Èrò Náà Wọnú Àwọn Ẹ̀sìn Ìlà-Oòrùn
“Mo máa ń rò pé àìleèkú ọkàn jẹ́ òtítọ́ tí gbogbo ènìyàn tẹ́wọ́ gbà kárí ayé. Nítorí náà, ìyàlẹ́nu gbáà ni ó jẹ́ fún mi láti gbọ́ pé àwọn ìjìmì láti Ìlà-Oòrùn àti Ìwọ̀-Oòrùn ń fi tagbára-tagbára jiyàn lòdì sí èrò ìgbàgbọ́ yìí. Báyìí, mo ń ṣe kàyéfì nípa bí èrò àìleèkú ṣe dé ọkàn àwọn ẹlẹ́sìn Híńdù.”—ỌMỌ YUNIFÁSÍTÌ KAN TÍ A BÍ SÍNÚ Ẹ̀SÌN HÍŃDÙ.
1. Èé ṣe tí a fi nífẹ̀ẹ́ sí ìmọ̀ nípa bí ẹ̀kọ́ pé ènìyàn jẹ́ aláìleèkú ṣe bẹ̀rẹ̀ àti bí ó ṣe tàn kálẹ̀ nínú onírúurú ẹ̀sìn?
BÁWO ni èrò náà pé ènìyàn ní ọkàn tí kò lè kú ṣe wọnú ẹ̀sìn Híńdù àti àwọn ẹ̀sìn Ìlà-Oòrùn yòókù? Kódà, àwọn ará Ìwọ̀-Oòrùn, tí wọ́n lè má mọ̀ nípa àwọn ẹ̀sìn wọ̀nyí, nífẹ̀ẹ́ sí ìbéèrè yìí níwọ̀n bí ìgbàgbọ́ yìí ti kan ojú ìwòye gbogbo ènìyàn nípa ọjọ́ ọ̀la. Nítorí pé ẹ̀kọ́ àìleèkú ènìyàn jẹ́ ìpìlẹ̀ nínú ọ̀pọ̀ jù lọ ẹ̀sìn lónìí, mímọ̀ nípa bí èrò náà ṣe bẹ̀rẹ̀ lè mú kí ìgbọ́ra-ẹni-yé àti ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ túbọ̀ dára sí i ní tòótọ́.
2. Èé ṣe tí Íńdíà fi jẹ́ orísun pàtàkì kan tí ẹ̀sìn ti ń nípa lórí ẹni ní Éṣíà?
2 Ninian Smart, ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ẹ̀kọ́ nípa ẹ̀sìn ní Yunifásítì ti Lancaster ní ilẹ̀ Britain, sọ pé: “Íńdíà ni ìkóríta pàtàkì jù lọ tí ẹ̀sìn ti ń nípa lórí ẹni ní Éṣíà. Èyí kì í wulẹ̀ ì ṣe tìtorí pé Íńdíà kúkú ni àwọn ẹ̀sìn mélòó kan—ẹ̀sìn Híńdù, Búdà, Jéìnì, Síìkì, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ—ti bẹ̀rẹ̀, ṣùgbọ́n nítorí pé ọ̀kan nínú ìwọ̀nyí, ẹ̀sìn Búdà, wá nípa tí ó bùáyà lórí àṣà ìbílẹ̀ ohun tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo Ìlà-Oòrùn Éṣíà.” Nikhilananda, ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ nínú ẹ̀sìn Híńdù, sọ pé ọ̀pọ̀ nínú àwùjọ tí a tipa báyìí nípa lé lórí “ṣì ń ka Íńdíà sí ìlú ìbílẹ̀ wọn nípa tẹ̀mí.” Báwo wá ni ẹ̀kọ́ àìleèkú yìí ṣe wọ Íńdíà àti àwọn apá yòókù ní Ésíà?
