Ǹjẹ́ O Mọ̀?
(Ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí wà nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì tí a tọ́ka sí. Ẹ ó sì rí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìdáhùn níbi tí a tẹ̀ ẹ́ sí lójú ìwé 15. Bí ẹ bá fẹ́ mọ púpọ̀ sí i nípa àwọn ìdáhùn yìí, ẹ wo ìwé “Insight on the Scriptures,” tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde.)
1. Kí ni wọ́n fi ṣe àwọn ìtẹ́lẹ̀ oníhò ìtẹ̀bọ̀ tí wọ́n lò fún ìpìlẹ̀ àgọ́ ìjọsìn? (Ẹ́kísódù 26:19-32)
2. Kí ni Bíbélì pe ìdáǹdè orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì kúrò lóko ẹrú ní Íjíbítì? (Hébérù 11:22)
3. Ìgbà mélòó ni Jésù sọ pé Pétérù á sẹ́ òun? (Mátíù 26:75)
4. Àwọn nǹkan mẹ́ta wo la fi ń dá ìjọ Kristẹni mọ̀ lẹ́yìn tí ẹ̀bùn ẹ̀mí tí wọ́n fi ń ṣiṣẹ́ ìyanu ti dópin? (1 Kọ́ríńtì 13:13)
5. Kí nìdí tó fi jẹ́ ìwà òmùgọ̀ láti máa bọ̀rìṣà? (Sáàmù 115:4-8)
6. Ìmọ̀ràn wo ni Pọ́ọ̀lù fún àwọn obìnrin tí wọ́n jẹ́ Kristẹni lórí aṣọ wíwọ̀? (1 Tímótì 2:9, 10)
7. Kí nìdí tí Pọ́ọ̀lù fi ka ara rẹ̀ sí ẹni tó “kéré jù lọ nínú àwọn àpọ́sítélì”? (1 Kọ́ríńtì 15:9)
8. Ohun ìjà wo ni Sámúsìnì fi pa ẹgbẹ̀rún ọkùnrin tí wọ́n jẹ́ Filísínì? (Àwọn Onídàájọ́ 15:15)
9. Kòkòrò wo làwọn ará Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn ti ń jẹ látọjọ́ tó ti pẹ́? (Léfítíkù 11:22)
10. Ìkéde wo ni Jòhánù Olùbatisí fi ọjọ́ méjì gbáko ṣe nípa Jésù? (Jòhánù 1:29, 35, 36)
11. Nítorí pé ibi kọ́lọ́fín ló wà nínú ara, ẹ̀yà ara wo ni Bíbélì fi ṣàpẹẹrẹ èrò àti ìmọ̀lára jíjinlẹ̀ jù lọ tí ẹnì kan ní? (Ìṣípayá 2:23)
12. Nínú ohun tí Ọlọ́run ṣí payá fún Jòhánù, àwọn wo ló rí tí wọ́n jókòó yí ìtẹ́ Jèhófà ká? (Ìṣípayá 4:4)
13. Irúgbìn wo ni Jésù ṣàpèjúwe pé ó “jẹ́ tín-ń-tín jù lọ nínú gbogbo irúgbìn tí ó wà lórí ilẹ̀ ayé”? (Máàkù 4:31)
14. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù dé Áténì nígbà ìrìn-àjò míṣọ́nnárì rẹ̀ ẹlẹ́ẹ̀kejì, àwọn ọkùnrin méjì wo ló ní kí wọ́n “wá bá òun ní kíákíá bí ó bá ti lè yá tó”? (Ìṣe 17:15)
15. Ta ni olórí Elénìní Ọlọ́run? (Jóòbù 1:6)
16. Ta ló ṣèèṣì bá Hánà wí pé ó ti mutí yó bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀? (1 Sámúẹ́lì 1:12-16)
17. Ta ni ‘ọkùnrin tí kò dára fún ohunkóhun’ tó dìtẹ̀ mọ́ Dáfídì tó sì mú kí gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dara pọ̀ mọ́ òun nínú ìdìtẹ̀ náà, àyàfi àwọn ọmọ Júdà? (2 Sámúẹ́lì 20:1, 2)
18. Dípò mánà tí Ọlọ́run fi iṣẹ́ ìyanu pèsè fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì, irú àwọn oúnjẹ tí wọ́n ti jẹ rí ní ilẹ̀ Íjíbítì wo lọkàn wọ́n tún ń fà sí? (Númérì 11:5)
Ìdáhùn sí Àwọn Ìbéèrè
1. Fàdákà
2. Ìjádelọ
3. Mẹ́ta
4. Ìgbàgbọ́, ìrètí àti ìfẹ́
5. Wọn kì í ṣe alààyè, iṣẹ́ ọwọ́ èèyàn ni wọ́n
6. Pé kó wà létòlétò àti níwọ̀ntúnwọ̀nsì, “lọ́nà tí ó yẹ àwọn obìnrin tí ó jẹ́wọ́ gbangba pé wọ́n ń fi ọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run”
7. Nítorí pé ó “ṣe inúnibíni sí ìjọ Ọlọ́run”
8. “Egungun páárì ẹ̀rẹ̀kẹ́ tútù kan ti akọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́”
9. Eéṣú
10. “Wò ó, Ọ̀dọ́ Àgùntàn Ọlọ́run!”
11. Kíndìnrín
12. Jòhánù rí àwọn alàgbà mẹ́rìnlélógún, tí wọ́n dúró fún àwọn ẹni àmì òróró tí wọ́n ń tẹ̀ lé ipasẹ̀ Jésù tí wọ́n wà ní ipò wọn lókè ọ̀run
13. “Hóró músítádì kan”
14. Sílà àti Tímótì
15. Sátánì
16. Élì, Àlùfáà àgbà
17. Ṣébà
18. Ẹja, apálá, bàrà olómi, ewébẹ̀ líìkì, àlùbọ́sà àti aáyù