Ìyàsímímọ́—Fún Ta Ni?
“Gbogbo èyí tí OLUWA wí ni àwa ó ṣe, àwa ó sì gbọ́ràn.”—EKSODU 24:7.
1, 2. (a) Kí ni àwọn ènìyàn kan ní ìfọkànsìn fún? (b) Ìyàsímímọ́ ha mọ́ sọ́dọ̀ àwọn wọnnì tí wọ́n ní ìṣepọ̀ pẹ̀lú ìsìn bí?
NÍ February 1945, a pe àwọn awakọ̀ òfúúrufú Zero tí a fi ń jagun tí ó jẹ́ ti ẹ̀ka ẹgbẹ́ ọmọ ogun Yatabe Flying Corps ti ilẹ̀ Japan jọ sí gbọ̀ngàn ńlá kan. A fún ẹnìkọ̀ọ̀kan ní pépà pélébé lórí èyí tí òun yóò kọ ọ́ sí yálà òun yóò yọ̀ǹda láti di mẹ́ḿbà ẹgbẹ́ ọmọ ogun afọkọ̀ òfúúrufú jagun. Ọ̀gágun kan tí ó wà níbẹ̀ nígbà yẹn sọ pé: “Mo ronú pé ojúṣe mi ní ó jẹ́ láti fi ara mi rúbọ ní àkókò rúkèrúdò orílẹ̀-èdè. Níwọ̀n bí mo ti nímọ̀lára pé kí n mú ara mi wà lárọ̀ọ́wọ́tó, mo yọ̀ọ̀da ara mi fún iṣẹ́ àkànṣe náà.” A dá a lẹ́kọ̀ọ́ nípa bí a ṣe ń lo ọkọ̀ òfúúrufú Ohka (ọkọ̀ rọ́kẹ́ẹ̀tì tí a fi ń panirun) àti bí a ṣe ń wà á kí a sì fi fọ́ ọkọ ogun ojú-omi ti àwọn ọ̀tá túútúú. Bí ó ti wù kí ó rí, ogun náà parí ṣáájú kí ó tó ní àǹfààní láti ṣe bẹ́ẹ̀ kí ó sì tipa bẹ́ẹ̀ kú fún orílẹ̀-èdè rẹ̀ àti olú-ọba rẹ̀. Ìgbàgbọ́ rẹ̀ nínú olú-ọba wọmi nígbà tí Japan pàdánù ogun náà.
2 Nígbà kan rí, ọ̀pọ̀ àwọn tí ń gbé ní Japan ní ìfọkànsìn fún olú-ọba, ẹni tí wọ́n gbàgbọ́ pé òun ni ọlọrun tí ń bẹ láàyè. Ní àwọn ilẹ̀ mìíràn, àwọn nǹkan mìíràn tí àwọn ènìyàn ń jọ́sìn ti wà wọ́n sì wà síbẹ̀síbẹ̀. Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ni ó ní ìfọkànsìn fún Maria, Buddha, tàbí àwọn ọlọrun mìíràn—tí àwọn òrìṣà sábà máa ń ṣojú fún. Nítorí ipa ìdarí tí ọ̀rọ̀ dídùn tí ń ru ìmọ̀lára sókè ti ní lórí wọn, àwọn kan ti da owó tí wọ́n làágùn kí wọ́n to rí sínú àpò àwọn ajíhìnrere orí tẹlifíṣọ̀n nínú ìsapá àfitọkàntọkànṣe tí ó ṣe rẹ́gí pẹ̀lú ìfọkànsìn wọn. Lẹ́yìn ogun náà, àwọn ará Japan tí wọ́n ní ìjákulẹ̀ wá ohun titun mìíràn tí wọ́n lè ya ìgbésí-ayé wọn sí mímọ́ fún. Fún àwọn kan, iṣẹ́ di ohun náà. Yálà ní Ìlà-Oòrùn tàbí Ìwọ̀-Oòrùn, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ya ara wọn sí mímọ́ fún kíkó ọrọ̀ jọ. Àwọn ọ̀dọ́ kọ́ ìgbésí ayé wọn yíká àwọn olórin, tí wọ́n sì ń ṣe àfarawé ọ̀nà ìgbésí-ayé wọn. Iye tí ó pọ̀ tìrìgàngàn lónìí ti di olùjọ́sìn ara wọn, ní sísọ àwọn ìfẹ́-ọkàn wọn di ohun tí wọ́n ní ìfọkànsìn fún. (Filippi 3:19; 2 Timoteu 3:2) Ṣùgbọ́n níti gidi ó ha yẹ kí ẹnì kan fún irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ tàbí àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ ní ìfọkànsìn tọkàntọkàn níti gidi bí?
