Láti Àwọn Ibùgbé Onílé Gogoro Ní Àwọn Ìlú Ńlá Títí Dé Àgbègbè Aṣálẹ̀ Gbalasa—Wọ́n Ń Tọ Àwọn Ènìyàn Lọ
KÌ Í ṣe òjò tàbí òjò dídì tàbí yìnyín tàbí ìkookò tàbí àmọ̀tẹ́kùn tàbí ìpínlẹ̀ àwọn oníkanra ni yóò paná ẹ̀mí ìmúratán tí wọ́n ní. Pẹ̀lú eré yíyanilẹ́nu, wọ́n ń fi ẹṣin rin 3,000 kìlómítà pápá ilẹ̀, wọ́n ń la àwọn odò tí ń ru gùdù, àti àfonífojì jíjìn kọjá láti kó àwọn ìwé tí ó jẹ́ kánjúkánjú ránṣẹ́ sí Etíkun Ìwọ̀ Oòrùn. Àwọn wo nìyẹn?
Àwọn ọ̀dọ́ ọ̀gẹṣin ti ilé iṣẹ́ pony express ni.a Kí ní ru irú ẹ̀mí ìmúratán lílágbára bẹ́ẹ̀ sókè lọ́kàn àwọn ọ̀dọ́kùnrin wọ̀nyí? Ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ ìpèníjà, ṣíṣen-tẹ́nìkan-ò-ṣe-rí, àti ìtẹ́nilọ́rùn tí ń wá láti inú mímú àwọn lẹ́tà náà dé ọ̀dọ̀ àwọn tí ó ni wọ́n. Lọ́nà tí ó dùn mọ́ni, ẹlẹ́ṣin kọ̀ọ̀kan ní Bíbélì pẹ̀lú àwọn lẹ́tà tí ó gbọ́dọ̀ kó ránṣẹ́, nínú àpò tí ń bẹ lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹṣin rẹ̀.
Ní ohun tí ó lé ní ọ̀rúndún kan lẹ́yìn náà, àwọn olùpòkìkí Ìjọba olùfọkànsìn tí ó lé ní 113,000 jákèjádò Kánádà, fi ẹ̀mí ìmúratán, ìtara, àti ìfọkànsìn tí ó túbọ̀ ga sí i hàn. Kí ní ń sún wọn ṣiṣẹ́? Ìfẹ́ fún Ọlọ́run àti fún aládùúgbò wọn ní ń sún wọn láti fúnni ní òtítọ́ Ìjọba nípasẹ̀ ìwé tí a tẹ̀ àti ọ̀rọ̀ ẹnu. Òtítọ́ tí ń fúnni níyè yìí ṣe kánjúkánjú ju ìwé èyíkéyìí tí ilé iṣẹ́ pony express fi jíṣẹ́ lọ. Bẹ́ẹ̀ ni, ó jẹ́ ìhìn iṣẹ́ Ìjọba ṣíṣeyebíye ti Bíbélì Mímọ́, ìwé náà gan-an tí a rí nínú àpò àwọn ẹlẹ́ṣin ilé iṣẹ́ pony express.—Òwe 2:21, 22; Aísáyà 2:2-4; 61:2; Mátíù 22:37-39; 24:14.
Ìfẹ́ fún Jèhófà àti fún Àwọn Ènìyàn Sún Wọn Ṣiṣẹ́
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nífẹ̀ẹ́ láti bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba náà. Ìwọ yóò rí wọn tí wọ́n ń ṣe bẹ́ẹ̀ ní àwọn ibùgbé onílé gogoro ní àwọn ìlú ńlá, ní àwọn ìgbèríko gbalasa, ní àwọn pápákọ̀ òfuurufú, lójú pópó àti ní àwọn ibòmíràn tí àwọn ènìyàn máa ń jẹ̀ sí, àti lórí tẹlifóònù. Èé ṣe tí ó fi jẹ́ ní onírúurú ibi bí ìwọ̀nyí?
