ORÍ KẸRÌNDÍNLÓGÚN
Fi Hàn Pé Ìsìn Tòótọ́ Lo Fẹ́ Ṣe
Kí ni Bíbélì sọ nípa lílo ère nínú ìjọsìn àti jíjọ́sìn àwọn baba ńlá?
Ojú wo làwọn Kristẹni fi ń wo àwọn ayẹyẹ ìsìn?
Báwo lo ṣe lè ṣàlàyé àwọn ohun tó o gbà gbọ́ fáwọn ẹlòmíràn lọ́nà tí kò ní bí wọn nínú?
1, 2. Ìbéèrè wo lo gbọ́dọ̀ bi ara rẹ̀ lẹ́yìn tó o bá fi ìsìn èké sílẹ̀, kí sì nìdí tó o fi rò pé ó ṣe pàtàkì kó o bi ara rẹ ní ìbéèrè náà?
KÁ SỌ pé ṣe lo kàn dédé rí i tí òórùn burúkú kan ba gbogbo àdúgbò tó ò ń gbé jẹ́. Olubi ẹ̀dá kan ló wá da nǹkan ẹlẹ́gbin tí òórùn rẹ̀ lè gbẹ̀mí ẹni sádùúgbò náà, ẹ̀mí tìẹ náà sì wà nínú ewu. Kí ni wàá ṣe? Ó dájú pé ńṣe ni wàá kó kúrò níbẹ̀ tó bá ṣeé ṣe. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn tó o bá ti kó kúrò níbẹ̀, ó yẹ kó o bi ara rẹ pé: ‘Ǹjẹ́ òórùn yẹn ò ti ṣàkóbá fún ara mi?’
2 Bí ọ̀ràn ìsìn èké ṣe rí nìyẹn o. Bíbélì fi kọ́ni pé ẹ̀kọ́ èké àti àwọn àṣà tí kò mọ́ ti ba ìsìn èké jẹ́. (2 Kọ́ríńtì 6:17) Ìdí nìyẹn tó fi ṣe pàtàkì pé kó o kúrò nínú “Bábílónì Ńlá,” tí í ṣe ilẹ̀ ọba ìsìn èké àgbáyé. (Ìṣípayá 18:2, 4) Ṣé o ti kúrò níbẹ̀? O káre tó o bá ti kúrò níbẹ̀. Àmọ́, kì í wá ṣe pé kó o kàn fi ìsìn èké sílẹ̀ nìkan ni o. Lẹ́yìn tó o bá ti kúrò níbẹ̀, o gbọ́dọ̀ bi ara rẹ pé: ‘Ǹjẹ́ mo ṣì ń ṣe àwọn nǹkan kan tí wọ́n ń ṣe nínú ìsìn èké?’ Gbé àpẹẹrẹ díẹ̀ yẹ̀ wò.
JÍJỌ́SÌN ÈRE ÀTÀWỌN BABA ŃLÁ
3. (a) Kí ni Bíbélì sọ nípa lílo ère, kí sì nìdí tó fi lè ṣòro fáwọn kan láti ka ère sí ohun tí Ọlọ́run kà á sí? (b) Kí ló yẹ kó o ṣe sí ohunkóhun tó o bá ní tó jẹ mọ́ ìsìn èké?