3. Báwo ni díẹ̀ lára àwọn nǹkan tí àwọn ènìyàn ń fún ní ìfọkànsìn ṣe jásí èyí tí kò níláárí?
3 Nígbà tí wọ́n bá dojúkọ ohun tí ó jẹ́ òtítọ́ gidi, ọkàn àwọn olùjọ́sìn òrìṣà sábà máa ń bàjẹ́. Ìfọkànsìn fún òrìṣà máa ń yọrísí ìjákulẹ̀ nígbà tí àwọn olùjọ́sìn náà bá mọ̀ pé àwọn òrìṣà wọn wulẹ̀ jẹ́ “iṣẹ́ ọwọ́ ènìyàn.” (Orin Dafidi 115:4) Nígbà tí a bá tú àṣírí ìwà ìbàjẹ́ àwọn gbajúgbajà ajíhìnrere, àwọn ènìyàn olótìítọ́ ọkàn máa ń nímọ̀lára pé a já wọn kulẹ̀. Nígbà tí ọrọ̀-ajé “rírọ̀ṣọ̀mù” bá fọ́ yángá, àwọn òṣìṣẹ́ máa ń ní ìrírí ìṣiṣẹ́gbòdì ọpọlọ bí wọ́n ṣe ń rí ara wọn lára àwọn wọnnì tí a lé kúrò lẹ́nu iṣẹ́. Ọrọ̀-ajé tí ó lọsílẹ̀ ní lọ́ọ́lọ́ọ́ fi àjẹkún ìyà jẹ́ àwọn olùjọ́sìn Mammoni. Gbèsè tí wọ́n tọrùnbọ̀ pẹ̀lú ìrètí rírí owó tabua di ẹrù-inira kò sí dájú pé wọ́n lè san gbèsè tí wọ́n jẹ padà. (Matteu 6:24, àkíyèsí-ẹsẹ̀-ìwé, New World Translation of the Holy Scriptures—With References) Nígbà tí àwọn ìlú-mọ̀ọ́ká olórin rọ́ọ̀kì àti àwọn eléré-ìnàjú mìíràn tí a ti sọ dòrìṣà bá kú tàbí tí ìgbà wọn bá kọjá lọ, àwọn olùjọ́sìn wọn máa ń di ẹni àpatì. Àwọn wọnnì tí wọ́n sì ti rìn ní ọ̀nà ìtẹ́ra-ẹni-lọ́rùn sábà máa ń kórè èso kíkan.—Galatia 6:7.
4. Kí ni ń sun àwọn ènìyàn láti ya ìgbésí-ayé wọn sí mímọ́ fún àwọn ohun tí kò níláárí?
4 Kí ní ń sún àwọn ènìyàn láti ya ara wọn sí mímọ́ fún irú ohun tí kò níláárí bẹ́ẹ̀? Títí dé àyè tí ó yẹ fún àfiyèsí, ó jẹ́ ẹ̀mí ayé tí ń bẹ lábẹ́ Satani Èṣù. (Efesu 2:2, 3) A ń rí ipa ìdarí ẹ̀mí yìí ní onírúurú ọ̀nà. Àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ ìdílé tí àwọn babańlá ẹnì kan ti fi lélẹ̀ lè máa darí rẹ̀. Ẹ̀kọ́-ìwé àti ọ̀nà tí a gbà tọ́nidàgbà lè ní ipa ìdarí lílágbára lórí ọ̀nà ìgbàronú. Ipò bí nǹkan ṣe ń lọ sí lẹ́nu iṣẹ́ lè sọ “àwọn ọ̀gá àgbà lẹ́nu iṣẹ́ ọ́fíìsì” di ẹni tí ń ṣe iṣẹ́ àṣekúdórógbó tí ó lè wu ìwàláàyè wọn léwu. Ìṣarasíhùwà onífẹ̀ẹ́ ọrọ̀-àlùmọ́nì ayé ni ó ń fa ìfẹ́-ọkàn láti ní púpọ̀ síi. A ti kéèràn ran ọkàn-àyà ọ̀pọ̀lọpọ̀, tí ó sì ń sún wọn láti fi ara wọn jìn fún ìfẹ́-ọkàn onímọtara-ẹni-nìkan tiwọn. Wọ́n kùnà láti ṣàyẹ̀wò yálà àwọn ìlépa wọ̀nyí yẹ fún irúfẹ́ ìfọkànsìn bẹ́ẹ̀.
