Ìfẹ́ (Agape)—Ohun Tí Kò jẹ́ Àti Ohun Tí Ó Jẹ́
“Ẹ fi . . . ìfẹ́ kún ìfẹ́ni ará yín.”—2 PETERU 1:5, 7, NW.
1. (a) Ànímọ́ wo ni Bibeli fún ní ìtayọlọ́lá jùlọ? (b) Àwọn ọ̀rọ̀ Griki mẹ́rin wo ni a sábà máa ń túmọ̀ sí “ìfẹ́,” èwo sì ni a tọ́ka sí ní 1 Johannu 4:8?
BÍ ÀNÍMỌ́ tàbí ìwàrere kan bá wà tí Ọ̀rọ̀ Ọlọrun, Bibeli, fún ní ìtayọlọ́lá jùlọ, ìfẹ́ ni. Ní Griki, tí ó jẹ́ èdè ìpilẹ̀ṣẹ̀ Ìwé Mímọ́ Kristian, àwọn ọ̀rọ̀ mẹ́rin ni ó wà tí a sábà máa ń túmọ̀ sí “ìfẹ́.” Ìfẹ́ tí ó jẹ wá lọ́kàn nísinsìnyí kìí ṣe ti eʹros (ọ̀rọ̀ kan tí a kò rí nínú Ìwé Mímọ́ Kristian Lédè Griki), tí a gbékarí ìfàmọ́ra ti ìbálòpọ̀ takọtabo; bẹ́ẹ̀ ni kìí ṣe ti stor·geʹ, ìmọ̀lára kan tí a gbékarí ipò-ìbátan alájọbi; bẹ́ẹ̀ ni kìí ṣe phi·liʹa, ìfẹ́ ọlọ́yàyà ti ọ̀rẹ́sọ́rẹ̀ẹ́, tí a gbékarí ìgbéníyì tọ̀túntòsì, tí a bójútó nínú ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ tí ó ṣáájú. Kàkà bẹ́ẹ̀, a·gaʹpe ni—ìfẹ́ tí a gbékarí ìlànà, tí a lè sọ pé ó jẹ́ ọ̀rọ̀ tí ó báramu pẹ̀lú àìmọtara-ẹni-nìkan, ìfẹ́ tí aposteli Johannu tọ́ka sí nígbà tí ó sọ pé: “Ọlọrun jẹ́ ìfẹ́.”—1 Johannu 4:8, NW.
2. Kí ni a ti sọ lọ́nà dídára nípa ìfẹ́ (a·gaʹpe)?
2 Nípa ìfẹ́ (a·gaʹpe) yìí, Ọ̀jọ̀gbọ́n William Barclay nínú ìwé New Testament Words rẹ̀ sọ pé: “Agapē níí ṣe pẹ̀lú èrò-inú: kìí wulẹ̀ ṣe èrò-ìmọ̀lára tí ń ru sókè láìròtẹ́lẹ̀ nínú ọkàn-àyà wa [gẹ́gẹ́ bí ọ̀ràn ti lè rí pẹ̀lú phi·liʹa]; ó jẹ́ ìlànà kan tí a ń mọ̀ọ́mọ̀ gbé nípa rẹ̀. Agapē níí ṣe pẹ̀lú ìfẹ́-inú lọ́nà gíga jùlọ. Ó jẹ́ ìṣẹ́gun, ìjagunmólú, àti àṣeyọrí kan. Kò sí ẹnìkan tí ó jẹ́ nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá rẹ̀ lọ́nà àdánidá. Láti nífẹ̀ẹ́ ọ̀tá ẹni jẹ́ ṣíṣẹ́gun gbogbo àwọn ìtẹ̀sí-ọkàn àti èrò-ìmọ̀lára àdánidá wa. Agapē yìí . . . ní tòótọ́ jẹ́ agbára láti nífẹ̀ẹ́ àwọn tí kò ṣeé nífẹ̀ẹ́, láti nífẹ̀ẹ́ àwọn ènìyàn tí a kò fẹ́ràn.”
3. Ìtẹnumọ́ wo ni Jesu Kristi àti Paulu gbékarí ìfẹ́?