3 Ó ti pẹ́ táwọn kan ti ní ère àti ojúbọ nínú ilé wọn. Àbí ìwọ náà ní ère àti ojúbọ nínú ilé rẹ? Tó o bá ní, bóyá o ò mọ̀ pé kò tọ̀nà kéèyàn máa lo ère tàbí kó máa dúró ní ojúbọ láti gbàdúrà sí Ọlọ́run. Ó lè jẹ́ pé ohun tó ò ń rò ni pé kò sí béèyàn ṣe lè gbàdúrà sí Ọlọ́run láìrí nǹkan kan. Ó tiẹ̀ ṣeé ṣe kó o nífẹ̀ẹ́ sí àwọn nǹkan tó wà ní ojúbọ náà gidigidi. Ṣùgbọ́n, Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ló máa sọ bá a ṣe gbọ́dọ̀ máa jọ́sìn òun. A sì rí i kà nínú Bíbélì pé Ọlọ́run ò fẹ́ ká máa lo ère. (Ka Ẹ́kísódù 20:4, 5; Sáàmù 115:4-8; Aísáyà 42:8; 1 Jòhánù 5:21) Nítorí náà, fi hàn pé ìsìn tòótọ́ lo fẹ́ ṣe nípa kíkó gbogbo ohun tó o bá ní tó jẹ mọ́ ìsìn èké dà nù, nítorí ohun tí a kì í jẹ, a kì í fi runmú. Rí i dájú pé ohun tí Ọlọ́run ka irú àwọn ohun bẹ́ẹ̀ sí ni ìwọ náà kà wọ́n sí, ìyẹn ni pé, wọ́n jẹ́ ohun “ìṣe-họ́ọ̀-sí.”—Diutarónómì 27:15.
4. (a) Báwo la ṣe mọ̀ pé kò sí àǹfààní kankan tó wà nínú kéèyàn máa jọ́sìn àwọn baba ńlá? (b) Kí nìdí tí Jèhófà fi pàṣẹ fáwọn èèyàn rẹ̀ pé wọn ò gbọ́dọ̀ lọ́wọ́ sí ìbẹ́mìílò èyíkéyìí?
4 Àṣà jíjọ́sìn àwọn baba ńlá náà tún wọ́pọ̀ nínú ọ̀pọ̀ ìsìn èké. Káwọn kan tó kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ìgbàgbọ́ wọn ni pé àwọn òkú ṣì mọ nǹkan. Wọ́n rò pé ibùgbé àwọn ẹni ẹ̀mí làwọn òkú wà. Wọ́n tún rò pé àwọn òkú lè ran àwọn tó wà láàyè lọ́wọ́ tàbí kí wọ́n ṣe wọ́n léṣe. Bóyá ìwọ náà tiẹ̀ máa ń ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe láti tu àwọn baba ńlá tí wọ́n ti kú lójú. Ṣùgbọ́n bó o ṣe kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ ní Orí Kẹfà, àwọn òkú kò sí níbì kankan, wọn kò sì mọ nǹkan kan. Nítorí náà, kò sí àǹfààní téèyàn lè rí tó bá ń gbìyànjú láti bá wọn sọ̀rọ̀. Tẹ́nì kan bá sì wá gbọ́ nǹkan kan tó dà bí ẹni pé èèyàn rẹ̀ kan tó ti kú ló sọ ọ́, àwọn ẹ̀mí èṣù gan-an ló sọ nǹkan ọ̀hún. Ìdí nìyẹn tí Jèhófà fi pàṣẹ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé wọn kò gbọ́dọ̀ gbìyànjú láti bá òkú sọ̀rọ̀, wọn kò sì gbọ́dọ̀ lọ́wọ́ sí ìbẹ́mìílò èyíkéyìí.—Ka Diutarónómì 18:10-12.
5. Tó bá jẹ́ pé wọ́n ń lo ère nínú ìsìn tó ò ń ṣe tẹ́lẹ̀ tí wọ́n sì máa ń jọ́sìn àwọn baba ńlá, kí lo lè ṣe?
5 Tó bá jẹ́ pé wọ́n ń lo ère nínú ìsìn tó ò ń ṣe tẹ́lẹ̀ tí wọ́n sì máa ń jọ́sìn àwọn baba ńlá, kí lo lè ṣe? Ka àwọn ẹsẹ Bíbélì tó sọ irú ojú tí Ọlọ́run fi ń wo àwọn nǹkan wọ̀nyí kó o sì ronú lórí àwọn ẹsẹ Bíbélì náà. Máa gbàdúrà sí Jèhófà lójoojúmọ́ pé ìsìn tòótọ́ lo fẹ́ ṣe, kó o sì bẹ̀ ẹ́ pé kó ràn ọ́ lọ́wọ́ kí ìrònú rẹ lè bá tiẹ̀ mu.—Aísáyà 55:9.