Ẹ̀kọ́ Àtúnwáyé Bí Ẹ̀sìn Híńdù Ṣe Fi Kọ́ni
3. Gẹ́gẹ́ bí òpìtàn kan ṣe wí, ipasẹ̀ ta ni ó ṣeé ṣe kí èrò ìpapòdà ọkàn ti wọ Íńdíà?
3 Ní ọ̀rúndún kẹfà ṣááju Sànmánì Tiwa, bí Pythagoras àti àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ní Gíríìsì ṣe ń ṣalágbàwí àbá èrò orí ti ìpapòdà àwọn ọkàn, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn amòye inú ẹ̀sìn Híńdù tí ń gbé lẹ́bàá odò Indus àti Ganges ní Íńdíà náà ń mú èrò kan náà yìí bọ̀ wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́. Òpìtàn náà, Arnold Toynbee, sọ pé, “agbára káká ni” yíyọjú tí ìgbàgbọ́ yìí yọjú lẹ́ẹ̀kan náà ní “àgbègbè àwọn Gíríìkì àti ti Íńdíà fi lè jẹ́ àkọsẹ̀bá.” Toynbee wí pé: “Orísun kan náà tí ó ṣeé ṣe [kí ó ti nípa lórí wọn] ni àwọn ará Eurasia tí ó máa ń ṣí kiri, tí ó jẹ́ pé, ní ọ̀rúndún kẹjọ sí keje ṣááju Sànmánì Tiwa, wọ́n ya bo Íńdíà, ìhà Gúúṣù sí Ìwọ̀-Oòrùn Éṣíà, ẹkùn pẹ̀tẹ́lẹ̀ tí ó tẹ́jú lọ salalu lẹ́bàá etídò àríwá Òkun Dúdú, àti ìyawọlẹ̀ omi ẹkùn ilẹ̀ Balkan àti Anatolia.” Ẹ̀rí fi hàn pé àwọn ẹ̀yà Eurasia tí ń ṣí kiri yìí ni ó mú èrò ìpapòdà ọkàn wọ Íńdíà.
4. Èé ṣe tí èrò ìpapòdà ọkàn fi wu àwọn amòye ẹ̀sìn Híńdù?
4 Ẹ̀sìn Híńdù ti bẹ̀rẹ̀ ní Íńdíà tipẹ́ ṣáájú ìgbà náà, ní ìgbà tí àwọn ìran Aryan débẹ̀ ní nǹkan bí ọdún 1500 ṣááju Sànmánì Tiwa. Láti ìbẹ̀rẹ̀ pàá, ẹ̀sìn Híńdù gbà gbọ́ pé ọkàn yàtọ̀ sí ara àti pé ọkàn ṣì máa ń wà láàyè lẹ́yìn ikú. Nípa báyìí, àwọn ẹlẹ́sìn Híńdù máa ń jọ́sìn àwọn baba ńlá wọn, wọn a sì tẹ́ oúnjẹ sílẹ̀ fún ọkàn àwọn òkú wọn láti jẹ. Ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún lẹ́yìn náà, tí èrò nípa ìpapòdà ọkàn dé Íńdíà, ó ti ní láti wu àwọn amòye inú ẹ̀sìn Híńdù tí wọ́n ṣì ń ṣakitiyan láti wá ojútùú sí ìṣòro ibi àti ìjìyà tí ń bá ènìyàn fínra kárí ayé. Ní pípa ìpapòdà ọkàn pọ̀ mọ́ ohun tí wọ́n pè ní òfin Kámà, òfin okùnfà àti àbájáde, àwọn amòye inú ẹ̀sìn Híńdù mú àbá èrò orí náà, àtúnwáyé, jáde, nípasẹ̀ èyí tí ènìyàn yóò fi gba èrè tàbí ìyà fún ire tàbí ibi tí ó ṣe nígbà ìgbé ayé kan nínú ìgbé ayé tí ó tẹ̀ lé e.
5. Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀sìn Híńdù ṣe fi kọ́ni, kí ni ó jẹ́ góńgó gíga jù lọ ọkàn?