3 Bẹ́ẹ̀ni, lára àwọn ohun tí ó ya ìjọsìn mímọ́ gaara ti Jehofa Ọlọrun sọ́tọ̀ kúrò lára gbogbo irú ìjọsìn mìíràn ni ìtẹnumọ́ rẹ̀ lórí irú ìfẹ́ yìí. Lọ́nà tí ó tọ́ ni Jesu Kristi sọ àwọn òfin-àṣẹ méjì títóbi jùlọ náà: “Èkínní, . . . Kí ìwọ kí ó [fi] gbogbo àyà rẹ, àti gbogbo ọkàn rẹ, àti gbogbo iyè rẹ, àti gbogbo agbára rẹ, fẹ́ Oluwa Ọlọrun rẹ: èyí ni òfin èkínní. Èkejì sì dàbí rẹ̀, Fẹ́ ọmọnìkejì rẹ bí ara rẹ. Kò sì sí òfin mìíràn, tí ó tóbi jù wọ̀nyí lọ.” (Marku 12:29-31) Aposteli Paulu fi ìtẹnumọ́ kan-náà sórí ìfẹ́ ní orí 13 nínú 1 Korinti. Lẹ́yìn nínu-ẹnu mọ́ ọn pé ìfẹ́ jẹ́ ọba ànímọ́ tí kòṣeémánìí, ó parí-ọ̀rọ̀ nípa sísọ pé: “Ǹjẹ́ nísinsìnyí ìgbàgbọ́, ìrètí, àti ìfẹ́ ń bẹ, àwọn mẹ́ta yìí: ṣùgbọ́n èyí tí ó tóbi jù nínú wọn ni ìfẹ́.” (1 Korinti 13:13) Jesu lọ́nà tí ó tọ́ sọ pé ìfẹ́ ni yóò jẹ́ àmì ìdánimọ̀ ti àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀.—Johannu 13:35.
Àwọn Ohun tí Ìfẹ́ Kò Jẹ́
4. Apá-ìhà aláìgbéniró àti apá-ìhà gbígbéniró mélòó níti ìfẹ́ ni Paulu mẹ́nukàn ní 1 Korinti 13:4-8?
4 A ti sọ kókó náà pé ó rọrùn láti sọ ohun tí ìfẹ́ kò jẹ́ ju láti sọ ohun tí ó jẹ́ lọ. Òtítọ́ díẹ̀ kan wà nínú ìyẹn, nítorí tí aposteli Paulu nínú orí-ìwé rẹ̀ lórí ìfẹ́, 1 Korinti 13, ní ẹsẹ 4 sí 8 (NW), mẹ́nukan àwọn ohun mẹ́sàn-án tí ìfẹ́ kò jẹ́ àti àwọn ohun méje tí ó jẹ́.
5. Báwo ni a ṣe túmọ̀ “owú,” báwo sì ni a ṣe lò ó ní èrò ìtumọ̀ tí ń gbéniró nínú Ìwé Mímọ́?
5 Ohun àkọ́kọ́ tí Paulu sọ pé ìfẹ́ kò jẹ́ ni pé “kìí jowú.” Ìyẹn nílò àlàyé díẹ̀ nítorí pé ìhà gbígbéniró àti aláìlègbéniró wà nípa owú. Ìwé atúmọ̀-èdè kan túmọ̀ “owú” gẹ́gẹ́ bíi “lílẹ́mìí àìrára gba ìbánidíje sí” àti gẹ́gẹ́ bíi “fífi dandan béèrè fún ìfọkànsìn tí a yàsọ́tọ̀ gédégbé.” Nípa báyìí, Mose sọ ní Eksodu 34:14 pé: “Ẹ̀yin kò gbọ́dọ̀ bọ òrìṣà: nítorí OLUWA, orúkọ ẹni tíí jẹ́ Òjòwú, Ọlọrun òjòwú ni òun.” Ní Eksodu 20:5 (NW), Jehofa sọ pé: “Èmi Jehofa Ọlọrun yín mo jẹ́ Ọlọrun tí ń fi dandan béèrè ìfọkànsìn tí a yàsọ́tọ̀ gédégbé.” Ní ọ̀nà kan-náà, aposteli Paulu kọ̀wé pé: “Èmi ń jowú lórí yín níti owú ẹni ìwà-bí-Ọlọ́run.”—2 Korinti 11:2.
6. Àwọn àpẹẹrẹ tí ó bá Ìwé Mímọ́ mu wo ni ó fi ìdí tí ìfẹ́ kìí fií jowú hàn?