ÀWỌN KRISTẸNI ÀKỌ́KỌ́BẸ̀RẸ̀ KÒ ṢAYẸYẸ KÉRÉSÌMESÌ
6, 7. (a) Kí ni wọ́n sọ pé wọ́n ń fi Kérésìmesì rántí, ṣé àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ọ̀rúndún kìíní sì ṣayẹyẹ yìí? (b) Nígbà ayé àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀, inú ìsìn wo ni wọ́n ti ń ṣayẹyẹ ọjọ́ ìbí?
6 Ìsìn èké lè ba ìjọsìn téèyàn ń ṣe jẹ́ o, ìyẹn téèyàn bá ń ṣe àwọn ayẹyẹ tó gbajúmọ̀. Bí àpẹẹrẹ, wo Kérésìmesì. Wọ́n sọ pé ọjọ́ ìbí Jésù Kristi ni wọ́n ń fi ayẹyẹ Kérésìmesì rántí, ó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ lè jẹ́ pé gbogbo àwọn ìsìn táwọn tó pe ara wọn ní Kristẹni ń ṣe ló ń ṣe ayẹyẹ yìí. Ṣùgbọ́n kò sí ẹ̀rí pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ní ọ̀rúndún kìíní ṣe irú ayẹyẹ bẹ́ẹ̀. Ìwé kan tí àkọlé rẹ̀ jẹ́ Sacred Origins of Profound Things sọ pé: “Látìgbà tí wọ́n ti bí Kristi títí di ọgọ́rùn-ún méjì ọdún lẹ́yìn náà, kò sẹ́ni tó mọ ìgbà tí wọ́n bí i, àwọn tó tiẹ̀ sì fẹ́ mọ ìgbà tí wọ́n bí i gan-an kò tó nǹkan.”
7 Kódà ká sọ pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ mọ ọjọ́ ìbí Jésù gan-an, wọn ò ní ṣayẹyẹ rẹ̀. Kí nìdí? Ìdí ni pé gẹ́gẹ́ bí ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The World Book Encyclopedia ti sọ, ‘àṣà Kèfèrí làwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ ka ṣíṣayẹyẹ ọjọ́ ìbí sí.’ Àwọn alákòóso tí kì í ṣe olùjọsìn Jèhófà ló ṣayẹyẹ ọjọ́ ìbí méjì péré tí Bíbélì mẹ́nu kàn. (Jẹ́nẹ́sísì 40:20; Máàkù 6:21) Àwọn Kèfèrí tún máa ń ṣayẹyẹ ọjọ́ ìbí láti fi júbà àwọn ọlọ́run wọn. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ará Róòmù máa ń ṣayẹyẹ ọjọ́ ìbí abo ọlọ́run tí wọ́n ń pè ní Diana ní May 24. Ọjọ́ tó tẹ̀ lé e ni wọ́n máa ń ṣe ọjọ́ ìbí ọlọ́run oòrùn tí wọ́n ń pè ní Apollo. Nítorí náà, ẹ̀sìn Kèfèrí ni a mọ ayẹyẹ ọjọ́ ìbí mọ́, kì í ṣe ẹ̀sìn Kristẹni.
8. Ṣàlàyé bí ayẹyẹ ọjọ́ ìbí ṣe pa pọ̀ mọ́ ìtàn èké.
