Àwọn Olùṣàkóso Ní Ilẹ̀-Àkóso Ẹ̀mí
TA NI ń ṣàkóso ayé? Àwọn àbójútó kan láti ọ̀dọ̀ agbára tí ó rékọjá ti ẹ̀dá ha wà bí? Àbí Ọlọrun ti fi àwọn ẹ̀dá ènìyàn sílẹ̀ láti máa bójútó ara wọn? Nínú wíwá ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí, ẹ jẹ́ kí a kọ́kọ́ ṣàgbéyẹ̀wò ìṣẹ̀lẹ̀ kan tí ó ṣẹlẹ̀ nígbà iṣẹ́-òjíṣẹ́ Jesu Kristi lórí ilẹ̀-ayé.
Kété lẹ́yìn ìrìbọmi rẹ̀, ẹ̀dá ẹ̀mí kan tí kò ṣeé fojúrí tí a ń pè ní Satani Èṣù dán Jesu wò. Nígbà tí ó ń sọ ọ̀kan nínú àwọn ìdánwò náà, Bibeli sọ pé: “Èṣù . . . mú . . . [Jesu] lọ sí òkè-ńlá kan tí ó ga lọ́nà kíkàmàmà, ó sì fi gbogbo awọn ìjọba ayé ati ògo wọn hàn án.” (Matteu 4:8) Lẹ́yìn náà Satani wí fún Jesu pé: “Gbogbo ọlá-àṣẹ yii ati ògo wọn ni emi yoo fi fún ọ dájúdájú, nitori pé a ti fi í lé mi lọ́wọ́, ẹni yòówù tí mo bá sì fẹ́ ni emi a fi í fún. Iwọ, nígbà naa, bí o bá ṣe ìṣe ìjọsìn kan níwájú mi, gbogbo rẹ̀ ni yoo jẹ́ tìrẹ.”—Luku 4:6, 7.
Satani jẹ́wọ́ pé òun ní ọlá-àṣẹ lórí gbogbo ìjọba, tàbí ìṣàkóso, ti ayé yìí. Jesu ha sẹ ìjẹ́wọ́ yìí bí? Rárá o. Níti tòótọ́, ó jẹ́rìí sí i ní àkókò ìṣẹ̀lẹ̀ mìíràn nípa títọ́ka sí Satani gẹ́gẹ́ bí “olùṣàkóso ayé.”—Johannu 14:30.
Ní ìbámu pẹ̀lú Bibeli, Satani jẹ́ áńgẹ́lì burúkú tí ó ní agbára ńláǹlà. Kristian aposteli Paulu so Satani pọ̀ mọ́ “awọn agbo ọmọ ogun ẹ̀mí burúkú” ó sì sọ̀rọ̀ nípa wọn gẹ́gẹ́ bí “awọn olùṣàkóso ayé òkùnkùn yii.” (Efesu 6:11, 12) Jù bẹ́ẹ̀ lọ, aposteli Johannu wí pé “gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú naa.” (1 Johannu 5:19) Ìwé Ìṣípayá nínú Bibeli sọ pé Satani “ń ṣi gbogbo ilẹ̀-ayé tí a ń gbé pátá lọ́nà.” (Ìṣípayá 12:9) Ní èdè ìṣàpẹẹrẹ, Ìṣípayá tún ṣàpèjúwe Satani gẹ́gẹ́ bí diragoni tí ó fi “agbára rẹ̀ ati ìtẹ́ rẹ̀ ati ọlá-àṣẹ ńlá” fún ètò ìṣèlú ayé.—Ìṣípayá 13:2.
Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ayé pẹ̀lú jẹ́rìí sí pé agbára búburú kan wà lẹ́nu iṣẹ́, tí ń dọ́gbọ́n darí àwọn ẹ̀dá ènìyàn sí ìpalára ara wọn. Fún ìdí mìíràn wo ni àwọn ìṣàkóso ẹ̀dá ènìyàn fi kùnà láti gbé àlàáfíà lárugẹ? Kí ni ohun mìíràn tí yóò mú kí àwọn ènìyàn máa kórìíra kí wọ́n sì máa dúḿbú ara wọn? Nítorí ìpayà tí ó dé bá a nítorí ìpalápalù àti ikú tí ó wáyé nínú ogun abẹ́lé kan, ẹnì kan tí ó ṣẹlẹ́rìí rẹ̀ wí pé: “Èmi kò lóye bí èyí ṣe lè ṣẹlẹ̀. Ó rékọjá ìkórìíra. Ẹ̀mí búburú kan ni ó ń lo àwọn ẹ̀dá adáríhunrun wọ̀nyí láti máa pa ara wọn.”