5 Ṣùgbọ́n èrò kan ṣì wà tí ó nípa lórí ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn Híńdù nípa ọkàn. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Encyclopædia of Religion and Ethics sọ pé: “Ó dà bí pé òótọ́ ni pé, ní àkókò kan náà tí a ń gbé àbá èrò orí ti ìpapòdà ọkàn àti ti kámà kalẹ̀, tàbí ṣáájú ìgbà náà pàápàá, èrò mìíràn . . . ti ń fìdí múlẹ̀ bọ̀ láwùjọ àwọn sànmọ̀rí ènìyàn ní Àríwá Íńdíà—ẹ̀kọ́ èrò orí ti Brahman-Ātman [Brahman gíga jù lọ, ẹni ayérayé, tí ó jẹ́ atóbijù].” A pa èrò yìí pọ̀ mọ́ àbá èrò orí ti àtúnwáyé láti fi sọ ohun tí ó jẹ́ góńgó gíga jù lọ tí àwọn ẹlẹ́sìn Híńdù ń lépa—ìtúsílẹ̀ kúrò nínú yíyípo ìpapòdà láti lè wà níṣọ̀kan pẹ̀lú ẹni atóbijù náà. Ìwà ọmọlúwàbí láwùjọ àti àkànṣe ìmọ̀ nínú ẹ̀sìn Híńdù ni àwọn ẹlẹ́sìn Híńdù sì gbà gbọ́ pé ó lè jẹ́ kí ọwọ́ tẹ èyí.
6, 7. Kí ni àwọn ẹlẹ́sìn Híńdù òde òní gbà gbọ́ nípa Ìwàláàyè Lẹ́yìn Ikú?
6 Bí àwọn ọlọ́gbọ́n nínú ẹ̀sìn Híńdù ṣe yí èrò ti ìpapòdà ọkàn padà di ẹ̀kọ́ àìleèkú ọkàn nìyẹn nípa pípa á pọ̀ mọ́ òfin Kámà àti èrò Brahman. Octavio Paz, akéwì kan tí ó gba Ẹ̀bùn Nobel tí ó sì jẹ́ aṣojú ìjọba Mexico ní ilẹ̀ Íńdíà nígbà kan rí, kọ̀wé pé: “Bí ẹ̀sìn Híńdù ṣe ń tàn kalẹ̀ lọ, bẹ́ẹ̀ náà ni èrò kan . . . tí ó jẹ́ kókó pàtàkì nínú ẹ̀sìn Brahma, ẹ̀sìn Búdà, àti àwọn ẹ̀sìn ilẹ̀ Éṣíà yòókù: ìṣíkiri ọkàn, tí ì ṣe ìpapòdà àwọn ọkàn láti inú ìgbé ayé kan bọ́ sínú òmíràn ní ìtòtẹ̀léra, ṣe ń tàn kálẹ̀.”
7 Ẹ̀kọ́ àtúnwáyé ni òpómúléró ẹ̀sìn Híńdù òde òní. Nikhilananda, ọlọ́gbọ́n èrò orí ti ẹ̀sìn Híńdù, sọ pé: “Ohun tí gbogbo ògidì Híńdù gbà gbọ́ dájú ni pé, dídé ipò àìleèkú kì í ṣe àǹfààní kan tí ó wà fún kìkì àwọn kéréje kan tí a yàn, bí kò ṣe ogún ìbí gbogbo ènìyàn.”
Ìyípo Àbítúnbí Nínú Ẹ̀sìn Búdà
8-10. (a) Kí ni ẹ̀sìn Búdà sọ pé ìwàláàyè jẹ́? (b) Báwo ni ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan nínú ẹ̀sìn Búdà ṣe ṣàlàyé àtúnbí?
8 A fi ẹ̀sìn Búdà lọ́lẹ̀ ní Íńdíà ní nǹkan bí ọdún 500 ṣááju Sànmánì Tiwa. Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀kọ́ àtọwọ́dọ́wọ́ ẹ̀sìn Búdà ti sọ, ọmọba Íńdíà kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Siddhārtha Gautama, tí a wá mọ̀ sí Búdà lẹ́yìn tí ó ti gba ìlàlóye, ni ó dá ẹ̀sìn Búdà sílẹ̀. Bí ó ti jẹ́ pé inú ẹ̀sìn Híńdù ni ó ti pilẹ̀, àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀ jọ ti ẹ̀sìn Híńdù ní àwọn ọ̀nà kan. Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀sìn Búdà ṣe sọ, ìwàláàyè jẹ́ àyípo àbítúnbí àti àkútúnkú tí ń bá a nìṣó, àti pé, bí ti ẹ̀sìn Híńdù, ohun tí olúkúlùkù bá ṣe nígbà ayé rẹ̀ tí ó kọjá ní ń pinnu ipò rẹ̀ nínú ayé ti ìsinsìnyí.
