Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí
“Iwọ ni Kristi naa, Ọmọkunrin Ọlọrun alaaye.”—MATIU 16:16, NW.
1, 2. (a) Ọna wo ni a lè gbà pinnu ìtóbilọla ọkunrin kan? (b) Awọn ọkunrin wo ninu ìtàn ni a ti pè ni Ńlá, eesitiṣe?
TA NI iwọ lero pe o jẹ ọkunrin titobilọla julọ ti o tíì gbé ayé rí? Bawo ni iwọ yoo ṣe diyele ìtóbilọ́lá ọkunrin kan? Nipa ọgbọn ìgbógun rẹ̀ ti o ṣàrà ọ̀tọ̀ ni bi? agbara òye rẹ̀ ti o tayọlọla ni bi? okun rẹ̀ ni bi?
2 Oniruuru awọn oluṣakoso ni a ti pe ni ẹni Ńlá, iru bii Kirusi Ńlá, Alexander Ńlá, ati Charlemagne, ẹni ti a pe ni “Ńlá” koda nigba ayé rẹ̀. Nipa irisi abanilẹru wọn, iru awọn eniyan bawọnyi ti lo agbara idari ńlá lori awọn wọnni ti wọn ṣakoso lé lori.
3. (a) Ki ni idiwọn nipa eyi ti a lè fi wọn ìtóbilọ́lá ọkunrin kan? (b) Ni lilo iru idiwọn kan bẹẹ, ta ni ọkunrin titobilọla julọ ti o tii gbé ayé rí?
3 Lọna ti o dunmọni, opitan H. G. Wells ṣapejuwe idiwọn tirẹ fun wíwọn bi ọkunrin kan ti tobilọla tó. Ni eyi ti o ju 50 ọdun sẹhin, oun kọwe pe: “Idiwọn opitan naa fun pipinnu bi ẹnikan ti tobilọla tó ni ‘Ki ni ó fi silẹ lati gbèrú lẹhin rẹ̀? Oun ha sun awọn eniyan lati bẹrẹ sii ronu lori awọn ipa ọna titun pẹlu okun inu alagbara ti ń baa lọ lẹhin iku rẹ̀ bi?’ Lori idiwọn yii,” Wells pari rẹ̀ pe, “Jesu gba ipo kìn-ín-ní.” Napoléon Bonaparte paapaa sọ ọ́ di mímọ̀ pe: “Jesu Kristi ti nipa lori o sì ti ṣakoso awọn ọmọ abẹ Rẹ̀ laisi nibẹ nipa ti ara.”
4. (a) Awọn oju-iwoye yiyatọ wo ni ó wà nipa Jesu? (b) Ipo wo ni awọn opitan ti kii ṣe Kristẹni fifun Jesu?
4 Sibẹ, awọn kan ti ṣatako pe Jesu kii ṣe ẹni gidi kan ninu ìtàn bikoṣe arosọ atọwọdọwọ kan. Ni ipẹkun keji ẹ̀wẹ̀, ọpọlọpọ ni wọn ti jọsin Jesu gẹgẹ bi Ọlọrun, ni sisọ pe Ọlọrun wá si ayé gẹgẹ bii Jesu. Bi o ti wu ki o ri, ni gbigbe awọn ipari ero rẹ̀ kárí kiki awọn ẹ̀rí ìtàn nipa wíwà Jesu gẹgẹ bi ọkunrin kan, Wells kọwe pe: “Ó jẹ́ ohun ti o dunmọni ti o sì ṣe pataki pe opitan kan laisi ẹtanu ẹkọ isin eyikeyii, lè rii pe oun kò lè fi ailabosi yaworan itẹsiwaju ẹ̀dá eniyan laifi ipo ti o gba iwaju julọ fun talaka olukọ kan lati Nasarẹti. . . . Opitan kan bii temi, ti kò tilẹ pe araarẹ ni Kristẹni, ri aworan naa ti o rọ̀gbà yí igbesi-aye ati iwa ọkunrin ti o ṣe pataki julọ yii ká laiṣe e yẹsilẹ.”
