Ẹ Nà ni Iṣọkan Nipasẹ Èdè Mímọ́gaara Naa
“Nigba naa ni emi yoo fi iyipada si èdè mímọ́gaara kan fun awọn eniyan, nitori ki gbogbo wọn baa le maa ke pe orukọ Jehofa, lati le maa ṣiṣẹ sin in ni ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́.”—SEFANAYA 3:9, NW.
1. Njẹ awọn eniyan ti gbọ ki Jehofa Ọlọrun sọrọ ri bi?
EDE Jehofa Ọlọrun jẹ mímọ́gaara. Ṣugbọn njẹ awọn eniyan ha tii gbọ ki o sọrọ ri? Họọwu, bẹẹni! Iyẹn ṣẹlẹ nigba ti Ọmọkunrin rẹ̀, Jesu Kristi, wà lori ilẹ-aye ni ọrundun 19 sẹhin. Fun apẹẹrẹ, nigba ti a baptisi Jesu, Ọlọrun ni a gbọ ti o sọ pe: “Eyi ni Ọmọkunrin mi, ààyò olùfẹ́, ẹni ti mo ti tẹwọgba.” (Matiu 3:13-17, NW) Iyẹn jẹ gbolohun ọrọ otitọ mímọ́gaara kan, ti Jesu ati Johanu arinibọmi gbọ ni ede eniyan.
2. Ki ni a fihan nipa itọka apọsteli Pọọlu si “ede ahọn ti . . . angẹli”?
2 Ni awọn ọdun diẹ lẹhin naa Kristian aposteli Pọọlu sọrọ nipa “ede ahọn ti eniyan ati ti angẹli.” (1 Kọrinti 13:1) Ki ni eyi fihan? Họọwu, O fihan pe kii ṣe awọn eniyan nikan ṣugbọn awọn ẹni ẹmi pẹlu ni ede ati ọrọ! Dajudaju nitootọ, Ọlọrun ati awọn angẹli kii ba araawọn sọrọ nipa lilo awọn ìró ohùn ati ede ti ndun jade ti o si le yé wa. Eeṣe ti ko fi ri bẹẹ? O jẹ nitori pe ofuurufu iru eyi ti o yi ilẹ-aye ka ni a nilo lati ta àtaré awọn ìgbì ohùn tí eti eniyan le gbọ ki o si loye.
3. Bawo ni ede eniyan ṣe pilẹṣẹ?
3 Bawo ni ede eniyan ṣe pilẹṣẹ? Awọn kan sọ pe awọn babanla wa jijakadi lati jumọsọrọpọ pẹlu araawọn nipa yiyiju si kíkùn-hùn-hùn ati gbígbin. Iwe naa Evolution (Akojọ Iwe kíkà Ẹda Abẹmi) sọ pe: “Inaki bi eniyan ti nnkan bii aadọta ọkẹ ọdun sẹhin. . .ni o ti ṣeeṣe ki o mọ iwọnba awọn ìró ọrọ siso diẹ dunju.” Ṣugbọn ìjìmì onṣewe atumọ ede Ludwig Koehler sọ pe: “Ọrọ sisọ eniyan jẹ aṣiri kan; o jẹ ẹbun atọrunwa kan, iṣẹ iyanu kan ni.” Bẹẹni, ‘ọrọ sisọ eniyan jẹ ẹbun atọrunwa kan,’ nitori Ọlọrun fun ọkunrin akọkọ, Adamu, ni ede kan. O han gbangba pe oun ni eyi ti a wá npe ni ede Heberu. Ede yẹn ni awọn ọmọ Israẹli ti wọn jẹ ọmọ iran “Aburamu Heberu naa” baba idile oloootọ sọ, ẹni ti babanla rẹ jẹ Ṣemu ọmọkunrin Noa ẹni ti o kan ọkọ áàkì naa. (Jẹnẹsisi 11:10-26; 14:13; 17:3-6) Loju iwoye ibukun alasọtẹlẹ ti Ọlọrun lori Ṣemu, o ba ọgbọn mu lati pari ero pe ede rẹ ni ohun kan ti Jehofa Ọlọrun ṣe lọna iyanu ni ọrundun 43 sẹhin ko nipa lori rẹ.—Jẹnẹsisi 9:26.
