Iwọ Yoo Ha Dahun Pada Si Ifẹ Jesu Bi?
“Ifẹ ti Kristi ni ń fi ọranyan mú wa.”—2 KỌRINTI 5:14, NW.
1. Bawo ni a ṣe lè ṣapejuwe ifẹ Jesu?
LOOOTỌ, ifẹ Jesu ti jẹ́ agbayanu tó! Nigba ti a bá gbé bi oun ti jiya lọna ti kò ṣee ṣapejuwe yẹwo bi o ti pese irapada naa, eyi ti o jẹ pe nipasẹ rẹ̀ nikanṣoṣo ni a lè jere ìyè ainipẹkun, dajudaju ọkan-aya wa ni a ru soke pẹlu imọriri fun un! Jehofa Ọlọrun ati Jesu funraarẹ lo idanuṣe. Wọn kọkọ nifẹẹ wa, nigba ti a jẹ́ ẹlẹṣẹ sibẹ. (Roomu 5:6-8; 1 Johanu 4:9-11) Mímọ “ifẹ Kristi,” ni apọsiteli Pọọlu kọwe, “ta imọ yọ.” (Efesu 3:19) Nitootọ, ifẹ Jesu tayọ rekọja imọ ori ti ẹkọ iwe. O ga rekọja ohun ti ẹ̀dá eniyan tíì rí tabi ni iriri rẹ̀ rí.
2. Ki ni kò lè fa Jesu sẹhin kuro ninu ninifẹẹ wa?
2 Ni kikọwe si awọn Kristẹni ni Roomu, Pọọlu beere pe: “Ta ni yoo ha yà wá kuro ninu ifẹ Kristi? Ipọnju ni, tabi wahala, tabi inunibini, tabi ìyàn, tabi ihoho, tabi ewu, tabi idà?” Kò si ọkankan ninu iru awọn nǹkan bẹẹ ti o lè fa Jesu sẹhin kuro ninu ninifẹẹ wa. Pọọlu ń baa lọ pe, “ó dá mi loju pe, kii ṣe ikú, tabi ìyè, tabi awọn angẹli, tabi awọn ijoye, tabi awọn alagbara, tabi ohun igba isinsinyi, tabi ohun igba ti ń bọ, tabi òkè, tabi, ọgbun, tabi ẹ̀dá miiran kan ni yoo lè yà wá kuro ninu ifẹ Ọlọrun, ti o wà ninu Kristi Jesu Oluwa wa.”—Roomu 8:35-39.
3. Kìki ohun wo ni o lè mu ki Jesu ati Baba rẹ̀ fi wa silẹ?
3 Bi ifẹ Jehofa Ọlọrun ati ti Jesu Kristi fun ọ ṣe lagbara tó niyẹn. Ohun kanṣoṣo ni ó lè da wọn duro kuro ninu ninifẹẹ rẹ, iyẹn sì jẹ́ mímọ̀ọ́mọ̀ kọ ifẹ wọn silẹ niha ọdọ tirẹ nipa kíkọ̀ lati ṣe ohun ti wọn beere. Wolii Ọlọrun kan nigbakan rí ṣalaye fun ọba Judia kan pe: “Jehofa wà pẹlu rẹ̀ niwọn igba ti iwọ ba ti fẹ̀rí han lati wà pẹlu rẹ̀; bi iwọ bá si wá a kiri, oun yoo jẹ́ ki iwọ ri oun, ṣugbọn bi iwọ bá fi i silẹ oun yoo fi ọ́ silẹ.” (2 Kironika 15:2, NW) Ta ni ninu wa ni yoo fẹ lati yipada kuro lọdọ iru awọn ọrẹ agbayanu, oníyọ̀ọ́nú bii Jehofa ati Ọmọkunrin rẹ̀, Jesu Kristi?
