Lo Ominira Kristian Rẹ Lọna Ọgbọn
“Ki ẹ wà gẹgẹ bi awọn eniyan ominira, sibẹ ki ẹ si di ominira yin mú . . . gẹgẹ bi awọn ẹrú Ọlọrun.”—1 PETERU 2:16, NW.
1. Ominira wo ni Adamu padanu, inu ominira wo si ni Jehofa yoo mu araye padabọsipo sí?
NIGBA ti awọn obi wa akọkọ dẹṣẹ ninu ọgba Edeni, wọn gbé ogún ologo kan—ominira kuro ninu ẹṣẹ ati idibajẹ fun awọn ọmọ wọn sọnu. Gẹgẹ bi iyọrisi rẹ̀, gbogbo wa ni a bi ní ẹrú si idibajẹ ati iku. Bi o ti wu ki o ri, lọna ti o munilayọ, Jehofa pete lati mu awọn ẹda eniyan oluṣotitọ padabọsipo ominira agbayanu kan. Lonii, awọn ẹni ọlọkantitọ ń fi iharagaga duro de “ifihan awọn ọmọ Ọlọrun,” gẹgẹ bi iyọrisi eyi ti a o “sọ ẹ̀dá tikararẹ di ominira kuro ninu ẹrú idibajẹ, si ominira ogo awọn ọmọ Ọlọrun.”—Romu 8:19-21.
‘A Fami Ororo Yàn Wọn Lati Waasu’
2, 3. (a) Awọn wo ni “awọn ọmọkunrin Ọlọrun”? (b) Ki ni iduro agbayanu ti wọn ń gbadun, ẹru-iṣẹ wo ni o sì mú wá?
2 Awọn wo ni “awọn ọmọ Ọlọrun” wọnyi? Wọn jẹ́ awọn arakunrin Jesu ti a fi ẹmi yan ti wọn yoo jẹ alakooso pẹlu rẹ̀ ninu Ijọba ti ọrun. Akọkọ ninu awọn wọnyi farahan ní ọrundun kìn-ín-ní C.E. Wọn tẹwọgba otitọ ti ń sọni dominira ti Jesu fi kọni, lati Pentikosti 33 C.E., wọn nipin-in ninu awọn anfaani ologo tí Peteru sọrọ nipa rẹ̀ nigba ti o kọwe si wọn pe: “Ẹyin ni ‘ẹ̀yà-iran kan ti a yàn, ẹgbẹ́-alufaa ọlọ́ba kan, orilẹ-ede mimọ kan, eniyan kan fun akanṣe ìní.’”—1 Peteru 2:9a, NW; Johannu 8:32.
3 Lati jẹ́ ohun-ini akanṣe fun Ọlọrun—ẹwo iru ibukun agbayanu wo ni o jẹ́! Awọn àṣẹ́kù ode-oni ti awọn ọmọkunrin Ọlọrun ti ẹni-ami-ororo wọnyi sì gbadun iduro onibukun kan-naa pẹlu Ọlọrun. Ṣugbọn pẹlu anfaani ti a gbega bẹẹ ni awọn ẹru-iṣẹ ń bárìn. Peteru pe afiyesi si ọkàn ninu iwọnyi nigba ti o ń baa lọ lati wi pe: “Ẹyin nilati kede kaakiri awọn itayọlọla ẹni naa ti o pè yin kuro ninu okunkun bọ sinu imọlẹ agbayanu rẹ.”—1 Peteru 2:9b, NW.
