Ki Ni Nipa “Awọn Ẹsẹ Iwe Àfiṣẹ̀rí fun” Mẹtalọkan?
AWỌN kan ti sọ pe awọn ẹsẹ Bibeli kan npese ẹ̀rí ni ìtìlẹ́hìn fun Mẹtalọkan. Bi o ti wu ki o rí, nigba ti a bá ńkà irufẹ awọn ẹsẹ bẹẹ, a gbọdọ fi sọ́kàn pe awọn ẹ̀rí Bibeli ati ìtàn kò tì Mẹtalọkan lẹ́hìn.
Itọkasi eyikeyii ninu Bibeli tí a fifúnni gẹgẹ bi ẹ̀rí ni a gbọdọ lóye ninu àyíká ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ gbogbo Bibeli pata tí ó baramu delẹdelẹ. Lọpọ igba ni ó maa ńjẹ́ pe itumọ tootọ iru ẹsẹ bẹẹ ni ọ̀rọ̀ awọn ẹsẹ̀ tí wọn yí i ká maa ńmu ṣe kedere.
Mẹta Ninu Ọ̀kan
NEW Catholic Encyclopedia fúnni ni mẹta lára iru “awọn ẹsẹ iwe àfiṣẹ̀rí” bẹẹ ṣugbọn ó gbà pẹlu pe: “Ẹ̀kọ́ Mẹtalọkan Mímọ́ ni a kò fi kọ́ni ninu M[ajẹmu] L[aelae]. Ninu M[ajẹmu T[itun] ẹ̀rí tí ó pẹ julọ wà ninu awọn lẹta Pọọlu, pàápàá julọ 2 Kọr 13.13 [ẹsẹ̀ 14 ninu awọn Bibeli miiran], ati 1 Kọr 12.4-6. Ninu awọn Iwe Ihinrere ẹ̀rí Mẹtalọkan ni a rí lọna kedere ní kíkún kìkì ninu ìlànà àwòṣiṣẹ́ ti baptism ninu Mat 28.19.”
Ninu awọn ẹsẹ̀ wọnni “awọn ẹni” mẹta naa ni a tò lẹ́sẹẹsẹ bí wọn ṣe tẹ̀le e yii ninu The New Jerusalem Bible. Iwe Keji Kọrinti 13:13 (14) mú awọn mẹtẹẹta papọ̀ ní ọ̀nà yii: “Oore-ọ̀fẹ́ Jesu Kristi Oluwa, ìfẹ́ ti Ọlọrun ati ìdàpọ̀ ti ẹ̀mí mímọ́ kí ó maa wà pẹlu gbogbo yin.” Iwe Kìn-ínní Kọrinti 12:4-6 sọ pe: “Ọpọlọpọ oniruuru awọn ẹ̀bùn ni wọn wà, ṣugbọn Ẹmi kan naa ni nigba gbogbo; ọpọ oniruuru awọn ìṣiṣẹ́sìn ni wọn wà, ṣugbọn Oluwa kan naa nigba gbogbo. Oniruuru awọn ètò igbokegbodo ni wọn wà, ṣugbọn ninu olukuluku Ọlọrun kan naa ni ó ńṣiṣẹ́ ninu gbogbo wọn pata.” Matiu 28:19 sì kà pe: “Nitori naa ẹ lọ, ẹ maa kọ́ orilẹ-ede gbogbo, kí ẹ sì maa baptisi wọn ní orúkọ Baba, ati niti Ọmọkunrin ati niti Ẹ̀mí Mímọ́.”
Awọn ẹsẹ̀ wọnyẹn ha sọ pe Ọlọrun, Kristi, ati ẹ̀mí mímọ́ parapọ̀ jẹ́ Ọlọrun ẹlẹni mẹ́ta ti awọn ẹlẹkọọ Mẹtalọkan bí, pe awọn mẹtẹẹta dọ́gba ninu ohun-ti-ara, agbára, ati ayérayé? Bẹẹkọ, wọn kò ṣe bẹẹ, bí a ko ti le reti ki ẹni mẹta ti a kọ orukọ wọn silẹ, iru bii Tom, Dick, ati Harry, tumọsi ẹni mẹta ninu ọ̀kan.
Iru itọkasi yii, ni Cyclopedia of Biblical, Theological, and Ecclesiastical Literature lati ọwọ́ McClintock ati Strong gbà pe, “ó fẹ̀rí hàn pe awọn ẹni mẹta ni a dárúkọ . . . ṣugbọn kò fẹ̀rí hàn, ninu araarẹ̀, pe gbogbo awọn mẹta naa jẹ́ ti ẹni ọrun naa, tí wọn sì ní ọlá àtọ̀runwá tí ó dọ́gba.”
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pe oun jẹ́ alátílẹ́hìn Mẹtalọkan, orísun yẹn sọ nipa 2 Kọrinti 13:13 (14) pe: “Awa kò lè de ipari ero ti o jẹ otitọ pe wọn ní àṣẹ didọ́gba, tabi jẹ ẹni kan naa. Niti Matiu 28:18-20 ó sọ pe: “Ẹsẹ yii, bi ó ti wu ki o ri, bí a bá wo o ninu araarẹ̀, kì yoo fẹ̀rí alaiṣiyemeji han niti yálà ipò jíjẹ́ ẹni kan ti awọn ẹni mẹta tí a mẹnukan tabi ìbáradọ́gba tabi ìjẹ́ tí ọ̀run wọn.”
Nigba ti a baptisi Jesu, Ọlọrun, Jesu, ati ẹ̀mí mímọ́ ni a mẹnuba pẹlu ní àyíká ọ̀rọ̀ kan naa. Jesu “rí ẹ̀mí Ọlọrun tí ó sọ̀kalẹ̀ bí àdàbà, ó sì bà lé e.” (Matiu 3:16) Eyi, bi o ti wu ki o ri, kò sọ pe awọn mẹta naa jẹ́ ọ̀kan. Aburahamu, Isaaki, ati Jakọbu ni a mẹnuba papọ̀ niye igba, ṣugbọn iyẹn kò sọ wọn di ọ̀kan. Peteru, Jakọbu, ati Johanu ni a dárúkọ papọ̀, ṣugbọn iyẹn kò sọ wọn di ọ̀kan bakan naa. Siwaju sii, ẹ̀mí Ọlọrun bà lé Jesu nígbà baptism rẹ̀, ní fifihan pe Jesu ni ẹ̀mí kò bà lé títí di ìgbà yẹn. Bí eyi ti jẹ́ bẹẹ, bawo ni oun ṣe lè jẹ́ apákan Mẹtalọkan nibi ti oun ti wà ní ọ̀kanṣoṣo pẹlu ẹ̀mí mímọ́ naa?