Idahunpada Titọna Si Ifẹ Jesu
4, 5. (a) Bawo ni ifẹ Jesu fun wa ṣe nilati nipa lori ipo ibatan wa pẹlu awọn eniyan ẹlẹgbẹ wa? (b) Ta tún ni a gbọdọ sún wa lati nifẹẹ nitori ifẹ Jesu fun wa?
4 Bawo ni ifẹ aláìláàlà Jesu fun ọ ṣe nipa lori rẹ gẹgẹ bi ẹnikan? Bawo ni o ṣe ti nilati nipa lori rẹ? Ó dara, Jesu fi bi aṣefihan ifẹ rẹ̀ ṣe nilati nipa lori ibaṣepọ wa pẹlu awọn eniyan ẹlẹgbẹ wa han. Lẹhin fifi tirẹlẹtirẹlẹ ṣiṣẹsin awọn apọsiteli rẹ̀ nipa wiwẹ ẹsẹ wọn, Jesu wi pe: “Mo ti fi apẹẹrẹ fun yin, ki ẹyin ki o lè maa ṣe gẹgẹ bi mo ti ṣe si yin.” Ó fikun un pe: “Ofin titun kan mo fifun yin, ki ẹyin ki o fẹ́ ọmọnikeji yin; gẹgẹ bi emi ti fẹran yin, ki ẹyin ki o sì lè fẹran ọmọnikeji yin.” (Johanu 13:15, 34) Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ kẹkọọ, a sì sún wọn lati gbiyanju lati ṣe gẹgẹ bi oun ti ṣe. “Nipa eyi ni awa mọ ifẹ,” ni apọsiteli Johanu kọwe, “nitori ti o fi ẹmi rẹ̀ lélẹ̀ fun wa: ó sì yẹ ki awa fi ẹmi wa lélẹ̀ fun awọn ará.”—1 Johanu 3:16.
5 Sibẹ, awa yoo padanu ète igbesi-aye ati iṣẹ-ojiṣẹ Jesu bi o bá jẹ́ pe kiki lati ṣiṣẹ sin ire awọn eniyan ẹlẹgbẹ wa ni apẹẹrẹ rẹ̀ sún wa lati ṣe. Kò ha yẹ ki ifẹ Jesu fun wa sún wa pẹlu lati fẹran rẹ̀ pada ati ni pataki lati fẹran Baba rẹ̀, ẹni ti ó kọ́ ọ ni ohun gbogbo ti ó mọ̀ bi? Iwọ yoo ha dahunpada si ifẹ Kristi ki o sì ṣiṣẹsin Baba rẹ̀ gẹgẹ bi oun ti ṣe bi?—Efesu 5:1, 2; 1 Peteru 1:8, 9.
6. Bawo ni a ṣe nipa lori apọsiteli Pọọlu nipa ifẹ Jesu fun un?
6 Gbé ọran ti Sọọlu, ẹni ti a mọ̀ sí Pọọlu lẹhin naa yẹwo. Ni akoko kan ó ṣenunibini si Jesu, “[ó] ń mi ẹmi ikilọ ati pipa sibẹ si awọn ọmọ ẹhin.” (Iṣe 9:1-5; Matiu 25:37-40) Nigba ti Pọọlu wá mọ Jesu niti gidi, oun kún fun imoore fun riri idariji gbà debi pe oun kò muratan lati jiya nititori Jesu nikan ṣugbọn ó tun ṣetan lati kú fun un. “A ti kan mi mọ igi pẹlu Kristi,” ni oun kọwe. “Kìí ṣe emi ni mo tun walaaye mọ́ . . . Nitootọ, wiwalaaye ti mo walaaye ninu ẹran ara nisinsinyi mo walaaye nipa igbagbọ ninu Ọmọkunrin Ọlọrun, ẹni ti o nifẹẹ mi ti o sì fi araarẹ lélẹ̀ fun mi.”—Galatia 2:20, NW.