4. Ta ni Nimrọdu, bawo si ni Satani Eṣu ṣe lò ó?
4 Ni akoko yẹn ‘gbogbo aye jẹ ede kan ati ọrọ kan.’ (Jẹnẹsisi 11:1) Nimrọdu, “ọdẹ alagbara nla kan ni ilodisi Jehofa,” wà laaye nigba naa. (Jẹnẹsisi 10:8, 9, NW) Olori ọta araye ti a ko le foju ri, Satani, lo Nimrọdu ni pataki lati gbe eto-ajọ Eṣu ti ori ilẹ-aye kalẹ. Nimrọdu fẹ ṣe orukọ fun ara rẹ, ẹmi-ironu onigberaga yẹn si tàn kalẹ de ọdọ awọn ọmọ ẹhin rẹ, awọn ti wọn bẹrẹ akanṣe idawọle ti iṣẹ ikọle kan ni ilẹ Ṣinari. Gẹgẹ bi Jẹnẹsisi ori 11, ẹsẹ 4 ti wi, wọn wìpe: “Ẹ wa, ẹ jẹ ki a tẹ ilu kan dó, ki a si mọ ile-iṣọ kan, ori eyi ti yoo si kan ọrun; [ki ẹ si jẹ ki a ṣe orukọ olokiki fun araawa, NW], ki a ma ba tuka kiri sori ilẹ gbogbo.” Idagbale yẹn ní iṣodisi aṣẹ Ọlọrun lati “kun aye” dopin nigba ti Jehofa da ede awọn ọlọtẹ naa ru. Akọsilẹ Bibeli wipe, “bẹẹni Oluwa [“Jehofa,” NW] tú wọn ka lati ibẹ lọ si ori ilẹ gbogbo: wọn si ṣiwọ ilu ti wọn ntẹdo.” (Jẹnẹsisi 9:1; 11:2-9) Ilu yẹn ni a pe ni Babeli, tabi Babiloni (ti o tumọsi “Ìdàrúdàpọ̀”) “nitori pe nibẹ ni Jehofa ti ṣàmúlùmálà ọrọ sisọ gbogbo ilẹ-aye.”—Byington.
5. (a) Ki ni a ṣedilọwọ fun nigba ti Ọlọrun da ede araye rú? (b) Ipari ero wo ni a le de nipa ede Noa ati Ṣemu?
5 Iṣẹ iyanu yẹn—idarudapọ ede araye kanṣoṣo naa—ṣamọna si kikun ilẹ-aye gẹgẹ bi Ọlọrun ti paṣẹ fun Noa, o si dí iwewee eyikeyii ti Satani lè ní lati fidii ijọsin àìmọ́ ti a sopọṣọkan mulẹ fun araarẹ lati ọwọ awọn ọlọtẹ eniyan ni ilodisi Oluwa Ọba-alaṣẹ ọrun ati ilẹ-aye. Lootọ, nipa ṣiṣe iru ijọsin eke eyikeyi, awọn eniyan di ẹran ijẹ fun Eṣu, wọn si nsin awọn ẹmi eṣu nigba ti wọn ṣe awọn ọlọrun akọ ati abo, ti wọn fun wọn ni orukọ ni awọn ede ọtọọtọ wọn, ti wọn si nsin wọn. (1 Kọrinti 10:20) Ṣugbọn igbesẹ ti Ọlọrun tootọ kanṣoṣo naa gbe ni Babeli ṣedilọwọ fun dida isin eke kanṣoṣo ti a sopọ ṣọkan silẹ ti nfun Ẹṣu ni ijọsin ti o han gbangba pe oun nifẹẹ si. Dajudaju, Noa olododo ati ọmọkunrin rẹ Ṣemu ko dara pọ lae ninu irukerudo yẹn ni ilẹ Sinari. Nitori naa a le pari ero lọna ti o bọgbọn mu pe ede wọn jẹ eyi ti Aburamu (tabi Aburahamu) oluṣotitọ sọ—ede ahọn ti Ọlọrun fi ba ọkunrin naa Adamu sọrọ ninu ọgba Edẹni.
