Àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa Káàkiri Ayé—Brazil
BRAZIL jẹ́ ilẹ̀ tí ó gbórín ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà. Níti títóbi àti iye olùgbé, òhun ni orílẹ̀-èdè karùn-ún tí ó tóbi jùlọ lágbàáyé. Ó gba èyí tí ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìlàjì agbègbè ilẹ̀ South America ó sì jẹ́ ilé àwọn ènìyàn tí ó pọ̀ ju àpapọ̀ gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn ní kọ́ńtínẹ́ǹtì yẹn. Brazil ni ó tún ní igbó kìjikìji tí ó tóbi jùlọ lágbàáyé. Odò tí ó tóbi jùlọ lórí ilẹ̀-ayé la aginju yẹn kọjá—odò Amazon.
Brazil tún gbórín lọ́nà mìíràn. Iye àwọn akéde ìhìnrere Ìjọba Ọlọrun tí ó ní ti ń súnmọ́ 400,000, ó sì lé ní 1,000,000 tí ó pésẹ̀ síbi Ìṣe-Ìrántí ikú Kristi ní èṣí. Ilẹ̀ yìí nígbà náà ní pàtàkì fa àfiyèsí níti wíwàásù Ìjọba náà. Àwọn ìrírí lọ́ọ́lọ́ọ́ yìí ṣàkàwé kókó yìí.
Ṣíṣiṣẹ́sìn Níbi Tí Àìní Gbé Pọ̀ Jù
Antonio àti aya rẹ̀ ṣe ìpinnu tí ó nira ti fífi àwọn mọ̀lẹ́bí wọn àti iṣẹ́ tí ó fọkànbalẹ̀, tí ó sì ń mówó tí ó jọjú wọlé sílẹ̀ ní São Paulo láti ṣiṣẹ́sìn níbi tí àìní fún àwọn olùpòkìkí Ìjọba gbé pọ̀ jù ní ìpínlẹ̀ Minas Gerais. Ìpínlẹ̀ wọn ní nínú ẹgbẹ́ àwùjọ àwọn òṣìṣẹ́ ní ilé-iṣẹ́ ṣúgà kan. Ní ọjọ́ àkọ́kọ́ tí wọ́n jẹ́rìí níbẹ̀, wọ́n bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli mẹ́sàn-án. Láàárín oṣù 18, wọ́n ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ tí ó lé ní 40!
Lákọ̀ọ́kọ́ ná, wọ́n ń ṣe ìpàdé ní ilé-iṣẹ́ náà. Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn akéde titun fẹ́ láti rí Gbọ̀ngàn Ìjọba gidi. Nítorí ìdí èyí, wọ́n háyà bọ́ọ̀sì kan láti gbé ẹni 75 lọ sí ìjọ tí ó súnmọ́ tòsí jùlọ. Lẹ́yìn náà ni àpéjọpọ̀ wáyé; 45 lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bibeli titun wọ̀nyí pésẹ̀ a sì fọ̀rọ̀ wá wọn lẹ́nu wò. Àwọn 15 lára àwọn wọ̀nyí ṣèrìbọmi ní àkókò ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn. Kò ṣẹ̀ṣẹ̀ ní à-ń-sọ pé, omijé ayọ̀ dà pẹ̀rẹ̀pẹ̀rẹ̀ lójú wọn!
Ilé-iṣẹ́ ọkọ̀ kan náà ni a lò fún irú àwọn ìrìn-àjò bí èyí, àwọn aláṣẹ ilé-iṣẹ́ náà sì pèsè àkànṣe ẹ̀dínwó. Láti lè fi ìmọrírì hàn, Antonio fún ẹni tí ó ni ilé-iṣẹ́ náà ní àrànṣe kan fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli. Ó gbà láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ yẹn gan-an ó sì ṣèrìbọmi lẹ́yìn oṣù mélòókan tí ó ti ń fi taápọn taápọn kẹ́kọ̀ọ́. Lákọ̀ọ́kọ́ ná, aya rẹ̀ tako ìkẹ́kọ̀ọ́ náà, ṣùgbọ́n nígbà tí ó yá, ìwà rẹ̀ rọlẹ̀. Lónìí òun pẹ̀lú ti di Ẹlẹ́rìí fún Jehofa tí ó ti ṣèrìbọmi.