7. Ki ni ifẹ Jesu gbọdọ sọ ọ́ di ọranyan fun wa lati ṣe?
7 Bawo ni ifẹ ti Jesu ni fun wa ṣe gbọdọ jẹ́ ipa asunniṣiṣẹ tó ninu igbesi-aye wa! “Ifẹ ti Kristi ní ń fi ọranyan mú wa,” ni Pọọlu kọwe si awọn ará Kọrinti, ‘lati maṣe walaaye fun araawa mọ, bikoṣe fun ẹni ti o kú fun wa ti a sì jí dide.’ (2 Kọrinti 5:14, 15, NW) Nitootọ, ìkún fun imoore si Jesu fun fifi iwalaaye rẹ̀ lélẹ̀ nititori wa nilati sún wa lati ṣe ohunkohun ti o bá beere. Kìkì ni ọna yii ni a lè fẹ̀rí han pe a fẹran rẹ̀ nitootọ. “Bi ẹyin bá fẹran mi, ẹ o pa ofin mi mọ́,” ni Jesu sọ. “Ẹni ti o ba ni ofin mi, ti o bá sì ń pa wọn mọ, oun ni ẹni ti ó fẹran mi.”—Johanu 14:15, 21; fiwe 1 Johanu 2:3-5.
8. Bawo ni ifẹ Jesu ṣe nipa lori igbesi-aye ọpọlọpọ awọn oluṣaitọ?
8 Lẹhin mímọ awọn ofin Jesu, awọn agbere, panṣaga, abẹ́yà-kannáà-lòpọ̀, ole, ọmuti, ati alọnilọwọgba ni Kọrinti igbaani dahunpada si ifẹ Jesu nipa jíjáwọ́ ninu awọn aṣa wọnni. Pọọlu kọwe nipa wọn pe: “A ti wẹ̀ yin nù, . . . a ti dá yin láre ni orukọ Jesu Kristi Oluwa [wa].” (1 Kọrinti 6:9-11) Bakan naa, ifẹ Jesu ti fi agbara sún ọpọlọpọ lonii lati ṣe awọn iyipada pipẹtẹri ninu igbesi-aye wọn. “Awọn aṣeyọri alayọ iṣẹgun ti isin Kristẹni tootọ ni a rí ninu sisọ awọn wọnni ti wọn jẹwọ igbagbọ rẹ̀ di awọn eniyan rere,” ni opitan John Lord kọwe. “A ni ẹ̀rí sí igbesi-aye alailabawọn wọn, sí iwarere aláìlábùkù wọn, sí jíjẹ́ ọlọ̀tọ̀ rere wọn, ati si awọn iwarere Kristẹni wọn.” Iru iyatọ wo ni awọn ikọni Jesu ti ṣe!
9. Ki ni fifetisilẹ si Jesu ni ninu?
9 Dajudaju, kò si ikẹkọọ kankan ti ẹni kan lè dáwọ́lé lonii ti ó ní ijẹpataki ju ti igbesi-aye ati iṣẹ-ojiṣẹ Jesu Kristi lọ. “Tẹjumọ . . . Jesu,” ni apọsiteli Pọọlu rọni. ‘Nitootọ, gbé ẹni [yẹn] yẹwo kínníkínní.’ (Heberu 12:2, 3, NW) Lakooko iyirapada Jesu, Ọlọrun funraarẹ paṣẹ nipa Ọmọkunrin rẹ̀ pe: “Ẹ fetisilẹ sii.” (Matiu 17:5, NW) Bi o ti wu ki o ri, a gbọdọ tẹnumọ ọn pe, fifetisilẹ si Jesu ni ninu ju wiwulẹ gbọ́ ohun ti o sọ lọ. Ó tumọ si kikọbiara si awọn itọni rẹ̀, bẹẹni, fifarawe e nipa ṣiṣe ohun ti o ṣe ni ọ̀nà ti ó gbà ṣe é. A dahunpada si ifẹ Jesu nipa gbigba a gẹgẹ bi awokọṣe wa, ni titẹle awọn ipasẹ rẹ̀ timọtimọ.