Itọka miiran tí ó sọ̀rọ̀ nipa awọn mẹta naa papọ̀ ni a rí ninu awọn ìtumọ̀ atijọ ti Bibeli ní 1 Johanu 5:7. Awọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́ jinlẹ̀ mọ̀ daju, bi o ti wu ki o ri, pe awọn ọ̀rọ̀ wọnyi kò sí ninu Bibeli ní ìpilẹ̀ṣẹ̀ ṣugbọn a fi wọn kún un lẹhin naa. Ọpọ julọ awọn olùtúmọ̀ ode-oni si ti fi ẹ̀tọ́ fò ẹsẹ̀-ìwé onímàgòmágó ayédèrú yii dá.
“Awọn ẹsẹ iwe àfiṣẹ̀rí” miiran sọ̀rọ̀ kìkì nipa ìbátan laaarin awọn meji—Baba ati Jesu. Ẹ jẹ́ kí a gbé diẹ lara wọn yẹ̀wò.
“Ọ̀kan ni Emi ati Baba Jásí”
ẸSẸ yẹn, ní Johanu 10:30, ni wọn saba maa ńtọ́kasí lati ṣetilẹhin fun Mẹtalọkan, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pe a kò mẹnuba ẹni kẹta kan níhìn-ín. Ṣugbọn Jesu fúnraarẹ̀ fi ohun tí ó nílọ́kàn nipa jíjẹ́ “ọ̀kan” pẹlu Baba rẹ̀ hàn. Ní Johanu 17:21, 22, oun gbadura sí Ọlọrun pe kí awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ “lè jẹ́ ọ̀kan; gẹgẹ bi iwọ, Baba, ti jẹ́ ninu mi, ati emi ninu rẹ, kí awọn pẹlu kí ó lè jẹ́ ọ̀kan ninu wa: . . . kí wọn kí ó lè jẹ́ ọ̀kan, gẹgẹ bi awa ti jẹ́ ọ̀kan.” Jesu ha ngbadura pe kí gbogbo awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ lè jẹ́ ẹni wiwa kanṣoṣo bi? Bẹẹkọ, ó han gbangba pe Jesu ngbadura pe kí wọn wà ní ìrẹ́pọ̀ ní ironu ati ète, bí oun ati Ọlọrun ti jẹ́.—Tún wo 1 Kọrinti 1:10.
Ní 1 Kọrinti 3:6, 8, Pọọlu sọ pe: “Emi gbìn, Apolo bomirin; . . . Ẹni tí ńgbìn, ati ẹni tí ńbomirin, ọ̀kan ni wọn jásí.” Pọọlu kò ni in lọ́kàn pe oun ati Apolo jẹ́ awọn ẹni meji ninu ẹyọkan; oun ni in lọ́kàn pe wọn sopọ̀sọ̀kan ní ète. Ọ̀rọ̀ Giriiki tí Pọọlu lò níhìn-ín fun ọ̀kan (hen) jẹ́ ti kòṣakọ-kòṣabo, tí ó tumọ ní ṣáńgílítí sí “(ohun) kan,” tí ó tọka sí jìjẹ́ ọ̀kan ninu ìfọwọ́sowọ́pọ̀. Ọ̀rọ̀ kan naa ni Jesu lò ní Johanu 10:30 lati ṣapejuwe ìbátan rẹ̀ pẹlu Baba rẹ̀. Oun tún ni ọ̀rọ̀ kan naa tí Jesu lò ní Johanu 17:21, 22. Nitori naa nigba ti oun lò ọ̀rọ̀ naa “ọ̀kan” (hen) ninu awọn ọ̀ràn wọnyi, oun ńsọ̀rọ̀ nipa ìsopọ̀ṣọ̀kan ìrònú ati ète.
Nipa Johanu 10:30, John Calvin (tí ó jẹ́ ẹlẹ́kọ̀ọ́ Mẹ́talọ́kan) sọ ninu iwe naa Commentary on the Gospel According to John pe: “Awọn ará igbaani ṣi apá àyọkà ọ̀rọ̀ yii lo lati fẹ̀rí hàn pe Kristi jẹ . . . ẹda kan naa pẹlu Baba. Nitori pe Kristi kò sọrọ nipa ìsopọ̀ṣọ̀kan nipa ti ara, ṣugbọn nipa ìfohùnṣọ̀kan tí ó ní pẹlu Baba.”
Gan-an nínú àyíká ọrọ ẹsẹ tí o tẹle Johanu 10:30, Jesu fi tokuntokun jiyàn pe awọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ kìí ṣe ìjẹ́wọ́ kan pe oun jẹ́ Ọlọrun. Oun beere lọwọ awọn Juu tí wọn fi àìtọ́ fà ìpari èrò yẹn yọ tí wọn sì fẹ́ lati sọ ọ lókùúta: “Eeṣe tí ẹyin ṣe fi ẹ̀sùn ọ̀rọ̀ òdì kàn mi nitori pe emi, tí Baba yàsímímọ́ tí ó sì rán wá sinu ayé, sọ pe ‘Mo jẹ́ Ọmọkunrin Ọlọrun’?” (Johanu 10:31-36, NE) Bẹẹkọ, Jesu kede pe oun, kìí ṣe Ọlọrun Ọmọkunrin, bíkòṣe Ọmọkunrin Ọlọrun.
“Ó Ńmú Araarẹ̀ Bá Ọlọrun Dọ́gba”?
IWE MIMỌ miiran tí wọn fifunni gẹgẹ bi ìtìlẹ́hìn fun Mẹtalọkan ni Johanu 5:18. Ó sọ pe awọn Juu (gẹgẹ bi o ti rí ní Johanu 10:31-36) fẹ́ lati pa Jesu nitori pe “o wi pẹlu pe, Baba oun ni Ọlọrun íṣe, ó ńmú araarẹ̀ bá Ọlọrun dọ́gba.”
