Èrò Náà Wọnú Ẹ̀sìn Àwọn Júù, Kirisẹ́ńdọ̀mù, àti Ìsìláàmù
“Ẹ̀sìn wà lára ọ̀nà tí a ń gbà mú kí àwọn ènìyàn gba òkodoro òtítọ́ náà gbọ́ pé ó di dandan kí àwọn kú lọ́jọ́ kan ṣáá, ì báà jẹ́ nípa ṣíṣèlérí ìgbésí ayé tí ó túbọ̀ gbé pẹ́ẹ́lí sí i lẹ́yìn ikú, àtúnbí, tàbí méjèèjì.”—GERHARD HERM, ÒǸṢÈWÉ, ỌMỌ ILẸ̀ GERMANY.
1. Orí ìgbàgbọ́ pàtàkì wo ni ọ̀pọ̀ jù lọ ẹ̀sìn gbé ìlérí wọn nípa ìwàláàyè lẹ́yìn ikú kà?
NÍ TI ṣíṣèlérí ìgbésí ayé lẹ́yìn ikú, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo ẹ̀sìn ni ó gbára lé ìgbàgbọ́ náà pé ènìyàn ní ọkàn kan tí ó jẹ́ àìleèkú, àti pé lẹ́yìn ikú a máa gbéra lọ sí ilẹ̀ ọba mìíràn, tàbí kí ó papò dà di ẹ̀dá mìíràn. Bí a ti fi hàn nínú apá tí ó ṣáájú èyí, ìgbàgbọ́ nínú àìleèkú ọkàn jẹ́ apá ṣíṣe kókó nínú ẹ̀sìn àwọn ará Ìlà-Oòrùn láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ wọn. Àmọ́, ẹ̀sìn àwọn Júù, Kirisẹ́ńdọ̀mù, àti Ìsìláàmù ńkọ́? Báwo ni ẹ̀kọ́ yìí ṣe wá di òpómúléró nínú ẹ̀sìn wọ̀nyí?
Ẹ̀sìn Àwọn Júù Gba Èrò Àwọn Gíríìkì Mọ́ra
2, 3. Gẹ́gẹ́ bí ìwé agbédègbẹ́yọ̀ Encyclopædia Judaica ṣe wí, ìwé mímọ́ àwọn Hébérù ha fi àìleèkú ọkàn kọ́ni bí?
2 Ìpilẹ̀ṣẹ̀ ẹ̀sìn àwọn Júù lọ jìnnà ṣẹ́yìn tó nǹkan bí 4,000 ọdún, sọ́dọ̀ Ábúráhámù. A bẹ̀rẹ̀ sí kọ ìwé mímọ́ àwọn Hébérù ní ọ̀rúndún kẹrìndínlógún ṣááju Sànmánì Tiwa, a sì parí rẹ̀ ní ìgbà tí Socrates àti Plato ṣàgbékalẹ̀ àbá èrò orí àìleèkú ọkàn. Ìwé Mímọ́ wọ̀nyí ha fi àìleèkú ọkàn kọ́ni bí?
3 Ìwé agbédègbẹ́yọ̀ Encyclopædia Judaica dáhùn pé: “Ẹ̀yìn ìgbà tí a kọ Bíbélì tán ni ìgbàgbọ́ tí ó hàn kedere tí ó sì fìdí múlẹ̀ nípa àìleèkú ọkàn ṣẹ̀ṣẹ̀ di èyí tí ó fẹsẹ̀ múlẹ̀ . . . tí ó sì wá di ọ̀kan nínú òkúta ìpìlẹ̀ ìgbàgbọ́ ẹ̀sìn àwọn Júù àti ti Kristẹni.” Ó tún sọ pé: “Odindi kan ni a ka ènìyàn sí ní ìgbà tí a ń kọ Bíbélì. Nípa báyìí, a kò fi ìyàtọ̀ pàtó sáàárín ọkàn àti ara.” Àwọn Júù ìjímìjí nígbàgbọ́ nínú àjíǹde àwọn òkú, ìwé agbédègbẹ́yọ̀ náà sì sọ pé “a gbọ́dọ̀ mọ̀ pé ó yàtọ̀ sí ìgbàgbọ́ nínú . . . àìleèkú ọkàn.”
