“Àwọn Ẹ̀bùn Tí Ó Jẹ́ Ènìyàn” Láti Máa Bójú Tó Àwọn Àgùntàn Jèhófà
“Nígbà tí ó gòkè lọ sí ibi gíga lókè, ó kó àwọn òǹdè lọ; ó fúnni ní àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ ènìyàn.”—ÉFÉSÙ 4:8.
1. Kí lọ̀rọ̀ tí Kristẹni arábìnrin kan sọ nípa àwọn alàgbà inú ìjọ rẹ̀?
“Ẹ MÀ kú ìtọ́jú wa o. Ẹ̀rín tó désàlẹ̀ ikùn lẹ̀ ń rín sí wa, kódà ọ̀yàyà yín àtọkànwá ni, tinútinú lẹ sì ń ṣàníyàn nípa wa. Gbogbo ìgbà lẹ máa ń tẹ́tí sílẹ̀ láti gbọ́ wa lágbọ̀ọ́yé, ẹ sì ń fi ọ̀rọ̀ Bíbélì tù wá nínú. Ọlọ́run má mà jẹ́ n kóyán yín kéré o.” Kristẹni arábìnrin kan ló kọ lẹ́tà yìí sáwọn alàgbà ìjọ ẹ̀. Dájúdájú, ìfẹ́ tí àwọn Kristẹni olùṣọ́ àgùntàn alábòójútó ń fi hàn ló wú u lórí tó bẹ́ẹ̀.—1 Pétérù 5:2, 3.
2, 3. (a) Gẹ́gẹ́ bí Aísáyà 32:1, 2, ti wí, báwo ni àwọn alàgbà oníyọ̀ọ́nú ṣe ń bójú tó àwọn àgùntàn Jèhófà? (b) Kí ló lè mú kí a ka alàgbà kan sí ẹ̀bùn?
2 Àwọn alàgbà jẹ́ ìpèsè látọ̀dọ̀ Jèhófà fún títọ́jú àwọn àgùntàn rẹ̀. (Lúùkù 12:32; Jòhánù 10:16) Àwọn àgùntàn Jèhófà ṣeyebíye lójú rẹ̀—àní, wọ́n ṣeyebíye tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tó fi jẹ́ pé ẹ̀jẹ̀ Jésù tó níye lórí gan-an ló fi rà wọ́n. Abájọ tí inú Jèhófà fi máa ń dùn táwọn alàgbà bá fọwọ́ jẹ̀lẹ́ńkẹ́ mú agbo rẹ̀. (Ìṣe 20:28, 29) Ṣàkíyèsí báa ṣe ṣàpèjúwe àwọn alàgbà, tàbí “àwọn ọmọ aládé” wọ̀nyí lọ́nà àsọtẹ́lẹ̀: “Olúkúlùkù yóò sì wá dà bí ibi ìfarapamọ́sí kúrò lọ́wọ́ ẹ̀fúùfù àti ibi ìlùmọ́ kúrò lọ́wọ́ ìjì òjò, bí àwọn ìṣàn omi ní ilẹ̀ aláìlómi, bí òjìji àpáta gàǹgà ní ilẹ̀ gbígbẹ táútáú.” (Aísáyà 32:1, 2) Bẹ́ẹ̀ ni, iṣẹ́ wọn ni láti máa dáàbò bo àwọn àgùntàn rẹ̀, láti máa tù wọ́n lára, àti láti máa tù wọ́n nínú. Fún ìdí yìí, àwọn alàgbà tó bá ń fi ẹ̀mí ìyọ́nú tọ́jú agbo ń sapá láti dójú ìlà ohun tí Ọlọ́run ń retí pé kí wọ́n ṣe.
3 Irúfẹ́ àwọn alàgbà bẹ́ẹ̀ ni Bíbélì pè ní “àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ ènìyàn.” (Éfésù 4:8) Tóo bá ronú nípa ẹ̀bùn kan, ọkàn rẹ yóò lọ sórí ohun kan táa fúnni láti kájú àìní kan tàbí láti mú kí ẹni tó rí i gbà láyọ̀. A lè ka alàgbà kan sí ẹ̀bùn, tó bá ń fi ìmọ̀ rẹ̀ pèsè ìrànlọ́wọ́ táa nílò, tó sì ń fi kún ayọ̀ agbo. Báwo ló ṣe lè ṣe èyí? Ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ nínú Éfésù 4:7-16, dáhùn ìbéèrè yìí, ìdáhùn náà sì fi hàn kedere pé Jèhófà bìkítà gidigidi fún àwọn àgùntàn rẹ̀.
