Ẹ Máa Bọlá Fáwọn Ẹlòmíràn
“Nínú bíbu ọlá fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, ẹ mú ipò iwájú.”—RÓÒMÙ 12:10.
1, 2. (a) Kí la gbọ́dọ̀ máa ṣe láti fi hàn pé a ní ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú? (b) Báwo ni Bíbélì ṣe sábà máa ń lo ọ̀rọ̀ náà, “bọlá,” àwọn wo ló sì máa ń rọrùn fún láti bọlá fúnni?
ÀPILẸ̀KỌ táa kà ṣáájú èyí tẹnu mọ́ ìmọ̀ràn inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run náà pé: “Gbogbo yín, ẹ fi ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú di ara yín lámùrè sí ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, nítorí Ọlọ́run kọ ojú ìjà sí àwọn onírera, ṣùgbọ́n ó ń fi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí fún àwọn onírẹ̀lẹ̀.” (1 Pétérù 5:5) Ọ̀nà kan táa lè gbà fi ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú di ara wa lámùrè ni nípa bíbọlá fáwọn ẹlòmíràn.
2 Nínú Bíbélì, a sábà máa ń lo ọ̀rọ̀ náà “ọlá” fún ọ̀wọ̀ àti iyì táa fi hàn sí àwọn ẹlòmíràn, àti báa ṣe gba tiwọn rò. A ń bọlá fáwọn ẹlòmíràn nípa híhùwà rere sí wọn, fífi ọ̀wọ̀ wọn wọ̀ wọ́n, títẹ́tí sílẹ̀ sí èrò wọn, ṣíṣetán láti ṣe ohun tó bọ́gbọ́n mu tí ẹnì kan bá rọ̀ wá pé ká ṣe. Lọ́pọ̀ ìgbà, èyí kò ní ṣòro fún àwọn tó ní ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú. Ṣùgbọ́n, fáwọn onígbèéraga, ṣe ni bíbọlá fúnni lọ́nà tó jẹ́ ojúlówó máa ń ni wọ́n lára kókó, kàkà tí wọn á sì fi bọlá fúnni, ojúure èèyàn ni wọn yóò máa wá, tí wọn a sì máa fẹ́ jàǹfààní lára ẹni nípa lílo ọ̀rọ̀ àpọ́nlé tí kò kọjá orí ahọ́n wọn.
Jèhófà Ń Bọlá fún Ènìyàn
3, 4. Báwo ni Jèhófà ṣe bọlá fún Ábúráhámù, èé sì ti ṣe?
3 Jèhófà alára ló fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ ní ti bíbọlá fúnni. Ó dá òmìnira ìfẹ́ inú mọ́ ènìyàn, kò sì bá wọn lò gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rọ lásán. (1 Pétérù 2:16) Fún àpẹẹrẹ, nígbà tó sọ fún Ábúráhámù pé òun máa pa Sódómù run nítorí ìwà ibi wọn tó ti lékenkà, Ábúráhámù béèrè pé: “Ìwọ, ní ti tòótọ́, yóò ha gbá olódodo lọ pẹ̀lú àwọn ẹni burúkú bí? Ká sọ pé àádọ́ta olódodo wà ní àárín ìlú ńlá náà. Nígbà náà, ìwọ yóò ha gbá wọn lọ, tí o kò sì ní dárí ji ibẹ̀ ní tìtorí àádọ́ta olódodo tí wọ́n wà nínú rẹ̀ bí?” Jèhófà fèsì pé, báa bá lè rí àádọ́ta olódodo, tìtorí tiwọn, òun yóò dá ìlú náà sí. Ni Ábúráhámù bá tún ń fi tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ bá ìjírẹ̀ẹ́bẹ̀ rẹ̀ lọ. Báa bá rí èèyàn márùndínláàádọ́ta ńkọ́? Báa bá rí ogójì ńkọ́? Ọgbọ̀n ńkọ́? Ogún ńkọ́? Bó bá jẹ́ mẹ́wàá la rí ńkọ́? Jèhófà mú un dá Ábúráhámù lójú pé òun kò ní pa Sódómù run bí ó bá lè rí ènìyàn mẹ́wàá péré níbẹ̀, tó jẹ́ olódodo.—Jẹ́nẹ́sísì 18:20-33.
