Awọn Eniyan Olominira Ṣugbọn Ti Wọn Yoo Jíhìn
“Ẹyin yoo si mọ otitọ, otitọ yoo si sọ yin di ominira.” —JOHANNU 8:32, New World Translation.
1, 2. (a) Bawo ni ominira ti ṣe wa farahan ninu ọrọ itan ẹda eniyan? (b) Ta ni ẹnikanṣoṣo naa ti o wà lominira nitootọ? Ṣalaye.
OMINIRA. Iyẹn ti jẹ́ ọrọ alagbara tó! Iran eniyan ti farada aimọye awọn ogun ati iyipada oṣelu ati ailonka awọn rukerudo ẹgbẹ-oun-ọgba bakan naa nitori ifẹ-ọkan awọn ẹda eniyan lati wà lominira. Nitootọ, iwe gbedegbẹyọ naa The Encyclopedia Americana sọ pe: ‘Ninu idagbasoke ọlaju, ko tii si erongba kankan ti o tíì kó ipa ti o ṣe pataki ju isọdominira lọ.’
2 Bi o ti wu ki o ri, awọn eniyan meloo ni wọn wà lominira nitootọ? Awọn meloo paapaa ni wọn mọ ohun ti ominira jẹ? The World Book Encyclopedia sọ pe: “Fun awọn eniyan lati ni ominira patapata, ko gbọdọ si ikalọwọko kankan lori bi wọn ṣe ń ronu, sọrọ, tabi huwa. Wọn gbọdọ mọ awọn ohun tí yíyàn wọn jẹ, wọn si gbọdọ lagbara lati pinnu laaarin awọn yiyan yẹn.” Loju iwoye eyi, iwọ ha mọ ẹni kankan ti o wà lominira nitootọ bi? Awọn wo ni wọn le sọ pe awọn “ko ni ikalọwọko kankan lori bi wọn ṣe ń ronu, sọrọ, tabi huwà”? Niti tootọ, ẹnikanṣoṣo ni gbogbo agbaye ni o ba apejuwe yẹn mu—Jehofa Ọlọrun. Oun nikanṣoṣo ni o ni ominira patapata. Oun nikanṣoṣo ni o le ṣe ipinnu eyikeyii ti o ba fẹ́ ki o si mú un ṣẹ laika gbogbo atako si. Oun ni “Olodumare.”—Ifihan 1:8; Isaiah 55:11.
3. Lori awọn ipo wo ni awọn ẹda eniyan saba maa ń gbadun ominira?
3 Fun awọn ẹda eniyan rirẹlẹ, ominira wulẹ le jẹ aláàlà. A saba maa ń fi funni tabi mú un daniloju nipasẹ ọla-aṣẹ kan ti o si tan mọ́ itẹriba wa fun ọla-aṣẹ yẹn. Nitootọ, ní ohun ti o fẹrẹẹ jẹ gbogbo ọran, ẹnikan le wà lominira kiki bi o bá mọyi ọla-aṣẹ ẹni ti o mú ominira rẹ̀ da a loju. Fun apẹẹrẹ, ẹnikọọkan ti ń gbé ni “ilẹ olominira” ń gbadun ọpọlọpọ anfaani, iru bii ominira irin, ominira ọrọ sisọ, ati ominira isin. Ki ni o mú awọn ominira wọnyi daniloju? Ofin ilẹ naa ni. Ẹnikan wulẹ le gbadun wọn niwọn igba ti o ba ṣegbọran si awọn ofin naa. Bi ó ba ṣi ominira rẹ̀ lo ti o tapa si ofin naa, awọn alaṣẹ yoo mú un fun ìjíhìn, ominira rẹ̀ ni a si le dinku lọna ti o lekoko nipa riran an lọ si ẹwọn.—Romu 13:1-4.
Ominira Ọlọrun—Pẹlu Ìjíhìn
4, 5. Ominira wo ni awọn olujọsin Jehofa ń gbadun, ki si ni oun yoo mu wọn jíhìn fun?
