Ìgbà Kan Ń Bọ̀ Tí Ẹnikẹ́ni Ò Ní Dá Wà Mọ́
NÍGBÀ tí Ọlọ́run dá ẹ̀dá èèyàn àkọ́kọ́, àkọsílẹ̀ inú Jẹ́nẹ́sísì 2:18 sọ pé: “Jèhófà Ọlọ́run sì ń bá a lọ láti wí pé: ‘Kò dára kí ọkùnrin náà máa wà nìṣó ní òun nìkan. Èmi yóò ṣe olùrànlọ́wọ́ kan fún un, gẹ́gẹ́ bí àṣekún rẹ̀.’” Kò sí ẹ̀dà èèyàn tí kì í fẹ́ kóun rẹni fojú jọ nítorí pé bí Ọlọ́run ṣe dá wa nìyẹn.
Jèhófà Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ni Ọ̀rẹ́ tó dára jù lọ tá a lè ní. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù mọ Jèhófà gẹ́gẹ́ bíi “Baba àánú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ àti Ọlọ́run ìtùnú gbogbo, ẹni tí ń tù wá nínú nínú gbogbo ìpọ́njú wa.” (2 Kọ́ríńtì 1:3, 4) Bí èyíkéyìí lára àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà bá ń jìyà, ó máa ń dun òun fúnra rẹ̀. Ọlọ́run tó máa ń gba tàwọn ẹlòmíì rò ni. “Òun fúnra rẹ̀ mọ ẹ̀dá wa, Ó rántí pé ekuru ni wá.” (Sáàmù 103:14) Ǹjẹ́ èyí ò mú kó wù ọ́ láti sún mọ́ Jèhófà Ọlọ́run kó o sì máa ṣọpẹ́ nítorí fífi tó ń fi ìfẹ́, inúure àti òye gba tiwa rò?
Jèhófà Ń Fún Àwọn Tó Dá Wà Lókun
Látijọ́, ọ̀pọ̀ lára àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run níṣòro dídá wà. Jèhófà tì wọ́n lẹ́yìn ó sì tù wọ́n nínú. Bí àpẹẹrẹ, ìwọ wo Jeremáyà tí Ọlọ́run ké sí láti jẹ́ wòlíì látìgbà èwe rẹ̀ wá. Lára àwọn ogójì èèyàn tó kọ Ìwé Mímọ́, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ Jeremáyà ló sọ̀rọ̀ jù lọ nípa bí nǹkan ṣe máa ń rí lára rẹ̀. Ó ń ṣojo, ó sì ń wo ara ẹ̀ bí ẹni tí kò tóótun nígbà tí Ọlọ́run yan iṣẹ́ rẹ̀ àkọ́kọ́ fún un. (Jeremáyà 1:6) Kó bàa lè ṣe iṣẹ́ náà yanjú, ó gbọ́dọ̀ gbára lé Jèhófà ní kíkún. Lóòótọ́, Jèhófà wà pẹ̀lú rẹ̀ “bí alágbára ńlá tí ń jáni láyà.”—Jeremáyà 1:18, 19; 20:11.
Ní nǹkan bí ọ̀ọ́dúnrún [300] ọdún ṣáájú àkókò Jeremáyà, nígbà tí Ayaba Jésíbẹ́lì gbọ́ nípa ikú àwọn wòlíì Báálì, ó búra pé òun á pa Èlíjà. Èlíjà sá, ó rìnrìn àjò tó jìnnà tó irínwó àti àádọ́ta [450] kìlómítà lọ sí iyànníyàn Hórébù, níbi Ìyawọlẹ̀ Omi Sínáì. Nígbà tó débẹ̀, ó wọnú ihò àpáta kan lọ kó lè sun ibẹ̀ mọ́jú, Jèhófà Ọlọ́run sì bi í pé: “Kí ni iṣẹ́ rẹ níhìn-ín, Èlíjà?” Èlíjà ṣàlàyé pé òun rò pé òun nìkan ni olùjọsìn Jèhófà tó ṣẹ́ kù ní gbogbo Ísírẹ́lì, wòlíì kan ṣoṣo tó kù tó nítara fún iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run. Jèhófà fi dá a lójú pé kò dá wà. Jèhófà wà pẹ̀lú rẹ̀, ẹgbẹ̀rún méje àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bíi tiẹ̀ sì tún wà pẹ̀lú rẹ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé Èlíjà ò mọ̀ bẹ́ẹ̀. Jèhófà tu Èlíjà nínú ó sì gbé ìgbàgbọ́ rẹ̀ ró. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ wọ Èlíjà lọ́kàn ṣinṣin, ó sì fún Èlíjà níṣìírí láti má ṣe fi iṣẹ́ rẹ̀ sílẹ̀. (1 Àwọn Ọba 19:4, 9-12, 15-18) Bíi ti Èlíjà, bó bá ń ṣe wá bíi pé a dá wà tàbí pé a ò já mọ́ nǹkan kan, àwa pẹ̀lú lè gbàdúrà sí Jèhófà pé kó fún wa lókun. Bákan náà, nípa lílo ìfòyemọ̀, àwọn alàgbà ìjọ Kristẹni lè sọ̀rọ̀ ìtùnú fáwọn olóòótọ́ ọkàn, kí wọ́n sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti rí ipa tí wọ́n ń kó nínú bí ète Ọlọ́run ṣe ń ní ìmúṣẹ.—1 Tẹsalóníkà 5:14.
