Sọ Èdè Mímọ́gaara naa Ki O Si Walaaye Titilae!
“Ẹ wa Jehofa . . . Ẹ wa ododo, ẹ wa inututu. Boya a o le fi yin pamọ nikọkọ ni ọjọ ibinu Jehofa.”—SEFANAYA 2:3, NW.
1. (a) Awọn ọna wo ni awọn akẹkọọ nlo lati kọ́ ede ajeji kan? (b) Eeṣe ti a fi nilati sọ èdè mímọ́gaara naa?
AWỌN akẹkọọ le kọ́ ede ahọn titun nipa lilo ọna ti girama tabi ọna ti ede sisọ. Labẹ ọna ti gírámà, nigbogbogboo wọn nlo awọn iwe ikẹkọọ wọn si ńkọ́ awọn ofin ti gírámà. Labẹ ọna ti ede sisọ, wọn nṣafarawe awọn ìró ati awọn apẹẹrẹ ọrọ ti olukọ wọn bá sọ. Ọna mejeeji ṣee fisilo ninu kikẹkọọ “èdè mímọ́gaara.” O si ṣe pataki pe ki a sọ ede yii bi a ba nireti pé a o “fi yin pamọ nikọkọ ni ọjọ ibinu Jehofa.”—Sefanaya 2:1-3, NW; 3:8, 9.
2. Bawo ni a ṣe le kọ́ ohun ti a le pe ni awọn ofin gírámà fun èdè mímọ́gaara naa?
2 Iwe ikẹkọọ pataki ti a nlo lati kọ́ èdè mímọ́gaara naa ni Bibeli. Ikẹkọọ alaapọn rẹ ati awọn itẹjade ti a gbekari Bibeli kọ́ ọ ni ohun ti a lè pè ni ofin girama fun èdè mímọ́gaara naa. Ikẹkọọ Bibeli inu ile kan ti a dari lati ọwọ ọ̀kan lara awọn Ẹlẹrii Jehofa jẹ ibẹrẹ ti o dara. Fun awọn wọnni ti wọn ti ṣe iyasimimọ fun Ọlọrun ṣaaju akoko yii, ikẹkọọ deedee ati ti alaapọn ninu Iwe Mimọ ṣekoko. Ṣugbọn njẹ awọn ọna ti wọn gbeṣẹ ni pataki ha wà lati kọ́ èdè mímọ́gaara naa? Awọn anfaani wo ni wọn si njẹ jade lati inu sisọ ọ́?
Bi A O Ṣe Kọ́ Èdè Mímọ́gaara Naa
3. Ki ni ọna kan lati kọ́ èdè mímọ́gaara naa?
3 Ọna kan lati kọ èdè mímọ́gaara naa ni lati so awọn otitọ ti iwọ nkẹkọọ pọ pẹlu awọn koko ti o ti mọ tẹlẹ, gẹgẹbi akẹkọọ kan ti le mu awọn ofin girama oniruuru tanmọra lọna ti o tẹlera. Fun apẹẹrẹ, ni akoko kan iwọ ti le mọ pe Jesu Kristi jẹ Ọmọkunrin Ọlọrun, ṣugbọn iwọ ko mọ pupọ nipa awọn iṣẹ rẹ. Lati igba naa wa, ikẹkọọ Bibeli ti le kọ́ ọ pé Kristi ti nṣakoso gẹgẹbi Ọba ti ọrun ati pe lakooko Ijọba Ẹlẹgbẹrun Ọdun rẹ, araye onigbọran ni a o gbéga soke si ijẹpipe. (Iṣipaya 20:5, 6) Bẹẹni, siso awọn ero titun pọ mọ awọn wọnni ti o ti mọ tẹlẹ mu oye rẹ nipa èdè mímọ́gaara pọ sii.