Àwọn ọ̀nà ìgbésí ayé tí ń yí padà tí ipò ìṣúnná owó àti ipò ṣíṣílọ sí àwọn ìlú ńlá ń gbé kalẹ̀ ń fa ìpèníjà ńlá ti bíbá àwọn ènìyàn nínú ilé wọn. Nínú ọ̀pọ̀ ọ̀ràn, tọkọtaya ní ń ṣiṣẹ́ láti bójú tó àwọn ohun kòṣeémánìí ti ìdílé, lọ́pọ̀ ìgbà ni wọ́n sì ń ṣàìka ohun tí wọ́n ṣaláìní nípa tẹ̀mí sí. Láàárín pákáǹleke àti másùnmáwo bẹ́ẹ̀, wọ́n nílò ìhìn iṣẹ́ amọ́kànyọ̀, tí ń fúnni nírètí, lójú méjèèjì. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń fayọ̀ dáhùn. Ní lílo ọgbọ́n inú àti inú rere, wọ́n ń ṣí àyè sílẹ̀ láti mú ìhìn rere wá sọ́dọ̀ gbogbo onírúurú ènìyàn ní ọ̀nà tí ń fani mọ́ra, tí ń ru ìrònú sókè.—1 Tímótì 2:3, 4.
Ní Àwọn Èdè Mìíràn: Nígbà tí Jésù pàṣẹ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti ‘lọ sọ àwọn ènìyàn di ọmọ ẹ̀yìn,’ ó yọ̀ǹda fún lílo àtinúdá àti ìmúratán ní mímú ìhìn iṣẹ́ ìrètí lọ sọ́dọ̀ àwọn ènìyàn gbogbo èdè. (Mátíù 28:19) Gẹ́gẹ́ bí ọ̀ràn ti rí ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀, Kánádà ti di àwùjọ onírúurú àṣà àti èdè, ọ̀pọ̀ olùpòkìkí Ìjọba sì ti mú ara wọn bá ipò náà mu nípa kíkọ́ àwọn èdè tuntun.
Fún àpẹẹrẹ, tọkọtaya kan, tí wọ́n jẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún ní Edmonton, Alberta, rí ìjẹ́pàtàkì dídé ọ̀dọ́ àwọn tí ń sọ èdè Mandarin Chinese ní ìlú ńlá tí wọ́n wà. Ṣùgbọ́n, lákọ̀ọ́kọ́, tọkọtaya náà ní láti kọ́ èdè náà, nítorí náà, wọ́n kàn sí ọmọ yunifásítì kan, tí ń sọ èdè Mandarin. Ó gbà láti kọ́ wọn ní èdè náà, kí ó sì kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ wọn lọ́wọ́ kan náà. Ẹ wo bí ipò náà ti rọni lọ́rùn tó! Láàárín oṣù 24, àwọn olùpòkìkí Ìjọba olùfọkànsìn méjì wọ̀nyí ti tóótun láti kọ́ni ní èdè Mandarin. Lọ́wọ́ kan náà, olùkọ́ òun akẹ́kọ̀ọ́ wọn ti tóótun láti ṣe batisí gẹ́gẹ́ bí Kristẹni.
A ń gbádùn irú ìrírí kan náà ní àwọn ìlú ńlá mìíràn bí àwọn olùpòkìkí Ìjọba, tí ìfẹ́ ń sún ṣiṣẹ́, ṣe ń kọ́ irú àwọn èdè bí Polish, Russian, àti Vietnamese.
Ní Ojú Ọ̀nà: Bí àwọn ẹlẹ́ṣin ilé iṣẹ́ pony express ti ọ̀rúndún tí ó kọjá, tí ń dá gẹṣin, àwọn olùpòkìkí Ìjọba kan ní British Columbia máa ń dá wa ọkọ̀ akẹ́rù. Wọ́n ń lo èyí tí ó pọ̀ jù nínú àkókò wọn lẹ́nu iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ wọn, ti wíwa ọkọ̀ gẹdú láti inú igbó lọ sí ilé iṣẹ́ tí wọ́n ti ń la igi gẹdú. Èyí ń béèrè kíkàn sí àwọn ọlọ́kọ̀ ẹrù yòókù lemọ́lemọ́ nípasẹ̀ rédíò CB (citizens band), láti sọ fún wọn nípa bí ọkọ̀ ṣe ń lọ sókè sódò tó àti nípa ewu ọ̀nà.
