Ori 1
Ifẹ-Ọkan fun Alaafia ati Àìléwu Kárí-Ayé
1, 2. Aini kanjukanju wo ni gbogbo araye ní, eesitiṣe?
ALAAFIA ati àìléwu ni ohun ti a ń fẹ nihin-in lori ilẹ̀-ayé. Aini naa fun iru ipo fifanilọkanmọra bẹẹ ko tii fi ìgbà kan rí jẹ́ kanjukanju tó bi o ti jẹ lonii. Eyi jẹ́ otitọ kii ṣe kìkì pẹlu wa gẹgẹ bi ẹnikọọkan nikan ṣugbọn pẹlu gbogbo idile eniyan pata yika ilẹ̀-ayé.
2 Idi niyẹn ti apapọ iye awọn eniyan ti ń gbe ori ilẹ̀-ayé fi ń gbe nisinsinyi ni akoko didayatọ julọ ninu itan! Iwọ lè beere pe, ‘Bawo ni ọran naa ṣe lè ri bẹẹ, niwọn ìgbà ti a ti rìn jinna ninu sáà ti o kun fun jìnnìjìnnì julọ ninu gbogbo itan eniyan, sanmani ohun ija alagbara atọmiki?’
3. (a) Ki ni wọn sọ pe ó jẹ́ idi rẹ̀ ti awọn orilẹ-ede fi ń ní bọmbu alagbara atọmiki ní-ìní? (b) Ki ni laakaye lásán yoo sọ funni?
3 Orilẹ-ede mẹjọ ó keretan ni a ti rohin pe wọn dangajia tó lati maa pese bọmbu alagbara atọmiki. A si ṣe idiwọn rẹ̀ pe orilẹ-ede 31 lè ní awọn ohun ija alagbara atọmiki nigba ti ó ba fi maa di ọdun 2000. Wọn sọ pe idi ti wọn fi ní eyi ti ó tayọ julọ ninu awọn bọmbu ní-ìní jẹ́ nititori idaabobo, idilọwọ fun awọn orilẹ-ede miiran ti wọn dira ogun bakan naa, ihalẹmọni niti ìforóyáró ti agbara atọmiki. Loju iru ipo awọn alamọri ayé bẹẹ, laakaye lásán yoo sọ funni pe o yẹ ki awọn orilẹ-ede fohunṣọkan lati gbe papọ ní ifẹgbẹkẹgbẹ pẹlu riri ara-gba-nǹkan-sí fun tọtuntosi.
4. Bi o tilẹ jẹ pe Ẹlẹ́dàá naa kò dínà awọn isapa eniyan lati wá àìléwu, ète wo ni oun ní niti ọran yii?
4 Bi o ti wu ki o ri, alaafia àtọwọ́ eniyan lasan dá ha ni a ń fẹ, papọ pẹlu àìléwu ti eniyan bá lè pese bi? Bi o tilẹ jẹ pe Ẹlẹ́dàá naa kò dínà awọn isapa eniyan lati fi alaafia ati àìléwu mulẹ kárí-ayé ki wọn si maa baa lọ bẹẹ, oun ní ọna pipe tirẹ̀ fun títẹ́ ifẹ-ọkan abinibi wa fun alaafia ati àìléwu lọ́rùn. O ní akoko tirẹ̀ ti oun ti yàn lati fopinsi gbogbo awọn oluyọ àìléwu awọn wọnni ti wọn fẹ lati jọsin rẹ̀ lẹnu. Ẹ wo bi awa ṣe lè layọ tó lati mọ̀ pe akoko rẹ̀ fun eyi ti kù si dẹ̀dẹ̀!