Jesu Ha Gbé Ayé Niti Gidi Bi?
5, 6. Ki ni opitan H. G. Wells ati Will Durant ni lati sọ nipa jíjẹ́ ti Jesu jẹ ẹni gidi ninu ìtàn?
5 Ṣugbọn bi ẹnikan bá sọ fun ọ pe Jesu kò figba kan gbé ayé rí, pe oun, nipa bẹẹ, jẹ́ arosọ atọwọdọwọ kan lasan, ihumọ awọn ọkunrin melookan ni ọgọrun-un ọdun kìn-ín-ní? Bawo ni iwọ yoo ṣe dahun si ẹsun yii? Nigba ti Wells gbà pe “awa kò mọ pupọ nipa [Jesu] gẹgẹ bi awa ìbá ti fẹ lati mọ,” o ṣakiyesi bi o ti wu ki o ri, pe: “Awọn Ihinrere mẹrin naa . . . fohunṣọkan ni fifun wa ni aworan ẹni gidi kan; wọn ni idaniloju ohun gidi kan ninu. Lati gba wi pe oun kò gbé ayé rí, pe akọsilẹ igbesi-aye rẹ̀ jẹ́ awọn ohun ti a humọ rẹ̀, jẹ́ ohun ti o tubọ nira ti ó sì gbé iṣoro pupọpupọ sii dide fun opitan ju lati tẹwọgba awọn àlàyé ṣiṣekoko inu awọn ìtàn Ihinrere naa gẹgẹ bi otitọ.”
6 Opitan ti a bọwọ fun naa Will Durant fi ọgbọ́n ronu ni ọna kan naa, ni ṣiṣalaye pe: “Pe awọn eniyan gbáàtúù kereje kan [ti wọn pe araawọn ni Kristẹni] ninu ìran kan yoo ti humọ ẹni gidi kan ti o lagbara ti o sì fanimọra bẹẹ, ilana iwarere ti o ga tobẹẹ ati aworan iṣọkan ẹgbẹ́ arakunrin ti o taniji bẹẹ, yoo ti jẹ́ iṣẹ iyanu gígadabú kan ti o tayọ eyikeyii ti a ṣakọsilẹ rẹ̀ sinu Awọn Ihinrere.”
7, 8. Lọna titobi wo ni Jesu gbà nipa lori ìtàn ẹ̀dá eniyan?
7 Nipa bayii, iwọ lè ronu pẹlu oniyemeji kan bẹẹ pe: Njẹ ẹni arosọ atọwọdọwọ kan—ẹnikan ti kò gbé ayé rí—ha lè nipa lori ìtàn ẹ̀dá eniyan lọna ti o kọyọyọ bẹẹ? Iwe itọkasi naa The Historians’ History of the World ṣalaye pe: “Abajade awọn igbokegbodo [Jesu] ti a gbekari ìtàn ṣe pataki pupọpupọ, kódà lati oju iwoye alaijẹ tẹmi kan, ju ti awọn iṣẹ ẹ̀dá eniyan miiran ninu ìtàn. Sáà titun kan, tí awọn ilẹ ọlọlaju pataki ninu ayé mọ daju, bẹrẹ nigba ìbí rẹ̀.” Ronu nipa rẹ̀ ná. Kódà awọn kalẹnda kan lonii ni a gbeka ori ọdun ti a lero pe a bí Jesu. “Awọn ọdun ṣaaju akoko naa ni a n pe ni B.C., tabi before Christ (ṣaaju ìbí Kristi),” ni iwe The World Book Encyclopedia ṣalaye. “Awọn ọdun lẹhin akoko naa ni a sì ń pe ni A.D., tabi anno Domini (ni ọdun Oluwa wa).”