9 Ṣùgbọ́n ẹ̀sìn Búdà kò fi ọ̀ràn ti pé ọkàn ṣì máa ń wà láàyè lẹ́yìn ikú ṣàlàyé ìwàláàyè. Arnold Toynbee sọ pé: “Ohun tí [Búdà] rí lára ènìyàn kò ju ọ̀wọ́ ìrònú òun ìṣesí ẹni, tí ó wà nípele-nípele gátagàta lásán, tí kì í wà pẹ́, tí ó sì jẹ́ pé kìkì ìfẹ́-ọkàn ni ó so ó pọ̀.” Síbẹ̀, Búdà gbà gbọ́ pé kiní kan—ipò tàbí ipá kan—wà tí a ń ta látaré láti ìgbé ayé kan sí òmíràn. Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ nínú ẹ̀sìn Búdà náà, Ọ̀mọ̀wé Walpola Rahula, ṣàlàyé pé:
10 “Ẹ̀dá kan kò ju àpapọ̀ ipá tàbí agbára tí ó ṣeé fojú rí àti ti èrò orí. Àìgbéṣẹ́ ara ìyára mọ́ rárá ni à ń pè ní ikú. Ṣé gbogbo ipá àti agbára wọ̀nyí máa ń dáwọ́ dúró pátápátá ni nígbà tí ara kò bá gbéṣẹ́ mọ́? Ẹ̀sìn Búdà sọ pé ‘Bẹ́ẹ̀ kọ́.’ Ìfẹ́ ẹni, ìpinnu ẹni, ìfẹ́-ọkàn, ìyánhànhàn láti wà láàyè, láti máa bá a nìṣó, láti máa bá àyípo àtúnbí nìṣó, ni ipá ńláǹlà tí ń ti gbogbo ìwàláàyè, gbogbo ìgbésí ayé pátá, tí ó tilẹ̀ ń ti gbogbo ayé pàápàá. Èyí ni ipá tí ó ga jù lọ, agbára tí ó ga jù lọ láyé. Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀sìn Búdà ṣe sọ, ipá yìí kì í dáwọ́ dúró nígbà tí ara kò bá ṣiṣẹ́ mọ́, tí í ṣe ikú; ṣùgbọ́n ó ń bá a lọ láti fara rẹ̀ hàn ní irú ọ̀nà mìíràn, tí ó sì máa ń fa pípadà wà láàyè tí a ń pè ní àtúnbí.”
11. Kí ni ojú ìwòye ẹ̀sìn Búdà nípa Ìwàláàyè Lẹ́yìn Ikú?
11 Ojú ìwòye ẹ̀sìn Búdà nípa Ìwàláàyè Lẹ́yìn Ikú ni pé: Ìwàláàyè jẹ́ gbére àyàfi bí onítọ̀hún bá dé góńgó ìkẹyìn ti Nirvana, ìtúsílẹ̀ nínú àyípo àbítúnbí. Nirvana kì í ṣe ipò ayọ̀ ayérayé bẹ́ẹ̀ ni kì í sì í ṣe ti ṣíṣọ̀kan pẹ̀lú ẹni atóbijù. Ó wulẹ̀ jẹ́ ipò àìwàláàyè—“ibi àìsí ikú” lẹ́yìn ìgbésí ayé ẹni. Ìwé atúmọ̀ èdè náà Webster’s Ninth New Collegiate Dictionary sọ pé “Nirvana” jẹ́ “ibi tàbí ipò kan tí a kò ti mọ ohun tí ń jẹ́ ìkẹ́, ìròra, tàbí ohun tí ń ṣẹlẹ̀ lóde ara.” A fún àwọn ẹlẹ́sìn Búdà níṣìírí pé dípò wíwá àìleèkú, kí wọ́n ré e kọjá nípa lílọ sí ipò Nirvana.
12-14. Báwo ni onírúurú ẹ̀ya ẹ̀sìn Búdà ṣe fi èrò àìleèkú kọ́ni?