4 Jèhófà kúkú mọ̀ pé kò sí èèyàn mẹ́wàá tó jẹ́ olódodo ní Sódómù, síbẹ̀ ó bọlá fún Ábúráhámù nípa títẹ́tí sí èrò rẹ̀, tó sì fi ọ̀wọ̀ tirẹ̀ wọ̀ ọ́. Èé ṣe? Nítorí pé Ábúráhámù “ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà; òun sì bẹ̀rẹ̀ sí kà á sí òdodo fún un.” A pe Ábúráhámù ní “ọ̀rẹ́ Jèhófà.” (Jẹ́nẹ́sísì 15:6; Jákọ́bù 2:23) Ní àfikún sí i, Jèhófà rí i pé Ábúráhámù máa ń bọlá fáwọn ẹlòmíràn. Nígbà tí aáwọ̀ kan bẹ́ sílẹ̀ lórí ọ̀ràn ìpínlẹ̀ láàárín àwọn darandaran rẹ̀ àti ti Lọ́ọ̀tì, tó jẹ́ ọmọ ẹ̀gbọ́n rẹ̀, Ábúráhámù bọlá fún Lọ́ọ̀tì nípa sísọ fún un pé kó kọ́kọ́ yan ibi tó bá fẹ́. Lọ́ọ̀tì yan ilẹ̀ tó rò pé ó dára jù lọ, ní Ábúráhámù bá ṣí lọ sí ibòmíràn.—Jẹ́nẹ́sísì 13:5-11.
5. Báwo ni Jèhófà ṣe bọlá fún Lọ́ọ̀tì?
5 Bákan náà, Jèhófà bọlá fún Lọ́ọ̀tì olódodo. Kó tó di pé a pa Sódómù run, ó sọ fún Lọ́ọ̀tì láti sá lọ sí àgbègbè olókè. Ṣùgbọ́n, Lọ́ọ̀tì sọ pé òun kò fẹ́ lọ síbẹ̀; ó yàn láti wà ní Sóárì tó wà nítòsí, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìlú náà wà ní àgbègbè tí a fẹ́ pa run. Jèhófà wí fún Lọ́ọ̀tì pé: “Kíyè sí i, mo fi ìgbatẹnirò hàn sí ọ dé ìwọ̀n yìí pẹ̀lú, ní ti pé èmi kò ní bi ìlú ńlá náà tí ìwọ ti sọ ṣubú.” Jèhófà bọlá fún Lọ́ọ̀tì olóòótọ́ nípa ṣíṣe ohun tí Lọ́ọ̀tì ní kó ṣe fóun.—Jẹ́nẹ́sísì 19:15-22; 2 Pétérù 2:6-9.
6. Báwo ni Jèhófà ṣe bọlá fún Mósè?
6 Nígbà tí Jèhófà rán Mósè padà sí Íjíbítì láti ṣáájú àwọn ènìyàn Rẹ̀ kúrò ní oko ẹrú àti láti bá Fáráò sọ̀rọ̀ nípa jíjẹ́ kí àwọn ènìyàn Rẹ̀ lọ, Mósè fèsì pé: “Dákun, Jèhófà, ṣùgbọ́n èmi kì í ṣe ẹni tí ń sọ̀rọ̀ lọ́nà tí ó já geere.” Jèhófà fọkàn Mósè balẹ̀ ní sísọ pé: “Èmi alára yóò . . . wà pẹ̀lú ẹnu rẹ, èmi yóò sì kọ́ ọ ní ohun tí ó yẹ kí o sọ.” Ṣùgbọ́n Mósè ṣì ń lọ́ra. Ni Jèhófà bá tún fi Mósè lọ́kàn balẹ̀, ó sì ṣètò láti rán Áárónì, arákùnrin rẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀, kó lè máa ṣe agbọ̀rọ̀sọ fún un.—Ẹ́kísódù 4:10-16.
7. Èé ṣe ti Jèhófà fi ṣe tán láti bọlá fún àwọn ẹlòmíràn?
7 Nínú gbogbo ipò wọ̀nyẹn, Jèhófà fi hàn pé òun múra tán láti bọlá fáwọn ẹlòmíràn, pàápàá jù lọ àwọn tí ń sìn ín. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ohun tí wọ́n béèrè fún lè yàtọ̀ sí ohun tí Jèhófà ní lọ́kàn lákọ̀ọ́kọ́, ó ń gba ohun tí wọ́n béèrè fún rò, lẹ́yìn náà yóò fún wọn láǹfààní náà, níwọ̀n ìgbà tí kò bá ti pa ète rẹ̀ lára.
