Sí Àwọn Ará Gálátíà
5 Kristi ti dá wa sílẹ̀ ká lè ní irú òmìnira yìí. Nítorí náà, ẹ dúró gbọn-in,+ ẹ má sì tọrùn bọ àjàgà ẹrú mọ́.+
2 Ẹ wò ó! Èmi, Pọ́ọ̀lù, ń sọ fún yín pé tí ẹ bá dádọ̀dọ́,* Kristi ò ní ṣe yín láǹfààní kankan.+ 3 Mo tún jẹ́rìí sí i pé dandan ni fún gbogbo ẹni tó bá dádọ̀dọ́* láti pa gbogbo Òfin mọ́.+ 4 Ẹ ti kúrò lọ́dọ̀ Kristi, ẹ̀yin tí ẹ fẹ́ kí a pè yín ní olódodo nípasẹ̀ òfin;+ ẹ ti yà kúrò nínú inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí rẹ̀. 5 Ní tiwa, nínú ẹ̀mí, à ń dúró de òdodo tí à ń retí lójú méjèèjì, èyí tó ń wá látinú ìgbàgbọ́. 6 Torí nínú Kristi Jésù, ìdádọ̀dọ́* tàbí àìdádọ̀dọ́* kò ṣàǹfààní,+ ìgbàgbọ́ tó ń ṣiṣẹ́ nípasẹ̀ ìfẹ́ ló ṣàǹfààní.
7 Ẹ ti ń sáré dáadáa tẹ́lẹ̀.+ Ta ló dí yín lọ́wọ́ kí ẹ má ṣègbọràn sí òtítọ́ mọ́? 8 Irú èrò tí wọ́n fi yí yín lọ́kàn pa dà yìí kò wá látọ̀dọ̀ Ẹni tó ń pè yín. 9 Ìwúkàrà díẹ̀ ló ń mú gbogbo ìṣùpọ̀ wú.+ 10 Ọkàn mi balẹ̀ pé ẹ̀yin tí ẹ wà nínú Olúwa+ kò ní ronú lọ́nà míì; àmọ́, ẹni tó ń dá wàhálà sílẹ̀ fún yín,+ ẹnì yòówù kó jẹ́, yóò gba ìdájọ́ tó tọ́ sí i. 11 Ní tèmi, ẹ̀yin ará, tí mo bá ṣì ń wàásù ìdádọ̀dọ́,* kí ló dé tí wọ́n tún ń ṣe inúnibíni sí mi? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, òpó igi oró*+ kì í ṣe ohun ìkọ̀sẹ̀ mọ́ fún àwọn tó ń ta kò mí. 12 Ó wù mí kí àwọn tó fẹ́ da àárín yín rú tẹ ara wọn lọ́dàá.*
13 Ẹ̀yin ará, a pè yín kí ẹ lè ní òmìnira; kìkì pé kí ẹ má ṣe lo òmìnira yìí láti máa ṣe ìfẹ́ ti ara,+ àmọ́ ẹ jẹ́ kí ìfẹ́ máa mú kí ẹ sin ara yín bí ẹrú.+ 14 Nítorí a ti mú gbogbo Òfin ṣẹ nínú* àṣẹ kan ṣoṣo, tó sọ pé: “Kí o nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì rẹ bí ara rẹ.”+ 15 Tí ẹ bá wá ń bu ara yín jẹ, tí ẹ sì ń fa ara yín ya,+ ẹ ṣọ́ra kí ẹ má bàa pa ara yín run.+
16 Àmọ́ mo sọ pé, Ẹ máa rìn nípa ẹ̀mí,+ ẹ kò sì ní ṣe ìfẹ́ ti ara rárá.+ 17 Nítorí ohun tí ara ń fẹ́ lòdì sí ohun tí ẹ̀mí ń fẹ́, ẹ̀mí sì lòdì sí ara; àwọn méjèèjì ta ko ara wọn, ìdí nìyẹn tí ẹ kò fi lè ṣe ohun tí ẹ fẹ́ ṣe.+ 18 Yàtọ̀ síyẹn, tí ẹ̀mí bá ń darí yín, ẹ kò sí lábẹ́ òfin.
19 Àwọn iṣẹ́ ti ara hàn kedere, àwọn sì ni ìṣekúṣe,*+ ìwà àìmọ́, ìwà àìnítìjú,*+ 20 ìbọ̀rìṣà, ìbẹ́mìílò,*+ ìkórìíra, wàhálà, owú, inú fùfù, awuyewuye, ìpínyà, ẹ̀ya ìsìn, 21 ìlara, ìmutíyó,+ àwọn àríyá aláriwo àti irú àwọn nǹkan yìí.+ Mò ń kìlọ̀ fún yín ṣáájú nípa àwọn nǹkan yìí, lọ́nà kan náà tí mo gbà kìlọ̀ fún yín tẹ́lẹ̀, pé àwọn tó bá ń ṣe àwọn nǹkan yìí kò ní jogún Ìjọba Ọlọ́run.+
22 Àmọ́, èso ti ẹ̀mí ni ìfẹ́, ayọ̀, àlàáfíà, sùúrù,* inú rere, ìwà rere,+ ìgbàgbọ́, 23 ìwà tútù, ìkóra-ẹni-níjàánu.+ Kò sí òfin kankan tó lòdì sí irú àwọn nǹkan yìí. 24 Yàtọ̀ síyẹn, àwọn tó jẹ́ ti Kristi Jésù ti kan ẹran ara mọ́gi* pẹ̀lú ohun tí ẹran ara ń fẹ́ àti ohun tó ń wù ú.+
25 Tí a bá wà láàyè nípa ẹ̀mí, ẹ jẹ́ kí a máa rìn létòlétò nípa ẹ̀mí.+ 26 Ẹ má ṣe jẹ́ kí a di agbéraga,+ kí a má ṣe máa bá ara wa díje,+ kí a má sì máa jowú ara wa.