8 Nipa awọn ẹkọ alagbara rẹ̀ ati ọna ti oun gbà gbé igbesi-aye rẹ̀ ní ibamu pẹlu wọn, Jesu ti ni ipá alagbara lori igbesi-aye aimọye ẹgbẹẹgbẹrun awọn eniyan fun eyi ti o fẹrẹẹ tó ẹgbẹrun meji ọdun. Gẹgẹ bi onkọwe kan ṣe ṣalaye rẹ̀ lọna ti o bamuwẹku pe: “Gbogbo ẹgbẹ́ ọmọ ogun ti o tíì yan lori ilẹ rí, gbogbo ẹgbẹ́ ọmọ ogun oju-omi ti a tíì kójọ rí, ati gbogbo igbimọ aṣofin giga julọ ti wọn tii jokoo rí, gbogbo awọn ọba ti wọn tii ṣakoso rí, ni apapọ kò tíì nipa lori igbesi-aye eniyan lori ilẹ-aye yii lọna alagbara bẹẹ.” Ṣugbọn awọn alatako sọ pe: ‘Gbogbo ohun ti a mọ niti gidi nipa Jesu ni a rí ninu Bibeli. Kò sí awọn akọsilẹ ìgbà naa miiran ti o sọrọ nipa rẹ̀ ti ń bẹ larọọwọto.’ Ṣugbọn eyi ha jẹ́ otitọ bi?
9, 10. (a) Ki ni awọn opitan ati onkọwe ayé ijimiji sọ nipa Jesu? (b) Lori ẹ̀rí awọn opitan ijimiji, ki ni iwe gbédègbẹ́yọ̀ ti a bọwọ fun kan pari ero sí?
9 Bi o tilẹ jẹ pe itọka awọn opitan ayé ni ijimiji si Jesu Kristi jẹ́ eyi ti kò tó nǹkan, iru awọn itọkasi bẹẹ wà. Cornelius Tacitus, opitan ara Roomu ti ọgọrun-un ọdun kìn-ín-ní ti a bọwọ fun kan, kọwe pe Nero olu-ọba Roomu ‘di ẹ̀bi ẹ̀sùn ti jíjó ilu Roomu ru awọn Kristẹni,’ ati lẹhin naa Tacitus ṣalaye pe: “Orukọ naa [Kristẹni] ni a fayọ lati inu Kristi, ẹni ti gomina Pọntu Pilatu mu ki a pa ni ìgbà iṣakoso Tiberiu.” Suetonius ati Pliny Kekere, awọn onkọwe ara Roomu miiran ti akoko naa, tun mẹnukan Kristi. Ni afikun sii, Flavius Josephus, opitan Juu ti ọrundun kìn-ín-ní, kọwe ninu Antiquities of the Jews nipa iku Jakọbu, Kristẹni ọmọlẹhin naa. Josephus sọ ninu àlàyé rẹ̀ pe Jakọbu jẹ́ “arakunrin Jesu, ẹni ti a ń pe ni Kristi.”
10 Iwe The New Encyclopædia Britannica tipa bayii pari ero si pe: “Awọn akọsilẹ ọtọọtọ wọnyi jẹrii pe ni ìgbà ijimiji awọn ọta Kristẹni paapaa ko ṣiyemeji jíjẹ́ ti Jesu jẹ́ ẹni ìtàn rara, eyi ti o wa di ọrọ ariyanjiyan fun ìgbà akọkọ ati lori ipilẹ ti kò lẹsẹ nilẹ ni opin ọgọrun-un ọdun kejidinlogun, ni ọgọrun-un ọdun kọkandinlogun, ati ni ibẹrẹ ọgọrun-un ọdun lọna ogun.”
Ta Ni Jesu Jẹ́ Niti Gidi?
11. (a) Ni pataki, ki ni orisun kanṣoṣo ti isọfunni onítàn nipa Jesu? (b) Ibeere wo ni awọn ọmọlẹhin Jesu funraarẹ beere nipa ìdámọ̀ rẹ̀?