4. Bawo ni awọn Kristian ẹni-ami-ororo ṣe mu ẹrù-iṣẹ́ naa ti o wá pẹlu ominira Kristian wọn ṣẹ?
4 Njẹ awọn Kristian ẹni-ami-ororo ti mú ẹrù-iṣẹ́ yii ṣẹ lati polongo itayọlọla Ọlọrun kaakiri bi? Bẹẹni. Ni sisọrọ lọna asọtẹlẹ nipa awọn ẹni-ami-ororo naa lati 1919, Isaiah wi pe: “Ẹmi Oluwa Jehofa ń bẹ lara mi: nitori o ti fi ami ororo yan mi lati waasu ihinrere fun awọn otoṣi; o ti rán mi lati ṣe àwòtán awọn onirobinujẹ ọkàn, lati kede idasilẹ fun awọn igbekun, ati iṣisilẹ tubu fun awọn òǹdè; lati kede ọdun itẹwọgba Oluwa, ati ọjọ ẹsan Ọlọrun wa.” (Isaiah 61:1, 2) Lonii, àṣẹ́kù ẹni-ami-ororo, ni titẹle apẹẹrẹ Jesu, ẹni ti a lo ẹsẹ iwe mimọ yii fun lakọọkọ, ń fi titaratitara polongo ihinrere ti ominira fun awọn ẹlomiran.—Matteu 4:23-25; Luku 4:14-21.
5, 6. (a) Ki ni o ti jẹyọ lati inu iwaasu onitara ọkàn ti awọn Kristẹni ẹni-ami-ororo? (b) Awọn anfaani ati ẹrù-iṣẹ́ wo ni awọn ogunlọgọ nla naa ń gbadun?
5 Gẹgẹ bi iyọrisi iwaasu onitara ọkàn wọn, ogunlọgọ nla ti awọn agutan miiran ti farahan ninu iran aye ni awọn apa ikẹhin ọjọ wọnyi. Wọn ti jade wá lati gbogbo orilẹ-ede lati darapọ mọ́ awọn ẹni-ami-ororo ni ṣiṣiṣẹsin Jehofa, otitọ si ti mú awọn wọnyi di ominira pẹlu. (Sekariah 8:23; Johannu 10:16) Gẹgẹ bii Abrahamu awọn ni a polongo bii olododo lori ipilẹ ìgbàgbọ́ ti wọn si ti wọnu ipo ibatan timọtimọ kan pẹlu Jehofa Ọlọrun. Ati gẹgẹ bii Rahabu pipolongo ti a polongo wọn bi olododo fi wọn sori ila fun lilaaja—ninu ọran tiwọn, lila Amagẹdoni já. (Jakọbu 2:23-25; Ifihan 16:14, 16) Ṣugbọn iru awọn anfaani ti a gbega bẹẹ tun ni ninu ẹru-iṣẹ naa lati sọ fun awọn ẹlomiran nipa ògo Ọlọrun. Idi niyẹn ti Johannu fi ri wọn ni gbangba ti wọn ń yin Jehofa, “wọn si kigbe ni ohun rara, wi pe, Igbala ni ti Ọlọrun wa ti o jokoo lori itẹ, ati ti Ọdọ-Agutan.”—Ifihan 7:9, 10, 14.
6 Ní ọdun ti o kọja ogunlọgọ nla naa, ti iye wọn ju million mẹrin nisinsinyi, papọ pẹlu ẹgbẹ awọn Kristian ẹni-ami-ororo kereje ti o ṣẹ́kù naa, lo eyi ti o fẹrẹẹ tó billion kan wakati ni pipolongo awọn itayọlọla Jehofa kaakiri. Eyi jẹ́ ọna didara julọ ti o ṣeeṣe lati gba lo ominira wọn nipa tẹmi.
“Ẹ Bu Ọla fun Ọba”
7, 8. Ki ni ẹrù-iṣẹ́ si awọn alaṣẹ aye alaijẹ ti isin ti ominira Kristian ní ninu, ati nipa eyi, ki ni iṣarasihuwa ti ko tọ́ ti a nilati yẹra fun?