4-6. Báwo ni ẹ̀kọ́ àìleèkú ọkàn ṣe di “ọ̀kan nínú òkúta ìpìlẹ̀” ẹ̀sìn àwọn Júù?
4 Nígbà náà, báwo ni ẹ̀kọ́ yìí ṣe wá di “ọ̀kan nínú òkúta ìpìlẹ̀” ẹ̀sìn àwọn Júù? Ìtàn fúnni ní ìdáhùn rẹ̀. Ní ọdún 332 ṣááju Sànmánì Tiwa, Alẹkisáńdà Ńlá ṣẹ́gun èyí tí ó pọ̀ jù lára ilẹ̀ Àárín Gbùngbùn Ìlà-Oòrùn ní wàrà-ǹ-ṣeṣà. Bí ó ṣe dé Jerúsálẹ́mù, àwọn Júù tẹ́wọ́ gbà á tọ̀yàyàtọ̀yàyà. Gẹ́gẹ́ bí Flavius Josephus, òpìtàn àwọn Júù ní ọ̀rúndún kìíní, ṣe wí, wọ́n tilẹ̀ fi àsọtẹ́lẹ̀ inú ìwé Dáníẹ́lì hàn án, èyí tí a ti kọ ní ohun tí ó ju 200 ọdún ṣáájú ìgbà náà, tí ó ṣàpèjúwe àwọn ìṣẹ́gun Alẹkisáńdà ní kedere gẹ́gẹ́ bí ẹni tí í ṣe “ọba Gíríìsì.” (Dáníẹ́lì 8:5-8, 21) Àwọn arọ́pò Alẹkisáńdà ń bá ètè rẹ̀ ti sísọni di Hélénì nìṣó, tí wọ́n mú kí èdè, àṣà ìbílẹ̀ àti ọgbọ́n èrò orí àwọn Gíríìkì gbalẹ̀ kan níbi gbogbo nínú ilẹ̀ ọba rẹ̀. Àyípọ̀ àṣà ìbílẹ̀ méjèèjì—ti Gíríìkì àti ti àwọn Júù—kò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀.
5 Ní apá ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún kẹta ṣááju Sànmánì Tiwa, a bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ìtumọ̀ àkọ́kọ́ ti Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù sí èdè Gíríìkì, a pè é ní Septuagint. Nípasẹ̀ rẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn Kèfèrí di ẹni tí ó bọ̀wọ̀ fún ẹ̀sìn àwọn Júù wọ́n sì wá mọ̀ ọ́n dáadáa, àwọn kan tilẹ̀ di ẹlẹ́sìn àwọn Júù. Àwọn Júù ní ti wọn, ti wá ń mọ̀ nípa èrò àwọn Gíríìkì, àwọn kan sì di ọlọ́gbọ́n èrò orí, ohun kan tí ó ṣàjèjì sí wọn gbáà. Ọ̀kan nínú irú àwọn Júù ọlọ́gbọ́n èrò orí bẹ́ẹ̀ ni Philo ti Alẹkisáńdíríà ti ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa.
6 Philo bọ̀wọ̀ fún Plato, ó sì sakun láti fi ọ̀rọ̀ ọgbọ́n èrò orí àwọn Gíríìkì ṣàlàyé ẹ̀sìn àwọn Júù. Ìwé náà, Heaven—A History, sọ pé: “Nípa gbígbé àdàlù àrà ọ̀tọ̀ kan tí ó jẹ́ ti ọgbọ́n èrò orí Plato àti àṣà àfilénilọ́wọ́ ti Bíbélì kalẹ̀, ṣe ni Philo lànà sílẹ̀ fún àwọn afìrònú-ṣiṣẹ́ṣe ti Kristẹni [àti ti àwọn Júù].” Kí sì ni Philo gbà gbọ́ nípa ọkàn? Ìwé náà ń bá a lọ pé: “Lójú tirẹ̀, ṣe ni ikú tún dá ọkàn padà sí ipò tí ó wà ní ìpilẹ̀ṣẹ̀ kí a tó bí i. Níwọ̀n bí ọkàn ti jẹ́ ti ayé ẹ̀mí, ìwàláàyè nínú ara ìyára wulẹ̀ jẹ́ ẹ̀ka kúkúrú kan, tí ó sábà máa ń jẹ́ oníbànújẹ́.” Lára àwọn Júù afìrònú-ṣiṣẹ́ṣe mìíràn tí wọ́n gba àìleèkú ọkàn gbọ́ ni Isaac Israeli, gbajúmọ̀ oníṣègùn ti ọ̀rúndún kẹwàá náà, àti Moses Mendelssohn, Júù kan tí ó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Germany, ọlọ́gbọ́n èrò orí ti ọ̀rúndún kejìdínlógún.