11 Bi o ti wu ki o ri, lọna ti o ṣekoko, gbogbo ohun ti a mọ bayii nipa Jesu ni a ṣe akọsilẹ rẹ̀ nipasẹ awọn ọmọlẹhin rẹ̀ ọgọrun-un ọdun kìn-ín-ní. Awọn akọsilẹ wọn ni a ti pamọ ninu Awọn Ihinrere—awọn iwe Bibeli ti a kọ lati ọwọ awọn apọsiteli rẹ̀ meji, Matiu ati Johanu, ati awọn meji miiran ti wọn jẹ́ ọmọlẹhin rẹ̀, Maaku ati Luuku. Ki ni ohun ti akọsilẹ awọn ọkunrin wọnyi ṣipaya nipa ẹni ti Jesu jẹ́? Ta ni oun tilẹ jẹ́ niti gidi? Awọn alabaakẹgbẹ Jesu Kristi ni ọgọrun-un ọdun kìn-ín-ní ṣaṣaro lori ibeere yii. Nigba ti wọn ri ti Jesu bá ìgbì okun wí ti o sì parọrọ, wọn ṣe kayefi tiyanutiyanu pe: “Ta ni eyi niti gidi?” Ni akoko miiran Jesu beere lọwọ awọn apọsiteli rẹ̀ pe: “Ta ni ẹyin ń fi mi pè?”—Maaku 4:41; Matiu 16:15.
12. Bawo ni a ṣe mọ̀ pe Jesu kii ṣe Ọlọrun?
12 Bi a ba bi ọ ni ibeere yẹn, bawo ni iwọ yoo ṣe dahun? Ta ni Jesu jẹ́ niti gidi? Dajudaju, ọpọlọpọ ninu Kristẹndọmu yoo wi pe oun ni Ọlọrun Olodumare ninu ẹran ara, Ọlọrun ti o gbé ẹran ara wọ̀. Sibẹ, awọn alabaakẹgbẹpọ Jesu funraarẹ kò figba kankan gbagbọ pe oun ni Ọlọrun. Apọsiteli Peteru pe e ni “Kristi naa, Ọmọkunrin Ọlọrun alaaye.” (Matiu 16:16, NW) Ṣe iwadii gẹgẹ bi o sì ti lè ṣe tó, iwọ ki yoo kà lae pe Jesu pe araarẹ ni Ọlọrun. Kaka bẹẹ, oun sọ fun awọn Juu pe oun jẹ́ “Ọmọkunrin Ọlọrun,” kii ṣe Ọlọrun.—Johanu 10:36.
13. Bawo ni Jesu ṣe yatọ si gbogbo awọn eniyan yooku?
13 Nigba ti Jesu rìn kọja laaarin ìgbì okun, awọn ọmọlẹhin rẹ̀ ni a tubọ tẹ otitọ naa mọ́ lọkan pe oun kii ṣe ọkunrin kan lasan gẹgẹ bi eniyan eyikeyii miiran. (Johanu 6:18-21) Oun jẹ́ eniyan akanṣe kan. Eyi jẹ́ nitori pe oun ti figbakan ri gbé gẹgẹ bi ẹ̀dá ẹmi kan pẹlu Ọlọrun ninu ọrun, bẹẹni, gẹgẹ bi angẹli kan, ti Bibeli tọka si gẹgẹ bi olori awọn angẹli. (1 Tẹsalonika 4:16; Juuda 9) Ọlọrun ti ṣẹda rẹ̀ ṣaaju ki O tó dá awọn ohun miiran gbogbo. (Kolose 1:15) Nipa bẹẹ, fun aimọye ọdun, ṣaaju ki a tó dá agbaye wa ti o ṣee fojuri paapaa, ni Jesu fi gbadun ibatan timọtimọ pẹlu Baba rẹ̀, Jehofa Ọlọrun, Ẹlẹdaa Atobilọla naa ni ọrun.—Owe 8:22, 27-31; Oniwaasu 12:1.