4 Ni ọrundun kìn-ín-ní, Jesu sọrọ nipa ominira. O sọ fun awọn Juu pe: “Bi ẹyin ba duro ninu ọrọ mi, nigba naa ni ẹyin jẹ ọmọ-ẹhin mi nitootọ. Ẹ o si mọ otitọ, otitọ yoo si sọ yin di ominira.” (Johannu 8:31, 32) Oun ko sọrọ nipa ominira ọrọ sisọ tabi ominira isin. Dajudaju oun ko sọrọ nipa isọdominira kuro labẹ ajaga Romu, eyi ti ọpọlọpọ awọn Juu ń wọna fun. Rara, eyi jẹ ohun kan ti o tubọ niyelori ju, ominira kan ti a fifunni, kì í ṣe nipa awọn ofin ẹda eniyan tabi ipinnu ẹda eniyan alaṣẹ kan ti a fi ìkùgbù ṣe, ṣugbọn nipasẹ Ọba Alaṣẹ Onipo Ajulọ ti agbaye, Jehofa. O jẹ ominira kuro ninu ìgbàgbọ́ asán, ominira kuro ninu aimọkan isin, ati pupọ pupọ sii. Ominira ti Jehofa fifunni jẹ ominira tootọ gidi, yoo si wà titilọ gbére.
5 Aposteli Paulu sọ pe: “Jehofa ni Ẹmi naa; nibi ti ẹmi Jehofa bá si wà, ominira wà nibẹ.” (2 Kọrinti 3:17, NW) La ọpọ ọrundun ja Jehofa ti ń bá iran eniyan lo ki o baa le ṣeeṣe lẹ́hìn-ọ̀-rẹhìn fun awọn eniyan oluṣotitọ lati gbadun ominira ẹda eniyan ti o dara julọ ti o sì ga julọ, “ominira ògo awọn ọmọ Ọlọrun.” (Romu 8:21) Ni bayii ná, Jehofa yọnda iwọn ominira fun wa nipasẹ otitọ Bibeli, o si beere pe ki a jíhìn bi a ba ṣi ominira yẹn lo. Aposteli Paulu kọwe pe: “Kò sì sí ẹ̀dá kan ti kò han si oju rẹ̀, ṣugbọn ohun gbogbo wà nihooho a si fi wọn han ni gbangba ni oju ẹni naa ti awa ni ijíhìn fun.”—Heberu 4:13, NW.
6-8. (a) Iru awọn ominira wo ni Adamu ati Efa gbadun, lori awọn ipo wo si ni wọn le maa pa awọn ominira wọnyẹn mọ́? (b) Ki ni Adamu ati Efa padanu fun araawọn ati awọn atọmọdọmọ wọn?
6 Ìjíhìn fun Jehofa ni a tẹnumọ nigba ti awọn òbí wa eniyan akọkọ, Adamu ati Efa, walaaye. Jehofa ṣẹda wọn pẹlu ẹ̀bùn ṣiṣeyebiye ti ominira ifẹ-inu. Niwọn igba ti wọn ba lo ominira ifẹ-inu yẹn lọna ti o mọ́gbọ́ndání, wọn a gbadun awọn ibukun miiran, iru bii ominira kuro ninu ibẹru, ominira kuro ninu aisan, ominira kuro ninu iku, ati ominira lati tọ Baba wọn ọrun lọ pẹlu ẹri-ọkan mimọ. Ṣugbọn nigba ti wọn ṣi ominira ifẹ-inu wọn lò, gbogbo iyẹn yipada.
7 Jehofa fi Adamu ati Efa sinu ọgba Edeni, ati fun igbadun wọn o fun wọn ni eso gbogbo awọn igi inu ọgba naa—ayafi ẹyọkan. Ọ̀kan yẹn ni o tọju fun araarẹ̀; o jẹ́ “igi imọ rere ati buburu.” (Genesisi 2:16, 17) Nipa fifasẹhin kuro ninu jijẹ eso igi yẹn, Adamu ati Efa yoo gbà pe Jehofa nikanṣoṣo ni o lominira lati fi ọpa idiwọn ohun ti o dara ati ohun ti o buru lelẹ. Bi wọn ba ṣe ohun ti o mọ́gbọ́ndání ti wọn si fasẹhin kuro ninu jijẹ eso ti a kaleewọ naa, Jehofa yoo maa baa lọ lati mú awọn ominira wọn yooku dá wọn loju.
