Àwọn Ìlú Ààbò—Ìpèsè Aláàánú Ọlọrun
“Ìlú mẹ́fà wọ̀nyí ni yóò máa jẹ́ ààbò fún . . . olúkúlùkù ẹni tí ó bá pa ènìyàn ní àìmọ̀ kí ó lè máa sá lọ síbẹ̀.”—NUMERI 35:15.
1. Kí ni ojú ìwòye Ọlọrun nípa ìwàláàyè àti ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀?
JEHOFA ỌLỌRUN ka ìwàláàyè ẹ̀dá ènìyàn sí ohun mímọ́ ọlọ́wọ̀. Inú ẹ̀jẹ̀ sì ni ìwàláàyè wà. (Lefitiku 17:11‚ 14) Nítorí náà, Kaini, ẹ̀dá ènìyàn tí a kọ́kọ́ bí lórí ilẹ̀ ayé, jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀, nígbà tí ó pa arákùnrin rẹ̀, Abeli. Nítorí ìdí èyí, Ọlọrun sọ fún Kaini pé: “Ohùn ẹ̀jẹ̀ arákùnrin rẹ ń kígbe pè mí láti inú ilẹ̀ wá.” Ẹ̀jẹ̀ tí ó sọ ọ̀gangan ibi tí a ti pànìyàn náà di eléèérí, ń jẹ́rìí kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́, ṣùgbọ́n lọ́nà tí ó lágbára, nípa ìwàláàyè tí a ti fi ìwà ìkà gé kúrú náà. Ẹ̀jẹ̀ Abeli kígbe sókè sí Ọlọrun, fún ẹ̀san.—Genesisi 4:4-11.
2. Báwo ni a ṣe tẹnu mọ́ ọ̀wọ̀ tí Jehofa ní fún ìwàláàyè lẹ́yìn Ìkún Omi?
2 A tẹnu mọ́ ọ̀wọ̀ tí Ọlọrun ní fún ìwàláàyè ẹ̀dá ènìyàn lẹ́yìn tí Noa olódodo àti ìdílé rẹ̀ jáde kúrò nínú ọkọ̀ áàkì gẹ́gẹ́ bí olùla Ìkún Omi àgbáyé já. Nígbà náà ni Jehofa fi ẹran ara ẹranko kún ohun tí ènìyàn ń jẹ, ṣùgbọ́n èyí kò kan ẹ̀jẹ̀. Ó tún pàṣẹ pé: “Ẹ̀jẹ̀ yín àní ẹ̀mí yín ni èmi óò sì béèrè; lọ́wọ́ gbogbo ẹranko ni èmi óò béèrè rẹ̀, àti lọ́wọ́ ènìyàn, lọ́wọ́ arákùnrin olúkúlùkù ènìyàn ni èmi óò béèrè ẹ̀mí ènìyàn. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ta ẹ̀jẹ̀ ènìyàn sílẹ̀, láti ọwọ́ ènìyàn ni a óò sì ta ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sílẹ̀: nítorí pé ní àwòrán Ọlọrun ni ó dá ènìyàn.” (Genesisi 9:5‚ 6) Jehofa tọ́ka sí ẹ̀tọ́ tí ìbátan tí ó sún mọ́ òjìyà náà jù lọ ní láti pa apànìyàn náà nígbà tí ó bá bá a.—Numeri 35:19.
3. Ìtẹnumọ́ wo ni Òfin Mose gbé karí ìjẹ́mímọ́ ọlọ́wọ̀ ìwàláàyè?