Orílẹ̀-Èdè Tí A Yàsímímọ́
5. Ìyàsímímọ́ wo fún Jehofa ni a ṣe ní ohun tí ó lé ní 3,500 ọdún sẹ́yìn?
5 Ní nǹkan tí ó lé ní 3,500 ọdún sẹ́yìn, gbogbo ènìyàn orílẹ̀-èdè kan rí ohun kan tí ó yẹ láti jọ́sìn gan-an. Wọ́n ya ara wọn sí mímọ́ fún Ọlọrun ọba aláṣẹ, Jehofa. Gẹ́gẹ́ bí àwùjọ kan, orílẹ̀-èdè Israeli polongo ìyàsímímọ́ ara rẹ̀ fún Ọlọrun ní aginjù Sinai.
6. Kí ni ó ti níláti jẹ́ ìjẹ́pàtàkì orúkọ Ọlọrun fún àwọn ọmọ Israeli?
6 Kí ni ó sún àwọn ọmọ Israeli láti hùwà lọ́nà yìí? Nígbà tí wọ́n wà ní oko-ẹrú ní Egipti, Jehofa fi àṣẹ fún Mose láti ṣáájú wọn lọ sí ilẹ̀ òmìnira. Mose béèrè bí òun yóò ṣe ṣàpèjúwe Ọlọrun tí ó rán òun, Ọlọrun sì ṣí ara rẹ̀ payá gẹ́gẹ́ bí “èmi yóò jásí ohun tí èmi yóò jásí.” Ó darí Mose láti sọ fún àwọn ọmọ Israeli pé: “Èmi yóò jásí ni ó rán mi sí yín.” (Eksodu 3:13, 14, NW) Gbólóhùn yìí fi hàn pé Jehofa ń di ohunkóhun yòówù tí ó bá pọndandan láti lè ṣe àṣeparí àwọn ète rẹ̀. Òun yóò ṣí ara rẹ̀ payá gẹ́gẹ́ bí Olùṣèmúṣẹ àwọn ìlérí lọ́nà kan tí àwọn babańlá àwọn ọmọ Israeli kò tí ì mọ̀ rí.—Eksodu 6:2, 3.
7, 8. Ẹ̀rí wo ni àwọn ọmọ Israeli ní pé Jehofa jẹ́ Ọlọrun tí ó yẹ fún wọn láti fọkànsìn?
7 Àwọn ọmọ Israeli fojúrí ìpọ́njú tí Ìyọnu Mẹ́wàá mú wá sórí ilẹ̀ Egipti àti àwọn ènìyàn rẹ̀. (Orin Dafidi 78:44-51) Lẹ́yìn náà, iye tí ó ṣeé ṣe kí ó lé ní million mẹ́ta lára wọn, títíkan àwọn obìnrin àti ọmọdé, palẹ̀ mọ́ wọ́n sì jáde kúrò ní ilẹ̀ Goṣeni ní òru ọjọ́ kan, èyí tí ó jẹ́ ohun àrà pípẹtẹrí fúnra rẹ̀. (Eksodu 12:37, 38) Lẹ́yìn èyí, ní Òkun Pupa, Jehofa fi ara rẹ̀ hàn gẹ́gẹ́ bí “akin ọkùnrin ogun” nígbà tí ó gba àwọn ènìyàn rẹ̀ la kúrò lọ́wọ́ ẹgbẹ́ ọmọ ogun Farao nípa pínpín òkun níyà kí àwọn ọmọ Israeli baà lè kọjá àti lẹ́yìn náà nípa pípa á dé kí àwọn ọmọ Egipti tí ń lépa wọn baà lè rì. Gẹ́gẹ́ bí ìyọrísí rẹ̀, “Israeli sì rí iṣẹ́ ńlá tí OLUWA ṣe lára àwọn ará Egipti: àwọn ènìyàn náà sì bẹ̀rù OLUWA, wọ́n sì gba OLUWA . . . gbọ́.”—Eksodu 14:31; 15:3, NW; Orin Dafidi 136:10-15.