8 Lọna ti o banininujẹ, Efa fetisilẹ si idamọran ọlọgbọn-ẹwẹ Ejo pe o gbọdọ ‘mọ rere ati buburu’ fun araarẹ̀. (Genesisi 3:1-5) Oun lakọọkọ, ati lẹhin naa Adamu, jẹ eso ti a kaleewọ naa. Gẹgẹ bi iyọrisi rẹ̀, nigba ti Jehofa Ọlọrun wá lati ba wọn sọrọ ninu ọgba Edeni, oju tì wọ́n wọ́n sì fi araawọn pamọ. (Genesisi 3:8, 9) Nisinsinyi wọn jẹ́ ẹlẹṣẹ ti o ti padanu imọlara ominira títọ Ọlọrun wá eyi ti o ti inu ẹri-ọkan mimọ jade. Nitori eyi, wọn tun padanu ominira kuro ninu aisan ati iku, fun araawọn ati fun awọn atọmọdọmọ wọn. Paulu wi pe: “Nitori gẹgẹ bi ẹṣẹ ti ti ipa ọdọ eniyan kan wọ aye, ati iku nipa ẹṣẹ; bẹẹ ni iku si kọja sori eniyan gbogbo, lati ọdọ ẹni ti gbogbo eniyan ti dẹṣẹ.”—Romu 5:12; Genesisi 3:16, 19.
9. Awọn wo ni wọn wà ninu akọsilẹ pe wọn lo iwọn ominira ti wọn gbadun daradara?
9 Bi o ti wu ki o ri, eniyan sibẹsibẹ ṣì ni ominira ifẹ-inu, ati bi akoko ti ń lọ, awọn ẹda eniyan alaipe kan lo eyi lọna ti o mọ́gbọ́ndání lati ṣiṣẹsin Jehofa. Orukọ diẹ lara wọn ni a ti tọjupamọ fun wa lati ọjọ́ igbaani wá. Awọn ọkunrin bii Abeli, Enọku, Noa, Abraham, Isaaki, ati Jakọbu (ti a tun n pe ni Israeli) jẹ awọn apẹẹrẹ awọn ẹni ti wọn lo iwọn ominira ti wọn sì gbadun lati ṣe ifẹ-inu Ọlọrun. Iyọrisi rẹ̀ si ni pe o dara fun wọn.—Heberu 11:4-21.
Ominira Awọn Eniyan Ayanfẹ Ọlọrun
10. Ki ni ipo ti a filelẹ fun majẹmu ti Jehofa ṣe pẹlu awọn eniyan rẹ̀ akanṣe?
10 Ni awọn ọjọ Mose, Jehofa sọ awọn ọmọ Israeli dominira—wọn jẹ araadọta ọkẹ nigba naa—kuro ninu oko ẹru ni Ijibiti o si dá majẹmu pẹlu wọn nipasẹ eyi ti wọn di awọn eniyan akanṣe fun un. Labẹ majẹmu yii, awọn ọmọ Israeli ní ipo alufaa ati eto awọn ẹbọ ẹran ti o bo awọn ẹṣẹ wọn lọna iṣapẹẹrẹ kan. Nipa bayii, wọn lominira lati tọ Ọlọrun lọ ninu ijọsin. Wọn si tun ni eto awọn ofin ati ilana lati sọ wọn dominira kuro ninu awọn aṣa onigbagbọ ninu ohun asán ati ijọsin èké. Lẹhin naa, wọn yoo gba Ilẹ Ileri naa gẹgẹ bi ogún, pẹlu idaniloju iranlọwọ atọrunwa lodisi awọn ọta wọn. Iha tiwọn ninu majẹmu naa beere pe ki awọn ọmọ Israeli pa Ofin Jehofa mọ́. Awọn ọmọ Israeli fi imuratan tẹwọgba ipo afilelẹ yii, ni wiwi pe: “Gbogbo ohun ti Jehofa ti sọ ni a muratan lati ṣe.”—Eksodu 19:3-8, NW; Deuteronomi 11:22-25.