4. (a) Ki ni ọna miiran lati kọ́ awọn ‘ofin girama’ ti èdè mímọ́gaara naa, akọsilẹ Bibeli wo ni a si lo lati ṣakawe eyi? (b) Ki ni o ṣẹlẹ bi Gidioni ati awọn ọ̀ọ́dúnrún ọkunrin rẹ ti gbeegbesẹ? (d) Akọsilẹ iṣẹlẹ nipa Gidioni kọni ni ẹkọ wo?
4 Ọna miiran ti o le gba kọ́ awọn ‘ofin girama’ èdè mímọ́gaara ni lati foju inu wo awọn iṣẹlẹ Bibeli. Lati ṣakawe: Gbiyanju lati ‘rí ki o si gbọ́’ iṣẹlẹ ti a ṣakọsilẹ rẹ ni awọn Onidaajọ 7:15-23. Wò ó! onidaajọ Israẹli Gidioni ti pín awọn agbo ọmọ-ogun rẹ si ẹgbẹ mẹta ti ọkọọkan ni ọgọrun un ọkunrin. Ninu okunkun, wọn rọra yọ́ sọkalẹ lati ori Oke Giliboa wọn si yi agọ awọn ara Midiani ti wọn nsun ka. Awọn ọgọrun un mẹta wọnyi ha dihamọra ogun daradara bi? Kii ṣe lọna ti ologun. Họọwu, wọn yoo fa ẹrin ẹlẹya lati ọdọ awọn onirera ologun! Ọkunrin kọọkan ni kiki ìwo kan, iṣà omi titobi nla kan, ti ètùfù kan si wà ninu iṣa naa. Ṣugbọn fetisilẹ! Bi a ti fun wọn ni ami kan, awọn ọgọrun un ọkunrin ti wọn wa pẹlu Gidioni fọn awọn ìwo wọn wọ́n si fọ awọn iṣa omi wọn túká yanga. Awọn ọgọrun un meji yooku ṣe ohun kan naa. Bi gbogbo wọn ti na awọn ètùfù ti njo lala soke, iwọ gbọ ti wọn hó yèè pe: “Ida Jehofa ati ti Gidioni!” Bawo ni eyi ti kopaya ba awọn ara Midiani to! Wọn ṣubú lébú kuro ninu awọn agọ wọn, ti oju wọn ti o kun fun oorun si là gbòò nitori jinnijinni fun ọ̀wọ́ ina tí ńjó bùlàbùlà ti o ntanmọlẹ sori awọn irisi ojiji ti o si fa awọn ibẹru igbagbọ ninu ohun asan wa. Bi awọn ara Midiani ti bẹrẹ sii salọ, awọn ọkunrin Gidioni nbaa lọ lati fọn awọn iwo wọn, Ọlọrun si da oju awọn olódì wọn kọ araawọn enikinni keji. Ẹkọ alagbara wo ni eyi jẹ ninu èdè mímọ́gaara! Ọlọrun le dá awọn eniyan rẹ nide laisi agbo ipá ologun ti eniyan kankan. Ju bẹẹ lọ, “Jehofa ki yoo kọ awọn eniyan rẹ tì nitori orukọ nla rẹ.”—1 Samuẹli 12:22, NW.
5. Bawo ni awọn ipade Kristian ṣe le ran wa lọwọ lati yọ́ ọrọ sisọ wa mọ́?
5 Nigba ti a ba kọ́ awọn akẹkọọ ni ede ahọn ajeji nipasẹ ọna ede sisọ, wọn gbiyanju lati sọ awọn ìró ati apẹẹrẹ ọrọ olukọ naa ni asọtunsọ lọna jija gaara. Iru awọn anfaani rere wo ni wọn wà lati sọ èdè mímọ́gaara ni awọn ipade Kristian! Nibẹ ni awa ngbọ ti awọn miiran nṣalaye araawọn ni ede otitọ ti Iwe mimọ yẹn, awa si le ni anfaani lati sọrọ funraawa. Ẹru ha nba wa pe awa le sọ ohun kan ti ko tọna bi? Ẹ maṣe jẹ ki iyẹn jẹ olori aniyan wa, nitori iṣina kan ti a fi inurere tọsọna nipasẹ alagba naa ti nṣe alaboojuto ni iru ipade gẹgẹbi Ikẹkọọ Ilé-ìṣọ́nà lọsọọsẹ le yọ́ ọrọ sisọ wa mọ́. Nitori naa, wà nibẹ ki o si kopa ninu awọn ipade Kristian deedee.—Heberu 10:24, 25.