Lọ́nà tí ó fi ìrònú hàn, àwọn olùpòkìkí Ìjọba wọ̀nyí ń lo rédíò CB wọn ní ọ̀nà àrà ọ̀tọ̀ kan. Wọ́n ń dá ìjíròrò sílẹ̀ lórí CB nípa sísọ̀rọ̀ lórí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ lọ́ọ́lọ́ọ́. Lẹ́yìn náà, wọn yóò fi ìjáfáfá tọ́ka sí Bíbélì. Nínú ọ̀ràn kan, ọlọ́kọ̀ ẹrù ẹlẹgbẹ́ wọn dáhùn padà sí ohun tí Bíbélì sọ nípa ìrètí tí ó wà fún àwọn òkú. (Jòhánù 5:28, 29; Ìṣe 24:15) Ikú awakọ̀ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ nínú ìjàǹbá òpópónà da ọkàn rẹ̀ rú gidigidi. Ó fi ìmọrírì tẹ́wọ́ gba ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, nísinsìnyí, a lè gbọ́ tí ó ń pòkìkí ìhìn rere fún àwọn òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀. Síwájú si, sí ìdùnnú rẹ̀, a bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú opó ọ̀rẹ́ rẹ̀ tí ó kú náà. Ẹ wo irú èrè tí èyí jẹ́ fún lílo àtinúdá láti gbé ìhìn iṣẹ́ òtítọ́ tí ń fúnni níyè kalẹ̀ ní ọ̀nà àrà ọ̀tọ̀ yìí!
Ní Òfuurufú: Nígbà tí ó bá kan fífúnni ní ìhìn iṣẹ́ òtítọ́ ṣíṣeyebíye, àwọn olùpòkìkí Ìjọba onítara máa ń lọ síbi tí àwọn ènìyàn wà, ‘wọ́n ń wọ abúlé’ nípasẹ̀ àwọn ọkọ̀ òfuurufú kékeré. (Mátíù 10:11, 12) Ní àìpẹ́ yìí, àwọn àwùjọ méjì tí ń lo ọkọ̀ òfuurufú láti fi wàásù, tí ìtara láti polongo ìhìn rere ń sún ṣiṣẹ́, tí wọ́n sì lo owó ara wọn, wọ ọkọ̀ òfuurufú lọ sọ́dọ̀ àwọn ènìyàn tí wọ́n wà káàkiri aginjù salalu, tí ó tẹ́ gbalasa. Àwùjọ inú ọkọ̀ òfuurufú kọ̀ọ̀kan kárí nǹkan bí 3,000 kìlómítà, wọ́n sì balẹ̀ sí abúlé 14 ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, ní rírin ìrìn àjò 250 kìlómítà wọ Arctic Circle. Àwọn olùpòkìkí tí kì í rẹ̀ yìí ń bá a nìṣó fún ọjọ́ méje gbáko láti dọ́dọ̀ àwọn ènìyàn tí wọ́n wà ládàádó, nítorí tí wọ́n jìnnà sígboro.
Gbogbo ìsapá yìí ha pọndandan bí? Tilẹ̀ ronú ná nípa ipa rere tí ìhìn iṣẹ́ Bíbélì ní lórí àwọn àwùjọ wọ̀nyí. Àwọn òjíṣẹ́ tí ń ṣèbẹ̀wò ṣèrànwọ́ láti kúnjú àìní tẹ̀mí ṣíṣe kókó kan, nígbà tí wọ́n sọ ète Jèhófà láti sọ orí ilẹ̀ ayé di párádísè kan ní ọjọ́ iwájú tí kò jìnnà. (Mátíù 5:3) Lẹ́yìn ìgbà pípẹ́ tí àwọn ońṣẹ́ náà bá ti lọ, ó máa ń ṣeé ṣe fún àwọn aláìlábòsí ọkàn nínú àwọn àwùjọ náà láti kà láti inú Bíbélì àti àwọn àrànṣe Bíbélì 542 àti ìwé ìròyìn 3,000 tí wọ́n gbà.—Fi wé Ìṣe 12:24.
