Ẹ Jí Kalẹ Ni “Akoko Opin”
“Ẹ maa ṣọna, ẹ jí kalẹ, nitori ẹyin kò mọ ìgbà ti akoko ti a yankalẹ jẹ́.”—MAAKU 13:33, NW.
1. Bawo ni a ṣe gbọdọ huwa pada bi awọn iṣẹlẹ ti ń runi soke ti ń di mímọ̀ ni “akoko opin” yii?
BI AWỌN iṣẹlẹ tí ń runi soke ti ń farahan ni “akoko opin” yii, bawo ni awọn Kristẹni ṣe gbọdọ huwa pada? (Daniẹli 12:4) A kò fi wọn silẹ sinu iyemeji. Jesu Kristi sọ asọtẹlẹ naa ti ó ni àmì alápá pupọ ninu ti ó sì ti ń ní imuṣẹ ni ọrundun lọna 20 yii. Ó sọ asọtẹlẹ ọpọ awọn ami hihan gbangba ti ó ti sàmì sí sáà akoko yii lati 1914 wá gẹgẹ bi eyi ti kò lẹ́gbẹ́. Niwọnbi o ti mọ nipa asọtẹlẹ Daniẹli nipa “akoko opin,” Jesu tẹsiwaju nipa asọtẹlẹ ńlá tirẹ nipa rirọ awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ lati “jí kalẹ.”—Luuku 21:36, NW.
2. Eeṣe ti aini ńláńlá lati jí kalẹ nipa tẹmi fi wa?
2 Eeṣe ti a fi nilati jí kalẹ? Nitori pe akoko ti ó lewu julọ niyii ninu ìtàn eniyan. Fun awọn Kristẹni lati faaye silẹ fun òògbé tẹmi ni akoko yii yoo kún fun jàm̀bá. Bi a bá di atẹ́ra-ẹni lọ́rùn tabi jẹ ki ọkan-aya wa di eyi ti a dẹ́rù pa pẹlu awọn aniyan igbesi-aye, awa yoo wà ninu ewu. Ni Luuku 21:34, 35 (NW), Jesu Kristi kilọ fun wa pe: “Ẹ maa kiyesi araayin ki ẹ maṣe fi àjẹjù ati àmujù ati awọn aniyan igbesi-aye dẹ́rùpa ọkan-aya yin, lojiji ki ọjọ yẹn sì dé bá yin lọgan gẹgẹ bi ìdẹkùn. Nitori yoo dé bá gbogbo awọn wọnni ti ń gbé ori gbogbo ilẹ̀-ayé.”
3, 4. (a) Ki ni Jesu ni lọkan nipa sisọ pe ọjọ ibinu Ọlọrun yoo dé lọgan sori awọn eniyan “gẹgẹ bi ìdẹ́kùn”? (b) Niwọn bi Ọlọrun kò ti kẹ́ ìdẹkùn, eeṣe ti ọjọ yẹn yoo fi dé bá awọn eniyan ni gbogbogboo lairotẹlẹ?
3 Pẹlu idi rere ni Jesu fi sọ pe ọjọ Jehofa yoo ‘dé lojiji lọgan gẹgẹ bi ìdẹkùn.’ Ìdẹkùn kan ni a sábà maa ń ṣe pẹlu ojóbó, a sì ń lò ó fun mímú awọn ẹyẹ ati awọn ẹran afọ́mọlọ́mú. Ìdẹkùn kan ní ohun ti a fi ń kẹ́ ẹ, ẹnikẹni ti ó bá sì rìn wọ inú rẹ́ a ré ohun ti a fi kẹ́ ẹ naa. Ìdẹkùn naa a sì ta wàì, ẹran ọdẹ ni a o sì gbámú. Lojiji gbáà ni gbogbo eyi maa ń ṣẹlẹ. Ni ọ̀nà kan naa, Jesu sọ pe, awọn alaiṣiṣẹ mọ nipa tẹmi ni ẹnu yoo yà ti “ọjọ ibinu” Ọlọrun yoo sì dé bá lojiji.—Owe 11:4.