7, 8. (a) Báwo ni Talmud ṣe ṣàpèjúwe ọkàn? (b) Kí ni àwọn ìwé idán àwọn Júù ẹ̀yìn ìgbà náà sọ nípa ọkàn?
7 Ìwé kan tí ó ti nípa lórí ìrònú àti ìgbésí ayé àwọn Júù gidigidi ni Talmud—àkọsílẹ̀ àkópọ̀ ohun tí wọ́n pè ní òfin àtẹnudẹ́nu, àti àwọn atótónu òun àlàyé lórí òfin yìí tí a ṣe lẹ́yìn náà, tí àwọn rábì ṣàkójọ rẹ̀ láti ọ̀rúndún kejì Sànmánì Tiwa dé Sànmánì Agbedeméjì. Ìwé agbédègbẹ́yọ̀ Encyclopædia Judaica sọ pé: “Àwọn tí ń kọ́ni ní Talmud nígbàgbọ́ nínú pé ọkàn ṣì máa ń wà láàyè lẹ́yìn ikú.” Talmud tilẹ̀ sọ pé òkú máa ń kàn sí alààyè. Ìwé agbédègbẹ́yọ̀ Encyclopædia of Religion and Ethics sọ pé: “Bóyá tìtorí agbára ìdarí tí ẹ̀kọ́ Plato ní, àwọn [rábì] gbà gbọ́ pé ọkàn ti máa ń wà láàyè kí a tó bíni.”
8 Kódà, Cabala, ìwé idán àwọn Júù ẹ̀yìn ìgbà náà, tilẹ̀ kúkú fi àtúnwáyé kọ́ni. Ìwé agbédègbẹ́yọ̀ The New Standard Jewish Encyclopedia ṣàlàyé pé: “Ó jọ pé Íńdíà ni èrò náà ti pilẹ̀. . . . Nínú ìwé Kabbalah, inú ìwé Bahir ni ó ti kọ́kọ́ fara hàn, lẹ́yìn náà, láti inú Zohar síwájú, ó di ohun tí àwọn apidán tẹ́wọ́ gbà fàlàlà, tí ó sì kó ipa pàtàkì nínú ìgbàgbọ́ àti àròkọ ẹgbẹ́ awo Hasid.” Ní Ísírẹ́lì lónìí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ó tẹ́wọ́ gba àtúnwáyé gẹ́gẹ́ bí ẹ̀kọ́ tí àwọn Júù fi kọ́ni.
9. Kí ni ojú ìwòye ọ̀pọ̀ jù lọ ẹ̀ya ẹ̀sìn àwọn Júù lónìí nípa àìleèkú ọkàn?
9 Nítorí náà, èrò àìleèkú ọkàn tipasẹ̀ agbára ìdarí ọgbọ́n èrò orí àwọn Gíríìkì wọnú ẹ̀sìn àwọn Júù, tí ọ̀pọ̀ jù lọ ẹ̀ya rẹ̀ sì wá tẹ́wọ́ gba èrò yìí lónìí. Kí ni a lè sọ nípa bí ẹ̀kọ́ náà ṣe wọnú Kirisẹ́ńdọ̀mù?
Kirisẹ́ńdọ̀mù Tẹ́wọ́ Gba Àwọn Èrò Plato
10. Kí ni òpin èrò tí gbajúmọ̀ ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀, ọmọ ilẹ̀ Sípéènì kan dé nípa ìgbàgbọ́ Jésù nípa àìleèkú ọkàn?