14. Bawo ni Jesu ṣe di ọkunrin kan?
14 Nigba naa, ni nǹkan bii ẹgbẹrun ọdun meji sẹhin, Ọlọrun ta àtaré iwalaaye Ọmọ rẹ̀ sinu ile ọlẹ̀ obinrin kan. Ó sì tipa bẹẹ di eniyan ọmọkunrin Ọlọrun, ti a bi lọna ti ẹ̀dá nipasẹ obinrin kan. (Galatia 4:4) Nigba ti Jesu ń dagba ninu ile ọmọ iya rẹ̀, Maria, ati lẹhin naa nigba ti oun ń dagba gẹgẹ bi ọmọkunrin kan, oun gbarale awọn wọnni ti Ọlọrun ti yàn lati jẹ́ obi rẹ̀ lori ilẹ-aye. Lẹhin-ọ-rẹhin Jesu dagba dé ipo ọkunrin, ati lọna ti o han gbangba nigba naa oun ni a fun ni iranti ibaṣepọ rẹ̀ ti o ti ní ṣaaju pẹlu Ọlọrun loke ọrun. Eyi ṣẹlẹ ‘nigba ti a ṣí awọn ọrun silẹ fun un’ ni akoko bamtisimu rẹ̀.—Matiu 3:16; Johanu 8:23; 17:5.
15. Bawo ni a ṣe mọ pe Jesu jẹ́ eniyan patapata nigba ti ó gbé lori ilẹ-aye?
15 Niti tootọ, Jesu jẹ́ ẹ̀dá eniyan alailẹgbẹ kan. Ṣugbọn oun, sibẹsibẹ, ṣì jẹ́ ọkunrin kan, ti o baradọgba pẹlu Adamu, ti Ọlọrun dá ni iṣaaju ti o sì fi sinu ọgba Edeni. Apọsiteli Pọọlu ṣalaye pe: “Adamu ọkunrin iṣaaju, alaaye ọkàn ni a dá a; Adamu ikẹhin ẹmi isọni daaye.” Jesu ni a pe ni “Adamu ikẹhin” nitori, gẹgẹ bii Adamu iṣaaju, Jesu jẹ́ ẹ̀dá eniyan pipe kan. Ṣugbọn lẹhin ti Jesu kú, a jí i dide, o sì pada darapọ mọ́ Baba rẹ̀ ọrun gẹgẹ bi ẹ̀dá ẹmi kan.—1 Kọrinti 15:45.
Ọna Ti O Dara Julọ Lati Gbà Kẹkọọ Nipa Ọlọrun
16. (a) Ki ni o sọ ibakẹgbẹ pẹlu Jesu di iru anfaani kan bẹẹ? (b) Eeṣe ti a fi lè sọ pe pe rírí Jesu rí bakan naa pẹlu rírí Ọlọrun?
16 Ronu fun iṣẹju diẹ nipa anfaani agbayanu ti awọn kan gbadun lati ni ibakẹgbẹpọ ti ara ẹni pẹlu Jesu nigba ti oun wà lori ilẹ ayé! Wo araarẹ gẹgẹ bi ẹni ti o ń fetisilẹ sii, ti o ń ba a sọrọ ti o ń wò, ti o tilẹ ń ṣiṣẹ pẹlu Ẹni naa ti o ti lo boya ọpọ billion ọdun gẹgẹ bi olubakẹgbẹpọ timọtimọ pẹlu Jehofa Ọlọrun ni ọrun! Gẹgẹ bi ọmọ oloootọ kan, Jesu ṣafarawe Baba rẹ̀ ọrun ninu ohun gbogbo ti o ṣe. Niti tootọ, Jesu ṣafarawe Baba rẹ̀ lọna ti o pe perepere ti oun fi lè sọ fun awọn apọsiteli rẹ̀ ṣaaju ki a tó pa á pe: “Ẹni ti o ba ti rí mi, o ti rí Baba.” (Johanu 14:9, 10) Bẹẹni, ninu oniruuru ipo ti oun ṣalabaapade nihin-in lori ilẹ-aye, Jesu ṣe gan-an gẹgẹ bii Baba rẹ̀, Ọlọrun Olodumare, yoo ti ṣe bi ó bá jẹ́ pe Oun wà nihin-in. Nipa bẹẹ, nigba ti awa bá kẹkọọ nipa igbesi-aye ati iṣẹ-ojiṣẹ Jesu Kristi, awa, niti tootọ, ń kẹkọọ iru ẹni ti Ọlọrun jẹ́ gan-an.