11. Ki ni o ṣẹlẹ nigba ti Israeli kuna lati pa apa tirẹ̀ ninu majẹmu pẹlu Jehofa mọ́?
11 Fun ohun ti o ju 1,500 ọdun lọ, awọn ọmọ Israeli wà ninu ibatan akanṣe yẹn pẹlu Jehofa. Ṣugbọn lati igba de igba wọn kùnà lati pa majẹmu naa mọ́. Leralera ni ijọsin èké yi wọn leropada dẹṣẹ wọn si wá sinu isinru si ibọriṣa ati ìgbàgbọ́ ninu ohun asán, nitori naa Ọlọrun yọnda wọn niti gidi lati wá sabẹ isinru awọn ọ̀tá wọn. (Onidajọ 2:11-19) Dipo ki wọn gbadun awọn ibukun asọnidominira ti o ń wá lati inu pipa majẹmu naa mọ́, a jẹ wọn niya nitori pe wọn ré e kọja. (Deuteronomi 28:1, 2, 15) Ni asẹhinwa-asẹhinbọ, ni 607 B.C.E., Jehofa yọnda ki orilẹ-ede naa di eyi ti a sọ dẹrú ní Babiloni.—2 Kronika 36:15-21.
12. Ki ni o wa ṣe kedere nipa majẹmu Ofin Mose nigba ti o ya?
12 Eyi jẹ ẹkọ arikọgbọn lilekoko kan. O ti yẹ ki wọn kẹkọọ ijẹpataki pipa Ofin mọ́ lati inu rẹ̀. Bi o ti wu ki o ri, lẹhin 70 ọdun, nigba ti awọn ọmọ Israeli pada si ilẹ tiwọn funraawọn, wọn ṣì kùnà lati pa Ofin majẹmu mọ́ lọna ti o bojumu. Ni eyi ti o fẹrẹẹ to ọgọrun-un ọdun lẹhin ti wọn pada, Jehofa sọ fun awọn alufaa Israeli pe: “Ẹyin ti yapa kuro ni ọna naa: ẹyin ti mu ọpọlọpọ kọsẹ ninu ofin; ẹyin ti ba majẹmu Lefi jẹ.” (Malaki 2:8) Nitootọ, eyi ti ó lotiitọ inu julọ lara awọn ọmọ Israeli paapaa kò le kaju oṣuwọn ohun ti Ofin pipe naa beere fun. Dipo ki o jẹ ibukun kan, o di, ni awọn ọrọ aposteli Paulu, “ègún.” (Galatia 3:13) Ni kedere, ohun kan ti o ju Ofin majẹmu Mose ni a nilo lati mu awọn ẹda eniyan alaipe, oluṣotitọ wá sinu ominira ògo awọn ọmọ Ọlọrun.
Apẹẹrẹ-Iru Ominira Kristian
13. Ipilẹ ti o dara ju fun ominira wo ni a pese nikẹhin?
13 Ohun kan ti ó ju iyẹn ni ẹbọ irapada ti Jesu Kristi. Ni nǹkan bii ọdun 50 C.E., Paulu kọwe si ijọ awọn ẹni ami ororo ni Galatia. O ṣapejuwe bi Jehofa ti sọ wọn di ominira kuro ninu isinru fun majẹmu Ofin o si sọ lẹhin naa pe: “Fun iru ominira bẹẹ ni Kristi dá wa silẹ lominira. Nitori naa ẹ duro ṣinṣin, ẹ ma si jẹ ki a tun sé yin mọ́ inú àjàgà oko-ẹrú mọ́.” (Galatia 5:1, NW) Ni awọn ọna wo ni Jesu gba sọ eniyan dominira?
14, 15. Ni awọn ọna agbayanu wo ni Jesu gbà dá awọn Ju ati awọn ti kì í ṣe Ju silẹ lominira?