3 Nínú Òfin tí a fún Israeli nípasẹ̀ wòlíì Mose, a tẹnu mọ́ ìjẹ́mímọ́ ọlọ́wọ̀ ìwàláàyè léraléra. Fún àpẹẹrẹ, Ọlọrun pàṣẹ pé: “Ìwọ kò gbọdọ̀ pànìyàn.” (Eksodu 20:13) Ọ̀wọ̀ fún ìwàláàyè tún hàn kedere nínú ohun tí Òfin Mose sọ nípa ikú tí ó bá kan aboyún. Òfin náà sọ ní kedere pé, bí òun tàbí ọlẹ̀ inú náà bá kú nítorí ìjàkadì láàárín ọkùnrin méjì, àwọn onídàájọ́ ní láti wo àyíká ipò náà àti bí ó ti ṣeé ṣe kí ó jẹ́ àmọ̀ọ́mọ̀ṣe tó, ṣùgbọ́n ìjìyà náà lè jẹ́ “ẹ̀mí dípò ẹ̀mí,” tàbí ìwàláàyè dípò ìwàláàyè. (Eksodu 21:22-25) Bí ó tilẹ̀ jẹ́ bẹ́ẹ̀, ó ha ṣeé ṣe fún apànìyàn kan ní Israeli láti bọ́ lọ́wọ́ àbájáde ìwà ìkà rẹ̀ lọ́nà kan ṣáá bí?
Ibi Ìsádi Ha Wà fún Àwọn Apànìyàn Bí?
4. Lẹ́yìn òde Israeli, ibi ìsádi wo ni ó wà ní ìgbà àtijọ́?
4 Ní àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn yàtọ̀ sí Israeli, a yọ̀ọ̀da fún àwọn apànìyàn àti àwọn ọ̀daràn mìíràn láti sá lọ sí ibi mímọ́, tàbí ibi ìsádi. Èyí rí bẹ́ẹ̀ ní àwọn ibì kan bíi tẹ́ḿpìlì àwọn abo ọlọrun Atẹmisi ní Efesu ìgbàanì. A ròyìn nípa irú àwọn ibi bẹ́ẹ̀ pé: “Àwọn ojúbọ kan ń fàyè gba kí àwọn ọ̀daràn máa pọ̀ sí i; ó sì máa ń fìgbà gbogbo pọn dandan láti dín iye ibi ìsádi kù. Ní Ateni, kìkì àwọn ibi mímọ́ díẹ̀ ni òfin fàyè gbà gẹ́gẹ́ bí ibi ààbò (fún àpẹẹrẹ, tẹ́ḿpìlì Theseus wà fún àwọn ẹrú); ní ìgbà Tiberiu, àwùjọ àwọn ọ̀daràn tí wọ́n wà ní àwọn ojúbọ wá di eléwu debi pé, ẹ̀tọ́ Ibi Ìsádi ni a fi mọ sí kìkì àwọn ìlú díẹ̀ (ní ọdún 22).” (The Jewish Encyclopedia, 1909, Ìdìpọ̀ II, ojú ìwé 256) Nígbà tí ó yá, àwọn ṣọ́ọ̀ṣì Kirisẹ́ńdọ̀mù di ibi ìsádi, ṣùgbọ́n ète èyí ni láti gba agbára kúrò lọ́wọ́ ìjọba kí ó sì di ti àlùfáà, ó sì ṣiṣẹ́ lòdì sí ṣíṣe ìdájọ́ òdodo lọ́nà ẹ̀tọ́. Àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, ṣíṣì í lò mú kí a fagi lé ètò yìí.
5. Ẹ̀rí wo ni ó fi hàn pé Òfin kò fàyè gba àìbìkítà gẹ́gẹ́ bí ìdí fún fífi àánú hàn nígbà tí a bá pa ẹnì kan?