4 Jehofa Ọlọrun ha ni ẹni naa ti ń kẹ́ ìdẹkùn silẹ fun awọn eniyan bi? Rara o, oun kò gẹ̀gùn lati mú awọn eniyan lojiji lati pa wọn run. Ṣugbọn ọjọ yẹn yoo dé bá awọn eniyan ni gbogbogboo lojiji nitori pe wọn kò fi igbeyẹwo pataki fun Ijọba Ọlọrun. Wọn mú ọ̀nà tiwọn pọ̀n ninu awọn ìlépa igbesi-aye, ní ṣiṣai fiyesi awọn iṣẹlẹ titun ti o yí wọn ká. Bi o ti wu ki o ri, eyi kò yí itolẹsẹẹsẹ Ọlọrun pada. Ó ni akoko tirẹ ti ó ti dá fun gbigbẹsan. Ati, pẹlu aanu, kò fi araye silẹ ni alaimọkan nipa idajọ rẹ̀ ti ń bọ̀.—Maaku 13:10.
5, 6. (a) Nitori idajọ tí ń bọ̀, ipese onifẹẹ wo ni Ẹlẹdaa ti ṣe fun awọn ẹ̀dá eniyan, ṣugbọn pẹlu iyọrisi gbogbogboo wo? (b) Ki ni a o gbeyẹwo lati ran wa lọwọ lati jí kalẹ?
5 Àwítẹ́lẹ̀ yii jẹ́ ipese onifẹẹ ni apa ọdọ Ẹlẹdaa atobilọla naa, ẹni ti ó nifẹẹ ọkàn ninu ire alaafia awọn ẹ̀dá eniyan nihin-in lori apoti itisẹ afiṣapẹẹrẹ rẹ̀. (Aisaya 66:1) Ó ń ṣìkẹ́ awọn olùgbé ibi ti a sọ pe ẹsẹ rẹ sinmi lé. Nitori naa nipasẹ awọn ikọ̀ ati aṣoju ikọ̀ rẹ̀ ti ilẹ̀-ayé, ó ń kilọ fun wọn nipa awọn iṣẹlẹ ti ó wà niwaju wọn. (2 Kọrinti 5:20) Sibẹ, laika gbogbo ikilọ ti a fi funni sí, awọn iṣẹlẹ wọnni yoo dé bá idile eniyan ni airotẹlẹ bi ẹni pe wọn ti tẹsẹ bọ inu ìdẹkùn kan. Eeṣe? Nitori pe ọpọ julọ awọn eniyan ń sùn nipa tẹmi. (1 Tẹsalonika 5:6) Kìkì iye táṣẹ́rẹ́ kan ni ifiwera ni o kọbiara si ikilọ naa ti wọn yoo sì la a já sinu ayé titun ti Ọlọrun.—Matiu 7:13, 14.
6 Bawo, nigba naa, ni a ṣe lè jí kalẹ ni akoko opin yii ki a baa lè kà wá mọ awọn wọnni ti a o gbala? Jehofa pese iranlọwọ ti a nilo. Ẹ jẹ ki a ṣakiyesi awọn ohun meje ti a lè ṣe.
Bá Ìpínyà-Ọkàn Jà
7. Ikilọ wo nipa ìpínyà-ọkàn ni Jesu fi funni?
7 Lakọọkọ ná, a gbọdọ bá ìpínyà-ọkàn jà. Ni Matiu 24:42, 44, Jesu sọ pe: “Nitori naa ẹ maa ṣọna; nitori ẹyin kò mọ wakati ti Oluwa yin yoo dé. Nitori naa ki ẹyin ki ó mura silẹ: nitori ni wakati ti ẹyin kò rò tẹlẹ ni Ọmọ eniyan yoo dé.” Èdè ti Jesu lò nihin-in fihan pe ni akoko lilekoko yii, ọpọlọpọ ìpínyà-ọkàn ni yoo wà, ìpínyà-ọkàn sì lè yọrisi iparun. Ni ọjọ Noa ọpọlọpọ nǹkan mú ọwọ́ awọn eniyan dí. Gẹgẹ bi iyọrisi rẹ̀, awọn eniyan ti ọkàn wọn pínyà naa “kò sì mọ̀” nipa ohun ti ó ń lọ, Ìkún-omi naa sì gbá gbogbo wọn lọ. Bakan naa, Jesu kilọ pe: “Gẹgẹ bẹẹ ni wíwá Ọmọ eniyan yoo rí pẹlu.”—Matiu 24:37-39.
