéékèèké mìíràn nípamọ́.” (Ìkọ̀wé wínníwínní jẹ́ tiwa.) Ìwé ìròyìn Bulletin of the Atomic Scientists sọ pé: “Èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àwọn ohun ìjà olóró tí orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ti kẹ́ sílẹ̀ tẹ́lẹ̀ ni wọ́n ti lọ kó pa mọ́ báyìí (wọ́n kó wọn pa pọ̀ mọ́ nǹkan bí ẹgbẹ̀rún márùn-ún [5,000] ohun ìjà olóró tó ti wà nípamọ́ tẹ́lẹ̀) dípò kí wọ́n pa àwọn ohun ìjà wọ̀nyí run.”
Nítorí náà, yàtọ̀ sí ẹgbẹẹgbẹ̀rún ohun ìjà ayọ́kẹ́lẹ́ṣọṣẹ́ tí wọ́n ti kẹ́ sílẹ̀ tó wà nípamọ́, tí wọ́n lè yìn láti ààlà orílẹ̀ èdè kan sí ààlà ilẹ̀ orílẹ̀-èdè mìíràn, ẹgbẹẹgbẹ̀rún ohun ìjà runlérùnnà àti ohun ìjà ayọ́kẹ́lẹ́ṣọṣẹ́ mìíràn ló wà tí wọ́n ti dìídì ṣe láti ta jàǹbá fáwọn orílẹ̀-èdè tó wà nítòsí. Láìsí tàbí-ṣùgbọ́n, àwọn orílẹ̀-èdè méjèèjì tó ń múpò iwájú nínú ṣíṣe ohun ìjà olóró ṣì ní àgbá runlérùnnà tí wọ́n to jọ pelemọ, èyí tó lè pa gbogbo ayé run láìmọye ìgbà! Kíkó àwọn ohun ìjà olóró wọ̀nyí jọ tún jẹ́ ohun mìíràn tó ń dẹ́rù bani, nítorí pé, tí wọ́n bá ṣèèṣì yin àwọn àdó olóró wọ̀nyí, yóò ṣe ọṣẹ́ tó burú jọjọ.
Ogun Ọ̀gbálẹ̀gbáràwé Tí Ì Bá Ṣẹlẹ̀
Robert S. McNamara àti James G. Blight tá a mẹ́nu kàn níbẹ̀rẹ̀ sọ pé: “Ohun tó ń mú kí orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà mọ ìgbà tí wọ́n á lo àwọn ohun ìjà tó ti wà ní sẹpẹ́ ni ‘ọ̀nà ìtanilólobó’ kan.” Kí ni ọ̀nà ìtanilólobó yìí? Wọ́n ṣàlàyé pé: “Àwọn ohun ìjà wa ti wà ní sẹpẹ́ fún lílò gbàrà tí àwọn ohun ìjà orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà bá ti wà nínú afẹ́fẹ́. Ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ò lè kọjá lẹ́yìn tí orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà bá kọ́kọ́ yin ohun ìjà olóró tí àwa náà yóò fi yin tiwa.” Ọ̀gágun tó ń darí yíyin àwọn ohun ìjà ayọ́kẹ́lẹ́ṣọṣẹ́ nígbà kan rí ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ pé: “Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo ohun ìjà tó wà nílẹ̀ ló ti wà ní sẹpẹ́ tá a sì lè lò láàárín ìṣẹ́jú méjì péré.”
Bó ṣe jẹ́ pé ká tó ṣẹ́jú pẹ́ẹ́ ni wọ́n lè yin àwọn ohun ìjà wọ̀nyí ti mú kí ẹ̀rù máa ba àwọn èèyàn, nítorí pé tọ̀tún tòsì wọn lè ṣi ara wọn lóye kí wọ́n sì ṣèèṣì yìn wọ́n. Àpilẹ̀kọ kan nínú ìwé ìròyìn U.S.News & World Report ṣàlàyé pé: “Ó ti ju ẹ̀ẹ̀kan lọ tí wọ́n ti ṣèèṣì pàṣẹ pé kí wọ́n lo ohun ìjà olóró nígbà tí wọ́n ń ṣe àfidánrawò lórí lílo àwọn ohun ìjà ọ̀gbálẹ̀gbáràwé ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà.” Irú àṣìlóye yẹn náà ti wáyé ní orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà. Nígbà tí ọkọ̀ òfuurufú ayára-bí-àṣá tí wọ́n fi máa ń wádìí ohun tó ń sẹlẹ̀ lójú sánmà tó jẹ́ tàwọn ará Norway fi ìsọfúnni ránṣẹ́ lọ́dún 1995 pé ogun ń bọ̀ nígbà tí kò sógun, lójú ẹsẹ̀ ni ààrẹ orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà ti bẹ̀rẹ̀ sí gbára dì fún yíyin àwọn ohun ìjà abúgbàù tiwọn náà.