“Àwọn Ẹ̀bùn Tí Ó Jẹ́ Ènìyàn” —Látọ̀dọ̀ Ta Ni Wọ́n Ti Wá?
4. Ní ìmúṣẹ Sáàmù 68:18, báwo ni Jèhófà ṣe “gòkè lọ sí ibi gíga lókè,” àwọn wo sì ni “àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ ènìyàn”?
4 Nígbà tí Pọ́ọ̀lù lo gbólóhùn náà “àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ ènìyàn,” ọ̀rọ̀ Ọba Dáfídì ló ń fà yọ, ẹni tó sọ nípa Jèhófà pé: “Ìwọ ti gòkè lọ sí ibi gíga lókè; ìwọ ti kó àwọn òǹdè lọ; ìwọ ti kó àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ ènìyàn.” (Sáàmù 68:18) Lẹ́yìn táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti wà ní Ilẹ̀ Ìlérí fún ọdún mélòó kan, Jèhófà “gòkè” lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ lọ sórí Òkè Síónì, ó sọ Jerúsálẹ́mù di olú ìlú ìjọba Ísírẹ́lì, ó sì fi Dáfídì jẹ ọba ibẹ̀. Ṣùgbọ́n àwọn wo ni “ẹ̀bùn tí ó jẹ́ ènìyàn”? Àwọn ni àwọn ènìyàn táa mú lóǹdè nígbà tí wọ́n ṣẹ́gun ilẹ̀ náà. Nígbà tó wá yá o, àwọn kan lára àwọn òǹdè wọ̀nyí di amúgbálẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ Léfì, tí wọ́n ń ràn wọ́n lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ àgọ́ ìjọsìn.—Ẹ́sírà 8:20.
5. (a) Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe fi hàn pé Sáàmù 68:18 ń ní ìmúṣẹ nínú ìjọ Kristẹni? (b) Báwo ni Jésù ṣe “gòkè lọ sí ibi gíga lókè”?
5 Nínú lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn ará Éfésù, ó fi hàn pé àwọn ọ̀rọ̀ onísáàmù náà ní ìmúṣẹ títóbi jù lọ nínú ìjọ Kristẹni. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń tún ọ̀rọ̀ inú Sáàmù 68:18 sọ, ó kọ̀wé pé: “Wàyí o, olúkúlùkù wa ni a fún ní inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí ní ìbámu pẹ̀lú bí Kristi ṣe díwọ̀n ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ náà fúnni. Nítorí náà ni ó ṣe wí pé: ‘Nígbà tí ó gòkè lọ sí ibi gíga lókè, ó kó àwọn òǹdè lọ; ó fúnni ní àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ ènìyàn.’” (Éfésù 4:7, 8) Pọ́ọ̀lù lo sáàmù yìí níhìn-ín fún Jésù gẹ́gẹ́ bí aṣojú Ọlọ́run. Jésù “ṣẹ́gun ayé” nípasẹ̀ ipa ọ̀nà ìṣòtítọ́ rẹ̀. (Jòhánù 16:33) Ó tún ṣẹ́gun ikú àti Sátánì nípa jíjí tí Ọlọ́run jí i dìde kúrò nínú òkú. (Ìṣe 2:24; Hébérù 2:14) Lọ́dún 33 Sànmánì Tiwa, Jésù tí a ti jí dìde gòkè “ré kọjá gbogbo ọ̀run”—a gbé e ga ju gbogbo àwọn ẹ̀dá ọ̀run yòókù. (Éfésù 4:9, 10; Fílípì 2:9-11) Gẹ́gẹ́ bí aṣẹ́gun, Jésù kó “àwọn òǹdè” láti inú àwọn ọ̀tá. Báwo ló ṣe rí bẹ́ẹ̀?
6. Bẹ̀rẹ̀ láti Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa, báwo ni Jésù tó ti gòkè lọ, ṣe bẹ̀rẹ̀ sí kó ẹrù ilé Sátánì, kí ló sì fi “àwọn òǹdè” náà ṣe?