12 Bí ẹ̀sìn Búdà ṣe ń tàn kálẹ̀ lọ sí onírúurú ibi ní Éṣíà, bẹ́ẹ̀ ni ó ń ṣe àtúnṣe sí àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀ láti lè gba ìgbàgbọ́ àdúgbò mọ́ra. Bí àpẹẹrẹ, ẹ̀sìn Búdà ti Mahayana, irú èyí tí ó wọ́pọ̀ jù lọ ní ilẹ̀ China àti Japan, nígbàgbọ́ pé àwọn ẹ̀dá abàmì kan, bodhisattva, tàbí Búdà ọjọ́ iwájú wà. Àwọn Bodhisattva máa ń sún dídé ipò Nirvana síwájú kí a bàa lè tún wọn bí láìmọye ìgbà fún ète sísin àwọn ẹlòmíràn kí wọ́n sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti dé ipò Nírvana. Nípa báyìí, ẹnì kan lè yàn láti máa bá àyípo àtúnbí nìṣó kódà lẹ́yìn tí ó bá ti dé ipò Nirvana.
13 Àtúnṣe mìíràn tí ó wá nípa lórí wọn ní pàtàkì ní ilẹ̀ China àti Japan ni ẹ̀kọ́ Ilẹ̀ Mímọ́ Níhà Ìwọ̀-Oòrùn, èyí tí Buddha Amitabha, tàbí Amida gbé kalẹ̀. Àwọn tí ó bá ń fi ìgbàgbọ́ ké pe orúkọ Búdà ni a óò túnbí sínú Ilẹ̀ Mímọ́, tàbí párádísè, níbi tí ipò àwọn nǹkan ti túbọ̀ rọrùn fúnni láti dé ipò ìlàlóye ìkẹyìn. Kí ni ó ti jẹyọ láti ara ẹ̀kọ́ yìí? Ọ̀jọ̀gbọ́n Smart, tí a ti mẹ́nu kàn níṣàájú, ṣàlàyé pé: “Bí a ti lè retí, ìdángbinrin párádísè, tí àwọn kan lára ìwé mímọ́ Mahayana ṣàpèjúwe rẹ̀ ní kedere, wá gbapò nirvana lọ́kàn àwọn púpọ̀, gẹ́gẹ́ bí góńgó tí ó ga jù lọ.”
14 Ẹ̀sìn Búdà ní ilẹ̀ Tibet fi ìgbàgbọ́ mìíràn ládùúgbò kún un. Bí àpẹẹrẹ, ìwé tí ilẹ̀ Tibet kọ nípa àwọn òkú ṣàpèjúwe kádàrá olúkúlùkù ní ipò tí ó wà ní agbedeméjì ṣáájú àtúnbí ẹni. Ó sọ pé ṣe ni wọ́n máa ń ṣí àwọn òkú payá sí ìmọ́lẹ̀ ẹni atóbijù náà tí ó mọ́lẹ̀ rekete, àwọn tí kò bá sì lè fara da ìmọ́lẹ̀ náà kò ní gba ìtúsílẹ̀ bí kò ṣe pé a óò tún wọn bí. Dájúdájú, èrò àìleèkú ni ẹ̀sìn Búdà lónírúurú fi ń kọ́ni.
Ìjọsìn Àwọn Baba Ńlá Nínú Ẹ̀sìn Ṣintó ti Japan
15-17. (a) Báwo ni bíbọ àwọn ìṣẹ̀run ṣe bẹ̀rẹ̀ nínú ẹ̀sìn Ṣintó? (b) Báwo ni ìgbàgbọ́ nínú àìleèkú ọkàn ṣe jẹ́ òpómúléró nínú ẹ̀sìn Ṣintó?
15 Ẹ̀sìn ti wà ní Japan kí ẹ̀sìn Búdà tó débẹ̀ ní ọ̀rúndún kẹfà ní Sànmánì Tiwa. Ẹ̀sìn tí kò lórúkọ ni, ó sì jẹ́ àpapọ̀ ìgbàgbọ́ àwọn ènìyàn ibẹ̀ ní ìsopọ̀ pẹ̀lú àṣà àti ìṣe wọn. Ṣùgbọ́n nígbà tí ẹ̀sìn Búdà wọ ibẹ̀, ó di dandan pé kí a ṣèyàtọ̀ láàárín ẹ̀sìn ilẹ̀ Japan àti ti àjèjì. Bí orúkọ náà, “Ṣintó,” tí ó túmọ̀ sí “ọ̀nà àwọn ọlọ́run,” ṣe yọjú nìyẹn.