6. Ni ọjọ Pẹntikọsti 33 C.E., bawo ni Jehofa ṣe fihan pe oun le funni ni agbara lati sọrọ ni awọn ede ahọn?
6 Jehofa, ti o da ede ipilẹṣẹ araye rú, tun le fi agbara naa funni lati fi awọn ede ahọn sọrọ. Họọwu, oun ṣe ohun yẹn gan an ni ọjọ Pẹntikọsti ni ọdun 33 Sanmani Tiwa! Gẹgẹ bi Iṣe 2:1-11 ti wi, nnkan bii 120 awọn ọmọlẹhin Jesu Kristi pejọ nigba naa sinu iyẹwu oke ti Jerusalẹmu. (Iṣe 1:13, 15, NW) Lojiji, ariwo kan wá lati ọrun “gan an gẹgẹ bii afẹfẹ lile arọ́ yìì.” “Awọn ahọn bi ti iná” si di eyi ti o ṣee ri a si pín wọn kaakiri. Nipa iyẹn, awọn ọmọ-ẹhin naa “kún fun ẹmi mimọ wọn si bẹrẹ sii sọrọ ni awọn ede ahọn ọtọọtọ, gan an gẹgẹ bi ẹmi ti nyọnda fifun wọn lati sọ asọjade ọrọ.” Ni awọn ede ti a fifun wọn latọrunwa wọnni, wọn sọrọ “nipa awọn nnkan gbigborinlọla Ọlọrun.” Ẹ si wo iru iṣẹ iyanu ti iyẹn jẹ́, bi awọn Juu ati awọn aláwọ̀ṣe ti wọn nsọrọ ni ede ahọn ọtọọtọ, ti wọn si wá lati iru awọn ibi jijinna sira bii Mesopotamia, Ijibiti, Libiya, ati Roomu, ti loye ihin iṣẹ ti nfunni ni iye naa!
Ede Kan Ti Ọlọrun Fifunni Loni!
7. Awọn ifojusọna wo ni yoo wà bi a ba nsọ ti a si loye kiki ede kanṣoṣo yika aye?
7 Niwọnbi Ọlọrun ti le fi awọn ede ahọn ọtọọtọ funni lọna iṣẹ iyanu, ki yoo ha jẹ iyalẹnu bi oun ba mu ki o ṣeeṣe pe ki a maa sọ ki a si lóye ede kanṣoṣo pere kari aye? Eyi nì yoo ṣe igbega siwaju igbọra ẹni yé pupọ sii laaarin idile eniyan. Gẹgẹbi The World Book Encyclopedia ti sọ: “Bi gbogbo eniyan ba nsọ ede ahọn kan naa, awọn ìdè ti aṣa iṣẹdalẹ ati ti eto ọrọ aje yoo tubọ sunmọra pẹkipẹki sii, ifẹ inurere yoo si pọ si laaarin awọn orilẹ ede.” O dara, o kere tan o ti to 600 awọn ede fun sisọ yika agbaye ti a ti dálábàá la awọn ọdun ja. Ninu iwọnyi, Esperanto ti ni ipa títóbi julọ nitori pe nkan bi 10,000,000 awọn eniyan ti kọ́ ọ lati igba iṣẹda rẹ̀ ni ọdun 1887. Sibẹ, awọn isapa eniyan lati mu araye ṣọkan nipasẹ ede kan fun sisọ yika agbaye ni ko tii ṣaṣeyọrisirere ri. Niti tootọ, awọn iṣoro pupọpupọ sii nfa iyapa ninu aye yii gẹgẹbi ‘awọn eniyan buruku ti nlọ siwaju lati buburu si buburu ju.’—2 Timoti 3:13, NW.