10 Ojúlówó ẹ̀sìn Kristẹni bẹ̀rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Jésù Kristi. Ohun tí Miguel de Unamuno, gbajúmọ̀ ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀, ọmọ ilẹ̀ Sípéènì ti ọ̀rúndún ogún kọ nípa Jésù ni pé: “Àjíǹde ara ìyára, gẹ́gẹ́ bí àwọn Júù ṣe mọ̀ ọ́n sí, ni òun gbà gbọ́, kì í ṣe àìleèkú ọkàn, gẹ́gẹ́ bí Plato [Gíríìkì] ṣe fi kọ́ni. . . . Ẹ̀rí èyí ni a lè rí nínú èyíkéyìí nínú àwọn ìwé ògbufọ̀ aláìlábòsí.” Ó parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Àìleèkú ọkàn . . . jẹ́ ẹ̀kọ́ èrò orí àwọn abọ̀rìṣà.”
11. Ìgbà wo ni ọgbọ́n èrò orí àwọn Gíríìkì bẹ̀rẹ̀ sí wọnú ẹ̀sìn Kristẹni?
11 Ìgbà wo àti báwo ni “ẹ̀kọ́ èrò orí àwọn abọ̀rìṣà” yìí ṣe wọnú ẹ̀sìn Kristẹni ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀? Ìwé agbédègbẹ́yọ̀ New Encyclopædia Britannica sọ pé: “Láti agbedeméjì ọ̀rúndún kejì Lẹ́yìn Ikú Olúwa Wa, àwọn Kristẹni tí ó bá ti gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ nínú ọgbọ́n èrò orí àwọn Gíríìkì máa ń fẹ́ fi àwọn gbólóhùn ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣàlàyé ìgbàgbọ́ tiwọn láti lè gbé ìmọ̀ wọn yọ àti láti lè yí àwọn abọ̀rìṣà tí ó jẹ́ ọ̀mọ̀wé lọ́kàn padà. Ọgbọ́n èrò orí tí ó yá wọn lára láti lò jù lọ ni ti Plato.”
12-14. Kí ni ipa tí Origen àti Augustine kó nínú yíyí ẹ̀kọ́ ọgbọ́n èrò orí Plato pọ̀ mọ́ ẹ̀sìn Kristẹni?
12 Àwọn ọlọ́gbọ́n èrò orí ìjímìjí méjì bẹ́ẹ̀ ni wọ́n lo ipa tí ó pọ̀ gidigidi lórí ẹ̀kọ́ Kirisẹ́ńdọ̀mù. Ọ̀kan ni Origen ti Alẹkisáńdíríà (nǹkan bí ọdún 185 sí 254 Sànmánì Tiwa), ìkejì ni Augustine ti Hippo (ọdún 354 sí 430 Sànmánì Tiwa). Ìwé agbédègbẹ́yọ̀ New Catholic Encyclopedia ṣàlàyé nípa wọn pé: “Kìkì ọ̀dọ̀ Origen ní Ìlà-Oòrùn àti St. Augustine ní Ìwọ̀-Oòrùn ni a ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ọkàn jẹ́ ohun tẹ̀mí kan, ibẹ̀ sì ni a ti gbé àbá èrò orí kalẹ̀ nípa bí ó ṣe jẹ́.” Orí ìpìlẹ̀ wo ni Origen àti Augustine gbé àbá èrò orí wọn nípa ọkàn kà?
13 Ìwé agbédègbẹ́yọ̀ New Catholic Encyclopedia sọ pé Origen jẹ́ ọmọ ilé ẹ̀kọ́ Clement ti Alẹkisáńdíríà tí ó jẹ́ “Baba Ṣọ́ọ̀ṣì tí ó kọ́kọ́ yá àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn Gíríìkì nípa ọkàn lò lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́.” Àwọn èrò Plato nípa ọkàn ti ní láti nípa lórí Origen gidigidi. Ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn náà, Werner Jaeger, kọ ọ́ sínú ìwé ìròyìn The Harvard Theological Review pé: “Gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀ ẹ̀kọ́ nípa ọkàn tí [Origen] kọ́ lọ́dọ̀ Plato pátá ni ó gbé wọnú ẹ̀kọ́ Kristẹni.”