16 Kí ni ìgbàgbọ́ àwọn Ṣintó ìpilẹ̀ṣẹ̀ nípa Ìwàláàyè Lẹ́yìn Ikú? Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Kodansha Encyclopedia of Japan ṣàlàyé pé, bí gbígbin ìrẹsì sí ilẹ̀ àbàtà ṣe dóde, “ṣíṣe ọ̀gbìn lórí ilẹ̀ àbàtà mú kí ó di dandan pé kí àwùjọ wà létòlétò kí wọ́n sì wà lójú kan, bí ààtò ẹbọ àgbẹ̀—tí ó wá padà kó ipa pàtàkì nínú ẹ̀sìn Ṣintó—ṣe délẹ̀ nìyẹn.” Ìbẹ̀rù àwọn ọkàn tí ó ti papò dà sì mú kí àwọn ènìyàn náà gbé àwọn ààtò láti fi tù wọ́n lójú kalẹ̀. Èyí wá di bíbọ tí wọ́n ń bọ àwọn ìṣẹ̀run.
17 Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀sìn Ṣintó ṣe kọ́ni, ìṣarasíhùwà ọkàn tí ó “papò dà” ṣì wà lára rẹ̀ ṣùgbọ́n ikú ti tàbààwọ́n sí i. Tí àwọn olóòkú bá ti ṣe àwọn ààtò ìrántí, ọkàn rẹ̀ a di fífọ̀mọ́ dé bi pé gbogbo kèéta ibẹ̀ yóò kúrò tí yóò sì wá di ẹlẹ́mìí àlàáfíà àti aṣenilóore. Nígbà tí ó bá yá, ìṣẹ̀run náà a wá dé ipò òrìṣà àjúbàfún, tàbí atọ́nisọ́nà. Bí ẹ̀sìn Ṣintó ṣe wà pa pọ̀ pẹ̀lú ẹ̀sìn Búdà, ó ti gba mélòó kan nínú àwọn ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn Búdà mọ́ra, títí kan ẹ̀kọ́ nípa párádísè. Nípa báyìí, a wá rí i pé ìgbàgbọ́ nínú àìleèkú jẹ́ òpómúléró nínú ẹ̀sìn Ṣintó.
Àìleèkú Nínú Ẹ̀sìn Tao, Ìjọsìn Àwọn Baba Ńlá Nínú Ẹ̀sìn Confucius
18. Kí ni èrò àwọn ẹlẹ́sìn Tao nípa àìleèkú?
18 Lao-tzu, tí a sọ pé ó gbé ní China ní ọ̀rúndún kẹfà ṣááju Sànmánì Tiwa ni ó dá ẹ̀sìn Tao sílẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀sìn Tao ṣe fi kọ́ni, góńgó ìwàláàyè ni láti mú kí ìgbòkègbodò ènìyàn wà níṣọ̀kan pẹ̀lú Tao—ọ̀nà ìṣẹ̀dá. Èrò ẹlẹ́sìn Tao nípa àìleèkú ni a lè ṣàkópọ̀ rẹ̀ lọ́nà yìí: Tao jẹ́ ìlànà tí ń ṣàkóso àgbáyé. Tao kò ní ìbẹ̀rẹ̀ kò sì lópin. Bí ẹnì kan bá gbé ní ìbámu pẹ̀lú Tao, yóò kópa nínú rẹ̀ yóò sí di ẹni ayérayé.
19-21. Àbá àwọn ẹlẹ́sìn Tao sún wọn dórí ṣíṣe kí ni?
19 Bí àwọn ẹlẹ́sìn Tao ṣe ń sapá láti wà níṣọ̀kan pẹ̀lú ìṣẹ̀dá, kò pẹ́ tí wọ́n fi ní ìfẹ́ àkànṣe nínú wíwà tí ó wà gbére tí ó sì rọ́kú. Wọ́n méfò pé bóyá nípa gbígbé ní ìbámu pẹ̀lú Tao, tàbí ọ̀nà ìṣẹ̀dá, ènìyàn lè lọ ṣàwárí àṣírí ìṣẹ̀dá bákan ṣá kí ó sì rí àjẹsára tí yóò dènà ìpalára, àìsàn, àti ikú pàápàá.