8 Bí ẹni pé wọn kò ní ẹ̀rí fún ohun tí orúkọ Ọlọrun túmọ̀ sí, àwọn ọmọ Israeli kùn sí Jehofa àti sí aṣojú rẹ̀ Mose nípa àìtó oúnjẹ àti omi. Jehofa fi àparò ránṣẹ́, ó rọ̀jò mana, ó sì mú kí omi tú jáde láti inú àpáta ní Meriba. (Eksodu 16:2-5, 12-15, 31; 17:2-7) Jehofa tún gba àwọn ọmọ Israeli là lọ́wọ́ ìgbéjàkoni àwọn Amaleki. (Eksodu 17:8-13) Kò sí ọ̀nà kankan tí àwọn ọmọ Israeli lè gbà sẹ́ ohun tí Jehofa sọ fún Mose lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn pé: “Jehofa, Jehofa, Ọlọrun aláàánú àti olóore-ọ̀fẹ́, ẹni tí ó lọ́ra láti bínú tí ó sì pọ̀ jùlọ ní inúrere-ìfẹ́ àti òtítọ́, ẹni tí ń pa inúrere-ìfẹ́ mọ́ fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún, tí ń dárí ìṣìnà àti ìrélànàkọjá àti ẹ̀ṣẹ̀ jì.” (Eksodu 34:6, 7, NW) Níti tòótọ́, Jehofa fi ara rẹ̀ hàn gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó yẹ kí wọ́n fi ìfọkànsìn wọn fún.
9. Èéṣe tí Jehofa fi fún àwọn ọmọ Israeli ní àǹfààní láti sọ̀rọ̀ nípa ìyàsímímọ́ wọn láti ṣiṣẹ́sìn ín, báwo sì ni wọ́n ṣe dáhùnpadà?
9 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Jehofa ní ẹ̀tọ́ sí jíjẹ́ olówó àwọn ọmọ Israeli nítorí pé ó ti rà wọ́n padà kúrò ní Egipti, òun, gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun olóore-ọ̀fẹ́ àti aláàánú, fínnúfíndọ̀ fún wọn ní àǹfààní náà láti sọ ìfẹ́-ọkàn wọn jáde láti ṣiṣẹ́sìn ín. (Deuteronomi 7:7, 8; 30:15-20) Ó tún gbé àwọn ipò tí májẹ̀mú tí ń bẹ láàárín òun àti àwọn ọmọ Israeli sinmi lé kalẹ̀. (Eksodu 19:3-8; 20:1–23:33) Nígbà tí Mose sọ àwọn ipò wọ̀nyí, àwọn ọmọ Israeli polongo pé: “Gbogbo èyí tí OLUWA wí ni àwa ó ṣe, àwa ó sì gbọ́ràn.” (Eksodu 24:3—7) Láti inú òmìnira ìfẹ́-inú wọn, wọ́n di orílẹ̀-èdè tí a yàsímímọ́ fún Jehofa Oluwa Ọba Aláṣẹ.
Ìmọrírì Ń Yọrísí Ìyàsímímọ́
10. Lórí kí ni a níláti gbé ìyàsímímọ́ wa fún Jehofa kà?
10 Jehofa, Ẹlẹ́dàá, ṣì ń bá a nìṣó ní yíyẹ fún ìfọkànsìn tọkàntọkàn wa. (Malaki 3:6; Matteu 22:37; Ìṣípayá 4:11) Bí ó ti wù kí ó rí, a kò níláti gbé ìyàsímímọ́ wa karí ìgbàgbọ́ oréfèé, èrò-ìmọ̀lára tí ń yára pòórá, tàbí ìfipámúni láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹlòmíràn—àní àwọn òbí pàápàá. A gbọ́dọ̀ gbé e karí ìmọ̀ pípéye ti òtítọ́ nípa Jehofa àti ìmọrírì fún ohun tí Jehofa ti ṣe fún wa. (Romu 10:2; Kolosse 1:9, 10; 1 Timoteu 2:4) Gan-an gẹ́gẹ́ bí Jehofa ti fi tinútinú fún àwọn ọmọ Israeli ní àǹfààní láti fi ìyàsímímọ́ wọn hàn jáde, bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ni ó fi tinútinú fún wa ní àyè láti ya ara wa sí mímọ́ kí a sì sọ ìyàsímímọ́ yẹn di mímọ̀ ní gbangba.—1 Peteru 3:21.