14 Àwọn kan ní Kirisẹ́ńdọ̀mù ka Augustine sí ẹni tí ó ga jù lọ nínú àwọn afìrònú-ṣiṣẹ́ṣe ìgbàanì. Kí Augustine tó di ẹlẹ́sìn “Kristẹni” ní ọmọ ọdún 33, ó ti nífẹ̀ẹ́ púpọ̀púpọ̀ sí ọgbọ́n èrò orí, ó sì ti di olùtẹ̀lé Àtúnṣe Èrò Plato.a Nígbà tí ó yí padà, bí olùtẹ̀lé Àtúnṣe Èrò Plato ni ó ṣì ṣe ń ronú. Ìwé agbédègbẹ́yọ̀ The New Encyclopædia Britannica sọ pé: “Ọpọlọ rẹ̀ ni agbada tí a ti yọ́ ẹ̀sìn Májẹ̀mú Tuntun pọ̀ pátápátá mọ́ àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ ti Plato nípa ọgbọ́n èrò orí àwọn Gíríìkì.” Ìwé agbédègbẹ́yọ̀ New Catholic Encyclopedia gbà pé “Àtúnṣe Èrò Plato . . . ni orísun pàtàkì fún ẹ̀kọ́” Augustine “[nípa ọkàn], tí ó wá di ìlànà ní Ìlà-Oòrùn títí di ọ̀rúndún kejìlá.”
15, 16. Ìfẹ́ nínú àwọn ẹ̀kọ́ Aristotle ní ọ̀rúndún kẹtàlá ha yí ìdúró ṣọ́ọ̀ṣì padà lórí ẹ̀kọ àìleèkú ọkàn?
15 Ní ọ̀rúndún kẹtàlá, àwọn ẹ̀kọ́ Aristotle ń gbilẹ̀ ní Yúróòpù, ní pàtàkì tìtorí pé ìwé àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ ará Arébíà tí wọ́n ṣe kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé lórí àwọn ìwé Aristotle wà lárọ̀ọ́wọ́tó ní èdè Látìn. Ìrònú Aristotle nípa tí ó jinlẹ̀ lórí ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ nínú ẹ̀sìn Kátólíìkì kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Thomas Aquinas. Nítorí àwọn ìwé Aquinas, ojú ìwòye Aristotle ní ipa tí ó túbọ̀ lágbára sí i lórí ẹ̀kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì ju ti Plato lọ. Àmọ́, ìtẹ̀sí yìí kò nípa lórí ẹ̀kọ́ àìleèkú ọkàn.
16 Aristotle fi kọ́ni pé ṣe ni ọkàn so pọ̀ mọ́ ara lọ́nà tí kò ṣeé yà sọ́tọ̀, pé kì í sì í dá wà láàyè lẹ́yìn ikú àti pé bí ohunkóhun tí ó jẹ́ ayérayé bá wà nínú ènìyàn, agbára ìmòye ẹni, tí kì í ṣe ẹ̀dá gidi kan ni. Fífi irú ojú yìí wo ọkàn kò bá ìgbàgbọ́ ṣọ́ọ̀ṣì pé ọkàn ẹni ṣì máa ń wà láàyè lẹ́yìn ikú mu. Nítorí náà, Aquinas ṣàtúnṣe sí ojú ìwòye Aristotle nípa ọkàn, ní fífi ìtẹnumọ́ kéde pé àìleèkú ọkàn ni a lè fi ẹ̀rí rẹ̀ múlẹ̀ nípa ṣíṣàlàyé rẹ̀. Nípa báyìí, ìgbàgbọ́ ṣọ́ọ̀ṣì nínú àìleèkú ọkàn wà bẹ́ẹ̀ láìyingin.
17, 18. (a) Ẹgbẹ́ Aṣàtúnṣe sí Ẹ̀sìn ti ọ̀rúndún kẹrìndínlógún ha ṣàtúnṣe sí ẹ̀kọ́ àìleèkú ọkàn bí? (b) Kí ni ojú ìwòye ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ìjọ Kirisẹ́ńdọ̀mù nípa àìleèkú ọkàn?