8 Ìdí mìíràn wà táwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní ò fi ní ṣayẹyẹ ọjọ́ ìbí Jésù ká tiẹ̀ sọ pé wọ́n mọ ọjọ́ ìbí rẹ̀. Ó ṣeé ṣe káwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù mọ̀ pé gbígba ìtàn èké gbọ́ ló mú káwọn èèyàn máa ṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí. Bí àpẹẹrẹ, àwọn Gíríìkì àtàwọn ará Róòmù ayé ọjọ́un gbà gbọ́ pé ẹ̀mí kan máa ń lọ síbi ayẹyẹ ọjọ́ ìbí, wọ́n sì gbà pé ẹ̀mí náà ló máa ń dáàbò bo ẹni tó ń ṣọjọ́ ìbí náà ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀. Ìwé náà The Lore of Birthdays sọ pé: “Ẹ̀mí yìí yóò ní àjọṣepọ̀ àràmàǹdà pẹ̀lú ọlọ́run tí ọjọ́ ìbí rẹ̀ bọ́ sí ọjọ́ tí wọ́n bí ẹni tó ń ṣe ọjọ́ ìbí náà.” Ó dájú pé Jèhófà kò ní nífẹ̀ẹ́ sí ayẹyẹ èyíkéyìí tó máa pa Jésù pọ̀ mọ́ ìtàn èké. (Aísáyà 65:11, 12) Tó bá rí bẹ́ẹ̀, báwo ló ṣe wá di pé àwọn èèyàn tó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ ń ṣe Kérésìmesì?
IBI TÍ KÉRÉSÌMESÌ TI WÁ
9. Báwo ló ṣe di pé wọ́n mú December 25 gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ tí wọ́n á máa ṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí Jésù?
9 Ọgọ́rùn-ún ọdún mélòó kan kọjá lẹ́yìn tí Jésù kúrò lórí ilẹ̀ ayé káwọn èèyàn tó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣayẹyẹ ọjọ́ ìbí rẹ̀ ní December 25. Àmọ́, oṣù December kọ́ ni wọ́n bí Jésù, nítorí ẹ̀rí fi hàn pé oṣù October ni wọ́n bí i.a Kí wá nìdí tí wọ́n fi mú December 25 gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ tí wọ́n bí i? Ó jọ pé àwọn kan tí wọ́n sọ pé Kristẹni làwọn nígbà tó yá ló “fẹ́ kí ọjọ́ náà bọ́ sí ọjọ́ àjọ̀dún táwọn Kèfèrí ará Róòmù fi ń ṣe ‘ọjọ́ ìbí oòrùn tẹ́nì kan ò lè ṣẹ́gun.’” (The New Encyclopædia Britannica) Ní ìgbà òtútù tó máa ń dà bí ẹni pé oòrùn kì í fi bẹ́ẹ̀ ràn, àwọn Kèfèrí máa ń bọ oòrùn, tí í ṣe orísun ìmọ́lẹ̀ àti ooru, kó lè padà wá láti ọ̀nà jíjìn tó lọ. December 25 yẹn gan-an ni wọ́n kà sí ọjọ́ tí oòrùn máa ń bẹ̀rẹ̀ ìpadàbọ̀ rẹ̀ láti ìrìn àjò tó lọ. Kí àwọn aṣáájú ìsìn lè sọ àwọn Kèfèrí di Kristẹni, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ayẹyẹ yìí, wọ́n sì jẹ́ kó dà bíi pé ti ìsìn “Kristẹni” nib