Ọgbọ́n kíkẹ́ ohun ìjà sílẹ̀ yìí ń kó wàhálà tí kò ṣeé fẹnu sọ bá àwọn tó ń ṣèpinnu. A dúpẹ́ pé láwọn àkókò tó ti kọjá, àwọn ọ̀gágun ti rí i pé ẹ̀tàn làwọn olobó tí wọ́n ń ta àwọn, ìyẹn ló ti ń jẹ́ kí wọ́n lè dènà ogun runlérùnnà títí di báyìí. Ọkùnrin olùṣèwádìí kan ṣàlàyé nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ọdún 1979 pé: “Ohun kan tó ń ṣiṣẹ́ bí alukoro táwọn ará Amẹ́ríkà fi sójú òfuurufú tó tètè ta wọ́n lólobó pé kò sí ohun ìjà àwọn ará Soviet lójú òfuurufú ni kò jẹ́ kí wọ́n rán ohun ìjà tiwọn náà sójú òfuurufú.” Àmọ́ ṣá o, kò pẹ́ tí irú ọ̀nà ìtanilólobó bẹ́ẹ̀ kò fi ṣiṣẹ́ dáadáa mọ́. Àwọn olùṣèwádìí àtàwọn tó máa ń ṣàrúnkúnná ọ̀rọ̀ ń kọminú lórí bí “èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àwọn ohun atanilólobó táwọn ará Rọ́ṣíà rán sójú òfuurufú ṣe daṣẹ́ sílẹ̀ tàbí bí wọ́n ṣe rìn kọjá ibi tí wọ́n fi wọ́n sí lójú òfuurufú.” Nítorí náà, gẹ́gẹ́ bí ọ̀gágun ojú omi ará Amẹ́ríkà kan tó ti jagun fẹ̀yìn tì ṣe sọ ní ọdún bíi mélòó kan sẹ́yìn lọ̀rọ̀ rí, pé: “Bí ọkàn àwọn èèyàn kò ṣe balẹ̀ páàpáà látijọ́ nítorí pé ìgbàkigbà ló ṣeé ṣe káwọn kan yọwọ́ ìjà káwọn míì tó ṣe tán àtijà, tàbí kí wọ́n ṣèèṣì yin ohun ìjà agbókèèrè-ṣọṣẹ́ nítorí pé ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ò yé wọn dáadáa, tàbí kí wọ́n gbé àṣẹ lé ẹni tí kò yẹ lọ́wọ́ tàbí kí ohun ìjà ṣèèṣì yìn, bẹ́ẹ̀ náà ni ọkàn àwọn èèyàn kò balẹ̀ páàpáà lónìí.”
Àwọn Orílẹ̀-Èdè Tó Ṣẹ̀ṣẹ̀ Ń Ṣe Ohun Ìjà Runlérùnnà
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn orílẹ̀-èdè méjèèjì tó ń múpò iwájú nínú ṣíṣe ohun ìjà olóró ló ní èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àwọn ohun ìjà olóró tí wọ́n tò jọ pelemọ, àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn tún wà tó ní àwọn ohun ìjà olóró, irú bí ilẹ̀ Faransé, ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti ilẹ̀ Ṣáínà. Àwọn orílẹ̀-èdè táwọn èèyàn ti mọ̀ pé àwọn ló ń múpò iwájú nínú ṣíṣe ohun ìjà olóró wọ̀nyí ni wọ́n ń pè ní àwọn orílẹ̀-èdè tó ń ṣe ohun ìjà runlérùnnà, àìpẹ́ yìí sì ni orílẹ̀-èdè Íńdíà àti orílẹ̀-èdè Pakistan náà dara pọ̀ mọ́ wọn. Yàtọ̀ sáwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí, àwọn orílẹ̀-èdè bíi mélòó kan, èyí tí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì wà lára wọn, làwọn èèyàn sábà máa ń kà kún àwọn orílẹ̀-èdè tó ń wá ọ̀nà láti ní ohun ìjà olóró tàbí tí wọ́n tiẹ̀ ti ní in.