7 Ominira Kristian wa mu awọn ẹru-iṣẹ miiran dani. Peteru tọkasi awọn melookan nigba ti o kọwe pe: “Ẹ bu ọla fun gbogbo oniruuru awọn eniyan, ẹ ní ifẹ fun gbogbo ẹgbẹ awọn ara, ẹ bẹru Ọlọrun, ẹ bu ọla fun ọba.” (1 Peteru 2:17, NW) Ki ni ohun ti ọrọ isọjade naa “ẹ bu ọla fun ọba” dọgbọn tumọsi?
8 “Ọba” duro fun awọn oluṣakoso aye alaijẹ ti isin. Lonii, ẹmi aibọwọ fun awọn alaṣẹ ti gbèrú ninu aye, ti eyi si le nipa lori awọn Kristẹni lọna ti o rọrun. Ani Kristian kan paapaa le ṣe kayefi nipa idi rẹ̀ ti oun fi gbọdọ bu ọla fun “ọba,” niwọn bi ‘gbogbo aye ti wà labẹ agbara ẹni buburu nì.’ (1 Johannu 5:19) Loju iwoye awọn ọrọ wọnyi, oun lè nimọlara lati ṣaigbọran si awọn ofin ti ko rọrun ki o si fasẹhin ni sisan owo ori bi oun ba lè mú un jẹ. Ṣugbọn eyi yoo lodisi aṣẹ ti Jesu sọ jade lati “fi ohun tii ṣe ti Kesari fun Kesari.” Yoo jẹ́, gẹgẹ bi abajade rẹ̀, ‘lilo ominira rẹ̀ gẹgẹ bi ìbòjú fun iwa buburu.’—Matteu 22:21; 1 Peteru 2:16.
9. Ki ni awọn idi rere meji fun jijẹ onigbọran si awọn alaṣẹ aye alaijẹ ti isin?
9 Awọn Kristian ni a fi sabẹ iṣẹ aigbọdọmaṣe lati bu ọla fun awọn alaṣẹ ati lati tẹriba fun wọn—ani bi eyi tilẹ jẹ ni ọna kan ti o láàlà paapaa. (Iṣe 5:29) Eeṣe? Ninu 1 Peteru 2:14, 15, Peteru tọkasi awọn idi mẹta nigba ti oun sọ pe awọn gomina ni a “rán lati ọdọ [Ọlọrun] fun igbẹsan lara awọn ti ń ṣe buburu, ati fun iyin awọn ti ń ṣe rere.” Ibẹru ijiya jẹ idi ti o pọ̀ tó fun ṣiṣegbọran si awọn alaṣẹ. Ẹ wo ojuti ti yoo jẹ́ pe ki a bu owo ìtanràn lé tabi jù Ẹlẹ́rìí Jehofa kan sẹwọn nitori ifipakọluni, ole jíjà, tabi iwa-ọdaran miiran kan! Ẹ finuwoye bi inu awọn kan yoo ti dun tó lati kede iru ohun kan bẹẹ! Ni ọwọ́ keji ẹ̀wẹ̀, bi awa ti ń mú orukọ rere dagba fun igbọran si ofin ilu, awa ń gba iyin lati ọdọ awọn alakooso ti wọn ní idajọ ododo. A lè fun wa ni ominira pupọ sii lati maa ba iṣẹ wa ti wiwaasu ihinrere naa niṣo. Siwaju sii, ‘nipa ṣiṣe rere awa yoo lè kó ọrọ alaimọkan awọn eniyan alailọgbọn-ninu níjàánu.’ (1 Peteru 2:15b, NW) Eyi ni idi keji fun ṣiṣegbọran si awọn alaṣẹ.—Romu 13:3.
