A Óò Ha Máa Fìgbà Gbogbo Nílò Ẹgbẹ́ Ọmọ Ogun Bí?
ẸGBẸ́ ọmọ ogun ti ná iye tí ó pọ̀ jù lọ nínú ohun àmúṣọrọ̀ ẹ̀dá ènìyàn, wọ́n sì ti pa ọ̀pọ̀ ayọ̀ ènìyàn run. Nítorí èyí, àwọn kan ti ṣe kàyéfì pé, ‘Ọwọ́ aráyé ha lè tẹ irú ààbò àgbáyé tí yóò yọ̀ǹda fún títú ẹgbẹ́ ọmọ ogun ká bí?’ Nísinsìnyí tí àwọn ohun ìjà ìparun tìrìgàngàn ti mú kí pípa gbogbo ohun alààyè run pátápátá di ohun tí ó ṣeé ṣe, ìbéèrè náà ti di ọ̀ràn kánjúkánjú. Báwo ni ó ti jóòótọ́ tó láti máa retí ayé kan tí kò sí ẹgbẹ́ ọmọ ogun?
Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àpẹẹrẹ ìṣáájú ti fi hàn pé nígbà tí àjọṣe láàárín àwọn orílẹ̀-èdè bá dán mọ́rán, ó ń yọrí sí ìgbọ́kànlé, tí ó lè yọrí sí dídín àwọn ohun ìjà ogun kù. Fún àpẹẹrẹ, ìbárẹ́ tí ó gbilẹ̀ láàárín Kánádà àti United States ti mú kí ó máà sí ẹgbẹ́ ọmọ ogun kankan ní ààlà ilẹ̀ wọn oníkìlómítà-5,000 fún ohun tí ó lé ní ọ̀tàlélọ́gọ́rùn-ún ọdún. Norway àti Sweden ti ní irú àjọṣe kan náà, bẹ́ẹ̀ sì ni ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè mìíràn. Ìfìmọ̀ṣọ̀kan láàárín gbogbo orílẹ̀-èdè ha lè yọrí sí ayé kan tí kò sí ẹgbẹ́ ọmọ ogún bí? Pẹ̀lú jìnnìjìnnì Ogun Àgbáyé Kìíní, èrò náà di èyí tí ó gbajúmọ̀ lọ́nà tí kò láfiwé.
Nígbà tí a ṣàdéhùn àlàáfíà ní ọdún 1918, ọ̀kan nínú àwọn ète àdéhùn àlàáfíà Versailles ni “láti mú kí bíbẹ̀rẹ̀ èrò dídín àwọn ohun ìjà ogun orílẹ̀-èdè gbogbo kù ṣeé ṣe.” Ní àwọn ọdún tí ó tẹ̀ lé e, èròǹgbà ogun-ò-tọ̀nà di èyí tí ó gbajúmọ̀. Àwọn eléròǹgbà ogun-ò-tọ̀nà kan gbé àbá èrò orí kalẹ̀ pé ogun ni ohun tí ó burú jù lọ tí ó lè ṣẹlẹ̀ sí orílẹ̀-èdè kan, nítorí náà, ó burú ju kí a ṣẹ́gun ẹni lọ. Àwọn alátakò èròǹgbà ogun-ò-tọ̀nà kò fohùn ṣọ̀kan pẹ̀lú èrò yìí, wọ́n tọ́ka sí i pé fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún, àwọn Júù tí ó wà ní àwọn àgbègbè gbígbòòrò kò lo ohun ìjà púpọ̀ láti kojú àwọn ọ̀tá wọn, síbẹ̀ ìgbìdánwò rírorò láti pa wọ́n run pátápátá ṣì ń bá a lọ. Àwọn ará Áfíríkà kò ní àǹfààní láti gbéjà ko àwọn tí wọ́n kó wọn lẹ́rú wá sí ilẹ̀ Amẹ́ríkà, síbẹ̀ a bá wọn lò lọ́nà rírorò fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún.
Ṣùgbọ́n, nígbà tí Ogun Àgbáyé Kejì bẹ́ sílẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn eléròǹgbà ogun-ò-tọ̀nà dórí èrò náà pé àwọn orílẹ̀-èdè nílò ààbò. Nítorí náà, nígbà tí wọ́n dá Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè sílẹ̀ lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kejì, a kò fi bẹ́ẹ̀ sọ̀rọ̀ lórí dídín ohun ìjà kù mọ́, ṣùgbọ́n a ń tẹnu mọ́ ìfọwọ́sowọ́pọ̀ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè láti lè dènà ìgbóguntini. Àwọn mẹ́ńbà retí pé ààbò tí ó bá tipasẹ̀ èyí wá yóò fún àwọn orílẹ̀-èdè ní ìfọ̀kànbalẹ̀ láti dín ohun ìjà wọn kù.