Bí rògbòdìyàn òṣèlú bá ṣẹlẹ̀ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè tó ń múpò iwájú nínú ṣíṣe ohun ìjà olóró, títí kan àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dara pọ̀ mọ́ wọn, ó lè súnná sí ogun ọ̀gbálẹ̀gbáràwé. Ìwé ìròyìn Bulletin of the Atomic Scientists sọ pé: “Yánpọnyánrin tó bẹ́ sílẹ̀ láàárín orílẹ̀-èdè Íńdíà àti orílẹ̀-èdè Pakistan ló sọ wọ́n di orílẹ̀-èdè méjì tó tíì sún mọ́ ogun runlérùnnà jù lọ látìgbà Àgbákò Ogun Tó Fẹ́ Ṣẹlẹ̀ ní Ilẹ̀ Cuba.” Nígbà táwọn èèyàn wá rí i bí ipò nǹkan ṣe túbọ̀ ń burú sí i ní apá ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 2002, ńṣe ni ìrọ́kẹ̀kẹ̀ ogun ọ̀gbálẹ̀gbáràwé túbọ̀ ń ba àwọn èèyàn lẹ́rù.
Ní àfikún, ṣíṣe oríṣi àwọn ohun ìjà olóró mìíràn tó lè ṣekú pa ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ èèyàn tún jẹ́ ìdí mìíràn tó fi ṣeé ṣe káwọn èèyàn ju àdó olóró. Ìwé ìròyìn The New York Times sọ nípa ìròyìn má-jẹ̀ẹ́-á-gbọ́ kan tó wá látọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ Ológun Tó Ga Jù Lọ ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà pé, “fífi àwọn ohun ìjà runlérùnnà run àwọn ohun ìjà táwọn ọ̀tá fi kòkòrò àrùn ṣe, èyí tí wọ́n fi kẹ́míkà ṣe àtàwọn ohun ìjà olóró tó lè ṣekú pa ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn èèyàn” ì bá ti wà lára ọ̀nà tí orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà gbà ń lo àwọn ohun ìjà olóró.
Ọṣẹ́ táwọn apániláyà ṣe ní ọjọ́ kọkànlá oṣù kẹsàn-án ọdún 2001 ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà tún ti mú kí gbogbo ayé máa bẹ̀rù ogun ọ̀gbálẹ̀gbáràwé. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti gbà báyìí pé àwùjọ àwọn apániláyà ń gbìyànjú láti ṣe àwọn ohun ìjà olóró, tàbí ká kúkú sọ pé wọ́n ti ní wọn lọ́wọ́. Ṣùgbọ́n báwo ni ìyẹn ṣe lè ṣeé ṣe?
Àwọn Apániláyà Ń Ṣe Bọ́ǹbù Àgbélẹ̀rọ
Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe láti fi àwọn èròjà tí wọ́n ń tà ní ọjà fàyàwọ́ ṣe àwọn ohun ìjà olóró? Ìwé ìròyìn Time sọ pé ó ṣeé ṣe. Ìwé ìròyìn yìí sọ̀rọ̀ lórí àjọ kan tí wọ́n gbé kalẹ̀ láti kòòré fífi ohun ìjà olóró páni láyà. Títí di báyìí, àjọ náà ‘ti ṣe bọ́ǹbù àtọwọ́dá tó ju méjìlá lọ,’ “àwọn ohun èlò téèyàn sì lè rí rà lórí àtẹ, ìyẹn lọ́dọ̀ àwọn tó ń ta ohun èlò tí ń lo iná àti àwọn èròjà mìíràn tí wọ́n fi ń ṣe ohun ìjà olóró tí wọ́n ń tà lọ́jà fàyàwọ́” ni wọ́n sì fi ṣe wọ́n.
Bíbọ́ra ogun sílẹ̀ àti títú àwọn ohun ìjà olóró palẹ̀ ló mú kó rọrùn fáwọn èèyàn láti jí àwọn ohun tí wọ́n tú palẹ̀ náà kó. Ìwé ìròyìn Time sọ pé: “Títú ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ohun ìjà olóró àwọn ará Rọ́ṣíà kúrò lára àwọn ohun ìjà tí wọ́n pa mọ́ dáadáa, àwọn ohun ìjà tó ń bú gbàù àtàwọn ọkọ ogun abẹ́ omi, ká sì tò wọ́n jọ síbi tí kò fi bẹ́ẹ̀ láàbò, yóò wulẹ̀ dán àwọn apániláyà tó ti gbékútà wò ni.” Bí ọwọ́ àwùjọ kékeré kan bá tẹ àwọn ohun ìjà tí a ti tú palẹ̀, tí wọ́n sì tún wọn tò, irú àwùjọ bẹ́ẹ̀ kò lè pẹ́ di ara àwọn tó ní ohun ìjà olóró!