Ní February 1992, a dá ìjọ kan tí ó ní akéde 22 sílẹ̀. Nígbà tí yóò fi di 1994 iye náà ti fò sókè dé 42, pẹ̀lú aṣáájú-ọ̀nà déédéé, tàbí oníwàásù ìhìnrere alákòókò kíkún 4. Ní ìyọrísí rẹ̀, Antonio parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Èmi àti aya mi ti ríi pé bí a bá ‘dán Jehofa wò,’ gẹ́gẹ́ bí Malaki 3:10 ṣe sọ, òun yóò ‘tú ìbùkún jáde tí kì yóò sì àyè láti gbà á.’”
Fífi Ìwé Ìkẹ́kọ̀ọ́ Lọni
Bóyá ìdí mìíràn tí iṣẹ́ ìwàásù náà fi ń tẹ̀síwájú lọ́nà tí ó gadabú ní Brazil ni pé àwọn Ẹlẹ́rìí ń fi ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bibeli lọni ní gbogbo ìgbà tí àǹfààní bá ṣí sílẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, ìjọ kan kọ̀wé sí ọ́fíìsì ẹ̀ka Watch Tower Society ní bíbéèrè fún 250 ẹ̀dà ìwé náà Questions Young People Ask—Answers That Work. Èéṣe tí wọ́n fi béèrè fún iye tí ó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀?
Lẹ́tà náà ṣàlàyé pé: ‘Ọ̀kan lára àwọn ilé-ẹ̀kọ́ ní ìlú ti pinnu láti lo ìwé yìí gẹ́gẹ́ bí ohun èlò ìkọ́ni nínú ọ̀kan lára àwọn kíláàsì rẹ̀. Ìpinnu àwọn aláṣẹ ilé-ẹ̀kọ́ náà jẹ́ látàrí ìjẹ́rìí àìjẹ́-bí-àṣà tí àwọn òbí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jehofa àti ọ̀kan lára àwọn olùdarí ilé-ẹ̀kọ́ náà ti ṣe. Ǹjẹ́ kí Jehofa máa bá a nìṣó ní bíbùkún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ bí wọ́n ti ń pèsè ìtọ́ni àtàtà pẹ̀lú ìwé yìí.’ Bẹ́ẹ̀ni, ǹjẹ́ kí Jehofa máa bá a nìṣó láti bùkún ìtẹ̀síwájú àtàtà ti iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà ní ilẹ̀ ńlá ti Brazil.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 8]
ÌSỌFÚNNI ṢÓKÍ NÍPA ORÍLẸ̀-ÈDÈ
Ọdún Iṣẹ́-Ìsìn 1994
GÓŃGÓ IYE ÀWỌN TÍ Ń JẸ́RÌÍ: 385,099
ÌṢIRÒ-ÌFIWÉRA: Ẹlẹ́rìí 1 sí 404
ÀWỌN TÍ WỌ́N PÉSẸ̀ SÍBI ÌṢE-ÌRÁNTÍ: 1,018,210
ÌPÍNDỌ́GBA ÀWỌN AKÉDE TÍ WỌ́N JẸ́ AṢÁÁJÚ-Ọ̀NÀ: 38,348
ÌPÍNDỌ́GBA ÀWỌN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ BIBELI: 461,343
IYE TÍ A BATISÍ: 24,634
IYE ÀWỌN ÌJỌ: 5,928
Ọ́FÍÌSÌ Ẹ̀KA: CESÁRIO LANGE
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ tí ń gbóhùn sáfẹ́fẹ́ ti a ń lò ní São Paulo ní nǹkan bíi 1940
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Jíjẹ́rìí ní Ọgbà Òdòdó ní Rio de Janeiro
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Ọ́fíìsì ẹ̀ka ní Cesário Lange