8, 9. (a) Bawo ni awọn ilepa igbesi-aye lasan ṣe lè mú ki a ní ìpínyà-ọkàn? (b) Awọn ikilọ wo ni Pọọlu ati Jesu fi fun wa?
8 Fi sọkan, pẹlu, pe ninu ikilọ rẹ̀ ni Luuku 21:34, 35, Jesu ń jiroro awọn apa ẹ̀ka kan lasan ninu igbesi-aye, iru bii jíjẹ, mímu, ati awọn aniyan lori wíwá àtijẹ. Wọn jẹ́ awọn nǹkan ti ó wọ́pọ̀ fun gbogbo eniyan, papọ pẹlu awọn ọmọ-ẹhin Jesu Oluwa. (Fiwe Maaku 6:31.) Awọn nǹkan wọnyi lè jẹ́ alaile panilara funraawọn, ṣugbọn bi a bá faaye gbà wọn, wọn lè pín ọkàn wa níyà, mú ọwọ́ wa dí, kí ó sì tipa bayii fa òògbé eléwu nipa tẹmi sinu wa.
9 Nitori naa, ẹ maṣe jẹ ki a ṣàì náání ohun tí ó ni ijẹpataki giga julọ—jijere ojurere atọrunwa. Dipo jíjẹ́ ki awọn nǹkan igbesi-aye lasan gbà wá lọkan, ẹ jẹ ki a lo wọn kìkì dé ìwọ̀n ti o mọ niwọn ti a nilo lati gbé wa ró. (Filipi 3:8) Wọn kò gbọdọ fun awọn ire Ijọba pa. Gẹgẹ bi Roomu 14:17 ti wi, “ijọba Ọlọrun kì í ṣe jíjẹ ati mímu; bikoṣe ododo, ati alaafia, ati ayọ̀ ninu ẹmi mimọ.” Ranti awọn ọrọ Jesu nigba ti o wi pe: “Ẹ tètè maa wá ijọba Ọlọrun ná, ati ododo rẹ̀; gbogbo nǹkan wọnyi ni a o sì fi kun un fun yin.” (Matiu 6:33) Siwaju sii, ni Luuku 9:62, Jesu polongo pe: “Kò sí ẹni, ti o fi ọwọ́ rẹ̀ lé ohun eelo ìtúlẹ̀, ti o sì wo ẹhin, ti o yẹ fun ijọba Ọlọrun.”
10. Ewu wo ni ó wà bi a kò ba pa oju wa mọ ni wíwo gongo naa ni ọ̀kánkán sàn-án?
10 Gbàrà ti a bá ti bẹrẹ sii túlẹ̀, ní sisọrọ lọna iṣapẹẹrẹ, a gbọdọ maa bá a lọ ni oju ìlà tààrà. Ọkunrin atúlẹ̀ kan ti ó wo ẹhin ki yoo kọ pooro ebè ti ó gún régé. Ọkàn rẹ̀ ti pínyà ó sì rọrun fun awọn ohun idiwọ kan lati tì í kuro loju ọ̀nà tabi dá a duro. Ẹ maṣe jẹ ki a dabi aya Lọti, ẹni ti ó wẹhin ti kò sì dé ibi aabo. A nilati pa oju wa mọ́ ni wíwo gongo naa ní ọ̀kánkán sàn-án. Lati ṣe iyẹn a gbọdọ bá ìpínyà-ọkàn jà.—Jẹnẹsisi 19:17, 26; Luuku 17:32.
Fi Gbogbo Ìtara Ọkàn Gbadura
11. Ki ni Jesu tẹnumọ lẹhin kikilọ fun wa nipa ewu ìpínyà-ọkàn?
11 Bi o ti wu ki o ri, pupọ sii wà ti a lè ṣe lati jí kalẹ. Ohun pataki keji kan ni pe: Fi gbogbo ìtara ọkàn gbadura. Lẹhin kikilọ fun wa lodisi didi ẹni ti ọkàn rẹ̀ pínyà nipasẹ awọn ilepa igbesi-aye lasan, Jesu funni ni imọran yii: “Ẹ wà lojufo, nigba naa, ni gbogbo ìgbà ni gbigba adura ẹ̀bẹ̀ ki ẹ lè ṣe aṣeyọri ni sisala kuro ninu gbogbo nǹkan wọnyi ti a ti kádàrá lati wáyé, ati ni diduro niwaju Ọmọkunrin eniyan.”—Luuku 21:36, NW.
