Bánábà—“Ọmọ Ìtùnú”
ÌGBÀ wo ni o rí ìtùnú gbà láti ọ̀dọ̀ ọ̀rẹ́ kan kẹ́yìn? O ha rántí ìgbà tí o tu ẹnì kan nínú kẹ́yìn bí? Láti ìgbàdégbà, gbogbo wa nílò ìṣírí, ẹ sì wo bí a ṣe mọrírì àwọn tí wọ́n ń fi ìfẹ́ fi í fúnni tó! Títuninínú dọ́gbọ́n túmọ̀ sí fífarabalẹ̀ tẹ́tí síni, lílóye ẹni, àti rírannilọ́wọ́. Ìwọ ha ṣe tán láti ṣe ìyẹn bí?
Ẹnì kan tí ó fi irú ìmúratán bẹ́ẹ̀ hàn lọ́nà àwòfiṣàpẹẹrẹ ni Bánábà, ẹni tí ó jẹ́ “ènìyàn rere, [tí] ó sì kún fún ẹ̀mí mímọ́ àti ìgbàgbọ́.” (Ìṣe 11:24) Èé ṣe tí a fi lè sọ ìyẹn nípa Bánábà? Kí ni ó ti ṣe kí a tó lè sọ̀rọ̀ rẹ̀ báyìí?
Ọ̀làwọ́ Arannilọ́wọ́
Jósẹ́fù gan-an ni orúkọ rẹ̀, ṣùgbọ́n àwọn àpọ́sítélì fún un ní àpèlé alápèjúwe kan tí ó bá ìwà rẹ̀ mú gẹ́lẹ́—Bánábà, tí ó túmọ̀ sí “Ọmọ Ìtùnú.”a (Ìṣe 4:36) Kò tí ì pẹ́ púpọ̀ tí a dá ìjọ Kristẹni sílẹ̀. Àwọn kan rò pé Bánábà ti jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Jésù tipẹ́. (Lúùkù 10:1, 2) Yálà bẹ́ẹ̀ ni tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́, ọkùnrin yìí ti fi hàn pé ẹniire ni òun jẹ́.
Kété lẹ́yìn Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa, Bánábà, tí ó jẹ́ ọmọ Léfì láti Kípírọ́sì, fínnúfíndọ̀ ta ilẹ̀ kan, ó sì kó owó rẹ̀ lé àwọn àpọ́sítélì lọ́wọ́. Èé ṣe tí ó fi ṣe ìyẹn? Àkọsílẹ̀ ìwé Ìṣe sọ fún wa pé láàárín àwọn Kristẹni ní Jerúsálẹ́mù ní àkókò náà, “wọn a pín nǹkan fún olúkúlùkù, gan-an gẹ́gẹ́ bí àìní rẹ̀ bá ṣe rí.” Ó hàn gbangba sí Bánábà pé àìní ń bẹ, ó sì fi ayọ̀ ṣe ohun kan nípa rẹ̀. (Ìṣe 4:34-37) Ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ ẹni tí ó rí jájẹ, ṣùgbọ́n kò lọ́ tìkọ̀ láti fi ohun ìní rẹ̀ tọrẹ, kí ó sì yọ̀ǹda ara rẹ̀ fún ìtẹ̀síwájú ire Ìjọba.b Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ náà, F. F. Bruce, wí pé: “Ibikíbi tí Bánábà bá ti rí àwọn ènìyàn tàbí ipò tí ó ń nílò ìṣírí, yóò fún wọn ní gbogbo ìṣírí tí ó bá lè fún wọn.” Èyí hàn gbangba nínú ìtàn kejì tí ó ti fara hàn.
Ní nǹkan bí ọdún 36 Sànmánì Tiwa, Sọ́ọ̀lù ará Tásù (tí yóò di àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù lọ́jọ́ iwájú), tí ó ti wá di Kristẹni nísinsìnyí, ń gbìyànjú láti kàn sí ìjọ Jerúsálẹ́mù, “ṣùgbọ́n gbogbo wọn ń fòyà rẹ̀, nítorí wọn kò gbà gbọ́ pé ọmọ ẹ̀yìn ni.” Báwo ni yóò ṣe mú un dá ìjọ lójú pé lóòótọ́ ni òun ti yí padà, pé kì í ṣe ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ láti túbọ̀ ba ìjọ jẹ́ ni òun ń dá? “Bánábà wá ṣe àrànṣe fún un, ó sì mú un lọ bá àwọn àpọ́sítélì.”—Ìṣe 9:26, 27; Gálátíà 1:13, 18, 19.