Jésù Bọlá Fáwọn Ẹlòmíràn
8. Báwo ni Jésù ṣe bọlá fún obìnrin kan tí àìsàn ń ṣe gidigidi?
8 Jésù fara wé Jèhófà nínú bíbọlá fáwọn ẹlòmíràn. Nígbà kan tó wà láàárín èrò, obìnrin kan wà níbẹ̀ tí ìsun ẹ̀jẹ̀ ti ń yọ lẹ́nu fún ọdún méjìlá. Àwọn oníṣègùn ti gbìyànjú títí, àmọ́ pàbó ni ìsapá wọn já sí. Lábẹ́ Òfin Mósè, aláìmọ́ lóbìnrin yìí gẹ́gẹ́ bí òfin náà ti sọ, kò sì yẹ kó wà láàárín èrò. Lóbìnrin ọ̀hún bá bọ́ sẹ́yìn Jésù, ló bá fọwọ́ kan ẹ̀wù rẹ̀, lara rẹ̀ bá yá. Jésù kò wá torí bẹ́ẹ̀ rin kinkin mọ́ Òfin, kó wá bẹ̀rẹ̀ sí láálí rẹ̀ nítorí ohun tó ṣe yẹn. Kàkà bẹ́ẹ̀, nítorí tó mọ ipò tí obìnrin náà wà, ó bọlá fún un, ó sọ pé: “Ọmọbìnrin, ìgbàgbọ́ rẹ ti mú ọ lára dá. Máa lọ ní àlàáfíà, kí o sì ní ìlera kúrò lọ́wọ́ àìsàn burúkú tí ń ṣe ọ́.”—Máàkù 5:25-34; Léfítíkù 15:25-27.
9. Báwo ni Jésù ṣe bọlá fún Kèfèrí?
9 Ní àkókò mìíràn, obìnrin kan tó jẹ́ ará Fòníṣíà sọ fún Jésù pé: “Ṣàánú fún mi, Olúwa, Ọmọkùnrin Dáfídì. Ẹ̀mí èṣù gbé ọmọbìnrin mi dè burúkú-burúkú.” Nítorí tí Jésù mọ̀ pé orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì la rán òun sí, kì í ṣe àwọn Kèfèrí, ó wí pé: “Kò tọ́ kí a mú búrẹ́dì àwọn ọmọ [ìyẹn ni Ísírẹ́lì], kí a sì sọ ọ́ sí àwọn ajá kéékèèké [ìyẹn àwọn Kèfèrí].” Ní obìnrin náà bá fèsì pé: “Ṣùgbọ́n àwọn ajá kéékèèké ní ti gidi máa ń jẹ nínú èérún tí ń jábọ́ láti orí tábìlì àwọn ọ̀gá wọn.” Jésù wá fún un lésì padà pé: “Ìwọ obìnrin yìí, títóbi ni ìgbàgbọ́ rẹ; kí ó ṣẹlẹ̀ sí ọ gẹ́gẹ́ bí o ti fẹ́.” A sì mú ọmọ rẹ̀ lára dá. Jésù bọlá fún Kèfèrí yìí nítorí ìgbàgbọ́ rẹ̀. Kódà bó ṣe lo “àwọn ajá kéékèèké,” dípò lílo àwọn ajá dìgbòlugi, mú kí ọ̀rọ̀ náà tuni lára, ó sì fi ìyọ́nú hàn.—Mátíù 15:21-28.
10. Ẹ̀kọ́ ńlá wo ni Jésù kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, èé sì ti ṣe tí wọ́n fi nílò rẹ̀?