10. Kí nìdí táwọn kan kò fi ṣe Kérésìmesì ní ọ̀rúndún kẹtàdínlógún?
10 Ọjọ́ ti pẹ́ táwọn èèyàn ti mọ̀ pé inú ìjọsìn àwọn Kèfèrí ni Kérésìmesì ti wá. Ní ọ̀rúndún kẹtàdínlógún, wọ́n ṣòfin ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti ní díẹ̀ lára àwọn ilẹ̀ òkèèrè tí orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ń ṣàkóso pé ẹnikẹ́ni kò gbọ́dọ̀ ṣe Kérésìmesì mọ́ nítorí wọ́n mọ̀ pé inú Ìwé Mímọ́ kọ́ ló ti wá. Kódà, tẹ́nì kan bá kọ̀ tí kò lọ síbi iṣẹ́ ní ọjọ́ ọdún Kérésìmesì, onítọ̀hún yóò jẹ iyán rẹ̀ níṣu. Ṣùgbọ́n kò pẹ́ kò jìnnà tí àṣà àtijọ́ yìí fi tún padà di àṣà tó lókìkí, kódà wọ́n tún fi àwọn nǹkan mìíràn kún un. Ni Kérésìmesì bá tún padà di ayẹyẹ tí wọ́n ti ń filé pọntí fọ̀nà rokà ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè di bá a ti ń sọ yìí. Ṣùgbọ́n àwọn tó fẹ́ múnú Ọlọ́run dùn kì í ṣayẹyẹ Kérésìmesì àtàwọn ayẹyẹ mìíràn tí wọ́n mọ̀ pé ó wá látinú ìjọsìn àwọn Kèfèrí nítorí pé ti ìsìn èké ni.c
ǸJẸ́ Ó YẸ KÉÈYÀN KA IBI TÁWỌN AYẸYẸ TI WÁ SÍ NǸKAN BÀBÀRÀ?
11. Kí nìdí táwọn kan fi ń ṣe àwọn ayẹyẹ, àmọ́ kí ló yẹ kó ṣe pàtàkì jù lójú wa?
11 Àwọn kan gbà pé inú ìjọsìn àwọn Kèfèrí làwọn ayẹyẹ bíi Kérésìmesì ti wá, síbẹ̀, wọ́n ṣì lérò pé kò sóhun tó burú nínú kéèyàn máa ṣe wọ́n. Ó ṣe tán, ọ̀pọ̀ ni kì í ronú nípa ìsìn èké lákòókò ọdún wọ̀nyí. Àkókò tí àwọn ìdílé sì fi ń wà pa pọ̀ ni. Ṣé ojú tí ìwọ náà fi wò ó nìyẹn? Tó bá jẹ́ pé ojú tó o fi wò ó nìyẹn, a jẹ́ pé ìfẹ́ tó o ní fún ìdílé rẹ ló mú kó ṣòro fún ọ láti fi hàn pé ìsìn tòótọ́ lo fẹ́ ṣe. Mọ̀ dájú pé, Jèhófà, ẹni tó dá ìdílé sílẹ̀ fẹ́ kí àárín ìwọ àtàwọn ẹbí rẹ dán mọ́rán. (Éfésù 3:14, 15) Àmọ́, ọ̀nà tó ní ìtẹ́wọ́gbà Ọlọ́run lo yẹ kó o gbà mú kí okùn ìfẹ́ tó wà láàárín ìwọ àti àwọn ẹbí rẹ lágbára. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé nípa ohun tó yẹ kó ṣe pàtàkì jù lójú wa, ó ní: “Ẹ máa bá a nìṣó ní wíwádìí ohun tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún Olúwa dájú.”—Éfésù 5:10.
12. Ṣàpèjúwe ìdí tó fi yẹ ká yẹra fún àwọn àṣà àtàwọn ayẹyẹ tó wá láti ibi àìmọ́.
12 O lè máa wò ó pé àwọn ayẹyẹ tí wọ́n ń ṣe lónìí kò ní nǹkan kan ṣe pẹ̀lú ibi táwọn ayẹyẹ náà ti wá. Ǹjẹ́ ó yẹ kéèyàn ka ibi tí wọ́n ti wá sí nǹkan bàbàrà? Bẹ́ẹ̀ ni o! Wo àpèjúwe yìí ná: Ká sọ pé o rí dáyá, ìyẹn súìtì kan nínú gọ́tà tàbí ojú ọ̀gbàrá, ṣé wàá fi sẹ́nu? Ó dájú pé o ò ní fi sẹ́nu! Ìdí ni pé ibi ìdọ̀tí lo ti rí i. Bí ohun aládùn yẹn, àwọn ayẹyẹ lè jẹ́ ohun tó máa ń dùn mọ́ni lóòótọ́, àmọ́ má gbàgbé pé ibi àìmọ́ ni wọ́n ti wá. Ká bàa lè fi hàn pé ìsìn tòótọ́ la fẹ́ ṣe, a ní láti ní irú èrò tí wòlíì Aísáyà ní. Ó sọ fáwọn tó ń ṣe ìsìn tòótọ́ pé: “Ẹ má fọwọ́ kan ohun àìmọ́ kankan.”—Aísáyà 52:11
FỌGBỌ́N BÁ ÀWỌN ẸLÒMÍRÀN LÒ
13. Àwọn ìṣòro wo lo lè ní tí o kò bá lọ́wọ́ sáwọn ayẹyẹ mọ́?