Ohun Ti Jesu Fẹ Ki A Ṣe
10. Awọn wo ni Jesu dalẹkọọ ati fun ète wo?
10 Aṣẹ Jesu lati ọdọ Ọlọrun ni lati waasu nipa Ijọba Baba rẹ̀, ó sì dá awọn ọmọlẹhin rẹ̀ lẹkọọ lati ṣe iṣẹ kan naa. “Ẹ jẹ ki a lọ si ilu miiran,” ni o sọ fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ akọkọ, “ki emi ki o lè waasu nibẹ pẹlu: nitori eyi ni emi sa ṣe wá.” (Maaku 1:38; Luuku 4:43) Nigba ti o yá, lẹhin dida awọn apọsiteli 12 lẹkọọ lọna ti ó gbòòrò, Jesu fun wọn ni itọni pe: “Bi ẹyin ti ń lọ, ẹ maa waasu, wi pe, Ijọba ọrun kù sí dẹ̀dẹ̀.” (Matiu 10:7) Oṣu diẹ lẹhin naa, lẹhin dídá awọn 70 miiran lẹkọọ, ó rán wọn jade pẹlu aṣẹ naa pe: “Ẹ . . . wí fun wọn pe, Ijọba Ọlọrun kù dẹ̀dẹ̀ si yin.” (Luuku 10:9) Ni kedere, Jesu fẹ́ ki awọn ọmọlẹhin rẹ̀ jẹ́ oniwaasu ati olukọni.
11. (a) Ni ọna wo ni awọn ọmọ-ẹhin Jesu gbà ṣe awọn iṣẹ titobi ju eyi ti ó ṣe lọ? (b) Ki ni o ṣẹlẹ si awọn ọmọ-ẹhin lẹhin ti wọn pa Jesu?
11 Jesu ń ba dídá awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ lẹkọọ fun iṣẹ yii lọ. Ni alẹ́ ti ó kẹhin ṣaaju iku rẹ̀, o fun wọn niṣiiri pẹlu awọn ọrọ naa: “Ẹni ti ó ba gbà mi gbọ́, iṣẹ ti emi ń ṣe ni oun naa yoo ṣe pẹlu; iṣẹ ti o tobi ju wọnyi lọ ni yoo sì ṣe.” (Johanu 14:12) Iṣẹ awọn ọmọlẹhin rẹ̀ yoo pọ ju tirẹ nitori pe ninu iṣẹ-ojiṣẹ wọn wọn yoo dé ọdọ awọn eniyan pupọ pupọ sii la agbegbe gbigbooro sii já ati fun iwọn akoko gigun sii. Sibẹ, lẹhin ti wọn pa Jesu, awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ ni a rọ lọ́wọ́ nitori ibẹru. Wọn bẹrẹ sii sapamọ wọn kò sì bá isẹ naa ti ó ti dá wọn lẹkọọ lati ṣe lọ. Awọn kan tilẹ pada sidii iṣẹ ẹja pipa. Bi o ti wu ki o ri, ni ọna ti kò ṣee gbagbe, ó tẹ̀ ẹ́ mọ awọn meje wọnyi lọkan ohun ti ó fẹ ki awọn, ati gbogbo awọn ọmọlẹhin rẹ̀ bakan naa, ṣe.
12. (a) Iṣẹ iyanu wo ni Jesu ṣe leti Okun Galili? (b) Lọna ti o han gbangba, ki ni Jesu ni lọkan nigba ti o beere lọwọ Peteru yala ó nifẹẹ Oun “ju awọn wọnyi lọ”?