6 Nígbà tó wà lórí ilẹ̀ ayé, Jésù fi hàn pé òun lágbára lórí Sátánì nípa títú àwọn òǹdè ẹ̀mí èṣù sílẹ̀. Ṣe ló dà bí ẹni pé Jésù gbógun ti ilé Sátánì, tó dè é, tó sì kó àwọn ẹrù rẹ̀. (Mátíù 12:22-29) Rò ó wò ná, níwọ̀n ìgbà táa ti jí Jésù dìde, táa sì ti fi ‘gbogbo ọlá àṣẹ ní ọ̀run àti lórí ilẹ̀ ayé fún un,’ kí ó máa piyẹ́ lọ ló kù o jàre! (Mátíù 28:18) Bẹ̀rẹ̀ láti Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa, Jésù tó ti gòkè lọ, gẹ́gẹ́ bí aṣojú Ọlọ́run, bẹ̀rẹ̀ sí kó ẹrù ilé Sátánì nípa ‘kíkó àwọn òǹdè lọ’—èyíinì ni àwọn èèyàn tó ti pẹ́ lóko ẹrú ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú lábẹ́ ìdarí Sátánì. “Àwọn òǹdè” wọ̀nyí fínnú-fíndọ̀ di “ẹrú Kristi, ní ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run tọkàntọkàn.” (Éfésù 6:6) Ohun tí ìyẹn túmọ̀ sí ni pé, Jésù já wọn gbà kúrò níkàáwọ́ Sátánì, ó sì fi wọ́n fún ìjọ, lórúkọ Jèhófà, gẹ́gẹ́ bí “àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ ènìyàn.” Sáà fojú inú wo inú burúkú tí yóò máa bí Sátánì, bó ti lajú ẹ̀ sílẹ̀ tí a sì ń já wọn gbà kúrò níkàáwọ́ rẹ̀!
7. (a) Irú àwọn iṣẹ́ wo ni “àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ ènìyàn” ń ṣe nínú ìjọ? (b) Àǹfààní wo ni Jèhófà ti fún olúkúlùkù tí ń sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà?
7 Ǹjẹ́ à ń rí irú “àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ ènìyàn” bẹ́ẹ̀ nínú ìjọ lónìí bí? Bẹ́ẹ̀ ni, à ń rí wọn! À ń rí wọn bí wọ́n ti ń sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà, tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ kára gẹ́gẹ́ bí ‘ajíhìnrere, olùṣọ́ àgùntàn, àti olùkọ́’ nínú àwọn ìjọ tó ju ọ̀kẹ́ mẹ́rìn-lé-lẹ́ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin [87,000] ti àwọn ènìyàn Ọlọ́run yíká ayé. (Éfésù 4:11) Ì bá wu Sátánì gan-an tó bá lè ṣẹlẹ̀ pé kí àwọn alàgbà máa han agbo léèmọ̀. Ṣùgbọ́n ìyẹn kọ́ ni ìdí tí Ọlọ́run, nípasẹ̀ Kristi, fi fi wọ́n fún ìjọ. Kàkà bẹ́ẹ̀, Jèhófà pèsè àwọn ọkùnrin wọ̀nyí fún ire ìjọ, wọn yóò sì jíhìn fún un nítorí àwọn àgùntàn tó fi síkàáwọ́ wọn. (Hébérù 13:17) Bóo bá ń sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà, Jèhófà ti fún ẹ ní àǹfààní àgbàyanu kí o lè fi ara rẹ hàn gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn, tàbí ìbùkún, fún àwọn arákùnrin rẹ. O lè jẹ́ bẹ́ẹ̀ nípa ṣíṣe àwọn ojúṣe mẹ́rin pàtàkì.
Nígbà Tí “Ìtọ́sọ́nàpadà” Bá Pọndandan
8. Ní àwọn ọ̀nà wo ni gbogbo wa ti nílò ìtọ́sọ́nàpadà nígbà mìíràn?
8 Èkíní, Pọ́ọ̀lù sọ pé ìdí táa fi pèsè “àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ ènìyàn” ni “láti lè ṣe ìtọ́sọ́nàpadà àwọn ẹni mímọ́.” (Éfésù 4:12) Ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà táa tú sí “ìtọ́sọ́nàpadà” túmọ̀ sí mímú kí nǹkan “gún régé.” Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá aláìpé, gbogbo wa la nílò ìtọ́sọ́nàpadà lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan—a nílò mímú ìrònú wa, ìṣesí wa, tàbí ìwà wa “gún régé” pẹ̀lú ìrònú àti ìfẹ́ Ọlọ́run. Jèhófà ti fi tìfẹ́tìfẹ́ pèsè “àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ ènìyàn” kí wọ́n lè máa ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe àwọn àtúnṣe tó pọndandan. Báwo ni wọ́n ṣe ń ṣe èyí?