14 Lẹhin iku Jesu, awọn Ju ti wọn tẹwọgba a gẹgẹ bii Messia ti wọn si di awọn ọmọlẹhin rẹ̀ wa sabẹ majẹmu titun kan, eyi ti o rọpo majẹmu Ofin ogbologboo. (Jeremiah 31:31-34; Heberu 8:7-13) Labẹ majẹmu titun yii, awọn—ati awọn onigbagbọ ti kì í ṣe Ju ti wọn darapọ mọ wọn lẹhin naa—di apakan orilẹ-ede titun, tẹmi kan ti o rọpo Israeli ti ara gẹgẹ bi awọn eniyan akanṣe Ọlọrun. (Romu 9:25, 26; Galatia 6:16) Nipa bẹẹ wọn gbadun ominira ti Jesu ṣeleri nigba ti o sọ pe: “Otitọ yoo sọ yin di ominira.” Yatọ si sisọ wọn dominira kuro labẹ egun Ofin Mose, otitọ sọ awọn Kristian Ju dominira kuro ninu gbogbo awọn ẹkọ atọwọdọwọ níniragógó tí awọn aṣaaju isin ti gbe ka wọn lori. O si tun tú awọn Kristian ti kì í ṣe Ju silẹ kuro ninu ibọriṣa ati ìgbàgbọ́ ninu ohun asán ti ijọsin wọn tẹ́lẹ̀. (Matteu 15:3, 6; 23:4; Iṣe 14:11-13; 17:16) Pupọ sii ṣi wà.
15 Nigba ti Jesu ń sọrọ nipa otitọ ti ń sọni dominira, o sọ pe: “Ẹnikẹni ti o ba ń dẹṣẹ, oun ni ẹrú ẹṣẹ.” (Johannu 8:34) Lati igba ti Adamu ati Efa ti dẹṣẹ, gbogbo ẹnikọọkan ti o tii walaaye rí ti jẹ ẹlẹṣẹ ati nipa bẹẹ wọn jẹ́ ẹrú ẹṣẹ. Àfi kanṣoṣo naa ni Jesu funraarẹ, ẹbọ Jesu si ni o tú awọn onígbàgbọ́ silẹ kuro ninu isinru yẹn. Loootọ, alaipe ni wọn sibẹ wọn si kun fun ẹṣẹ lọna ti ẹ̀dá. Bi o ti wu ki o ri, nisinsinyi wọn lè ronupiwada kuro ninu ẹṣẹ wọn ki wọn si bẹbẹ fun idariji lori ipilẹ ẹbọ Jesu, pẹlu igbẹkẹle pe ẹbẹ wọn ni a o gbọ́. (1 Johannu 2:1, 2) Lori ipilẹ ẹbọ irapada Jesu, Ọlọrun ka wọn si olododo, wọn si lè tọ̀ ọ́ lọ pẹlu ẹri-ọkan ti a wẹ̀mọ́. (Romu 8:33) Ju bẹẹ lọ, niwọn bi irapada ti ṣi ifojusọna fun ajinde si iwalaaye ailopin silẹ, otitọ pẹlu tun tú wọn silẹ kuro ninu ibẹru iku.—Matteu 10:28; Heberu 2:15.
16. Lọna wo ni ominira Kristian fi gbà kó ọpọlọpọ mọra ju ominira eyikeyii ti aye yii le fi funni lọ?
16 Lọna agbayanu, ominira Kristian ni a ṣí silẹ fun ọkunrin ati obinrin laika ipo wọn si ki a sọ ọ bii ti ẹ̀dá. Awọn eniyan alaini, awọn ẹlẹwọn, ani awọn ẹrú paapaa, le di ominira. Ni ọwọ keji ẹwẹ, awọn ẹni giga ninu aye ti wọn kọ ihin-iṣẹ nipa Kristi silẹ ṣi wà labẹ isinru fun ìgbàgbọ́ ninu ohun asán, ẹṣẹ, ati ibẹru iku. A ko gbọdọ dẹkun didupẹ lọwọ Jehofa lae fun ominira yii ti awa ń gbadun. Ko si ohun kan ti aye yii le nawọ rẹ̀ sini ti o sunmọ biba a dọgba.
Wọn Wà Lominira Ṣugbọn Wọn Yoo Jihin
17. (a) Bawo ni awọn kan ni ọrundun kìn-ín-ní ṣe padanu ninu ominira Kristian? (b) Eeṣe ti a kò gbọdọ fi tàn wa jẹ nipa ohun ti o dabi ominira ninu aye Satani?