5 Láàárín àwọn ọmọ Israeli, a kò gba àwọn amọ̀ọ́mọ̀ pànìyàn láyè láti lọ sí ibi mímọ́ tàbí ibi ìsádi. Àlùfáà Lefi pàápàá, tí ń ṣiṣẹ́ sìn níwájú pẹpẹ Ọlọrun, ni a ní láti mú lọ fún pípa bí ó bá dìtẹ̀ pànìyàn. (Eksodu 21:12-14) Ní àfikún sí i, Òfin náà kò fàyè gba àìbìkítà gẹ́gẹ́ bí ìdí fún fífi àánú hàn nígbà tí a bá pa ẹnì kan. Fún àpẹẹrẹ, ọkùnrin kan ní láti ṣe ìgbátí sí òrùlé ilé rẹ̀ tuntun. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, yóò jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀, bí ẹnì kan bá ṣubú láti orí òrùlé náà, tí ó sì kú. (Deuteronomi 22:8) Síwájú sí i, bí a bá ti kìlọ̀ fún olówó màlúù kan tí í máa ń kan ènìyàn níwo láti tọ́jú màlúù rẹ̀, ṣùgbọ́n tí kò mú màlúù rẹ̀ so, tí ó sì pa ẹnì kan, olówó màlúù náà jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀, a sì lè pa á. (Eksodu 21:28-32) Ẹ̀rí síwájú sí i nípa ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ tí Ọlọrun ní fún ìwàláàyè hàn gbangba ní ti pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá lu olè pa, jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀, bí ó bá ṣẹlẹ̀ ní ojúmọmọ nígbà tí a lè rí ọ̀yọjúràn náà, tí a sì lè dá a mọ̀. (Eksodu 22:2‚ 3) Nígbà náà, ó ṣe kedere pé, àwọn ìlànà Ọlọrun tí a mú pé pérépéré kò fàyè gba ẹni tí ó mọ̀ọ́mọ̀ pànìyàn láti bọ́ lọ́wọ́ ìjìyà ikú.
6. Báwo ni a ṣe ń mú òfin “ẹ̀mí dípò ẹ̀mí” ṣẹ ní Israeli ìgbàanì?
6 Bí a bá pànìyàn ní Israeli ìgbàanì, a ní láti gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ òjìyà náà. A óò mú òfin “ẹ̀mí dípò ẹ̀mí” ṣẹ nígbà tí “agbẹ̀san ẹ̀jẹ̀” bá pa apànìyàn náà. (Numeri 35:19) Agbẹ̀san náà ni ìbátan tí ó sún mọ́ ẹni tí a pa náà jù lọ lọ́kùnrin. Kí ni nípa ti ẹni tí kò mọ̀ọ́mọ̀ pànìyàn?
Ìpèsè Aláàánú Jehofa
7. Ìpèsè wo ni Ọlọrun ṣe fún àwọn tí kò bá mọ̀ọ́mọ̀ pànìyàn?
7 Ní ti àwọn tí wọ́n bá ṣèèṣì pànìyàn tàbí tí wọn kò mọ̀ọ́mọ̀, Ọlọrun fi tìfẹ́tìfẹ́ pèsè àwọn ìlú ààbò. Nípa èyí, a sọ fún Mose pé: “Sọ fún àwọn ọmọ Israeli, kí o sì wí fún wọn pé, Nígbà tí ẹ̀yin bá gòkè Jordani lọ sí ilẹ̀ Kenaani; nígbà náà ni kí ẹ̀yin kí ó yan ìlú fún ara yín tí yóò jẹ́ ìlú ààbò fún yín; kí apànìyàn tí ó pa ènìyàn ní àìmọ̀ kí ó lè máa sá lọ síbẹ̀. Wọ́n ó sì já sí ìlú ààbò kúrò lọ́wọ́ agbẹ̀san; kí ẹni tí ó pa ènìyàn kí ó má baà kú títí yóò fi dúró níwájú ìjọ àwọn ènìyàn ní ìdájọ́. Àti nínú ìlú wọ̀nyí tí ẹ̀yin óò fi fún wọn, mẹ́fà yóò jẹ́ ìlú ààbò fún yín. Kí ẹ̀yin kí ó yan ìlú mẹ́ta ní ìhà ìhín Jordani, kí ẹ̀yin kí ó sì yan ìlú mẹ́ta ní ilẹ̀ Kenaani, tí yóò máa jẹ́ ìlú ààbò . . . fún olúkúlùkù ẹni tí ó bá pa ènìyàn ní àìmọ̀ kí ó lè máa sá lọ síbẹ̀.”—Numeri 35:9-15.