Ṣugbọn ta ni ó sọ pe Jesu nmú araarẹ̀ bá Ọlọrun dọ́gba? Kìí ṣe Jesu. Oun gbèjà araarẹ̀ lodisi ẹ̀sùn èké yii ní ẹsẹ̀ tí ó tẹle e gan-an (19) pe: “Sí ẹ̀sùn yii Jesu fèsìpadà pe: . . . ‘Ọmọkunrin kò lè ṣe ohunkohun nipasẹ araarẹ̀; kìkì ohun tí ó bá rí Baba rẹ̀ tí ó ńṣe ni oun lè ṣe.’”—JB.
Nipasẹ eyi, Jesu fihan awọn Juu pe oun kò dọ́gba pẹlu Ọlọrun ati nitori naa oun kò lè ṣe ohunkohun lori àtinúdá tirẹ̀ fúnraarẹ̀. A ha lè ronú ẹnikan tí ó báradọgba pẹlu Ọlọrun Olodumare tí ó ńsọ pe oun kò lè “ṣe ohunkohun nipasẹ araarẹ̀”? (Fiwe Daniẹli 4:34, 35.) Lọna tí ńru ọkàn ìfẹ́ sókè àyíká ọ̀rọ̀ Johanu 5:18 ati 10:30 fihan pe Jesu gbèjà araarẹ̀ lodisi awọn ẹ̀sùn èké lati ọ̀dọ̀ awọn Juu ti wọn ńdé awọn ipari èrò àìtọ̀ bii awọn Ẹlẹkọ Mẹtalọkan ti nṣe!
“Bára Dọ́gba Pẹlu Ọlọrun” Bí?
NÍ FILIPI 2:6 Douay Version (Dy) ti Katoliki ti 1609 sọ nipa Jesu pe: “Ẹni tí ó wà ní àwòrán Ọlọrun, kò rò ó pe ó jẹ́ ìjanilólè lati dọ́gba pẹlu Ọlọrun.” King James Version (KJ) ti 1611 kà lọna tí ó fẹrẹẹ rí bakan naa patapata. Ọpọ iru awọn ìtẹ̀jáde bẹẹ ni awọn kan ṣì ńlò sibẹ lati fi ṣètìlẹ́hìn fún èrò naa pe Jesu dọ́gba pẹlu Ọlọrun. Ṣugbọn ṣakiyesi bí awọn ẹda miiran tí túmọ̀ ẹsẹ̀ yii:
1869: “ẹni ti, bí ó ti wà ni àwòrán Ọlọrun, kò kà wíwà ní ìdọ́gba pẹlu Ọlọrun sí ohun kan lati jágbà.” The New Testament, lati ọwọ́ G. R. Noyes.
1965: “Oun—tí ó jẹ ẹda ọrun nitootọ!—kò fi ìgbọ́kànléra ẹni mú araarẹ̀ dọ́gba pẹlu Ọlọrun láéláé.” Das Neue Testament, ẹ̀dà tí a túngbéyẹ̀wò, lati ọwọ́ Friedrich Pfäfflin.
1968: “ẹni tí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ ó wà ní àwòrán Ọlọrun, kò kà wíwà ní ìdọ́gba pẹlu Ọlọrun sí ohun kan tí oun lè fi ìwọra sọ di tirẹ̀ fúnraarẹ̀.” La Bibbia Concordata.
1976: “Oun ti fi igba gbogbo jẹ iru ẹni ti Ọlọrun jẹ, ṣugbọn oun kò ronu pe nipasẹ ipá oun gbọdọ gbìyànjú lati di abáradọ́gba pẹlu Ọlọrun.” Today’s English Version.
1984: “ẹni tí, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pe ó wà ní àwòrán Ọlọrun, kò fi ironu fun fifi ipa gba nǹkan, eyiini ni, pe oun nilati bá Ọlọrun dọ́gba.” New World Translation of the Holy Scriptures.
1985: “Ẹni tí, bí ó ti wà ní àwòrán Ọlọrun, kò kà ìbáradọ́gba pẹlu Ọlọrun sí ohun kan lati jágbà.” The New Jerusalem Bible.
Awọn kan sọ, bí ó ti wu kí ó rí, pe àní awọn ìtúmọ̀ tí wọn tubọ péye wọnyi túmọ̀sí pe (1) Jesu ti ní ìdọ́gba ná ṣugbọn kò fẹ́ dírọ̀mọ́ iyẹn tabi pe (2) kò jẹ́ ọ̀ranyàn fun un lati já ìbádọ́gba gbà nitori pe oun ti ní in tẹlẹ.
Nipa eyi, Ralph Martin, ninu The Epistle of Paul to the Philippians, sọ nipa èdè Giriiki ìpilẹ̀ṣẹ̀ pe: “Ó kun fun iyemeji, bi o ti wu ki o rí, boya ìtumọ̀ ọ̀rọ̀-ìṣe naa lè yọ̀tẹ̀rẹ́ lati itumọ tootọ rẹ̀ tí ó jẹ́ ‘lati fi ipa gba,’ ‘lati jágbà lojiji pẹlu ìwà ipá’ sí ‘lati dìmúṣinṣin.’” The Expositor’s Greek Testament sọ pẹlu pe: “A kò lè rí apá àyọkà ọ̀rọ̀ kan nibi ti ἁρπάζω [har·paʹzo] tabi eyikeyii lara awọn ọ̀rọ̀ àrífàyọ rẹ̀ ti ní ìtumọ̀ ‘dídi ohun-ìní mú,’ ‘dídìmútítí’. Ó dabi ẹni pe láìṣeéyipadà ó tumọsi ‘fi ipa gba,’ ‘jágbà lojiji pẹlu ìwà-ipá’. Nipa bayii a kò fàyègbà á lati yọ̀tẹ̀rẹ́ lati ìtumọ̀ tootọ naa ‘gbámú’ sí ọ̀kan tí ó yàtọ̀ patapata, ‘dìmúṣinṣin.’”
Lati inu ohun tí a ti ńsọ bọ̀ ó ṣe kedere pe awọn olùṣètumọ̀ awọn ẹ̀dá bii Douay ati King James ńṣẹ́ òfin po lati ṣètìlẹ́hìn fun ẹkọ Mẹtalọkan. Jìnnàjìnnà sí sísọ pe Jesu lérò pe ó bá a mu lati dọ́gba pẹlu Ọlọrun, ọ̀rọ̀ Giriiki tí ó wà ní Filipi 2:6, ti a bá kà á láìṣègbè, fi odikeji gan-an hàn, pe Jesu kò ronú pe ó ba a mu.