Ìyọ́wọlé awọn Ohun Àìmọ́
6. Eeṣe ti iru iyatọ bẹẹ fi wà laaarin awọn Ẹlẹrii Jehofa ati awọn eto-ajọ onisin ti Kristẹndọm?
6 Awọn wọnni ti wọn npolongo ète Jehofa ti wọn si nkede Ijọba rẹ ọrun nsọ èdè mímọ́gaara gẹgẹbi awọn Ẹlẹrii rẹ. Wọn sọ orukọ rẹ di mímọ̀ wọn si nsin ín “ni ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́,” tabi pẹlu ijọhẹn kan. (Sefanaya 3:9, NW) Bi o tilẹ jẹ pe awọn isin Kristẹndọm ni Bibeli, wọn ko sọ èdè mímọ́gaara naa tabi kepe orukọ Ọlọrun ninu igbagbọ. (Joẹli 2:32) Wọn ko ni ihin-iṣẹ ti o ṣọkan ti a gbekari Iwe Mimọ. Eeṣe? Nitori pe wọn gbé ẹkọ atọwọdọwọ isin, awọn ọgbọn imọ ọran aye, ati iduroṣinṣin fun ọran iṣelu ga ju Ọrọ Ọlọrun lọ. Awọn ete, ireti, ati ọna ti wọn ngba ṣe e jẹ́ ti aye buburu yii.
7. Awọn iyatọ wo laaarin awọn Ẹlẹrii Jehofa ati isin eke ni a fihan ni 1 Johanu 4:4-6?
7 Kristẹndọm—niti tootọ, gbogbo ilẹ-ọba isin eke agbaye—ko sọ ede kan naa gẹgẹ bi ti awọn Ẹlẹrii Jehofa. Lọna ti o fani lọkan mọra, si awọn wọnni ti wọn nsọ èdè mímọ́gaara, apọsteli Johanu kowe pe: “Ẹyin pilẹṣẹ lọdọ Ọlọrun, . . .ẹ si ti ṣẹgun awọn eniyan wọnni, nitori pe ẹniti o wà ni irẹpọ pẹlu yin tobi ju ẹni ti o wà ni irẹpọ pẹlu aye. Wọn pilẹṣẹ lọdọ aye; iyẹn ni idi rẹ ti wọn fi nsọrọ ohun ti o jade lati ọdọ aye aye si nfetisilẹ si wọn. Awa pilẹṣẹ lọdọ Ọlọrun. Ẹniti ti o jere imọ Ọlọrun a maa fetisilẹ si wa; ẹni ti ko ba pilẹṣẹ lọdọ Ọlọrun kii fetisilẹ si wa.” (1 Johanu 4:4-6, NW) Awọn iranṣẹ Jehofa ti ṣẹgun awọn olukọ eke nitori pe Ọlọrun, ẹniti o wà ni irẹpọ pẹlu awọn eniyan rẹ, “tobiju [Eṣu, ẹniti] o wà ni irẹpọ pẹlu aye,” awujọ eniyan alaiṣododo. Niwọnbi ipẹhinda ti “pilẹṣẹ pẹlu aye” ti o si ni ẹmi buburu rẹ, ‘wọn nsọrọ ohun ti o njade lati ọdọ aye aye si nfetisilẹ si wọn.’ Ṣugbọn awọn ẹnikọọkan ti wọn jẹ ẹni bi agutan nfetisilẹ si awọn wọnni ti wọnpilẹṣẹ pẹlu Ọlọrun, ni mímọ̀ daju pe awọn eniyan Jehofa nsọ èdè mímọ́gaara ti otitọ Bibeli ti a pese nipasẹ eto-ajọ rẹ.