13 Ìṣòro lè dé nígbà tó o bá pinnu pé o ò ní ṣe àwọn ayẹyẹ. Bí àpẹẹrẹ, ó lè máa ya àwọn tẹ́ ẹ jọ ń ṣiṣẹ́ lẹ́nu pé o kì í bá wọn lọ́wọ́ sí àwọn ohun kan tí wọ́n máa ń ṣe nígbà ayẹyẹ. Kí ni wàá ṣe tẹ́nì kan bá fún ọ lẹ́bùn Kérésìmesì? Ǹjẹ́ ohun tó burú ni tó o bá gbà á? Bí ìgbàgbọ́ ọkọ rẹ tàbí ti aya rẹ bá yàtọ̀ sí tìẹ ńkọ́? Kí lo lè ṣe táwọn ọmọ rẹ kò fi ní rò pé àwọn ń pàdánù nítorí pé ẹ kì í ṣe àwọn ayẹyẹ?
14, 15. Kí lo lè ṣe tẹ́nì kan bá kí ọ kú ọdún tàbí tó bá fẹ́ fún ọ lẹ́bùn?
14 Ó gba ọgbọ́n láti lè mọ ohun tó yẹ kó o ṣe nígbà tó o bá dojú kọ irú àwọn ọ̀ràn wọ̀nyẹn. Bí ẹnì kan bá kí ọ kú ọdún, o kàn lè sọ fónítọ̀hún pé ó ṣeun. Ṣùgbọ́n tó bá jẹ́ pé ẹni tó ò ń rí déédéé tàbí tẹ́ ẹ jọ ń ṣiṣẹ́ lójoojúmọ́ ni ńkọ́? O lè túbọ̀ ṣàlàyé fún irú ẹni bẹ́ẹ̀. Àmọ́ ẹni yòówù kó jẹ́, ó ṣì gba ọgbọ́n. Bíbélì gbà wá nímọ̀ràn pé: “Ẹ jẹ́ kí àsọjáde yín máa fìgbà gbogbo jẹ́ pẹ̀lú oore ọ̀fẹ́, tí a fi iyọ̀ dùn, kí ẹ lè mọ bí ó ti yẹ kí ẹ fi ìdáhùn fún ẹnì kọ̀ọ̀kan.” (Kólósè 4:6) Rí i dájú pé o kò ṣàìbọ̀wọ̀ fún àwọn ẹlòmíràn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ni kó o rọra fọgbọ́n ṣàlàyé ìgbàgbọ́ rẹ fún wọn. Jẹ́ kó yé wọn yékéyéké pé o ò lòdì sí ká fúnni lẹ́bùn tàbí ká kóra jọ, àmọ́ pé ìwọ kì í fẹ́ báwọn ṣe irú ohun tó jọ bẹ́ẹ̀ lákòókò ọdún.