10. Ki ni idi ti o lagbara julọ fun ṣiṣe igbọran si awọn alaṣẹ aye alaijẹ ti isin?
10 Ṣugbọn idi kan ti o lagbara ju wà. Awọn alaṣẹ wà nipa iyọọda Jehofa. Gẹgẹ bi Peteru ti sọ, awọn oluṣakoso oṣelu ni a “ran lati ọdọ” Jehofa ti o si jẹ́ “ifẹ Ọlọrun” pe ki awọn Kristian wà ní itẹriba fun wọn. (1 Peteru 2:15a) Lọna ti o jọra, aposteli Paulu wi pe: “Awọn alaṣẹ ti o si wà, lati ọdọ Ọlọrun ni a ti lana rẹ̀ wá.” Nitori idi eyi, ẹri-ọkan wa ti a fi Bibeli dalẹkọọ ń sún wa lati ṣegbọran si awọn alaṣẹ. Bi a bá kọ̀ lati mu araawa tẹriba fun wọn, a ti “tàpá si ilana Ọlọrun.” (Romu 13:1, 2, 5) Ta ni lara wa ti yoo fẹ lati mu iduro kan lodisi iṣeto Ọlọrun? Ẹ wo bi iyẹn yoo ti jẹ aṣilo ominira Kristian tó!
‘Ní Ifẹ fun Awọn Arakunrin’
11, 12. (a) Ẹrù-iṣẹ́ wo si awọn onigbagbọ ẹlẹgbẹ wa ni o ń bá ominira Kristian rìn? (b) Ki ni ohun naa ni pataki ti o yẹ fun igbeyẹwo onifẹẹ wa, eesitiṣe?
11 Peteru pẹlu sọ pe Kristian kan gbọdọ “ní ifẹ fun gbogbo ẹgbẹ awọn arakunrin.” (1 Peteru 2:17, NW) Eyi jẹ́ ẹrù-iṣẹ́ miiran ti ń ba ominira Kristian rin. Ọpọjulọ ninu wa jẹ ti ijọ kan. Nitootọ, gbogbo wa jẹ ti ibakẹẹgbẹ jakejado awọn orilẹ-ede naa, tabi eto-àjọ ti awọn arakunrin. Fifi ifẹ han fun awọn wọnyi jẹ lilo ominira wa pẹlu ọgbọ́n.—Johannu 15:12, 13.
12 Aposteli Paulu ya awujọ awọn Kristian kan ti wọn yẹ fun ifẹ wa ni pataki sọtọ fun afiyesi akanṣe. Oun wi pe: “Ẹ maa gbọ ti awọn ti ń ṣe olori yin, ki ẹ si maa tẹriba fun wọn: nitori wọn ń ṣọ́ ẹ̀ṣọ́ nitori ọkàn yin, bi awọn ti yoo ṣe iṣiro, ki wọn ki o lè fi ayọ ṣe eyi, ni aisi ibinujẹ, nitori eyiyii yoo jẹ́ ailere fun yin.” (Heberu 13:17) Awọn wọnni ti ń mú ipo iwaju ninu ijọ ni awọn alagba. Nitootọ, awọn ọkunrin wọnyi kì í ṣe ẹni pipe. Bi o tilẹ ri bẹẹ, awọn ni a yansipo labẹ idari Ẹgbẹ Oluṣakoso. Wọn ń mu ipo iwaju nipasẹ apẹẹrẹ ati igbatẹniro, awọn ni a si yanṣẹ fun lati ṣọ́ ẹṣọ lori ọkàn wa. Ẹ wo iru iṣẹ ayanfunni wiwuwo ti eyi jẹ́! (Heberu 13:7) Lọna ti o munilayọ, eyi ti o pọ julọ ninu awọn ijọ ní ẹmi rere ati ti onifọwọsowọpọ, o si jẹ̀ idunnu fun awọn alagba lati ṣiṣẹ pẹlu wọn. O tubọ maa ń ṣoro nigba ti awọn ẹnikọọkan kò ba fẹ́ lati fọwọsowọpọ. Alagba naa yoo ṣì maa ba iṣẹ rẹ̀ lọ, ṣugbọn gẹgẹ bi Paulu ti wi, ó ń ṣe é pẹlu “ibinujẹ.” Dajudaju, awa ko fẹ lati mu ki awọn alagba banujẹ! A fẹ ki wọn layọ ninu iṣẹ wọn ki wọn baa lè gbé wa ró.