A kò sọ ìdí tí Bánábà fi fọkàn tán Sọ́ọ̀lù. Ohun yòówù tí ó lè jẹ́, “Ọmọ Ìtùnú” náà gbé ní ìbámu pẹ̀lú àpèlé rẹ̀ nípa títẹ́tísílẹ̀ sí Sọ́ọ̀lù àti ríràn án lọ́wọ́ láti yọ nínú ipò àìnírètí tí ó jọ pé ó wà. Bí Sọ́ọ̀lù tilẹ̀ padà sí ìlú rẹ̀, Tásù, àwọn méjèèjì ti di ọ̀rẹ́. Ní àwọn ọdún mélòó kan sí i, ìyẹn yóò ní àbájáde pàtàkì.—Ìṣe 9:30.
Ní Áńtíókù
Ní nǹkan bí ọdún 45 Sànmánì Tiwa, ìròyìn nípa ìṣẹ̀lẹ̀ ṣíṣàjèjì tí ó wáyé ní Áńtíókù ti Síríà dé Jerúsálẹ́mù—ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn olùgbé ìlú náà tí wọ́n ń sọ èdè Gíríìkì ti ń di onígbàgbọ́. Ìjọ rán Bánábà lọ láti lọ wádìí, kí ó sì ṣètò iṣẹ́ níbẹ̀. Òun ni ẹni tí ó tóótun tí wọ́n lè yàn láti lọ. Lúùkù sọ pé: “Nígbà tí ó dé, tí ó sì rí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run, ó yọ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fún gbogbo wọn ní ìṣírí láti máa bá a lọ nínú Olúwa pẹ̀lú ète àtọkànwá; nítorí ó jẹ́ ènìyàn rere, ó sì kún fún ẹ̀mí mímọ́ àti ìgbàgbọ́. Ogunlọ́gọ̀ tí ó pọ̀ ni a sì fi kún Olúwa.”—Ìṣe 11:22-24.
Ìyẹn nìkan kọ́ ni ohun tí ó ṣe. Gẹ́gẹ́ bí ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ náà, Giuseppe Ricciotti, ti sọ, “Bánábà jẹ́ ẹni tí kì í fọ̀rọ̀ falẹ̀, kíá ni ó mọ̀ pé òun ní láti mú iṣẹ́ ṣe láti lè rí i dájú pé ìkórè rẹpẹtẹ ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn irú ìmésojáde lọ́nà tí ó fi hàn pé nǹkan yóò ṣẹnuure bẹ́ẹ̀. Nítorí náà, wíwá àwọn òṣìṣẹ́ ìkórè rí ni ohun àkọ́kọ́ tí a nílò.” Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ Kípírọ́sì ni Bánábà ti wá, ó ṣeé ṣe kí ó ti mọ bí a ti í bá àwọn Kèfèrí lò. Ó ti lè nímọ̀lára ní pàtàkì pé òun tóótun láti wàásù fún àwọn abọ̀rìṣà. Ṣùgbọ́n ó ṣe tán láti jẹ́ kí àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ nínú ìgbòkègbodò tí ń mórí yá, tí ó sì ń fúnni níṣìírí yìí.
Bánábà ronú kan Sọ́ọ̀lù. Ó ṣeé ṣe pé, Bánábà gbọ́ nípa ìṣípayá alásọtẹ́lẹ̀ tí a fi han Ananíà nígbà tí Sọ́ọ̀lù yí padà, pé ẹni náà tí ń ṣenúnibíni tẹ́lẹ̀ jẹ́ ‘ohun èlò, láti gbé orúkọ Jésù lọ sọ́dọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè.’ (Ìṣe 9:15) Nítorí náà, Bánábà forí lé Tásù—ìrìn àjò tí ó lé ní nǹkan bí 200 kìlómítà ní àlọ nìkan—láti wá Sọ́ọ̀lù kàn. Àwọn méjèèjì ṣiṣẹ́ pa pọ̀ gẹ́gẹ́ bí alábàáṣiṣẹ́pọ̀ fún odiidi ọdún kan, “Áńtíókù sì ni a ti kọ́kọ́ tipasẹ̀ ìdarí àtọ̀runwá pe àwọn ọmọ ẹ̀yìn ní Kristẹni,” láàárín àkókò yìí.—Ìṣe 11:25, 26.