6 Bí ó ti wù kí ó rí, ní gbogbogbòò, “owú” ní èrò àgbéyọsọ́kàn búburú kan, èyí tí a fi kà á kún àwọn iṣẹ́ ti ara ní Galatia 5:20. Bẹ́ẹ̀ni, irú owú bẹ́ẹ̀ jẹ́ onímọtara-ẹni-nìkan ó sì ń fa ìkórìíra, ìkórìíra sì jẹ́ òdìkejì ìfẹ́. Owú mú kí Kaini kórìíra Abeli dórí kókó pípa á, ó sì mú kí àwọn arákùnrin mẹ́wàá ọmọ bàbá Josefu kórìíra rẹ̀ dórí fífẹ́ láti pa á. Ìfẹ́ kìí fi owú di kùnrùngbùn sí ohun-ìní tàbí àǹfààní àwọn ẹlòmíràn, gẹ́gẹ́ bí Ọba Ahabu ti fi owú di kùnrùngbùn láti gba ọgbà àjàrà Naboti.—1 Ọba 21:1-19.
7. (a) Ìṣẹ̀lẹ̀ wo ni ó fihàn pè inú Jehofa kò dùn sí ìfọ́nnu? (b) Èéṣe tí ìfẹ́ kìí fií fọ́nnu àní láìronú jinlẹ̀ pàápàá?
7 Paulu sọ fún wa tẹ̀lé e pé ìfẹ́ “kìí fọ́nnu.” Fífọ́nnu fi àìní ìfẹ́ hàn, nítorí tí ó ń mú kí ẹnìkan gbé ara rẹ̀ sí ipò kan tí ó ga ju ti àwọn mìíràn lọ. Jehofa kò ní inúdídùn sí àwọn afọ́nnu, gẹ́gẹ́ bí a ti lè rí i nínú ọ̀nà tí ó gbà rẹ Ọba Nebukadnessari sílẹ̀ nígbà tí ó fọ́nnu. (Danieli 4:30-35) Fífọ́nnu ni a sábà máa ń ṣe láìronú nítorí jíjẹ́ ẹni tí ó nítẹ̀ẹ́lọ́rùn kọjá ààyè pẹ̀lú àṣeyọrí tẹni fúnra-ẹni tàbí àwọn ohun-ìní. Àwọn kan lè nítẹ̀sí láti ṣògo nípa àṣeyọrí wọn nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́ Kristian. Àwọn mìíràn dàbí alàgbà náà tí ó níláti fóònù àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ láti sọ fún wọn nípa pé òun ti ra mọ́tò titun tí iye rẹ̀ fẹ́rẹ̀ẹ́ tó $50,000. Gbogbo nǹkan báwọ̀nyẹn kò fi ìfẹ́ hàn nítorí pé ó fi afọ́nnu náà hàn bí ẹni tí ó ní ju àwọn olùgbọ́ rẹ̀ lọ.
8. (a) Kí ni ìṣarasíhùwà Jehofa síhà àwọn wọnnì tí wọ́n ń wú fùkẹ̀? (b) Èéṣe tí ìfẹ́ kìí fií hùwà ní ọ̀nà yẹn?
8 Lẹ́yìn náà a sọ fún wa pé ìfẹ́ “kìí wú fùkẹ̀.” Ẹnìkan tí ń wú fùkẹ̀, tàbí tí ń gbéraga, ń fi àìnífẹ̀ẹ́ gbé araarẹ ga ju àwọn mìíràn lọ. Irú ìṣarasíhùwà èrò-orí kan bẹ́ẹ̀ jẹ́ aláìlọ́gbọ́n jùlọ nítorí pé “Ọlọrun kọ ojú ìjà sí àwọn agbéraga, ṣùgbọ́n ó fi oore-òfẹ́ fún àwọn onírẹ̀lẹ̀ ọkàn.” (Jakọbu 4:6) Ìfẹ́ ń hùwà ní ọ̀nà òdìkejì gan-an; ó ń ka àwọn ẹlòmíràn sí ọlọ́lá jù. Paulu kọ̀wé ní Filippi 2:2, 3 (NW) pé: “Ẹ sọ ìdùnnú mi di kíkún níti pé kí ẹ ní èrò-inú kan-náà kí ẹ sì ní ìfẹ́ kan-náà, kí a so yín pọ̀ papọ̀ nínú ọkàn, ní dídi ìrònú kan-náà mú nínú èrò-inú, láìṣe ohunkóhun láti inú ẹ̀mí gbólóhùn-asọ̀ tàbí láti inú ògo-asán, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ èrò-inú kí ẹ máa kà á sí pé àwọn ẹlòmíràn lọ́lá jù yín lọ.” Irú ìṣarasíhùwà èrò-orí kan bẹ́ẹ̀ ń mú kí ara dẹ àwọn ẹlòmíràn, nígbà tí onígbèéraga kan ń mú kí ara ni àwọn ẹlòmíràn nítorí ẹ̀mí-asọ̀.