12 Jesu gbe ara eniyan wọ̀ ó sì farahan ni eti Okun Galili. Awọn apọsiteli meje wà ninu ọkọ oju-omi ṣugbọn wọn kò tii ri ẹja eyikeyii mú ní gbogbo òru. Jesu kigbe lati etikun wá pe: “Ẹ sọ àwọ̀n si apa ọ̀tún ọkọ̀, ẹyin yoo sì rí.” Nigba ti ẹja kún inu àwọ̀n naa lọna agbayanu dori fífàjá, awọn wọnni ti wọn wà ninu ọkọ̀ mọ pe Jesu ni ó wà lori ebute, wọn sì yára lọ si ibi ti ó duro si. Lẹhin pipese ounjẹ aarọ fun wọn, Jesu, ti ó ṣeeṣe ki ó maa wo ẹja pupọ rẹpẹtẹ ti a kó naa, beere lọwọ Peteru pe: “Simoni, ọmọ Jona, iwọ fẹ́ mi ju awọn wọnyi lọ bi?” (Johanu 21:1-15) Jesu laiṣiyemeji ni i lọkan pe, Iwọ ha ni isopọ mọ iṣẹ ẹja pipa ju iṣẹ iwaasu ti mo ti mura rẹ silẹ lati ṣe bi?
13. Bawo ni Jesu ṣe tẹ̀ ọna ti awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ gbọdọ gbà dahun pada si ifẹ rẹ̀ mọ wọn lọkan lọna lilagbara?
13 Peteru dahun pada pe: “Bẹẹni Oluwa; iwọ mọ pe, mo fẹran rẹ.” Jesu dahun pe: “Maa bọ́ awọn agutan mi.” Ni igba keji Jesu beere pe: “Simoni ọmọ Jona iwọ fẹ́ mi bi?” Lẹẹkan sii Peteru dahun pada, laiṣiyemeji pẹlu idaniloju lilagbara sii pe: “Bẹẹni Oluwa; iwọ mọ pe, mo fẹran rẹ.” Lẹẹkan sii Jesu paṣẹ pe: “Maa bọ́ awọn agutan mi.” Ni igba kẹta Jesu beere pe: “Simoni, ọmọ Jona, iwọ fẹran mi bi?” Nisinsinyi Peteru banujẹ. Kiki iwọnba ọjọ diẹ ṣaaju, oun ti sẹ́ mímọ Jesu lẹẹmẹta, nitori naa oun lè ti ṣe kayefi bakan naa yala Jesu ṣiyemeji nipa iduroṣinṣin rẹ̀. Nitori naa, fun igba kẹta, Peteru dahunpada, boya pẹlu ìró ohun ẹlẹ́bẹ̀ pe: “Oluwa, iwọ mọ ohun gbogbo; iwọ mọ pe, mo fẹran rẹ.” Jesu wulẹ dahun pe: “Maa bọ́ awọn agutan mi.” (Johanu 21:15-17) Iyemeji kankan ha lè wà niti ohun ti Jesu fẹ́ ki Peteru ati awọn alabaakẹgbẹ rẹ̀ ṣe bi? Ẹ wo bi oun ti tẹ̀ ẹ́ mọ́ wọn lọkan—ati mọ ẹnikẹni ti yoo di ọmọ-ẹhin rẹ̀ lonii lọkan pinpin tó—pe bi wọn ba nifẹẹ oun, wọn yoo ṣajọpin ninu iṣẹ sisọni di ọmọ-ẹhin!
14. Ni awọn akoko miiran, bawo ni Jesu ṣe fi ọna ti awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ gbọdọ gbà dahun pada si ifẹ rẹ̀ han?
14 Ni iwọnba ọjọ diẹ lẹhin ijumọsọrọpọ etikun yẹn, Jesu farahan lori oke kan ni Galili ó sì fun apejọpọ alayọ ti o tó 500 awọn ọmọlẹhin ni itọni pe: “Nitori naa ẹ lọ ki ẹ sì sọ awọn eniyan gbogbo orilẹ-ede di ọmọ-ẹhin, . . . ki ẹ maa kọ́ wọn lati kiyesi ohun gbogbo ti mo ti palaṣẹ fun yin.” (Matiu 28:19, 20, NW; 1 Kọrinti 15:6) Ronu nipa rẹ̀ ná! Awọn ọkunrin, obinrin, ati ọmọde gbogbo wọn gba aṣẹ kan naa yii. Sibẹ lẹhin naa, ṣaaju ki o tó goke lọ si ọrun, Jesu sọ fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe: “Ẹ o maa ṣe ẹlẹ́rìí mi . . . titi de opin ilẹ-aye.” (Iṣe 1:8) Lẹhin gbogbo iṣinileti yii, kò yanilẹnu ti Peteru, ni ọpọ ọdun lẹhin naa, fi sọ pe: “[Jesu] sì paṣẹ fun wa lati waasu fun awọn eniyan, ati lati jẹrii.”—Iṣe 10:42.