11. Kí ni ìkẹ́kọ̀ọ́ wa nínú Bibeli ti ṣí payá nípa Jehofa?
11 Nípasẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli, a ti wá mọ Ọlọrun gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ràn wá lọ́wọ́ láti finúmòye àwọn ànímọ́ rẹ̀ bí ó ṣe hàn lára àwọn ìṣẹ̀dá rẹ̀. (Orin Dafidi 19:1-4) A lè rí i láti inú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé òun kì í ṣe àdììtú Mẹ́talọ́kan tí a kò lè lóye. Kì í fìdí rẹmi lójú ogun nípa bẹ́ẹ̀ kò sí ìdí fún un láti kọ ipò jíjẹ́ Ọlọrun rẹ̀ sílẹ̀. (Eksodu 15:11; 1 Korinti 8:5, 6; Ìṣípayá 11:17, 18) Nítorí pé ó ti mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ, a rán wa létí ohun tí orúkọ rẹ̀ rírẹwà, Jehofa, dúró fún. Òun ni Atóbilọ́lá Olùpète. (Genesisi 2:4, àkíyèsí-ẹsẹ̀-ìwé New World Translation of the Holy Scriptures—With References; Orin Dafidi 83:18; Isaiah 46:9-11) Nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli, a wá lóye ní kedere bí òun ti jẹ́ olùṣòtítọ́ àti ẹni tí ó ṣeé gbẹ́kẹ̀lé tó.—Deuteronomi 7:9; Orin Dafidi 19:7, 9; 111:7.
12. (a) Kí ni ó fà wá mọ́ Jehofa? (b) Báwo ni àwọn ìrírí ìgbésí-ayé tí ó jẹ́ òtítọ́ gidi tí a kọ sílẹ̀ sínú Bibeli ṣe ń sún wa láti fẹ́ láti ṣiṣẹ́sin Jehofa? (d) Kí ni ìmọ̀lára rẹ nípa ṣíṣiṣẹ́sin Jehofa?
12 Ní pàtàkì ohun tí ó fà wá mọ́ Jehofa ni ànímọ́ onífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Bibeli fi bí ó ṣe jẹ́ onífẹ̀ẹ́, adáríjini, àti aláàánú tó nínú ìbálò rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ẹ̀dá ènìyàn hàn. Ronú nípa bí ó ṣe mú kí Jobu ní aásìkí lẹ́yìn tí Jobu ti fi ìṣòtítọ́ pa ìwàtítọ́ rẹ̀ mọ́. Ìrírí Jobu fi hàn kedere pé “Jehofa jẹ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ gidigidi ninu ìfẹ́ni ó sì jẹ́ aláàánú.” (Jakọbu 5:11, NW; Jobu 42:12-17) Ronú nípa bí Jehofa ṣe bá Dafidi lo nígbà tí ó dẹ́ṣẹ̀ panṣágà àti ìpànìyàn. Bẹ́ẹ̀ni, Jehofa ṣetán láti dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí ó wúwo pàápàá jì nígbà tí ẹlẹ́ṣẹ̀ bá tọ̀ ọ́ lọ pẹ̀lú “ìròbìnújẹ́ àti ìrora àyà.” (Orin Dafidi 51:3-11, 17) Ronú nípa ọ̀nà tí Jehofa gbà bá Saulu ara Tarsu lò, ẹni tí ó jẹ́ aṣenúnibíni láìdábọ̀ sí àwọn ènìyàn Ọlọrun. Àwọn àpẹẹrẹ wọ̀nyí fi àánú Ọlọrun àti ìmúratán fàlàlà láti lo àwọn wọnnì tí wọ́n bá ronúpìwàdà hàn kedere. (1 Korinti 15:9; 1 Timoteu 1:15, 16) Paulu nímọ̀lára pé òun lè fi ìgbésí-ayé òun jìn fún ṣíṣiṣẹ́sin Ọlọrun onífẹ̀ẹ́ yìí. (Romu 14:8) Ìwọ ha nímọ̀lára lọ́nà kan náà bí?
13. Ìfihàn ìfẹ́ lọ́nà títóbi wo níhà ọ̀dọ̀ Jehofa ni ó ń sọ ọ́ di ọ̀ranyàn fún àwọn ọlọ́kàn-àyà títọ́ láti ya ara wọn sí mímọ́ fún un?