12. Iru adura wo ni a nilo, pẹlu iyọrisi wo sì ni?
12 Nipa bayii, a gbọdọ maa gba adura ẹ̀bẹ̀ lemọlemọ nipa ewu ipo wa ati aini wa lati wà lojufo. Nitori naa ẹ jẹ ki a lọ sọdọ Ọlọrun taduratadura pẹlu igbe ẹ̀bẹ̀ onitara ọkàn. Pọọlu sọ ni Roomu 12:12 (NW) pe: “Ẹ ni iforiti ninu adura.” Ati ni Efesu 6:18, a ka pe: “Pẹlu gbogbo adura ati ẹbẹ . . . ẹ maa gbadura nigba gbogbo ninu ẹmi, ki ẹ sì maa ṣọra sii [“jí kalẹ̀,” NW] ninu iduroṣinṣin gbogbo.” Eyi ki i wulẹ ṣe ọ̀ràn gbigba adura bi ẹni pe ó jẹ́ ọ̀ràn àkọsẹ̀bá kan ti kò ní abajade bàbàrà. Iwalaaye wa gan-an ni ó wà ninu ewu. Nitori naa a nilati fi ìtara ọkàn bẹbẹ fun iranlọwọ atọrunwa. (Fiwe Heberu 5:7.) Ni ọ̀nà yẹn awa yoo mu araawa wà ni ìhà ọdọ Jehofa titilọ. Kò sí ohun ti ó lè ṣanfaani julọ ni ríràn wá lọwọ lati ṣaṣepari eyi ju pe ki a ‘maa gba adura ẹ̀bẹ̀ nigba gbogbo.’ Nigba naa ni Jehofa yoo sì mu ki a jẹ́ ẹni ti ń wà lojufo nipasẹ akiyesi. Ó ti ṣe pataki tó, nigba naa, lati tẹpẹlẹ mọ́ adura!
Rọ̀ Timọtimọ Mọ́ Eto-Ajọ Ọlọrun ati Iṣẹ Rẹ̀
13. Iru ibakẹgbeẹpọ wo ni a nilo lati jí kalẹ?
13 A fẹ́ lati yèbọ́ ninu gbogbo nǹkan wọnyi ti yoo wá sori ayé. A fẹ́ lati duro niwaju Ọmọkunrin eniyan, lati ni itẹwọgba rẹ̀. Dé opin yii ohun kẹta wà ti a lè ṣe: Dirọ laiṣeeja mọ eto-ajọ atọrunwa ti Jehofa. A nilati kẹgbẹpọ láìkùsíbìkankan pẹlu eto-ajọ yẹn ki a sì ṣajọpin ninu awọn igbokegbodo rẹ̀. Ni ọ̀nà yii awa yoo fi araawa han laisi aṣiṣe gẹgẹ bii Kristẹni ti ń ṣọna.
14, 15. (a) Lilọwọ ninu iṣẹ wo ni yoo ràn wa lọwọ lati jí kalẹ? (b) Ta ni ń pinnu ìgbà ti iṣẹ iwaasu bá ti pari, bawo sì ni a ṣe gbọdọ nimọlara nipa rẹ̀? (c) Lẹhin ipọnju ńlá, ki ni a o loye nigba ti a bá wẹhin wo iṣẹ iwaasu Ijọba naa ti a ti ṣe?
