O Lè Jèrè Arákùnrin Rẹ
“Lọ fi àléébù rẹ̀ hàn án láàárín ìwọ àti òun nìkan. Bí ó bá fetí sí ọ, ìwọ ti jèrè arákùnrin rẹ.”—MÁTÍÙ 18:15.
1, 2. Ìmọ̀ràn tó gbéṣẹ́ wo nípa báa ṣe lè yanjú aáwọ̀ ni Jésù fún wa?
BÓ TILẸ̀ jẹ́ pé gbogbo àkókò tí Jésù máa lò nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ kò pé ọdún kan mọ́, ó ṣì ní ẹ̀kọ́ pàtàkì láti kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. O lè rí ẹ̀kọ́ wọ̀nyí kà nínú Mátíù orí kejìdínlógún. Ọ̀kan nínú wọn ni ìjẹ́pàtàkì jíjẹ́ onírẹ̀lẹ̀, ìyẹn ni pé ká dà bí ọmọdé. Lẹ́yìn náà, ó tẹnu mọ́ ọn pé, a gbọ́dọ̀ yẹra fún mímú “ọ̀kan nínú àwọn ẹni kékeré wọ̀nyí” kọsẹ̀, a sì tún gbọ́dọ̀ gbìyànjú láti wá “àwọn ẹni kékeré” tó ti ń ṣáko lọ, kí wọn má bàá ṣègbé. Ẹ̀yìn èyí ni Jésù wá fi ìmọ̀ràn tó yè kooro, tó tún gbéṣẹ́ yìí kún un, èyí tó dá lórí yíyanjú aáwọ̀ láàárín àwọn Kristẹni.
2 O lè rántí àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Bí arákùnrin rẹ bá dá ẹ̀ṣẹ̀ kan, lọ fi àléébù rẹ̀ hàn án láàárín ìwọ àti òun nìkan. Bí ó bá fetí sí ọ, ìwọ ti jèrè arákùnrin rẹ. Ṣùgbọ́n bí kò bá fetí sílẹ̀, mú ẹnì kan tàbí méjì sí i dání pẹ̀lú rẹ, kí a lè fi ìdí ọ̀ràn gbogbo múlẹ̀ ní ẹnu ẹlẹ́rìí méjì tàbí mẹ́ta. Bí kò bá fetí sí wọn, sọ fún ìjọ. Bí kò bá fetí sí ìjọ pàápàá, jẹ́ kí ó rí sí ọ gan-an gẹ́gẹ́ bí ènìyàn àwọn orílẹ̀-èdè àti gẹ́gẹ́ bí agbowó orí.” (Mátíù 18:15-17) Ìgbà wo la lè lo irú ìmọ̀ràn yìí, kí ló sì yẹ kó jẹ́ ìṣarasíhùwà wa, nígbà táa bá ń lò ó?
3. Ọ̀nà wo ló yẹ ká gbà yanjú ohun tẹ́nì kan ṣe sí wa?
3 Àpilẹ̀kọ tó ṣáájú tẹnu mọ́ ọn pé, níwọ̀n bí gbogbo wa ti jẹ́ aláìpé, tí kò sì sẹ́ni tí kò lè ṣàṣìṣe nínú wa, gbogbo wa ló yẹ ká gbìyànjú láti lẹ́mìí ìdáríjì. Ìyẹn tún ṣe pàtàkì gidigidi nígbà tí ohun tí Kristẹni kan sọ tàbí ìwà tó hù bá dùn wá. (1 Pétérù 4:8) Lọ́pọ̀ ìgbà, ohun tó dára jù ni pé ká gbójú fo ọ̀ràn náà—ká dárí ji onítọ̀hún, ká sì mọ́kàn kúrò níbẹ̀. A lè ka èyí sí fífikún àlàáfíà tó wà nínú ìjọ Kristẹni. (Sáàmù 133:1; Òwe 19:11) Síbẹ̀, ìgbà mìíràn lè wà tí wàá ní in lọ́kàn pé ó yẹ kóo yanjú ohun tí arákùnrin tàbí arábìnrin rẹ ṣe tó dùn ọ́. Nínú irú ọ̀ràn bẹ́ẹ̀, ọ̀rọ̀ Jésù tó wà lókè yìí tọ́ wa sọ́nà.
