Àkọsílẹ̀ Mátíù
22 Jésù tún fi àwọn àpèjúwe bá wọn sọ̀rọ̀, ó sọ pé: 2 “A lè fi Ìjọba ọ̀run wé ọba kan tó se àsè ìgbéyàwó+ fún ọmọkùnrin rẹ̀. 3 Ó wá rán àwọn ẹrú rẹ̀ kí wọ́n lọ pe àwọn tí wọ́n pè síbi àsè ìgbéyàwó náà wá, àmọ́ wọn ò fẹ́ wá.+ 4 Ó tún rán àwọn ẹrú míì, ó sọ pé, ‘Ẹ sọ fún àwọn tí a pè, pé: “Ẹ wò ó! Mo ti pèsè oúnjẹ alẹ́ mi sílẹ̀, mo ti pa àwọn akọ màlúù mi àtàwọn ẹran mi tó sanra, gbogbo nǹkan sì ti wà ní sẹpẹ́. Ẹ wá síbi àsè ìgbéyàwó náà.”’ 5 Àmọ́ wọn ò kà á sí, wọ́n jáde lọ, ọ̀kan lọ sí oko rẹ̀, òmíràn lọ síbi òwò rẹ̀;+ 6 àmọ́ àwọn tó kù gbá àwọn ẹrú rẹ̀ mú, wọ́n kàn wọ́n lábùkù, wọ́n sì pa wọ́n.
7 “Inú bí ọba náà, ló bá rán àwọn ọmọ ogun rẹ̀ lọ pa àwọn apààyàn náà, ó sì dáná sun ìlú wọn.+ 8 Ó wá sọ fún àwọn ẹrú rẹ̀ pé, ‘Àsè ìgbéyàwó náà ti wà ní sẹpẹ́, àmọ́ àwọn tí a pè kò yẹ.+ 9 Torí náà, ẹ lọ sí àwọn ojú ọ̀nà tó jáde látinú ìlú, kí ẹ sì pe ẹnikẹ́ni tí ẹ bá rí wá síbi àsè ìgbéyàwó náà.’+ 10 Àwọn ẹrú náà ṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n jáde lọ sí àwọn ojú ọ̀nà, wọ́n sì kó gbogbo àwọn tí wọ́n rí jọ, ẹni burúkú àti ẹni rere; àwọn tó ń jẹun* sì kún inú yàrá tí wọ́n ti ń ṣe ayẹyẹ ìgbéyàwó náà.
11 “Nígbà tí ọba náà wọlé wá wo àwọn àlejò, ó tajú kán rí ọkùnrin kan tí kò wọ aṣọ ìgbéyàwó. 12 Ó wá bi í pé, ‘Ọ̀gbẹ́ni, báwo lo ṣe wọlé síbí láìwọ aṣọ ìgbéyàwó?’ Ọkùnrin náà ò lè sọ nǹkan kan. 13 Ọba wá sọ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, ‘Ẹ dè é tọwọ́ tẹsẹ̀, kí ẹ sì jù ú sínú òkùnkùn níta. Ibẹ̀ lá ti máa sunkún, tí á sì ti máa payín keke.’
14 “Torí ọ̀pọ̀ la pè, àmọ́ díẹ̀ la yàn.”
15 Àwọn Farisí wá lọ gbìmọ̀ pọ̀, kí wọ́n lè fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ mú un.+ 16 Torí náà, wọ́n rán àwọn ọmọ ẹ̀yìn wọn sí i, pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Hẹ́rọ́dù,+ wọ́n sọ pé: “Olùkọ́, a mọ̀ pé olóòótọ́ ni ọ́, ò ń kọ́ni ní ọ̀nà Ọlọ́run ní òtítọ́, o kì í wá ojúure ẹnikẹ́ni, torí kì í ṣe ìrísí àwọn èèyàn lò ń wò. 17 Torí náà, sọ fún wa, kí lèrò rẹ? Ṣé ó bófin mu* láti san owó orí fún Késárì àbí kò bófin mu?” 18 Àmọ́ Jésù mọ èrò burúkú wọn, ó sọ pé: “Ẹ̀yin alágàbàgebè, kí ló dé tí ẹ̀ ń dán mi wò? 19 Ẹ fi ẹyọ owó tí ẹ fi ń san owó orí hàn mí.” Wọ́n mú owó dínárì* kan wá fún un. 20 Ó sì sọ fún wọn pé: “Àwòrán àti àkọlé ta nìyí?” 21 Wọ́n sọ pé: “Ti Késárì ni.” Ó wá sọ fún wọn pé: “Torí náà, ẹ san àwọn ohun ti Késárì pa dà fún Késárì, àmọ́ ẹ fi àwọn ohun ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run.”+ 22 Nígbà tí wọ́n gbọ́ ìyẹn, ó yà wọ́n lẹ́nu, wọ́n kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n sì lọ.