10 Jésù kó dẹ́kun kíkọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ nípa ìjẹ́pàtàkì jíjẹ́ onírẹ̀lẹ̀ èrò inú àti ẹni tí ń bọlá fáwọn ẹlòmíràn, nítorí pé wọ́n níṣòro ẹ̀mí tèmi-làkọ́kọ́. Ìgbà kan wà tí wọ́n ń bá ara wọn jiyàn, tí Jésù wá béèrè pé: “Kí ni ẹ ń jiyàn lé lórí lójú ọ̀nà?” Ni gbogbo wọ́n bá dákẹ́, nítorí “wọ́n ti jiyàn láàárín ara wọn lórí ẹni tí ó tóbi jù.” (Máàkù 9:33, 34) Àní ní alẹ́ tó ṣáájú ìgbà tí Jésù kú pàápàá, “awuyewuye gbígbónájanjan kan tún dìde láàárín wọn lórí èwo nínú wọn ni ó dà bí ẹni tí ó tóbi jù lọ.” (Lúùkù 22:24) Nítorí náà, nígbà oúnjẹ Ìrékọjá, Jésù “bu omi sínú bàsíà kan, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí wẹ ẹsẹ̀ àwọn ọmọ ẹ̀yìn.” Ẹ̀kọ́ ńlá mà lèyí jẹ́ o! Ọmọ Ọlọ́run mà ni Jésù, ni gbogbo àgbáyé, táa bá ti mú Jèhófà tán, òun ló kàn. Síbẹ̀, ó kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ní ẹ̀kọ́ ńlá nípa wíwẹ ẹsẹ̀ wọn. Ó wí pé: “Nítorí mo fi àwòṣe lélẹ̀ fún yín, pé, gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe fún yín, ni kí ẹ máa ṣe pẹ̀lú.”—Jòhánù 13:5-15.
Pọ́ọ̀lù Bọlá Fúnni
11, 12. Lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù di Kristẹni, kí ló kọ́, báwo ló sì ṣe lo ẹ̀kọ́ yìí nínú ọ̀ràn òun àti Fílémónì?
11 Gẹ́gẹ́ bí aláfarawé Kristi, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù bọlá fáwọn ẹlòmíràn. (1 Kọ́ríńtì 11:1) Ó wí pé: “Bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe pé a ti ń wá ògo láti ọ̀dọ̀ ènìyàn . . . Kàkà bẹ́ẹ̀, àwa di ẹni pẹ̀lẹ́ láàárín yín, bí ìgbà tí abiyamọ ń ṣìkẹ́ àwọn ọmọ tirẹ̀.” (1 Tẹsalóníkà 2:6, 7) Ṣe ni abiyamọ máa ń kẹ́ àwọn ọmọ rẹ̀ kéékèèké. Lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù di Kristẹni, ó kọ́ báa ṣe lè ní ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú, ó si bọlá fáwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, nípa fífi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ bá wọn lò. Ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀, ó fọ̀wọ̀ tiwọn wọ̀ wọ́n, gẹ́gẹ́ bó ti hàn nínú ìṣẹ̀lẹ̀ kan tó wáyé nígbà tó ń ṣẹ̀wọ̀n ní Róòmù.
12 Ẹrú kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ónẹ́símù, tó ti sá kúrò lọ́dọ̀ ọ̀gá rẹ̀, fetí sí ẹ̀kọ́ Pọ́ọ̀lù. Ó di Kristẹni, ó sì tún di ọ̀rẹ́ Pọ́ọ̀lù. Fílémónì ni olówó ẹrú yìí, Kristẹni sì lòun náà, Éṣíà Kékeré ló ń gbé. Nínú lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ sí Fílémónì, ó sọ bí Ónẹ́símù ti wúlò fún un tó sínú rẹ̀, ó sọ pé: “Èmi ì bá fẹ́ láti dá a dúró fún ara mi.” Síbẹ̀, Pọ́ọ̀lù jẹ́ kí Ónẹ́símù padà sọ́dọ̀ Fílémónì, nítorí tí ó kọ̀wé pé: “Láìsí ìfohùnṣọ̀kan rẹ, èmi kò fẹ́ láti ṣe ohunkóhun, kí ìṣe rẹ dídára má bàa jẹ́ bí ẹni pé lábẹ́ àfipáṣe, bí kò ṣe láti inú ìfẹ́ àtinúwá ti ìwọ fúnra rẹ.” Pọ́ọ̀lù kò sọ pé nítorí tóun ti jẹ́ àpọ́sítélì, òun lè lo ọlá yẹn lórí ọ̀ràn yìí, ṣùgbọ́n, ó bọlá fún Fílémónì nípa pé kò sọ pé kí Fílémónì jẹ́ kí Ónẹ́símù kúkú dúró sọ́dọ̀ òun ní Róòmù. Ní àfikún sí i, Pọ́ọ̀lù rọ Fílémónì láti bọlá fún Ónẹ́símù, kó mú un “gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó ju ẹrú lọ, gẹ́gẹ́ bí arákùnrin olùfẹ́.”—Fílémónì 13-16.