8. Ani bi a ba ṣe mú ede agbaye kan lò ni aye toni paapaa, ki ni yoo ṣi wà sibẹ, eesitiṣe?
8 Ki a sọ niti isin, idarudapọ ńláǹlà ni o wà. Ṣugbọn ko ha yẹ ki a reti eyi bi, niwọnbi iwe Bibeli ti Iṣipaya ti pe ilẹ-ọba isin eke agbaye ni “Babiloni Nla”? (Iṣipaya 18:2) Bẹẹni, nitori “Babiloni” tumọsi “idarudapọ.” Ani bi ede atọwọda kan tabi ede ahọn abinibi kan iru bi Gẹẹsi, Faranse, Jamani, tabi Rọṣia, ba nilati di eyi ti a gbamulo gẹgẹbi ede agbaye yika kan ninu aye lonii, sibẹ aisi iṣọkan yoo ṣì wa niti isin ati ni ọna miiran. Eeṣe? Nitoripe “gbogbo aye ni o wa ni abẹ agbara ẹni buburu nì,” Satani Eṣu. (1 Johanu 5:19) Oun gan an ni apẹẹrẹ akopọ imọtara ẹni-nikan, o si nfi tiwọra tiwọra ṣafẹẹri pe ki gbogbo araye jọsin oun gan an gẹgẹbi o ti ṣe ni awọn ọjọ Nimrọdu ati Ile-iṣọ Babeli. Họọwu, ede agbaye kan ti awọn eniyan ẹlẹṣẹ ba nsọ le fun Satani ni anfaani lati gbe ijọsin Eṣu ti o wa ni iṣọkan kalẹ! Ṣugbọn Jehofa ki yoo yọnda iyẹn lae; nitootọ, oun yoo mu opin wa si gbogbo ijọsin eke, ti Eṣu misi laipẹ.
9. Bawo ni a ṣe nmu awọn eniyan gbogbo orilẹ-ede ati ẹya ṣọkan nisinsinyi?
9 Sibẹ, otitọ amuni ṣe kayefi kan ni pe awọn eniyan daradara lati awọn orilẹ-ede ati ẹya gbogbo ni a ti nmu ṣọkan nisinsinyi. Eyi nṣẹlẹ lori awọn ipo ti Ọlọrun filelẹ ati nititori ijọsin rẹ. Lonii, Ọlọrun mu ki o ṣeeṣe fun eniyan lati kẹkọọ ati lati sọ èdè mímọ́gaara kanṣoṣo ti o wà lori ilẹ-aye. O si jẹ ede agbaye kan niti gidi. Niti tootọ, Jehofa Ọlọrun ńkọ́ ọpọlọpọ awọn eniyan ti awọn orilẹ-ede ati gbogbo ilẹ-aye lonii ni èdè mímọ́gaara yii. Eyi jẹ ni imuṣẹ ileri alasọtẹlẹ ti Ọlọrun nipasẹ wolii ati Ẹlẹrii rẹ Sefanaya: “Nigba naa ni emi yoo fi èdè mímọ́gaara kan [ní olowuuru, “ètè mimọ tonitoni kan”] fun awọn eniyan, nitori ki wọn baa le ma kepe orukọ Jehofa lati le maa ṣiṣẹ sin in ni ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́.” (Sefanaya 3:9, NW) Ki ni “èdè mímọ́gaara” yii?
A Ṣetumọ Èdè Mímọ́gaara
10. Ki ni èdè mímọ́gaara naa?
10 Èdè mímọ́gaara naa ni otitọ Ọlọrun ti a ri ninu Ọrọ tirẹ funraarẹ, Iwe Mimọ. Ni pataki o jẹ otitọ nipa Ijọba Ọlọrun, eyi ti yoo mu alaafia ati awọn ibukun miiran wa fun araye. Ede mímọ́gaara fopin si iṣina isin ati ijọsin eke. O so gbogbo awọn ti wọn nsọ ọ pọ ṣọkan ninu ijọsin mímọ́gaara, mimọ tonitoni, ti o péye ti Ọlọrun otitọ ati alaaye, Jehofa. Lonii, iye ede ti o to 3,000 nṣiṣẹ gẹgẹ bi ìdínà fun oye, ọgọrọọrun awọn isin eke si nda nnkan rú mọ araye loju. Nitori naa bawo ni a ti layọ to pe Ọlọrun fun awa eniyan ni iyipada si èdè mímọ́gaara ti o kun fun agbayanu yii!