9. Báwo ni alàgbà kan ṣe lè ṣèrànwọ́ láti tọ́ àgùntàn kan tó ti ṣìnà sọ́nà padà?
9 Nígbà mìíràn, a lè ké sí alàgbà pé kí ó wá ran àgùntàn kan tó ti ṣìnà lọ́wọ́, bóyá tó “ṣi ẹsẹ̀ gbé kí ó tó mọ̀.” Báwo ni alàgbà ṣe lè ràn án lọ́wọ́? “Kí ẹ̀yin tí ẹ tóótun nípa tẹ̀mí gbìyànjú láti tọ́ irúfẹ́ ẹni bẹ́ẹ̀ sọ́nà padà nínú ẹ̀mí ìwà tútù,” ni Gálátíà 6:1 wí. Nítorí náà, nígbà tí alàgbà bá ń gba ẹni tó ṣìnà nímọ̀ràn, kò ní máa sọ ọ̀rọ̀ kòbákùngbé sí i, bẹ́ẹ̀ sì ni kò ní máa sọ ọ̀rọ̀ líle-líle sí i. Ṣe ló yẹ kí ìmọ̀ràn fúnni ní ìṣírí, kì í ṣe pé kí ó “já” ẹni tí à ń fún “láyà.” (2 Kọ́ríńtì 10:9; fi wé Jóòbù 33:7.) Ojú tilẹ̀ lè ti máa ti ẹni náà tẹ́lẹ̀, fún ìdí yìí, olùṣọ́ àgùntàn onífẹ̀ẹ́ máa ń yẹra fún kíkó ìrẹ̀wẹ̀sì bá onítọ̀hún. Tó bá ṣe kedere pé ìfẹ́ ló sún wa fúnni nímọ̀ràn, tàbí tó sún wa fúnni ní ìbáwí tí a kò fi sábẹ́ ahọ́n sọ pàápàá, yóò tọ́ ìrònú tàbí ìṣesí ẹni tó ṣìnà sọ́nà, yóò sì tipa bẹ́ẹ̀ mú un padà bọ̀ sípò.—2 Tímótì 4:2.
10. Kí ló wé mọ́ láti tọ́ àwọn èèyàn sọ́nà padà?
10 Ìdí tí Jèhófà fi pèsè “àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ ènìyàn” fún ìtọ́sọ́nàpadà wa ni pé, ó fẹ́ káwọn alàgbà máa tuni lára nípa tẹ̀mí, kí wọ́n sì jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ láàárín àwọn èèyàn rẹ̀. (1 Kọ́ríńtì 16:17, 18; Fílípì 3:17) Títọ́ àwọn èèyàn sọ́nà kò mọ sórí wíwulẹ̀ fàṣìṣe han àwọn tó tọ ipa ọ̀nà àìtọ́, ṣùgbọ́n ó tún wé mọ́ ríran àwọn olóòótọ́ lọ́wọ́ láti máa tọ ipa ọ̀nà títọ́ nìṣó.a Lónìí, pẹ̀lú ọ̀pọ̀ òkè ìṣòro tó máa ń bani lọ́kàn jẹ́, ọ̀pọ̀ èèyàn ló nílò ìṣírí tí yóò mú kí wọ́n ṣara gírí. Àwọn kan lè nílò ìrànlọ́wọ́ oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ tí yóò jẹ́ kí wọ́n mú ìrònú wọn bá ti Ọlọ́run mu. Fún àpẹẹrẹ, àwọn Kristẹni olóòótọ́ kan ń tiraka láti lè borí ìmọ̀lára jíjinlẹ̀ ti àìtóótun tàbí àìwúlò. Irú “àwọn ọkàn tí ó soríkọ́” bẹ́ẹ̀ lè nímọ̀lára pé Jèhófà kò lè fẹ́ràn àwọn láé, àti pé gbogbo ìsapá tí wọ́n ń fi torí-tọrùn ṣe láti sin Ọlọ́run pàápàá kò lè já sí ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ rẹ̀ láé. (1 Tẹsalóníkà 5:14) Ṣùgbọ́n ọ̀nà ìrònú yìí kò sí ní ìbámu pẹ̀lú irú ìmọ̀lára tòótọ́ tí Ọlọ́run ní fún àwọn tí ń sìn ín.