Ẹni Gidi kan Tako Ọlọrun
Lónìí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ kò ní ìgbàgbọ́ nínú Satani Èṣù. Síbẹ̀, òun kì í wulẹ̀ ṣe ìlànà ìwà-ibi nínú ẹ̀dá ènìyàn, bí àwọn kan ti gbàgbọ́. Bibeli àti àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ayé fi hàn pé ẹni gidi kan ni. Síwájú síi, Satani tako Jehofa Ọlọrun délẹ̀délẹ̀. Àmọ́ ṣáá o, Satani kò bá Ọlọrun dọ́gba. Níwọ̀n bí Jehofa ti jẹ́ Ẹlẹ́dàá alágbára gbogbo, òun ni Olùṣàkóso tí ó ní ẹ̀tọ́ lórí gbogbo ẹ̀dá.—Ìṣípayá 4:11.
Ọlọrun kò dá ẹ̀dá burúkú kan láti tako òun fúnra rẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ọ̀kan lára àwọn áńgẹ́lì “àwọn ọmọ Ọlọrun” mú ìfẹ́-ọkàn onímọtara-ẹni-nìkan dàgbà fúnra rẹ̀ láti gba ìjọsìn tí ó fi pẹ̀lú ẹ̀tọ́ jẹ́ ti Jehofa fún ara rẹ̀. (Jobu 38:7; Jakọbu 1:14, 15) Ìfẹ́-ọkàn yìí sún un láti dágbálé ìwà ọ̀tẹ̀ sí Ọlọrun. Nípa síṣọ̀tẹ̀, ẹ̀dá ẹ̀mí yìí sọ ara rẹ̀ di Satani (tí ó túmọ̀ sí “alátakò”) àti Èṣù (tí ó túmọ̀ sí “abanijẹ́”). Lójú ìwòye gbogbo èyí, o lè ṣe kàyéfì pé èéṣe tí a fi fàyègba Satani láti ṣàkóso ayé.
Ìdí Tí A Fi Yọ̀ǹda fún Satani Láti Ṣàkóso
O ha rántí ohun tí Satani sọ fún Jesu nípa ìṣàkóso lórí ilẹ̀-ayé bí? Satani wí pé: “Gbogbo ọlá-àṣẹ yii ati ògo wọn ni emi yoo fi fún ọ dájúdájú, nitori pé a ti fi í lé mi lọ́wọ́.” (Luku 4:6) Gbólóhùn yìí fi hàn pé Satani Èṣù ń lo ọlá-àṣẹ kìkì nípa ìyọ̀ọ̀da Ọlọrun. Ṣùgbọ́n èéṣe tí Ọlọrun fi fàyègba Satani?
Ìdáhùn sí ìbéèrè yẹn níí ṣe pẹ̀lú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ní ọgbà-ọ̀gbìn Edeni, níbi tí Satani ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́-ìgbésí-ayé rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso ayé. Níbẹ̀ Satani sọ pé Ọlọrun ń ṣàkóso lọ́nà búburú nípa fífa ọwọ́ ohun rere sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ ọkùnrin àti obìnrin àkọ́kọ́, Adamu àti Efa. Gẹ́gẹ́ bí ohun tí Satani sọ, bí wọ́n bá jẹ èso tí Ọlọrun kàléèwọ̀, wọn yóò dòmìnira. Adamu àti Efa yóò wà lómìnira wọ́n kì yóò sì sí lábẹ́ Jehofa. Wọn yóò dàbí Ọlọrun fúnra rẹ̀!—Genesisi 2:16, 17; 3:1-5.
Nípa píparọ́ ní ọ̀nà yìí tí ó sì tan Efa jẹ tí ó sì tipasẹ̀ rẹ̀ sún Adamu láti rú òfin Ọlọrun, Satani mú ẹ̀dá tọkọtaya ènìyàn àkọ́kọ́ wá sábẹ́ ìdarí àti àkóso rẹ̀. Èṣù tipa báyìí di ọlọrun wọn, ẹnì kan tí ó jẹ́ alátakò Jehofa. Bí ó ti wù kí ó rí, dípò dídòmìnira Adamu àti Efa ní ìrírí sísìnrú fún Satani, fún ẹ̀ṣẹ̀, àti fún ikú.—Romu 6:16; Heberu 2:14, 15.