23 Lọ́jọ́ yẹn, àwọn Sadusí, tí wọ́n sọ pé kò sí àjíǹde,+ wá bi í pé:+ 24 “Olùkọ́, Mósè sọ pé: ‘Tí ọkùnrin èyíkéyìí bá kú láìní ọmọ, kí arákùnrin rẹ̀ fẹ́ ìyàwó rẹ̀, kó sì bímọ fún arákùnrin rẹ̀.’+ 25 Ó ṣẹlẹ̀ pé arákùnrin méje wà pẹ̀lú wa. Ẹni àkọ́kọ́ fẹ́ ìyàwó, ó sì kú, ó fi ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀ fún arákùnrin rẹ̀, nígbà tó jẹ́ pé kò bí ọmọ kankan. 26 Ohun kan náà ló ṣẹlẹ̀ sí ẹnì kejì àti ẹnì kẹta, títí dórí ẹnì keje. 27 Nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, obìnrin náà kú. 28 Tí àwọn méjèèje bá wá jíǹde, èwo nínú wọn ló máa fẹ́? Torí gbogbo wọn ni wọ́n ti fi ṣe aya.”
29 Jésù dá wọn lóhùn pé: “Ẹ ti ṣàṣìṣe, torí pé ẹ ò mọ Ìwé Mímọ́, ẹ ò sì mọ agbára Ọlọ́run;+ 30 torí nígbà àjíǹde, àwọn ọkùnrin kì í gbéyàwó, a kì í sì í fa àwọn obìnrin fún ọkọ, àmọ́ wọ́n máa dà bí àwọn áńgẹ́lì ní ọ̀run.+ 31 Ní ti àjíǹde àwọn òkú, ṣé ẹ ò tíì ka ohun tí Ọlọ́run sọ fún yín ni, pé: 32 ‘Èmi ni Ọlọ́run Ábúráhámù, Ọlọ́run Ísákì àti Ọlọ́run Jékọ́bù’?+ Kì í ṣe Ọlọ́run àwọn òkú, àmọ́ ó jẹ́ Ọlọ́run àwọn alààyè.”+ 33 Nígbà tí àwọn èrò náà gbọ́ ìyẹn, bó ṣe ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ yà wọ́n lẹ́nu.+
34 Lẹ́yìn tí àwọn Farisí gbọ́ pé ó ti pa àwọn Sadusí lẹ́nu mọ́, wọ́n kóra jọ, wọ́n sì wá. 35 Ọ̀kan lára wọn, tó mọ Òfin dunjú, bi í ní ìbéèrè láti dán an wò: 36 “Olùkọ́, àṣẹ wo ló tóbi jù lọ nínú Òfin?”+ 37 Ó sọ fún un pé: “‘Kí o fi gbogbo ọkàn rẹ àti gbogbo ara* rẹ àti gbogbo èrò rẹ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà* Ọlọ́run rẹ.’+ 38 Èyí ni àṣẹ tó tóbi jù lọ, tó sì jẹ́ àkọ́kọ́. 39 Ìkejì tó dà bíi rẹ̀ nìyí: ‘Kí o nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì rẹ bí ara rẹ.’+ 40 Àṣẹ méjì yìí ni gbogbo Òfin àti àwọn Wòlíì rọ̀ mọ́.”+
41 Nígbà tí àwọn Farisí kóra jọ, Jésù bi wọ́n pé:+ 42 “Kí lèrò yín nípa Kristi? Ọmọ ta ni?” Wọ́n sọ fún un pé: “Ọmọ Dáfídì ni.”+ 43 Ó bi wọ́n pé: “Kí wá nìdí tí Dáfídì fi pè é ní Olúwa nípasẹ̀ ìmísí,+ tó sọ pé, 44 ‘Jèhófà* sọ fún Olúwa mi pé: “Jókòó sí ọwọ́ ọ̀tún mi, títí màá fi fi àwọn ọ̀tá rẹ sábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ”’?+ 45 Tí Dáfídì bá pè é ní Olúwa, báwo ló ṣe jẹ́ ọmọ rẹ̀?”+ 46 Kò sẹ́ni tó lè dá a lóhùn rárá, láti ọjọ́ yẹn lọ, kò sẹ́ni tó jẹ́ bi í ní ìbéèrè mọ́.