Nípasẹ̀ Tẹlifóònù: Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn olùgbé ìlú ńlá ń gbé nínú àwọn ibùgbé onílé gogoro tí ó ní ìgbékalẹ̀ ààbò tí ó díjú. Àní bí ó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, àwọn olùpòkìkí Ìjọba tí wọ́n ti ya ara wọn sí mímọ́ ń fi ìtara àti ọgbọ́n inú tẹ̀ síwájú. Báwo ni ó ṣe ṣeé ṣe fún wọn láti lọ síbi tí àwọn ènìyàn wọ̀nyí wà? Bí ó tilẹ̀ wù wọ́n láti rí wọn sójú, lọ́pọ̀ ìgbà, wọ́n máa ń ṣàṣeyọrí ní lílo ẹ̀rọ gbohùngbohùn tí ó wà láàárín ilé. Nígbà tí èyí kò bá ṣeé ṣe, wọ́n máa ń lo ìka ọwọ́ wọn láti fi tẹ àwọn ènìyàn láago.
Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kan, ìyá àgbàlagbà kan dáhùn tẹlifóònù rẹ̀. Lẹ́yìn ìkíni ọmọlúwàbí ṣókí, a bi í bóyá ó rò pé àkókò kan yóò wà nígbà tí yóò ṣeé ṣe fún àwọn ènìyàn láti rìn ní àwọn òpópónà lálẹ́ láìséwu. A ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ fún un láti mú kí ó dá a lójú pé àlàáfíà yóò pọ̀ rẹpẹtẹ ní ọjọ́ iwájú. (Sáàmù 37:10, 11; Dáníẹ́lì 2:44; Mátíù 6:9, 10) Ó gbà pé kí a bá òun sọ̀rọ̀ lórí tẹlifóònù ní ọ̀sẹ̀ tí ó tẹ̀ le, ní àkókò kan náà, láti jíròrò ìdí tí a fi lè gba àwọn ìlérí Ọlọ́run gbọ́. Lẹ́yìn tí olùpòkìkí Ìjọba náà ti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú ìyá náà lórí tẹlifóònù fún oṣù kan, tí ó ń ka àwọn ìpínrọ̀ sí i létí láti inú àrànṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan, tí ó sì ń bi í ní àwọn ìbéèrè tí ó yẹ, ìyá náà yìn ín fún mímú onírúurú ìwàásù wá lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Àkókò ti tó wàyí láti sọ ìwé tí a ń lò fún ìkẹ́kọ̀ọ́ náà, kí a sì fi ẹ̀dà tirẹ̀ lọ̀ ọ́. Lẹ́yìn náà, àwọn méjèèjì ṣètò láti ríra sójú. Ní ti gidi, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti fi ìfẹ́ tí wọ́n ní sí àwọn ènìyàn hàn, àwọn ènìyàn sì ń dáhùn padà, wọ́n ń mọ̀ pé Jèhófà ń bẹ pẹ̀lú àwọn Kristẹni oníwàásù wọ̀nyí.—Fi wé 1 Kọ́ríńtì 14:25.
Nípasẹ̀ Àwọn Ìwé Tí A Tẹ̀: Àwọn olùpòkìkí Ìjọba ní ẹkùn ìpínlẹ̀ Quebec, tí ó jẹ́ èdè Faransé ni a ń sọ jù lọ, pẹ̀lú ń lọ síbi tí àwọn ènìyàn wà. Òjíṣẹ́ arìnrìn àjò kan sọ pé: “Fún ọ̀pọ̀ ọdún, àwọn ará rò pé àwọn kò ṣàṣeyọrí kankan nítorí àtakò gbígbóná janjan tí ṣọ́ọ̀ṣì ń ṣe. Ṣùgbọ́n, nípasẹ̀ iṣẹ́ àṣekára àwọn ará àti kíkésíni lemọ́lemọ́ wọn, Bíbélì, tí ó jẹ́ ìwé tí ọ̀pọ̀ kò mọ̀, tí ó jẹ́ àwọn kéréje nìkan ni ó ń kà á, ni a ti ń rí káàkiri nínú ilé àwọn ènìyàn nísinsìnyí.”