13. Ki ni awọn ọna diẹ ninu eyi ti a lè gbà fọwọsowọpọ pẹlu awọn alagba?
13 Awọn ọna diẹ wo ni a le gba fọwọsowọpọ pẹlu awọn alagba? Ọkàn jẹ ṣiṣeranwọ pẹlu titọju ati sisọ Gbọngan Ijọba di mimọ tonitoni. Omiran jẹ nipa fifọwọsowọpọ ninu iṣẹ ṣiṣebẹwo sọdọ awọn alaisan ati riran awọn alaabọ ara lọwọ. Ni afikun sii, awa lè lakaka lati wà ní alagbara titilọ nipa tẹmi, ki a ma baa di ẹrù-ìnira kan. Apa ṣiṣepataki kan fun ifọwọsowọpọ jẹ ti imọtonitoni ijọ nipa tẹmi ati ti iwarere, nipa iwa tiwa funraawa ati nipa rirohin awọn ọran ẹsẹ wiwuwo ti o wá si afiyesi wa.
14. Bawo ni a ṣe lè fọwọsowọpọ pẹlu igbesẹ ibawi ti awọn alagba bá gbé?
14 Nigba miiran, ki a baa lè pa ijọ mọ́ ni tonitoni, awọn alagba nilati yọ awọn oniwa aitọ alaironupiwada kan lẹgbẹ. (1 Kọrinti 5:1-5) Eyi daabobo ijọ naa. O lè ran oniwa aitọ naa lọwọ pẹlu. Lọpọ igba, iru ibawi bẹẹ ti ṣeranwọ lati pe ori oniwa aitọ kan wálé. Bi o ti wu ki o ri, ki ni bi ẹni ti a yọlẹgbẹ naa ba jẹ́ ọrẹ timọtimọ kan tabi ibatan? Ka sọ pe ẹni naa jẹ́ baba tabi iya wa tabi ọmọkunrin tabi ọmọbinrin wa. Awa bi o tilẹ ri bẹẹ yoo ha bọwọ fun igbesẹ ti awọn alagba gbe bi? Nitootọ, yoo jẹ ohun ti o ṣoro. Ṣugbọn ẹ wo bi yoo ti jẹ́ aṣilo ominira wa to lati gbe ibeere dide nipa ipinnu awọn alagba ki a si ma baa lọ lati kẹgbẹpọ nipa tẹmi pẹlu ẹnikan ti o fi ẹ̀rí hàn pe oun jẹ́ asunni-huwa ibajẹ ninu ijọ! (2 Johannu 10, 11) Awọn eniyan Jehofa yẹ ni ẹni ti à bá gboriyin fun nitori ọna ti wọn ń gbà fọwọsowọpọ ninu iru awọn ọran bẹẹ. Gẹgẹ bi iyọrisi rẹ̀, ètò-àjọ Jehofa ni a pamọ ní mimọ tonitoni ti o si wà lailẹgbin ninu aye alaimọtonitoni yii.—Jakọbu 1:27.
15. Bi ẹnikan bá dá ẹṣẹ wiwuwo kan, ki ni oun gbọdọ ṣe lẹsẹkẹsẹ?
15 Ki ni bi awa ba dẹṣẹ wiwuwo kan? Ọba Dafidi ṣapejuwe awọn wọnni ti Jehofa ṣojurere si nigba ti o wi pe: “Ta ni yoo gun ori oke Oluwa [“Jehofa,” NW] lọ? Tabi ta ni yoo duro ní ibi mimọ rẹ̀? Ẹni ti o ni ọwọ́ mimọ, ati aya funfun: ẹni ti ko gbé ọkàn rẹ̀ soke si asan, ti ko si bura ẹ̀tàn.” (Orin Dafidi 24:3, 4) Fun awọn idi kan bi awa ko ba jẹ́ ‘ọlọ́wọ́ mimọ ati ọlọkan-aya funfun’ mọ́, awa nilati gbe igbesẹ ni kanjukanju. Iye ainipẹkun wa ń bẹ ninu ewu.
