Awọn Ère Ha Lè Túbọ̀ Mú Ọ Sunmọ Ọlọrun Bi?
ỌGỌỌRỌ awọn ère Ijibiti, Babiloni, ati Giriiki kún inu awọn ile ti a ń kó ohun ìṣẹ̀ǹbáyé pamọ si lonii. Awọn aworan ère ti wọn ti figbakan rí jẹ́ ohun ìfitaratara kunlẹbọ ni a pàtẹ wọn nisinsinyi gẹgẹ bi awọn iṣẹ ọnà igbaani lasan. Kìkì ninu ironu awọn wọnni ti ń jọsin wọn ni agbara wọn wà. Pẹlu ikọjalọ awọn eniyan ti wọn júbà wọn lẹhin-ọ-rẹhin, agbara ti a lero pe o jẹ́ ti awọn ère wọnyi poora pẹlu. Awọn ère naa ni a fihan sode bi eyi ti o jẹ́ alailagbara—eyi tí wọn ti figba gbogbo jẹ́ niti gidi—ohun alailẹmii ti igi, okuta, tabi irin.
Ki ni nipa awọn ère ti awọn eniyan ń júbà ti wọn sì ń jọsin lonii? Awọn ère wọnyii ha tubọ lagbara ju awọn ère Ijibiti, Babiloni, ati Giriiki igbaani lọ bi? Wọn ha ti jẹ́ ohun eelo ninu ríran eniyan lọwọ lati tubọ sunmọ Ọlọrun nitootọ bi?
Pẹlu ikọjalọ iran kọọkan, ó jọ bii pe araye ń súnlọ siwaju ati siwaju sii jinna kuro lọdọ Ọlọrun. Ki sì ni gbogbo awọn ère ninu ayé lè ṣe nipa rẹ̀? Bi a bá fi silẹ laibojuto o, eruku a bò wọn wọn a sì dípẹtà tabi jẹrà lẹhin-ọ-rẹhin. Wọn kò lè bojuto araawọn, ki a má tii sọ ṣiṣe ohunkohun fun awọn eniyan. Bi o ti wu ki o ri, eyi ti o ṣe pataki ju ni pé, ki ni ohun ti Bibeli ní lati sọ lori ọran yii?
Wọn Gbowolori, Wọn Kàndudu, Ṣugbọn Wọn Kò Wulo
Lọna ti kò yanilẹnu, Bibeli fi awọn ère han gẹgẹ bi alaiwulo ati alaile ran awọn olufọkansin wọn lọwọ lati tubọ sunmọ Ọlọrun. Bi o tilẹ jẹ pe awọn ère isin saba maa ń gbowolori ti wọn sì maa ń kàndudu, Bibeli fi ohun ti wọn jámọ́ nitootọ han nigba ti o wi pe: “Fàdákà ati wúrà ni ère wọn, iṣẹ ọwọ eniyan. Wọn ni ẹnu ṣugbọn wọn kò sọrọ: wọn ni oju, ṣugbọn wọn kò ríran. Wọn ni eti, ṣugbọn wọn kò gbọ́ràn: wọn ni imú, ṣugbọn wọn kò gboorun. Wọn ni ọwọ ṣugbọn wọn kò lò ó: wọn ni ẹsẹ, ṣugbọn wọn kò rìn: bẹẹni wọn kò sọrọ lati ọ̀fun wọn jade. Awọn ti ń ṣe wọn dabi wọn; bẹẹni olukuluku ẹni ti ó gbẹkẹle wọn.”—Saamu 115:4-8.
Kii ṣe pe Bibeli tudii awọn oriṣa gẹgẹ alaiwulo nikan ni ṣugbọn ó tun fi ọrọ dẹ́bi fun awọn ère ati awọn olujọsin wọn: “Wọn nàró bi igi ọpẹ, ṣugbọn wọn kò fọhun: gbigbe ni a ń gbe wọn, nitori wọn kò lè rìn. Má bẹru wọn; nitori wọn kò lè ṣe buburu, bẹẹ ni ati ṣe rere, kò si ninu wọn. Aṣiwere ni gbogbo eniyan nitori òye kò sí: oju ti olukuluku alagbẹdẹ niwaju ère rẹ̀, nitori ère dídá rẹ̀ èké ni, kò sì sí ẹmi ninu rẹ̀. Asan ni wọn, ati iṣẹ iṣina.”—Jeremaya 10:5, 14, 15.