15. Nipa ki ni kò lè si iyemeji?
15 Kò lè si iyemeji niti bi a ṣe nilati dahunpada si ifẹ Jesu. Gẹgẹ bi o ti sọ fun awọn apọsiteli rẹ̀: “Bi ẹyin bá pa ofin mi mọ́, ẹ o duro ninu ifẹ mi . . . Ọrẹ mi ni ẹyin iṣe, bi ẹ bá ṣe ohun ti emi palaṣẹ fun yin.” (Johanu 15:10-14) Ibeere naa ni pe, Iwọ yoo ha fi imọriri han fun ifẹ Jesu nipa ṣiṣegbọran si aṣẹ rẹ̀ lati ṣajọpin ninu iṣẹ sisọni di ọmọ-ẹhin? Loootọ, eyi lè má rọrun fun ọ nitori oniruuru idi. Ṣugbọn kò rọrun fun Jesu pẹlu. Gbé awọn iyipada ti a beere fun niha ọdọ rẹ̀ yẹwo.
Tẹle Apẹẹrẹ Jesu
16. Apẹẹrẹ agbayanu wo ni Jesu pese?
16 Ọmọkunrin bibi-kanṣoṣo ti Ọlọrun gbadun ipo gigalọla julọ ti ogo ti ọrun ti ó tayọ ti gbogbo awọn angẹli. Oun jẹ́ ọlọ́rọ̀ nitootọ! Sibẹ oun fi imuratan sọ araarẹ dòfo, a bí i gẹgẹ bi mẹmba idile òtòṣì kan, ó sì dagba laaarin awọn eniyan ti ń ṣaisan, ti ń kú. Ó ṣe eyi nititori wa, gẹgẹ bi apọsiteli Pọọlu ti ṣalaye: “Nitori ẹyin mọ oore ọfẹ Oluwa wa Jesu Kristi, pe bi oun ti jẹ́ ọlọ́rọ̀ rí, ṣugbọn nitori yin o di talaka, ki a lè sọ yin di ọlọ́rọ̀ nipa aini rẹ̀.” (2 Kọrinti 8:9; Filipi 2:5-8) Iru apẹẹrẹ wo ni eyi! Iru aṣefihan ifẹ wo sì ni ó jẹ́! Kò si ẹnikẹni ti o tíì fi ohun pupọ bẹẹ silẹ tabi jiya ohun pupọ nititori awọn ẹlomiran bẹẹ rí. Kò sì sí ẹni ti o tíì mu ki o ṣeeṣe fun awọn ẹlomiran lati gbadun ọrọ̀ ti o tobi ju, bẹẹni, ìyè ainipẹkun ninu ìjẹ́pípé!