13 Fún àwọn ọmọ Israeli, Jehofa pèsè ìgbàlà kúrò nínú ìdè-ẹrú Egipti, ó sì ti ṣètò ọ̀nà kan láti gbà wá lọ́wọ́ ìdè-ẹrú ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú—ẹbọ ìràpadà Jesu Kristi. (Johannu 3:16) Paulu sọ pé: “Ọlọrun dámọ̀ràn ìfẹ́ tirẹ̀ fún ìtẹ́wọ́gbà wa níti pé, nígbà tí awa ṣì jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, Kristi kú fún wa.” (Romu 5:8, NW) Ìṣètò onífẹ̀ẹ́ yìí sọ ọ́ di ọ̀ranyàn fún àwọn ọlọ́kàn-àyà títọ́ láti ya ara wọn sí mímọ́ fún Jehofa nípasẹ̀ Jesu Kristi. “Nitori ìfẹ́ tí Kristi ní sọ ọ́ di ọ̀ranyàn fún wa, nitori èyí ni ohun tí awa ti ṣèdájọ́, pé ọkùnrin kan kú fún gbogbo ènìyàn; nitori bẹ́ẹ̀, nígbà naa, gbogbo wọ́n ti kú; oun sì kú fún gbogbo wọn kí awọn wọnnì tí ó wà láàyè máṣe tún wà láàyè fún ara wọn mọ́, bíkòṣe fún ẹni tí ó kú fún wọn tí a sì gbé dìde.”—2 Korinti 5:14, 15, NW; Romu 8:35-39.
14. Níní ìmọ̀ lásán nípa àwọn ìbálò Jehofa ha ti tó láti sún wa láti ya ìgbésí-ayé wa sí mímọ́ fún un bí? Ṣàlàyé.
14 Síbẹ̀síbẹ̀, níní ìmọ̀ nípa àkópọ̀ ànímọ́ Jehofa àti ìbálò rẹ̀ pẹ̀lú aráyé kò tó. A gbọ́dọ̀ mú ìmọrírì ara-ẹni fún Jehofa dàgbà. Báwo ni a ṣe lè ṣe ìyẹn? Nípa fífi Ọ̀rọ̀ Ọlọrun sílò nínú ìgbésí-ayé wa kí a sì rí i fúnra wa pé àwọn ìlànà tí a rí nínú rẹ̀ ń ṣiṣẹ́ níti gidi. (Isaiah 48:17) A níláti nímọ̀lára pé Jehofa ti yọ wá kúrò nínú ẹrẹ̀ ayé búburú yìí tí ń bẹ lábẹ́ àkóso Satani. (Fiwé 1 Korinti 6:11.) Nínú ìjàkadì wa láti ṣe ohun tí ó tọ́, a ń kọ́ láti gbáralé Jehofa, a sì ń ní ìrírí rẹ̀ fúnra wa pé Jehofa ni Ọlọrun alààyè, “Olùgbọ́ àdúrà.” (Orin Dafidi 62:8; 65:2) Láìpẹ́ láìjìnnà a óò nímọ̀lára wíwà pẹ́kípẹ́kí pẹ̀lú rẹ̀ yóò sì ṣeé ṣe fún wa láti sọ àwọn ìmọ̀lára tí ń bẹ nínú wa lọ́hùn-ún fún un. Ìmọ̀lára ọlọ́yàyà ti ìfẹ́ fún Jehofa yóò dàgbà nínú wa. Kò sí iyèméjì pé èyí yóò ṣamọ̀nà wa láti ya ìgbésí-ayé wa sí mímọ́ fún un.