16, 17. Eeṣe ti ẹni ti o jẹbi ẹṣẹ wiwuwo kò fi gbọdọ gbiyanju lati yanju ọran naa ni oun nikan?
16 Awọn kan ni a ti dẹwo lati bo awọn ẹṣẹ wiwuwo mọlẹ, boya ní rironu pe: ‘Mo ti jẹwọ fun Jehofa mo si ti ronupiwada. Nitori naa eeṣe ti mo fi gbọdọ fi ọran lọ awọn alagba?’ Oniwa aitọ naa ni a le mútìjú bá tabi ki o bẹru ohun ti awọn alagba lè ṣe. Bi o ti wu ki o ri, oun nilati ranti pe bi o tilẹ jẹ pe Jehofa nikan ni o le fọ ẹ̀ṣẹ̀ wa mọ́, Oun ti yan ẹrù-iṣẹ́ fun awọn alagba lati ri si imọgaara ijọ ni pataki. (Orin Dafidi 51:2) Wọn wà nibẹ fun imularada, fun “aṣepe awọn eniyan mimọ.” (Efesu 4:12) Ṣiṣailọ sọdọ wọn nigba ti a ba nilo iranwọ tẹmi dabi ṣiṣailọ sọdọ dokita kan nigba ti a ba ń ṣaisan.
17 Awọn kan ti wọn gbiyanju lati bojuto awọn ọran funraawọn nikan rii pe ọpọ oṣu tabi ọdun lẹhin naa, ẹri-ọkan wọn ṣi ń wahala wọn lọna lilekenka. Eyi ti o tilẹ buru ju paapaa, awọn miiran ti wọn bo aṣiṣe wiwuwo kan mọlẹ ń ṣubu sinu ẹṣẹ lẹẹkeji ati lẹẹkẹta paapaa. Nigba ti ọran naa ba wá si afiyesi awọn alagba nigbẹhin-gbẹhin, o jẹ́ ọran iwa aitọ alaṣetunṣe. Ẹ wo bi o ti sànjù tó lati tẹle imọran Jakọbu! Oun kọwe pe: “Ẹnikẹni ṣe aisan ninu yin bi? Ki o pe awọn agba ijọ, ki wọn si gbadura sori rẹ̀, ki wọn fi ororo kùn ún ní orukọ Oluwa.” (Jakọbu 5:14) Lọ sọdọ awọn alagba nigba ti akoko ṣì wà fun imularada. Bi awa ba duro pẹ́ jù, awa lè di ẹni ti o jingiri sinu ipa-ọna ẹṣẹ.—Oniwasu 3:3; Isaiah 32:1, 2.
Irisi ati Eré Inaju
18, 19. Eeṣe ti alufaa kan fi sọrọ lọna rere bẹẹ nipa Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa?
18 Ní ọdun marun-un sẹhin, ninu iwe irohin parish kan, alufaa Katoliki kan ní Italy fi tọyaya tọyaya sọrọ nipa Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa.a Oun wi pe: “Gẹgẹ bi ẹnikan, mo fẹran Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa; emi ń jẹwọ eyi laifọrọ sabẹ ahọn sọ. . . . Awọn wọnni ti mo mọ̀ ń huwa laisi ariwisi, wọn ń sọrọ jẹ́jẹ́ . . . wọn [si] mọ̀ bi a ti ń yinileropada julọ. Nigba wo ni a maa to loye pe otitọ nilo igbekalẹ onitẹwọgba kan? Pe kò yẹ ki awọn wọnni ti ń kede otitọ jẹ alaifi gbogbo ọkàn ṣiṣẹ, olóòórùn buruku, onidọti, alaibikita?”