8. Ki ni a fi dá ọkunrin iwa ailofin naa mọ?
8 Ipẹhinda ńláǹlà ni a sọtẹlẹ, ‘ohun ijinlẹ iwa ailofin’ si wà lẹnu iṣẹ ni ọgọrun un ọdun kin-inni ti sanmani tiwa sibẹ. Bi akoko ti nlọ, awọn eniyan ti wọn tẹwọgba—tabi fipa gba—awọn ipo kikọni ninu ijọ fi ọpọlọpọ ẹkọ eke kọni. Ede wọn jinna si mimọgaara. Nitori naa “ọkunrin iwa ailofin” alápá pupọ kan dide, awujọ alufaa Kristẹndọm, ti wọn dìrọ pinpin mọ awọn ofin atọwọdọwọ isin eke, ọgbọn imọ ọran aye, ati awọn ẹkọ ti wọn ko ba iwe mimọ mu.—2 Tẹsalonika 2:3, 7, NW.
A Gbọ́ Ede Mimọgaara Yika Aye
9. Awọn idagbasoke onisin wo ni o wà laaarin ọgọrun un ọdun kọkandinlogun?
9 Kiki awọn eniyan olubẹru Ọlọrun ti wọn kere niye ni wọn ‘ja ija lile ti igbagbọ ti a fi le awọn ẹni mimọ lọwọ.’ (Juuda 3) Nibo ni a ti le ri iru awọn onigbagbọ bẹẹ? Fun ọpọ ọrundun, isin eke pa ògídímèje awọn eniyan mọ́ sinu okunkun tẹmi, ṣugbọn Ọlọrun mọ awọn diẹ ti wọn ni itẹwọgba rẹ. (2 Timoti 2:19) Ati nigba naa, laaarin iyipada eto iṣowo, awujọ ile-iṣẹ, ati ẹgbẹ-oun-ọgba ti ọgọrun un ọdun kọkandinlogun, awọn ohùn ti wọn yatọ si ti apapọ babeli ti idarudapọ isin eke dide. Awọn awujọ keekeeke ngbiyanju lati loye ami awọn akoko ki wọn si sọ asọtẹlẹ bibọ Jesu ẹlẹẹkeji, ṣugbọn kii ṣe gbogbo wọn ni wọn sọ èdè mímọ́gaara naa.
10. Awujọ “ipadabọ ẹlẹẹkeji” wo ni Ọlọrun yàn lati sọ èdè mímọ́gaara naa, eeṣe ti o si fi han gbangba pe ọwọ Jehofa ti wà pẹlu wọn?
10 Bi o ti wu ki o ri, ni 1879, ohùn “ipadabọ ẹlẹẹkeji” ti Jehofa yàn lati sọ èdè mímọ́gaara naa gẹgẹbi awọn Ẹlẹrii rẹ ni o wá han kedere. Nigba naa lọhun un awujọ akẹkọọ Bibeli kekere kan ninu eyi ti Charles Taze Russell mu ipo iwaju npade pọ̀ ni Pittsburgh, Pennsylvania, U.S.A. Wọn ti ni idaniloju pe ipadabọ ẹlẹẹkeji Jesu ni yoo bẹrẹ wiwa nihin in rẹ ti a ko le ri, pe akoko idaamu wà niwaju, ati pe eyi ni Ijọba Ẹlẹgbẹrun Ọdun Kristi ti yoo ṣe imupadabọsipo Paradise lori ilẹ-aye, pẹlu iye ayeraye fun awọn eniyan onigbọran. Ni July 1879 awọn Akẹkọọ Bibeli wọnyii bẹrẹ sii tẹ iwe-irohin ti a mọ nisinsinyi gẹgẹbi Ilé-ìṣọ́nà jade. Kiki 6,000 ẹ̀dà ni a pin kiri ninu itẹjade rẹ̀ akọkọ. Ṣugbọn “ọwọ́ Jehofa” wà pẹlu awọn Ẹlẹrii wọnni nitori iwe irohin yii ni a ntẹ jade nisinsinyi ni ede 111, pẹlu ipindọgba iwe titẹ ti o ju 15,000,000 fun itẹjade kọọkan.—Fiwe Iṣe 11:19-21.