11. Kí ni àwọn alàgbà lè ṣe láti ṣèrànwọ́ fún àwọn tí ń tiraka láti borí ìmọ̀lára pé àwọn kò wúlò?
11 Ẹ̀yin alàgbà, kí lẹ lè ṣe láti ran irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́? Ẹ fi inú rere ṣàjọpín ẹ̀rí láti inú Ìwé Mímọ́ pẹ̀lú wọn, ẹ̀rí tó fi hàn pé Jèhófà bìkítà nípa àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lẹ́nì kọ̀ọ̀kan, kí ẹ sì mú un dá wọn lójú pé àwọn gan-an ni ẹsẹ Bíbélì wọ̀nyí ń bá sọ̀rọ̀. (Lúùkù 12:6, 7, 24) Ẹ ràn wọ́n lọ́wọ́ láti rí i pé Jèhófà ti “fà” wọ́n wá láti wá sin òun, fún ìdí yìí, kò sí àní-àní pé wọ́n níye lórí lójú rẹ̀. (Jòhánù 6:44) Fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀ pé kì í ṣe àwọn nìkan—ọ̀pọ̀ ìránṣẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà ló ti ní irú ìmọ̀lára bẹ́ẹ̀. Ìgbà kan wà tí wòlíì Èlíjà sorí kọ́ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tó fi ń ronú àtikú. (1 Ọba 19:1-4) Ọkàn-àyà àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró kan ní ọ̀rúndún kìíní bẹ̀rẹ̀ sí ‘dá wọn lẹ́bi.’ (1 Jòhánù 3:20) A lè rí ìtùnú nínú mímọ̀ pé àwọn olóòótọ́ tó gbé ayé nígbà táa kọ Bíbélì “ní ìmọ̀lára bí tiwa.” (Jákọ́bù 5:17) Pẹ̀lúpẹ̀lù, ẹ lè ṣàyẹ̀wò àwọn àpilẹ̀kọ tí ń múni lọ́kàn le nínú Ilé Ìṣọ́ àti Jí! pẹ̀lú àwọn oníròbìnújẹ́ ọkàn. Ọlọ́run, tó fi yín fúnni gẹ́gẹ́ bí “àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ ènìyàn,” kò ní fojú kéré àwọn ìsapá onífẹ̀ẹ́ tí ẹ bá ṣe láti gbé ìgbọ́kànlé irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ró.—Hébérù 6:10.
“Gbígbé” Agbo “Ró”
12. Kí ni gbólóhùn náà “gbígbé ara Kristi ró” túmọ̀ sí, kí sì ní ohun pàtàkì táa nílò fún gbígbé agbo ró?
12 Èkejì, a pèsè “àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ ènìyàn” fún “gbígbé ara Kristi ró.” (Éfésù 4:12) Àkànlò èdè ni Pọ́ọ̀lù lò níhìn-ín. Ohun tí ‘gbígbé ró’ mú wá síni lọ́kàn ni iṣẹ́ ilé kíkọ́, nígbà tí “ara Kristi” tọ́ka sí àwọn èèyàn—àwọn mẹ́ńbà ìjọ Kristẹni ẹni àmì òróró. (1 Kọ́ríńtì 12:27; Éfésù 5:23, 29, 30) Ó ṣe pàtàkì kí àwọn alàgbà ran àwọn ará lọ́wọ́ láti di alágbára nípa tẹ̀mí. Góńgó wọn ni láti ‘gbé agbo ró, kì í ṣe láti ya á lulẹ̀.’ (2 Kọ́ríńtì 10:8) Ohun pàtàkì táa nílò fún gbígbé agbo ro ni ìfẹ́, nítorí pé “ìfẹ́ a máa gbéni ró.”—1 Kọ́ríńtì 8:1.
13. Kí ló túmọ̀ sí láti lẹ́mìí ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò, èé sì ti ṣe tó fi ṣe pàtàkì pé káwọn alàgbà máa lẹ́mìí ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò?
13 Ànímọ́ kan tí ìfẹ́ ní, tó máa ń ran àwọn alàgbà lọ́wọ́ láti gbé agbo ró ni ẹ̀mí ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò. Láti ní ẹ̀mí ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò jẹ́ láti máa fara ẹni sípò àwọn ẹlòmíràn—láti lóye ìdí tí ìrònú àti ìmọ̀lára wọ́n fi yàtọ̀, lójú ìwòye ibi tí agbára wọn mọ. (1 Pétérù 3:8) Èé ṣe tó fi ṣe pàtàkì pé káwọn alàgbà ní ẹ̀mí ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò? Lékè gbogbo rẹ̀, ẹ̀mí yìí ṣe pàtàkì nítorí pé Jèhófà—tó fi “àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ ènìyàn” fúnni—jẹ́ Ọlọ́run tó lẹ́mìí ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò. Nígbà táwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ bá ń jìyà tàbí tí wọ́n bá wà nínú ìrora, ó máa ń bá wọn kẹ́dùn. (Ẹ́kísódù 3:7; Aísáyà 63:9) Ó mọ ibi tí agbára wọ́n mọ. (Sáàmù 103:14) Báwo wá ni àwọn alàgbà ṣe lè fi ẹ̀mí ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò hàn?
14. Àwọn ọ̀nà wo ni àwọn alàgbà lè gbà fi ẹ̀mí ìfọ̀rọ̀rora-ẹnì-wò hàn sáwọn èèyàn?