Ìṣòro mìíràn túbọ̀ ń fara hàn. Lọ́pọ̀ ìgbà, ìsapá orílẹ̀-èdè kan láti pèsè ààbò fún ara rẹ̀ ń mú kí ọkàn orílẹ̀-èdè tí ó wà nítòsí rẹ̀ má balẹ̀. Ìyípoyípo ọ̀ràn yìí yọrí sí fífi ohun ìjà ogun díje. Ṣùgbọ́n, láìpẹ́ yìí, okùn àjọṣe àwọn orílẹ̀-èdè pàtàkì-pàtàkì tí ó ń yi sí i ń fún ìrètí dídín ohun ìjà ogun kù lókun. Ṣùgbọ́n, láti ìgbà yìí wá, Ogun Gulf àti rògbòdìyàn tí ó wà ní Yugoslavia tẹ́lẹ̀ rí ti fọ́ ìrètí dídín ohun ìjà ogun kù yángá mọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ lọ́wọ́. Ní nǹkan bí ọdún márùn-ún sẹ́yìn, ìwé ìròyìn Time sọ pé: “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ogun tútù ti parí, ayé ti túbọ̀ di ibi tí ó léwu si, dípò ibi tí kò fi bẹ́ẹ̀ léwu.”
Fífẹ́ Láti Ní “Ọlọ́pàá” Àgbáyé
Ọ̀pọ̀ àwọn olùṣàkíyèsí parí èrò pé aráyé nílò ìjọba àgbáyé kan ṣoṣo tí ó ní ẹgbẹ́ ọmọ ogun tí ó lágbára tó láti dáàbò bo olúkúlùkù. Níwọ̀n bí èyí kò ti ṣeé ṣe fún àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè tàbí àwọn òléwájú ológun lágbàáyé, àwọn kan rò pé kò sí ìrètí fún ọjọ́ ọ̀la. Ṣùgbọ́n bí o bá gba Bíbélì gẹ́gẹ́ bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ìwọ ti lè ṣe kàyéfì bóyá Ọlọ́run Olódùmarè yóò tẹ́ àìní kánjúkánjú yìí lọ́rùn.
Ẹni tí Bíbélì pè ní “Ọlọ́run ìfẹ́ àti àlàáfíà” yóò ha lo agbára ológun láti mú kí ìdájọ́ òdodo wà bí? Bí ó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, ẹgbẹ́ ọmọ ogun wo ni yóò lò? Ọ̀pọ̀ ẹgbẹ́ ọmọ ogun òde òní ń sọ pé Ọlọ́run ni ó ń bẹ lẹ́yìn àwọn, ṣùgbọ́n, wọn ha ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ní tòótọ́ bí? Àbí Ọlọ́run ní ọ̀nà mìíràn tí yóò fi dá si, tí yóò sì fi mú àlàáfíà àti ààbò wá?—2 Kọ́ríńtì 13:11.
Ọlọ́run Olódùmarè wá nǹkan ṣe sí ìṣọ̀tẹ̀ àkọ́kọ́ nípa lílé Ádámù àti Éfà jáde kúrò ní Édẹ́nì, tí ó sì fi àwọn kérúbù ṣọ́ ẹnu ọ̀nà rẹ̀ kí wọ́n má baà lè padà wọlé. Ó tún kéde ète rẹ̀ láti pa gbogbo ìṣọ̀tẹ̀ lòdì sí ipò ọba aláṣẹ rẹ̀ run. (Jẹ́nẹ́sísì 3:15) Ìyẹn ha lè túmọ̀ sí pé Ọlọ́run lo ọmọ ogun bí?
Bíbélì sọ nípa àwọn ìgbà tí Ọlọ́run lo ẹgbẹ́ ọmọ ogun láti mú ìdájọ́ rẹ̀ ṣẹ. Fún àpẹẹrẹ, àwọn ìjọba ní ilẹ̀ Kénáánì ń bá ẹranko lòpọ̀, wọ́n ń fi ọmọ rúbọ, wọ́n sì ń jagun rírorò. Ọlọ́run pàṣẹ pé kí a pa wọ́n run pátápátá, ó sì lo ẹgbẹ́ ọmọ ogun Jóṣúà láti múdàájọ́ náà ṣẹ. (Diutarónómì 7:1, 2) Bákan náà, ẹgbẹ́ ọmọ ogun Ọba Dáfídì múdàájọ́ Ọlọ́run ṣẹ sórí àwọn Filísínì gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ bí Ọlọ́run yóò ṣe pa gbogbo ìwà burúkú run ní ọjọ́ ìdájọ́ àṣekágbá rẹ̀.
Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wọ̀nyẹn kọ́ni lọ́gbọ́n. Jèhófà fi hàn pé òun lè lo ẹgbẹ́ ọmọ ogun láti dáàbò bo àwọn ènìyàn. Ní tòótọ́, Jèhófà ní ẹgbẹ́ ọmọ ogun kan tí ó yàtọ̀ gédégbé, tí yóò wá nǹkan ṣe sí ìṣọ̀tẹ̀ tí ó kárí ayé, tí ó lòdì sí ìṣàkóso rẹ̀.
“Jèhófà Àwọn Ẹgbẹ́ Ọmọ Ogun”
Bíbélì lo gbólóhùn náà, “Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun,” ní ìgbà tí ó lé ní 250. Ní pàtàkì, gbólóhùn náà ń tọ́ka sí ipò Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ọ̀gágun ẹgbàágbèje àwọn áńgẹ́lì. Ní àkókò kan, wòlíì Mikáyà sọ fún Ọba Áhábù àti Ọba Jèhóṣáfátì pé: “Dájúdájú, mo rí i tí Jèhófà jókòó sórí ìtẹ́ rẹ̀, gbogbo ẹgbẹ́ ọmọ ogun ọ̀run sì dúró sẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀, síhà ọ̀tún rẹ̀ àti òsì rẹ̀.” (1 Àwọn Ọba 22:19) Ẹgbẹ́ ọmọ ogun ti àwọn áńgẹ́lì ni a ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ níhìn-ín. Jèhófà lo ẹgbẹ́ ọmọ ogun yìí láti dáàbò bo àwọn ènìyàn rẹ̀. Nígbà tí a sàgati ìlú Dótánì, ìránṣẹ́ Èlíṣà sọ̀rètí nù. Ṣùgbọ́n, láti fọkàn rẹ̀ balẹ̀, Ọlọ́run jẹ́ kí ó rí ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ ti àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí nínú ìran. “Jèhófà la ojú ẹmẹ̀wà náà, bẹ́ẹ̀ ni ó sì ríran; sì wò ó! ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá náà kún fún àwọn ẹṣin àti àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin ogun oníná.”—2 Àwọn Ọba 6:15-17.
Irú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ ha fi hàn pé Ọlọ́run ń ti ẹgbẹ́ ọmọ ogun lẹ́yìn lónìí bí? Àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun kan tí ó jẹ́ ti Kirisẹ́ńdọ̀mù lè sọ pé ẹgbẹ́ ọmọ ogun Ọlọ́run làwọn. Ọ̀pọ̀ ti ní kí àwọn àlùfáà gbàdúrà fún àwọn. Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ ìgbà ni àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun Kirisẹ́ńdọ̀mù ń bá ara wọn jà, tí wọ́n sì ń dojú ìjà kọ àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn. Àwọn ogun àgbáyé méjèèjì ti ọ̀rúndún yìí bẹ̀rẹ̀ láàárín àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun méjì tí wọ́n sọ pé àwọn jẹ́ ẹlẹ́sìn Kristẹni. Èyí kò lè jẹ́ iṣẹ́ Ọlọ́run. (1 Jòhánù 4:20) Nígbà tí irú àwọn ọmọ ogun bẹ́ẹ̀ sọ pé àwọn ń jà fún àlàáfíà, Jésù ha fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ nítọ̀ọ́ni láti kó irú ẹgbẹ́ ọmọ ogun bẹ́ẹ̀ jọ láti lè dènà rúkèrúdò nínú ayé bí?