5. Ki ni olorin ti a misi naa sọ nipa ilẹ̀-ayé, ki sì ni ète Ẹlẹ́dàá fun eniyan?
5 Lẹhin ẹgbẹẹgbẹrun ọdun onirudurudu ti itan eniyan, o yẹ ki a fojusọna pe ifẹ-ọkan gbígbóná janjan kárí-ayé nilati wà fun alaafia ati àìléwu. Ilẹ̀-ayé ti jẹ́ ibi ibugbe adanida ti eniyan lati ibẹrẹ ọjọ-aye ẹda eniyan gan-an. Olorin ti a misi naa sọ pe: “Ọrun ani ọ̀run ni ti Oluwa, ṣugbọn ayé ni ó fifun awọn ọmọ eniyan.” (Orin Dafidi 115:16) Lati ibẹrẹpẹpẹ gan-an, ète onifẹẹ ti Ẹlẹ́dàá naa ni pe ki eniyan gbadun ẹkunrẹrẹ iwalaaye ninu ile rẹ̀ ti ilẹ̀-ayé tí Ọlọrun fifun un.
6. Ní ọna wo ni ọkunrin akọkọ ati awọn ọmọ-inu rẹ̀ ìbá ti lè gbe igbesẹ bii ti Ọlọrun?
6 Gẹgẹ bi akọsilẹ ìṣẹ̀dá ninu Genesisi 2:7 ti wi, “Ọlọrun si fi erupẹ ilẹ mọ eniyan; o si mí ẹmi iye si iho imu rẹ̀, eniyan si di alaaye ọkàn.” Kò si ẹda alaaye eyikeyii miiran lori ilẹ̀-ayé ti ó wà lori ipele-ìwọ̀n iwalaaye ti eniyan tabi lori ipò-ìwọ̀n ipegede ti eniyan—ti ó ṣeeṣe fun lati lè gbe igbesẹ bii ti Ọlọrun niti lilo aṣẹ iṣakoso. Siwaju sii, aṣẹ iṣakoso yii ni a kì yoo fimọ sọdọ ẹda eniyan akọkọ ṣugbọn o jẹ́ ohun tí awọn ọmọ-inu rẹ̀ yoo lo ti wọn yoo si gbadun pẹlu.
7. Bawo ni Adamu ṣe wá ní aya kan, ki ni o si wi nigba ti a fi ẹ̀dá pipe yii fun un tán?
7 Nitori idi yẹn, Ẹlẹ́dàá naa fun Adamu ní aya kan. Oun ni yoo wá jẹ́ iya gbogbo eniyan olugbe ilẹ̀-ayé ní ẹhin-ọla. Idi rẹ̀ niyẹn ti ọkunrin naa fi lè sọ, nigba ti a fi ẹda pipe yii fun un tán pe: “Eyiyii ni egungun ninu egungun mi, ati ẹran-ara ninu ẹran-ara mi.” Nitori naa o pè é ní abo irú-ẹ̀dá eniyan, ’ish·shahʹ, eyi ti ó jẹ́ abo ẹ̀dà ọ̀rọ̀ Heberu naa ti a tumọ si ọkunrin, eyiini ni, ’ish.—Genesisi 2:21-23.
8. Awọn itọni wo ni Ẹlẹ́dàá fifun tọkọtaya eniyan akọkọ naa?
8 Ẹlẹ́dàá ati Baba ọ̀run naa sọ fun tọkọtaya eniyan akọkọ naa pe: “Ẹ maa bisii, ki ẹ si maa rẹ̀, ki ẹ si gbilẹ, ki ẹ si ṣe ikawọ rẹ̀.” (Genesisi 1:28) Ilana yii jẹ́ ohun titun kan patapata gbaa ninu itan ìṣẹ̀dá ọlọgbọnloye. Awọn ẹ̀dá ẹmi olugbe inu awọn ọ̀run ti a kò lè fojuri ni a kò muwa si iwalaaye nipasẹ ibimọ.