14 Nígbà tí ẹnì kan tí ọkàn rẹ̀ rẹ̀wẹ̀sì bá tọ̀ wọ́n wá, wọn yóò fetí sílẹ̀, wọn yóò sì bá a kẹ́dùn. Wọn yóò sapá láti mọ ipò àtẹ̀yìnwá àwọn ará, àti irú ẹni tí wọ́n jẹ́, àti ipò tó yí wọn ká. Nígbà náà, tí àwọn alàgbà bá wá pèsè ìrànlọ́wọ́ tí ń gbéni ró láti inú Ìwé Mímọ́, yóò rọrùn fáwọn àgùntàn láti tẹ́wọ́ gbà á, torí pé ó wá látọ̀dọ̀ àwọn olùṣọ́ àgùntàn tó lóye wọn ní tòótọ́, tó sì bìkítà nípa wọn. (Òwe 16:23) Ẹ̀mí ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò tún máa ń sún àwọn alàgbà láti ronú nípa ibi tí agbára àwọn ẹlòmíràn mọ, àti ìmọ̀lára tó lè jẹ yọ nítorí èyí. Fún àpẹẹrẹ, àwọn Kristẹni kan, lábẹ́ ìdarí ẹ̀rí ọkàn wọn, lè máa rò pé àwọn ti ṣẹ̀ nítorí pé wọn kò lè ṣe púpọ̀ sí i nínú sísin Ọlọ́run, bóyá nítorí ọjọ́ ogbó tàbí òjòjò. Ní òdìkejì, àwọn kan lè nílò ìṣírí láti mú kí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn gbé pẹ́ẹ́lí sí i. (Hébérù 5:12; 6:1) Ẹ̀mí ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò yóò sún àwọn alàgbà láti wá “ọ̀rọ̀ dídùn” tí yóò gbéni ró. (Oníwàásù 12:10) Nígbà táa bá gbé àwọn àgùntàn Jèhófà ró, táa sì fún wọn ní ìwúrí, ìfẹ́ wọn fún Ọlọ́run yóò sún wọn láti ṣe gbogbo ohun tí wọ́n bá lè ṣe nínú sísìn ín!
Àwọn Ọkùnrin Tí Ń Gbé Ìṣọ̀kan Lárugẹ
15. Kí ni gbólóhùn náà “ìṣọ̀kanṣoṣo nínú ìgbàgbọ́” tọ́ka sí?
15 Ẹ̀kẹta, a pèsè “àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ ènìyàn” kí “gbogbo wa [lè] dé ìṣọ̀kanṣoṣo nínú ìgbàgbọ́ àti nínú ìmọ̀ pípéye nípa Ọmọ Ọlọ́run.” (Éfésù 4:13) Gbólóhùn náà “ìṣọ̀kanṣoṣo nínú ìgbàgbọ́” tọ́ka sí ìrẹ́pọ̀ kì í ṣe nínú ìgbàgbọ́ nìkan, ṣùgbọ́n láàárín àwọn onígbàgbọ́ pẹ̀lú. Nítorí náà, èyí ni ìdí mìíràn tí Ọlọ́run fi fún wa ní “àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ ènìyàn”—láti gbé ìṣọ̀kan lárugẹ láàárín àwọn èèyàn rẹ̀. Báwo ni wọ́n ṣe ń ṣe èyí?
16. Èé ṣe tó fi ṣe pàtàkì pé kí àwọn alàgbà wà ní ìṣọ̀kan láàárín ara wọn?
16 Lákọ̀ọ́kọ́ ná, wọ́n gbọ́dọ̀ wà ní ìṣọ̀kan láàárín ara wọn. Bí àwọn olùṣọ́ àgùntàn bá yapa, wọ́n lè pa àwọn àgùntàn tì. Wọ́n lè bẹ̀rẹ̀ sí fàkókò gidi tí wọn ì bá fi ṣolùṣọ́ àgùntàn ṣòfò nídìí àwọn ìpàdé gígùn àti nídìí fífa àwọn ọ̀rọ̀ tí kò tó nǹkan. (1 Tímótì 2:8) Àwọn alàgbà lè má tètè fohùn ṣọ̀kan lórí gbogbo ohun tí wọ́n bá jíròrò, torí pé ẹ̀dá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n. Ìṣọ̀kan ò ní kí wọ́n má ṣe ní èrò ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tàbí kí wọ́n tilẹ̀ sọ irú èrò bẹ́ẹ̀ jáde lọ́nà tó wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì nínú ìjíròrò tí olúkúlùkù ti lómìnira àtisọ ojú ìwòye rẹ̀. Àwọn alàgbà máa ń pa ìṣọ̀kan wọn mọ́ nípa fífi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ fetí sí ara wọn láìsí ẹ̀tanú. Níwọ̀n ìgbà tí a kò bá rú ìlànà Bíbélì kankan, ó yẹ kí olúkúlùkù ṣe tán láti fara mọ́ ìpinnu tí ẹgbẹ́ àwọn alàgbà bá fẹnu kò sí, kí wọ́n sì kọ́wọ́ ti ìpinnu ọ̀hún lẹ́yìn. Níní irú ẹ̀mí yìí fi hàn pé “ọgbọ́n tí ó wá láti òkè” ló ń darí wọn, ọgbọ́n yìí sì “lẹ́mìí àlàáfíà, ó ń fòye báni lò.”—Jákọ́bù 3:17, 18.