Ìwé ìròyìn Peace tẹnu mọ́ ọn pé kò dìgbà tí orílẹ̀-èdè kan bá ń to ohun ìjà olóró kó tó dara àwọn orílẹ̀-èdè tó ń ṣe ohun ìjà olóró. Gbogbo ohun tí wọ́n nílò kò ju kí wọ́n ṣáà ti ní ìwọ̀nba èròjà uranium tàbí èròjà plutonium tí wọ́n lè fọ́ sí wẹ́wẹ́. Ìwé ìròyìn yẹn sọ pé: “Ó rọrùn fáwọn apániláyà tó bá ní èròjà uranium tí wọ́n lè fi ṣe ohun ìjà olóró láti ṣe ohun ìjà abúgbàù, kìkì ohun tí wọ́n nílò láti ṣe kò ju pé kí wọ́n ṣáà ti da ìdajì kan pọ̀ mọ́ ìdajì mìíràn.” Báwo ni ohun ìjà olóró tí wọ́n ní láti pò pọ̀ yóò ṣe pọ̀ tó? Gẹ́gẹ́ bí ohun tí ìwé ìròyìn yẹn sọ, ó ní “kìlógíráàmù mẹ́ta péré ti tó.” Èyí fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ohun èlò tí wọ́n lè fi ṣe ohun ìjà olóró tí wọ́n gbẹ́sẹ̀ lé lọ́wọ́ àwọn onífàyàwọ́ tí wọ́n mú ní Orílẹ̀-èdè Olómìnira Czech ní ọdún 1994!
Wọ́n tún lè fi àwọn àlòkù èròjà ìtànṣán olóró ṣe ohun ìjà olóró. Ìwé The American Spectator sọ pé: “Ohun tó ń dààmú àwọn ògbógi ni bí wọ́n ṣe da àlòkù àwọn ohun ìtànṣán olóró àtàwọn ohun abúgbàù tó lè ṣekú pani pọ̀ mọ́ ara wọn.” Irú àwọn ohun ìjà tí wọ́n fi àwọn ohun ìtànṣán olóró ṣe yìí ni wọ́n ń pè ní bọ́ǹbù àgbélẹ̀rọ. Báwo ni irú àwọn ohun ìjà tí wọ́n ṣe lọ́nà yìí ṣe léwu tó? Ìwé ìròyìn IHT Asahi Shimbun ṣàlàyé pé àwọn bọ́ǹbù àgbélẹ̀rọ “máa ń lo àwọn ohun abúgbàù láti tú àwọn ohun ìtànṣán olóró ká, tí ìtànṣán olóró tó tú ká yẹn yóò sì wá di májèlé fún àwọn ọ̀tá dípò kó jẹ́ pé ìbúgbàù àti ooru tó bá jáde níbẹ̀ lá pa wọ́n.” Ó tún fi kún un pé: “Ìyẹn lè mú kí àìsàn tí ìtànṣán olóró ń fà máa ṣe àwọn èèyàn tàbí kí ẹnì kan máa kú ikú oró díẹ̀díẹ̀.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan sọ pé lílo àlòkù àwọn ohun ìjà olóró téèyàn lè rí nítòsí kò fi bẹ́ẹ̀ léwu, ohun tó kó ìdààmú bá àwọn èèyàn ni bí àdàlú ohun ìjà olóró ṣe wà lọ́jà fàyàwọ́. Àbájáde ìwádìí kan tí wọ́n ṣe kárí ayé láìpẹ́ yìí fi hàn pé nínú ọgọ́rùn-ún àwọn tí wọ́n fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò, ó lé ní ọgọ́ta lára wọn tó gbà pé fífi ohun ìjà olóró páni láyà máa wáyé láàárín ọdún mẹ́wàá tó ń bọ̀.
