ORÍ 61
Jésù Wo Ọmọkùnrin Tí Ẹ̀mí Èṣù ń yọ Lẹ́nu Sàn
MÁTÍÙ 17:14-20 MÁÀKÙ 9:14-29 LÚÙKÙ 9:37-43
WỌ́N NÍLÒ ÌGBÀGBỌ́ TÓ LÁGBÁRA LÁTI ṢE ÌWÒSÁN
Bí Jésù, Pétérù, Jémíìsì àti Jòhánù ṣe ń bọ̀ látorí òkè tí wọ́n lọ, wọ́n bá èrò rẹpẹtẹ tó pé jọ. Wọ́n rí i pé nǹkan kan ti ń ṣẹlẹ̀, torí àwọn akọ̀wé òfin ti yí àwọn ọmọ ẹ̀yìn ká, wọ́n sì ń bá wọn jiyàn. Ó ya àwọn èèyàn yẹn lẹ́nu nígbà tí wọ́n rí Jésù, ni wọ́n bá sáré lọ pàdé rẹ̀. Jésù wá bi wọ́n pé: “Kí ni ẹ̀ ń bá wọn jiyàn lé lórí?”—Máàkù 9:16.
Ọkùnrin kan tó wà láàárín èrò náà kúnlẹ̀ síwájú Jésù, ó sì sọ fún un pé: “Olùkọ́, mo mú ọmọkùnrin mi wá sọ́dọ̀ rẹ torí ó ní ẹ̀mí kan tí kò jẹ́ kó lè sọ̀rọ̀. Ní ibikíbi tó bá ti mú un, ṣe ló máa ń gbé e ṣánlẹ̀, á sì máa yọ ìfófòó lẹ́nu, á máa wa eyín pọ̀, kò sì ní lókun mọ́. Mo ní kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ lé e jáde, àmọ́ wọn ò rí i ṣe.”—Máàkù 9:17, 18.
Ó jọ pé ṣe ni àwọn akọ̀wé òfin yẹn ń bẹnu àtẹ́ lu àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù torí pé wọn ò lè wo ọmọ náà sàn, ó tiẹ̀ ṣeé ṣe kí wọ́n máa fi wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́. Dípò tí Jésù á fi dá bàbá tí ọkàn ẹ̀ ti dàrú náà lóhùn, àwọn èèyàn yẹn ló yíjú sí, ó sọ fún wọn pé: “Ìran aláìnígbàgbọ́ àti oníbékebèke, títí dìgbà wo ni màá fi wà pẹ̀lú yín? Títí dìgbà wo ni màá fi máa fara dà á fún yín?” Kò sí àní-àní pé àwọn akọ̀wé òfin lọ̀rọ̀ yìí ń bá wí torí pé àwọn ló ń fayé ni àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ lára nígbà tí kò sí Jésù lọ́dọ̀ wọn. Jésù wá yíjú sí bàbá ọmọ náà, ó sì sọ fún un pé: “Mú un wá sọ́dọ̀ mi níbí.”—Mátíù 17:17.
Bí wọ́n ṣe ń mú ọmọ náà lọ sọ́dọ̀ Jésù, ẹ̀mí èṣù tó ń yọ ọ́ lẹ́nu gbé e ṣánlẹ̀, gìrì sì gbé e. Lọmọ náà bá bẹ̀rẹ̀ sí í yí kiri, ó sì ń yọ ìfófòó lẹ́nu. Jésù wá bi bàbá ọmọ náà pé: “Ó tó ìgbà wo tí nǹkan yìí ti ń ṣe ọmọ yìí?” Bàbá náà fèsì pé: “Láti kékeré ni, ó máa ń gbé e jù sínú iná àti sínú omi lọ́pọ̀ ìgbà kó lè pa á.” Bàbá náà wá bẹ Jésù pé: “Tí o bá lè ṣe ohunkóhun sí i, ṣàánú wa, kí o sì ràn wá lọ́wọ́.”—Máàkù 9:21, 22.