20 Àwọn ẹlẹ́sìn Tao wá bẹ̀rẹ̀ sí ṣe àṣeyẹ̀wò lórí àṣàrò ṣíṣe, mímí sínú àti sóde, àti ìlànà síse oúnjẹ jẹ, èyí tí wọ́n sọ pé ó lè fawọ́ ìdíbàjẹ́ ara àti ikú sẹ́yìn. Láìpẹ́, ìtàn àtẹnudẹ́nu bẹ̀rẹ̀ sí tàn kálẹ̀ pé àwọn ẹ̀dá àìleèkú kan wà tí wọ́n lè fò lójú sánmà, tí wọ́n lè fara hàn kí wọ́n sì pòórá bí wọ́n ṣe fẹ́, tí wọ́n sì ń gbé orí àwọn òkè ńláńlá ọlọ́wọ̀ tàbí ní àwọn erékùṣù jíjìnnà réré láti àìmọye ọdún wá, tí ó jẹ́ pé ìrì tàbí àwọn èso idán ní ń gbẹ́mìí wọn ró. Ìtàn ilẹ̀ China sọ pé ní ọdún 219 ṣááju Sànmánì Tiwa, olú-ọba Ch’in Shih Huang Ti rán ọ̀wọ́ ọkọ̀ òkun kan tòun ti 3,000 ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin láti lọ wá erékùṣù P’eng-lai, tí ìtàn àròsọ sọ pé ó jẹ́ ibùgbé àwọn ẹ̀dá àìleèkú, kí wọ́n bàa lè gba egbòogi àìleèkú bọ̀. Láìwulẹ̀ déènà pẹnu, gbogbo-ǹ-ṣe náà kò bá wọn wá.
21 Wíwá tí àwọn ẹlẹ́sìn Tao ń wá ìyè ayérayé kiri mú kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ṣe àṣeyẹ̀wò lórí fífi ìlànà ìṣegbékúdè ṣe àwọn egbòogi àìleèkú oníhóró. Lójú ẹlẹ́sìn Tao, ìwàláàyè ni ó máa ń yọrí sí nígbà tí ipá títakora méjì, yin àti yang (abo àti akọ), bá pa pọ̀. Nítorí náà, àwọn aṣegbékúdè wọ̀nyí ń ṣàfarawé ìṣẹ̀dá nípa yíyọ́ òjé (àwọ̀ dúdú tàbí yin) pa pọ̀ mọ́ mẹ́kúrì (àwọ̀ títàn yanran tàbí yang), wọ́n sì rò pé ohun tí ó bá ti ibẹ̀ jáde yóò di egbòogi àìleèkú oníhóró.
22. Kí ni àbájáde ipa tí ẹ̀sìn Búdà ní lórí ọ̀nà ìgbàjọ́sìn àwọn ará China?
22 Nígbà tí yóò fi di ọ̀rúndún keje Sànmánì Tiwa, ẹ̀sìn Búdà ti kó wọ ọ̀nà ìgbàjọ́sìn àwọn ará China. Àbájáde rẹ̀ ni pé, àwọn ẹ̀kọ́ díẹ̀ láti inú ẹ̀sìn Búdà, díẹ̀ nínú ìbẹ́mìílò, àti díẹ̀ nínú ìjọsìn baba ńlá wá para pọ̀ di àmúlùmálà kan ṣoṣo. Ọ̀jọ̀gbọ́n Smart sọ pé: “Ẹ̀sìn Búdà àti ti Tao ni ó gbé ìgbàgbọ́ nínú ìyè lẹ́yìn ikú, tí kò fi bẹ́ẹ̀ lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ nínú ìjọsìn àwọn baba ńlá ní ilẹ̀ China ìgbàanì, kalẹ̀ lẹ́sẹẹsẹ tí wọ́n sì fún un nítumọ̀.”
23. Kí ni ìhà tí Confucius kọ sí jíjọ́sìn àwọn baba ńlá?
23 Confucius, tí ó tún jẹ́ gbajúmọ̀ amòye ní China ní ọ̀rúndún kẹfà ṣááju Sànmánì Tiwa, tí ẹ̀kọ́ ọgbọ́n èrò orí tirẹ̀ di ìpìlẹ̀ fún ẹ̀sìn Confucius, kò fi bẹ́ẹ̀ ṣàlàyé púpọ̀ lórí Ìwàláàyè Lẹ́yìn Ikú. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìjẹ́pàtàkì jíjẹ́ onínúure àti ìwà ọmọlúwàbí ni ó tẹnu mọ́. Àmọ́, ó fi ojú tí ó sunwọ̀n wo jíjọ́sìn àwọn baba ńlá, ó sì tẹnu mọ́ pípa àwọn ààtò àti ayẹyẹ tí ó jẹ mọ́ ti bíbọ àwọn ìṣẹ̀run mọ́ gidigidi.