15 Tẹ́nì kan bá fẹ́ fún ọ lẹ́bùn ńkọ́? Bọ́rọ̀ náà bá ṣe rí ló máa pinnu ohun tí wàá ṣe. Ẹni tó fẹ́ fún ọ lẹ́bùn náà lè sọ pé: “Mo mọ̀ pé o kì í ṣe ọdún tá à ń ṣe yìí. Ẹ̀bùn yìí kàn tọkàn mi wá ni.” O lè pinnu pé bọ́rọ̀ ṣe rí yìí, tó o bá gba ẹ̀bùn náà, o kò tíì lọ́wọ́ sí ayẹyẹ náà. Àmọ́ bí onítọ̀hún ò bá mọ àwọn ohun tó o gbà gbọ́, o lè sọ fún un pé o kì í ṣe ayẹyẹ tí wọ́n ń ṣe náà. Ìyẹn lè jẹ́ kó mọ ìdí tó fi jẹ́ pé bó tilẹ̀ jẹ́ pé o gba ẹ̀bùn ọ̀hún, ìwọ kì í fún èèyàn lẹ́bùn lákòókò náà. Àmọ́ ṣá o, tó bá hàn gbangba pé ohun tẹ́ni tó fẹ́ fún ọ lẹ́bùn náà fẹ́ fi hàn ni pé tó o bá rí ẹ̀bùn, wàá pa ohun tó o gbà gbọ́ tì nítorí àwọn nǹkan tara, kò ní bọ́gbọ́n mu kó o gbà á.
BÍ ÌGBÀGBỌ́ ÀWỌN ÌBÁTAN RẸ BÁ YÀTỌ̀ SÍ TÌẸ ŃKỌ́?
16. Báwo lo ṣe lè lo ọgbọ́n tó o ba ń yanjú àwọn ọ̀rọ̀ tó dá lórí ayẹyẹ?
16 Bí ìgbàgbọ́ àwọn ará ilé rẹ bá yàtọ̀ sí tìẹ ńkọ́? Ìyẹn náà gba ọgbọ́n o. Kò pọn dandan kó o máa bá àwọn ìbátan rẹ jiyàn lórí gbogbo ayẹyẹ tàbí àwọn nǹkan mìíràn tí wọ́n bá fẹ́ ṣe. Kàkà bẹ́ẹ̀, mọ̀ pé wọ́n lẹ́tọ̀ọ́ láti gba ohun tó wù wọ́n gbọ́, bó o ṣe fẹ́ káwọn náà mọ̀ pé o lẹ́tọ̀ọ́ láti gba ohun tó wù ọ́ gbọ́. (Ka Mátíù 7:12) Yàgò fún ohunkóhun tó máa mú ọ di ẹni tó lọ́wọ́ sí ayẹyẹ náà. Ṣùgbọ́n tó bá kan ti ìkórajọ tí kò jẹ mọ́ àwọn ayẹyẹ, má ṣe le koko jù. Ohun tí ẹ̀rí ọkàn rẹ kò fi ní máa dá ọ lẹ́bi ni kó o máa ṣe ní gbogbo ìgbà.—Ka 1 Tímótì 1:18, 19.
17. Báwo lo ṣe lè ran àwọn ọmọ rẹ lọ́wọ́ tí wọn kò fi ní máa rò pé wọ́n ń pàdánù nítorí pé wọ́n rí i táwọn mìíràn ń ṣayẹyẹ?
17 Kí lo lè ṣe táwọn ọmọ rẹ kò fi ní rò pé àwọn ń pàdánù nítorí pé ẹ kì í ṣe àwọn ayẹyẹ tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu? Ìyẹn wà lọ́wọ́ ohun tó o bá ń ṣe láwọn àkókò mìíràn nínú ọdún. Àwọn òbí kan ti ya àwọn ìgbà kan sọ́tọ̀ tí wọ́n á máa fún àwọn ọmọ wọn lẹ́bùn. Lára àwọn ẹ̀bùn tó dára jù lọ tó o lè fún àwọn ọmọ rẹ ni kó o máa wáyè tó pọ̀ tó láti wà pẹ̀lú wọn kó o sì máa mójú tó wọn tìfẹ́tìfẹ́.
ṢE ÌSÌN TÒÓTỌ́
18. Báwo ni lílọ sáwọn ìpàdé Kristẹni ṣe lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti fi hàn pé ìsìn tòótọ́ lo fẹ́ ṣe?