Láìṣe àní àní, aráyé ò tíì gbà pé ogun ọ̀gbálẹ̀gbáràwé kò ní jà. Ìwé ìròyìn ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ kan nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tí wọ́n ń pè ní Guardian Weekly ti January 16 sí 22, 2003 sọ pé: “Ńṣe ló túbọ̀ ń dájú sí i ju ti ìgbàkígbà rí lọ pé Amẹ́ríkà yóò fàbọ̀ sórí lílo àwọn ohun ìjà olóró, pàápàá látìgbà ọ̀tẹ̀ abẹ́lẹ̀ tó burú jáì. . . . Ńṣe ni Amẹ́ríkà túbọ̀ ń rí àwọn ohun tó lè mú kí òun jagun ọ̀gbálẹ̀gbáràwé.” Nítorí náà, ó bọ́gbọ́n mu láti béèrè pé: Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe kí ogun ọ̀gbálẹ̀gbáràwé má jà? Ǹjẹ́ ayé kan tiẹ̀ lè wà tí wọn ò ti ní í fi ohun ìjà olóró dẹ́rù bani mọ́? A óò dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 6]
Ṣé Aráyé Tún Ti Wọ Sáà Ogun Ọ̀gbálẹ̀gbáràwé Kejì Ni?
Nígbà tí Bill Keller tó jẹ́ akọ̀ròyìn fún ìwé ìròyìn The New York Times (tó ti di olóòtú àgbà fún The New York Times báyìí) ń kọ̀wé, ó sọ èrò rẹ̀ pé aráyé tún ti wọ sáà ogun ọ̀gbálẹ̀gbáràwé kejì. Sáà ogun ọ̀gbálẹ̀gbáràwé àkọ́kọ́ parí ní oṣù January ọdún 1994, nígbà tí orílẹ̀-èdè Ukraine gbà láti run àwọn ohun ìjà tó jogún lọ́wọ́ Soviet Union àtijọ́. Kí nìdí tó fi sọ̀rọ̀ nípa ogun ọ̀gbálẹ̀gbáràwé kejì?
Keller kọ̀wé pé: “Wọ́n kéde ogun ọ̀gbálẹ̀gbáràwé kejì nígbà tí wọ́n gbọ́ ariwo àgbá ọta márùn-ún tí ìjọba Hindu tó ń gbé ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni lárugẹ, tó ṣẹ̀ṣẹ̀ gorí àlééfà ní Íńdíà nígbà yẹn, yìn wò ní aṣálẹ̀ Rajasthani lọ́dún 1998. Ọ̀sẹ̀ méjì lẹ́yìn náà ni orílẹ̀-èdè Pakistan ṣe ohun kan náà.” Kí ló mú kí yíyin àwọn ohun ìjà olóró yìí wò yàtọ̀ sí ti sáà ogun ọ̀gbálẹ̀gbáràwé ti tẹ́lẹ̀? “Nítorí àwọn àgbègbè kan pàtó ni wọ́n fi ṣe àwọn ohun ìjà olóró náà.”
Nítorí náà, ṣé aráyé wá lè láàbò bí orílẹ̀-èdè méjì tó jẹ́ akíkanjú bá tún dara pọ̀ mọ́ àwọn orílẹ̀-èdè tó ń ṣe ohun ìjà olóró? Keller ń bá a lọ pé: “Bí orílẹ̀-èdè kọ̀ọ̀kan ṣe ń ní àwọn ohun ìjà olóró, ni ogun láàárín àwọn orílẹ̀-èdè tó ní àwọn ohun ìjà olóró ṣe lè tètè wáyé sí.”—“Ohun Tó Lè Ṣẹlẹ̀,” ìwé ìròyìn The New York Times Magazine, May 4, 2003, ojú ìwé 50.
Ìròyìn kan nípa Àríwá Korea ló mú kí ipò náà túbọ̀ burú sí i, ìròyìn ọ̀hún sọ pé, ó ṣeé ṣe kí Àríwá Korea ní “èròjà plutonium tó máa tó ṣe àdó olóró tuntun mẹ́fà. . . . Bí ọjọ́ ṣe ń gorí ọjọ́ ni ewu náà túbọ̀ ń pọ̀ sí i, nítorí pé, lọ́jọ́ kan Àríwá Korea yóò ṣe ohun ìjà olóró tuntun, tó sì jẹ́ pé ó ṣeé ṣe kó dán ọ̀kan wò nínú wọn láti mọ bó ṣe lè ṣiṣẹ́ sí.”—Ìwé ìròyìn The New York Times, July 18, 2003.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Àwọn ohun èlò atanilólobó tí wọ́n ń lò tẹ́lẹ̀ ti ń bà jẹ́
[Credit Line]
AP Photo/Dennis Cook
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Òṣìṣẹ́ ìjọba kan fi àdó olóró kan tó da bí “àpò” ṣe fọ́rífọ́rí
[Credit Line]
Fọ́tò NASA
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 5]
Ilẹ̀ Ayé: Fọ́tò NASA