Bíbọlá Fúnni ní Ọjọ́ Tiwa Lónìí
13. Kí ni Róòmù 12:10 sọ pé ká ṣe?
13 Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbani nímọ̀ràn pé: “Nínú bíbu ọlá fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, ẹ mú ipò iwájú.” (Róòmù 12:10) Èyí túmọ̀ sí pé kò yẹ ká máa retí káwọn ẹlòmín-ìn kọ́kọ́ bọlá fún wa, ṣùgbọ́n àwa gan-an ló yẹ ká kọ́kọ́ gbé ìgbésẹ̀ yẹn. “Kí olúkúlùkù má ṣe máa wá àǹfààní ti ara rẹ̀, bí kò ṣe ti ẹnì kejì.” (1 Kọ́ríńtì 10:24; 1 Pétérù 3:8, 9) Nítorí èyí, àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà máa ń wá ọ̀nà àtibọlá fáwọn tó wà nínú agbo ìdílé wọn, àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wọn nínú ìjọ, àní àwọn tí kò sí nínú ìjọ pàápàá.
14. Báwo ni ọkọ àti aya ṣe lè máa bọlá fúnra wọn?
14 Bíbélì sọ pé: “Orí olúkúlùkù ọkùnrin ni Kristi; ẹ̀wẹ̀, orí obìnrin ni ọkùnrin.” (1 Kọ́ríńtì 11:3) Jèhófà pa á láṣẹ fún ọkùnrin láti fọwọ́ tí Kristi fi mú ìjọ mú aya rẹ̀. Nínú 1 Pétérù 3:7, a pàṣẹ fún ọkọ láti fún aya rẹ̀ ní “ọlá . . . gẹ́gẹ́ bí fún ohun èlò tí ó túbọ̀ jẹ́ aláìlera, ọ̀kan tí ó jẹ́ abo.” Ó lè ṣe èyí nípa fífihàn pé òun múra tán lóòótọ́ láti tẹ́tí sílẹ̀ sí aya rẹ̀ àti nípa gbígba àwọn àbá tó bá mú wá rò. (Jẹ́nẹ́sísì 21:12) Ó lè gbà láti ṣe ohun tí aya rẹ̀ bá ń fẹ́ níwọ̀n ìgbà tí kò bá ti ta ko ìlànà Bíbélì èyíkéyìí, yóò máa ràn án lọ́wọ́, yóò sì máa fi inú rere bá a lò. Ẹ̀wẹ̀, “kí aya ní ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún ọkọ rẹ̀.” (Éfésù 5:33) Yóò máa tẹ́tí sí i, kò ní máa fẹ́ kó jẹ́ pé gbogbo ohun tí òun bá ṣáà ti fẹ́ ló gbọ́dọ̀ di ṣíṣe, kò ní máa tẹ́ńbẹ́lú rẹ̀ tàbí kò máa fẹjọ́ sú u. Yóò fi ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú hàn nípa gbígbìyànjú láti má ṣe jọba lé ọkọ rẹ̀ lórí, kódà bó bá tiẹ̀ ní àwọn nǹkan kan tí ọkọ rẹ̀ kò ní.
15. Ìgbatẹnirò wo la fi hàn sáwọn àgbàlagbà, báwo ló sì ṣe yẹ káwọn náà máa ṣe?
15 Nínú ìjọ Kristẹni, àwọn kan wà tó jẹ́ pé ní pàtàkì wọ́n yẹ lẹ́ni àá bọlá fún, irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ni àwọn àgbàlagbà. “Kí o dìde dúró níwájú orí ewú, kí o sì fi ìgbatẹnirò hàn fún arúgbó [yálà ọkùnrin tàbí obìnrin].” (Léfítíkù 19:32) Èyí ṣe pàtàkì, pàápàá jù lọ nígbà tọ́ràn bá kan àwọn tó ti fi òótọ́-ọkàn sin Jèhófà fún ọ̀pọ̀ ọdún nítorí “orí ewú jẹ́ adé ẹwà nígbà tí a bá rí i ní ọ̀nà òdodo.” (Òwe 16:31) Ó yẹ kí àwọn alábòójútó fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ nípa bíbuyì tó yẹ fún àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wọn tí wọ́n dàgbà jù wọ́n lọ. Àmọ́ ṣá o, ó yẹ kí àwọn arúgbó pẹ̀lú máa fi ọ̀wọ̀ ti àwọn ọmọdé wọ̀ wọ́n, pàápàá jù lọ àwọn tí wọ́n ní ẹrù iṣẹ́ ṣíṣe àbójútó agbo.—1 Pétérù 5:2, 3.
