Máà Jẹ́ Kí Àníyàn Borí Rẹ
“ẸMÁ ṣàníyàn láé nípa ọ̀la, nítorí ọ̀la yóò ní àwọn àníyàn tirẹ̀. Búburú ti ọjọ́ kọ̀ọ̀kan tó fún un.” (Mátíù 6:34) Dájúdájú, ìmọ̀ràn yẹn, tí Jésù Kristi fúnni, wúlò fún gbogbo àwa táa ń gbé nínú àwùjọ sáré-n-bájà òde òní tó kún fún pákáǹleke.
Ṣùgbọ́n ṣá, ká sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà, ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe kí a má ṣàníyàn nípa àwọn ìṣòro wa, ìpinnu wa, ẹrù iṣẹ́ wa, àti ojúṣe wa? Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn ló sorí kọ́, tí ìdààmú ti bá, tí ọrùn sì wọ̀. Ìdí nìyẹn tí òwò egbòogi amárarọni àti àwọn oògùn akunnilóorun fi ń di èyí tí ń mú òbítíbitì owó tabua wọlé.
Ó Yẹ Kí Ó Ní Ààlà
Ó yẹ ká wéwèé, ká sì múra sílẹ̀ fún ojúṣe wa, ẹrù iṣẹ́ wa, ìpinnu wa, àti àwọn ìṣòro wa—yálà wọ́n jẹ́ kánjúkánjú tàbí wọn kò jẹ́ kánjúkánjú. Bíbélì rọ̀ wá pé ká “kọ́kọ́ jókòó, kí [a] sì gbéṣirò lé ìnáwó,” ká tó dáwọ́ lé iṣẹ́ pàtàkì èyíkéyìí. (Lúùkù 14:28-30) Èyí kan ríronú lórí àwọn yíyàn tó wà lárọ̀ọ́wọ́tó, ṣíṣàyẹ̀wò fínnífínní lórí àwọn ohun tó ṣeé ṣe kó tìdí ẹ̀ yọ, àti gbígbéṣirò lé àkókò, agbára, àti owó tí yóò náni.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó yẹ ká fara balẹ̀ gbé ohun tó lè ṣẹlẹ̀ yẹ̀ wò, kò ṣeé ṣe, bẹ́ẹ̀ ni kò bọ́gbọ́n mu láti gbìyànjú láti ronú kan gbogbo ohun tó lè tìdí ẹ̀ yọ. Fún àpẹẹrẹ, nítorí ààbò ìdílé, o lè ronú nípa ohun tó yẹ ní ṣíṣe bí ilé rẹ bá gbiná. O lè ra àwọn ẹ̀rọ tí ń han gooro nígbà tí èéfín bá wà nínú ilé, o sì tún lè ra àwọn ohun èlò àfipaná, kí o sì fi wọ́n síbi yíyẹ nínú ilé. Ẹ lè wéwèé, kí ẹ sì ṣe ìfidánrawò onírúurú ọ̀nà tí ẹ lè gbà sá jáde bí ilé bá ń jó. Ṣùgbọ́n kò ha yẹ kí ààlà wà láàárín ìwéwèé tó mọ́gbọ́n dání, tó ṣeé mú lò àti àníyàn àṣekúdórógbó tí kò nídìí? Irú àníyàn yẹn máa ń bẹ̀rẹ̀ nígbà tóo bá bẹ̀rẹ̀ sí jara pàrà nítorí àìmọye ohun tó ṣeé ṣe kó ṣẹlẹ̀, ìròkurò ló sì máa ń fa ọ̀pọ̀ lára irú ìrònú bẹ́ẹ̀. Àwọn èrò tí ń gbéni lọ́kàn sókè lè bò ẹ́ mọ́lẹ̀, kí ó máa dà ẹ́ láàmú ṣáá pé ó jọ pé o ti gbójú fo nǹkan kan dá, tàbí pé o kò tíì dáàbò bo ìdílé rẹ tó. Làásìgbò àfọwọ́fà yìí lè dà ẹ́ lọ́kàn rú tó bẹ́ẹ̀ tí o kò fi ní rí oorun sùn.