4. Gẹ́gẹ́ bí ìlànà, báwo la ṣe lè lo Mátíù 18:15 láti yanjú ohun tẹ́nì kan ṣe sí wa?
4 Jésù gbà ọ́ nímọ̀ràn pé kóo “lọ fi àléébù rẹ̀ hàn án láàárín ìwọ àti òun nìkan.” Ìyẹn bọ́gbọ́n mu. Àwọn ìtumọ̀ kan lédè Jámánì sọ pé, kí o sọ àṣìṣe rẹ̀ “lábẹ́ ojú mẹ́rin,” ìyẹn túmọ̀ sí láàárín ìwọ àtirẹ̀ méjì. Tóo bá fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ ṣàlàyé ohun kan tó ń bí ọ nínú fún ẹnì kan láàárín ìwọ àtirẹ̀ nìkan, lọ́pọ̀ ìgbà, ó máa ń rọrùn láti yanjú. Arákùnrin kan tó ṣe ohun tó dùn ọ́ tàbí tó sọ̀rọ̀ tó mú ọkàn rẹ gbọgbẹ́ tàbí tó fi hàn pé òun ò náání rẹ rárá lè tètè gbà pé òun ṣàṣìṣe, bó bá jẹ́ ìwọ rẹ̀ nìkan lẹ jọ sọ ọ́. Àmọ́ táwọn mìíràn bá lọ wà níbẹ̀, ìwà ẹ̀dá aláìpé lè mú kó sẹ́, kó lóun ò ṣe ohun tó jọ bẹ́ẹ̀ tàbí kò bẹ̀rẹ̀ sí í wáwìíjàre. Ṣùgbọ́n tó bá jẹ́ pé “lábẹ́ ojú mẹ́rin” péré lẹ ti jókòó sọ ọ́, kàkà tí wàá fi kà á sẹ́ṣẹ̀ sí i lọ́run, tàbí tí wàá fi gbà pé ó mọ̀ọ́mọ̀ fi dá ẹ lára ni, ó ṣeé ṣe kóo wá rí i pé àìgbọ́ra-ẹni-yé lásán ni. Gbàrà tẹ́yin méjèèjì bá ti gbà pé àìgbọ́ra-ẹni-yé ni, kẹ́ẹ yanjú ẹ̀ ló kù, kẹ́ẹ má lọ jẹ́ kí ọ̀ràn tí ò tó nǹkan ba àjọṣe yín jẹ́. Nítorí náà, ìlànà tó wà nínú Mátíù 18:15 ṣeé lò nínú àwọn ọ̀ràn kéékèèké tó lè jẹ yọ nínú ìgbésí ayé ojoojúmọ́ pàápàá.
Kí Ló Ní Lọ́kàn?
5, 6. Táa bá gbé àyíká ọ̀rọ̀ yẹ̀ wò, irú ẹ̀ṣẹ̀ wo ni Mátíù 18:15 ń tọ́ka sí, kí ló sì fi èyí hàn?
5 Ní ti gidi, ìmọ̀ràn Jésù dá lórí àwọn ọ̀ràn tó túbọ̀ nípọn. Jésù wí pé: “Bí arákùnrin rẹ bá dá ẹ̀ṣẹ̀.” Ní ìtumọ̀ tó gbòòrò, “ẹ̀ṣẹ̀” lè jẹ́ àṣìṣe tàbí ìkùdíẹ̀káàtó. (Jóòbù 2:10; Òwe 21:4; Jákọ́bù 4:17) Ṣùgbọ́n, àyíká ọ̀rọ̀ náà fi hàn pé ẹ̀ṣẹ̀ tí Jésù ní lọ́kàn níhìn-ín, ẹ̀ṣẹ̀ ńlá ni. Ẹ̀ṣẹ̀ náà wúwo débi tó ti lè yọrí sí kíka oníwà àìtọ́ náà sí “ènìyàn àwọn orílẹ̀-èdè àti gẹ́gẹ́ bí agbowó orí.” Kí ni gbólóhùn yẹn túmọ̀ sí?