9. Bawo ni Orin Dafidi 8:4, 5 ṣe ṣapejuwe iṣeto awọn nǹkan latọrunwa?
9 Abajọ ti o fi jẹ pe, nigba ìṣẹ̀dá ilẹ̀-ayé, “awọn irawọ owurọ jumọ kọrin pọ̀, ti gbogbo awọn ọmọ Ọlọrun ń ho iho ayọ̀.” (Jobu 38:7) Ní akoko yẹn, gbogbo nǹkan wà ní alaafia ati ní iṣọkan jakejado gbogbo agbaye. Ninu Orin Dafidi kẹjọ, bi olorin naa ti kun fun inudidun nipa iṣeto awọn nǹkan latọrunwa, o ṣe saafula nipa eniyan pe: “Iwọ saa da a ní onirẹlẹ diẹ ju [“awọn ẹni bi,” NW] Ọlọrun lọ, iwọ si ti fi ogo ati ọlá de e ní ade.” (Orin Dafidi Ẹsẹ 4, 5) Gẹgẹ bi Orin Dafidi yii ti wí, Ọlọrun fi ohun gbogbo nihin-in lori ilẹ̀-ayé sabẹ ẹsẹ eniyan.
Ibẹrẹ Ipo Ọba-Alaṣẹ Abanidije Kan
10. (a) Ṣaaju ki a tó loyun ọmọ eniyan akọkọ, ki ni bẹsilẹ? (b) Ki ni a lè tipa bayii gbekalẹ lori iran-eniyan?
10 Lọna ti o ṣeni ni kayeefi, ṣaaju ki a tó loyun ọmọ eniyan akọkọ, ọ̀tẹ̀ bẹsilẹ ninu ètò-àjọ agbaye ti Jehofa Ọlọrun. Ipo naa lè jalẹ si gbigbe ipo ọba-alaṣẹ titun kan, agbara iṣakoso gigadabu titun kan kalẹ̀, lori iran eniyan—bi o ba ṣeeṣe lati pin iran-eniyan niya ki a si sọ ọ di ajeji si ètò-àjọ agbaye ti Jehofa. Ipo ọba-alaṣẹ kan ni a lè gbekalẹ ní ibaradije pẹlu tirẹ̀. Eyi beere fun pipa irọ akọkọ, eyi ti ń fi Jehofa Ọlọrun hàn lọna odi.
11. Nipa fifi Jehofa Ọlọrun han lọna odi, ọlọ̀tẹ̀ akọkọ di ki ni?
11 Eke ṣiṣe akọkọ naa sọ ọlọ̀tẹ̀ akọkọ yii si Ọlọrun di opurọ akọkọ, eṣu akọkọ, tabi abanilorukọjẹ. Ní iyatọ patapata si i, Jesu Kristi wi pe: “Emi ni ọna, ati otitọ ati iye.” (Johannu 14:6) Jesu sọ fun awọn alatako rẹ̀ onisin pe: “Ti Eṣu baba yin ni ẹyin ń ṣe, ifẹkufẹẹ baba yin ni ẹ si ń fẹ ṣe. Apaniyan ni oun lati atetekọṣe, ko si duro ninu otitọ; nitori ti kò si otitọ ninu rẹ̀. Nigba ti ó ba ń ṣeke, ninu ohun tirẹ̀ ni ó ń sọ, nitori eke ni, ati baba eke.”—Johannu 8:44.
12. (a) Bawo ni Eṣu ṣe mu ki a pa irọ akọkọ, ki si ni iyọrisi rẹ̀ lori Efa? (b) Ki ni o yọrisi nigba ti Adamu jẹ eso ti a kàléèwọ̀ naa?