16. Báwo ni àwọn òbí àti àwọn ọmọ ṣe lè máa bọlá fún ara wọn?
16 Ó yẹ kí àwọn èwe máa bọlá fún àwọn òbí wọn: “Ẹ̀yin ọmọ, ẹ jẹ́ onígbọràn sí àwọn òbí yín ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Olúwa, nítorí èyí jẹ́ òdodo: ‘Bọlá fún baba rẹ àti ìyá rẹ’; èyí tí í ṣe àṣẹ kìíní pẹ̀lú ìlérí: ‘Kí nǹkan lè máa lọ dáadáa fún ọ, kí ìwọ sì lè wà fún àkókò gígùn lórí ilẹ̀ ayé.’” Ẹ̀wẹ̀, àwọn òbí ní láti máa bọlá fún àwọn ìpẹ́ẹ̀rẹ̀ wọn, nítorí a sọ fún wọn pé ‘kí wọ́n má ṣe sún àwọn ọmọ wọn bínú, ṣùgbọ́n kí wọ́n máa bá a lọ ní títọ́ wọn dàgbà nínú ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà.’—Éfésù 6:1-4; Ẹ́kísódù 20:12.
17. Àwọn wo ló yẹ ká máa fún ní “ọlá ìlọ́po méjì”?
17 Àwọn tó tún yẹ ká bọlá fún ni àwọn tí ń ṣiṣẹ́ kára nípa sísin ìjọ: “Kí a ka àwọn àgbà ọkùnrin tí ń ṣe àbójútó lọ́nà tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ yẹ fún ọlá ìlọ́po méjì, ní pàtàkì, àwọn tí ń ṣiṣẹ́ kára nínú ọ̀rọ̀ sísọ àti kíkọ́ni.” (1 Tímótì 5:17) Ọ̀nà kan tí a lè gbà bọlá fún wọn ni nípa ṣíṣe ohun tí Hébérù 13:17 sọ pé: “Ẹ jẹ́ onígbọràn sí àwọn tí ń mú ipò iwájú láàárín yín, kí ẹ sì jẹ́ ẹni tí ń tẹrí ba.”
18. Kí ló yẹ ká ṣe sáwọn tí kò sí nínú ìjọ?
18 Ǹjẹ́ ó yẹ ká tún máa bọlá fáwọn tí kò sí nínú ìjọ? Bẹ́ẹ̀ ni. Fún àpẹẹrẹ, a fún wa nítọ̀ọ́ni pé: “Kí olúkúlùkù ọkàn wà lábẹ́ àwọn aláṣẹ onípò gíga.” (Róòmù 13:1) Àwọn wọ̀nyí ni àwọn alákòóso ayé tí Jèhófà yọ̀ǹda fún láti lo ọlá àṣẹ títí tí yóò fi fi Ìjọba rẹ̀ rọ́pò wọn. (Dáníẹ́lì 2:44) Nítorí náà, a óò máa “fi ẹ̀tọ́ gbogbo ènìyàn fún wọn, ẹni tí ó béèrè fún owó orí, ẹ fún un ní owó orí; ẹni tí ó béèrè fún owó òde, ẹ fún un ní owó òde; ẹni tí ó béèrè fún ìbẹ̀rù, ẹ fún un ní irúfẹ́ ìbẹ̀rù bẹ́ẹ̀; ẹni tí ó béèrè fún ọlá, ẹ fún un ní irúfẹ́ ọlá bẹ́ẹ̀.” (Róòmù 13:7) A ní láti máa “bọlá fún onírúurú ènìyàn gbogbo [ì báà ṣe ọkùnrin, ì báà ṣe obìnrin].”—1 Pétérù 2:17.