14 Eyi ti ó sopọ timọtimọ ni ohun kẹrin ti ó lè ràn wa lọwọ lati jí kalẹ̀. A gbọdọ wà lara awọn wọnni ti wọn ń kilọ fun awọn eniyan nipa bíbọ̀ opin eto igbekalẹ awọn nǹkan yii. Opin eto igbekalẹ ogbologboo yii patapata kò ni ṣẹlẹ titi di ìgbà ti a bá tó waasu “ihinrere ijọba yii” dé ìwọ̀n ti Ọlọrun Olodumare ti pète. (Matiu 24:14) Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa kì í ṣe awọn ti yoo pinnu ìgbà ti a ṣaṣepari iṣẹ naa tán. Jehofa pa ẹ̀tọ́ yẹn mọ fun araarẹ̀. (Maaku 13:32, 33) Bi o ti wu ki o ri, awa, pinnu lati ṣiṣẹ kára bi o bá ti lè ṣeeṣe tó ati bi ó bá ti pọndandan tó ni wiwaasu nipa ijọba didara julọ ti araye lè ní rí, Ijọba Ọlọrun. Ìbẹ́sílẹ̀ “ipọnju ńlá” yoo dé nigba ti a ṣì ń lọwọ ninu iṣẹ yii. (Matiu 24:21) Ni gbogbo akoko ọjọ iwaju, awọn ẹni ti a gbala yoo lè wẹhin wo ki wọn sì fi tọkantọkan jẹrii si i pe Jesu Kristi kì í ṣe wolii èké. (Iṣipaya 19:11) Iṣẹ wiwaasu ni a o ti ṣaṣepari rẹ̀ dé ìwọ̀n kan ti ó ju eyi ti awọn olùkópa ninu rẹ ti reti lọ fíìfíì.
15 Nipa bẹẹ, ni akoko pataki gidi naa nigba ti a o ti ṣaṣepari iṣẹ yii si itẹlọrun Ọlọrun fúnraarẹ̀, awọn eniyan pupọ sii ni ó ṣeeṣe pe wọn yoo maa lọwọ ninu rẹ̀ ju ti sáà akoko eyikeyii ṣaaju. A o ti kún fun imoore tó lati ni ipin ninu iṣẹ ńláǹlà yii! Apọsiteli Peteru mú un dá wa loju pe Jehofa kò “fẹ́ ki ẹnikẹni ki o ṣègbé, bikoṣe ki gbogbo eniyan ki o wá si ironupiwada.” (2 Peteru 3:9) Nitori eyi, ipá agbekankanṣiṣẹ Ọlọrun Olodumare ń ṣiṣẹ lonii lọna ti o tubọ mú hánhán ju ti igbakigba ri lọ, Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa sì fọkanfẹ lati maa ba a lọ ninu igbokegbodo tí ẹmi ń sunni ṣe yii. Nitori naa rọ̀ timọtimọ mọ eto-ajọ Jehofa, ki o sì jẹ ki ọwọ́ rẹ dí ninu iṣẹ-ojiṣẹ itagbangba. Eyi yoo jẹ́ aranṣe ninu jíjíkalẹ rẹ.
Ṣe Àyẹ̀wò Ara-Ẹni
16. Eeṣe ti a fi gbọdọ ṣe àyẹ̀wò ara-ẹni nipa ipo tẹmi wa isinsinyi?
16 Ohun karun-un wà ti a lè ṣe ki a baa lè jí kalẹ. Lẹnikọọkan, a gbọdọ ṣe àyẹ̀wò ara-ẹni nipa ipo wa isinsinyi. Eyi yẹ bẹẹ nisinsinyi ju ti igbakigba ri lọ. A nilati fẹ̀rí ìhà ọdọ ẹni ti a fi ipinnu duro sí han. Ni Galatia 6:4, Pọọlu sọ pe: “Ki olukuluku ki o yẹ iṣẹ araarẹ̀ wo.” Ṣe àyẹ̀wò ara-ẹni ni ibamu pẹlu awọn ọrọ Pọọlu ni 1 Tẹsalonika 5:6-8 pe: “Ẹ maṣe jẹ ki a sùn, bi awọn ìyókù ti ń ṣe; ṣugbọn ẹ jẹ ki a maa ṣọna [“wà lójúfò,” NW] ki a sì maa wà ni airekọja. Nitori awọn ti ń sùn, a maa sùn ni oru; ati awọn ti ń mọtipara, a maa mọtipara ni òru. Ṣugbọn ẹ jẹ ki awa, bi a ti jẹ ti ọ̀sán, maa wà ni airekọja, ki a maa gbé ìgbàyà igbagbọ ati ifẹ wọ̀; ati ireti igbala fun aṣibori.”