8. Níbo ni a kọ́ àwọn ìlú ààbò sí, báwo ni a sì ṣe ń ran ẹnì kan tí kò mọ̀ọ́mọ̀ pànìyàn lọ́wọ́ láti dé ibẹ̀?
8 Nígbà tí àwọn ọmọ Israeli wọ Ilẹ̀ Ìlérí náà, wọ́n ṣègbọràn ní dídá ìlú ààbò mẹ́fà sílẹ̀. Mẹ́ta nínú ìlú wọ̀nyí—Kedeṣi, Ṣekemu, àti Hebroni—wà ní àríwá Odò Jordani. Ní ìlà oòrùn Jordani ni àwọn ìlú ààbò ti Golani, Ramotu, àti Beseri wà. A dá àwọn ìlú ààbò mẹ́fẹ̀ẹ̀fà náà sílẹ̀ ni àwọn ibi tí ó wà ní tòsí ní àwọn ojú ọ̀nà tí ó dára. A ri àmì tí ó ní àkọlé náà “ààbò” mọ́ àwọn ibi yíyẹ ní àwọn ojú ọ̀nà wọ̀nyí. Àwọn àmì wọ̀nyí tọ́ka sí ọ̀gangan ìlú ààbò náà, ẹni tí ó ṣèèṣì pànìyàn náà yóò sì sá àsálà fún ẹmí rẹ̀ lọ sí èyí tí ó sún mọ́ ọn jù lọ. Níbẹ̀ ni ó ti lè rí ààbò kúrò lọ́wọ́ agbẹ̀san ẹ̀jẹ̀.—Joṣua 20:2-9.
9. Èé ṣe tí Jehofa fi pèsè àwọn ìlú ààbò, fún àǹfààní àwọn wo sì ni a ṣe pèsè wọn?
9 Èé ṣe tí Ọlọrun fi pèsè àwọn ìlú ààbò? A pèsè wọn kí a má baà fi ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ ba ilẹ̀ náà jẹ́, kí ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ sì wá sórí àwọn ènìyàn náà. (Deuteronomi 19:10) Nítorí àwọn wo ni a ṣe pèsè àwọn ìlú ààbò náà? Òfin náà sọ pé: “Ìlú mẹ́fà wọ̀nyí ni yóò máa jẹ́ ààbò fún àwọn ọmọ Israeli, àti fún [àlejò olùgbé, NW] àti fún àtìpó láàárín wọn: kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá pa ènìyàn ní àìmọ̀ kí ó lè máa sá lọ síbẹ̀.” (Numeri 35:15) Nípa báyìí, kí ó má baà sí ojúsàájú, kí ó baà sì lè bá góńgó rẹ̀ ti ìdájọ́ òdodo mu, bí a ti ń fàánú hàn, Jehofa sọ fún àwọn ọmọ Israeli láti ya àwọn ìlú ààbò sọ́tọ̀ fún (1) àwọn ọmọ Israeli, (2) àwọn àlejò olùgbé ní Israeli, tàbí (3) àwọn àtìpó láti orílẹ̀-èdè mìíràn tí wọ́n ń gbé ilẹ̀ náà, tí kò bá mọ̀ọ́mọ̀ pànìyàn.
10. Èé ṣe tí a fi lè sọ pé àwọn ìlú ààbò jẹ́ ìpèsè aláàánú tí Ọlọrun ṣe?
10 Ó gba àfiyè sí pé, bí ẹni náà kò bá tilẹ̀ mọ̀ọ́mọ̀ pànìyàn, ikú tó sí i lábẹ́ òfin Ọlọrun pé: “Ẹnikẹ́ni tí ó bá ta ẹ̀jẹ̀ ènìyàn sílẹ̀, láti ọwọ́ ènìyàn ni a óò sì ta ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sílẹ̀.” Nítorí náà, kìkì nítorí ìpèsè aláàánú Jehofa Ọlọrun ni ẹni tí kò mọ̀ọ́mọ̀ pànìyàn fi lè sá lọ sí ọ̀kan nínú àwọn ìlú ààbò náà. Ó dájú pé, àwọn ènìyàn náà lápapọ̀ ń bá ẹnikẹ́ni tí ó bá ń sá fún agbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ kẹ́dùn, nítorí gbogbo wọn mọ̀ pé àwọn náà lè dá irú ọ̀ràn bẹ́ẹ̀ láìmọ̀ọ́mọ̀, kí àwọ́n sì ní láti wá ààbò àti àánú.
