Èé Ṣe Tí Àkókò Fi Kéré Tó Bẹ́ẹ̀?
ÀKÓKÒ. Ó lè má rọrùn fún wa láti fún ọ̀rọ̀ yìí nítumọ̀ tó ṣe rẹ́gí, ṣùgbọ́n, ohun kan táa mọ̀ ni pé, ó jọ pé kò sígbà kan tí àkókò tí a ní máa ń tó. A sì tún mọ̀ pé ká tó ṣẹ́jú pẹ́, àkókò ti lọ. Lóòótọ́, a sábà máa ń fi tẹ̀dùntẹ̀dùn sọ pé, “A ò rọ́jọ́ mú so lókùn.”
Síbẹ̀síbẹ̀, ó ṣe kedere pé, akéwì ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì nì, Austin Dobson, kò ṣì sọ nígbà tó sọ ọ̀rọ̀ yìí lọ́dún 1877 pé: “Àkókò ń lọ, àbí kí lo wí? Áà, rárá o! Ó mà ṣe o, àkókò ò rebì kan, àwa èèyàn là ń lọ.” Ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọgọ́rin ọdún báyìí tí Dobson ti kú, àmọ́, láti ìgbà tó ti kú lọ́dún 1921 yẹn; àkókò ò rebì kankan o.
Àkókò Wà Rẹpẹtẹ
Nígbà tí Bíbélì ń sọ̀rọ̀ nípa Ẹlẹ́dàá aráyé, ó sọ fún wa pé: “Àní kí a tó bí àwọn òkè ńlá, tàbí kí o tó bẹ̀rẹ̀ sí bí ilẹ̀ ayé àti ilẹ̀ eléso gẹ́gẹ́ bí ẹni pé pẹ̀lú ìrora ìrọbí, àní láti àkókò tí ó lọ kánrin títí dé àkókò tí ó lọ kánrin, ìwọ ni Ọlọ́run.” (Sáàmù 90:2) Tàbí bí The New Jerusalem Bible ṣe túmọ̀ rẹ̀, “láti ayérayé títí dé ayérayé ìwọ ni Ọlọ́run.” Nítorí náà, níwọ̀n ìgbà tí Ọlọ́run bá ṣì wà, àkókò yóò máa wà—yóò máa wà títí láé!
Ní ìyàtọ̀ pátápátá sí ti Ọlọ́run, ẹni tó jẹ́ pé títí ayérayé ni àkókò tirẹ̀, a kà nípa àwa èèyàn pé: “Nítorí pé gbogbo ọjọ́ wa ti ń lọ sí òpin wọn nínú ìbínú kíkan rẹ; àwa ti parí àwọn ọdún wa gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ wúyẹ́wúyẹ́. Nínú ara wọn, ọjọ́ àwọn ọdún wa jẹ́ àádọ́rin ọdún; bí wọ́n bá sì jẹ́ ọgọ́rin ọdún nítorí àkànṣe agbára ńlá, síbẹ̀, wíwà nìṣó wọn jẹ́ lórí ìdààmú àti àwọn ohun aṣenilọ́ṣẹ́; nítorí pé kíákíá ni yóò kọjá lọ, àwa yóò sì fò lọ.”—Sáàmù 90:9, 10.
Kí ló wá fà á tí ìwàláàyè fi kúrú tó bẹ́ẹ̀ lónìí, níwọ̀n ìgbà tí Bíbélì fi kọ́ni kedere pé ète Ọlọ́run fún ènìyàn ni pé, kí ó wà láàyè títí láé? (Jẹ́nẹ́sísì 1:27, 28; Sáàmù 37:29) Dípò tí ìwàláàyè ènìyàn yóò fi jẹ́ èyí tí kò lópin gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti fẹ́ kó rí, èé ṣe tó fi wá jẹ́ pé ní ìpíndọ́gba, ẹni tó bá dàgbà jù lọ, ló ń lo ọ̀kẹ́ kan ààbọ̀ ọjọ́ [30,000] lókè eèpẹ̀? Èé ṣe tí àkókò tí èèyàn ní fi kéré tó bẹ́ẹ̀? Ta ló mú ipò ìbànújẹ́ yìí wá, kí ló sì fà á? Bíbélì pèsè ìdáhùn tó ṣe kedere, tó sì tẹ́ni lọ́rùn.a
Àkókò Túbọ̀ Ń Kéré Sí I
Àwọn àgbàlagbà yóò jẹ́rìí sí i pé, ní àwọn ẹ̀wádún àìpẹ́ yìí, ìgbésí ayé sáré-n-bájà làwọn èèyàn ń gbé. Akọ̀ròyìn kan, Ọ̀mọ̀wé Sybille Fritsch, sọ pé, ní igba ọdún [200] tó ti kọjá, iye wákàtí táa fi ń ṣiṣẹ́ láàárín ọ̀sẹ̀ tí lọ sílẹ̀ láti orí ọgọ́rin sí wákàtí méjìdínlógójì, “síbẹ̀ àròyé wa kò dín kù.” Obìnrin náà jẹ́ kó túbọ̀ yéni pé nǹkan táa sábà ń gbọ́ ni pé: “Kò sáyè; àkókò wọ́n jowó lọ; a ń wá àkókò bí ìgbà tí ẹni tí àárẹ̀ mú bá ń wá èémí tí yóò mí; a ń gbé ìgbésí ayé kòó-kòó jàn-án-jàn-án.”