12 Nipa sisọrọ nipasẹ ejo kan ninu ọgba Edeni, tabi paradise idunnu, Eṣu mu ki a gbé irọ akọkọ kalẹ niwaju obinrin akọkọ naa. O sọ pe Ẹlẹ́dàá obinrin naa jẹ́ opurọ, o si tipa bayii da alaafia ero-inu Efa rú. O mu ki ó nimọlara ailaabo ninu ipo aimọkan ti o finuwoye pe oun wà, nitori naa ó jẹ ninu eso ti a kàléèwọ̀ naa. Obinrin naa yí ọkọ rẹ̀, Adamu, leropada lati ṣalabaapin ninu eso ti a kàléèwọ̀ naa pẹlu rẹ̀ ti ó si tipa bayii darapọ mọ ọn ninu ìṣọ̀tẹ̀ rẹ̀ si Jehofa Ọlọrun. (Genesisi 3:1-6) Tọkọtaya alaigbọran naa padanu alaafia wọn pẹlu Ọlọrun ti a si lé wọn jade kuro ninu paradise idunnu naa lati lọ maa gbé ninu ipo ailaabo lẹhin-ode. Romu 5:12 ṣapejuwe ipo-ọran aṣenilaaanu yii, ní sisọ pe: “Nitori gẹgẹ bi ẹṣẹ ti tipa ọdọ eniyan kan wọ ayé, ati iku nipa ẹṣẹ; bẹẹni iku si kọja sori eniyan gbogbo, lati ọdọ ẹni ti gbogbo eniyan ti dẹṣẹ.”
13. Yíyàn wo ni ẹnikọọkan wa gbọdọ ṣe lonii?
13 Ipo ọjọ wa ń beere fun ṣiṣe yíyàn pato kan lọwọ wa. O jẹ́ yíyàn kan laaarin ipo ọba-alaṣẹ abanidije ti Satani Eṣu, “ọlọrun ayé yii,” ati ipo ọba-alaṣẹ ti Jehofa, Ẹni Giga Julọ ati Ọlọrun Olodumare ti agbaye.—2 Korinti 4:4; Orin Dafidi 83:18.
Ọna Lati Gbadun Alaafia Pẹlu Ọlọrun
14. Alaafia ati àìléwu wo ni a lè bẹrẹsii gbadun rẹ̀ ani nisinsinyi paapaa?
14 Pẹlu ọṣẹ́ aronilara fun araawọn, ọpọ julọ ninu araye kò fẹ lati tẹwọgba tabi lati gbagbọ ninu ipese Ọlọrun Olodumare fun awọn olujọsin rẹ̀ lati gbadun alaafia ati àìléwu bi o ba ti lè ṣeeṣe to ani ninu ipo bibanininujẹ julọ yii ninu awọn alamọri eniyan. Bi o ti wu ki o ri, Jehofa ni “Ọlọrun alaafia,” o si jẹ́ anfaani onibukun kan fun wa nisinsinyi lati wọnu alaafia ati àìléwu ti ki yoo kuna lae. (Romu 16:20; Filippi 4:6, 7, 9) Ani nisinsinyi paapaa o jẹ́ alaafia ati àìléwu ti oun ń fifun ẹgbẹ awọn iranṣẹ rẹ̀ lori ilẹ̀-ayé, ètò-àjọ rẹ̀ ti a lè fojuri, ní imuṣẹ awọn ileri rẹ̀ ti wọn ṣee gbarale nigba gbogbo. O jẹ́ alaafia ati àìléwu ti a lè gbadun kiki ninu ibakẹgbẹpọ pẹlu ètò-àjọ rẹ̀ ti a lè fojuri lori ilẹ̀-ayé.
15. O ha ṣailọgbọn ninu lati ronu pe Ọlọrun ní ètò-àjọ kan, ki si ni ohun ti Jesu Kristi mọ̀?
15 Kò ní bá awọn ẹkọ ṣiṣe kedere ti inu Iwe Mímọ́ mu lati gbagbọ pe Ọlọrun kò ní ètò-àjọ kan, awọn eniyan kan ti ó ṣetojọ, ti oun mọ̀ lọna ti a yasọtọ gedegbe. Jesu Kristi mọ̀ pe Baba rẹ̀ ọ̀run ní ètò-àjọ kan ti a lè fojuri. Titi di Pentekosti 33 C.E., o jẹ́ ètò-àjọ awọn Ju ninu ipo ibatan onimajẹmu pẹlu Jehofa Ọlọrun labẹ Ofin Mose.—Luku 16:16.