Rúkèrúdò ńláǹlà bẹ́ sílẹ̀ nígbà tí àwùjọ àwọn èèyànkéèyàn kan tí wọ́n mú ohun ìjà dání, mú Jésù nínú ọgbà tí ó ti ń gbàdúrà pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. Ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ẹ̀yìn náà fi idà rẹ̀ ṣá ọ̀kan lára àwọn ọkùnrin tí ó wà nínú àwùjọ èèyànkéèyàn náà. Jésù lo àkókò náà láti ṣàlàyé ìlànà pàtàkì kan. Ó wí pé: “Dá idà rẹ̀ padà sí àyè rẹ̀, nítorí gbogbo àwọn tí wọ́n bá ń mú idà yóò ṣègbé nípasẹ̀ idà. Tàbí ìwọ ha rò pé èmi kò lè ké gbàjarè sí Baba mi láti pèsè àwọn áńgẹ́lì tí ó ju líjíónì méjìlá fún mi ní ìṣẹ́jú yìí?” Jésù ní ẹgbàágbèje ọmọ ogun tí ó lè pàṣẹ fún, ṣùgbọ́n Pétérù kò sí lára wọn, bẹ́ẹ̀ sì ni ẹ̀dá ènìyàn èyíkéyìí. Kàkà bẹ́ẹ̀, a ti pe Pétérù àti àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù yòókù láti jẹ́ “apẹja ènìyàn.” (Mátíù 4:19; 26:47-53) Wákàtí díẹ̀ lẹ́yìn náà, Jésù jẹ́ kí Pílátù lóye ipò náà lọ́nà tí ó ṣe kedere. Ó wí pé: “Ìjọba mi kì í ṣe apà kan ayé yìí. Bí ìjọba mi bá jẹ́ apá kan ayé yìí, àwọn ẹmẹ̀wà mi ì bá ti jà kí a má bàa fà mí lé àwọn Júù lọ́wọ́. Ṣùgbọ́n, gẹ́gẹ́ bí ó ti rí, ìjọba mi kì í ṣe láti orísun yìí.” (Jòhánù 18:36) Láìdàbí ìjọba Dáfídì tí a gbé kalẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé, ọ̀run ni Ìjọba tí Ọlọ́run fún Jésù wà, yóò sì mú àlàáfíà wá sórí ilẹ̀ ayé.
Ẹgbẹ́ Ọmọ Ogun Ọlọ́run Yóò Jagun
Láìpẹ́, ẹgbẹ́ ọmọ ogun Ọlọ́run yóò gbé ìgbésẹ̀. Ní ṣíṣàpèjúwe ìforígbárí tí ń bẹ níwájú, Ìṣípayá pe Jésù ní “Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.” A kà pé: “Àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun tí ń bẹ ní ọ̀run ń tẹ̀ lé e lórí àwọn ẹṣin funfun, wọ́n sì wọ aṣọ ọ̀gbọ̀ àtàtà, funfun, tí ó mọ́. Idà gígùn mímú sì yọ jáde láti ẹnu rẹ̀, kí ó lè fi í ṣá àwọn orílẹ̀-èdè.” Bíbélì sọ pé ìjà yìí yóò yọrí sí òpin “àwọn ọba ilẹ̀ ayé àti àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wọn.” Ní ti àwọn yòókù tí wọ́n kùnà láti fi ìdúróṣinṣin wọn hàn sí Ọlọ́run, àsọtẹ́lẹ̀ náà fi kún un pé: “Àwọn ìyókù ni a fi idà gígùn ẹni tí ó jókòó sórí ẹṣin pa tán.” Àní a óò gba agbára lọ́wọ́ Sátánì Èṣù pàápàá. Ní tòótọ́, èyí yóò mú kí ayé alálàáfíà kan tí kò sí ẹgbẹ́ ọmọ ogun wà.—Ìṣípayá 19:11-21; 20:1-3.
Fọkàn Yàwòrán Ayé Kan Tí Kò Sí Ogun
Ìwọ ha lè fojú inú wo ayé kan tí ó láàbò tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí a kò fi nílò àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun? Sáàmù kan nínú Bíbélì sọ pé: “Ẹ wá wo àwọn ìgbòkègbodò Jèhófà, bí ó ti gbé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ayanilẹ́nu kalẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé. Ó mú kí ogun kásẹ̀ nílẹ̀ títí dé ìkangun ilẹ̀ ayé.”—Sáàmù 46:8, 9.
Ìtura ńláǹlà ni èyí yóò mà jẹ́ o! Fọkàn yàwòrán ṣíṣeéṣe náà fún àwùjọ ẹ̀dá ènìyàn láti bọ́ lọ́wọ́ ìnira pípanilára ti sísanwó ẹgbẹ́ ọmọ ogun àti ohun èlò wọn! Yóò ṣeé ṣe fún àwọn ènìyàn láti darí agbára wọn síhà mímú ipò ìgbésí ayé ẹnìkọ̀ọ̀kan sunwọ̀n si, síhà títún ilẹ̀ ayé ṣe àti sísọ ọ́ di tuntun. Àwọn àǹfààní tuntun yóò wà láti hùmọ̀ àwọn nǹkan tí yóò ṣàǹfààní gidigidi fún aráyé.