Nígbà ìṣàkóso Claudius, ìyàn mú gan-an ní ọ̀pọ̀ àgbègbè Ilẹ̀ Ọba Róòmù. Gẹ́gẹ́ bí òpìtàn Júù náà, Josephus, ti sọ, ní Jerúsálẹ́mù “ọ̀pọ̀ ènìyàn kú nítorí wọn kò ní ohun tí wọn yóò fi ra oúnjẹ.” Nípa báyìí, àwọn ọmọ ẹ̀yìn ní Áńtíókù “pinnu, ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn gẹ́gẹ́ bí agbára olúkúlùkù ti lè gbé e, láti fi ìpèsè a-dín-ìṣòrokù ránṣẹ́ sí àwọn ará tí ń gbé ní Jùdíà; èyí ni wọ́n sì ṣe, wọ́n fi í ránṣẹ́ sí àwọn àgbà ọkùnrin láti ọwọ́ Bánábà àti Sọ́ọ̀lù.” Lẹ́yìn tí wọ́n parí iṣẹ́ náà pátápátá, Jòhánù Máàkù bá àwọn méjèèjì padà sí Áńtíókù, níbi tí a ti kà wọ́n mọ́ àwọn wòlíì àti olùkọ́ ìjọ.—Ìṣe 11:29, 30; 12:25; 13:1.
Iṣẹ́ Àyànfúnni Míṣọ́nnárì Àkànṣe
Lẹ́yìn ìyẹn ìṣẹ̀lẹ̀ àrà ọ̀tọ̀ kan wáyé. “Bí wọ́n ti ń ṣèránṣẹ́ fún Jèhófà ní gbangba, tí wọ́n sì ń gbààwẹ̀, ẹ̀mí mímọ́ wí pé: ‘Nínú gbogbo ènìyàn, ẹ ya Bánábà àti Sọ́ọ̀lù sọ́tọ̀ gedegbe fún mi fún iṣẹ́ tí mo pè wọ́n sí.’” Rò ó wò ná! Ẹ̀mí Jèhófà pàṣẹ pé kí a yán iṣẹ́ àkànṣe fún àwọn méjèèjì. “Ní ìbámu pẹ̀lú èyí, àwọn ọkùnrin wọ̀nyí, tí ẹ̀mí mímọ́ rán jáde, sọ̀ kalẹ̀ lọ sí Séléúkíà, wọ́n sì ṣíkọ̀ láti ibẹ̀ lọ sí Kípírù.” A tún lè pe Bánábà ní àpọ́sítélì, tàbí ẹni tí a rán jáde.—Ìṣe 13:2, 4; 14:14.
Lẹ́yìn rírin ìrìn àjò lọ sí Kípírù, tí wọ́n sì yí Sájíọ́sì Pọ́lọ́sì, gómìnà ẹkùn erékùṣù Róòmù, lọ́kàn padà, wọ́n kọjá lọ sí Pẹ́gà, ní gúúsù etíkun Éṣíà Kékeré, ibi tí Jòhánù Máàkù ti fi wọ́n sílẹ̀, tí ó sì padà sí Jerúsálẹ́mù. (Ìṣe 13:13) Ó dàbí ẹni pé títí di ìgbà yẹn Bánábà ni ó ń mú ipò iwájú, bóyá nítorí pé òun ni alábàáṣiṣẹ́pọ̀ tí ó ní ìrírí jù. Láti àkókò yìí lọ, Sọ́ọ̀lù (tí a ń pè ní Pọ́ọ̀lù nísinsìnyí) ni ó ń mú ipò iwájú. (Fi wé Ìṣe 13:7, 13, 16; 15:2.) Èyí ha ba Bánábà lọ́kàn jẹ́ bí? Rárá o, ó jẹ́ Kristẹni kan tí ó dàgbà dénú, tí ó fi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ gbà pé Jèhófà ń lo alábàáṣiṣẹ́pọ̀ òun pẹ̀lú lọ́nà tí ó lágbára. Nípasẹ̀ wọn, Jèhófà fẹ́ kí àwọn ìpínlẹ̀ mìíràn gbọ́ ìhìn rere náà.