11. Ki ni èdè mímọ́gaara ti ṣe fun awọn eniyan gbogbo orilẹ-ede ati ẹya?
11 Bẹẹni, èdè mímọ́gaara ni awọn eniyan gbogbo orilẹ-ede ati ẹya nmọ dunju. Gẹgẹbi ede ahọn mímọ́gaara tẹmi kanṣoṣo lori ilẹ-aye, o ṣiṣẹ gẹgẹbi ipá amuniṣọkan ti o lagbara. O fun gbogbo awọn wọnni ti nsọ ọ́ lagbara “lati kepe orukọ Jehofa, lati le maa ṣiṣẹ́sìn ín ni ifẹgbẹkẹgbẹ,” tabi lọna olowuuru, “pẹlu ejika kan naa.” Wọn tipa bayii ṣiṣẹsin Ọlọrun “pẹlu ijọhẹn kan naa” “pẹlu ijọhẹn alápohùnpọ̀ ṣọ̀kan ati pẹlu ejika onisopọṣọkan.” (The New English Bible; The Amplified Bible) Itumọ lati ọwọ Steven T. Byington ka pe: “Nigba naa ni ẹmi [Jehofa Ọlọrun] yoo yi ètè gbogbo awọn eniyan pada di mimọ tonitoni, ki wọn le maa kepe orukọ Jehofa, ki wọn si fọwọsowọpọ ninu iṣẹ-isin rẹ.” Iru ifọwọsowọpọ kari aye bẹẹ laaarin oniruuru ede ninu iṣẹ-isin Ọlọrun wa laaarin awọn Ẹlẹrii Jehofa nikanṣọṣo. Ni 212 awọn orilẹ-ede lonii, iye ti o ju 4,000,000 awọn olupokiki ijọba wọnyi nwaasu ihin rere ni ọpọlọpọ awọn ede eniyan. Sibẹ, awọn Ẹlẹrii naa “nsọrọ ni ìfohùnṣọ̀kan” a si ‘so wọn pọ̀ ṣọkan ni ibamu rẹgi ni inú kan naa ati ni ọ̀nà ìgbà ronu kan naa.’ (1 Kọrinti 1:10, NW) Eyi ri bẹẹ nitoripe, ni ibikibi yoowu ki wọn wa lori ilẹ-aye, gbogbo awọn Ẹlẹrii Jehofa nsọ èdè mímọ́gaara kanṣoṣo naa, si iyin ati ogo Baba wọn ọrun.
Kọ́ Èdè Mímọ́gaara Naa Nisinsinyi!
12, 13. (a) Eeṣe ti iwọ fi nilati daniyan nipa sisọ èdè mímọ́gaara naa? (b)Eeṣe ti awọn ọrọ ni Sefanaya 3:8, 9 fi ṣe pataki tobẹẹ lonii?
12 Eeṣe ti iwọ fi nilati daniyan nipa sisọ èdè mímọ́gaara? Idi kan ni pe nitori pe iwalaaye rẹ simi lori kikẹkọọ ati sisọ ọ́. Kete ṣaaju ki Ọlọrun to ṣeleri lati “fi iyipada si èdè mímọ́gaara fun awọn eniyan,” oun kilọ pe: “‘Ẹ maa pa ara yin mọ ni ifojusọna fun mi,’ ni asọjade ọrọ Jehofa, ‘titi di ọjọ idide mi si ìkógun, nitori ipinnu idajọ mi ni lati ko awọn orilẹ-ede jọ, fun mi lati ṣa awọn ijọba jọpọ, fun ete lati tú ibawi ikannu mi jade sori wọn, gbogbo ibinu jijofofo mi; nitori gbogbo ilẹ-aye ni a o jẹ ráúráú nipasẹ ina itara mi.’”—Sefanaya 3:8, NW.