19. Báwo la ṣe lè máa “ṣe ohun rere” sí àwọn ẹlòmíràn, kí a sì bọlá fún wọn?
19 Bó tilẹ̀ jẹ́ òótọ́ pé a ní láti bọlá fún àwọn tí kò sí nínú ìjọ, ẹ ṣàkíyèsí ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tẹnu mọ́ pé: “Níwọ̀n ìgbà tí a bá ní àkókò tí ó wọ̀ fún un, ẹ jẹ́ kí a máa ṣe ohun rere sí gbogbo ènìyàn, ṣùgbọ́n ní pàtàkì sí àwọn tí ó bá wa tan nínú ìgbàgbọ́.” (Gálátíà 6:10) Àmọ́ ṣá o, ọ̀nà dídára jù lọ táa lè gbà “ṣe ohun rere” fún àwọn mìíràn ni láti lè mọ àìní wọn nípa tẹ̀mí, kí a sì kúnjú rẹ̀. (Mátíù 5:3) A lè ṣe èyí nípa kíkọbi ara sí ìṣílétí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù náà pé: “Sa gbogbo ipá rẹ láti fi ara rẹ hàn fún Ọlọ́run ní ẹni tí a tẹ́wọ́ gbà, aṣiṣẹ́ tí kò ní ohun kankan láti tì í lójú, tí ń fi ọwọ́ títọ̀nà mú ọ̀rọ̀ òtítọ́.” Nígbà táa bá fọgbọ́n lo gbogbo àǹfààní táa bá ní láti jẹ́rìí fúnni, ‘táa ṣàṣeparí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa,’ kì í ṣe pé à ń ṣe ohun rere sí àwọn ẹlòmíràn nìkan ni, ṣùgbọ́n a tún ń bọlá fún wọn.—2 Tímótì 2:15; 4:5.
Bíbọlá fún Jèhófà
20. Kí ló ṣẹlẹ̀ sí Fáráò àti àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀, èé sì ti ṣe?
20 Jèhófà ń bọlá fún àwọn ohun tó dá. Nígbà náà, ó bọ́gbọ́n mu pé kí àwa pẹ̀lú bọlá fún un. (Òwe 3:9; Ìṣípayá 4:11) Ọ̀rọ̀ Jèhófà tún sọ pé: “Àwọn tí ń bọlá fún mi ni èmi yóò bọlá fún, àwọn tí ó sì ń tẹ́ńbẹ́lú mi yóò jẹ́ aláìjámọ́ pàtàkì.” (1 Sámúẹ́lì 2:30) Nígbà tí a sọ fún Fáráò ní Íjíbítì pé, kó jẹ́ kí àwọn ènìyàn Ọlọ́run lọ, ẹ̀mí ìrera ló fi fèsì pé: “Ta ni Jèhófà, tí èmi yóò fi ṣègbọràn sí ohùn rẹ̀?” (Ẹ́kísódù 5:2) Nígbà tí Fáráò rán àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogún rẹ̀ lọ láti pa àwọn ọmọ Ísírẹ́lì run, Jèhófà mú kí omi Òkun Pupa pín sí méjì fún Ísírẹ́lì. Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn ará Íjíbítì gbá tọ̀ wọ́n, Jèhófà mú kí omi náà panu pọ̀. “Àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin Fáráò àti àwọn ẹgbẹ́ ológun rẹ̀ ni [Jèhófà] sọ sínú òkun.” (Ẹ́kísódù 14:26-28; 15:4) Nítorí náà, fífi tí Fáráò fàáké kọ́rí pé òun kò ní bọlá fún Jèhófà, ìjàǹbá ló yọrí sí fún un níkẹyìn.—Sáàmù 136:15.
21. Èé ṣe tí Jèhófà fi kọjúùjà sí Bẹliṣásárì, kí ló sì yọrí sí?
21 Bẹliṣásárì Ọba Bábílónì pẹ̀lú kọ̀ láti bọlá fún Jèhófà. Nígbà àsè ọlọ́tí àmupara tó ṣe, ó fi Jèhófà ṣe yẹ̀yẹ́ nípa fífi àwọn ohun èlò wúrà àti fàdákà tí wọ́n kó wá láti tẹ́ńpìlì Jerúsálẹ́mù mu wáìnì. Bó sì ṣe ń ṣe èyí lọ́wọ́, bẹ́ẹ̀ ló ń fògo fún àwọn ọlọ́run òrìṣà rẹ̀. Àmọ́ Dáníẹ́lì, ìránṣẹ́ Jèhófà sọ fún un pé: “Ìwọ kò rẹ ọkàn-àyà rẹ̀ sílẹ̀ . . . Ṣùgbọ́n o gbé ara rẹ ga sí Olúwa ọ̀run.” Lóru ọjọ́ yẹn gan-an la pa Bẹliṣásárì, tí a sì gba ìjọba rẹ̀ lọ́wọ́ rẹ̀.—Dáníẹ́lì 5:22-31.