17. Ipa-ọna wo ni a gbekalẹ si iwaju wa, ki ni yoo sì jẹ abajade titẹle e?
17 A lè tẹle apẹẹrẹ Jesu ki a sì jẹ́ iru anfaani kan naa fun awọn miiran. Leralera, Jesu rọ awọn eniyan lati di ọmọlẹhin rẹ̀. (Maaku 2:14; Luuku 9:59; 18:22) Ni tootọ, Peteru kọwe pe: “Nitori inu eyi ni a pe yin sí: nitori Kristi pẹlu jiya fun yin, o fi apẹẹrẹ silẹ fun yin, ki ẹyin ki o lè maa tọ ipasẹ rẹ̀.” (1 Peteru 2:21) Iwọ yoo ha dahun pada si ifẹ Kristi dé iwọn jijiya ki o ba lè ṣiṣẹsin Baba rẹ̀ gẹgẹ bi oun ti ṣe bi? Iru ipa-ọna bẹẹ ti ṣanfaani tó! Nitootọ, nipa titẹle apẹẹrẹ Jesu, nipa fifi awọn ẹkọ ti ó gbà lati ọdọ Baba rẹ̀ silo ni kikun, “iwọ yoo gba araarẹ ati awọn ti ń gbọ ọrọ rẹ là.”—1 Timoti 4:16.
18. (a) Apẹẹrẹ wo ni Jesu gbekalẹ niti iṣarasihuwa rẹ̀ si awọn eniyan? (b) Bawo ni awọn eniyan ṣe dahunpada si animọ Jesu?
18 Lati ran awọn eniyan lọwọ julọ, a gbọdọ tun nimọlara gẹgẹ bi Jesu ti ṣe nipa wọn. Asọtẹlẹ kan sọ nipa rẹ̀ pe: “Oun yoo dá talaka ati alaini sí.” (Saamu 72:13) Awọn ọmọlẹhin rẹ lè ṣakiyesi pe Jesu “nimọlara ifẹ” fun awọn wọnni ti oun ń ba sọrọ ati pe oun nitootọ fẹ́ lati ran wọn lọwọ. (Maaku 1:40-42; 10:21, NW) “Nigba ti o ri ọpọ eniyan,” ni Bibeli sọ, “aanu wọn ṣe e, nitori ti àárẹ̀ mu wọn, wọn sì tuka kiri bi awọn agutan ti kò ni oluṣọ.” (Matiu 9:36) Ani awọn ẹlẹṣẹ wiwuwo paapaa nimọlara ifẹ rẹ̀ a sì fà wọn sunmọ ọn. Nipa ìró ohùn rẹ̀, irisi, ati ọna ìgbàkọ́ni rẹ̀, a fara wọn balẹ̀. Gẹgẹ bi iyọrisi, ani awọn agbowo-ode ti a kò kàsí ati awọn kárùwà jade wá a lọ.—Matiu 9:9-13; Luuku 7:36-38; 19:1-10.
19. Bawo ni Pọọlu ṣe ṣafarawe Jesu, ki ni iyọrisi rẹ̀ yoo sì jẹ́ ti awa pẹlu bá ṣe ohun kan naa?
19 Awọn ọmọ-ẹhin Jesu ni ọrundun kìn-ín-ní ṣafarawe apẹẹrẹ onifẹẹ rẹ̀. Pọọlu kọwe si awọn diẹ ti oun ṣeranṣẹ fun pe: “Awa di ẹni pẹ̀lẹ́ laaarin yin, gẹgẹ bi ìgbà ti abiyamọ ń ṣìkẹ́ awọn ọmọ tirẹ funraarẹ . . . Gẹgẹ bi baba ti ń ṣe si awọn ọmọ rẹ̀, a ń baa lọ ni gbígba olukuluku yin niyanju, a sì ń tù yin ninu a sì ń jẹrii fun yin.” (1 Tẹsalonika 2:7-11, NW) Iwọ ha nimọlara ojulowo idaniyan kan naa tí awọn obi onifẹẹ ní fun awọn ọmọ wọn olùfẹ́ ọwọn fun awọn wọnni ti wọn wà ni ipinlẹ rẹ bi? Fifi iru idaniyan bẹẹ han ninu ìró ohùn rẹ, irisi oju rẹ, ati awọn iṣe rẹ yoo mu ki ihin-iṣẹ Ijọba naa fa awọn ẹni bi agutan mọra.
20, 21. Ki ni awọn apẹẹrẹ diẹ ti awọn eniyan ode oni ti wọn tẹle apẹẹrẹ Jesu ti ifẹ?