Ìlérí yìí yóò ní ìmúṣẹ kárí ayé: “A kì yóò gbọ́ ìwà ipá mọ́ ní ilẹ̀ rẹ, a kì yóò gbọ́ ìfiṣèjẹ tàbí ìwópalẹ̀ ní ààlà rẹ.” (Aísáyà 60:18) A kì yóò tún gbọ́ nípa àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn olùwá-ibi-ìsádi tí ń wọ́nà èyíkéyìí tí wọ́n fi lè sá kúrò níbi tí ogun ti ń jà, tí a fipá mú láti sá fi ilé àti dúkíà wọn sílẹ̀, láti máa gbé nínú àwọn ibùdó tí ó kún fún ipò ìnira. A kì yóò tún gbọ́ nípa àwọn ènìyàn tí ń pohùn rere ẹkún nítorí àwọn olólùfẹ́ wọn tí a pa tàbí tí a sọ daláàbọ̀ ara nínú ìjà láàárín àwọn orílẹ̀-èdè. Ọba ọ̀run Jèhófà yóò gbé àlàáfíà pípẹ́ títí kan kalẹ̀ kárí ayé. “Ní àwọn ọjọ́ rẹ̀, olódodo yóò rú jáde, àti ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà títí òṣùpá kì yóò fi sí mọ́. Yóò tún ọkàn wọn rà padà lọ́wọ́ ìnilára àti lọ́wọ́ ìwà ipá.”—Sáàmù 72:7, 14.
Ohun tí yóò tún dùn mọ́ni ni ìgbésí ayé láàárín àwọn ènìyàn tí wọ́n ti kọ́ láti fara wé àwọn ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà ń fi ìfẹ́ hàn, kì í ṣe láti kórìíra. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Wọn kì yóò ṣe ìpalára èyíkéyìí, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò fa ìparun èyíkéyìí ní gbogbo òkè ńlá mímọ́ mi; nítorí pé, ṣe ni ilẹ̀ ayé yóò kún fún ìmọ̀ Jèhófà bí omi ti bo okun.” Báwo ni gbígbé láàárín àwọn ènìyàn tí wọ́n mọ Jèhófà, tí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ yóò ti rí? Ìwé kan náà sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Iṣẹ́ òdodo tòótọ́ yóò sì di àlàáfíà; iṣẹ́ ìsìn òdodo tòótọ́ yóò sì di ìdákẹ́jẹ́ẹ́ àti ààbò fún àkókò tí ó lọ kánrin. Àwọn ènìyàn mi yóò sì máa gbé ní ibi gbígbé tí ó kún fún àlàáfíà àti ní àwọn ibùgbé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìgbọ́kànlé àti ní àwọn ibi ìsinmi tí kò ní ìyọlẹ́nu.”—Aísáyà 11:9; 32:17, 18.
Àwọn tí wọ́n gbé ìgbàgbọ́ wọn karí ìmọ̀ Bíbélì fòye mọ̀ pé ẹgbẹ́ ọmọ ogun Ọlọ́run ti wà ní sẹpẹ́ láti gba gbogbo àwọn ọ̀tá àlàáfíà kúrò ní ilẹ̀ ayé. Ìmọ̀ yìí fún wọn ní ìgbọ́kànlé láti fi ohun tí Bíbélì sọ pé “yóò . . . ṣẹlẹ̀ ní apá ìgbẹ̀yìn àwọn ọjọ́” sílò. Ìyẹn ni pé: “Wọn yóò ní láti fi idà wọn rọ abẹ ohun ìtúlẹ̀, wọn yóò sì fi ọ̀kọ̀ wọn rọ ọ̀bẹ ìrẹ́wọ́-ọ̀gbìn. Orílẹ̀-èdè kì yóò gbé idà sókè sí orílẹ̀-èdè, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò kọ́ṣẹ́ ogun mọ́.”—Aísáyà 2:2-4.
Àwọn ènìyàn tí ó ti inú ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè wá tí wọ́n ti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti yọwọ́ nínú ‘kíkọ́ṣẹ́ ogun’ tẹ́lẹ̀. Wọ́n ti fi ìgbọ́kànlé wọn sínú ààbò ẹgbẹ́ ọmọ ogun ọ̀run ti Ọlọ́run. Nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú wọn, ìwọ pẹ̀lú lè mú irú ìgbọ́kànlé bẹ́ẹ̀ dàgbà.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 28]
Fọ́tò U.S. National Archives