Ìwé Kejì sí Àwọn Ará Kọ́ríńtì
4 Nígbà náà, torí pé ipasẹ̀ àánú tí a fi hàn sí wa la fi rí iṣẹ́ òjíṣẹ́ yìí gbà, a kò juwọ́ sílẹ̀. 2 Àmọ́ a ti kọ àwọn ohun ìtìjú tí kò ṣeé gbọ́ sétí sílẹ̀ pátápátá, a kò rin ìrìn ẹ̀tàn, bẹ́ẹ̀ ni a kò ṣe àbùlà ọ̀rọ̀ Ọlọ́run;+ àmọ́ bí a ṣe ń fi òtítọ́ hàn kedere, à ń dámọ̀ràn ara wa fún ẹ̀rí ọkàn gbogbo èèyàn níwájú Ọlọ́run.+ 3 Tí ìhìn rere tí à ń kéde bá wà lábẹ́ ìbòjú lóòótọ́, á jẹ́ pé ó wà lábẹ́ ìbòjú láàárín àwọn tó ń ṣègbé, 4 láàárín àwọn tí ọlọ́run ètò àwọn nǹkan yìí*+ ti fọ́ ojú inú àwọn aláìgbàgbọ́,+ kí ìmọ́lẹ̀* ìhìn rere ológo nípa Kristi, ẹni tó jẹ́ àwòrán Ọlọ́run,+ má bàa mọ́lẹ̀ wọlé.+ 5 Nítorí kì í ṣe ara wa là ń wàásù rẹ̀, Jésù Kristi là ń wàásù gẹ́gẹ́ bí Olúwa, a sì ń sọ pé a jẹ́ ẹrú yín nítorí Jésù. 6 Torí Ọlọ́run ni ẹni tó sọ pé: “Kí ìmọ́lẹ̀ tàn láti inú òkùnkùn,”+ ó sì ti tan ìmọ́lẹ̀ sí ọkàn wa+ láti mú kí ìmọ̀ ológo nípa Ọlọ́run mọ́lẹ̀ nípasẹ̀ ojú Kristi.
7 Àmọ́ ṣá o, a ní ìṣúra yìí+ nínú àwọn ohun èlò* tí a fi amọ̀ ṣe,+ kí agbára tó kọjá ti ẹ̀dá lè jẹ́ ti Ọlọ́run, kó má sì jẹ́ látọ̀dọ̀ wa.+ 8 Wọ́n há wa gádígádí ní gbogbo ọ̀nà, àmọ́ kò le débi tí a ò fi lè yíra; ọkàn wa dà rú, àmọ́ kì í ṣe láìsí ọ̀nà àbáyọ rárá;*+ 9 wọ́n ṣe inúnibíni sí wa, àmọ́ a ò pa wá tì;+ wọ́n gbé wa ṣánlẹ̀, àmọ́ a ò pa run.+ 10 Nínú ara wa, ìgbà gbogbo là ń fara da ìyà àti ewu ikú tí Jésù dojú kọ,+ kí ìgbésí ayé Jésù lè hàn kedere lára wa. 11 Nítorí ìgbà gbogbo ni wọ́n ń mú kí àwa tí a wà láàyè fojú kojú pẹ̀lú ikú+ nítorí Jésù, kí ìgbésí ayé Jésù lè hàn kedere nínú ara kíkú wa. 12 Torí náà, ikú wà lẹ́nu iṣẹ́ nínú wa, àmọ́ ìyè wà lẹ́nu iṣẹ́ nínú yín.
13 Ní báyìí, torí a ní ẹ̀mí ìgbàgbọ́ kan náà, irú èyí tí a kọ nípa rẹ̀ pé: “Mo ní ìgbàgbọ́, torí náà mo sọ̀rọ̀”;+ àwa náà ní ìgbàgbọ́, torí náà a sọ̀rọ̀, 14 bí a ṣe mọ̀ pé Ẹni tó gbé Jésù dìde máa gbé àwa náà dìde pẹ̀lú Jésù, ó sì máa mú àwa pẹ̀lú yín wá síwájú rẹ̀.+ 15 Gbogbo èyí jẹ́ nítorí yín, kí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí tó ń pọ̀ sí i lè túbọ̀ pọ̀ gidigidi, nítorí àwọn púpọ̀ sí i tó ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run ń fi ògo fún un.+
16 Nítorí náà, a kò juwọ́ sílẹ̀, kódà bí ẹni tí a jẹ́ ní òde bá tilẹ̀ ń joro, ó dájú pé ẹni tí a jẹ́ ní inú ń di ọ̀tun láti ọjọ́ dé ọjọ́. 17 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìpọ́njú* náà jẹ́ fún ìgbà díẹ̀, kò sì lágbára, ó ń yọrí sí ògo fún wa, ògo tí ó tóbi* gan-an, tí ó sì jẹ́ ti ayérayé;+ 18 bí a ṣe ń tẹ ojú wa mọ́ àwọn ohun tí a kò rí dípò àwọn ohun tí à ń rí.+ Nítorí àwọn ohun tí à ń rí wà fún ìgbà díẹ̀, àmọ́ àwọn ohun tí a kò rí máa wà títí ayérayé.