Àyíká ọrọ awọn ẹsẹ tí ó yí i ká (3-5, 7, 8, Dy) mú un ṣe kedere bí a ṣe nilati lóye ẹsẹ̀ 6. A rọ̀ awọn ará Filipi pe: “Ninu ìrẹ̀lẹ̀ ọkàn, ẹ́ jẹ́ kí ẹnikọọkan gbé awọn ẹlomiran níyì lọna tí ó dára ju araawọn lọ.” Lẹhin naa Pọọlu lò Kristi gẹgẹ bi apẹẹrẹ titayọ niti ẹmi ironu yii pe: “Ẹ jẹ́ kí èrò inú yii wà ninu yin, eyi tí ó wà pẹlu ninu Kristi Jesu.” “Èrò inú” wo? Lati ‘ronu rẹ̀ pe kìí ṣe ìjanilólè lati báradọ́gba pẹlu Ọlọrun’? Bẹẹkọ, iyẹn yoo jẹ́ odikeji kókó naa gan-an tí oun ńmú jáde! Kàkà bẹẹ, Jesu, ẹni tí ó ‘gbé Ọlọrun níyì lọna tí ó dára ju araarẹ̀ lọ,’ kì yoo ‘já idọgba pẹlu Ọlọrun gbà’ láéláé, ṣugbọn dípò rẹ̀ oun “rẹ̀ araarẹ̀ sílẹ̀, ní didi onígbọràn títí dé ojú ikú.”
Dajudaju, iyẹn kò lè maa sọ̀rọ̀ nipa apá eyikeyii ninu Ọlọrun Olodumare. Ó ńsọ̀rọ̀ nipa Jesu Kristi, ẹni tí ó ṣàkàwé kókó akiyesi Pọọlu níhìn-ín lọna pípé—eyiini ni ijẹpataki ẹmi ìrẹ̀lẹ̀ ati ìgbọràn sí ẹni Gigajulọ ati Ẹlẹdaa ẹni, Jehofa Ọlọrun.
“Emi Ni”
NÍ JOHANU 8:58 iye awọn ìtúmọ̀ kan, fun àpẹẹrẹ The Jerusalem Bible, ní ninu rẹ̀ pe Jesu sọ pe: “Kí Aburahamu tó wà rárá, Emi Ni.” Jesu ha ńkọ́ni níbẹ̀, gẹgẹ bi awọn Ẹlẹ́kọ̀ọ́ Mẹ́talọ́kan ṣe tẹnumọ ọn, pe a mọ̀ ọn pẹlu orúkọ oyè naa “Emi Ni”? Ati gẹgẹ bi wọn ṣe sọ, eyi ha tumọsi pe oun ni Jehofa ti inu Iwe Mimọ lédè Heberu, niwọn bi King James Version ní Ẹkisodu 3:14 ti sọ pe: “Ọlọrun si wi fun Mose pe, EMI NI ẸNI TÍ Ó WÀ”?
Ní Ẹkisodu 3:14 (KJ) ọ̀rọ̀ ṣoki naa “EMI NI” ni a lò gẹgẹ bi orúkọ oyè fun Ọlọrun lati fihan pe oun wà niti gidi oun yoo sì ṣe ohun ti oun ṣeleri. Iwe naa The Pentateuch and Haftorahs, tí Dokita J. H. Hertz ṣàtúnṣe, sọ nipa ọ̀rọ̀ ṣoki naa pe: “Sí awọn ọmọ Isirẹli tí wọn wà ninu ìdè ìsìnrú, itumọ naa yoo jẹ́, ‘Bí o tilẹ̀ jẹ́ pe Oun kò tíì fi agbára Rẹ̀ han fun yin síbẹ̀, Oun yoo ṣe bẹẹ; Oun wà títí ayérayé yoo sì dá yin nídè dajudaju.’ Ọpọ julọ awọn eniyan ti wọn ni oju iwoye igbalode tẹ̀lé Rashi [alálàyé Bibeli kan lédè French ati Talmud] ni títúmọ̀ [Ẹkisodu 3:14] sí ‘Emi yoo jẹ́ ohun tí emi yoo jẹ́.’”
Ọ̀rọ̀ naa ní Johanu 8:58 yàtọ̀ patapata sí ti ọ̀kan tí a lò ní Ẹkisodu 3:14. Jesu kò lò ó gẹgẹ bi orúkọ kan tabi orúkọ oyè kan bíkòṣe gẹgẹ bi ọ̀nà fun ṣíṣàlàyé wíwà rẹ̀ ṣaaju ki o to di ẹ̀dá ènìyàn. Nipa bayii, ṣakiyesi bí awọn ẹ̀dà Bibeli miiran ṣe túmọ̀ Johanu 8:58:
1869: “Kí Aburahamu tó wà, mo ti wa.” The New Testament, lati ọwọ G. R. Noyes.
1935: “Mo ti wà kí a tó bí Aburahamu!” The Bible—An American Translation, lati ọwọ́ J. M. P. Smith ati E. J. Goodspeed.
1965: “Ṣaaju kí a tó bí Aburahamu, mo ti jẹ́ ẹni tí emi jẹ́ ná.” Das Neue Testament, lati ọwọ́ Jörg Zink.
1981: “Mo walaaye ṣaaju kí a tó bí Aburahamu!” The Simple English Bible.
1984: “Kí Aburahamu tó wà, emi ti wà.” New World Translation of the Holy Scriptures.
Nipa bayii, èrò tootọ tí ọ̀rọ̀ Giriiki tí a lò níhìn-ín ní ni pe Jesu, “àkọ́bí” ninu iṣẹda Ọlọrun, ti wà tipẹ́tipẹ́ ṣaaju kí a tó bí Aburahamu.—Kolose 1:15; Owe 8:22, 23, 30; Iṣipaya 3:14.
Lẹẹkan sii, àyíká ọ̀rọ̀ naa fi eyi hàn pe ó jẹ́ óye tí ó tọna. Lọ́tẹ̀ yìí awọn Juu fẹ́ lati sọ Jesu lókùúta fun sisọ pe oun “ti rí Aburahamu” bi ó tilẹ̀ jẹ́ pe, gẹgẹ bi wọn ṣe sọ, kò tíì tó ẹni 50 ọdun. (Ẹsẹ̀ 57) Ìdáhùn Jesu lọna ti ẹ̀dá ni lati sọ otitọ nipa ọjọ́-orí rẹ̀. Nitori naa oun sọ lọna tí ẹ̀dá fun wọn pe oun “ti walaaye ṣaaju kí a tó bí Aburahamu!”—The Simple English Bible.