17. Nigba ti a bá ń ṣe àyẹ̀wò ara-ẹni, awọn ibeere wo ni a gbọdọ beere lọwọ araawa?
17 Awa ń kọ́? Ǹjẹ́ àyẹ̀wò ara-ẹni wa fihan pe a wà lójúfò, pe a ni ireti gẹgẹ bi aṣibori igbala bi? Awa ha jẹ́ eniyan ti o ti ya araawa sọtọ kuro ninu eto igbekalẹ awọn nǹkan ogbologboo lọna ti o ṣe pato ti a kò sì fi awọn èrò rẹ̀ dá araawa laraya mọ́ bi? Awa ha ni ẹmi ayé titun ti Ọlọrun nitootọ bi? Awa ha wà lojufo ni kikun niti ibi ti eto igbekalẹ yii forile bi? Bi o bá ri bẹẹ, ọjọ Jehofa ki yoo dé bá wa lojiji bi ẹni pe a jẹ́ olè.—1 Tẹsalonika 5:4.
18. Awọn ibeere siwaju sii wo ni a nilati bi araawa, pẹlu iyọrisi wo sì ni?
18 Bi o ti wu ki o ri, ki ni, bi àyẹ̀wò ara-ẹni wa bá ṣipaya pe a ń lakaka lati gbé ọ̀nà igbesi-aye pípinminrin, ti o ṣe jọ́mújọ́mú, onidẹra, ti o tunilara kan kalẹ? Ki ni bi a bá ṣawari pe oju tẹmi wa ti kún fun òògbé ati oorun? Ǹjẹ́ a wà ni ipo àlá lílá, tí a sì ń sare tọ awọn àlá asán ti ayé melookan lẹhin bi? Bi o bá rí bẹẹ, nigba naa ẹ jẹ ki a ta jí!—1 Kọrinti 15:34.
Ronu Jinlẹ Lori Awọn Asọtẹlẹ Ti Wọn Ti Ni Imuṣẹ
19. Ki ni diẹ ninu awọn asọtẹlẹ ti a ti rí tí ó ti ni imuṣẹ?
19 Nisinsinyi a dé ori ohun kẹfa ti yoo ran wa lọwọ lati jí kalẹ: Ronu jinlẹ lori ọpọlọpọ awọn asọtẹlẹ ti o ti ni imuṣẹ ni akoko opin yii. A ti kọja ọdun 77 ná lati ìgbà ti akoko ti a yàn fun awọn orilẹ-ede [keferi] ti dopin ni 1914. Bi a ti ń wẹhin rekọja ìdà mẹta ninu mẹrin ọrundun kan, a lè ri bi asọtẹlẹ kan lẹhin omiran ti di eyi ti o ní imuṣẹ—imupadabọsipo ijọsin tootọ; idande awọn aṣẹku ẹni ami ororo, papọ pẹlu awọn alabaakẹgbẹ wọn, sinu paradise tẹmi kan; iwaasu ihinrere Ijọba ni ìwọ̀n kan ti o yika ayé; ifarahan awọn ogunlọgọ ńlá. (Aisaya 2:2, 3; ori 35; Sekaraya 8:23; Matiu 24:14; Iṣipaya 7:9) Sisọ orukọ titobi Jehofa ati ipo ọba-alaṣẹ agbaye rẹ̀ di titobi ńlá ti wà, bakan naa sì ni imupọ sii ẹni kekere kan lati di ẹgbẹrun ati ẹni kekere kan lati di alagbara orilẹ-ede, bi Jehofa ti ń mú un yára kánkán ni akoko rẹ̀. (Aisaya 60:22; Esekiẹli 38:23) Awọn iran apọsiteli Johanu ninu akọsilẹ Iṣipaya sì ń sunmọ otente wọn nisinsinyi.
20. Imudaniloju wo ni Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ṣajọpin, ki ni wọn sì ti fẹ̀rí han lati jẹ́ niti tootọ?
20 Nitori naa, ju ti igbakigba ri lọ, Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní idaniloju gbọnyingbọnyin nipa iṣerẹ́gí òye wọn nipa itumọ awọn àlámọ̀rí ayé lati 1914. Bi wọn ti ni idaniloju yẹn, wọn ti jasi ohun eelo ni ọwọ Ọlọrun Ọga Ogo. Awọn ni a ti fi sisọ ihin-iṣẹ atọrunwa naa lé lọwọ ni akoko pataki gidi yii. (Roomu 10:15, 18) Bẹẹni, awọn ọrọ Jehofa fun akoko opin ti jasi otitọ. (Aisaya 55:11) Eyi, ni ipa tirẹ̀, gbọdọ ru wa soke lati maa ba a lọ titi ti a o fi rí imuṣẹ ikẹhin ti gbogbo awọn ileri Ọlọrun nipasẹ Jesu Kristi.