Oju-Iwoye Katoliki
Otitọ ni pe, ọpọ awọn ti ń foribalẹ, gbadura, ti wọn ń tan abẹla sí, ti wọn sì ń fi ẹnu ko awọn ère isin lẹnu kò wo araawọn gẹgẹ bi abọriṣa tabi olujọsin ère. Fun apẹẹrẹ, awọn Katoliki sọ pe awọn ń júbà awọn ère Kristi ati Maria, kii ṣe nitori pe awọn ère naa ninu araawọn ni ipo ọrun eyikeyii, ṣugbọn nitori ẹni ti awọn ère naa duro fun. The World Book Encyclopedia sọ pe “ninu Ṣọọṣi Roman Katoliki, awọn ère ni a ń kunlẹ bọ gẹgẹ bi ami awọn eniyan ti wọn duro fun.” Alufaa Katoliki ti waasu pe ó tọna lati júbà ère kan niwọn igba ti ìjúbà naa bá ti jẹ́ eyi ti ijojulowo rẹ̀ rẹlẹ si eyi ti ti o tọ́ sí Ọlọrun funraarẹ.
Otitọ naa ni pe awọn ère wọnyi ni a ń júbà. Ani New Catholic Encyclopedia paapaa gba pe iru ìjúbà bẹẹ jẹ́ “iṣe ijọsin kan.” Bi o ti wu ki o ri, Jesu Kristi wọgile ìlò awọn ère gẹgẹ bi aranṣe ninu titọ Ọlọrun lọ nigba ti o wi pe: “Kò sí ẹnikẹni ti o lè wá sọdọ Baba, bikoṣe nipasẹ mi.” (Johanu 14:6) Kii ṣe ohun iyalẹnu, nigba naa, pe awọn Kristẹni ọrundun kìn-ín-ní kọ ìlò awọn ère ninu ijọsin silẹ.
Laika eyiini si, lonii awọn isin Kristẹndọmu tayọ gbogbo awọn yooku ninu ailonka oniruuru awọn ère. Bẹẹni, loju gbogbo ẹ̀rí ìtàn ati ti Iwe Mimọ ti ń ṣí iwa ẹ̀gọ̀ ti ń bẹ lẹhin ìjúba ère kan paya, awọn Kristẹni alafẹnujẹ kari ayé ń baa lọ lati maa tẹriba ati lati gbadura niwaju awọn ère ninu iwakiri olotiitọ ọkàn wọn fun Ọlọrun. Eeṣe?
A Tàn Wọn Jẹ Nipasẹ Ọta Kan
Wolii Aisaya sọ pe awọn olujọsin ère ọjọ rẹ̀ kuna lati rí iwa ẹ̀gọ̀ igbesẹ wọn nitori pe oju wọn ni a ti “lẹ̀ pọ ki wọn má baa ríran, ọkan-aya wọn ki wọn má baa ni ijinlẹ oye kankan.” (Aisaya 44:18, New World Translation [Gẹẹsi]) Ta ni o ṣeeṣe ki o lo iru agbara idari kan bẹẹ lori awọn eniyan? Igbimọ olùpa-ère-run ti 754 C.E. kede pe ìjúba awọn ère ni Satani mú wọle wá fun ète titan eniyan jẹ́ kuro lọdọ Ọlọrun otitọ naa. Ipari ero yii ha tọna bi?
Bẹẹni, nitori ti ó fohunṣọkan pẹlu Bibeli ti a mísí, eyi ti o sọ ni ọpọ ọrundun ṣaaju pe olori ọ̀tá Ọlọrun, Satani Eṣu, “ti sọ ọkàn” awọn eniyan “di afọju” ki imọlẹ otitọ ma baa “mọlẹ ninu wọn.” (2 Kọrinti 4:4) Nitori naa nigba ti ó bá ń júbà ère kan, dipo titubọ sunmọ Ọlọrun, ẹnikan niti tootọ ń ṣiṣẹsin ire awọn ẹmi eṣu.—1 Kọrinti 10:19, 20.
Titubọ Sunmọ Ọlọrun
Awọn ère kò lè ran wa lọwọ lati tubọ sunmọ Ọlọrun. Ẹlẹdaa Atobilọla, Jehofa Ọlọrun, koriira ìjúbà awọn ère. (Deutaronomi 7:25) “Jehofa jẹ Ọlọrun ti ń fi dandan beere ifọkansin ti a yasọtọ gedegbe.” (Nahumu 1:2, NW) Ó sọ pe: “Emi ni Jehofa. Orukọ mi niyẹn; kii sii ṣe ẹlomiran kankan ni emi yoo fi ogo temi tikaraami fun, yala ìyìn mi fun awọn ère gbigbẹ.” (Aisaya 42:8, NW) Lọna ti o ba a mu, Bibeli funni ni ikilọ pe awọn wọnni ti ń júbà awọn ère “ki yoo jogun ijọba Ọlọrun.”—Galatia 5:19-21.