“Ọlọrun Ni Ọ̀rọ̀ Naa”
NÍ JOHANU 1:1 King James Version ka pe: “Ní àtètèkọ́ṣe ní Ọ̀rọ̀ wà, Ọ̀rọ̀ sì wà pẹlu Ọlọrun, Ọlọrun sì ni Ọ̀rọ̀ naa.” Awọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ Mẹ́talọ́kan sọ pe eyi tumọsi pe “Ọ̀rọ̀ naa” (Giriiki, ho loʹgos) tí ó wá sori ilẹ̀-ayé gẹgẹ bi Jesu Kristi ni Ọlọrun Olodumare fúnraarẹ̀.
Ṣakiyesi, bi o ti wu ki o ri, pe níhìn-ín lẹẹkan sii àyíká ọ̀rọ̀ naa fi ipilẹ lélẹ̀ fun ìlóye tí ó péye. Kódà King James Version sọ pe: Ọ̀rọ̀ naa wà pẹlu Ọlọrun.” (Ikọwe wínníwínní jẹ́ tiwa.) Ẹni kan tí ó wà “pẹlu” ẹlomiran kò lè jẹ́ ẹni kan naa pẹlu ẹlomiran yẹn. Ní ìfohùnṣọ̀kan pẹlu eyi, iwe naa Journal of Biblical Literature, tí onisin Jesuit naa Joseph A. Fitzmyer ṣàtúnṣe, ṣakiyesi pe bí a bá tumọ apá tí ó kẹhin ninu Johanu 1:1 si Ọlọrun “naa,” eyi “yoo tako gbólóhùn tí ó ṣaaju nigba naa,” eyi tí ó sọ pe Ọ̀rọ̀ naa wà pẹlu Ọlọrun.
Ṣakiyesi, pẹlu, bí awọn ìtúmọ̀ miiran ṣe ṣetumọ ẹsẹ̀ yii:
1808: “ọ̀rọ̀ naa sì jẹ́ ọlọrun kan.” The New Testament in an Improved Version, Upon the Basis of Archbishop Newcome’s New Translation: With a Corrected Text.
1864: “ọlọrun kan sì ní ọ̀rọ̀ naa jẹ́.” The Emphatic Diaglott, ìkàwé àkọsẹ́gbẹ̀ẹ́, lati ọwọ̀ Benjamin Wilson.
1928: “Ọ̀rọ̀ naa sì jẹ́ alaaye ọrun kan.” La Bible du Centenaire, L’Evangile selon Jean, lati ọwọ́ Maurice Goguel.
1935: “Ọ̀rọ̀ naa sì jẹ́ ti ọ̀run.” The Bible—An American Translation, lati ọwọ́ J. M. P. Smith ati E. J. Goodspeed.
1946: “Ọ̀rọ̀ naa sì jẹ́ irú ti ọ̀run kan.” Das Neue Testament, lati ọwọ́ Ludwig Thimme.
1950: “Ọ̀rọ̀ naa sì jẹ ọlọrun kan.” New World Translation of the Christian Greek Scriptures.
1958: “Ọ̀rọ̀ naa sì jẹ́ Ọlọrun kan.” The New Testament, lati ọwọ́ James L. Tomanek.
1975: “ọlọrun kan (tabi, irú ti ọ̀run kan) sì ni Ọ̀rọ̀ naa.” Das Evangelium nach Johannes, lati ọwọ́ Siegfried Schulz.
1978: “irú ẹni bí ọlọ́run sì ní Logos naa.” Das Evangelium nach Johannes, lati ọwọ́ Johannes Schneider.
Ní Johanu 1:1 ibi meji ni ọ̀rọ̀ orúkọ Giriiki naa the·osʹ (ọlọrun) ti farahan. Ifarahan àkọ́kọ́ tọkasi Ọlọrun Olodumare, ẹni tí Ọ̀rọ̀ naa wà pẹlu rẹ (“Ọ̀rọ̀ [loʹgos] naa sì wà pẹlu Ọlọrun [irú the·osʹ kan]”). The·osʹ àkọ́kọ́ yii ni ọ̀rọ̀ naa ton (naa) ṣaaju rẹ, iru ọ̀rọ̀ atọ́ka pàtó Giriiki kan tí ó tọkasi ẹni kan tí ó dáyàtọ̀, tí ó jẹ́ Ọlọrun Olodumare ní ọ̀ràn yii (“Ọ̀rọ̀ naa sì wà pẹlu Ọlọrun [naa]”).
Ní ọwọ́ keji ẹ̀wẹ̀, kò sí ọ̀rọ̀ atọka pàtó kankan ṣaaju the·osʹ keji ní Johanu 1:1. Nitori naa ìtúmọ̀ ṣáńgílítí kan yoo kà pe: “ọlọrun sì ní Ọ̀rọ̀ naa.” Síbẹ̀ a ti rí i pe ọpọlọpọ awọn ìtúmọ̀ tumọ the·osʹ (ọ̀rọ̀ orúkọ oníkókó gbólóhùn) keji yii gẹgẹ bi “ti ọ̀run,” “ẹni-bi-Ọlọrun,” tabi “ọlọrun kan.” Aṣẹ wo ni wọn ní lati ṣe eyi?
Èdè Giriiki ti Koine ní ọ̀rọ̀ atọ́ka pàtó kan (“naa”), ṣugbọn kò ní ọ̀rọ̀ aláìtọ́ka pàtó (“kan”). Nitori naa nigba ti ọ̀rọ̀ atọ́ka pàtó kan kò bá ṣaaju ọ̀rọ̀ orúkọ inu kókó gbólóhùn kan, ó lè jẹ́ ọ̀rọ̀ aláìtọ́ka pàtó, ni sisinmi lori ohun ti àyíká ọ̀rọ̀ naa jẹ.
Iwe-irohin naa Journal of Biblical Literature sọ pe awọn gbolohun ọrọ “pẹlu kókó gbólóhùn aláìní ọ̀rọ̀ atọ́ka tí ó kọ́kọ́ ṣaaju ọ̀rọ̀-ìṣe, ní itumọ rẹ pilẹ jẹ lati ṣapejuwe awọn animọ.” Gẹgẹ bi iwe-irohin Journal naa ti ṣakiyesi, eyi fihan pe loʹgos ni a lè fiwé ọlọrun. Ó tún sọ pẹlu ní Johanu 1:1 pe: “Agbara àpèjúwe ànímọ́ ti kókó gbólóhùn naa ṣekoko tí ó fi jẹ́ pe ọ̀rọ̀-orúkọ naa [the·osʹ] ni a kò lè kásí atọ́ka-pàtó.