9. Èéṣe tí ìfẹ́ kìí fií hùwà lọ́nà àìbójúmu?
9 Paulu sọ síwájú síi pé ìfẹ́ “kìí hùwà lọ́nà àìbójúmu.” Ìwé atúmọ̀-èdè náà túmọ̀ “àìbójúmu” gẹ́gẹ́ bí “àìbẹ́tọ̀ọ́mu lọ́nà rírinlẹ̀ tàbí aṣeláìfí sí ìwà-híhù tàbí ìlànà ìwàrere.” Ẹnìkan tí ń hùwà lọ́nà àìbójúmu (lọ́nà àìnífẹ̀ẹ́) kò ka ìmọ̀lára àwọn ẹlòmíràn sí. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀dà-ìtumọ̀ Bibeli túmọ̀ èdè Griki náà gẹ́gẹ́ bíi “àìmọ̀wàáhù.” Irú ẹnìkan bẹ́ẹ̀ ń tàpá sí ohun tí a kà sí èyí tí ó yẹ tí ó sì dára. Dájúdájú, ìgbatẹnirò onífẹ̀ẹ́ fún àwọn ẹlòmíràn yóò túmọ̀sí yíyẹra fún gbogbo ohun tí ó jẹ́ ti àìmọ̀wàáhù tàbí àìbójúmu, àwọn ohun tí ń bíni nínú tí ó tilẹ̀ lè dáyàfoni pàápàá.
Àwọn Ohun Mìíràn tí Ìfẹ́ Kò Jẹ́
10. Ní ọ̀nà wo ni ìfẹ́ kìí gbà wá ire ti araarẹ̀?
10 Tẹ̀lé e a sọ fún wa pé ìfẹ́ “kìí wá ire ti ara rẹ̀ nìkan,” ìyẹn ni pé, nígbà tí ọ̀ràn bá dìde nípa ohun tí àwa fúnraawa àti àwọn ẹlòmíràn bá nífẹ̀ẹ́-ọkàn sí. Aposteli náà sọ níbòmíràn pé: “Kò sí ẹnìkan tí ó tíì kórìíra ara rẹ̀; bíkòṣe pé kí ó máa bọ́ ọ kí ó sì máa ṣìkẹ́ rẹ̀.” (Efesu 5:29) Bí ó ti wù kí ó rí, nígbà tí àwọn ire tiwa bá ń foríwọnrí pẹ̀lú ti àwọn ẹlòmíràn tí kò sì sí àwọn ìlànà Bibeli mìíràn tí ó wémọ́ ọn, a níláti ṣe gẹ́gẹ́ bí Abrahamu ti ṣe pẹ̀lú Loti, kí á fi tìfẹ́tìfẹ́ mú kí ẹnìkejì ní yíyàn àkọ́kọ́ náà.—Genesisi 13:8-11.
11. Pé a kìí tán ìfẹ́ ní sùúrù túmọ̀ sí kí ni?
11 Ìfẹ́ kìí tún tètè gbìnàyá. Nítorí náà Paulu sọ fún wa pé “a kìí tán [ìfẹ́] ní sùúrù.” Kìí ṣe oníkanra. Ó ń lo ìkóra-ẹni-níjàánu. Àwọn tọkọtaya ní pàtàkì níláti fi ìṣínilétí yìí sọ́kàn nípa ṣíṣọ́ra fún gbígbé ohùn wọn sókè láìní sùúrù tàbí lílọgun lé araawọn lórí. Àwọn ipò wà nígbà tí ó rọrùn láti di ẹni tí a tán ní sùúrù, fún ìdí èyí tí Paulu fi nímọ̀lára àìní náà láti gba Timoteu nímọ̀ràn pé: “Ìráńṣẹ́ Oluwa kò sì gbọ́dọ̀ jà; bíkòṣe kí ó jẹ́ ẹni pẹ̀lẹ́ sí ènìyàn gbogbo, ẹni tí ó lè kọ́ni, onísùúrù”—bẹ́ẹ̀ni, kìí di ẹni tí a tán ní sùúrù—“ẹni tí yóò máa kọ́ àwọn aṣòdì pẹ̀lú ìwà tútù.”—2 Timoteu 2:24, 25.