17. Ète rere wo ni ọ̀wọ́ ọrọ-ẹkọ Ilé-Ìṣọ́nà ti “Igbesi-aye ati Iṣẹ-ojiṣẹ Jesu” ṣiṣẹ fun?
17 Nitori naa, kii ṣe pe ọ̀wọ́ ọrọ-ẹkọ naa “Igbesi-aye ati Iṣẹ-ojiṣẹ Jesu,” eyi ti a rí ninu awọn itẹjade Ilé-Ìṣọ́nà ti wọn tẹlera lati April 1985 si June 1991, pese apejuwe rere ti ọkunrin naa Jesu nikan, ṣugbọn o tun kọni ni ohun pupọ nipa Baba rẹ̀ ọrun, Jehofa Ọlọrun. Lẹhin ipin meji akọkọ, ojiṣẹ aṣaaju-ọna kan kọwe si Watch Tower Society pẹlu imọriri, ni sisọ pe: “Iru ọna didaraju wo ni o wà lati tubọ fà mọ Baba ju lati mọ Ọmọ daradara sii!” Ẹ wo bi eyi ti jẹ́ otitọ tó! Itọju onikẹẹ Baba fun awọn eniyan ati iwa ọlawọ rẹ̀ ni a gbega ninu igbesi-aye Ọmọkunrin rẹ̀.
18. Ta ni Olupilẹṣẹ ihin Ijọba naa, bawo sì ni Jesu ṣe jẹwọ eyi?
18 Ifẹ Jesu fun Baba rẹ̀, gẹgẹ bi o ti ṣaṣefihan rẹ̀ nipa itẹriba patapata fun ifẹ Baba rẹ̀, jẹ́ ohun ti o wuyì nitootọ lati ṣakiyesi. “Emi kò dá ohunkohun ṣe fun araami,” ni Jesu sọ fun awọn Juu ti wọn ń wa ọna lati pa á, “ṣugbọn bi Baba ti kọ́ mi, emi ń sọ nǹkan wọnyi.” (Johanu 8:28) Wayi o, nigba naa, Jesu kọ́ ni olupilẹṣẹ awọn ihin Ijọba eyi ti oun waasu rẹ̀. Jehofa Ọlọrun ni! Jesu sì fi ogo fun Baba rẹ̀ lọpọ ìgbà leralera. “Nitori emi kò dá ọrọ sọ fun araami,” ni oun sọ, “ṣugbọn Baba ti o rán mi, oun ni o ti fun mi ni aṣẹ, ohun ti emi yoo sọ, ati eyi ti emi yoo wi. . . . Nitori naa, ohun wọnni ti mo ba wi, gẹgẹ bi Baba ti sọ fun mi, bẹẹ ni mo wi.”—Johanu 12:49, 50.
19. (a) Bawo ni a ṣe mọ pe Jesu kọni ni ọna ti Jehofa ń gbà kọni? (b) Eeṣe ti Jesu fi jẹ́ ọkunrin titobilọla julọ naa ti o tii gbé ayé rí?