Látinú èyí àtàwọn àpẹẹrẹ mìíràn, a lè mọrírì mímú tí Jèhófà múra tán láti tì wá lẹ́yìn kó sì fìfẹ́ tu àwọn tó nìṣòro dídá wà nínú. Bẹ́ẹ̀ ni, “Jèhófà yóò sì di ibi gíga ààbò fún ẹni tí a ni lára, ibi gíga ààbò ní àwọn àkókò wàhálà.”—Sáàmù 9:9; 46:1; Náhúmù 1:7.
Ọkùnrin Kan Tó Ní Ìmọ̀lára Tó Jinlẹ̀ Àtẹ̀mí Ìbánikẹ́dùn
Jésù Kristi jẹ́ ẹnì tó yẹ kéèyàn mọyì ẹ̀ nítorí pé ó jẹ́ àpẹẹrẹ pípé ní ti ẹni tí ìmọ̀lára ẹ̀ wà déédéé ní àfarawé Jèhófà. Lúùkù ṣàpèjúwe ohun tí Jésù ṣe nígbà tó pàdé àwọn èèyàn tí wọ́n ń tò lọ́ síbi ìsìnkú ní ìlú Náínì, ó sọ pé: “Wọ́n ń gbé ọkùnrin kan tí ó ti kú jáde, ọmọkùnrin bíbí kan ṣoṣo ìyá rẹ̀. . . . Nígbà tí Olúwa sì tajú kán rí i, àánú rẹ̀ ṣe é, ó sì wí fún un pé: ‘Dẹ́kun sísunkún.’ Pẹ̀lú èyíinì, ó sún mọ́ ọn, ó sì fọwọ́ kan agà ìgbókùú náà, àwọn tí wọ́n gbé e sì dúró jẹ́ẹ́, ó sì wí pé: ‘Ọ̀dọ́kùnrin, mo wí fún ọ, Dìde!’ Ọkùnrin tí ó ti kú náà sì dìde jókòó, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀, ó sì fi í fún ìyá rẹ̀.” (Lúùkù 7:12-15) Àánú ṣe Jésù. Ẹni tó níyọ̀ọ́nú ni. Ayọ̀ ńlá gbáà ni Jésù mú kí obìnrin opó tó dá wà náà ní nígbà tó jí ọmọkùnrin rẹ̀ dìde tó sì fà á lé e lọ́wọ́! Kò tún ní dá wà mọ́.
Àwa náà lè rí ẹ̀rí tó fi hàn dájú pé Jésù lè “báni kẹ́dùn fún àwọn àìlera wa.” Ó dájú pé ó máa ń bá àwọn ẹni ìdúróṣinṣin tí wọ́n dá wà kẹ́dùn. Kódà, nípasẹ̀ rẹ̀ “a lè rí àánú gbà, kí a sì rí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí fún ìrànlọ́wọ́ ní àkókò tí ó tọ́.” (Hébérù 4:15, 16) A lè bá àwọn tó ń banú jẹ́, tójú ń pọ́n, tí wọ́n sì dá wà kẹ́dùn bá a bá ń fara wé Jésù. Agbára káká la ó fi dá wà bá a bá ń ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́. Ṣùgbọ́n ọ̀nà mìíràn ṣì wà tá a lè gbà rí ìrànlọ́wọ́ láti borí èrò búburú tí dídá wà máa ń mú wá.