Ní tòótọ́, kí a tó lé àwọn méjèèjì jáde kúrò ní Áńtíókù ní Písídíà, gbogbo àgbègbè náà ti gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run láti ẹnu Pọ́ọ̀lù àti Bánábà, ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ wọn sì gba ìhìn iṣẹ́ náà. (Ìṣe 13:43, 48-52) Ní Íkóníónì, “ògìdìgbó ńlá àwọn Júù àti Gíríìkì di onígbàgbọ́.” Èyí sún Pọ́ọ̀lù àti Bánábà láti lo àkókò gígùn níbẹ̀, ‘wọ́n ń sọ̀rọ̀ pẹ̀lú àìṣojo nípasẹ̀ ọlá àṣẹ Jèhófà, ẹni tí ó jẹ́ kí iṣẹ́ àmì àti àmì àgbàyanu máa ṣẹlẹ̀ láti ọwọ́ wọn.’ Nígbà tí wọ́n gbọ́ pé àwọn kan ti gbìmọ̀ láti sọ wọ́n ní òkúta, àwọn méjèèjì fi ọgbọ́n fẹsẹ̀ fẹ́ẹ, wọ́n sì ń bá iṣẹ́ wọn lọ ní Likaóníà, Lísírà, àti Déébè. Láìka ìrírí tí ó wu ẹ̀mí wọn léwu, tí wọ́n bá pàdé ní Lísírà sí, Bánábà àti Pọ́ọ̀lù ń bá a nìṣó, “wọ́n ń fún ọkàn àwọn ọmọ ẹ̀yìn lókun, wọ́n ń fún wọn ní ìṣírí láti dúró nínú ìgbàgbọ́, wọ́n sì wí pé: ‘A gbọ́dọ̀ ti inú ọ̀pọ̀ ìpọ́njú wọ ìjọba Ọlọ́run.’”—Ìṣe 14:1-7, 19-22.
Àwọn ọ̀jáfáfá oníwàásù méjèèjì wọ̀nyí kò ní gbà kí a mú wọn láyà pami. Ní òdì kejì, wọ́n padà lọ láti gbé àwọn Kristẹni tuntun ró ní ọ̀pọ̀ ibi tí wọ́n ti kojú àtakò gbígbóná janjan tẹ́lẹ̀ rí, ó ṣeé ṣe kí wọ́n máa ran àwọn ọkùnrin tí ó tóótun lọ́wọ́ láti mú ipò iwájú nínú àwọn ìjọ tuntun.
Ọ̀ràn Ìdádọ̀dọ́
Ní nǹkan bí ọdún 16 lẹ́yìn Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa, Bánábà lọ́wọ́ nínú ìṣẹ̀lẹ̀ mánigbàgbé kan tí ó dá lórí ọ̀ràn ìdádọ̀dọ́. “Àwọn ọkùnrin kan sọ̀ kalẹ̀ wá láti Jùdíà [sí Áńtíókù ti Síríà], wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ àwọn ará pé: ‘Láìjẹ́ pé ẹ dádọ̀dọ́ gẹ́gẹ́ bí àṣà tí Mósè fi lélẹ̀, a kò lè gbà yín là.’” Ìrírí jẹ́ kí Bánábà àti Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé èyí kò rí bẹ́ẹ̀, wọ́n sì tako kókó náà. Dípò lílo agbára tí wọ́n ní, wọ́n lóye pé èyí jẹ́ ìbéèrè kan tí a ní láti yanjú fún ire gbogbo ẹgbẹ́ ará. Nítorí náà, wọ́n darí ìbéèrè náà sí ẹgbẹ́ olùṣàkóso ní Jerúsálẹ́mù, níbi tí ìròyìn wọn ti ṣèrànwọ́ láti yanjú ọ̀ràn náà. Lẹ́yìn náà, Pọ́ọ̀lù àti Bánábà, tí a ṣàpèjúwe gẹ́gẹ́ bí “àwọn olólùfẹ́ wa . . . tí wọ́n ti jọ̀wọ́ ọkàn wọn lọ́wọ́ nítorí orúkọ Jésù Kristi Olúwa wa,” wà lára àwọn tí a rán lọ láti lọ fi ìpinnu náà tó àwọn ará ní Áńtíókù létí. Nígbà tí wọ́n ka lẹ́tà tí ẹgbẹ́ olùṣàkóso kọ, tí wọ́n sì sọ àwíyé, ìjọ náà “yọ̀ nítorí ìṣírí náà,” a sì fún wọn “lókun.”—Ìṣe 15:1, 2, 4, 25-32.
“Ìbújáde Ìbínú Mímúná”
Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ àkọsílẹ̀ rere nípa rẹ̀, a lè rò pé kò lè ṣeé ṣe fún wa láti ṣe bí ti Bánábà láé. Síbẹ̀, “Ọmọ Ìtùnú” náà jẹ́ aláìpé gẹ́gẹ́ bí àwa pẹ̀lú ti jẹ́. Nígbà tí òun àti Pọ́ọ̀lù ń wéwèé ìrìn àjò míṣọ́nnárì ẹlẹ́ẹ̀kejì láti bẹ àwọn ìjọ wò, aáwọ̀ kan wáyé láàárín wọn. Bánábà pinnu láti mú Jòhánù Máàkù ọmọ ẹ̀gbọ́n rẹ̀, dání, ṣùgbọ́n Pọ́ọ̀lù kò rò pé ó tọ́, níwọ̀n bí Jòhánù Máàkù ti fi wọ́n sílẹ̀ nígbà ìrìn àjò míṣọ́nnárì àkọ́kọ́. “Ìbújáde ìbínú mímúná wáyé, tí ó fi jẹ́ pé wọ́n pínyà kúrò lọ́dọ̀ ara wọn; Bánábà mú Máàkù dání, ó sì ṣíkọ̀ lọ sí Kípírù,” nígbà tí “Pọ́ọ̀lù yan Sílà, ó sì lọ” sí apá ibòmíràn.—Ìṣe 15:36-40.