6 Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ yẹn mọ̀ pé àwọn ọmọọ̀lú àwọn kò jẹ́ bá àwọn Kèfèrí ṣe wọléwọ̀de. (Jòhánù 4:9; 18:28; Ìṣe 10:28) Dájúdájú, wọ́n máa ń yẹra fáwọn agbowó orí, àwọn tó jẹ́ pé lóòótọ́ Júù ni wọ́n o, àmọ́ wọ́n ti di oníjìbìtì. Nítorí náà, ká kúkú sọjú abẹ níkòó, ẹ̀ṣẹ̀ ńlá ni Mátíù 18:15-17 ń tọ́ka sí, kì í ṣe aáwọ̀ lásán láàárín ẹnì kan sẹ́nì kan tàbí ìwà àfojúdi tẹ́nì kan hù sí ọ́, tàbí ohun tẹ́nì kan ṣe tó mú ọkàn rẹ gbọgbẹ́, tóo lè dárí jì í, tàbí tóo lè gbàgbé ẹ̀.—Mátíù 18:21, 22.a
7, 8. (a) Irú ẹ̀ṣẹ̀ wo la lè pe àwọn alàgbà kí wọ́n bá wa yanjú ẹ̀? (b) Irú ẹ̀ṣẹ̀ wo làwọn Kristẹni méjì lè yanjú láàárín ara wọn, ní ìbámu pẹ̀lú Mátíù 18:15-17?
7 Lábẹ́ Òfin, àwọn ẹ̀ṣẹ̀ kan wà tó jẹ́ pé ohun tó ń béèrè ju pé kí ẹni táa ṣẹ̀ kàn forí jini lọ. Sísọ̀rọ̀ òdì, ìpẹ̀yìndà, ìbọ̀rìṣà, àti ẹ̀ṣẹ̀ tó jẹ mọ ìṣekúṣe, irú bí àgbèrè, panṣágà, àti ìbẹ́yà-kannáà-lòpọ̀ la gbọ́dọ̀ fi tó àwọn àgbààgbà (tàbí àwọn àlùfáà) létí, àwọn ni yóò sì mójú tó o. Bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe rí nínú ìjọ Kristẹni. (Léfítíkù 5:1; 20:10-13; Númérì 5:30; 35:12; Diutarónómì 17:9; 19:16-19; Òwe 29:24) Ṣùgbọ́n, ṣàkíyèsí pé ẹ̀ṣẹ̀ tí Jésù ń sọ níhìn-ín jẹ́ èyí táa lè yanjú rẹ̀ láàárín ẹni méjì tọ́ràn náà kàn. Fún àpẹẹrẹ: Nítorí tí inú bí ẹnì kan tàbí torí pé ó ń ṣèlara ẹnì kejì rẹ̀, tó wá lọ bà á lórúkọ jẹ́. Kí ẹnì kan ṣàdéhùn pé òun yóò lo oríṣi ohun èlò ìkọ́lé kan pàtó láti fi kọ́lé àti pe òun yóò parí rẹ̀ nígbà báyìí, àmọ́ kó wá lọ lo nǹkan mí-ìn, kó má sì parí ẹ̀ nígbà tó dá. Kí Kristẹni kan ṣèlérí pé òun yóò san owó tí òun yá padà nígbà báyìí tàbí lọ́jọ́ báyìí àmọ́ kó yẹ àdéhùn. Kí Kristẹni kan lérí-léka pé bí ẹni tó gba òun síṣẹ́ bá lè kọ́ òun níṣẹ́ náà tán, fún sáà kan pàtó tàbí ní àgbègbè kan tí wọ́n fohùn ṣọ̀kan lé lórí, (kódà bí òun kò bá bá a ṣiṣẹ́ mọ́) òun ò ní fi iṣẹ́ tòun pa tiẹ̀ lára tàbí kóun máa dọ́gbọ́n fajú àwọn oníbàárà rẹ̀ mọ́ra, kí arákùnrin náà máà wá mú ìlérí yìí ṣẹ.b Bí arákùnrin kan kò bá mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ, tí kò sì ronú pìwà dà, kó gbà pé ìwà àìtọ́ gbáà lòun hù, ẹ̀ṣẹ̀ ńlá nìyẹn o. (Ìṣípayá 21:8) Àmọ́ ṣá o, àwọn méjèèjì tọ́ràn náà kàn ṣì lè yanjú rẹ̀ láàárín ara wọn.