17. Báwo làwọn alàgbà ṣe lè ṣèrànwọ́ láti pa ìṣọ̀kan ìjọ mọ́?
17 Àwọn alàgbà tún máa ń wà lójúfò láti gbé ìṣọ̀kan lárugẹ nínú ìjọ. Nígbà táwọn nǹkan tó lè fa ìyapa—bí sísọ̀rọ̀ àwọn èèyàn láìdáa lẹ́yìn wọn, níní èrò òdì síni, tàbí jíjẹ́ alásọ̀—bá fẹ́ ba àlàáfíà jẹ́, kíákíá ni wọ́n máa ń fúnni ní ìmọ̀ràn tó lè ranni lọ́wọ́. (Fílípì 2:2, 3) Fún àpẹẹrẹ, àwọn alàgbà lè mọ àwọn kan tí wọ́n kúndùn ṣíṣe lámèyítọ́, tàbí àwọn kan tó fẹ́ràn àtimáa tojú bọ ọ̀ràn ọlọ́ràn, tí èyí sì ti sọ wọ́n di ọ̀yọjúràn. (1 Tímótì 5:13; 1 Pétérù 4:15) Àwọn alàgbà yóò gbìyànjú láti ran irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́ láti rí i pé ipa ọ̀nà yìí lòdì sóhun tí Ọlọ́run ti fi kọ́ wa, àti pé olúkúlùkù ni “yóò ru ẹrù ti ara rẹ̀.” (Gálátíà 6:5, 7; 1 Tẹsalóníkà 4:9-12) Wọn yóò lo Ìwé Mímọ́ láti fi ṣàlàyé pé Jèhófà fi àwọn nǹkan mìíràn sílẹ̀ fún ẹ̀rí-ọkàn kálukú, fún ìdí yìí, kò yẹ kí ẹnikẹ́ni máa dá àwọn ẹlòmíràn lẹ́jọ́ lórí irú àwọn ọ̀ràn bẹ́ẹ̀. (Mátíù 7:1, 2; Jákọ́bù 4:10-12) Bí a óò bá máa sìn pa pọ̀ ní ìṣọ̀kan, ẹ̀mí ìgbẹ́kẹ̀lé àti ìbọ̀wọ̀fúnni gbọ́dọ̀ wà nínú ìjọ. Nípa pípèsè ìmọ̀ràn tó bá Ìwé Mímọ́ mu nígbà táa bá nílò rẹ̀, “àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ ènìyàn” ń ràn wá lọ́wọ́ láti pa àlàáfíà àti ìṣọ̀kan wa mọ́.—Róòmù 14:19.
Dídáàbòbo Agbo
18, 19. (a) “Àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ ènìyàn” ń dáàbò bò wá lọ́wọ́ àwọn wo? (b) Àwọn àgùntàn nílò ààbò kúrò nínú ewu mìíràn wo, báwo sì ni àwọn alàgbà ṣe máa ń gbégbèésẹ̀ láti dáàbò bo àwọn àgùntàn?
18 Ẹ̀kẹrin, Jèhófà pèsè “àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ ènìyàn” láti dáàbò bò wá kí a má bàa di ẹni tí a ń dà ríborìbo “nípasẹ̀ gbogbo ẹ̀fúùfù ẹ̀kọ́ nípasẹ̀ ìwà àgálámàṣà àwọn ènìyàn, nípasẹ̀ àlùmọ̀kọ́rọ́yí nínú dídọ́gbọ́n hùmọ̀ ìṣìnà.” (Éfésù 4:14) Ọ̀rọ̀ ìpilẹ̀ṣẹ̀ tí a fi tú “ìwà àgálámàṣà” ni a sọ pé ó túmọ̀ sí “ṣíṣèrú nídìí ayò tẹ́tẹ́” tàbí “mímọ òjóró ṣe nídìí ayò tẹ́tẹ́.” Ìyẹn kò ha rán wa létí ọgbọ́n féfé táwọn apẹ̀yìndà fi ń ṣọṣẹ́? Nípa fífi ẹnu dídùn mọ̀ràn-ìn mọran-in gbé ìjiyàn kalẹ̀, wọn ń yí Ìwé Mímọ́ po bí wọ́n ti ń gbìyànjú láti fọgbọ́n tan àwọn Kristẹni tòótọ́ kúrò nínú ìgbàgbọ́ wọn. Àwọn alàgbà ní láti wà lójúfò fún irúfẹ́ “àwọn aninilára ìkookò” bẹ́ẹ̀!—Ìṣe 20:29, 30.