13 Awọn ọrọ Jehofa Oluwa Ọba-alaṣẹ wọnni ni a kọkọ sọ ni 26 ọrundun sẹhin ni Juda, eyi ti Jerusalẹmu jẹ olu ilu fun. Ṣugbọn gbolohun ọrọ yẹn ni pataki ni a ni lọkan fun ọjọ wa nitori pe Jerusalẹmu jẹ ojiji iṣaaju fun Kristẹndọm. Akoko wa si ni ọjọ Jehofa fun kiko awọn orilẹ-ede jọ pọ ati pipe awọn ijọba jọ, niwọnbi a ti gbé Ijọba Ọlọrun ti ọrun kalẹ ni 1914 C.E. O ti nmu gbogbo wọn wá papọ sabẹ afiyesi rẹ nipasẹ ijẹrii ńláǹlà kan. Ni tiwọn ẹwẹ, eyi ti ru wọn soke ni ilodi si ete rẹ̀. Bi o ti wu ki o ri, Jehofa Ọlọrun, fi tàánútàánú mu ki awọn eniyan lati inu gbogbo orilẹ-ede wọnyi lagbara lati sopọ ṣọkan ninu sisọ èdè mímọ́gaara naa. Pẹlu rẹ, gbogbo awọn ti wọn nwa iye ninu aye titun rẹ ti o ṣeleri le ṣiṣẹsin ín ni iṣọkan ṣaaju ki a to fi ọrọ asọjade amúbí ina ti ibinu atọrunwa jẹ gbogbo awọn orilẹ-ede run ráúráú ni “ogun ọjọ nla Ọlọrun Olodumare,” ti a npe lọna wiwọpọ ni Amagẹdọn. (Iṣipaya 16:14, 16; 2 Peteru 3:13) Lọna ti o muni layọ, awọn ti wọn nsọ èdè mímọ́gaara naa ti wọn si nfi igbagbọ kepe orukọ Jehofa gẹgẹbi awọn olujọsin tootọ ti a sopọṣọkan yoo gbadun aabo atọrunwa lakooko ti ijaba aye yẹn ba ngbona janjan. Ọlọrun yoo mu wọn wa sinu aye titun naa laisewu, nibiti kiki èdè mímọ́gaara naa yoo ti wà lori ete gbogbo araye nikẹhin.
14. Nipasẹ Sefanaya, bawo ni Ọlọrun ṣe fihan pe lila opin eto igbekalẹ awọn nnkan yii já nbeere fun igbesẹ lọgan?
14 Nipasẹ wolii rẹ Sefanaya, Jehofa mu ṣe kedere pe awọn wọnni ti wọn nireti lati la opin eto igbekalẹ awọn nnkan buburu isinsinyi já gbọdọ gbéègbésẹ̀ lọgan. Gẹgẹ bi o ti wà ninu Sefanaya 2:1-3 (NW), Ọlọrun wipe: “Ẹ ko ara yin jọ pọ, bẹẹni, ẹ ṣe ikorajọpọ naa, óò orilẹ-ede ti ko rẹwẹsi loju nitori itiju. Ṣaaju ki ilana ofin naa to bi ohunkohun, ṣaaju ki ọjọ naa to kọja lọ gan an gẹgẹbi ìyàngbò, ṣaaju ki ibinu jijofofo ti Jehofa to wá sori ẹyin eniyan, ṣaaju ki ọjọ ibinu Jehofa to wá sori yin, ẹ wá Jehofa, gbogbo ẹyin oninututu ilẹ-aye, ti ẹ ti sọ ṣiṣe ipinnu idajọ Rẹ funraarẹ daṣa. Ẹ wá ododo, ẹ wá inututu. Boya a o le fi yin pamọ nikọkọ ni ọjọ ibinu Jehofa.”
15. (a) Ki ni imuṣẹ akọkọ ti Sefanaya 2:1-3? (b) Awọn ta ni o la imuṣẹ idajọ Ọlọrun sori Juda já, ki ni yoo si ba lilaaja yi dọgba rẹgi ni ọjọ wa?