11, 12. Awọn otitọ Iwe Mimọ diẹ wo ni awọn wọnni ti nsọ èdè mímọ́gaara naa loye?
11 Nipasẹ Bibeli ati itẹjade awọn Ẹlẹrii Jehofa, ati ni pataki nipasẹ ipokiki ihin rere onitara awọn Kristian wọnyi, èdè mímọ́gaara naa ti di mimọ jakejado aye. Iru anfaani titobi lọla wo ni awọn wọnni ti wọn si nsọ ọ ngbadun! Dipo sisọ pe ‘Ọlọrun ni Ọlọrun, Kristi ni Ọlọrun, Ẹmi Mimọ si ni Ọlọrun’ ni àdàmọ̀dì ede ti ohun ijinlẹ igbagbọ ninu Mẹtalọkan, wọn fohunṣọkan pẹlu ipo Bibeli pe Jehofa ni Ọga Ogo, Jesu Kristi gẹgẹbi ẹnikan ti o rẹlẹ ju ni Ọmọkunrin Rẹ, ti ẹmi mimọ si jẹ ipá agbekankan ṣiṣẹ yiyanilẹnu ti Ọlọrun. (Jẹnẹsisi 1:2; Saamu 83:18; Matiu 3:16, 17) Awọn ti nsọ èdè mímọ́gaara mọ̀ pe eniyan ko huyọ jade lati inu iwalaaye rirẹlẹ kan ṣugbọn a da a lati ọwọ Ọlọrun onifẹẹ kan. (Jẹnẹsisi 1:27; 2:7) Wọn mọ daju pe ọkan ṣiwọ lati maa wa laaye nigba iku—otitọ kan ti o mu ibẹru oku kuro. (Oniwaasu 9:5, 10; Esekiẹli 18:4) Hell ni wọn loye rẹ pe o jẹ sàréè araye lapapọ, kii ṣe ibi ijiya onina kan ti ọlọrun ajọsin fun onika buruku kan hùmọ̀ rẹ. (Joobu 14:13) Wọn tun mọ pe ajinde jẹ ireti ti Ọlọrun fi funni nipa awọn oku.—Johanu 5:28, 29; 11:25; Iṣe 24:15.
12 Awọn wọnni ti wọn nsọ èdè mímọ́gaara naa fi ọ̀wọ̀ han fun ẹjẹ ati iwalaaye. (Jẹnẹsisi 9:3, 4; Iṣe 15:28, 29) Wọn mọ daju pe iwalaaye Kristi ori ilẹ-aye ni iye owo irapada ti a san fun awọn eniyan onigbọran. (Matiu 20:28; 1 Johanu 2:1, 2) Wọn ko gbadura si “awọn eniyan mimọ” ri, ni mimọ pe awọn adura wọn ni a gbọdọ dari si Jehofa Ọlọrun nipasẹ Jesu Kristi. (Johanu 4:6, 13, 14) Niwọnbi Ọrọ Ọlọrun ti dẹbi fun ibọriṣa, awọn ère ni a ko lo ninu ijọsin wọn. (Ẹkisodu 20:4-6; 1 Kọrinti 10:14) Wọn si yẹra fun awọn ewu nla ti ibẹmi eṣu lò nitori pe wọn kọ ibẹmiilo tì, eyi ti a da lẹbi ninu Bibeli bakan naa.—Deuteronomi 18:10-12; Galatia 5:19-21.