18 O gbọ́dọ̀ kúrò nínú ìsìn èké kó o sì fi hàn pé ìsìn tòótọ́ lo fẹ́ ṣe kó o bàa lè múnú Ọlọ́run dùn. Àwọn ọ̀nà wo lo lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀? Bíbélì sọ pé: “Ẹ sì jẹ́ kí a gba ti ara wa rò lẹ́nì kìíní-kejì láti ru ara wa sókè sí ìfẹ́ àti sí àwọn iṣẹ́ àtàtà, kí a má máa kọ ìpéjọpọ̀ ara wa sílẹ̀, bí àwọn kan ti ní àṣà náà, ṣùgbọ́n kí a máa fún ara wa ní ìṣírí lẹ́nì kìíní-kejì, pàápàá jù lọ bí ẹ ti rí i pé ọjọ́ náà ń sún mọ́lé.” (Hébérù 10:24, 25) Àwọn ìpàdé Kristẹni jẹ́ ibi aláyọ̀ tó o ti lè jọ́sìn Ọlọ́run lọ́nà tí Ọlọ́run tẹ́wọ́ gbà. (Sáàmù 22:22; 122:1) Láwọn ìpàdé bẹ́ẹ̀, àwọn Kristẹni olóòótọ́ máa ń ‘fún ara wọn ní ìṣírí.’—Róòmù 1:12.
19. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kó o sọ àwọn ohun tó o kọ́ látinú Bíbélì fáwọn ẹlòmíràn?
19 Ọ̀pọ̀ nǹkan lo ti mọ̀ bó o ti ń bá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ọ̀nà mìíràn tó o lè gbà fi hàn pé ìsìn tòótọ́ lo fẹ́ ṣe ni pé kó o máa sọ àwọn ohun tó o ti mọ̀ náà fáwọn ẹlòmíràn. Kò sí àní-àní pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń “ń mí ìmí ẹ̀dùn, tí wọ́n sì ń kérora” nítorí ìwà búburú tó gba ayé kan. (Ìsíkíẹ́lì 9:4) Bóyá o tiẹ̀ mọ àwọn kan tó ń kérora nítorí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láyé. O ò ṣe kúkú sọ ìrètí tó o ní nípa ọjọ́ ọ̀la fún wọn, ìyẹn ìrètí tó wà nínú Bíbélì? Tó o bá ń bá àwọn Kristẹni tòótọ́ kẹ́gbẹ́, tó o sì ń sọ òtítọ́ tó o kọ́ nínú Bíbélì fáwọn ẹlòmíràn, wàá rí i pé díẹ̀díẹ̀ ni àwọn ohun kan tí wọ́n ń ṣe nínú ìsìn èké tí ọkàn rẹ ṣì ń fà sí máa lọ kúrò lọ́kàn rẹ pátápátá. Kó dá ọ lójú pé wàá láyọ̀, wàá sì rí ọ̀pọ̀ ìbùkún tó o bá ṣe ìsìn tòótọ́.—Málákì 3:10.
a Wo Àfikún, “Ṣé Oṣù December Ni Wọ́n Bí Jésù?”
b Àjọ̀dún Saturnalia náà wà lára ohun tí wọ́n wò tí wọ́n fi mú December 25. Àjọ̀dún Saturnalia yìí ni wọ́n fi ń júbà ọlọ́run ọ̀gbìn, December 17 sí 24 ni wọ́n sì máa ń ṣe é. Wọ́n máa ń se àsè, wọ́n sì máa ń fún ara wọn lẹ́bùn lákòókò Saturnalia.
c Wo Àfikún, “Ǹjẹ́ Ó Yẹ Ká Máa Ṣe Ọdún àti Àwọn Ayẹyẹ Kan?” kó o lè rí àlàyé nípa ojú táwọn Kristẹni tòótọ́ fi ń wo àwọn ayẹyẹ mìíràn tó lókìkí.