8 Ṣùgbọ́n, báwo lo ṣe wá fẹ́ yanjú ọ̀ràn yìí? Ìgbésẹ̀ mẹ́ta la sábà ń gbà pé o wà nínú ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ. Ẹ jẹ́ ká gbé ọ̀kọ̀ọ̀kan rẹ̀ yẹ̀ wò. Kàkà tí wàá fi kà wọ́n sí ìlànà tí kò ṣeé yí padà, ì bá dára tóo bá lè gbìyànjú láti lóye ohun tó túmọ̀ sí, kóo má sì gbàgbé góńgó onífẹ̀ẹ́ tóo ní lọ́kàn.
Sapá Láti Jèrè Arákùnrin Rẹ
9. Kí ló yẹ ká fi sọ́kàn táa bá ń lo Mátíù 18:15?
9 Bí Jésù ṣe bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ rèé: “Bí arákùnrin rẹ bá dá ẹ̀ṣẹ̀ kan, lọ fi àléébù rẹ̀ hàn án láàárín ìwọ àti òun nìkan. Bí ó bá fetí sí ọ, ìwọ ti jèrè arákùnrin rẹ.” Kò sí àní-àní pé, ìgbésẹ̀ yìí kì í ṣe èyí táa gbé nítorí pé a ń fura sẹ́nì kan. O gbọ́dọ̀ ní ẹ̀rí tàbí ìsọfúnni pàtó lọ́wọ́ tóo lè fi ran arákùnrin rẹ lọ́wọ́, kó lè rí i pé òun ti hùwà àìdáa, kó sì mọ̀ pé òun ní láti mú ọ̀ràn náà tọ́. Ó dára ká tètè gbégbèésẹ̀, ká máà jẹ́ kọ́ràn náà di iṣu-ata-yán-an-yàn-an tàbí kó wá dórí pé onítọ̀hún ti bẹ̀rẹ̀ sí í fi hùwà. Má sì ṣe gbàgbé pé dídì kunkun nítorí rẹ̀ lè ṣàkóbá fún ìwọ alára. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé àárín ẹ̀yin méjèèjì nìkan ni ìjíròrò náà ti wáyé, ṣọ́ra fún rírojọ́ fáwọn ẹlòmí-ìn kó tó di pé ẹ jọ jókòó sọ ọ́, má torí kí wọ́n lè bá ọ káàánú rojọ́ kiri tàbí torí kí wọ́n lè mọ̀ pé èèyànre ni ọ́. (Òwe 12:25; 17:9) Èé ṣe tí wàá fi ṣe gbogbo ìyẹn? Nítorí góńgó tóo ní lọ́kàn ni.