13. Eeṣe ti awọn wọnni ti wọn nsọ èdè mímọ́gaara naa ko fi ni idaamu?
13 Awọn iranṣẹ Jehofa, ti wọn nsọ èdè mímọ́gaara, ni a kò kó ṣìbáṣìbo bá nipa ibi ti wọn wa ninu ìṣàn akoko. Jehofa ti kọ́ wọn pe wọn wà ni “akoko opin,” pẹlu Jesu ti o ti wa nihin in gẹgẹbi ẹmi ologo ti a ko le foju ri. (Daniẹli 12:4; Matiu 24:3-14; 2 Timoti 3:1-5; 1 Peteru 3:18) Pẹlu agbo ọmọ-ogun ọrun alagbara nla lẹhin rẹ, Kristi maa to ṣetan lati kówọnu ija ogun lati mu idajọ Ọlọrun ṣẹ lodisi eto igbekalẹ awọn nnkan yii. (Daniẹli 2:44; Iṣipaya 16:14, 16; 18:1-8; 19:11-21) Bẹẹni, awọn wọnni ti wọn nsọ èdè mímọ́gaara naa ni a si mu ọwọ wọn di ni pipolongo ihin rere naa pe Ijọba Ọlọrun labẹ Kristi yoo to mu awọn ibukun ńláǹlà wa fun gbogbo araye onigbọran lori paradise ilẹ-aye kan. (Aisaya 9:6, 7; Daniẹli 7:13, 14; Matiu 6:9, 10; 24:14; Luuku 23:43) Pẹlu gbogbo iyẹn, awọn ohun tí a sọrọ nipa rẹ̀ ṣi jẹ oréfèé. Dajudaju, èdè mímọ́gaara naa jẹ ede ahọn ti o dọṣọ julọ, ti o ṣeyebiye julọ lori ilẹ-aye!
14. Awọn anfaani miiran wo ni awọn wọnni ti nsọ èdè mímọ́gaara naa ngbadun?
14 Awọn anfaani ti awọn wọnni ti nsọ èdè mímọ́gaara ngbadun ní nínú “alaafia Ọlọrun” ti o pa awọn agbara ọkan-aya ati ero-ori mọ́. (Filipi 4:6, 7) Wọn ṣegbọran si awọn ofin Bibeli, eyi ti o gbe ilera, ayọ, ati itẹlọrun ti o nwa lati inu ṣiṣe ohun ti o wu Jehofa ga. (1 Kọrinti 6:9, 10) Bẹẹni, awọn ti nsọ èdè mímọ́gaara naa ni ireti iye ayeraye ninu aye titun tí Ọlọrun ṣeleri.—2 Peteru 3:13.
Lò Ó tabi Ki O Padanu Rẹ
15. Bawo ni iwọ yoo ṣe janfaani lati inu oye daradara ti èdè mímọ́gaara naa?
15 Bi iwọ ba ni lati sọ èdè mímọ́gaara ninu aye titun, iwọ gbọdọ mọ daadaa debi pe o di ede ninu eyi ti iwọ nronu. Nigba ti ẹnikan ba nkọ ede kan, lakọọkọ oun nronu ni ede ahọn ibilẹ tirẹ oun yoo si ṣetumọ awọn ironu rẹ si ede titun naa. Ṣugbọn bi o ti tubọ ndi ogboṣaṣa ninu ede titun naa, oun yoo bẹrẹ sii lò ó ninu rironu laisi idi fun ṣiṣe itumọ. Lọna ti o farajọra, nipasẹ ikẹkọọ alaapọn, iwọ le ni iru oye rere bẹẹ nipa èdè mímọ́gaara naa ti iwọ yoo ti mọ bi a ti nfi awọn ofin ati ilana Bibeli silo lati yanju awọn iṣoro ki o si maa baa lọ ni “ipa ọna iye.”—Saamu 16:11.