19 Sibẹ, Jesu kò wulẹ sọrọ tabi kọni ni ohun ti Baba rẹ̀ sọ fun un. Oun ṣe ju bẹẹ lọ. Oun sọ ọ tabi fi kọni ni ọna ti Baba rẹ̀ yoo gbà sọ ọ́ tabi fi kọni. Ju bẹẹ lọ, ninu gbogbo igbokegbodo ati ibaṣepọ rẹ̀, oun huwa ó sì ṣe gan-an gẹgẹ bi Baba rẹ̀ yoo ti huwa ti yoo sì ṣe labẹ iru awọn ipo kan naa. “Ọmọ [“Ọmọkunrin,” NW] kò lè ṣe ohunkohun fun araarẹ,” ni Jesu ṣalaye, “bikoṣe ohun ti o bá ri pe Baba ń ṣe: nitori ohunkohun ti Ó ba ń ṣe, wọnyi ni ọmọ [“Ọmọkunrin,” NW] sì ń ṣe bẹẹ gẹgẹ.” (Johanu 5:19) Ni gbogbo ọna, Jesu jẹ́ aworan pipe ti Baba rẹ̀, Jehofa Ọlọrun. Nitori naa kò yanilẹnu pe Jesu ni ọkunrin titobilọla julọ ti o tii gbé ayé rí! Dajudaju, nigba naa, ó jẹ́ ohun ti o ṣe pataki gidi pe ki a gbé ọkunrin titayọlọla julọ yii yẹwo kínníkínní!
Ifẹ Ọlọrun Ni A Rí Ninu Jesu
20. Bawo ni apọsiteli Johanu ṣe mọ pe “Ọlọrun jẹ́ ifẹ”?
20 Ni pataki ki ni awa rí kọ́ nipa ikẹkọọ jijinlẹ, ti a fi iṣọra ṣe nipa igbesi-aye ati iṣẹ-ojiṣẹ Jesu? Ó dara, apọsiteli Johanu jẹwọ pe “kò sí ẹni ti o rí Ọlọrun rí.” (Johanu 1:18) Ṣugbọn, Johanu kọwe pẹlu idaniloju hán-únhán-ún ninu 1 Johanu 4:8 (NW) pe: “Ọlọrun jẹ́ ifẹ.” Johanu lè sọ eyi nitori pe oun mọ ifẹ Ọlọrun nipasẹ ohun ti o ti rí ninu Jesu.
21. Ki ni nipa Jesu ni o sọ ọ́ di ọkunrin titobilọla julọ naa ti ó tíì gbé ayé rí?
21 Gẹgẹ bi Baba, Jesu jẹ́ oníyọ̀ọ́nú, aláàánú, onirẹlẹ, ati ẹni ti o ṣee sunmọ. Awọn alailera ati awọn ti a jẹgaba lé lori ni imọlara ifọkanbalẹ pẹlu rẹ̀, gẹgẹ bi oniruuru awọn eniyan ti ṣe—ọkunrin, obinrin, ọmọde, awọn ọlọ́rọ̀, awọn talaka, awọn sàràkí, ati awọn ẹlẹṣẹ ti a mọ̀ bi ẹni mowo pẹlu. Loootọ, ni pataki ni o jẹ pe apẹẹrẹ ifẹ titayọ ti Jesu, ni ifarawe Baba rẹ̀, ni o mu ki o jẹ́ ọkunrin titobilọla julọ ti o tíì gbé ayé rí. Koda irohin fihan pe Napoléon Bonaparte sọ pe: “Alexander, Caesar, Charlemagne, ati emi funraami tẹ ilẹ ọba dó, ṣugbọn lori ki ni awa mu iṣẹda ara ọtọ wa sinmi le? Lori lilo ipá. Jesu Kristi nikan ni o dá ijọba rẹ̀ silẹ lori ifẹ, ati titi di ọjọ oni ẹgbẹẹgbẹrun awọn eniyan ni yoo fẹ lati kú nitori rẹ̀.”
22. Ki ni o mú iyipada pataki wá ninu awọn ikọni Jesu?
22 Awọn ẹkọ Jesu jẹ́ eyi ti o mú iyipada pataki wá. “Ẹ maṣe kọ ibi,” ni Jesu rọni, “ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba gbá ọ́ ni ẹ̀rẹ̀kẹ́ ọtun, yi ti òsì si i pẹlu.” “Ẹ fẹ́ awọn ọta yin, ẹ súre fun awọn ẹni ti o ń fi yin ré.” ‘Ṣe sí ẹlomiran gẹgẹ bi iwọ ti ń fẹ́ ki wọn ṣe si ọ.’ (Matiu 5:39, 44; 7:12, NW) Bawo ni ayé ìbá ti yatọ tó ki a ni gbogbo eniyan lè fi awọn ẹkọ gigalọla wọnyi silo!