Ìsákiri fún Ààbò
11. Ní Israeli ìgbàanì, kí ni ẹnì kan lè ṣe bí ó bá ṣèèṣì pa alábàáṣiṣẹ́pọ̀ kan?
11 Àpèjúwe kan lè jẹ́ kí o túbọ̀ mọrírì ìṣètò aláàánú Ọlọrun fún ààbò. Finú wò ó náà, pé o ń gé igi ní Israeli ìgbàanì. Ká ni orí àáké náà fò yọ lójijì kúrò lára èèkù rẹ̀, tí ó sì pa alábàáṣiṣẹ́pọ̀ kan. Kí ni ìwọ yóò ṣe? Tóò, Òfin yọ̀ọ̀da fún irú ipò yìí. Ó dájú pé, ìwọ̀ yóò lo àǹfààní tí Ọlọrun pèsè yìí pé: “Èyí sì ni ọ̀ràn apànìyàn, tí yóò máa sá síbẹ̀ [sí ìlú ààbò], kí ó lè yè: ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣèèṣì pa ẹnìkejì rẹ̀, tí òun kò kórìíra rẹ̀ tẹ́lẹ̀ rí; bíi nígbà tí ènìyàn bá wọ inú igbó lọ pẹ̀lú ẹnì kejì rẹ̀ láti ké igi, tí ó sì fi ọwọ́ rẹ̀ gbé àáké láti fi ké igi náà lulẹ̀, tí àáké sì yọ kúrò nínú ẹ̀rú, tí ó sì ba ẹnì kejì rẹ̀, tí òun kú; kí ó sá lọ sí ọ̀kan nínú ìlú wọnnì, kí ó sì yè.” (Deuteronomi 19:4‚ 5) Síbẹ̀, bí o bá tilẹ̀ dé ìlú ààbò náà, ìwọ kì yóò bọ́ pátápátá lọ́wọ́ jíjíhìn ohun tí ó ṣẹlẹ̀.
12. Àwọn ìlànà wo ni a ní láti tẹ̀ lé, lẹ́yìn tí ẹnì kan tí kò mọ̀ọ́mọ̀ pànìyàn bá ti dé ìlú ààbò?
12 Bí a tilẹ̀ gbà ọ́ tọwọ́tẹsẹ̀, o ṣì ní láti rojọ́ lọ́dọ̀ àwọn àgbààgbà ní ẹnu bodè ìlú ààbò náà. Lẹ́yìn tí ó bá ti wọ ìlú náà, a óò dá ọ padà láti rojọ́ níwájú àwọn àgbààgbà tí ń ṣojú fún ìjọ Israeli ní ẹnu bodè ìlú tí wọ́n ní àṣẹ lórí àgbègbè ibi tí ìpànìyàn náà ti ṣẹlẹ̀. Níbẹ̀ ni ìwọ yóò ti ní àǹfààní láti fi ẹ̀rí hàn pé o kò jẹ̀bi.
Nígbà Tí Àwọn Apànìyàn Bá Ń Jẹ́jọ́
13, 14. Kí ni àwọn ohun tí àwọn àgbààgbà yóò fẹ́ láti mọ̀ dájú nígbà tí wọ́n bá ń gbẹ́jọ́ apànìyàn kan?