16. (a) Laaarin awọn wo ni Mose ti jẹ́ alarina? (b) Laaarin awọn wo ni Mose Gigaju naa, Jesu Kristi, ti jẹ́ Alarina?
16 Gan-an gẹgẹ bi orilẹ-ede Israeli igbaani ti wà ninu ipo ibatan onimajẹmu pẹlu Jehofa Ọlọrun nipasẹ Mose ti ó jẹ́ alarina, bakan naa ní orilẹ-ede Israeli tẹmi, “Israeli Ọlọrun,” ṣe ní ipo ibatan onimajẹmu nipasẹ alarina kan. (Galatia 6:16) O jẹ́ gẹgẹ bi aposteli Paulu ti kọwe si Kristian oṣiṣẹ ẹlẹgbẹ rẹ̀: “Ọlọrun kan ni ń bẹ, ati alarina kan laaarin Ọlọrun ati eniyan, Kristi Jesu, eniyan.” (1 Timoteu 2:5, NW) Mose ha ni alarina laaarin Jehofa Ọlọrun ati araye lapapọ bi? Ó tì o, oun jẹ́ alarina laaarin Ọlọrun Abrahamu, Isaaki ati Jakọbu ati orilẹ-ede awọn atọmọdọmọ wọn nipa ti ara. Bẹẹ gẹgẹ, Mose Gigaju naa, Jesu Kristi, kii ṣe Alarina laaarin Jehofa Ọlọrun ati gbogbo araye. Oun jẹ́ Alarina laaarin Baba rẹ̀ ọ̀run, Jehofa Ọlọrun, ati orilẹ-ede Israeli tẹmi, eyi ti a fimọ si kìkì mẹmba 144,000. Orilẹ-ede tẹmi yii dabi agbo kekere kan ti awọn ẹni-bi-agutan ti Jehofa.—Romu 9:6; Ìfihàn 7:4.
Oluṣọ-Agutan Lori Ohun Ti Ó Ju “Agbo Kekere” naa Lọ
17. (a) Ki ni Jehofa Ọlọrun ti yan Jesu Kristi lati jẹ́? (b) Ki ni Jesu sọ fun awọn wọnni ti wọn yoo jogun Ijọba ti ọ̀run?
17 Ninu Orin Dafidi 23:1, Ọba Dafidi ti Israeli igbaani ni a misi lati sọ pe: “Oluwa [“Jehofa,” NW] ni Oluṣọ-agutan mi; emi ki yoo ṣe alaini.” Jehofa, Oluṣọ-Agutan Onipo-Ajulọ naa, ti yan Jesu Kristi lati jẹ́ “oluṣọ-agutan rere.” (Johannu 10:11) Ninu Luku 12:32, Jesu funraarẹ bá awọn wọnni ti oun jẹ́ Oluṣọ-Agutan Rere fun sọrọ taarata pe: “Má bẹru, agbo kekere; nitori didun inu Baba yin ni lati fi ijọba fun yin.”
18. (a) Awọn wo lonii ni wọn ṣerẹgi pẹlu ọpọ eniyan ti o dàpọ̀ mọ́ ti o si fi Egipti silẹ pẹlu awọn ọmọ Israeli? (b) Pẹlu awọn wo ni wọn ní ibakẹgbẹpọ timọtimọ?