Mósè Wá Síwájú Fáráò
Jèhófà Ọlọ́run rán Mósè, wòlíì rẹ̀, ní iṣẹ́ kan tó ṣòro. Lákọ̀ọ́kọ́, Mósè ní láti fara hàn níwájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, kí ó sì mú un dá wọn lójú pé Jèhófà ló yan òun láti wá kó wọn jáde kúrò ní Íjíbítì. Lẹ́yìn èyí, Mósè ní láti fara hàn níwájú Fáráò, kí ó sì sọ fún un pé kó jẹ́ kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde lọ. Níkẹyìn, Mósè ní láti kó àwọn èèyàn tí iye wọ́n tó àràádọ́ta ọ̀kẹ́ la aginjù já, lọ sí ilẹ̀ kan tí àwọn ọ̀tá ń gbé. (Ẹ́kísódù 3:1-10) Gbogbo èyí lè dẹ́rù bani gan-an, ṣùgbọ́n ǹjẹ́ Mósè jẹ́ kí ẹrù iṣẹ́ yìí kó òun sínú àníyàn tí kò yẹ?
Láìṣẹ̀ṣẹ̀ máa sọ, Mósè ṣàníyàn nípa àwọn ọ̀ràn mélòó kan. Ó béèrè lọ́wọ́ Jèhófà pé: “Ká ní mo wá dé ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí mo sì sọ fún wọn pé, ‘Ọlọ́run àwọn baba ńlá yín ni ó rán mi sí yín,’ tí wọ́n sì sọ fún mi pé, ‘Kí ni orúkọ rẹ̀?’ Kí ni èmi yóò sọ fún wọn?” Jèhófà kọ́ ọ ní èsì tí yóò fọ̀. (Ẹ́kísódù 3:13, 14) Mósè tún ṣàníyàn nípa ohun tó lè ṣẹlẹ̀ bí Fáráò kò bá gba òun gbọ́. Lẹ́ẹ̀kan sí i, Jèhófà dá wòlíì náà lóhùn. Ìṣòro kan ṣoṣo tó kù rèé—Mósè sọ pé òun kò lè “sọ̀rọ̀ lọ́nà tí ó já geere.” Kí la o ti wá ṣèyí sí o? Jèhófà ní kí Áárónì ṣe agbọ̀rọ̀sọ Mósè.—Ẹ́kísódù 4:1-5; 10-16.
Nígbà tí Mósè rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè rẹ̀ àti nítorí pé ó ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run, ó ṣe ohun tí Jèhófà pa láṣẹ. Dípò kí ó máa fi àwọn èrò adáyàjáni fòòró ẹ̀mí ara rẹ̀, nípa ohun tó lè ṣẹlẹ̀ nígbà tóun bá dé iwájú Fáráò, Mósè “ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́.” (Ẹ́kísódù 7:6) Ká ní ó jẹ́ kí àníyàn bo òun mọ́lẹ̀ ni, èyí ì bá bomi pa ìgbàgbọ́ àti ìgboyà tó nílò láti fi ṣe iṣẹ́ tí Ọlọ́run rán an.
Sùúrù tí Mósè lò láti bójú tó iṣẹ́ náà jẹ́ àpẹẹrẹ ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pè ní “ìyèkooro èrò inú.” (2 Tímótì 1:7; Títù 2:2-6) Ká ní Mósè kò lo ìyèkooro èrò inú ni, iṣẹ́ bàǹtà-banta tó wà níwájú rẹ̀ ì bá ti mú un láyà pami débi pé ì bá kọ̀ láti jẹ́ iṣẹ́ yẹn.
Ṣíṣàkóso Ìrònú Rẹ
Nínú ìgbésí ayé rẹ ojoojúmọ́, báwo lo ṣe ń hùwà padà tí àwọn ìdánwò ìgbàgbọ́ tàbí ìṣòro bá dojú kọ ẹ́? Ó ha sábà máa ń gbọ̀n jìnnìjìnnì, tí yóò sì wá jẹ́ pé kìkì àwọn ìṣòro àti ìpèníjà tó wà níwájú ni wàá máa ronú lé lórí? Tàbí kẹ̀, o ha máa ń fọkàn ara rẹ balẹ̀ bí? Bí àwọn kan ti máa ń sọ, ‘Kò yẹ kí èèyàn kú de ikú.’ Òótọ́ ni, nítorí ikú tilẹ̀ lè máà dé! Nítorí náà, èé ṣe tí oó fi jẹ́ kí ohun tó lè má ṣẹlẹ̀ láé máa fòòró ẹ̀mí rẹ? Bíbélì sọ pé: “Àníyàn ṣíṣe nínú ọkàn-àyà ènìyàn ni yóò mú un tẹ̀ ba, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ rere ní ń mú un yọ̀.” (Òwe 12:25) Ohun tó sábà máa ń yọrí sí ni pé èèyàn á wá bẹ̀rẹ̀ sí sún ìpinnu síwájú, á máa fòní-dónìí fọ̀la-dọ́la, títí yóò fi pẹ́ jù.
