ORÍ 83
Àwọn Tí Ọlọ́run Pè Síbi Àsè Kan
Ẹ̀KỌ́ NÍPA Ẹ̀MÍ ÌRẸ̀LẸ̀
ÀWỌN ÀLEJÒ WÁ ÀWÁWÍ
Jésù wà nílé Farisí kan lẹ́yìn tó wo ọkùnrin tí ara rẹ̀ wú sàn. Jésù kíyè sí i pé àwọn kan fẹ́ràn kí wọ́n jókòó síbi tó lọ́lá jù níbi àsè náà, ó wá lo àǹfààní yẹn láti kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ nípa ìrẹ̀lẹ̀.
Jésù wá sọ pé: “Tí ẹnì kan bá pè ọ́ síbi àsè ìgbéyàwó, má ṣe jókòó síbi tó lọ́lá jù. Ó ṣeé ṣe kó ti pe ẹnì kan tí wọ́n kà sí pàtàkì jù ọ́ lọ. Ẹni tó pe ẹ̀yin méjèèjì á wá sọ fún ọ pé, ‘Dìde fún ọkùnrin yìí.’ O máa wá fi ìtìjú dìde lọ jókòó síbi tó rẹlẹ̀ jù lọ.”—Lúùkù 14:8, 9.
Lẹ́yìn náà, Jésù sọ pé: “Tí wọ́n bá pè ọ́, lọ jókòó síbi tó rẹlẹ̀ jù, kó lè jẹ́ pé tí ẹni tó pè ọ́ wá bá dé, ó máa sọ fún ọ pé, ‘Ọ̀rẹ́, lọ síbi tó ga.’ Ìgbà yẹn lo máa wá gbayì níṣojú gbogbo àwọn tí ẹ jọ jẹ́ àlejò.” Ọ̀rọ̀ yìí kọjá kéèyàn kàn níwà ọmọlúàbí. Jésù ṣàlàyé pé: “Torí gbogbo ẹni tó bá gbé ara rẹ̀ ga, a máa rẹ̀ ẹ́ sílẹ̀, ẹnikẹ́ni tó bá sì rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, a máa gbé e ga.” (Lúùkù 14:10, 11) Bẹ́ẹ̀ ni, Jésù ń gba àwọn olùgbọ́ rẹ̀ níyànjú pé kí wọ́n lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀.
Lẹ́yìn ìyẹn, Jésù sọ̀rọ̀ nípa ohun kan táá kọ́ Farisí tó pè é wá jẹun lẹ́kọ̀ọ́. Ó sọ bó ṣe lè pe àwọn èèyàn síbi àsè rẹ̀ kínú Ọlọ́run sì dùn sí i. Ó ní: “Tí o bá se àsè oúnjẹ ọ̀sán tàbí oúnjẹ alẹ́, má pe àwọn ọ̀rẹ́ rẹ tàbí àwọn arákùnrin rẹ tàbí àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ tàbí àwọn aládùúgbò rẹ tí wọ́n jẹ́ ọlọ́rọ̀. Torí tó bá yá, àwọn náà lè pè ọ́ wá, wọ́n á sì fìyẹn san án fún ọ. Àmọ́ tí o bá se àsè, àwọn aláìní, arọ, àwọn tí kò lè rìn dáadáa àti afọ́jú ni kí o pè; o sì máa láyọ̀, torí wọn ò ní ohunkóhun láti fi san án pa dà fún ọ.”—Lúùkù 14:12-14.