Àwọn Ẹ̀sìn Ìlà-Oòrùn Yòókù
24. Kí ni ẹ̀sìn Jéìnì fi kọ́ni nípa ọkàn?
24 A dá ẹ̀sìn Jéìnì sílẹ̀ ní Íńdíà ní ọ̀rúndún kẹfà ṣááju Sànmánì Tiwa. Mahāvīra, tí ó dá a sílẹ̀, kọ́ni pé gbogbo ẹ̀dá alààyè ni ó ní ọkàn ayérayé, àti pé ìsẹ́ra-ẹni pẹ̀lú títọ́ra-ẹni dé góńgó àti ṣíṣàìhùwà-ipá sí gbogbo ìṣẹ̀dá lọ́nàkọ́nà nìkan ni ó lè gba ọkàn là kúrò nínú ìgbèkùn òfin Kámà. Ìgbàgbọ́ àwọn Jéìnì títí di òní nìwọ̀nyí.
25, 26. Àwọn ìgbàgbọ́ ẹ̀sìn Híńdù wo ni a rí nínú ẹ̀sìn Síìkì pẹ̀lú?
25 Íńdíà tún ni ibi tí ẹ̀sìn Síìkì, tí mílíọ̀nù 19 ènìyàn ń ṣe, ti bẹ̀rẹ̀. Ẹ̀sìn yìí bẹ̀rẹ̀ ní ọ̀rúndún kẹrìndínlógún, nígbà tí Guru Nānak pinnu láti ṣe àyípọ̀ ohun tí ó dára jù lọ nínú ẹ̀sìn Híńdù àti ti Ìsìláàmù láti lè dá ẹ̀sìn oníṣọ̀kan sílẹ̀. Ẹ̀sìn Síìkì tẹ́wọ́ gba ìgbàgbọ́ ẹ̀sìn Híńdù nípa àìleèkú ọkàn, àtúnwáyé, àti Kámà.
26 Dájúdájú, ìgbàgbọ́ náà pé ìwàláàyè ń bá a nìṣó lẹ́yìn ikú ara jẹ́ apá tí ó ṣe kókó nínú àwọn ẹ̀sìn Ìlà-Oòrùn. Ṣùgbọ́n, àwọn Kirisẹ́ńdọ̀mù, ẹ̀sìn àwọn Júù àti Ìsìláàmù wá ńkọ́?
[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 10]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
ÀÁRÍN GBÙNGBÙN ÉṢÍÀ
KASHMIR
TIBET
CHINA
KOREA
JAPAN
Banaras
ÍŃDÍÀ
Buddh Gaya
MYANMAR
THAILAND
SRI LANKA
CAMBODIA
JAVA
Ọ̀RÚNDÚN KẸTA ṢÁÁJU SÀNMÁNÌ TIWA
Ọ̀RÚNDÚN KÌÍNÍ ṢÁÁJU SÀNMÁNÌ TIWA
Ọ̀RÚNDÚN KÌÍNÍ SÀNMÁNÌ TIWA
Ọ̀RÚNDÚN KẸRIN SÀNMÁNÌ TIWA
Ọ̀RÚNDÚN KẸFÀ SÀNMÁNÌ TIWA
Ọ̀RÚNDÚN KEJE SÀNMÁNÌ TIWA
Ẹ̀sìn Búdà nípa lórí gbogbo Ìlà-Oòrùn Éṣíà
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Ìgbàgbọ́ nínú àtúnwáyé ni igi lẹ́yìn ọgbà ẹ̀sìn Híńdù
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]
Nípa gbígbé ní ìbámu pẹ̀lú ìṣẹ̀dá, àwọn ẹlẹ́sìn Tao ń sapá láti di ẹni ayérayé
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]
Confucius fojú rere wo jíjọ́sìn àwọn baba ńlá