18 Ní igbaani, awọn ti wọn kii ṣe Ju wà, iru bii ọpọ eniyan ti o dàpọ̀ mọ́ ti o si fi Egipti silẹ pẹlu orilẹ-ede Israeli. (Eksodu 12:38) Bakan naa lonii, awọn ọkunrin ati obinrin wà ti wọn ti ya araawọn si mímọ́ patapata fun Ọlọrun nipasẹ Jesu Kristi ṣugbọn ti wọn kii ṣe ọmọ Israeli nipa tẹmi. Bi o ti wu ki o ri, wọn ní ibakẹgbẹpọ pẹlu àṣẹ́kù Israeli tẹmi nitori pe wọn ya araawọn si mímọ́ fun Jehofa Ọlọrun nipasẹ Jesu Kristi, “ẹni ti o fi araarẹ̀ ṣe irapada fun gbogbo eniyan.” (1 Timoteu 2:6) Lonii, awọn wọnyi pọ̀ níye gan-an ju awọn 144,000 ọmọ Israeli nipa tẹmi, ti wọn yoo jogun Ijọba ti ọ̀run.
19. Ki ni Jesu Kristi sọ lati fihan pe oun yoo jẹ́ Oluṣọ-Agutan lori eyi ti ó ju “agbo kekere” naa lọ?
19 Nipa bayii Jesu Kristi ní a o pin iṣẹ fun, ní akoko yíyẹ ti Ọlọrun, lati jẹ́ Oluṣọ-Agutan lori agbo awọn ẹni-bi-agutan ti wọn tubọ pọ̀ ju bẹẹ lọ ti yoo jogun ilẹ̀-ayé nipasẹ rẹ̀. Awọn wọnyi ni oun ní lọkan nigba ti o wi pe: “Emi si ni awọn agutan miiran, ti kii ṣe ti agbo yii: awọn ni emi kò lè ṣe alaimu wá pẹlu, wọn o si gbọ ohun mi; wọn o si jẹ́ agbo kan, oluṣọ-agutan kan.” Ní níní “awọn agutan miiran” wọnyi lọkan, aposteli Johannu tun kọwe nipa Jesu pe: “Oun si ni etutu fun ẹṣẹ wa: kii sii ṣe fun tiwa nikan, ṣugbọn fun ti gbogbo araye pẹlu.”—Johannu 10:16; 1 Johannu 2:2.
20. (a) Bawo ni a ṣe lè fi iye awọn “agutan miiran” naa wera pẹlu awọn ti wọn ṣẹku ninu “agbo kekere” naa? (b) Ki ni ohun ti iṣẹ abojuto onitọọju ti Oluṣọ-Agutan Rere naa tumọsi fun gbogbo wọn?
20 Lonii, nǹkan bii 9,000 ni wọn sọ pe awọn jẹ́ mẹmba àṣẹ́kù “agbo kekere” ti awọn agutan tẹmi. Ní odikeji ẹ̀wẹ̀, ọpọ million awọn oluṣeyasimimọ ni wọn wà ti wọn ń kẹgbẹpọ pẹlu àṣẹ́kù awọn ẹni-ami-ororo naa ní titẹle ipasẹ Oluṣọ-Agutan Rere naa, Jesu Kristi. A lè ri wọn ní eyi ti o ju 200 ilẹ lọ yika ilẹ̀-ayé. Ki ni ohun ti iṣẹ abojuto onitọọju ti Oluṣọ-Agutan Rere naa tumọsi fun gbogbo wọn? O tumọsi ìjẹ̀gbádùn alaafia ati àìléwu! Bi wọn kò bá ní alaafia ninu òtú wọn, ki yoo si iṣọkan atọkanwa ati ifọwọsowọpọ alaileṣeefọ laaarin wọn. Bi wọn kò ba ní aniyan onifẹẹ fun tọtuntosi niti awọn ire tẹmi, wọn ki bá ti ní àìléwu naa ti wọn ń gbadun. Nipa bayii, ifẹ-ọkan wọn fun alaafia ati àìléwu kari ilẹ̀-ayé ni a ti bẹrẹsii tẹlọrun ani nisinsinyi paapaa.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4, 5]
Ẹlẹ́dàá naa ní ọna pipe tirẹ̀ fun titẹ ifẹ-ọkan eniyan fun alaafia ati àìléwu lọrun