12. (a) Ní ọ̀nà wo ni ìfẹ́ kìí gbà ṣàkọsílẹ̀ ìṣeniléṣe? (b) Èéṣe tí kò fi bọ́gbọ́nmu láti pa àkọsílẹ̀ ìṣeniléṣe mọ́?
12 Ní bíbáa nìṣó pẹ̀lú àwọn ohun tí ìfẹ́ kò jẹ́, Paulu gbaninímọ̀ràn pé: “Ìfẹ́ . . . kìí kọ àkọsílẹ̀ nípa ìṣeniléṣe.” Ìyẹn kò túmọ̀ sí pé ìfẹ́ kìí fiyèsí ìṣeniléṣe kankan. Jesu fi bí a ṣe níláti bójútó àwọn ọ̀ràn hàn nígbà tí a bá ti ṣe wá léṣe gidigidi. (Matteu 18:15-17) Ṣùgbọ́n ìfẹ́ kìí gbà wá láàyè láti máa báa lọ láti kún fún ìbínú, láti di kùnrùngbùn. Láti máṣe kọ àkọsílẹ̀ ìṣeniléṣe túmọ̀sí láti jẹ́ adáríjini àti láti gbàgbé nípa rẹ̀ ní gbàrà tí a bá ti bójútó ọ̀ràn náà ní ọ̀nà tí ó bá Ìwé Mímọ́ mu. Bẹ́ẹ̀ni, máṣe dá araàrẹ lóró tàbí kó ìdààmú bá araàrẹ nípa bíbáa lọ láti máa ní àròdùn ọkàn nípa àìtọ́ kan, ní pípa àkọsílẹ̀ ìṣeniléṣe mọ́!
13. Kí ni ó túmọ̀ sí láti máṣe yọ̀ lórí àìṣòdodo, èésìtiṣe tí ìfẹ́ kìí fií ṣe ìyẹn?
13 Jù bẹ́ẹ̀ lọ, a sọ fún wa pé ìfẹ́ “kìí yọ̀ lórí àìṣòdodo.” Ayé a máa yọ̀ lórí àìṣòdodo, gẹ́gẹ́ bí a ṣe lè rí i nípa ìgbajúmọ̀ ìwà-ipá àti ìwé arùfẹ́-ìṣekúṣe-sókè, sinimá, àti àwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ orí tẹlifíṣọ̀n. Gbogbo irú ayọ̀ bẹ́ẹ̀ jẹ́ onímọtara-ẹni-nìkan, tí kò ní ọ̀wọ̀ kankan fún àwọn ìlànà òdodo Ọlọrun tàbí ire àwọn ẹlòmíràn. Gbogbo irú ayọ̀ onímọtara-ẹni-nìkan bẹ́ẹ̀ jẹ́ fífúnrúgbìn sípa ti ara àti nígbà tí ó bá yá yóò ká ìdibàjẹ́ láti inú ara.—Galatia 6:8.
14. Èéṣe tí a fi lè sọ pẹ̀lú ìdánilójú pé ìfẹ́ kìí yẹ̀ láé?
14 Wàyí o ohun tí ó kẹ́yìn tí ìfẹ́ kìí ṣe: “Ìfẹ́ kìí yẹ̀ láé.” Ohun kan ni pé, ìfẹ́ kìí yẹ̀ láé tàbí dópin nítorí pé Ọlọrun jẹ́ ìfẹ́, òun sì ni “Ọba ayérayé.” (1 Timoteu 1:17) Ní Romu 8:38, 39, a mú un dá wa lójú pé ìfẹ́ Jehofa fún wa kò ní yẹ̀ láé: “Ó dá mi lójú pé, kìí ṣe ikú, tàbí ìyè, tàbí àwọn angẹli, tàbí àwọn ìjòyè, tàbí àwọn alágbára, tàbí ohun ìgbà ìsinsìnyí, tàbí ohun ìgbà tí ń bọ̀ tàbí òkè, tàbí ọ̀gbun, tàbí ẹ̀dá mìíràn kan ni yóò lè yà wá kúrò nínú ìfẹ́ Ọlọrun, tí ó wà nínú Kristi Jesu Oluwa wa.” Pẹ̀lúpẹ̀lú, ìfẹ́ kìí yẹ̀ láé níti pé kò jẹ́ ṣaláìtó láé. Ìfẹ́ kájú àkókò ìṣẹ̀lẹ̀ èyíkéyìí, ó kájú ìpèníjà èyíkéyìí.