A ń gbádùn ìyọrísí wíwúnilórí bí àwọn ajíhìnrere tuntun ti ń wá láti inú gbogbo ẹgbẹ́ àwùjọ Quebec, títí kan àwùjọ àwọn oníṣègùn. Bí ọ̀ràn dókítà kan ti rí nìyẹn. Ìyàwó rẹ̀, tí òun fúnra rẹ̀ jẹ́ olùpòkìkí Ìjọba, máa ń jíròrò ìrètí tí Bíbélì nawọ́ rẹ̀ síni pẹ̀lú rẹ̀ lemọ́lemọ́. Alàgbà ìjọ kan tí ó wà lójúfò lo àtinúdá láti ké sí dókítà náà wá sí ìpàdé ìjọ nígbà tí a ń kẹ́kọ̀ọ́ ìwé pẹlẹbẹ náà, How Can Blood Save Your Life? Ó wá, ó tilẹ̀ kópa nínú rẹ̀. Nítorí tí ìjójúlówó ìjíròrò náà àti bí ó ti jinlẹ̀ tó nípa tẹ̀mí wú u lórí, ó gbà pé kí a máa bá òun kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Òun náà ti di olùpòkìkí Ìjọba nísinsìnyí.
Lílo àwọn ìwé ìròyìn lọ́nà tí ó gbéṣẹ́ ti kó ipa pàtàkì nínú fífa àwọn ènìyàn mọ́ Bíbélì. A kò mọ àpilẹ̀kọ tí yóò ṣiṣẹ́ láti fa ẹnì kan sínú òtítọ́. Olùpòkìkí Ìjọba kan fi ìtẹ̀jáde Jí! lọ aládùúgbò rẹ̀ tí kò fẹ́ fetí sí ìhìn iṣẹ́ náà, ṣùgbọ́n tí ó nífẹ̀ẹ́ nínú ọ̀nà ìgbésí ayé àwọn kòkòrò. Àwòrán inú àpilẹ̀kọ “Àrùn ‘Chagas’—Ti Kò Gbóògùn,” tí ó jáde nínú Jí! November 22, 1992, ru ú lọ́kàn sókè. Nítorí tí ohun tí ó kà wú u lórí, ó béèrè fún ìwé ìròyìn púpọ̀ si. A bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú rẹ̀, ó sì ti bẹ̀rẹ̀ sí jẹ́rìí fún àwọn ẹlòmíràn láàárín oṣù mẹ́fà.
Ní Àwọn Ibi Tí Àwọn Ènìyàn Ń Jẹ̀ Sí: Òfin Kánádà yọ̀ǹda fún òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ ní àwọn ibi tí àwọn ènìyàn ń jẹ̀ sí, irú bí ibùdókọ̀ òfuurufú. Ní Ibùdókọ̀ Òfuurufú Ńlá ti Halifax, àwọn olùpòkìkí Ìjọba máa ń lo ọgbọ́n inú láti tọ àwọn arìnrìn àjò tí ń tinú ọkọ̀ òfuurufú kan bọ́ sí òmíràn lọ, wọ́n ń jíròrò pẹ̀lú wọn. Wọ́n máa ń lo àwọn ìbéèrè tí ó bá àkókò mu láti darí ìjíròrò náà sórí Bíbélì. Níwọ̀n bí wọ́n ti ní Bíbélì kékeré àti àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́, wọ́n lè dáhùn padà sí àwọn àìní tẹ̀mí. Àwọn oníṣẹ́ abẹ, onímọ̀ sáyẹ́ǹsì, amòfin, awakọ̀ òfuurufú, àlùfáà, ọlọ́pàá, àwọn awakọ̀ takisí, àwọn onímọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ, àwọn olùkọ́, àwọn ológun, àti àwọn olóṣèlú láti àwọn orílẹ̀-èdè òkèèrè wà lára àwọn tí ó ti gbọ́ ìhìn iṣẹ́ Ìjọba lọ́nà yìí, wọ́n sì ti mú hóró òtítọ́ lọ láti mú èso jáde ní àwọn ibi jíjìnnà réré.—Kólósè 1:6.