Igbala Sunmọtosi Ju Ìgbà Ti A Di Onigbagbọ Lọ
21. Iranlọwọ keje wo lati wà lójúfò nipa tẹmi ni a ní?
21 Nikẹhin, iranlọwọ keje lati ran wa lọwọ ninu ṣiṣọna wa ni: Maa fi sọkan nigba gbogbo pe igbala wa ti sunmọtosi ju ìgbà ti a kọkọ di onigbagbọ lọ. Eyi ti o ṣe pataki ju, idalare ipo ọba-alaṣẹ agbaye Jehofa ati isọdimimọ orukọ rẹ̀ ni o ti tubọ sunmọ tosi. Nitori naa aini naa lati jí kalẹ̀ jẹ́ kanjukanju ju ti igbakigba ri lọ. Apọsiteli Pọọlu kọwe pe: “Bi ẹ ti mọ akoko pe, o ti tó wakati nisinsinyi fun yin lati jí loju oorun: nitori nisinsinyi ni igbala wa sunmọ etile ju ìgbà ti awa ti gbagbọ lọ. Òru bukọja tán, ilẹ sì fẹ́rẹ̀ẹ́ mọ́.”—Roomu 13:11, 12.
22. Bawo ni isunmọle igbala ṣe gbọdọ nipa lori wa?
22 Pẹlu igbala wa ti ó tubọ sunmọ tosi tobẹẹ, a gbọdọ jí kalẹ! A kò gbọdọ jẹ ki awọn ire ti ara-ẹni tabi ti ayé eyikeyii tẹ̀wọ̀n kọja imọriri wa fun ohun ti Jehofa ń ṣe fun awọn eniyan rẹ̀ ni akoko opin yii. (Daniẹli 12:3) A nilati fi itẹpẹlẹmọ pupọ sii ju ti igbakigba ri lọ han ki a ma baa yi pada kuro ni oju ọ̀nà ti Ọrọ Ọlọrun damọran ni kedere fun wa. (Matiu 13:22) Ẹ̀rí fihan kedere pe ayé yii wà ni awọn ọjọ ikẹhin rẹ̀. Laipẹ a o pa a rẹ́ kuro ti kò ni sí mọ́ titilae lati faaye silẹ fun ayé titun ododo.—2 Peteru 3:13.
23. Ni ọ̀nà wo ni Jehofa yoo gbà ràn wa lọwọ, pẹlu iyọrisi onibukun wo sì ni?
23 Nitori naa, ẹ jẹ ki a jí kalẹ ni gbogbo ọ̀nà. Ju ti igbakigba ri lọ, ẹ jẹ ki a wà lojufo si ibi ti a wà ninu ìṣàn akoko. Ranti pe, Jehofa kò ni sun ninu ọ̀ran yii lae. Kaka bẹẹ, oun yoo maa ràn wa lọwọ titi ninu wíwà lójúfò ni akoko opin yii. Òru ti bukọja tán. Ilẹ sì ti fẹ́rẹ̀ẹ́ mọ́. Nitori naa ẹ jí kalẹ! Laipẹ a o niriiri awọn ọjọ didara julọ ninu gbogbo awọn ọjọ, bi Ijọba Mesaya naa ti ń mú ète Jehofa ṣe siha ilẹ̀-ayé!—Iṣipaya 21:4, 5.
Ki Ni Awọn Idahun Rẹ?
◻ Ki ni Jesu ni lọkan nigba ti ó wi pe ọjọ ibinu Ọlọrun yoo dé sori awọn eniyan “gẹgẹ bi ìdẹkùn”?
◻ Eeṣe ti a fi gbọdọ bá ìpínyà-ọkàn jà, bawo sì ni a ṣe lè ṣe bẹẹ?
◻ Iru adura wo ni a nilo ki a baa lè wà lójúfò?
◻ Iru ibakẹgbẹpọ wo ni o ṣe pataki?
◻ Eeṣe ti a fi gbọdọ ṣe àyẹ̀wò ara-ẹni nipa ipo tẹmi wa?
◻ Ipa wo ni asọtẹlẹ kó ninu jíjí kalẹ wa?