Àwọn Ohun tí Ìfẹ́ Jẹ́
15. Èéṣe ti Paulu fi kọ́kọ́ ṣe ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìpamọ́ra láàárín àwọn apá-ìhà agbéniró ti ìfẹ́?
15 Ní fífàbọ̀ sórí apá tí ń gbéniró wàyí, àwọn ohun tí ìfẹ́ jẹ́, Paulu bẹ̀rẹ̀ pé: “Ìfẹ́ a máa ní ìpamọ́ra.” A ti sọ pé kò lè sí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ bíi ìdàpọ̀ Kristian láìsí ìpamọ́ra, ìyẹn ni, láìsí fífi sùúrù faradà á fún ẹnìkínní kejì. Ìyẹn rí bẹ́ẹ̀ nítorí pé gbogbo wa jẹ́ aláìpé, àìpé àti àìdójú-ìwọ̀n wa sì ń dán àwọn ẹlòmíràn wò. Abájọ tí aposteli Paulu fi kọ́kọ́ ṣètòlẹ́sẹẹsẹ apá-ìhà yìí nípa ohun tí ìfẹ́ jẹ́!
16. Ní àwọn ọ̀nà wo ni àwọn mẹ́ḿbà ìdílé kan lè gbà fi inúrere hàn sí araawọn ẹnìkínní kejì?
16 Paulu sọ pé ìfẹ́ tún jẹ́ “onínúure.” Ìyẹn ni pé, ìfẹ́ jẹ́ arannilọ́wọ́, onírònújinlẹ̀, olùgba ti àwọn ẹlòmíràn rò. Inúrere ń fi araarẹ̀ hàn nínú àwọn ohun ńlá àti kékeré. Dájúdájú aláàánú ará Samaria náà fi inúrere hàn sí ọkùnrin tí àwọn dánàdánà dá lọ́nà. (Luku 10:30-37) Ìfẹ́ ní inúdídùn nínú sísọ pé “jọ̀wọ́.” Láti sọ pé, “Nawọ́ búrẹ́dì yẹn sí mi” jẹ́ àṣẹ kan. Láti bẹ̀rẹ̀ ìyẹn pẹ̀lú “jọ̀wọ́” mú kí ó di ẹ̀bẹ̀ kan. Àwọn ọkọ jẹ́ onínúure sí àwọn aya wọn nígbà tí wọ́n bá kọbiara sí ìmọ̀ràn 1 Peteru 3:7 pé: “Ẹ̀yin ọkọ, ẹ máa fi òye bá àwọn aya yín gbé, ẹ máa fi ọlá fún aya, bí ohun èèlò tí kò lágbára, àti pẹ̀lú bí ajùmọ̀-jogún oore-ọ̀fẹ́ ìyè; kí àdúrà yín kí ó má baà ní ìdènà.” Àwọn aya jẹ́ onínúure sí àwọn ọkọ wọn nígbà tí wọ́n bá fi “ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀” hàn fún wọn. (Efesu 5:33, NW) Àwọn bàbá jẹ́ onínúure sí àwọn ọmọ wọn nígbà tí wọ́n bá tẹ̀lé ìmọ̀ràn tí ó wà ní Efesu 6:4: “Ẹ̀yin bàbá, ẹ máṣe mú àwọn ọmọ yín bínú: ṣùgbọ́n ẹ máa tọ́ wọn nínú ẹ̀kọ́ àti ìkìlọ̀ Oluwa.”