17 Láàárín ọ̀rúndún kẹrìnlá sí ìkẹẹ̀ẹ́dógún, ní apá ìbẹ̀rẹ̀ ìgbà Ìmúsọjí Ọ̀làjú, a tún mú ìfẹ́ nínú Plato sọjí. Ìdílé Medici, tí ó gbajúmọ̀ ní Ítálì, tilẹ̀ ṣèrànwọ́ láti dá ilé ẹ̀kọ́ Plato sílẹ̀ ní ìlú Florence láti gbé ẹ̀kọ́ nípa ọgbọ́n èrò orí Plato lárugẹ. Láàárín ọ̀rúndún kẹrìndínlógún sí ìkẹtàdínlógún ìfẹ́ nínú Aristotle lọ sílẹ̀. Ẹgbẹ́ Aṣàtúnṣe sí Ẹ̀sìn ti ọ̀rúndún kẹrìndínlógún kò sì ṣàtúnṣe sí ẹ̀kọ́ nípa ọkàn. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Aṣàtúnṣe ti Pùròtẹ́sítáǹtì jiyàn lórí ẹ̀kọ́ pọ́gátórì, wọ́n tẹ́wọ́ gba èrò ti ìjìyà tàbí èrè ayérayé.
18 Bí ẹ̀kọ́ àìleèkú ọkàn ṣe borí nínú ọ̀pọ̀ jù lọ ìjọ Kirisẹ́ńdọ̀mù nìyẹn. Nígbà tí ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan ní ilẹ̀ America ṣàkíyèsí èyí, ó kọ̀wé pé: “Ká sòótọ́, lójú ọ̀pọ̀ jù lọ nínú ìran tiwa, ẹ̀sìn túmọ̀ sí àìleèkú, kò sì jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ọlọ́run ni olùṣe àìleèkú.”
Àìleèkú àti Ẹ̀sìn Ìsìláàmù
19. Ìgbà wo ni a dá ẹ̀sìn Ìsìláàmù sílẹ̀, láti ọwọ́ ta sì ni?
19 Ẹ̀sìn Ìsìláàmù bẹ̀rẹ̀ nígbà tí a pe Mọ̀ọ́mọ́dù láti di wòlíì nígbà tí ó wà ní ọmọ 40 ọdún. Ní gbogbogbòò, àwọn Mùsùlùmí gbà gbọ́ pé ó ń rí ìṣípayá gbà fún nǹkan bí 20 ọdún sí ọdún 23, láti nǹkan bí ọdún 610 Sànmánì Tiwa títí di ìgbà ikú rẹ̀ ní ọdún 632 Sànmánì Tiwa. Ìṣípayá wọ̀nyí ni a kọ sínú Kùránì, ìwé mímọ́ ti àwọn Mùsùlùmí. Ìgbà tí Ìsìláàmù fi máa bẹ̀rẹ̀, èrò ti Plato nípa ọkàn ti wọnú ẹ̀sìn àwọn Júù àti Kirisẹ́ńdọ̀mù.
20, 21. Kí ni àwọn Mùsùlùmí gbà gbọ́ nípa Ìwàláàyè Lẹ́yìn Ikú?
20 Àwọn Mùsùlùmí gbà gbọ́ pé ìgbàgbọ́ tiwọn jẹ́ paríparì àwọn ìṣípayá tí a fi fún àwọn Hébérù àti Kristẹni olóòótọ́ nígbà láéláé. Kùránì tọ́ka sí Ìwé Mímọ́ lédè Hébérù àti lédè Gíríìkì. Àmọ́, lórí ọ̀ràn ẹ̀kọ́ àìleèkú ọkàn, Kùránì yà kúrò nínú ìwé wọ̀nyí. Kùránì fi kọ́ni pé ènìyàn ní ọkàn tí ó ṣì máa ń wà láàyè lẹ́yìn ikú. Ó tún sọ nípa àjíǹde òkú, ọjọ́ ìdájọ́, àti kádàrá ọkàn níkẹyìn—bóyá láti wà láàyè nínú ọgbà párádísè kan ní ọ̀run tàbí kí ó máa jìyà nínú iná àjóòkú.