Sibẹ, Jehofa tun jẹ́ aláàánú ati Ọlọrun ti ń darijini. Bibeli sọ nipa awọn wọnni ti wọn yipada si Ọlọrun kuro ninu awọn oriṣa wọn ti a sì polongo ni olododo lẹhin ti wọn ti dawọ awọn àṣà ibọriṣa wọn duro. (1 Kọrinti 6:9-11; 1 Tẹsalonika 1:9) Wọn kọbiara si awọn ọrọ Jesu pe: “Ẹmi ni Ọlọrun: awọn ẹni ti ń sin in kò lè ṣe alaisin in ni ẹmi ati ni otitọ.”—Johanu 4:24.
Ikẹkọọ Bibeli taapọntaapọn yoo ṣipaya pe kò ṣoro lati tubọ sunmọ Ọlọrun. (Iṣe 17:26-28) O ni animọ ọlọyaya, onifẹẹ, ati jíjẹ́ ẹni ti o ṣee tọ̀ lọ, ó sì ké si wa ó sì reti pe ki a mu ipo ibatan timọtimọ dagba pẹlu oun.—Aisaya 1:18.
Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ké sí ọ lati mọ Baba wa ọrun gẹgẹ bi Ẹnikan, lati mọ nipa orukọ rẹ̀, Jehofa, ati nipa awọn animọ ati ibalo rẹ̀ pẹlu araye. Nipasẹ awọn oju-iwe Ọrọ rẹ̀, Bibeli, iwọ yoo wá loye idi ti iwọ niti gidi kò fi nilo awọn aranṣe àfojúrí, iru bii awọn aworan ère ati aworan, lati tọ Ọlọrun lọ. Bẹẹni, ‘sunmọ Ọlọrun, oun yoo sì sunmọ ọ.’—Jakobu 4:8.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 6]
Awọn Opitan Ṣakiyesi pe . . .
◻ “Ó jẹ́ otitọ ti a mọ dunju pe isin Buddha, ti a dasilẹ ni ọrundun kẹfa BCE, kò ri ère akọkọ ti oludasilẹ rẹ̀ titi fi di nǹkan bii ọrundun kìn-ín-ní CE.”
“Fun ọpọ ọrundun, igbagbọ atọwọdọwọ Hindu ni pataki jẹ́ ọ̀kan ti kò ni ère ninu.”
“Isin Hindu ati isin Buddha papọ bẹrẹ lọna alaini ère wọn sì wulẹ tẹwọgba awọn ère ni kẹrẹkẹrẹ sinu ijọsin wọn ni. Isin Kristẹni ṣe bakan naa.”—The Encyclopedia of Religion, lati ọwọ Mircea Eliade.
◻ “Lati inu oniruuru akọsilẹ Bibeli ni o ti ṣe kedere pe ijọsin Ọlọrun tootọ kò ni awọn ère ninu. . . . Ninu MT [Majẹmu Titun], pẹlu, ijọsin awọn ọlọrun ati oriṣa ajeji ni a kàléèwọ̀.”—New Catholic Encyclopedia.
◻ “Awọn ère ni a kò mọ ninu ijọsin awọn Kristẹni akọkọ.”—Cyclopedia of Biblical, Theological, and Ecclesiastical Literature, lati ọwọ McClintock ati Strong.
◻ “Yala ninu Majẹmu Titun, tabi ninu awọn ikọwe ojulowo eyikeyii ti sanmani akọkọ ti isin Kristẹni, ni a kò ti lè ri ipa ìlò aworan ère ati awọn aworan eyikeyii ninu ijọsin awọn Kristẹni, yala ni gbangba tabi ni ìdákọ́ńkọ́.” —A Concise Cyclopedia of Religious Knowledge, lati ọwọ Elias Benjamin Sanford.
◻ “Awọn Kristẹni ijimiji ìbá ti fi oju buruku wo idamọran wiwulẹ gbe ère sinu awọn ṣọọṣi, wọn ìbá sì ti ka fiforibalẹ tabi gbigbadura niwaju wọn si ohun ti kò kere si ibọriṣa.” —History of the Christian Church, lati ọwọ John Fletcher Hurst.
◻ “Ninu ṣọọṣi ijimiji, ṣiṣe ati jíjúbà aworan Kristi ati awọn ẹni mimọ ni a kọjúùjà sí lọna ti ó ṣọkan délẹ̀.”—The New Encyclopedia Britannica.
◻ “Bi o tilẹ jẹ pe Ṣọọṣi akọkọ ni kò fẹran iṣẹ ọnà, sibẹ kò ni awọn ère Kristi.” —Schaff-Herzog Encyclopedia of Religious Knowledge.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Jesu tẹnumọ ọn pe Ọlọrun ń wá awọn wọnni ti wọn ń “jọsin Baba ni ẹmi ati ni otitọ”