Gbogbo nǹkan ti tojú sú bàbá ọmọ náà, èyí tó wá burú jù ni pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn ò lè wo ọmọ náà sàn. Jésù káàánú ọkùnrin náà, ó sì fi dá a lójú pé: “Kì í ṣe ọ̀rọ̀, ‘Tí o bá lè’! Ó dájú pé ohun gbogbo ṣeé ṣe fún ẹni tó bá ní ìgbàgbọ́.” Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, bàbá ọmọ náà kígbe pé: “Mo ní ìgbàgbọ́! Ràn mí lọ́wọ́ níbi tí mo ti nílò ìgbàgbọ́!”—Máàkù 9:23, 24.
Jésù rí i pé àwọn èrò ń rọ́ gììrì bọ̀ lọ́dọ̀ òun, gbogbo wọ́n sì ń háragàgà láti rí ohun tó fẹ́ ṣẹlẹ̀. Jésù wá bá ẹ̀mí èṣù náà wí, ó ní: “Ìwọ ẹ̀mí tí kò jẹ́ kó lè sọ̀rọ̀, tó sì di í létí, mo pàṣẹ fún ọ, jáde kúrò lára rẹ̀, o ò sì gbọ́dọ̀ wọ inú rẹ̀ mọ́!” Bí ẹ̀mí èṣù náà ṣe ń jáde lára ọmọ náà, ó mú kó kígbe lóhùn rara, ó sì mú kí gìrì ṣe é léraléra. Lẹ́yìn ìyẹn, ọmọ náà sùn sílẹ̀ bọrọgidi. Kódà, nígbà táwọn èèyàn náà rí bó ṣe sùn sílẹ̀, wọ́n sọ pé: “Ó ti kú!” (Máàkù 9:25, 26) Àmọ́ nígbà tí Jésù di ọwọ́ rẹ̀ mú, ó gbé e dìde, ara ẹ̀ sì “yá láti wákàtí yẹn.” (Mátíù 17:18) Ká sòótọ́, ẹnu ya àwọn èèyàn náà nígbà tí wọ́n rí ohun tí Jésù ń ṣe.
Ẹ rántí pé ìgbà kan wà tí Jésù rán àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n lọ wàásù, ó fún wọn lágbára láti lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde. Torí náà, nígbà tí wọ́n wọnú ilé, tó sì ku òun àtàwọn nìkan, wọ́n béèrè lọ́wọ́ Jésù pé: “Kí ló dé tí a ò fi lè lé e jáde?” Jésù ṣàlàyé fún wọn pé àìnígbàgbọ́ wọn ló fà á, ó wá fi kún un pé: “Àdúrà nìkan ló lè lé irú èyí jáde.” (Máàkù 9:28, 29) Ó jẹ́ kó yé wọn pé tí wọ́n bá máa lé irú ẹ̀mí èṣù tó lágbára bẹ́ẹ̀ jáde, wọ́n nílò ìgbàgbọ́ tó lágbára kí wọ́n sì bẹ Ọlọ́run pé kó ran àwọn lọ́wọ́.
Jésù wá fi gbólóhùn yìí parí ọ̀rọ̀ ẹ̀, ó ní: “Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, tí ẹ bá ní ìgbàgbọ́ tó rí bíi hóró músítádì, ẹ máa sọ fún òkè yìí pé, ‘Kúrò níbí lọ sí ọ̀hún,’ ó sì máa lọ, kò sì sí ohun tí ẹ ò ní lè ṣe.” (Mátíù 17:20) Ẹ ò rí i pé ìgbàgbọ́ lágbára gan-an!
Àwọn ìṣòro àtàwọn ohun ìdènà míì tí kì í jẹ́ kéèyàn tẹ̀ síwájú lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà lè dà bí òkè gìrìwò tí kò ṣeé gùn, tí kò sì ṣeé ṣí kúrò. Síbẹ̀, tá a bá nígbàgbọ́, bó ti wù kí òkè ìṣòro wa ga tó, àá borí wọn.