22. (a) Èé ṣe tí ìbínú Jèhófà fi dé sórí àwọn aṣáájú Ísírẹ́lì àti àwọn ènìyàn wọn? (b) Àwọn wo ni Jèhófà ṣojúure sí, kí ló sì yọrí sí?
22 Ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa yìí, Hẹ́rọ́dù Ọba ń báwọn èèyàn sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, ni wọ́n bá kígbe pé: “Ohùn ọlọ́run kan ni, kì í sì í ṣe ti ènìyàn!” Ọba yẹ̀yẹ́ yìí kò tètè sọ pé, bẹ́ẹ̀ kọ́ o, ṣùgbọ́n ògo yẹn wù ú. Nípa bẹ́ẹ̀, “áńgẹ́lì Jèhófà kọlù ú, nítorí pé kò fi ògo fún Ọlọ́run.” (Ìṣe 12:21-23) Hẹ́rọ́dù bọlá fún ara rẹ̀, kò bọlá fún Jèhófà, a sì pa á. Àwọn aṣáájú ìsìn ayé ìgbà yẹn pẹ̀lú tàbùkù sí Ọlọ́run nípa gbígbìmọ̀ pọ̀ pa Jésù, Ọmọ rẹ̀. Àwọn alákòóso kan mọ̀ pé òtítọ́ ni Jésù fi ń kọ́ni ṣùgbọ́n wọn kò lè tẹ̀ lé e, “nítorí pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ ògo ènìyàn ju ògo Ọlọ́run.” (Jòhánù 11:47-53; 12:42, 43) Orílẹ̀-èdè náà lódindi kò bọlá fún Jèhófà, bẹ́ẹ̀ sì ni wọn kò bọlá fún Jésù, Aṣojú rẹ̀ tó yàn. Ìyọrísí rẹ̀ ni pé, Jèhófà pẹ̀lú kò bọlá fún wọn mọ́, ló bá pa wọ́n tì, a sì pa tẹ́ńpìlì wọn run. Ṣùgbọ́n ó pa àwọn tí wọ́n bọlá fún òun àti Ọmọ rẹ̀ mọ́.—Mátíù 23:38; Lúùkù 21:20-22.
23. Kí la gbọ́dọ̀ ṣe táa bá fẹ́ gbé nínú ayé tuntun Ọlọ́run? (Sáàmù 37:9-11; Mátíù 5:5)
23 Gbogbo àwọn tí wọ́n bá fẹ́ gbé nínú ayé tuntun Ọlọ́run lẹ́yìn tí a bá ti pa ètò àwọn nǹkan ti ìsinsìnyí run gbọ́dọ̀ bọlá fún Ọlọ́run àti Jésù Kristi, Ọmọ rẹ̀, kí wọ́n sì ṣègbọràn sí wọn. (Jòhánù 5:22, 23; Fílípì 2:9-11) Àwọn tí kò bá fi irú ọlá bẹ́ẹ̀ hàn ni “a óò ké . . . kúrò lórí ilẹ̀ ayé gan-an.” Ní òdìkejì ẹ̀wẹ̀, àwọn adúróṣánṣán, tí wọ́n bọlá fún Ọlọ́run àti Kristi, tí wọ́n sì ṣègbọràn sí wọn “ni àwọn tí yóò máa gbé ilẹ̀ ayé.”—Òwe 2:21, 22.
Àtúnyẹ̀wò
◻ Kí ló túmọ̀ sí láti bọlá fún àwọn ẹlòmíràn, báwo sì ni Jèhófà ṣe ń ṣe èyí?
◻ Báwo ni Jésù àti Pọ́ọ̀lù ṣe bọlá fún àwọn ẹlòmíràn?
◻ Àwọn wo ló yẹ ká bọlá fún ní ọjọ́ wa?
◻ Èé ṣe táa fi gbọ́dọ̀ bọlá fún Jèhófà àti Jésù?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Jèhófà bọlá fún Ábúráhámù nípa gbígba ẹ̀bẹ̀ rẹ̀ rò
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Nínú ìgbéyàwó aláṣeyọrí, tọkọtaya máa ń bọlá fúnra wọn