17 Ni ọrundun kìn-ín-ní, o ṣeeṣe ki o jẹ pe eyi ti o pọ julọ ninu awọn Kristian ẹni ami ororo layọ ninu ominira wọn ti wọn sì pa iwatitọ wọn mọ laika ohunkohun ti o ná wọn si. Bi o ti wu ki o ri, ó banininujẹ́, pe awọn kan tọ́ ominira Kristian pẹlu gbogbo awọn ibukun rẹ̀ wò wọn si gàn án lẹhin naa, ni pipada sinu isinru ninu aye. Eeṣe ti eyi fi ri bẹẹ? Laisi tabi ṣugbọn o rẹ ọpọlọpọ, wọn si wulẹ ‘súlọ.’ (Heberu 2:1) Awọn miiran ‘gbé ìgbàgbọ́ ati ẹri-ọkan rere jù sẹ́gbẹ̀ẹ́kan wọn si niriiri ọkọ̀ rírì nipa ìgbàgbọ́ wọn.’ (1 Timoteu 1:19) Boya wọn ṣubu sinu ifẹ ọrọ alumọọni tabi ipa-ọna igbesi-aye oniwa palapala. O ti ṣe pataki tó pe ki a pa ìgbàgbọ́ wa mọ́ ki a si maa mú un pọ̀ sii, ni jíjẹ́ ki ọwọ wa dí ninu idakẹkọọ, ibakẹgbẹpọ, adura ati igbokegbodo Kristian! (2 Peteru 1:5-8) Njẹ ki a maṣe kùnà lae lati fi imọriri han fun ominira Kristian! Otitọ ni, pe awọn kan ni a lè dẹkùn mú nipa ìṣedẹńgbẹrẹ ti wọn ri lẹhin ode ijọ, ni rironu pe awọn ti wọn wà ninu aye lominira jù wá lọ. Bi o ti wu ki o ri, niti gidi, ohun ti o dabi ominira ninu aye wulẹ saba maa n jẹ ainimọlara fun ìjíhìn. Bi awa kì í ba ṣe ẹrú Ọlọrun, ẹrú ẹṣẹ ni wa, isinru yẹn si ń san iye owo kikoro kan.—Romu 6:23; Galatia 6:7, 8.
18-20. (a) Bawo ni awọn kan ṣe di “ọ̀tá opo igi idaloro”? (b) Bawo ni awọn kan ṣe ‘di ominira wọn mu bi ìbòjú fun iwa buburu’?
18 Siwaju sii, ninu lẹta rẹ si awọn ara Filippi, Paulu kọwe pe: “Ọpọlọpọ ni ń bẹ, emi ti maa ń mẹnukan wọn nigbakuugba ri ṣugbọn nisinsinsyi mo tun mẹnukan wọn pẹlu ẹkún, ti wọn ń rìn gẹgẹ bi ọ̀tá igi idaloro Kristi.” (Filippi 3:18, NW) Bẹẹni, awọn Kristian tẹlẹri kan wà ti wọn wá di ọ̀tá ìgbàgbọ́, boya ti wọn di apẹhinda. O ti ṣe pataki tó pe ki awa maṣe tẹle ipa-ọna wọn! Ni afikun, Peteru kọwe pe: “Ki ẹ wà gẹgẹ bi ominira eniyan, sibẹ ki ẹ si di ominira yin mu, kì í ṣe gẹgẹ bi ìbòjú fun iwa buburu, ṣugbọn gẹgẹ bi awọn ẹru Ọlọrun.” (1 Peteru 2:16, NW) Bawo ni ẹnikan ṣe le di ominira rẹ̀ mu gẹgẹ bi ìbòjú fun iwa buburu? Nipa dida awọn ẹṣẹ ti o wuwo—boya níkọ̀kọ̀—nigba ti o ṣi ń darapọ mọ ijọ.
19 Ranti Diotrefe. Johannu sọ nipa rẹ̀ pe: “Diotrefe, ẹni ti o fẹ lati jẹ́ olori [ninu ijọ], kò gbà wá. . . . Bẹẹ ni oun . . . kò gba awọn ará, awọn ti o si ń fẹ́ gbà wọn, o ń dá wọn lẹ́kun, o si ń lé wọn jade kuro ninu ijọ.” (3 Johanu 9, 10) Diotrefe lo ominira rẹ̀ gẹgẹ bi ìbòjú fun ilepa-aṣeyọri onimọtara-ẹni nikan rẹ̀.