19 Ó tún ṣe pàtàkì pé kí a dáàbò bo àwọn àgùntàn Jèhófà kúrò nínú àwọn ewu mìíràn pẹ̀lú. Dáfídì, olùṣọ́ àgùntàn ìgbàanì fìgboyà dáàbò bo agbo baba rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ àwọn apẹranjẹ. (1 Sámúẹ́lì 17:34-36) Lónìí, pẹ̀lú, àwọn ìgbà kan máa ń wà táwọn Kristẹni olùṣọ́ àgùntàn tó bìkítà ní láti lo ìgboyà kí wọ́n bàa lè dáàbò bo agbo lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ han àwọn àgùntàn Jèhófà léèmọ̀, tàbí tó fẹ́ ni wọ́n lára, pàápàá jù lọ àwọn àgùntàn tó ṣe ẹlẹgẹ́. Àwọn alàgbà yóò tètè yọ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ àmọ̀ọ́mọ̀dá kúrò nínú ìjọ, àwọn tó dìídì ń lo ìwà àgálámàṣà, ẹ̀tàn, àti ìwà àrékérekè kí wọ́n lè ráyè máa hu ìwà ibi wọn nìṣó.b—1 Kọ́ríńtì 5:9-13; fi wé Sáàmù 101:7.
20. Èé ṣe tí ọkàn wa fi balẹ̀ lábẹ́ àbójútó “àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ ènìyàn”?
20 A mà dúpẹ́ o, fún níní “àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ ènìyàn”! Ọkàn wa balẹ̀ lábẹ́ àbójútó onífẹ̀ẹ́ wọn, nítorí pé ọwọ́ jẹ̀lẹ́ńkẹ́ ni wọ́n fi ń tọ́ wa sọ́nà, tìfẹ́tìfẹ́ ni wọ́n ń gbé wa ró, tọkàntara ni wọ́n ń sapá láti pa ìṣọ̀kan wa mọ́, wọ́n sì ń fìgboyà dáàbò bò wá. Àmọ́, ojú wo ló yẹ kí “àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ ènìyàn” máa fi wo ipa tí wọ́n ń kó nínú ìjọ? Báwo sì la ṣe lè fi hàn pé a mọrírì wọn? A óò dáhùn ìbéèrè wọ̀nyí nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Nínú ẹ̀dà Septuagint ti Gíríìkì, ọ̀rọ̀ ìṣe kan náà táa tú sí “tọ́ sọ́nà padà” ló wà nínú Sáàmù 17[16]:5, níbi tí Dáfídì ti gbàdúrà pé kí àwọn ìṣísẹ̀ òun fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin ní àwọn òpó ọ̀nà Jèhófà.
b Fún àpẹẹrẹ, wo “Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé” nínú ìtẹ̀jáde Ile-Iṣọ Naa, ti May 15, 1980, ojú ìwé 31 sí 32, àti “Ẹ Jẹ́ Kí A Kórìíra Ohun Búburú Tẹ̀gàntẹ̀gàn” nínú ìtẹ̀jáde ti January 1, 1997, ojú ìwé 26 sí 29.
Ǹjẹ́ O Rántí?
◻ Àwọn wo ni “àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ ènìyàn,” èé sì ti ṣe tí Ọlọ́run fi wọ́n fún ìjọ nípasẹ̀ Kristi?
◻ Báwo ni àwọn alàgbà ṣe máa ń ṣe ojúṣe wọn láti tọ́ agbo sọ́nà?
◻ Kí làwọn alàgbà lè ṣe láti gbé àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn ró?
◻ Báwo làwọn alàgbà ṣe lè pa ìṣọ̀kan ìjọ mọ́?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Ẹ̀mí ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò ń ran àwọn alàgbà lọ́wọ́ láti fún àwọn oníròbìnújẹ́ ọkàn níṣìírí
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Ìṣọ̀kan láàárín àwọn alàgbà ń gbé ìṣọ̀kan ìjọ lárugẹ