15. Kí ni ó sún ọkùnrin kan, tí ó ti fi ara jìn fún iṣẹ́ tẹ́lẹ̀rí, láti ṣiṣẹ́sin Jehofa?
15 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ti wá láti wá mọ Ọlọrun onífẹ̀ẹ́ yìí, Jehofa, wọ́n sì ti ya ìgbésí-ayé wọn sí mímọ́ láti ṣiṣẹ́sìn ín. Gbé àpẹẹrẹ oníṣẹ́ iná mànàmáná kan tí ó ní iṣẹ́-ajé tí ń gbèrú yẹ̀wò. Àwọn àkókò kan wà tí òun yóò bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní àárọ̀ tí yóò sì ṣiṣẹ́ jálẹ̀ gbogbo ọjọ́ títí di ààjìn òru, tí yóò sì padà wálé ní aago márùn-ún ìdájí ọjọ́ kejì. Lẹ́yìn sísinmi fún nǹkan bí wákàtí kan, yóò jáde lọ fún iṣẹ́ mìíràn. Ó rántí pé: “Mo farajìn fún iṣẹ́ mi.” Nígbà tí aya rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bibeli, ó darapọ̀ mọ́ ọn. Ó sọ pé: “Gbogbo àwọn ọlọrun tí mo ti mọ̀ títí di àkókò yẹn wulẹ̀ ń dúró kí a máa sìn wọ́n, láìṣe ohunkóhun láti ṣe wá láǹfààní. Ṣùgbọ́n Jehofa lo ọgbọ́n àtinúdá ó sì rán Ọmọkùnrin rẹ̀ olùfẹ́ ọ̀wọ́n sí ilẹ̀-ayé pẹ̀lú ìfara-ẹni-rúbọ ńláǹlà.” (1 Johannu 4:10, 19) Láàárín oṣù mẹ́wàá, ọkùnrin yìí ti ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Jehofa. Lẹ́yìn ìyẹn, ó pọkànpọ̀ sórí ṣíṣiṣẹ́sin Ọlọrun alààyè. Ó tẹ́wọ́gba iṣẹ́-òjíṣẹ́ alákòókò kíkún ó sì ṣí lọ láti sìn ní ibi tí àìní gbé pọ̀ jù. Òun, gẹ́gẹ́ bíi ti àwọn aposteli, ‘fi ohun gbogbo sílẹ̀ ó sì tọ Jesu lẹ́yìn.’ (Matteu 19:27, NW) Lẹ́yìn oṣù méjì, a késí òun àti aya rẹ̀ láti ṣiṣẹ́sìn ní ẹ̀ka Watch Tower Bible and Tract Society ní orílẹ̀-èdè tí wọ́n ń gbé, kí ó baà lè fi iṣẹ́ iná mànàmáná ṣe ìrànlọ́wọ́. Ó ti ń ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka náà fún ohun tí ó lé ní 20 ọdún, ní ṣíṣe iṣẹ́ tí ó nífẹ̀ẹ́ sí—kì í ṣe fún ara rẹ̀ bíkòṣe fún Jehofa.
Sọ Ìyàsímímọ́ Rẹ Di Mímọ̀ Ní Gbangba
16. Kí ni àwọn ìgbésẹ̀ díẹ̀ tí ẹnì kan yóò gbé láti ṣe ìyàsímímọ́ fún Jehofa?
16 Lẹ́yìn kíkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli fún ìgbà díẹ̀, tàgbà tèwe yóò wá mọrírì Jehofa àti ohun tí ó ti ṣe fún wọn. Èyí gbọ́dọ̀ sún wọn láti ya ara wọn sí mímọ́ fún Ọlọrun. Ìwọ lè jẹ́ ọ̀kan lára àwọn wọ̀nyí. Báwo ni ó ṣe lè ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Jehofa? Lẹ́yìn gbígba ìmọ̀ pípéye láti inú Bibeli, ó níláti ṣiṣẹ́ lórí ìmọ̀ yẹn kí o sì lo ìgbàgbọ́ nínú Jehofa àti Jesu Kristi. (Johannu 17:3) Ronúpìwàdà kí o sì yípadà kúrò nínú ipa-ọ̀nà ẹlẹ́ṣẹ̀ èyíkéyìí tí o ti ń tọ̀ tẹ́lẹ̀. (Ìṣe 3:19) Lẹ́yìn náà ni ìwọ yóò dórí ìpele ṣíṣe ìyàsímímọ́, ní sísọ ọ́ jáde nínú ọ̀rọ̀ onírònújinlẹ̀ ti àdúrà sí Jehofa. Kò sí iyèméjì pé àdúrà yìí yóò fi ohun kan tí o kò lè gbàgbé láéláé sínú ọkàn rẹ̀, nítorí tí yóò jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ipò-ìbátan titun kan pẹ̀lú Jehofa.
17. (a) Èéṣe tí àwọn alàgbà fi ń ṣàtúnyẹ̀wò àwọn ìbéèrè tí a ti ṣètò pẹ̀lú àwọn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe ìyàsímímọ́? (b) Ìgbésẹ̀ pàtàkì wo ni ẹnì kan níláti gbé gbàrà lẹ́yìn ìyàsímímọ́ rẹ̀, fún ète wo sì ni?