Àwọn ohun táwọn èèyàn ṣẹ̀ṣẹ̀ hùmọ̀ ti ṣí ọ̀pọ̀ àǹfààní sílẹ̀, èyí táwọn ará ọjọ́un kò tiẹ̀ lálàá rẹ̀ rárá. Ṣùgbọ́n bí àǹfààní àtilọ́wọ́ nínú ọ̀pọ̀ ìgbòkègbodò ti ń pọ̀ sí i, bẹ́ẹ̀ náà ni ìjákulẹ̀ ń pọ̀ sí i nítorí àìsí àkókò tó tó láti ṣe wọ́n. Lóde ìwòyí, ní ọ̀pọ̀ ibi nínú ayé, àkókò àwọn ènìyàn há débi pé, aago ni wọ́n ń bá ṣiṣẹ́. Aago méje òwúrọ̀ ni Dádì gbọ́dọ̀ lọ síbi iṣẹ́, Mọ́mì ti gbọ́dọ̀ mú àwọn ọmọ dé iléèwé láago mẹ́jọ ààbọ̀ àárọ̀, Dókítà ní kí Baba Àgbà wá láago mẹ́wàá ku ogun ìṣẹ́jú, gbogbo wa sí gbọ́dọ̀ múra sílẹ̀ fún ìpàdé pàtàkì kan láago méje ààbọ̀ alẹ́. Níbi táa bá ti ń sáré àtilè mú àdéhùn kan ṣẹ, agbára káká làyè fi ń wà fún sísinmi. Bẹ́ẹ̀ la ò sì yéé ṣàròyé nípa ságbàsúlà ojoojúmọ́, àti nípa kòó-kòó jàn-án-jàn-án tí à ń bá kiri.
Ọ̀ràn Àkókò Tó Kéré Kì Í Ṣe Ìṣòro Àwa Nìkan
Sátánì Èṣù, Elénìní Ọlọ́run, ẹni tó jẹ́ pé ètekéte rẹ̀ ló sún aráyé sínú ìwàláàyè táa gé kúrú, ti wá ń jẹ̀rán ìwà ibi tó fọwọ́ ara rẹ̀ dá sílẹ̀ báyìí o. (Fi wé Gálátíà 6:7, 8.) Nígbà tí Ìṣípayá 12:12 ń sọ nípa ìbí Ìjọba Mèsáyà náà lókè ọ̀run, ó fi wá lọ́kàn balẹ̀, nígbà tó wí pé: “Ní tìtorí èyí, ẹ máa yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀, ẹ̀yin ọ̀run àti ẹ̀yin tí ń gbé inú wọn! Ègbé ni fún ilẹ̀ ayé àti fún òkun, nítorí Èṣù ti sọ̀ kalẹ̀ wá bá yín, ó ní ìbínú ńlá, ó mọ̀ pé sáà àkókò kúkúrú ni òun ní.”
Ní ìbámu pẹ̀lú ìṣirò ọjọ́ nínú Bíbélì àti ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ inú Bíbélì, òpin “sáà àkókò kúkúrú” yẹn ni a ń gbé báyìí. Inú wa mà dùn o, pé gbogbo àkókò tí Sátánì ní ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tán pátápátá! Gbàrà tí a bá ti mú un kúrò, a ó lè mú àwọn ènìyàn onígbọràn padà bọ̀ sí ìjẹ́pípé, ọwọ́ wọn á sì lè tẹ ìyè àìnípẹ̀kun tí Jèhófà ti pète fún wọn láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀. (Ìṣípayá 21:1-4) Nígbà náà, ìṣòro àìsí àkókò kò ní sí mọ́.