Nitori naa Johanu 1:1 tẹnumọ́ ànímọ́ Ọ̀rọ̀ naa, pe oun jẹ́ “ti ọ̀run” “ẹni-bí-ọlọ́run,” “ọlọrun kan,” ṣugbọn kìí ṣe Ọlọrun Olodumare. Eyi ṣerẹ́gí pẹlu apa yooku ninu Bibeli, tí ó fihan pe Jesu, tí a pè ní “Ọ̀rọ̀ naa” níhìn-ín ninu ipo rẹ̀ gẹgẹ bi Agbọ̀rọ̀sọ Ọlọrun jẹ́ òṣìṣẹ́ ọmọ-abẹ́ onígbọràn tí Agalọ́lájù ọga rẹ, Ọlọrun Olodumare rán wá sí ilẹ̀-ayé.
Ọpọlọpọ awọn ẹsẹ̀ Bibeli miiran wà ninu eyi tí ó fẹrẹẹ jẹ́ gbogbo awọn olùtúmọ̀ ninu awọn èdè yooku ni wọn fi ìṣedéédéé ki ọ̀rọ̀ atọ́ka naa “kan” bọ̀ ọ́ nigba ti wọn ńtúmọ̀ awọn ọ̀rọ̀ Giriiki tí ó ní iru ìgbékalẹ̀ kan naa. Fun apẹẹrẹ, ní Maaku 6:49, nigba ti awọn ọmọ-ẹhin rí Jesu tí ó ńrìn lori omi, King James Version sọ pe: “Wọn ṣèbí ẹ̀mí [kan] ni.” Ninu èdè Giriiki ti Koine, kò sí “kan” ṣaaju “ẹ̀mí.” Ṣugbọn ó fẹrẹẹ jẹ́ gbogbo awọn ìtúmọ̀ ní èdè miiran ni wọn fi “kan” kún un kí wọn baà lè mú kí ìtumọ̀ naa bá àyíká ọ̀rọ̀ naa mú. Ní ọ̀nà kan naa, niwọn bi Johanu 1:1 ti fihan pe Ọ̀rọ̀ naa wà pẹlu Ọlọrun, oun kò lè jẹ́ Ọlọrun ṣugbọn oun jẹ́ “ọlọrun kan,” tabi “ti ọ̀run.”
Joseph Henry Thayer, ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn ati ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́ jinlẹ̀ tí ó ṣiṣẹ́ lori American Standard Version, sọ lọna rirọrun pe: “Logos naa jẹ́ ti ọ̀run, kìí ṣe Ọlọrun ọrun fúnraarẹ̀.” Onisin Jesuit naa John L. McKenzie sì kọ̀wé ninu Dictionary of the Bible rẹ̀ pe: “Johanu 1:1 ni a nilati túmọ̀ lọna ti o ṣe gẹlẹ sí . . . ‘ọ̀rọ̀ naa jẹ́ ẹda ọ̀run kan.’”
Títẹ̀ Ìlànà kan Lójú Ni Bi?
AWỌN kan sọ, bi o ti wu ki o ri, pe irufẹ ìtumọ̀ bẹẹ tẹ̀ ilana gírámà Giriiki ti Koine lójú eyi tí ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́ jinlẹ̀ Giriiki naa E. C. Colwell tẹ̀jáde lẹhin lọhun-un ní 1933. Oun tẹnumọ ọn pe ninu èdè Giriiki ọ̀rọ̀ orúkọ ninu kókó gbólóhùn kan “ní ọ̀rọ̀ atọ́ka [pàtó] nigba ti ó bá tẹ̀lé ọ̀rọ̀-ìṣe; kii ní ọ̀rọ̀-atọ́ka [pàtó] nigba ti ó bá ṣaaju ọ̀rọ̀-ìṣe.” Nipa eyi ó ni in lọ́kàn pe ọ̀rọ̀-orúkọ inu kókó-gbólóhùn tí ó ṣaaju ọ̀rọ̀-ìṣe ni a gbọdọ lóye bí ẹni pe ó ní ọ̀rọ̀-atọ́ka pàtó (“naa”) ní iwaju rẹ̀. Ní Johanu 1:1 ọ̀rọ̀ orúkọ keji (the·osʹ), tí ó jẹ́ kókó-gbólóhùn naa, kọ́kọ́ ṣaaju ọ̀rọ̀-ìṣe—“[the·osʹ] sì ní Ọ̀rọ̀ naa.” Nitori naa, Colwell sọ pe, Johanu 1:1 gbọdọ kà pe “Ọlọrun [naa] sì ni Ọ̀rọ̀ naa.”
Ṣugbọn ronu nipa apẹẹrẹ meji péré tí a rí ní Johanu 8:44. Níbẹ̀ Jesu sọ nipa Eṣu pe: “Apànìyàn kan ni ẹni yẹn” ati pe “òpùrọ́ kan ni oun.” Gan-an gẹgẹ bi ó ti rí ní Johanu 1:1, awọn ọ̀rọ̀ orúkọ ninu kókó gbólóhùn naa (“apànìyàn” ati “òpùrọ́”) ṣaaju awọn ọ̀rọ̀-ìṣe naa (“ni”) ninu èdè Giriiki. Kò sí ọ̀rọ̀ aláìtọ́ka pàtó kankan ní iwaju ọ̀rọ̀-orúkọ́ mejeeji nitori pe kò sí ọ̀rọ̀ aláìtọ́ka pàtó kankan ninu èdè Giriiki ti Koine. Ṣugbọn ọpọ julọ awọn ìtumọ̀ kì ọ̀rọ̀ naa “kan” bọ̀ ọ́ nínú nitori pe gírámà Giriiki ati àyíká ọ̀rọ̀ beere fun un.—Tún wo Maaku 11:32; Johanu 4:19; 6:70; 9:17; 10:1; 12:6 bakan naa.