Ọ̀rọ̀ Jèhófà Lè Ràn Wá Lọ́wọ́ Láti Borí Dídá Wà
Ọ̀pọ̀ ti rí i pé “nípasẹ̀ ìtùnú láti inú Ìwé Mímọ́ . . . a lè ní ìrètí.” Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kún fún ìmọ̀ràn wíwúlò tó lè ràn wá lọ́wọ́ láti borí dídá wà. (Róòmù 15:4; Sáàmù 32:8) Bí àpẹẹrẹ, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbà wá níyànjú pé ‘ká má ṣe ro ara wa ju bí ó ti yẹ ní rírò lọ.’ (Róòmù 12:3) Láti lè fi ìmọ̀ràn yìí sílò, a ní láti yí ọ̀nà tá a gbà ń ronú padà. Ó dájú pé ìwà ìrẹ̀lẹ̀ àti wíwà níwọ̀ntúnwọ̀nsì, ìyẹn ni mímọ̀ pé ó láwọn ibì kan tá a kù díẹ̀ káàtó sí, á ràn wá lọ́wọ́ láti má ṣe retí ohun tó pọ̀ jù lọ́wọ́ ara wa, ká sì máa fòye bá ara wa lò. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tún gbà wá níyànjú láti ní ojúlówó ìfẹ́ nínú ire àwọn ẹlòmíràn. (Fílípì 2:4) Oore kì í gbé. Bá a bá ṣoore fáwọn ẹlòmíì, àwa náà á rí oore gbà. Níní ìbákẹ́gbẹ́ rere pẹ̀lú àwọn ẹlòmíì máa ń mú kí ìṣòro dídá wà fúyẹ́, á sì jẹ́ kí ìgbésí ayé wa nítumọ̀.
Gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni, Bíbélì gbà wá níyànjú pé ‘kí a má ṣe kọ ìpéjọpọ̀ ara wa sílẹ̀.’ (Hébérù 10:24, 25) Nítorí náà, máa ṣe ohun tó bá ní láárí, irú bíi lílọ sí ìpàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà déédéé. Láìsí àníàní, àwọn ìpàdé Kristẹni lè mú kí ipò tẹ̀mí wa sunwọ̀n sí i, kí ọkàn wa balẹ̀, kí ara wa sì yá gágá. Sísọ̀rọ̀ ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fáwọn ẹlòmíràn jẹ́ ọ̀nà kan tó lárinrin tá a lè gbà mú kọ́wọ́ wá dí fún ìgbòkègbodò gbígbámúṣé. Ó ń mú kí ọkàn wa pa pọ̀ sórí ohun tó tọ́, ó ń fún ìgbàgbọ́ wa lókun ó sì ń pa ìrètí wa mọ́.—Éfésù 6:14-17.
Sún mọ́ Jèhófà nínú àdúrà. Dáfídì gbà wá níyànjú pé: “Ju ẹrù ìnira rẹ sọ́dọ̀ Jèhófà fúnra rẹ̀, Òun fúnra rẹ̀ yóò sì gbé ọ ró.” (Sáàmù 55:22) Wà á máa láyọ̀ bó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (Sáàmù 1:1-3) Bí ìrònú nípa ìṣòro dídá wà bá ń gbà ọ́ lọ́kàn, máa ṣàṣàrò lórí bí Jèhófà ṣe ń fìfẹ́ bójú tó wa, gẹ́gẹ́ báa ṣe rí i nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Onísáàmù náà kọ̀wé pé: “Ọkàn mi ti ń lẹ̀ mọ́ ekuru. Pa mí mọ́ láàyè ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ rẹ.”—Sáàmù 119:25.
Ìgbà Kan Ń Bọ̀ Tí Kò Sẹ́ni Tí Yóò Sọ Pé, “Mo Ní Ìṣòro Dídá Wà” Mọ́
Jèhófà Ọlọ́run ti ṣèlérí ayé tuntun kan fún wa nínú èyí tí kò ní sí àníyàn, ìjákulẹ̀ àti èròkérò mọ́. Bíbélì sọ pé: “Yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.” (Ìṣípayá 21:4) Bẹ́ẹ̀ ni, lára àwọn ohun àtijọ́ tí yóò kọjá lọ yẹn ni àwọn ìrora tá a máa ń ní lónìí, irú bí ìṣòro nípa tara, ti ọpọlọ àti ti ìrònú.
Ayé á kún fún àwọn èèyàn oníwà-bí-ọ̀rẹ́ tí wọn á mú káyé dùn-ún gbé fún wa. Nípasẹ̀ Ìjọba rẹ̀ lókè ọ̀run, lábẹ́ ìdarí Jésù Kristi, Jèhófà á wo ìṣòro dídá wà ní àwòtán. Yóò fún wa láwọn nǹkan tuntun àtàwọn nǹkan àgbàyanu láti ṣe nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé. Ọjọ́ náà máa tó dé tá ò tún ní sọ láé mọ́ pé, “Mo níṣòro dídá wà.”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8, 9]
Pẹ̀lú ìtìlẹyìn Jèhófà, a ò ní dá wà kódà, nígbà tó bá ṣe àwa nìkan
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Kí la rí kọ́ látinú ohun tí Bíbélì sọ fún wa nípa Jeremáyà àti Èlíjà?