23. Ki ni Jesu ṣe lati wọni lọkan ki o sì sún awọn eniyan lati ṣe rere?
23 Awọn àkàwé, tabi awọn apejuwe, Jesu jẹ́ eyi ti o wọni lọkan ṣinṣin, ti o ń sun awọn eniyan ṣiṣẹ lati ṣe rere ati lati yẹra fun ibi. Iwọ lè ranti ìtàn rẹ̀ gbigbajumọ nipa ara Samaria ti a kẹgan, ẹni ti o ṣeranlọwọ fun ọkunrin kan ti a ṣeleṣe ti o ti inu ẹ̀yà miiran wá nigba ti awọn ọkunrin onisin ti ẹ̀yà ọkunrin naa kò ṣe bẹẹ. Tabi ti àkàwé baba oníyọ̀ọ́nú, oludarijini kan ati ọmọkunrin rẹ̀ onínàákúnàá. Ki sì ni nipa ti ìtàn ọba naa ti o fi gbese 60 million owo idẹ ji ẹrú kan, sibẹ ti ẹrú naa yipada ti o sì sọ ẹrú ẹlẹgbẹ rẹ̀ kan sinu tubu nitori àìlèsan gbese kiki 100 owo idẹ? Pẹlu awọn apejuwe rirọrun, Jesu sọ awọn iwa onimọtara-ẹni-nikan ati ọkanjuwa di ohun akóninírìíra ti o sì mu ki awọn iṣe ifẹ ati aanu di eyi ti o fanimọra tobẹẹ!—Matiu 18:23-35; Luuku 10:30-37; 15:11-32.
24. Eeṣe ti a fi lè sọ pe Jesu ni ọkunrin titobilọla julọ ti o tii gbé ayé rí laiṣiyemeji?
24 Bi o ti wu ki o ri, ohun pataki ti o fa awọn eniyan mọ Jesu ti o sì nipa lori wọn fun rere ni pe igbesi-aye rẹ̀ ṣe deedee delẹdelẹ pẹlu ohun ti o fi kọni. O fi ohun ti o kọni ṣèwàhù. Oun fi suuru farada àléébù awọn ẹlomiran. Nigba ti awọn ọmọlẹhin rẹ̀ ni aáwọ̀ laaarin araawọn nipa ẹni ti o tobi ju, oun fi inurere tọ́ wọn sọna dipo bíbá wọn wí lọna lilekoko. Oun fi irẹlẹ bojuto awọn aini wọn, o tilẹ fọ ẹsẹ wọn paapaa. (Maaku 9:30-37; 10:35-45; Luuku 22:24-27; Johanu 13:5) Nikẹhin, oun jọwọ araarẹ silẹ lati kú ikú oró, kii ṣe nitori tiwọn nikan ni, ṣugbọn nititori gbogbo ìran eniyan! Laisi iyemeji, Jesu ni ọkunrin titobilọla julọ ti o tii gbé ayé rí.
Bawo ni Iwọ Yoo Ṣe Dahun?
◻ Ẹ̀rí wo ni ó wà nibẹ pe Jesu jẹ́ ẹni gidi kan ninu ìtàn?
◻ Bawo ni a ṣe mọ pe Jesu jẹ́ ọkunrin kan, sibẹ bawo ni ó ṣe yatọ si gbogbo awọn ọkunrin miiran?
◻ Eeṣe ti kikẹkọọ igbesi-aye Jesu fi jẹ́ ọna didara julọ lati kẹkọọ nipa Ọlọrun?
◻ Ki ni a lè kẹkọọ nipa ifẹ Ọlọrun ni kikẹkọọ nipa Jesu?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]
Awọn apọsiteli Jesu ṣe kayefi pẹlu iyanu: “Ta ni eyi niti gidi?”