20 Ni ọjọ olótùútù kan ni Spain, Awọn Ẹlẹ́rìí meji pade obinrin agbalagba kan ti ń fi ọ̀pá ìkásẹ̀lé rìn ti ile rẹ̀ tutù rinrin nitori pe igi idana ti jó tán. Ó ń duro de ọmọkunrin rẹ̀ lati dé lati ibi iṣẹ ki ó sì wá gé igi sii. Awọn Ẹlẹ́rìí naa gé igi naa, wọn sì fi iwe irohin silẹ fun un lati kà. Nigba ti ọmọkunrin rẹ̀ dé, idaniyan onifẹẹ Awọn Ẹlẹ́rìí naa fun ìyá rẹ̀ wú u lori gidigidi debi pe o ka iwe ikẹkọọ naa, ó bẹrẹ sii kẹkọọ Bibeli, a bamtisi rẹ, ati laipẹ ó kówọnú iṣẹ-ojiṣẹ aṣaaju-ọna.
21 Ni Australia ọkunrin kan ati aya rẹ̀ ṣalaye fun Awọn Ẹlẹ́rìí kan ti ń ṣebẹwo pe awọn kò lówó lati fi bọ́ idile wọn. Tọkọtaya Ẹlẹ́rìí naa lọ wọn sì ra awọn èèlò ounjẹ diẹ, ati súùtì fun awọn ọmọ wọn. Awọn obi naa búsígbe, ni wiwi pe awọn ṣalaini gan-an debi pe awọn ti gbèrò ipa-ara-ẹni. Awọn mejeeji bẹrẹ sii kẹkọọ Bibeli, aya naa ni a sì bamtisi lẹnu aipẹ yii. Obinrin kan ni United States ti o ni ẹ̀tanú si Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa rohin lẹhin ipade kan pe: “Emi kò ranti ohun ti a sọrọ lé lori niti gidi, ṣugbọn ohun ti mo ranti ni bi o ti jẹ oninuure sí mi tó, ati bi o ti jẹ́ ẹlẹmii alejo ṣiṣe ati onirẹlẹ tó. Mo nimọlara pe a fà mi sunmọ ọn gẹgẹ bi ẹnikan. Mo ṣìkẹ́ ibalo rẹ titi di oni yii.”
22. Lẹhin ṣiṣayẹwo igbesi-aye Jesu, ki ni ipari ero wa nipa rẹ̀?
22 Nigba ti a ba dahun pada si ifẹ Jesu nipa ṣiṣe iṣẹ ti ó ṣe ni ọna ti ó gbà ṣe é, iru awọn ibukun agbayanu wo ni a lè gbadun! Ìtóbilọ́lá Jesu ni o ṣe kedere ti o sì ga pupọpupọ. A sún wa lati tun awọn ọrọ gomina ara Roomu naa Pọntu Pilatu sọ pe: “Ẹ wò ó! Ọkunrin naa!” Bẹẹ ni, nitootọ, “Ọkunrin naa,” ọkunrin titobilọla julọ naa ti o tii gbé ayé rí.—Johanu 19:5, NW.
Bawo ni Iwọ Yoo Ṣe Dahun?
◻ Bawo ni ifẹ Jesu ti tobi tó?
◻ Ta ni ifẹ Jesu gbọdọ sun wa lati nifẹẹ sí, ki sì ni ifẹ rẹ̀ gbọdọ mú ki a ṣe?
◻ Iṣẹ wo ni Jesu fẹ́ ki a ṣe?
◻ Bawo ni Jesu ṣe jẹ́ ọlọ́rọ̀, eesitiṣe ti o fi di òtòṣì?
◻ Bawo ni a ṣe gbọdọ ṣafarawe Jesu ni ọna ti o gbà ṣeranṣẹ fun awọn eniyan?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Jesu fi àwòkọ́ṣe ti fifi ifẹ han lélẹ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Jesu ṣapejuwe lọna lilagbara bi awọn ọmọ-ẹhin oun ṣe gbọdọ fi ifẹ han fun oun tó