Ìpalára tẹ̀mí tí àníyàn lè fà tún wá burú jù. Jésù Kristi fi hàn pé agbára ìtannijẹ ọrọ̀ àti “àníyàn ètò àwọn nǹkan yìí” lè fún ìmọrírì tí ẹnì kan ní fún “ọ̀rọ̀ ìjọba náà” pa. (Mátíù 13:19, 22) Gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹ̀gún ti lè ṣèdíwọ́ fún irúgbìn láti dàgbà kí ó sì sèso, bẹ́ẹ̀ náà ni àníyàn tó pàpọ̀jù lè ṣèdíwọ́ fún ìtẹ̀síwájú wa nípa tẹ̀mí àti sísèso fún ìyìn Ọlọ́run. Làásìgbò àfọwọ́fà tí ń jẹni run tilẹ̀ ti mú kí àwọn kan fawọ́ yíya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà sẹ́yìn. Wọ́n ń dààmú pé, ‘Bí n kò bá gbé ní ìbámu pẹ̀lú ìyàsímímọ́ mi ńkọ́?’
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ fún wa pé nínú ogun tẹ̀mí táa ń jà, a ń sapá láti mú “gbogbo ìrònú wá sí oko òǹdè láti mú un ṣègbọràn sí Kristi.” (2 Kọ́ríńtì 10:5) Inú Sátánì Èṣù, olórí ọ̀tá wa, yóò dùn gan-an láti gùn lé ìdààmú wa kí ó lè mú wa rẹ̀wẹ̀sì, kí ó sì kó àárẹ̀ bá wa nípa tara, nípa ti èrò ìmọ̀lára, àti nípa tẹ̀mí. Ọ̀gá ni nínú fífi iyèméjì dẹ páńpẹ́ mú ẹni tí kò bá fura. Ìdí nìyẹn tí Pọ́ọ̀lù tún fi kìlọ̀ fún àwọn Kristẹni pé kí wọ́n “má ṣe fi àyè sílẹ̀ fún Èṣù.” (Éfésù 4:27) Gẹ́gẹ́ bí “ọlọ́run ètò àwọn nǹkan yìí,” Sátánì ti kẹ́sẹ járí nínú ‘fífọ́ èrò inú àwọn aláìgbàgbọ́ lójú.’ (2 Kọ́ríńtì 4:4) Ǹjẹ́ kí a má yọ̀ǹda fún un láé láti ṣàkóso èrò inú wa!
Ìrànlọ́wọ́ Wà Lárọ̀ọ́wọ́tó
Nígbà tí ọmọ kan bá dojú kọ ìṣòro, ó lè tọ baba onífẹ̀ẹ́ lọ, yóò sì rí ìtọ́sọ́nà àti ìtùnú gbà. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, a lè mú àwọn ìṣòro wa tọ Jèhófà, Baba wa ọ̀run, lọ. Ní tòótọ́, Jèhófà ké sí wa pé ká ju ẹrù ìnira àti àníyàn wa sọ́dọ̀ òun. (Sáàmù 55:22) Bí ọmọ tí kò dààmú mọ́ nípa ìṣòro rẹ̀ ni lẹ́yìn tí baba rẹ̀ bá ti fi í lọ́kàn balẹ̀, ẹ jẹ́ ká ju ẹrù ìnira wa sọ́dọ̀ Jèhófà, ṣùgbọ́n kò tán síbẹ̀ o, a tún ní láti fi í sílẹ̀ sọ́dọ̀ rẹ̀.—Jákọ́bù 1:6.
Báwo la ṣe lè ju àníyàn wa sọ́dọ̀ Jèhófà? Ìwé Fílípì 4:6, 7 dáhùn, ó ní: “Ẹ má ṣe máa ṣàníyàn nípa ohunkóhun, ṣùgbọ́n nínú ohun gbogbo nípasẹ̀ àdúrà àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́ kí ẹ máa sọ àwọn ohun tí ẹ ń tọrọ di mímọ̀ fún Ọlọ́run; àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ yóò sì máa ṣọ́ ọkàn-àyà yín àti agbára èrò orí yín nípasẹ̀ Kristi Jésù.” Bẹ́ẹ̀ ni, ní ìdáhùn sí àdúrà àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ wa láìdábọ̀, Jèhófà lè fún wa ní ìfàyàbalẹ̀ tí yóò dáàbò bo ìrònú wa, kí àníyàn tí kò nídìí má bàa kó wàhálà bá wa.—Jeremáyà 17:7, 8; Mátíù 6:25-34.