19 Ni ibamu pẹlu awọn ọrọ wọnyi, alufaa naa ni a wu lori, papọ pẹlu awọn nǹkan miiran, nipa ọna ti Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ń gba mura ti wọn si ń gba fi araawọn hàn. Lọna ti o han gbangba, awọn ti oun ti ba pade ti fetisilẹ si itọni tí “ẹrú oluṣotitọ ati ọlọgbọn inu naa” fi funni ní awọn ọdun ti o ti kọja. (Matteu 24:45, NW) Bibeli wi pe aṣọ wiwọ fun awọn obinrin gbọdọ jẹ eyi ti a ‘ṣeto daradara ti o si mọ niwọn.’ (1 Timoteu 2:9) Ni akoko tí iwarere ti wolulẹ, imọran yẹn dara fun awọn ọkunrin pẹlu. Njẹ ko ha bọgbọnmu pe ki awọn aṣoju Ijọba Ọlọrun fi araawọn han lọna ti o bojumu fun awọn ẹlomiran?
20. Eeṣe ti Kristian kan fi gbọdọ ṣọra nipa iwọṣọ rẹ̀ ni gbogbo igba?
20 Awọn kan lè gbà pe ni awọn ipade ati ninu papa, awọn gbọdọ ṣọra nipa ọna ti awọn ń gbà mura, ṣugbọn wọn lè nimọlara pe awọn ilana Bibeli ko ṣee fisilo ni awọn igba miiran. Bi o ti wu ki o ri, igba kan ha wa ti a ń ṣiwọ jíjẹ́ aṣoju Ijọba Ọlọrun bi? Nitootọ, awọn ayika ipo yatọsira. Bi a ba ń ṣeranwọ ninu kíkọ́ Gbọngan Ijọba kan, awa yoo mura yatọ si igba ti a ba lọ si ipade ninu Gbọngan Ijọba yẹn kan-naa. Nigba ti a ba ń gbafẹ́, o ṣeeṣe ki a mura lọna ti o tubọ ṣe gbẹndẹkẹ. Ṣugbọn nigbakugba ti awọn ẹlomiran ba rí wa, iwọṣọ wa gbọdọ figba gbogbo jẹ eyi ti a ṣeto daradara ti o si mọ niwọn.
21, 22. Ọna wo ni a gba daabobo wa kuro lọwọ eré ìnàjú apanilara, oju wo ni a si gbọdọ fi wo imọran ninu iru awọn ọran bẹẹ?
21 Agbegbe miiran ti o ti gba afiyesi pupọ gan-an ni eré ìnajú. Awọn eniyan—paapaa julọ awọn ọ̀dọ́—nilo eré ìnàjú. Kì í ṣe ẹṣẹ tabi fifi akoko ṣòfò lati wewee isinmi itura fun idile. Koda Jesu ké si awọn ọmọlẹhin rẹ̀ lati “sinmi diẹ.” (Marku 6:31) Ṣugbọn ṣọra ki eré inàjú maṣe ṣí ilẹkun naa silẹ fun isọdeeri tẹmi. Awa ń gbé ninu aye kan nibi ti eré ìnàjú ti ń fa afiyesi si iwa palapala ibalopọ takọtabo, iwa-ipa ti o lekenka, ẹrujẹnjẹn, ati biba ẹmi lò. (2 Timoteu 3:3; Ifihan 22:15) Ẹrú oluṣotitọ ati ọlọgbọn inu ti wà lojufo lodisi iru awọn ewu bẹẹ ti wọn si ń kilọ fun wa lodisi wọn leralera. Iwọ ha nimọlara pe awọn irannileti wọnyi jẹ́ títẹ ominira rẹ lójú bi? Tabi iwọ ha ní imọriri pe eto ajọ Jehofa bikita tó nipa rẹ̀ lati mu iru awọn ewu bẹẹ wá si afiyesi rẹ nigba gbogbo bi?—Orin Dafidi 19:7; 119:95.