17. Ní àwọn ọ̀nà méjì wo ni ìfẹ́ gbà ń yọ̀ pẹ̀lú òtítọ́?
17 Ìfẹ́ kìí yọ̀ lórí àìṣòdodo ṣùgbọ́n “ó ń yọ̀ pẹ̀lú òtítọ́.” Ìfẹ́ àti òtítọ́ jọ ń rìn ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ ni—Ọlọrun jẹ́ ìfẹ́, àti ní àkókò kan-náà, òun ni “Ọlọrun òtítọ́.” (Orin Dafidi 31:5) Ìfẹ́ ń yọ̀ ní rírí i kí òtítọ́ yọ ayọ̀ ìṣẹ́gun lórí èké kí ó sì tú u fó; èyí pèsè àlàyé ní apákan fún ìbísí ńláǹlà tí ń wáyé nínú iye àwọn olùjọ́sìn Jehofa lónìí. Bí ó ti wù kí ó rí, níwọ̀n bí òtítọ́ ti yàtọ̀ gédégédé sí àìṣòdodo, èrò náà tún lè jẹ́ pé ìfẹ́ ń yọ̀ pẹ̀lú òdodo. Ìfẹ́ ń yọ̀ nítorí ìṣẹ́gun òdodo, gẹ́gẹ́ bí a ti pàṣẹ fún àwọn olùjọ́sìn Jehofa láti ṣe nígbà ìṣubú Babiloni Ńlá.—Ìfihàn 18:20.
18. Ní èrò ìtumọ̀ wo ni ìfẹ́ gbà ń mú ohun gbogbo mọ́ra?
18 Paulu tún sọ fún wa pé ìfẹ́ “ń mú ohun gbogbo mọ́ra.” Gẹ́gẹ́ bí Kingdom Interlinear ti fihàn, èrò náà ni pé ìfẹ́ ń borí ohun gbogbo. Kìí “rojọ́ àṣìṣe” arákùnrin, gẹ́gẹ́ bí àwọn olùṣe búburú ti máa ń nítẹ̀sí láti ṣe. (Orin Dafidi 50:20, NW; Owe 10:12; 17:9) Bẹ́ẹ̀ni, èrò náà tí ó wà níhìn-ín rí bákan náà bíi ti 1 Peteru 4:8: “Ìfẹ́ ní ń bo ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ mọ́lẹ̀.” Dájúdájú, ìdúróṣinṣin kò ní jẹ́ kí ẹnìkan bo àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wíwúwo lòdìsí Jehofa àti lòdìsí ìjọ Kristian mọ́lẹ̀.
19. Ní ọ̀nà wo ni ìfẹ́ gbà ń gba ohun gbogbo gbọ́?
19 Ìfẹ́ “ń gba ohun gbogbo gbọ́.” Ìfẹ́ jẹ́ agbéniró, kìí ṣe aláìgbéniró. Èyí kò túmọ̀ sí pé ìfẹ́ jẹ́ adùn-ún-tànjẹ. Kìí yára gba àwọn gbólóhùn elérò-ìmọ̀lára gbọ́. Ṣùgbọ́n fún ẹnìkan láti wá ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọrun, olúwarẹ̀ gbọ́dọ̀ ní ìfẹ́-inú láti gbàgbọ́. Nítorí náà ìfẹ́ kìí ṣe ẹlẹ́mìí tàbí-tàbí, aṣelámèyítọ́ láìnídìí. Kìí dènà gbígbàgbọ́ gẹ́gẹ́ bí àwọn aláìgbọlọ́rungbọ́ tií ṣe, àwọn tí wọ́n ń fi gbígbà láìjanpata sọ pé kò sí Ọlọrun, bẹ́ẹ̀ ni kìí ṣe bí àwọn onígbàgbọ́ Ọlọrun kò ṣeémọ̀, tí wọ́n fi gbígbà láìjanpata tẹnumọ́ ọn pé kò wulẹ̀ ṣeéṣe láti mọ ibi tí a ti wá, ìdí tí a fi wà níhìn-ín, àti ohun tí ọjọ́-ọ̀la yóò jẹ́. Ọ̀rọ̀ Ọlọrun fún wa ní ìdánilójú nípa gbogbo nǹkan wọ̀nyí. Ìfẹ́ tún ṣetán láti gbàgbọ́ nítorí pé ó ń nígbẹ̀ẹ́kẹ̀lé, kìí ṣe afura láìnídìí.