Ní ìbámu pẹ̀lú ìdájọ́ òdodo pípé rẹ̀, Jehofa ìbá ti pa Satani àti àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ méjèèjì lójú ẹsẹ̀. (Deuteronomi 32:4) Síbẹ̀, ọ̀ràn ìwàrere kan wémọ́ ọn. Satani ti pe ẹ̀tọ́ ọ̀nà tí Jehofa gbà ń ṣàkóso níjà. Nínú ọgbọ́n rẹ̀, Ọlọrun jẹ́ kí àkókò kọjá kí a baà lè jẹ́rìí síi pé gbígba òmìnira kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀ ń mú ìjábá wá. Jehofa fàyègba àwọn ọlọ̀tẹ̀ náà láti máa wàláàyè nìṣó fún ìgbà kan, ní yíyọ̀ǹda fún Adamu àti Efa láti bímọ.—Genesisi 3:14-19.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èyí tí ó pọ̀ jùlọ nínú àwọn ọmọ Adamu kò tí ì juwọ́sílẹ̀ fún ìṣàkóso Jehofa, ìbálò Ọlọrun pẹ̀lú àwọn olùjọ́sìn Rẹ̀ ti fi ipò-àjùlọ rẹ̀ hàn. Mímọ ọlá-àṣẹ Jehofa dáradára ń mú ayọ̀ àti àìléwu tòótọ́ wá. Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, ìṣàkóso ẹ̀dá ènìyàn lábẹ́ agbára ìdarí Satani ti yọrí sí ìṣẹ́ àti ewu. Bẹ́ẹ̀ni, “ẹnì kan ń ṣe olórí ẹnìkejì fún ìfarapa rẹ̀.” (Oniwasu 8:9) Ẹ̀dá ènìyàn kò tí ì rí ojúlówó àìléwu àti ayọ̀ pípẹ́títí lábẹ́ ìṣàkóso ẹ̀dá ènìyàn nínú ayé tí ó wà lábẹ́ agbára Satani yìí. Bí ó ti wù kí ó rí, ìdí tí ó yèkooro wà fún níní ẹ̀mí nǹkan-yóò-dára.
Àkókò Satani Kúrú!
Agbára ìdarí Satani lórí ilẹ̀-ayé jẹ́ fún ìgbà díẹ̀. Jehofa kì yóò fàyègba ìṣàkóso Satani fún ìgbà pípẹ́ mọ́! Láìpẹ́ Èṣù yóò di akúrẹtẹ̀. Olùṣàkóso titun yóò gba àkóso ilẹ̀-ayé, ọba òdodo tí Ọlọrun fúnra rẹ̀ yàn. Jesu Kristi ni Ọba náà. Nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀ nípa ìgbégorí-ìtẹ́ rẹ̀ ní ọ̀run, Ìṣípayá sọ pé: “Ìjọba ayé di ìjọba Oluwa wa [Jehofa] ati ti Kristi rẹ̀.” (Ìṣípayá 11:15) Ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọjọ́ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ inú Bibeli, papọ̀ pẹ̀lú ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ Ìwé Mímọ́, fi ẹ̀rí hàn pé ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ṣẹlẹ̀ ní ọdún 1914.—Matteu 24:3, 6, 7.
Bibeli tún ṣàpèjúwe ohun tí ó ṣẹlẹ̀ kété lẹ́yìn tí a gbé Jesu gun orí ìtẹ́. Ó sọ pé: “Ogun sì bẹ́sílẹ̀ ní ọ̀run: Mikaeli [Jesu Kristi] ati awọn áńgẹ́lì rẹ̀ bá diragoni naa [Satani Èṣù] ja ìjà ogun, diragoni naa ati awọn áńgẹ́lì rẹ̀ sì ja ìjà ogun ṣugbọn oun kò borí, bẹ́ẹ̀ ni a kò rí àyè kankan fún wọn mọ́ ní ọ̀run. Bẹ́ẹ̀ ni a fi diragoni ńlá naa sọ̀kò sísàlẹ̀, ejò ìpilẹ̀ṣẹ̀ naa, ẹni tí a ń pè ní Èṣù ati Satani, ẹni tí ń ṣi gbogbo ilẹ̀-ayé tí a ń gbé pátá lọ́nà; a fi í sọ̀kò sísàlẹ̀ sí ilẹ̀-ayé, a sì fi awọn áńgẹ́lì rẹ̀ sọ̀kò sísàlẹ̀ pẹlu rẹ̀.”—Ìṣípayá 12:7-9.