Kò sóhun tó burú téèyàn bá pe àwọn ọ̀rẹ́, ẹbí tàbí aládùúgbò síbi àsè rẹ̀, Jésù ò sì sọ pé kò dáa. Àmọ́ ó tẹnu mọ́ ọn pé ọ̀pọ̀ ìbùkún la máa rí tá a bá pe àwọn aláìní síbi àsè wa, irú bí àwọn òtòṣì, arọ àtàwọn afọ́jú. Jésù wá sọ fẹ́ni tó gbà á lálejò pé: “A máa san án pa dà fún ọ nígbà àjíǹde àwọn olódodo.” Ọ̀kan nínú àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ àlejò fara mọ́ ohun tí Jésù sọ, ó wá sọ pé: “Aláyọ̀ ni ẹni tó ń jẹun ní Ìjọba Ọlọ́run.” (Lúùkù 14:15) Ọkùnrin yìí rí i pé àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ nìyẹn máa jẹ́. Àmọ́ kì í ṣe gbogbo èèyàn ló mọyì àǹfààní yẹn. Àpèjúwe tí Jésù sọ tẹ̀ lé e jẹ́ ká mọ̀ bẹ́ẹ̀, ó sọ pé:
“Ọkùnrin kan ń se àsè oúnjẹ alẹ́ rẹpẹtẹ, ó sì pe ọ̀pọ̀ èèyàn. Ó rán ẹrú rẹ̀ jáde . . . láti sọ fún àwọn tó pè wá pé, ‘Ẹ máa bọ̀, torí gbogbo nǹkan ti wà ní sẹpẹ́ báyìí.’ Àmọ́ ohun kan náà ni gbogbo wọn ṣe, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í wá àwáwí. Ẹni àkọ́kọ́ sọ fún un pé, ‘Mo ra pápá kan, ó sì yẹ kí n jáde lọ wò ó; jọ̀ọ́, yọ̀ǹda mi.’ Ẹlòmíì sọ pé, ‘Mo ra màlúù mẹ́wàá, mo sì fẹ́ lọ yẹ̀ wọ́n wò; jọ̀ọ́, yọ̀ǹda mi.’ Ẹlòmíì tún sọ pé, ‘Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ gbéyàwó ni, torí náà, mi ò ní lè wá.’”—Lúùkù 14:16-20.
Àwáwí tí ò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ ni gbogbo wọn ń wá! Kéèyàn tó ra pápá tàbí màlúù ló yẹ kéèyàn ti wò ó, torí náà, kì í ṣe dandan kí wọ́n lọ wò ó kíákíá, ó ṣe tán, wọ́n ti rà á. Bákan náà, kì í ṣe pé ẹni kẹta ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́ gbéyàwó, ó ti gbéyàwó, torí náà kò yẹ kíyẹn dí i lọ́wọ́ láti lọ síbi àsè pàtàkì tí wọ́n pè é sí. Nígbà tí ọ̀gá yẹn gbọ́ bí gbogbo wọn ṣe ń wá àwáwí, inú bí i, ó sì sọ fún ẹrú rẹ̀ pé:
“Tètè jáde lọ sí àwọn ọ̀nà tó bọ́ sí gbangba àti àwọn ọ̀nà tóóró nínú ìlú, kí o sì mú àwọn òtòṣì, arọ, afọ́jú àti àwọn tí kò lè rìn dáadáa wọlé wá síbí.” Lẹ́yìn tí ẹrú náà ṣe ohun tí ọ̀gá rẹ̀ sọ, wọ́n rí i pé àwọn àlejò tí wọ́n ń retí ò tíì pé. Ni ọ̀gá náà bá tún sọ fún un pé: “Jáde lọ sí àwọn ojú ọ̀nà àti àwọn ọ̀nà tí kò fẹ̀, kí o sì fi dandan mú wọn wọlé wá, kí ilé mi lè kún. Torí mò ń sọ fún yín pé, ìkankan nínú àwọn èèyàn tí mo pè yẹn ò ní tọ́ oúnjẹ alẹ́ mi wò.”—Lúùkù 14:21-24.
Àpèjúwe tí Jésù ṣe yìí jẹ́ ká rí bí Jèhófà ṣe lo Jésù láti pe àwọn èèyàn kí wọ́n lè wọ Ìjọba ọ̀run. Àwọn Júù ló kọ́kọ́ pè, ní pàtàkì àwọn aṣáájú ẹ̀sìn. Àmọ́ èyí tó pọ̀ jù nínú wọn ni ò gba ìkésíni yẹn jálẹ̀ gbogbo àkókò tí Jésù fi ṣiṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀. Jésù wá jẹ́ kó ṣe kedere pé tó bá dọjọ́ iwájú, òun ṣì máa pe àwọn tó bá lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ lára àwọn Júù àtàwọn tí kì í ṣe Júù. Nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, Ọlọ́run máa pe àwọn èèyàn táwọn Júù ò gbà pé wọ́n lè rí ojúure Ọlọ́run.—Ìṣe 10:28-48.
Ọ̀rọ̀ Jésù yìí fi hàn pé òótọ́ lọ̀rọ̀ tí ọkùnrin tí wọ́n jọ jẹ́ àlejò sọ, pé: “Aláyọ̀ ni ẹni tó ń jẹun ní Ìjọba Ọlọ́run.”