17 Gẹ́gẹ́ bí Mose ti ṣàlàyé àwọn ipò tí wíwọnú ipò-ìbátan onímájẹ̀mú pẹ̀lú Jehofa fún àwọn ọmọ Israeli, àwọn alàgbà nínú ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ń ran àwọn wọnnì tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe ìyàsímímọ́ lọ́wọ́ láti ṣe àyẹ̀wò ohun pàtó tí ó wémọ ọn. Wọ́n ń lo àwọn ìbéèrè tí a ti ṣètò láti jẹ́rìí síi pé ẹnìkọ̀ọ̀kan lóye àwọn ìpìlẹ̀ ẹ̀kọ́ Bibeli ní kíkún tí ó sì mọ ohun tí jíjẹ́ Ẹlẹ́rìí Jehofa ní nínú. Lẹ́yìn náà, ayẹyẹ kan láti ṣe ìyàsímímọ́ náà ní gbangba jẹ́ ohun tí ó yẹ jùlọ. Lọ́nà tí ó bá ìwà ẹ̀dá mu, ẹnì kan tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe ìyàsímímọ́ ń háragàgà láti jẹ́ kí àwọn ẹlòmíràn mọ̀ pé òun ti wá sínú ipò-ìbátan aláǹfààní àkànṣe yìí pẹ̀lú Jehofa. (Fiwé Jeremiah 9:24.) Èyí ni a máa ń ṣe lọ́nà tí ó yẹ nípa ṣíṣe ìrìbọmi nínú omi gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ ìyàsímímọ́. Dídi ẹni tí a rì bọmi tí a sì gbé dìde ń ṣàpẹẹrẹ pé ó di òkú sí ipa-ọ̀nà ìgbésí-ayé ìtẹ́ra-ẹni-lọ́rùn tí ó ti ń gbé tẹ́lẹ̀ tí a sì gbé e dìde sí ọ̀nà ìgbésí-ayé titun, ti ṣíṣe ìfẹ́-inú Ọlọrun. Kì í ṣe sakramẹnti, bẹ́ẹ̀ sì ni kì í ṣe ìrúbọ bíi ti ààtò misogi ti ìsìn Shinto nínú èyí tí a ti retí pé kí a fi omi wẹ ẹnì kan mọ́ tónítóní.a Kàkà bẹ́ẹ̀, ìbatisí jẹ́ ìpolongo ìyàsímímọ́ tí a ti ṣe nínú àdúrà tẹ́lẹ̀ ní gbangba.
18. Èéṣe tí a fi lè ní ìdánilójú pé ìyàsímímọ́ wa kì yóò jẹ́ lórí asán?
18 Ayẹyẹ pípabambarì yìí jẹ́ ìrírí tí kò ṣeé gbàgbé, tí ń rán ẹni tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ di ìránṣẹ́ Ọlọrun náà létí nípa ipò-ìbátan pípẹ́títí tí òun ní nísinsìnyí pẹ̀lú Jehofa. Ní ìyàtọ̀ sí ìyàsímímọ́ tí awakọ̀ òfúúrufú tí a fi ń jagun ṣe fún orílẹ̀-èdè àti olú-ọba rẹ̀, ìyàsímímọ́ yìí fún Jehofa kì yóò jẹ́ lórí asán, nítorí pé òun ni Ọlọrun olodumare ẹni ayérayé tí ń ṣàṣeparí gbogbo ohun tí ó ti là sílẹ̀ láti ṣe. Òun, àní òun nìkanṣoṣo, ni ó yẹ fún ìfọkànsìn tọkàntọkàn wa.—Isaiah 55:9-11.
19. Kí ni a óò jíròrò nínú ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ tí yóò tẹ̀lé e?
19 Bí ó ti wù kí ó rí, ohun púpọ̀ ni ó wémọ́ ìyàsímímọ́. Fún àpẹẹrẹ, báwo ni ìyàsímímọ́ ṣe nípa lórí ìgbésí-ayé wa ojoojúmọ́? Èyí ni a óò jíròrò nínú ọ̀rọ̀-ẹ̀kọ́ tí yóò tẹ̀lé e.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo Mankind’s Search for God, tí a tẹ̀jáde láti ọwọ́ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., ojú-ìwé 194 sí 195.
Ìwọ Ha Rántí Bí?
◻ Èéṣe tí ìyàsímímọ́ gẹ́gẹ́ bí ó ṣe ń wáyé nínú ayé fi ń yọrísí ìjákulẹ̀?
◻ Kí ni ó sún àwọn ọmọ Israeli láti ya ara wọn sí mímọ́ fún Jehofa?
◻ Kí ni ó ń sún wa láti ya ara wa sí mímọ́ fún Jehofa lónìí?
◻ Báwo ni a ṣe ń ya ara wa sí mímọ́ fún Ọlọrun?
◻ Kí ni ìjẹ́pàtàkì ìrìbọmi nínú omi?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Israeli ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Jehofa ní Sinai