Ní òwúrọ̀ kùtùkùtù ọjọ́ kan ní ibùdókọ̀ òfuurufú, ọkùnrin kan gba ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí! Lẹ́yìn náà, ó sọ ní ohùn ìrẹ̀lẹ̀ ní jẹ́jẹ́ pé: “Ó tì o, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kẹ̀!” Kí ló fa irú ìhùwàpadà bẹ́ẹ̀? Mùsùlùmí olùfọkànsìn ni ọkùnrin náà, tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ gbàdúrà tán ní yàrá àdúrà kékeré tí ó wà ní ibùdókọ̀ òfuurufú náà. Ó ti bẹ Ọlọ́run pé kí ó fi ọgbọ́n, ìjìnlẹ̀ òye, àti òtítọ́ han òun. Èrò náà pé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ìdáhùn ẹsẹ̀kẹsẹ̀ sí àdúrà òun yà á lẹ́nu gidigidi.
Ní tòótọ́, àwọn olùpòkìkí Ìjọba onígboyà ní Kánádà kì í jẹ́ kí ohunkóhun dí wọn lọ́wọ́ gbígbé ìhìn iṣẹ́ Ìjọba ṣíṣeyebíye kalẹ̀. Wọn kì í jẹ́ kí èdè àjèjì, àwọn ojú ọ̀nà págunpàgun elékuru, àwọn ìgbèríko jíjìnnà réré, tàbí àwọn ibùgbé onílé gogoro tí a ká mọ́ ní àwọn ìlú ńlá dí wọn lọ́wọ́. Wọ́n ti pinnu láti mú ìhìn iṣẹ́ Ọlọ́run tí ń fúnni níyè wá fún àwọn olùwá òtítọ́ aláìlábòsí ọkàn. Wọ́n ń fi àìmọtara-ẹni-nìkan ṣègbọràn sí àṣẹ Jésù pé kí wọ́n ‘lọ máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn,’ pẹ̀lú ẹgbẹ́ ará àwọn òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ wọn kárí ayé.—Mátíù 28:19.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ilé iṣẹ́ pony express jẹ́ ilé iṣẹ́ kan tí ń fìwé ránṣẹ́ ní United States, tí ó ṣiṣẹ́ fún oṣù 18 péré láti ọdún 1860 sí 1861.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 27]
Àwọn Olùpòkìkí Ìjọba Tí Wọ́n Ń Kẹ́sẹ Járí Ń Lo Tẹlifóònù
Àwọn kan ti sọ pé: “Ẹ kú dédé ìwòyí o. Orúkọ mi ni [sọ orúkọ rẹ]. Mo ti ń bá àwọn ènìyàn tí ń gbé ní ilé yín sọ̀rọ̀ ní ṣókí nípa bí ọwọ́ wá ṣe lè tẹ àlàáfíà. Ìwọ ha rò pé àlàáfíà yóò fìgbà kan wà kárí ayé bí? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Láti fọkàn rẹ balẹ̀, n kò ṣe ìwádìí kankan tàbí ta ohunkóhun. Kàkà bẹ́ẹ̀, mo ti ń ṣàjọpín èrò láti inú Ìwé Mímọ́ pẹ̀lú àwọn ènìyàn pé Ọlọ́run yóò mú àlàáfíà wá nítòótọ́.” Lẹ́yìn náà, ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ náà lè tẹ̀ síwájú nípa jíjíròrò láti inú Ìwé Mímọ́ ní ṣókí.
Àwọn mìíràn ti sọ pé: “Ẹ kú ìrọ̀lẹ́ o. Orúkọ mí a máa jẹ́ [sọ orúkọ rẹ]. Mo jẹ́ olùyọ̀ǹda ara ẹni ní àdúgbò rẹ. Mo ti ń gba èrò àwọn ènìyàn tí ń gbé ní ilé yín. Ọ̀pọ̀ ń ṣàníyàn nípa ààbò ara ẹni lójú ìwòye ìwà ipá àti ìwà ọ̀daràn tí ń ga sí i ládùúgbò wa. Èyí ha jẹ́ ohun tí ìwọ ń ṣàníyàn nípa rẹ̀ bí? [Jẹ́ kí ó fèsì.] Ìwọ ha rò pé àkókò kan yóò fìgbà kan wà tí gbogbo ayé yóò nímọ̀lára àìséwu bí?” Jẹ́ kí ó fèsì, kí o sì tẹ̀ síwájú pẹ̀lú ìhìn iṣẹ́ láti inú Ìwé Mímọ́.