20 Ọmọ-ẹhin naa Juda kọwe pe: “Nitori awọn eniyan kan ń bẹ ti wọn ń yọ́ wọlé, awọn ẹni ti a ti yàn lati igba atijọ si ẹ̀bi yii, awọn alaiwa-bi-Ọlọrun, ti ń yí oore ọ̀fẹ́ Ọlọrun wa pada si wọbia, ti wọn sì ń sẹ́ Oluwa wa kanṣoṣo naa, ani Jesu Kristi Oluwa.” (Juda 4) Nigba ti wọn ń darapọ mọ ijọ, awọn ẹni wọnyi jẹ́ agbara idari ti ń sọnidibajẹ. (Juda 8-10, 16) Ninu Ifihan a ka pe ni ijọ Pergamu ati Tiatira, iyapa isin, ibọriṣa, ati iwapalapala wà nibẹ. (Ifihan 2:14, 15, 20-23) Iru aṣilo ominira Kristian wo ni eyi jẹ́!
21. Ki ni ń duro de awọn wọnni ti wọn ṣi ominira Kristian wọn lò?
21 Ki ni o ń duro de awọn ti wọn ba ṣi ominira Kristian wọn lò ni ọna yii? Ranti ohun ti o ṣẹlẹ si Israeli. Israeli jẹ orilẹ-ede ayanfẹ Ọlọrun, ṣugbọn nigbẹhingbẹhin Jehofa kọ̀ ọ́ silẹ. Eeṣe? Nitori pe awọn ọmọ Israeli lo ibatan wọn pẹlu Ọlọrun gẹgẹ bi ìbòjú fun iwa buburu. Wọn yangan pe awọn jẹ awọn ọmọkunrin Abraham ṣugbọn wọn kọ Jesu silẹ, Iru-ọmọ Abraham ati Messia ti Jehofa yàn. (Matiu 23:37-39; Johannu 8:39-47; Iṣe 2:36; Galatia 3:16) “Israeli Ọlọrun” lapapọ ki yoo jasi alaiṣotitọ bakan naa. (Galatia 6:16) Ṣugbọn Kristian eyikeyii kan ti o ba ṣokunfa isọdeeri nipa tẹmi tabi niti iwahihu yoo dojukọ ibawi ni asẹhinwa asẹhinbọ, ani idajọ ti ko barade paapaa. Gbogbo wa ni a o jíhìn fun bi a ṣe lo ominira Kristian wa.
22. Idunnu wo ni o ń wá sọdọ awọn wọnni ti wọn lo ominira Kristian wọn lati sinru fun Ọlọrun?
22 Bawo ni o ti dara tó lati sinru fun Ọlọrun ki a si di ominira nitootọ. Jehofa nikanṣoṣo ni ń yọnda ominira ti o niyelori niti tootọ. Owe sọ pe: “Ọmọ mi, ki iwọ, ki o gbọ́n, ki o si mú inu mi dùn, ki emi ki o le dá ẹni ti ń gàn mi lohun.” (Owe 27:11) Ẹ jẹ ki a lo ominira Kristian wa fun idalare Jehofa. Bi a ba ṣe bẹẹ, igbesi-aye wa yoo ni itumọ, awa yoo mú idunnu wá bá Baba wa ọrun, ati nigbẹhin rẹ̀ a o wà lara awọn ti wọn yoo gbadun ominira ògo awọn ọmọ Ọlọrun.
Iwọ Ha Le Ṣalaye Bi?
◻ Ta ni ẹnikanṣoṣo naa ti o wà lominira nitootọ?
◻ Awọn ominira wo ni Adamu ati Efa gbadun, eesitiṣe ti wọn fi padanu wọn?
◻ Iru ominira wo ni awọn ọmọ Israeli gbadun nigba ti wọn pa majẹmu wọn pẹlu Jehofa mọ́?
◻ Iru awọn ominira wo ni o wá sọdọ awọn ti wọn tẹwọgba Jesu?
◻ Bawo ni awọn kan ni ọrundun kìn-ín-ní ṣe padanu tabi ṣi ominira Kristian wọn lò?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
Ominira ti Jesu funni dara pupọpupọ ju ominira eyikeyii ti eniyan le fifunni