Kí ni yóò jẹ́ ìyọrísí lílé Satani kúrò ní ọ̀run? Àwọn wọnnì tí ń bẹ ní ọ̀run yóò yọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀, ṣùgbọ́n kí ni nípa ti àwọn olùgbé ilẹ̀-ayé? Ìwé Ìṣípayá 12:12 sọ pé: “Ègbé ni fún ilẹ̀-ayé ati fún òkun, nitori Èṣù ti sọ̀kalẹ̀ wá bá yín, ó ní ìbínú ńlá, ní mímọ̀ pé sáà àkókò kúkúrú ni oun ní.” Nítòótọ́, lílé Satani jùnù kúrò ní ọ̀run ti mú ègbé wá fún ilẹ̀-ayé. Ìwé The Columbia History of the World sọ pé: “Àjálù ńláǹlà ti Ogun Ọdún Mẹ́rin ti 1914 sí 1918 . . . fi han apá Ìwọ̀-Oòrùn ayé pé kò lè dáàbò bo ọ̀làjú rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ìwà òmùgọ̀ tàbí ẹ̀mí ìsúnniṣe búburú rẹ̀. Ayé Ìwọ̀-Oòrùn kò tí ì jèrè okun rẹ̀ padà láti inú ìrunbàjẹ́ yẹn.”
Ohun tí ó rékọjá ẹ̀mí ìrunbàjẹ́ fíìfíì ni ó sàmì sí ègbé ti ìran yìí. Jesu sọtẹ́lẹ̀ pé: “Orílẹ̀-èdè yoo dìde sí orílẹ̀-èdè ati ìjọba sí ìjọba, àìtó oúnjẹ ati ìmìtìtì-ilẹ̀ yoo sì wà lati ibi kan dé ibòmíràn.” Ó tún sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa àjàkálẹ̀ àrùn. (Matteu 24:7, 8; Luku 21:11) Jù bẹ́ẹ̀ lọ, Bibeli sọ pé ní “awọn ọjọ́ ìkẹyìn” ètò-ìgbékalẹ̀ Satani ti ìsinsìnyí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ yóò jẹ́ “olùfẹ́ ara wọn, olùfẹ́ owó, . . . aṣàìgbọràn sí òbí, . . . aláìṣeé bá ṣe àdéhùn kankan.” Àwọn ènìyàn yóò tún jẹ́ “olùfẹ́ adùn dípò olùfẹ́ Ọlọrun.”—2 Timoteu 3:1-5.
Ogun, àjàkálẹ̀ àrùn, àìtó oúnjẹ, ìmìtìtì-ilẹ̀, àti àyípadà sí burúkú nínú ọ̀pá ìdiwọ̀n ìwàhíhù—gbogbo àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ ti ṣẹlẹ̀ ní ìwọ̀n tí kò láfiwé láti 1914, gan-an gẹ́gẹ́ bí Bibeli ṣe sọtẹ́lẹ̀. Wọ́n fi hàn pé ọ̀tá Ọlọrun àti ènìyàn tí inú ń bí náà—Satani Èṣù—ni a ti lé jáde ní ọ̀run tí yóò sì fi ìrunú rẹ̀ mọ sí ilẹ̀-àkóso ti ilẹ̀-ayé. Ṣùgbọ́n Bibeli tún fi hàn pé a kò ní yọ̀ǹda fún Satani láti máa bá iṣẹ́ lọ fún ìgbà pípẹ́ mọ́. Kìkì “sáà àkókò kúkúrú” ni ó ṣẹ́kù kí Armageddoni dé, nígbà tí Ọlọrun yóò pa ètò-ìgbékalẹ̀ ayé tí Satani ń darí run.
Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí Satani lẹ́yìn náà? Aposteli Johannu kọ̀wé pé: “Mo sì rí áńgẹ́lì kan tí ń sọ̀kalẹ̀ lati ọ̀run wá pẹlu kọ́kọ́rọ́ ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ ati ọ̀gbàrà-ẹ̀wọ̀n ńlá kan ní ọwọ́ rẹ̀. Ó sì gbá diragoni naa mú, ejò ìpilẹ̀ṣẹ̀ naa, ẹni tí í ṣe Èṣù ati Satani, ó sì dè é fún ẹgbẹ̀rún ọdún. Ó sì fi í sọ̀kò sínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ naa ó sì tì í ó sì fi èdìdì dí i lórí rẹ̀.” (Ìṣípayá 20:1-3) Ẹ wo irú ìtura tí èyí yóò jẹ́ fún aráyé tí ń jìyà!
Yíyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ Lábẹ́ Ìṣàkóso Ìjọba
Nígbà tí Satani bá kúrò lọ́nà, Ìjọba Ọlọrun lábẹ́ Jesu Kristi yóò gba àkóso àlámọ̀rí aráyé lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́. Dípò níní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àkóso lórí ilẹ̀-ayé, kìkì àkóso ti ọ̀run kanṣoṣo ni yóò ṣẹ́kù láti ṣàkóso lórí planẹẹti ilẹ̀-ayé látòkèdélẹ̀. Ogun yóò di ohun àtijọ́, àlàáfíà yóò sì gbalégbòde níbi gbogbo. Lábẹ́ ìṣàkóso Ìjọba Ọlọrun, gbogbo ènìyàn yóò máa gbé papọ̀ nínú ẹgbẹ́ ará onífẹ̀ẹ́.—Orin Dafidi 72:7, 8; 133:1; Danieli 2:44.
Irú olùṣàkóso wo ni Jesu yóò fi ẹ̀rí hàn pé òun jẹ́? Nígbà tí ó wà lórí ilẹ̀-ayé, ó fi ìfẹ́ jíjinlẹ̀ hàn sí àwọn ènìyàn. Jesu fi pẹ̀lú ìyọ́nú fún àwọn tí ebi ń pa ní oúnjẹ. Ó wo àwọn aláìsàn sàn ó sì la ojú afọ́jú, ó mú kí odi sọ̀rọ̀, ó sì mú ẹsẹ̀ arọ lókun. Àní Jesu jí àwọn òkú pàápàá dìde! (Matteu 15:30-38; Marku 1:34; Luku 7:11-17) Àwọn iṣẹ́ ìyanu wọ̀nyẹn jẹ́ ìrí fìrí àwọn nǹkan àwòyanu tí òun yóò ṣe gẹ́gẹ́ bí Ọba. Ẹ wo bí yóò ti jẹ́ ohun àgbàyanu tó láti ní irú ẹlẹ́mìí-ìṣoore olùṣàkóso bẹ́ẹ̀!
Ìbùkún tí kò lópin ni àwọn wọnnì tí wọ́n bá juwọ́sílẹ̀ fún ipò ọba-aláṣẹ Jehofa yóò gbádùn. Ìwé Mímọ́ ṣèlérí pé: “Nígbà náà ni ojú àwọn afọ́jú yóò là, etí àwọn adití yóò sì ṣí. Nígbà náà ni àwọn arọ yóò fò bí àgbọ̀nrín, àti ahọ́n odi yóò kọrin.” (Isaiah 35:5, 6) Nígbà tí ó ń tọ́ka sí ọjọ́ pípabambarì yìí, aposteli Johannu kọ̀wé pé: “Mo gbọ́ ohùn rara lati orí ìtẹ́ naa wá wí pé: ‘Wò ó! Àgọ́ Ọlọrun wà pẹlu aráyé, oun yoo sì máa bá wọn gbé, wọn yoo sì máa jẹ́ ènìyàn rẹ̀. Ọlọrun fúnra rẹ̀ yoo sì wà pẹlu wọn. Oun yoo sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yoo sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yoo sí ọ̀fọ̀ tabi igbe ẹkún tabi ìrora mọ́. Awọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.’”—Ìṣípayá 21:3, 4.
Ìgbádùn tí ìṣàkóso Jehofa Ọlọrun yóò fi jíǹkí ènìyàn nípasẹ̀ Ọmọkùnrin rẹ̀, Jesu Kristi, yóò san àsanpadà tí ó rékọjá fún ìjìyà èyíkéyìí tí a ti lè ní ìrírí rẹ̀ nínú ètò-ìgbékalẹ̀ ìsinsìnyí tí Satani Èṣù jẹgàba lé lórí. Nínú ayé titun tí Ọlọrun ṣèlérí, àwọn ènìyàn kò ní máa ṣe kàyéfì pé, ‘Ta ní ń ṣàkóso nítòótọ́?’ (2 Peteru 3:13) Aráyé onígbọràn yóò láyọ̀ wọn yóò sì wà ní àìléwu nínú pápá àkóso ilẹ̀-ayé ti àwọn Olùṣàkóso onífẹ̀ẹ́ tí ń bẹ ní ilẹ̀ àkóso ẹ̀mí, Jehofa ati Kristi. Ó ha jẹ́ ìrètí rẹ láti wà lára àwọn ọmọ-abẹ́ wọn bí?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Aráyé yóò wà ní àìléwu nínú pápá àkóso Ìjọba Ọlọrun
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 4]
Fọ́tò NASA