13 Nígbà ìjẹ́jọ́ níwájú àwọn àgbààgbà ní ẹnu bodè ìlú tí wọ́n ń ṣàkóso náà, láìṣàníàní, ìwọ yóò ṣàkíyèsí pẹ̀lú ìmọrírì pé a tẹnu mọ́ ìṣesí rẹ àtẹ̀yìnwá. Àwọn àgbààgbà náà yóò fi tìṣọ́ratìṣọ́ra yẹ ìbáṣepọ̀ rẹ pẹ̀lú òjìyà náà wò. O ha kórìíra ẹni náà, o ha lúgọ dè é, tí o sì mọ̀ọ́mọ̀ lù ú pa bí? Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, àwọn àgbààgbà náà yóò fà ọ́ lé agbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ lọ́wọ́, ìwọ yóò sì kú. Àwọn ọkùnrin tí wọ́n níláárí wọ̀nyí yóò mọ ohun tí Òfin béèrè fún pé ‘kí a mú ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ kúrò ní Israeli.’ (Deuteronomi 19:11-13) Ní ìfiwéra, nígbà ìgbésẹ̀ ìdájọ́ lónìí, àwọn Kristian alàgbà ní láti mọ Ìwé Mímọ́ dáradára, kí wọ́n sì ṣiṣẹ́ ní ìbámu pẹ̀lú wọn, bí wọ́n ti ń gbé ìṣe àti ìwà àtẹ̀yìnwá ẹlẹ́ṣẹ̀ náà yẹ̀ wò.
14 Bí wọ́n ti ń fi inú rere ṣe ìwádìí, àwọn àgbààgbà ìlú náà yóò fẹ́ láti mọ̀ bóyá o ba de òjìyà náà. (Eksodu 21:12‚ 13) O ha kọlù ú láti ibi tí o sá pamọ́ sí bí? (Deuteronomi 27:24) Inú rẹ ha ru gùdù sí onítọ̀hún débi pé o pète láti pa á bí? Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, o tọ́ sí ikú. (Eksodu 21:14) Ní pàtàkì, àwọn àgbààgbà náà ní láti mọ̀ bí ọ̀tá, tàbí ìkórìíra, bá wà láàárín ìwọ àti òjìyà náà. (Deuteronomi 19:4‚ 6‚ 7; Joṣua 20:5) Jẹ́ kí a sọ pé àwọn àgbààgbà rí i pé o kò jẹbi, tí wọ́n sì dá ọ padà sí ìlú ààbò. Wo bí ọpẹ́ rẹ yóò ti pọ̀ tó fún àánú tí wọ́n fi hàn!
Ìgbésí Ayé Nínú Ìlú Ààbò
15. Àwọn ohun àbéèrèfún wo ni a kàn nípá fún ẹni tí ó mọ̀ọ́mọ̀ pànìyàn?
15 Ẹni tí kò mọ̀ọ́mọ̀ pànìyàn náà ní láti dúró sí ìlú ààbò náà tàbí ní ibi tí kò ju 1,000 ìgbọ̀nwọ́ (nǹkan bíi 442 mítà) sí odi ìlú náà. (Numeri 35:2-4) Bí ó bá rìn gbéregbère kọjá ibẹ̀ yẹn, ó lè pàdé agbẹ̀san ẹ̀jẹ̀. Lábẹ́ àwọn ipò báyìí, agbẹ̀san náà lè pa apànìyàn náà láìjẹ̀bi rárá. Ṣùgbọ́n, a kò de apànìyàn náà ní ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ tàbí fi í sẹ́wọ̀n. Gẹ́gẹ́ bí olùgbé ìlú ààbò náà, ó ní láti kọ́ òwò kan, kí ó jẹ́ òṣìṣẹ́, kí ó sì ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bíi mẹ́ḿbà tí ó wúlò láwùjọ.
16. (a) Báwo ni ẹni tí kò mọ̀ọ́mọ̀ pànìyàn náà ṣe ní láti wà ní ìlú ààbò pẹ́ tó? (b) Èé ṣe tí ikú àlùfáà àgbà fi mú kí ó ṣeé ṣe fún apànìyàn náà láti kúrò ní ìlú ààbò?