15 Awọn ọrọ wọnni ni imuṣẹ akọkọ wọn lori Juda ti Jerusalẹmu igbaani. Awọn eniyan Juda ti wọn kun fun ẹṣẹ ko fi ojurere dahun pada si iparọwa Ọlọrun, bi o ti fihan nipasẹ mimu idajọ rẹ ṣẹ ni kikun le wọn lori lati ọwọ awọn ara Babiloni ni ọdun 607 B.C.E. Ani gẹgẹbi Juda ti jẹ “orilẹ-ede ti ko rẹwẹsi loju nitori itiju” niwaju Ọlọrun, bẹẹni Kristẹndọm ti jẹ “orilẹ-ede” alainitiju niwaju Jehofa. Bi o ti wu ki o ri, nitori kikọbiara si ọrọ Ọlọrun, awọn ara Judia kan ati awọn elomiran laaja, lara wọn ni Jeremaya Wolii oluṣotitọ ti Jehofa wà. Awọn olulaaja miiran ni ara Etiopia naa ti orukọ rẹ njẹ Ebedi-meleki ati awọn ọmọ iran Jehonadabu. (Jeremaya 35:18, 19; 39:11, 12, 16-18) Lọna ti o farajọra lonii, “ogunlọgọ nla” ti “awọn agutan miiran” ti Jesu ti a kojọpọ lati inu awọn orile-ede yoo la Amagẹdọn ja sinu aye titun ti Ọlọrun. (Iṣipaya 7:9, NW; Johanu 10:14-16) Kiki awọn wọnni ti wọn kẹkọọ ti wọn si nsọ èdè mímọ́gaara ni wọn yoo jẹ olulaaja alayọ.
16. Ki ni a gbọdọ ṣe lati di ẹni ti a fi pamọ nikọkọ “ni ọjọ ibinu Jehofa”?
16 Gan an gẹgẹbi o ti jẹ ilana ofin Jehofa pe Juda ati Jerusalẹmu ni a nilati nù nù kuro, bẹẹ naa ni Kristẹndọm gbọdọ ṣegbe. Nitootọ, iparun gbogbo isin eke ti sunmọle, awọn wọnni ti wọn ṣi ndaniyan lati laaja gbọdọ gbégbèésẹ̀ lẹsẹkẹsẹ. Wọn gbọdọ ṣe bẹẹ “ki ọjọ naa to kọja lọ gan an gẹgẹbi ìyàngbò,” eyi ti ẹ̀fúùfù nyara fẹ́ danu, bi igba ti a ba da ọkà soke sinu afẹfẹ ni ilẹ ìpakà. Lati ri idande kuro ninu ibinu Ọlọrun, a gbọdọ sọ èdè mímọ́gaara naa ki a si dahun pada si ikilọ Ọlọrun ṣaaju ki ọjọ ibinu jijofofo ti Jehofa to de sori wa. Ni ọjọ Sefanaya ati lonii, awọn oninu tutu nwa Jehofa Ọlọrun, papọ pẹlu iwa ododo ati inututu. Wiwa Jehofa wa tumọsi ninifẹẹ rẹ pẹlu gbogbo ọkan-aya, ọkan, iro-inu, ati okun wa. (Maaku 12:29, 30) “Boya a o fi [awọn wọnni ti wọn nṣe bẹẹ] pamọ nikọkọ ni ọjọ ibinu Jehofa.” Ṣugbọn eeṣe ti asọtẹlẹ naa fi wipe “boya”? Nitori igbala sinmi lori iṣotitọ ati ifarada. (Matiu 24:13) Awọn wọnni ti wọn ba awọn ọpa idiwọn ododo Ọlọrun ṣe deedee ti wọn si nbaa lọ ni sisọ èdè mímọ́gaara naa ni a o pamọ nikọkọ ni ọjọ ibinu Jehofa.
17. Awọn ibeere wo ni wọn ṣẹ́kù fun igbeyẹwo wa?
17 Niwọnbi ọjọ ibinu Jehofa ti sunmọle ti igbala si sinmi lori kikẹkọọ ati lilo èdè mímọ́gaara, nisinsinyi ni akoko naa lati kówọnu kikẹkọọ rẹ jinlẹjinlẹ ati sisọ ọ́. Ṣugbọn bawo ni ẹni kan ṣe le kọ́ èdè mímọ́gaara naa? Bawo si ni iwọ ṣe le janfaani lati inu sisọ ọ́?
Bawo ni Iwọ Yoo Ṣe Dahun?
◻ Bawo ni ọrọ sisọ eniyan ṣe pilẹṣẹ?
◻ Ki ni èdè mímọ́gaara naa?
◻ Eeṣe ti awọn ọrọ ni Sefanaya 3:8, 9 fi ṣe pataki tobẹẹ lonii?
◻ Ki ni a gbọdọ ṣe lati fi wa pamọ nikọkọ “ni ọjọ ibinu Jehofa”?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]
Ni Babeli, Ọlọrun tú araye ká nipa dida èdè wọn rú