16. Ki ni o le ṣẹlẹ bi iwọ ko ba lo èdè mímọ́gaara naa deedee?
16 Iwọ gbọdọ lo èdè mímọ́gaara naa deedee, bi bẹẹ kọ́ iwọ yoo padanu agbara lati sọ ọ daradara. Lati ṣakawe: Ni ọpọ ọdun sẹhin, diẹ ninu wa kẹkọọ ede ajeji kan. Awa le ranti awọn ọrọ diẹ ninu ede ahọn yẹn ṣugbọn o ṣeeṣe ki a ti sọ agbara mimọ ọn lo wa nù nitori pe awa ko fisilo nigba gbogbo. Ohun kan naa ni o le ṣẹlẹ pẹlu èdè mímọ́gaara. Bi awa ko ba lo o deedee, awa le padanu mimọ ọn lo wa, iyẹn yoo si ni awọn abajade ọlọran ibanujẹ nipa tẹmi. Nitori naa ẹ jẹki a maa sọ ọ deedee ni awọn ipade ati ninu iṣẹ-ojiṣẹ Kristian. Awọn igbokegbodo wọnyi, papọ pẹlu ikẹkọọ ara ẹni, yoo fun wa lagbara lati sọ awọn nnkan ni èdè mímọ́gaara lọna titọna. Bawo si ni iyẹn ti ṣe pataki to!
17. Ki ni o ṣàkàwé pe ọrọ sisọ le jẹ agbẹ̀mílà tabi aṣekupani?
17 Ọrọ sisọ le jẹ agbẹ̀mílà tabi aṣekupani. Eyi ni a fihan lakooko rogbodiyan laaarin ẹya Israẹli ti Efuraimu ati Onidaajọ Jẹfita ti Giliadi. Lati dá awọn ara Efuraimu mọ ti wọn ngbiyanju lati sa rekọja Odo Jọdani, awọn ara Giliadi lo ọrọ iyọnda ẹni lati kọja naa “Ṣiboleti,” eyi ti o ni ìró ibẹrẹ “ṣ.” Awọn ọkunrin Efraimu fi ara wọn le awọn ologun adena Giliadi lọwọ ni ìwọ́dò Jọdani nipa sisọ pe “Siboleti“ dipo “Ṣiboleti,” ni ṣiṣi ìró ibẹrẹ ọrọ naa pè. Gẹgẹbi iyọrisi rẹ̀, 42,000 awọn ara Efuraimu ni a pa! (Onidaajọ 12:5, 6) Lọna ti o farajọra, ohun ti awujọ alufaa Kristẹndọm fi kọni le dún bi eyi ti o sunmọ èdè mímọ́gaara naa fun awọn wọnni ti wọn ko dojulumọ otitọ Bibeli daradara. Ṣugbọn sisọrọ ni ọna isin eke yoo jasi aṣekupani ni ọjọ ibinu Jehofa.
A Wà Ni Iṣọkan
18, 19. Ki ni ijẹpataki Sefanaya 3:1-5?
18 Ni titọka si Jerusalẹmu alaiṣootọ ti igba laelae ati alabaakẹgbẹ rẹ̀ ode oni, Kristẹndọm, a sọ ni Sefanaya 3:1-5 (NW) pe: “Egbe ni fun ẹni ti nṣọtẹ ti o si nsọ ara rẹ di eleeri, ilu aninilara! Oun ko fetisilẹ si ohùn kan; oun ko tẹwọgba ibawi. Oun ko nigbẹkẹle ninu Jehofa. Oun ko sunmọ itosi Ọlọrun rẹ. Kininun ti nke ramuramu ni awọn ọmọ alade rẹ ti wọn wa laaarin rẹ. Ikoko alẹ ni awọn onidajọ rẹ ti wọn ko ginrin egungun jẹ titi di owurọ. Awọn wolii rẹ jẹ alafojudi, wọn jẹ awọn ọkunrin aládàkàdekè. Awọn alufaa rẹ funraawọn ti sọ ohun mimọ di alaimọ; wọn hu iwa ipa si ofin. Ododo ni Jehofa jẹ laaarin rẹ; oun ki yoo ṣe aiṣododo. Ni oroowurọ ni o nbaa lọ lati funni ni ipinnu idajọ tirẹ funraarẹ. Ni ojoojumọ ko jasi ṣiṣalaini. Ṣugbọn awọn alaiṣododo ko mọ itiju kankan.” Ki ni ijẹpataki awọn ọrọ wọnni?