10. Kí ni yóò ràn wá lọ́wọ́ láti jèrè arákùnrin wa?
10 Ohun tó yẹ kó wà lọ́kàn rẹ ni pé o fẹ́ jèrè arákùnrin rẹ, kì í ṣe pé o fẹ́ láálí ẹ̀, pé ó fẹ́ tẹ́ ẹ, tàbí pé o fẹ́ fọ̀rọ̀ ba tiẹ̀ jẹ́. Ká lóòótọ́ ló ti hùwà àìdáa, ìbátan rẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà wà nínú ewu. Ó dájú pé, o fẹ́ kó ṣì máa jẹ́ Kristẹni arákùnrin rẹ. Ìjíròrò náà lè sèso rere tó bá jẹ́ pé nígbà tẹ́ẹ jọ jókòó sọ̀rọ̀ náà, o fara balẹ̀, oò sọ̀rọ̀ kòbákùngbé sí i, ohùn rẹ ò le jù, tí kò jọ pé ò ń fẹ̀sùn kàn án. Nínú ìjíròrò onífẹ̀ẹ́ yìí, o rántí pé aláìpé lẹ̀yin méjèèjì. (Róòmù 3:23, 24) Níwọ̀n ìgbà tó ti mọ̀ pé oò tíì sọ̀rọ̀ òun lẹ́yìn, tó sì mọ̀ pé ṣe lo fẹ́ ran òun lọ́wọ́, ó dájú pé ọ̀ràn náà á yanjú. Ó dájú pé tẹ́ẹ bá fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ jíròrò rẹ̀ lọ́nà tó ṣe kedere báyìí, èyí yóò fi ọgbọ́n hàn, àgàgà tó bá lọ yọrí sí pé ẹ̀yin méjèèjì lẹ gbà pé ẹ jẹ̀bi tàbí lẹ jọ gbà pé àìgbọ́ra-ẹni-yé lásán ló jẹ́ kí nǹkan rí bẹ́ẹ̀.—Òwe 25:9, 10; 26:20; Jákọ́bù 3:5, 6.
11. Kódà bí ẹni tó ṣẹ̀ wá kò bá tẹ́tí sí wa, kí la lè ṣe?
11 Bóo bá ràn án lọ́wọ́ láti mọ ẹ̀ṣẹ̀ tó ṣẹ̀ ọ́, tóo sì jẹ́ kó mọ bó ṣe wúwo tó, ìyẹn lè sún un láti ronú pìwà dà. Àmọ́, ká sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ọ́ wà, ìgbéraga tún lè fa ìṣòro. (Òwe 16:18; 17:19) Nítorí náà, bí kò bá tilẹ̀ kọ́kọ́ fẹ́ gba àṣìṣe náà kó sì ronú pìwà dà, kọ́kọ́ sinmẹ̀dọ̀, kóo tó gbé ìgbésẹ̀ mìíràn. Jésù kò sọ pé ‘lọ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo, kí o sì fi àlèébù rẹ̀ hàn án.’ Níwọ̀n bó ti jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ tẹ́ẹ lè jọ yanjú ni, ronú lórí pípadà tọ̀ ọ́ lọ pẹ̀lú ẹ̀mí tí Gálátíà 6:1 sọ, kí ó sì jẹ́ “lábẹ́ ojú mẹ́rin.” O ṣeé ṣe kọ́ràn náà yanjú pátápátá. (Fi wé Júúdà 22, 23.) Síbẹ̀, ká ló dá ọ lójú pé ó ṣàìdáa sí ọ ńkọ́, tóo sì mọ̀ pé ṣe ló máa yarí kanlẹ̀, tí kò ní fẹ́ gbà?
Wá Ìrànlọ́wọ́ Àwọn Tó Dàgbà Dénú
12, 13. (a) Kí ni ìgbésẹ̀ kejì tí Jésù sọ pé a lè gbé láti yanjú aáwọ̀? (b) Àwọn ìmọ̀ràn yíyẹ wo ló tọ́ láti fiyè sí nígbà táa bá ń gbé ìgbésẹ̀ yìí?