20. Báwo ni a ṣe so ìfẹ́ pọ̀ mọ́ ìrètí?
20 Aposteli Paulu mú un dá wa lójú síwájú síi pé ìfẹ́ “ń retí ohun gbogbo.” Níwọ̀n bí ìfẹ́ ti jẹ́ agbéniró, tí kìí ṣe aláìgbéniró, ó ní ìrètí lílágbára nínú gbogbo ohun tí a ṣèlérí nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọrun. A sọ fún wa pé: “Kí ẹni tí ń túlẹ̀ kí ó lè máa túlẹ̀ ní ìrètí; àti ẹni tí ń pakà, kí ó lè ní ìrètí àti ṣe olùbápín nínú rẹ̀.” (1 Korinti 9:10) Àní gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ ti kún fún ìgbẹ́kẹ̀lé, ó tún kún fún ìrètí, ó ń retí ohun dídára jùlọ nígbà gbogbo.
21. Ìdánilójú Ìwé Mímọ́ wo ni ó wà pé ìfẹ́ ń faradà?
21 Níkẹyìn, a mú un dá wa lójú pé ìfẹ́ “ń farada ohun gbogbo.” Ó lè ṣe bẹ́ẹ̀ nítorí ohun tí aposteli Paulu sọ fún wa ní 1 Korinti 10:13: “Kò sí ìdánwò kan tí ó tíì bá yín, bíkòṣe irú èyí tí ó mọ níwọ̀n fún ènìyàn: ṣùgbọ́n olódodo ni Ọlọrun, ẹni tí kì yóò jẹ́ kí á dán yín wò ju bí ẹ̀yin ti lè gbà; ṣùgbọ́n tí yóò sì ṣe ọ̀nà àtiyọ pẹ̀lú nínú ìdánwò náà, kí ẹ̀yin kí ó baà lè gbà á.” Ìfẹ́ yóò mú wa kíyèsí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àpẹẹrẹ nínú Ìwé Mímọ́ nípa àwọn ìráńṣẹ́ Ọlọrun tí wọ́n ti faradà, nínú àwọn ẹni tí Jesu Kristi jẹ́ olórí, gẹ́gẹ́ bí a ti rán wa létí ní Heberu 12:2, 3.
22. Gẹ́gẹ́ bí ọmọ Ọlọrun, ànímọ́ títayọlọ́lá wo ni a gbọ́dọ̀ máa dàníyàn nígbà gbogbo láti fihàn?
22 Lóòótọ́, ìfẹ́ (a·gaʹpe) ni ànímọ́ títayọlọ́lá ti àwa gẹ́gẹ́ bíi Kristian, Ẹlẹ́rìí Jehofa, níláti mú dàgbà, níti ohun tí kò jẹ́ àti níti ohun tí ó jẹ́. Gẹ́gẹ́ bí ọmọ Ọlọrun, ǹjẹ́ kí àwa máa dàníyàn nígbà gbogbo pẹ̀lú fífi èso ẹ̀mí Ọlọrun yìí hàn. Láti ṣe bẹ́ẹ̀ jẹ́ láti dàbí Ọlọrun, nítorí, rántí pé, “Ọlọrun jẹ́ ìfẹ́.”
Ìwọ Ha Rántí Bí?
◻ Báwo ni Jesu Kristi àti Paulu ṣe fi ìtayọlọ́lá ìfẹ́ hàn?
◻ Ìfẹ́ kìí jowú, lọ́nà wo?
◻ Báwo ni ìfẹ́ ṣe “ń gba ohun gbogbo mọ́ra”?
◻ Èéṣe tí a fi lè sọ pé ìfẹ́ kìí yẹ̀ láé?
◻ Ní àwọn ọ̀nà méjì wo ni ìfẹ́ gbà ń yọ̀ pẹ̀lú òtítọ́?
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 21]
ÌFẸ́ (AGAPE)
Ohun tí Kò Jẹ́ Ohun tí Ó Jẹ́
1. Kìí jowú 1. Ó nípamọ́ra
2. Kìí fọ́nnu 2. Ó nínúure
3. Kìí wú fùkẹ̀ 3. Ń yọ̀ pẹ̀lú òtítọ́
4. Kìí hùwà lọ́nà àìbójúmu 4. Ń mú ohun gbogbo mọ́ra
5. Kìí wá ire ti ara rẹ̀ nìkan 5. Ń gba ohun gbogbo gbọ́
6. Kìí di ẹni tí a tán ní sùúrù 6. Ń retí ohun gbogbo
7. Kìí kọ àkọsílẹ̀ nípa ìṣeniléṣe 7. Ń farada ohun gbogbo
8. Kìí yọ̀ lórí àìṣòdodo
9. Kìí yẹ̀ láé
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Jehofa rẹ Nebukadnessari sílẹ̀ nítorí fífọ́nnu