19 Jerusalẹmu igbaani ati Kristẹndọm ode oni lapapọ ṣọtẹ lodisi Jehofa wọn si fi ijọsin eke sọ ara wọn di eleeri. Iwa aitọ awọn aṣaaju wọn yọrisi inilara. Laika awọn ikilọ Ọlọrun ti o sọ ni asọtunsọ sí, wọn ko fetisilẹ, ki wọn si fà sunmọ ọn. Awọn ọmọ alade wọn ti dabi awọn kinniun riroro, ti nfi igberaga ṣaika iwa ododo si. Bi awọn ikooko apanijẹ, awọn onidaajọ wọn ti fa idajọ-ododo ya si wẹwẹ. Awọn alufaa wọn ti ‘sọ ohun mimọ di alaimọ wọn si ti hu iwa ipa si ofin’ Ọlọrun. Nitori naa Jehofa ti ṣetan ‘lati ko awọn orilẹ ede jọ ki o si ṣa awọn ijọba jọ pọ̀, fun ete lati tú ibawi ìkannu rẹ sori wọn, gbogbo ibinu jijofofo rẹ.’—Sefanaya 3:8.
20. (a) Ki ni a gbọdọ ṣe lati la ọjọ ibinu Jehofa já? (b) Bawo ni iwọ ṣe le reti lati gbadun awọn ibukun ayeraye lati ọdọ Ọlọrun?
20 Ọjọ ibinu Jehofa nyara sunmọ tosi. Nitori naa, lati laaja sinu aye titun ti Ọlọrun, kọ́ ki o si maa sọ èdè mímọ́gaara laijafara. Kiki nipa ṣiṣe bẹẹ ni iwọ to le ri aabo kuro lọwọ ìjába tẹmi nisinsinyi ati lọwọ àjálù ibi yika aye ti nyara sunmọ tosi. Awọn Ẹlẹrii Jehofa npolongo ọjọ ibinu Ọlọrun ati ihin-iṣẹ amunilọkanle ti Ijọba rẹ. Bawo ni o ti dun mọ wọn ninu to lati sọrọ nipa ogo ipo ọba rẹ! (Saamu 145:10-13) Wa ni iṣọkan pẹlu wọn, iwọ si le reti lati gbadun iye ayeraye ati awọn ibukun miiran lati ọdọ Olupilẹṣẹ èdè mímọ́gaara naa, Jehofa Oluwa Ọba-alaṣẹ.
Bawo ni Iwọ Yoo Ṣe Dahun?
◻ Ki ni diẹ lara awọn ọna lati kọ́ èdè mímọ́gaara naa?
◻ Eeṣe ti o fi ṣanfaani lati sọ èdè mímọ́gaara naa?
◻ Ki ni o le ṣẹlẹ bi iwọ ko ba lo èdè mímọ́gaara naa deedee?
◻ Bawo ni ẹnikan ṣe le la ọjọ ibinu Jehofa já ki o si gbadun awọn ibukun ayeraye?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
Gidioni ati awọn ọkunrin rẹ fọn awọn iwo wọn wọ́n si gbe awọn ètùfù wọn soke
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Lati 1879 siwaju ni a ti mú un ṣe kedere pe Charles Taze Russell ati awọn alabakẹgbẹ rẹ ni Ọlọrun nlo lati gbé èdè mímọ́gaara naa ga
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
Njẹ iwọ wà ni iṣọkan pẹlu awọn Ẹlẹrii Jehofa ni sisọ èdè mímọ́gaara naa?