Èyí mà bani nínú jẹ́ o! Àní bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, ìṣẹ̀lẹ̀ náà jẹ́ kí a mọ ohun mìíràn nípa àkópọ̀ ìwà Bánábà. Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan sọ pé: “Títí láé ni mímúra tí Bánábà múra tán láti fẹ̀mí ara rẹ̀ wewu àti níní tí ó ní ìgbọ́kànlé nínú Máàkù lẹ́ẹ̀kejì yóò máa fi kún iyì rẹ̀.” Gẹ́gẹ́ bí èrò òǹkọ̀wé yẹn, ó ti lè jẹ́ pé “ìgbọ́kànlé tí Bánábà ní nínú Máàkù ni ó ràn án lọ́wọ́ láti jẹ́ kí òun fúnra rẹ̀ di ẹni tí ó padà ní ìgbọ́kànlé nínú ara rẹ̀, tí ó sì ràn án lọ́wọ́ láti mú ẹ̀mí ìfarajìn tí ó ní sọjí.” Ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, ẹ̀rí fi hàn pé ìgbọ́kànlé tí Bánábà ní nínú rẹ̀ tọ́, nítorí pé nígbà tí ó yá Pọ́ọ̀lù pàápàá sọ bí Máàkù ti wúlò tó nínú iṣẹ́ ìsìn Kristẹni.—2 Tímótì 4:11; fi wé Kólósè 4:10.
Àpẹẹrẹ Bánábà lè ru wá sókè láti wá àkókò láti tẹ́tí sílẹ̀, láti lóye, kí a sì fún àwọn tí wọ́n sorí kodò ní ìṣírí, kí a sì pèsè ìrànwọ́ tí ó gbéṣẹ́ níbikíbi tí a bá ti rí i pé ó wúlò. Àkọsílẹ̀ ìmúratán rẹ̀ láti fi ìwà tútù àti ìgboyà sin àwọn ará rẹ̀, àti ìyọrísí kíkọyọyọ tí ó tibẹ̀ jáde, jẹ́ ìṣírí fúnra rẹ̀. Ìbùkún ńlá gbáà ni ó mà jẹ́ o láti ní àwọn ènìyàn bí Bánábà nínú àwọn ìjọ wa lónìí!
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Pípe ẹnì kan ni “ọmọ” ànímọ́ kan pàtó fi hàn pé ẹni náà ní ànímọ́ náà lọ́nà tí ó tayọ lọ́lá. (Wo Diutarónómì 3:18, àkíyèsí ẹsẹ̀ ìwé.) Ní ọ̀rúndún kìíní, ó jẹ́ ohun tí ó wọ́pọ̀ láti lo àpèlé láti pe àfiyèsí sí àwọn ànímọ́ ẹnì kan. (Fi wé Máàkù 3:17.) Ara jíjẹ́ gbajúmọ̀ ni èyí jẹ́.
b Ní ṣíṣàgbéyẹ̀wò ohun tí Òfin Mósè ti gbé kalẹ̀, àwọn kan ti béèrè bí Bánábà, ọmọ Léfì kan, ṣe wá di ẹni tí ó ní ilẹ̀. (Númérì 18:20) Ṣùgbọ́n, ó yẹ kí a kíyè sí i pé, kò ṣe kedere bóyá Palẹ́sìnì ni ilẹ̀ náà wà tàbí Kípírọ́sì. Síwájú si, ó ṣeé ṣe kí èyí wulẹ̀ jẹ́ ilẹ̀ ìsìnkú tí Bánábà ti rà ní àgbègbè Jerúsálẹ́mù. Ohun yòówù tí ì báà jẹ́, Bánábà ta ilẹ̀ rẹ̀ láti ṣèrànwọ́ fún àwọn ẹlòmíràn.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Bánábà jẹ́ “ènìyàn rere, ó sì kún fún ẹ̀mí mímọ́ àti ìgbàgbọ́”