12 Ká lóo hùwà kan tó burú jáì, ǹjẹ́ wàá fẹ́ káwọn èèyàn pa ẹ́ tì torí pé oò tètè yí padà? Kò dájú pé wàá fẹ́ bẹ́ẹ̀. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, Jésù fi hàn pé lẹ́yìn tóo ti gbé ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́, o kò gbọ́dọ̀ jẹ́ kó rẹ̀ ọ́ láti jèrè arákùnrin rẹ, kí ìwọ àtòun àtàwọn yòókù lè jọ wà ní ìrẹ́pọ̀, kẹ́ sì lè jọ máa jọ́sìn Ọlọ́run lọ́nà tó fẹ́. Jésù sọ ìgbésẹ̀ kejì, ó ní: “Bí kò bá fetí sílẹ̀, mú ẹnì kan tàbí méjì sí i dání pẹ̀lú rẹ, kí a lè fi ìdí ọ̀ràn gbogbo múlẹ̀ ní ẹnu ẹlẹ́rìí méjì tàbí mẹ́ta.”
13 Ó ní kóo mú “ẹnì kan tàbí méjì” dání. Kò sọ pé lẹ́yìn tóo bá ti gbégbèésẹ̀ àkọ́kọ́, o ti lómìnira láti bẹ̀rẹ̀ sí í rojọ́ fáwọn ẹlòmí-ìn, kóo wá bẹ̀rẹ̀ sí í wá alábòójútó arìnrìn-àjò kiri láti fi tó o létí, tàbí kóo bẹ̀rẹ̀ sí kọ lẹ́tà sáwọn ará nípa ìṣòro náà. Bó ti wù kó dá ẹ lójú tó pé lóòótọ́ ló ṣẹ̀ ọ́, ẹ̀yin méjèèjì ò tíì fìdí ọ̀ràn náà múlẹ̀. Ó sì dájú pé o kò ní fẹ́ tan ọ̀rọ̀ èké, tó lè wá sọ ẹ́ di abanijẹ́, kálẹ̀. (Òwe 16:28; 18:8) Ṣùgbọ́n, ohun tí Jésù wí ni pé, mú ẹnì kan tàbí méjì dání. Èé ṣe tó fi sọ bẹ́ẹ̀? Àwọn wo la sì lè mú dání?
14. Ta la lè mú lọ́wọ́ táa bá fẹ́ gbé ìgbésẹ̀ kejì?
14 Ò ń gbìyànjú láti jèrè arákùnrin rẹ̀ nípa jíjẹ́ kó mọ̀ pé ó ti ṣẹ̀ ọ́ àti pé o fẹ́ sún un láti ronú pìwà dá, kí ó bàa lè wà ní àlàáfíà pẹ̀lú rẹ àti pẹ̀lú Ọlọ́run. Kí èyí lè ṣeé ṣe, ohun tí yóò dára jù ni pé kí “ẹnì kan tàbí méjì” náà jẹ́ àwọn tí wọ́n jẹ́ ẹlẹ́rìí sí ohun tí ẹni yẹn ṣe. Ó lè jẹ́ pé wọ́n wà níbẹ̀ nígbà tọ́ràn náà wáyé, tàbí wọ́n ní ìsọfúnni tó ṣeé gbára lé lọ́wọ́ nípa ohun tó wáyé (tàbí tí kò wáyé) nínú ọ̀ràn ìṣòwò náà. Bí kò bá sí irú àwọn ẹlẹ́rìí bẹ́ẹ̀, àwọn tóo pè lè jẹ́ àwọn tí wọ́n ti ní ìrírí nípa irú ohun tó fa awuyewuye náà, tí wọn yóò sì lè fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé lóòótọ́ ni ohun tí onítọ̀hún ṣe ò dáa. Láfikún sí i, nítorí à ò mọ ẹ̀yìn ọ̀ràn, àwọn pẹ̀lú lè jẹ́ ẹlẹ́rìí sí ohun tẹ́ẹ sọ, tàbí kí wọ́n jẹ́rìí sí àwọn kókó tẹ́ẹ gbé kalẹ̀ àti ìsapá tẹ́ẹ ṣe. (Númérì 35:30; Diutarónómì 17:6) Nítorí náà, wọn kì í ṣe ẹni tí kò mọ nǹkan kan rárá nípa ọ̀ràn náà, ẹni tó jẹ́ pé ó kàn wá gbẹ́jọ́ lásán ni; síbẹ̀, wíwà tí wọ́n wà níbẹ̀ jẹ́ láti ṣèrànwọ́ láti jèrè arákùnrin rẹ àti arákùnrin wọn.