Colwell nilati wá mọ̀ eyi ní àmọ̀dájú nipa ọ̀rọ̀ orúkọ inú kókó gbólóhùn naa, nitori oun sọ pe: “Ó [“kan” tabi “ọkan”] jẹ́ aláìtọ́ka pàtó nínú ipò yii kìkì nigba ti àyíká ọ̀rọ̀ bá fi dandangbọn beere fun un. Nitori naa àní oun tilẹ̀ gbà pàápàá pe nigba ti àyíká ọ̀rọ̀ bá beere fun un, awọn olùtúmọ̀ lè kì ọ̀rọ̀ aláìtọka pàtó kan bọ̀ iwaju ọ̀rọ̀ orúkọ naa ninu iru ìgbékalẹ̀ gbólóhùn-ọ̀rọ̀ yii.
Àyíká ọ̀rọ̀ ha beere fun ọ̀rọ̀ aláìtọ́ka pàtó ní Johanu 1:1 bi? Bẹẹni, nitori pe gbogbo ẹ̀rí Bibeli pata ni pe Jesu kìí ṣe Ọlọrun Olodumare. Nipa bayii, kìí ṣe ilana gírámà oniyemeji ti Colwell, bíkòṣe àyíká ọ̀rọ̀ ni ó gbọdọ ṣamọna olùtúmọ̀ ninu iru awọn ọ̀ràn bẹẹ. Ó sì ṣe kedere lati inu ọpọlọpọ awọn ìtúmọ̀ tí wọn kì ọ̀rọ̀ aláìtọ́ka pàtó naa “kan” bọ̀ inú Johanu 1:1 ati ní awọn ibomiran pe ọpọlọpọ awọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́ jinlẹ̀ lodi si irufẹ ilana àtọwọ́dá kan bẹẹ, bẹẹ sì ni Ọ̀rọ̀ Ọlọrun pẹlu.
Kò Sí Ìforígbárí Kankan
ǸJẸ́ sísọ pe Jesu Kristi jẹ́ “ọlọrun kan” ha forígbárí pẹlu ẹ̀kọ́ Bibeli pe Ọlọrun kanṣoṣo ni ó wà? Bẹẹkọ, nitori pe ní awọn ìgbà miiran Bibeli maa nlo èdè ìsọ̀rọ̀ naa lati tọkasi awọn ẹ̀dá alágbára-ńlá. Saamu 8:5 (NW), kà pe: “Iwọ sáà dá a [eniyan] ni onírẹ̀lẹ̀ diẹ ju awọn ẹni-bi-Ọlọrun [Heberu, ʼelo·himʹ] lọ,” iyẹn ni awọn angẹli. Ninu ìgbèjà ẹjọ Jesu lodisi ẹ̀sùn awọn Juu, pé oun pè araarẹ ni Ọlọrun, oun ṣakiyesi pe: “Ofin naa ńlò ọ̀rọ̀ naa awọn ọlọrun fun awọn wọnni tí a darí ọ̀rọ̀ Ọlọrun sí,” iyẹn ni awọn ènìyàn onídaajọ. (Johanu 10:34, 35, JB; Saamu 82:1-6) Àní Satan pàápàá ni a pè ní “ọlọrun ayé yii” ní 2 Kọrinti 4:4.
Jesu ní ipò tí ó ga jù ti awọn angẹli, awọn eniyan aláìpé, tabi Satani. Niwọn bi a ti tọkasi awọn wọnyi gẹgẹ bi “awọn ọlọrun,” awọn eniyan alágbára, dajudaju Jesu lè jẹ́ ó sì jẹ́ “ọlọrun kan.” Nitori ìpò aláìlẹ́gbẹ́ rẹ ní ìbátan sí Jehofa, Jesu jẹ́ “Ọlọrun Alágbára.”—Johanu 1:1; Aisaya 9:6, NW.
Ṣugbọn ǹjẹ́ “Ọlọrun Alágbára” pẹlu awọn lẹ́tà nla ìbẹ̀rẹ̀ rẹ̀ ko fihan pe Jesu ní awọn ọ̀nà kan dọ́gba pẹlu Jehofa Ọlọrun? Bẹẹkọ rárá. Aisaya wulẹ̀ sọ asọtẹlẹ yii lati jẹ́ ọ̀kan lára awọn orukọ mẹrin tí a ó pè Jesu, ninu èdè Gẹẹsi lẹta nla si ni a maa nfi bẹ̀rẹ̀ iru awọn orúkọ bẹẹ. Síbẹ̀, bi o tilẹ̀ jẹ́ pe a pè Jesu ní “Alágbára,” ẹni kanṣoṣo ni ó wà tí ó lè jẹ́ “Olodumare.” Lati pè Jehofa ní “Olodumare” yoo ní ìjámọ́pàtàkì alaito nǹkan àyàfi bí awọn miiran bá wà tí a ńpè ní awọn ọlọrun pẹlu ṣugbọn tí wọn gbà ipò kíkéréjù tabi rírẹlẹ̀.
Iwe-irohin Bulletin of the John Rylands Library ní England ṣakiyesi pe gẹgẹ bi ẹlẹ́kọ̀ọ́-ìsìn Katoliki naa Karl Rahner ti wi, nigba ti ó jẹ́ pe a lò the·osʹ ninu awọn iwe mimọ iru bii Johanu 1:1 ní itọkasí Kristi, “kò sí ọ̀kankan ninu awọn apẹẹrẹ wọnyi tí a ti lò ‘theos’ ni iru ọ̀nà kan bẹẹ lati mọ Jesu mọ́ ẹni tí ó jẹ́ pe ní ibomiran ninu Majẹmu Titun ó dúró gẹgẹ bi ‘ho Theos,’ eyiini ni, Ọlọrun Giga Julọ.” Iwe-irohin Bulletin naa sì fikun un pe: “Bí awọn òǹkọ̀wé Majẹmu Titun bá gbàgbọ́ pe ó ṣepataki pe ki awọn olùṣòtítọ́ jẹwọ Jesu gẹgẹ bi ‘Ọlọrun,’ ǹjẹ́ ohun tí ó fẹrẹẹ jẹ́ àìsí irú ìjẹ́wọ́ yii gan-an gẹlẹ ninu Majẹmu Titun yoo ha ṣeé ṣàlàyé bi?