Ǹjẹ́ o lè fojú inú wo ohun tí yóò túmọ̀ sí láti ní ìyè àìnípẹ̀kun—láti wà láàyè títí láé? O kò tún ní níṣòro ríronú nípa àwọn ohun tó yẹ kóo ṣe, ṣùgbọ́n tí àyè tí kò sí mú kóo pa tì. Nígbà yẹn, bí àyè ò bá sí lọ́jọ́ kan, ọ̀la ṣì wà níbẹ̀, ọ̀sẹ̀ tó ń bọ̀ wà níbẹ̀, tàbí ọdún tó ń bọ̀—àní, àkókò tó lọ kánrin wà níwájú rẹ!
Fífi Ọgbọ́n Lo Àkókò Táa Ní Nísinsìnyí
Nítorí tí Sátánì ti mọ̀ pé àkókò tí òun ní láti lo agbára lórí àwọn ènìyàn kò tó nǹkan mọ́, ó ń gbìyànjú láti mú kí ọwọ́ àwọn ènìyàn dí, débi tí wọn kò ti ní rí àyè láti fetí sí ìhìn rere Ìjọba tí Ọlọ́run ti gbé kalẹ̀. Nítorí náà, ì bá dáa táa bá lè kọbi ara sí ìmọ̀ràn àtọ̀runwá náà pé: “Ẹ máa ṣọ́ra lójú méjèèjì pé bí ẹ ṣe ń rìn kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí aláìlọ́gbọ́n ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ọlọ́gbọ́n, ní ríra àkókò tí ó rọgbọ padà fún ara yín, nítorí pé àwọn ọjọ́ burú. Ní tìtorí èyí, ẹ ṣíwọ́ dídi aláìlọ́gbọ́n-nínú, ṣùgbọ́n ẹ máa bá a lọ ní ríróye ohun tí ìfẹ́ Jèhófà jẹ́.”—Éfésù 5:15-17.
Dípò tí a óò fi máa fàkókò wa tàfàlà lórí àwọn nǹkan tí kò lè mú àǹfààní tí yóò wà pẹ́ títí wá, ẹ wo bó ti ṣe pàtàkì tó pé kí a fọgbọ́n lo àkókò wa fún àwọn nǹkan tó ṣe pàtàkì jù! Irú ẹ̀mí tí Mósè ní nígbà tí ó fi àwọn ọ̀rọ̀ àtọkànwá yìí bẹ Jèhófà, ló yẹ kí àwa náà ní, ó bẹ̀ ẹ́ pé: “Fi hàn wá, àní bí àwa yóò ṣe máa ka àwọn ọjọ́ wa ní irú ọ̀nà tí a ó fi lè jèrè ọkàn-àyà ọgbọ́n.”—Sáàmù 90:12.
Lóòótọ́, nínú ayé tí à ń gbé lónìí, kò sẹ́ni tọ́wọ́ rẹ̀ ò dí. Síbẹ̀síbẹ̀, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń rọ̀ ọ́ pé, kóo jọ̀wọ́ lo díẹ̀ nínú àkókò ṣíṣeyebíye tóo ní láti kọ́ nípa àwọn ohun tí Ọlọ́run ń béèrè, kóo bàa lè jèrè ìyè àìnípẹ̀kun lábẹ́ Ìjọba rẹ̀. Tóo bá ń lo wákàtí kan lọ́sẹ̀ láti máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì díẹ̀díẹ̀, “ní ríróye ohun tí ìfẹ́ Jèhófà jẹ́,” èyí lè jẹ́ kí o gbádùn ìmúṣẹ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí pé: “Yí padà kúrò nínú ohun búburú, kí o sì máa ṣe rere, kí o sì tipa bẹ́ẹ̀ máa wà fún àkókò tí ó lọ kánrin. Àwọn olódodo ni yóò ni ilẹ̀ ayé, wọn yóò sì máa gbé títí láé lórí rẹ̀.”—Sáàmù 37:27, 29.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo ìwé Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun, orí kẹfà, èyí tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.