Ṣùgbọ́n o, láti ṣiṣẹ́ ní ìbámu pẹ̀lú àdúrà wa, kò yẹ ká ya ara wa sọ́tọ̀, yálà nípa tara tàbí nípa ti èrò orí. (Òwe 18:1) Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló yẹ ká gbé àwọn ìlànà àti ìtọ́sọ́nà Bíbélì tó jẹ mọ́ ìṣòro wa yẹ̀ wò, ká tipa bẹ́ẹ̀ yẹra fún gbígbáralé òye tara wa. (Òwe 3:5, 6) Lọ́mọdé lágbà, a lè yíjú sí Bíbélì àti àwọn ìtẹ̀jáde Watch Tower fún òbítíbitì ìsọfúnni nípa báa ṣe lè ṣèpinnu àti báa ṣe lè kojú ìṣòro. Ní àfikún, nínú ìjọ Kristẹni, a fi àwọn alàgbà ọlọgbọ́n tí wọ́n tún jẹ́ ẹni ìrírí àti àwọn Kristẹni mìíràn tó dàgbà dénú jíǹkí wa, àwọn tó máa ń fẹ́ bá wa sọ̀rọ̀ nígbà gbogbo. (Òwe 11:14; 15:22) Àwọn tí ìṣòro wa kò tíì kó ìdààmú bá, tí èrò wọn sì bá ti Ọlọ́run mu lórí ọ̀ràn ọ̀hún, lè ràn wá lọ́wọ́ lọ́pọ̀ ìgbà láti fojú mìíràn wo ìṣòro wa. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kò ní ṣe ìpinnu fún wa, síbẹ̀ wọ́n lè jẹ́ orísun ìṣírí àti ìtìlẹyìn gbágbáágbá.
“Dúró De Ọlọ́run”
Kò sẹ́ni tó lè sẹ́ òtítọ́ náà pé másùnmáwo tó wà nínú kíkojú àwọn ìṣòro táa ń bá pàdé lójoojúmọ́ ti tó gẹ́ẹ́, kí a máà tún ṣẹ̀ṣẹ̀ dá kún wọn nípa dídààmú nípa àwọn ìṣòro àfọkànrò. Bí àníyàn nípa ohun tó lè ṣẹlẹ̀ bá ń já wa láyà, tó sì ń fa inú fuu ẹ̀dọ̀ fuu, nígbà náà, ẹ jẹ́ ká yíjú sí Jèhófà nínú àdúrà àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀. Yíjú sí Ọ̀rọ̀ àti ètò àjọ rẹ̀ fún ìtọ́sọ́nà, ọgbọ́n, àti ìyèkooro èrò inú. A óò rí i pé ipòkípò tó bá dìde, ìrànlọ́wọ́ ń bẹ lárọ̀ọ́wọ́tó láti kojú rẹ̀.
Nígbà tí ọkàn onísáàmù bàjẹ́, tí ṣìbáṣìbo bá a, ó kọ ọ́ lórin pé: “Èé ṣe tí o fi ń bọ́hùn, ìwọ ọkàn mi, èé sì ti ṣe tí o fi ń ru gùdù nínú mi? Dúró de Ọlọ́run, nítorí pé síbẹ̀síbẹ̀, èmi yóò máa gbé e lárugẹ gẹ́gẹ́ bí ìgbàlà títóbi lọ́lá fún èmi alára àti gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run mi.” (Sáàmù 42:11) Kí èrò yẹn jẹ́ tawa náà.
Bẹ́ẹ̀ ni, wéwèé fún ohun tó lè ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú, kí o sì fi ohun tó lè ṣẹlẹ̀ láìròtẹ́lẹ̀ sílẹ̀ fún Jèhófà. “[Ẹ] kó gbogbo àníyàn yín lé e, nítorí ó bìkítà fún yín.”—1 Pétérù 5:7.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Gẹ́gẹ́ bíi Dáfídì, ǹjẹ́ o máa ń ju ẹrù ìnira àti àníyàn rẹ sọ́dọ̀ Jèhófà?