Ṣugbọn ki ni nipa ti apọsiteli Tọmaasi tí ó sọ pe, “Oluwa mi ati Ọlọrun mi!” sí Jesu ní Johanu 20:28? Sí Tọmaasi, Jesu dabii “ọlọrun kan,” pàápàá ní pataki ninu awọn àyíká oníṣẹ́ ìyanu tí ó sún un ṣe kayefi. Awọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́ jinlẹ̀ kan dámọ̀ràn pe ó lè wulẹ̀ jẹ́ pe Tọmaasi fi ìmọ̀lára ìṣekàyéfì han, eyi tí ó sọ sí Jesu ṣugbọn tí ó darí rẹ̀ sí Ọlọrun. Ninu ọ̀ràn mejeeji, Tọmaasi kò ronu pe Jesu jẹ́ Ọlọrun Olodumare, nitori oun ati gbogbo awọn apọsiteli yooku mọ̀ pe Jesu kò sọ nígbà kankan rí pe oun jẹ́ Ọlọrun ṣugbọn ó kọ́ni pe Jehofa nìkanṣoṣo ni “Ọlọrun otitọ kanṣoṣo naa.”—Johanu 17:3, NW.
Lẹẹkan sii, àyíká ọ̀rọ̀ naa ràn wa lọ́wọ́ lati lòye eyi. Ní ìwọ̀nba awọn ọjọ́ diẹ ṣaaju, Jesu tí a ti ji dide sọ fun Maria Magidaleni lati sọ fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe: “Emi ńgòkè lọ sọ́dọ̀ Baba mi, ati Baba yin; ati sọ́dọ̀ Ọlọrun mi, ati Ọlọrun yin.” (Johanu 20:17) Bi ó tilẹ̀ jẹ́ pe ṣaaju ìgbà yẹn a ti jí Jesu dìde tẹlẹ gẹgẹ bi ẹ̀mí alágbára, Jehofa ṣì ní Ọlọrun rẹ̀. Jesu sì nba a lọ lati tọ́ka sí I bẹẹ gẹ́gẹ́ àní ninu iwe tí ó kẹhin ninu Bibeli pàápàá, lẹhin tí a ti ṣe é lógo.—Iṣipaya 1:5, 6; 3:2, 12.
Kìkì ẹsẹ̀ mẹta lẹhin kayefi Tọmaasi, ní Johanu 20:31, Bibeli mú ọ̀ràn naa tubọ ṣe kedere siwaju sii nipa sísọ pe: “Iwọnyi ni a kọ́, kí ẹyin kí ó lè gbàgbọ́ pe, Jesu níí ṣe Kristi naa, Ọmọ [“Ọmọkunrin,” NW] Ọlọrun,” kìí ṣe pe oun ní Ọlọrun Olodumare. Ó sì tumọsi “Ọmọkunrin” ní ìtúmọ̀ ṣangiliti, gẹgẹ bi ti baba kan ati ọmọkunrin lọna ti ẹ̀dá, kìí ṣe gẹgẹ bi apá olóhun ìjìnlẹ̀ kan ti Ọlọrun ẹlẹni mẹ́ta ti Mẹtalọkan.
Ó Gbọdọ Báramu Pẹlu Bibeli
AWỌN kan ti sọ pe awọn iwe mimọ melookan miiran ṣètìlẹ́hìn fun Mẹtalọkan. Ṣugbọn awọn wọnyi farajọra pẹlu awọn wọnni tí a ti jiroro lókè niti pe, nigba ti a bá farabalẹ̀ ṣàyẹ̀wò wọn, wọn kò funni ni ìtìlẹ́hìn gidi kankan. Iru awọn ọ̀rọ̀ ìwé bẹẹ mu un ṣe kedere pe nigba ti a bá ńgbé ohun ti wọn pe ni ìtìlẹ́hìn eyikeyii fun Mẹtalọkan yẹwo, ẹnikan gbọdọ beere pe: Ǹjẹ́ ìtúmọ̀ naa ha báramu pẹlu ẹ̀kọ́ ti o ṣe déédéé pẹlu gbogbo Bibeli pata—pe Jehofa Ọlọrun nìkanṣoṣo ni Ẹni Giga Julọ? Bí kò bá jẹ́ bẹẹ, nigba naa ìtúmọ̀ naa gbọdọ jẹ́ ìṣìnà.
A tún nílò lati fi sọ́kàn pe ko si ọkankan ninu “ọ̀rọ̀-ìwé àfiṣẹ̀rí” ti ó sọ pe Ọlọrun, Jesu, ati ẹ̀mí mímọ́ jẹ́ ọ̀kan ninu ohun ìjìnlẹ̀ ti Ọlọrun ẹlẹni mẹ́ta. Kò sí iwe mimọ kan nibikibi ninu Bibeli tí ó sọ pe awọn mẹtẹẹta jẹ́ ohun kan naa ninu ohun-ti-ara, agbára, ati ayérayé. Bibeli fohun ṣọkan ninu ṣíṣí Ọlọrun Olodumare, Jehofa payá, gẹgẹ bi Ẹni Giga Julọ kanṣoṣo, Jesu gẹgẹ bi Ọmọkunrin rẹ̀ tí a ṣẹ̀dá, ati ẹ̀mí mímọ́ gẹgẹ bi ipá agbékánkánṣiṣẹ́ Ọlọrun.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 24]
“Awọn ará igbaani ṣi [Johanu 10:30] lò lati fẹ̀rí hàn pe Kristi jẹ́ . . . ẹda kan naa pẹlu Baba.”—Commentary on the Gospel According to John, lati ọwọ́ John Calvin
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 27]
Ẹni kan ti ó wà “pẹlu” ẹlomiran kò lè jẹ́ ẹlomiran yẹn
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 28]
“Logos naa jẹ́ ti ọ̀run, kìí ṣe Ọlọrun ọ̀run fúnraarẹ̀.”—Joseph Henry Thayer, ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́ jinlẹ̀ Bibeli
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24, 25]
Jesu gbadura sí Ọlọrun pe kí awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ lè ‘‘jẹ́ ọ̀kan,” gan-an gẹgẹ bi oun ati Baba ti “jẹ́ ọ̀kan”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Jesu fihan awọn Juu pe oun kò dọ́gba pẹlu Ọlọrun, ní sísọ pe oun kò le ‘ṣe ohunkohun nipasẹ araarẹ bikoṣe ohun ti o ba ri pe Baba nṣe’
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]
Niwọn bi Bibeli ti pe awọn ènìyàn, awọn angẹli, àní Satani pàápàá, ní “awọn ọlọrun,” tabi awọn ẹni alágbára, Jesu gigajù ninu ọ̀run ni a lè fi pẹlu ẹ̀tọ́ pè ní “ọlọrun kan”