16 Báwo ni ẹni tí kò mọ̀ọ́mọ̀ pànìyàn náà yóò ti pẹ́ tó ní ìlú ààbò? Ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ fún gbogbo ìyókù ìgbésí ayé rẹ̀. Èyí ó wù kí ó jẹ́, Òfin sọ pé: “Nítorí pé òun ì bá jókòó nínú ìlú ààbò rẹ̀ títí di ìgbà ikú [àlùfáà àgbà, NW]: àti lẹ́yìn ikú [àlùfáà àgbà, NW] kí apànìyàn náà kí ó padà lọ sí ilẹ̀ ìní rẹ̀.” (Numeri 35:26-28) Èé ṣe tí ikú àlùfáà àgbà fi yọ̀ọ̀da fún ẹni tí kò mọ̀ọ́mọ̀ pànìyàn náà láti fi ìlú ààbò sílẹ̀? Tóò, àlùfáà àgbà náà jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ẹni yíyọrí ọlá jù lọ ní orílẹ̀-èdè náà. Nítorí náà, ikú rẹ̀ yóò jẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ kan tí wọn yóò mọ̀ láàárín gbogbo ẹ̀yà Israeli. Nígbà náà, gbogbo àwọn olùwáibiìsádi lè padà sí ilé wọn, kí wọ́n sì bọ́ lọ́wọ́ ewu àwọn agbẹ̀san ẹ̀jẹ̀. Èé ṣe? Nítorí pé Òfin Ọlọrun ti pàṣẹ pé, àǹfààní tí agbẹ̀san ní láti pa apànìyàn náà dópin nígbà tí àlùfáà àgbà náà bá kú, gbogbo ènìyàn sì mọ èyí. Bí ẹni tí ó sún mọ́ ọn jù lọ bá ní láti gbẹ̀san ikú náà lẹ́yìn ìyẹn, yóò di apànìyàn, a óò sì pa òun náà.
Àbájáde Wíwà Pẹ́ Títí
17. Kí ni ó lè jẹ́ àbájáde àwọn ìkàléèwọ̀ tí a gbé karí ẹni náà tí kò mọ̀ọ́mọ̀ pànìyàn?
17 Kí ni àwọn àbájáde tí ó ṣeé ṣe kí ìkàléèwọ̀ náà gbé karí ẹni tí kò mọ̀ọ́mọ̀ pànìyàn náà? Wọ́n jẹ́ ìránnilétí pé ó ti pa ẹnì kan. Ó ṣeé ṣe, kí ó máa fojú wo ìwàláàyè ẹ̀dá ènìyàn gẹ́gẹ́ bí ohun mímọ́ ọlọ́wọ̀ títí gbére. Ní àfikún sí i, kò ní gbàgbé láé pé a fi àánú hàn sí òun. Ní ti pé a ti fi àánú hàn sí i, dájúdájú, yóò fẹ́ láti fi àánú hàn sí àwọn ẹlòmíràn. Ètò àwọn ìlú ààbò pẹ̀lú àwọn ìkàléèwọ̀ wọn tún jẹ́ àǹfààní fún àwọn ènìyàn náà ní gbogbogbòò. Báwo ni ó ṣe rí bẹ́ẹ̀? Ó ti ní láti tẹ̀ ẹ́ mọ́ wọn lọ́kàn pé, wọn kò gbọdọ̀ ṣàìbìkítà tàbí dágunlá nípa ìwàláàyè ẹ̀dá ènìyàn. Nípa báyìí, ó yẹ kí àwọn Kristian rántí pé wọn ní láti yẹra fún àìbìkítà tí ó lè yọrí sí ṣíṣèèṣì pànìyàn. Nígbà náà pẹ̀lú, ó yẹ kí ìṣètò aláàánú Ọlọrun fún àwọn ìlú ààbò sún wa láti fi àánú hàn nígbà tí ó bá yẹ bẹ́ẹ̀.—Jakọbu 2:13.