22 Maṣe gbagbe lae pe bi o tilẹ jẹ pe ominira wa wá lati ọ̀dọ̀ Jehofa, awa yoo jíhìn fun bi a ba ṣe lò ó. Bi awa ba ṣaifiyesi imọran rere ti a si ṣe awọn ipinnu ti kò tọ́, awa kò lè dẹbi fun ẹlomiran kan. Aposteli Paulu wi pe: “Olukuluku wa ni yoo jíhìn araarẹ fun Ọlọrun.”—Romu 14:12; Heberu 4:13.
Fojusọna fun Ominira Awọn Ọmọ Ọlọrun
23. (a) Ki ni awọn ibukun ti o nii ṣe pẹlu ominira ti awa ń gbadun nisinsinyi? (b) Ki ni awọn ibukun ti awa ń fi iharagaga duro de?
23 Awa niti gidi jẹ eniyan alabukunfun. Awa wà lominira kuro ninu isin èké ati igbagbọ ninu ohun asán. Ọpẹ ni fun ẹbọ irapada Jesu Kristi, awa lè wá sọdọ Jehofa pẹlu ẹri-ọkan mimọ tonitoni, ti o wà lominira lọna tẹmi kuro ninu isinru ẹṣẹ ati iku. Ati laipẹ “ifihan awọn ọmọ Ọlọrun” yoo dé. Ni Har-mageddoni, awọn arakunrin Jesu ninu ogo wọn ti ọrun ni a o fihan fun awọn eniyan gẹgẹ bi oluṣeparun fun awọn ọ̀tá Ọlọrun. (Romu 8:19; 2 Tẹsalonika 1:6-8; Ifihan 2:26, 27) Lẹhin naa, awọn ọmọkunrin Ọlọrun wọnyi ni a o ṣipaya gẹgẹ bi oju-ọna fun awọn ibukun ti ń ṣàn jade lati ibi ìtẹ́ Ọlọrun wá sọdọ araye. (Ifihan 22:1-5) Nigbẹhin-gbẹhin, iṣipaya awọn ọmọkunrin Ọlọrun wọnyi yoo yọrisi bibukun araye oluṣotitọ pẹlu ominira ologo ti awọn ọmọ Ọlọrun. Iwọ ha ń nàgà fun akoko yẹn bi? Nigba naa lo ominira Kristian rẹ lọna ọgbọn. Sìnrú fun Ọlọrun nisinsinyi, iwọ yoo si gbadun agbayanu ominira yẹn fun gbogbo ayeraye!
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Alufaa naa pada kó ọrọ igboriyin funni yii jẹ́, labẹ ikimọlẹ lòna ti o hàn gbangba.
Apoti Atunyẹwo
◻ Bawo ni awọn ẹni-ami-ororo ati awọn agutan miiran ṣe fi ogo fun Jehofa?
◻ Eeṣe ti awọn Kristian fi gbọdọ bọla fun awọn alaṣẹ aye alaijẹ ti isin?
◻ Ni awọn ọna wo ni Kristian kan lè gba fọwọsowọpọ pẹlu awọn alagba?
◻ Nipa ti iwọṣọ, eeṣe ti Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa fi dayatọ gedegbe si awọn ti o pọ julọ ninu aye?
◻ Ki ni ohun ti a nilati ṣe nigba ti o ba kan eré ìnàjú?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Awọn alagba ni pataki yẹ fun ifẹ ati ifọwọsowọpọ wa
[Àwọ̀n àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Aṣọ Kristian kan ni a gbọdọ ṣeto daradara, ki o mọ niwọn, ki o si bá akoko naa mu wẹku