21 Àwọn Mùsùlùmí gbà pé ọkàn òkú máa ń lọ sí Barzakh, tàbí ibi “Ìpínyà,” “ibi tàbí ipò kan tí ènìyàn yóò wà lẹ́yìn ikú àti ṣáájú Ìdájọ́.” (Súrà 23:99, 100, The Holy Qur-an, àlàyé ẹsẹ̀ ìwé) Ọkàn mọ ohun tí ń ṣẹlẹ̀, ibẹ̀ ni yóò sì ti fara gba ohun tí wọ́n pè ní “Ìyà Inú Sàréè” bí ẹni náà bá jẹ́ ẹni burúkú tàbí kí ó máa gbádùn ayọ̀ bí ó bá jẹ́ olóòótọ́. Ṣùgbọ́n àwọn olóòótọ́ ní láti jìyà díẹ̀ nítorí ìwọ̀nba ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n dá nígbà tí wọ́n wà láàyè. Lọ́jọ́ ìdájọ́, olúkúlùkù yóò dojú kọ kádàrá rẹ̀ ayérayé, èyí tí yóò fòpin sí ipò agbedeméjì yẹn.
22. Àbá èrò orí tí ó yàtọ̀ síra wo ni àwọn ọlọ́gbọ́n èrò orí ará Arébíà kan gbé kalẹ̀ nípa ohun tí ó máa ń ṣẹlẹ̀ sí ọkàn?
22 Èrò àìleèkú ọkàn dé inú ẹ̀sìn àwọn Júù àti Kirisẹ́ńdọ̀mù nítorí ipa tí Plato ní lórí wọn, ṣùgbọ́n láti ìbẹ̀rẹ̀ ẹ̀sìn Ìsìláàmù ni a ti gbé èrò náà kalẹ̀ sínú rẹ̀. Èyí kò túmọ̀ sí pé àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ ará Arébíà kò sapá láti yí àwọn ẹ̀kọ́ Ìsìláàmù pọ̀ mọ́ ọgbọ́n èrò orí Gíríìkì. Ní ti gidi, ìwé Aristotle nípa lórí àwọn ará Arébíà gidigidi. Àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ ará Arébíà tí ó lókìkí, bí Avicenna àti Averroës, túbọ̀ fẹ ìrònú Aristotle lójú, wọ́n sì mú un gbòòrò sí i. Àmọ́ ṣá, bí wọ́n ṣe ń sapá láti mú ìrònú àwọn ará Gíríìkì dọ́gba pẹ̀lú ohun tí àwọn Mùsùlùmí kọ́ni nípa ọkàn, àwọn àbá èrò orí tí ó yàtọ̀ síra ni wọ́n gbé yọ. Bí àpẹẹrẹ, Avicenna polongo pé ọkàn ẹni jẹ́ aláìleèkú. Averroës, ní tirẹ̀, tako ojú ìwòye yẹn. Láìka ojú ìwòye wọ̀nyí sí, àìleèkú ọkàn ṣì jẹ́ ohun tí àwọn Mùsùlùmí gbà gbọ́.
23. Ipò wo ni ẹ̀sìn àwọn Júù, Kirisẹ́ńdọ̀mù, àti Ìsìláàmù dì mú nípa àìleèkú ọkàn?
23 Nígbà náà, ó ṣe kedere pé àti ẹ̀sìn àwọn Júù, Kirisẹ́ńdọ̀mù, àti Ìsìláàmù, gbogbo wọn ní ń fi ẹ̀kọ́ àìleèkú ọkàn kọ́ni.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ẹni tí ó tẹ́wọ́ gba Àtúnṣe Èrò Plato, àkọ̀tun ẹ̀dà ọgbọ́n èrò orí Plato tí Plotinus mú jáde ní Róòmù ti ọ̀rúndún kẹta.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]
Ìṣẹ́gun láti ọwọ́ Alẹkisáńdà Ńlá ni ó fa àyípọ̀ àṣà ìbílẹ̀ àwọn Gíríìkì àti ti àwọn Júù
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Lápá òkè, Origen àti Augustine gbìyànjú láti yí ọgbọ́n èrò orí Plato pọ̀ mọ́ ẹ̀sìn Kristẹni
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Lápá òkè, Avicenna polongo pé ọkàn ẹni jẹ́ àìleèkú. Averroës tako ojú ìwòye yẹn