18. Ní àwọn ọ̀nà wo ni ṣíṣètò tí Ọlọrun ṣètò fún àwọn ìlú ààbò fi ṣàǹfààní?
18 Pípèsè tí Jehofa Ọlọrun pèsè àwọn ìlú ààbò tún ṣàǹfààní ní àwọn ọ̀nà mìíràn. Àwọn ènìyàn náà kò dá ìgbìmọ̀ tí ń mú ọ̀daràn sílẹ̀, láti máa lépa apànìyàn náà pẹ̀lú fífi ìkùgbù rò pé ó jẹ̀bi, ṣáájú kí a tó gbẹ́jọ́ rẹ̀. Dípò bẹ́ẹ̀, wọ́n kà á sí ẹni tí kò jẹ̀bi ní ti ọ̀ràn mímọ̀ọ́mọ̀ pànìyàn, wọ́n tilẹ̀ ń ràn án lọ́wọ́ láti lọ sí ibi tí kò séwu. Síwájú sí i, ìpèsè àwọn ìlú ààbò jẹ́ òdì kejì ìṣètò òde òní ti fífi apànìyàn náà sẹ́wọ̀n, níbi tí àwọn ará ìlú ti ń fi owó ràn wọ́n lọ́wọ́, tí wọ́n sì máa ń di ọ̀daràn tí ó burú sí i nítorí ìfararora wọn pẹ̀lú àwọn oníwà àìtọ́ mìíràn. Nínú ìṣètò ìlú ààbò, kò pọn dandan láti kọ́, láti ṣàbójútó, àti láti máa ṣọ́ àwọn ògiri olówó gọbọi, tí a fi irin sí ẹnu ọ̀nà rẹ̀ tí àwọn ẹlẹ́wọ̀n sábà máa ń fẹ́ láti gbà sá lọ. Ní ti gidi, apànìyàn náà sá wá sí “ọgbà ẹ̀wọ̀n,” ó sì dúró síbẹ̀ láàárín àkókò tí a yàn kalẹ̀ náà. Ó tún ní láti jẹ́ òṣìṣẹ́, kí ó sì máa tipa báyìí ṣe ohun tí yóò ṣàǹfààní fún àwọn ẹ̀dá ènìyàn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀.
19. Àwọn ìbéèrè wo ni ó dìde nípa àwọn ìlú ààbò?
19 Ní tòótọ́, ìṣètò àwọn ìlú ààbò ní Israeli, tí Jehofa ṣe fún dídáàbò bo àwọn tí kò mọ̀ọ́mọ̀ pànìyàn, jẹ́ ti àánú. Dájúdájú, ìpèsè yìí gbé ọ̀wọ̀ fún ìwàláàyè ró. Ṣùgbọ́n, àwọn ìlú ààbò ti ìgbàanì ha ní ìtumọ̀ fún àwọn ènìyàn tí ń gbé ní ọ̀rúndún ogún bí? A ha lè jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ níwájú Jehofa Ọlọrun, kí á má sì mọ̀ pé a nílò àánú rẹ̀ bí? Àwọn ìlú ààbò Israeli ha ní ìjẹ́pàtàkì kankan fún wa ní òde òní bí?
Báwo Ni Ìwọ Yóò Ṣe Dáhùn?
◻ Ojú wo ni Jehofa fi ń wo ìwàláàyè ẹ̀dá ènìyàn?
◻ Ìpèsè aláàánú wo ni Ọlọrun ṣe fún àwọn tí kò mọ̀ọ́mọ̀ pànìyàn?
◻ Báwo ni apànìyàn kan ṣe ń wọnú ìlú ààbò, báwo ni yóò sì ṣe pẹ́ tó níbẹ̀?
◻ Kí ni ó lè jẹ́ àbájáde ìkàléèwọ̀ tí a gbé karí ẹni náà tí kò mọ̀ọ́mọ̀ pànìyàn?
[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 12]
A kọ́ àwọn ìlú ààbò ní Israeli síbi tí ó rọrùn
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
KEDEṢI Odò Jordani GOLANI
ṢEKEMU RAMOTU
HEBRONI BESERI