15. Èé ṣe tí àwọn Kristẹni àlàgbà lè ṣèrànwọ́ báa bá fẹ́ gbé ìgbésẹ̀ kejì?
15 Kò pọndandan pé àwọn alàgbà ìjọ lo gbọ́dọ̀ pè. Àmọ́ ṣá o, àwọn ọkùnrin tó dàgbà dénú, tí wọ́n jẹ́ alàgbà lè ṣèrànwọ́, nítorí àwọn ànímọ́ tẹ̀mí tí wọ́n ní. Irú àwọn alàgbà bẹ́ẹ̀ jẹ́ “ibi ìfarapamọ́sí kúrò lọ́wọ́ ẹ̀fúùfù àti ibi ìlùmọ́ kúrò lọ́wọ́ ìjì òjò, bí àwọn ìṣàn omi ní ilẹ̀ aláìlómi, bí òjìji àpáta gàǹgà ní ilẹ̀ gbígbẹ táútáú.” (Aísáyà 32:1, 2) Tó bá dọ̀ràn ká fèròwérò pẹ̀lú àwọn arákùnrin àti arábìnrin, ká sì mú wọn padà bọ̀ sípò, onírìírí làwọn alàgbà jẹ́. Ẹni tó hùwà àìtọ́ náà yóò sì lè gbára lé irú “àwọn ẹ̀bùn [tí ó jẹ́] ènìyàn” bẹ́ẹ̀.c (Éfésù 4:8, 11, 12) Sísọ bí ọ̀ràn náà ṣe rí gan-an níwájú irú àwọn tó dàgbà dénú bẹ́ẹ̀ àti dídara pọ̀ mọ́ wọn nínú àdúrà lè yí nǹkan padà, kí ohun táa rò pé ó ti di ìṣòro ńlá wá di ìtì ọ̀gẹ̀dẹ̀, tí kò tó nǹkan tí à ń lọ àdá sí.—Fi wé Jákọ́bù 5:14, 15.
Ìsapá Ìkẹyìn Láti Jèrè Rẹ̀
16. Kí ni ìgbésẹ̀ kẹta tí Jésù lá sílẹ̀?
16 Bí ìgbésẹ̀ kejì ò bá yanjú ọ̀ràn náà, ó ti wá di dandan pé kí àwọn alábòójútó ìjọ kópa nínú ìgbésẹ̀ kẹta. “Bí kò bá fetí sí wọn [ìyẹn ni ẹnì kan tàbí méjì], sọ fún ìjọ. Bí kò bá fetí sí ìjọ pàápàá, jẹ́ kí ó rí sí ọ gan-an gẹ́gẹ́ bí ènìyàn àwọn orílẹ̀-èdè àti gẹ́gẹ́ bí agbowó orí.” Kí lèyí túmọ̀ sí?
17, 18. (a) Àpẹẹrẹ wo ló ràn wá lọ́wọ́ láti lóye ìjẹ́pàtàkì ‘sísọ fún ìjọ’? (b) Báwo la ṣe ń gbé ìgbésẹ̀ yìí lónìí?
17 A ò ka èyí sí pé ṣe là ń fún wa láṣẹ láti mú ẹ̀ṣẹ̀ náà tàbí ìwà àìtọ́ náà wá sétígbọ̀ọ́ gbogbo ìjọ lọ́jọ́ ìpàdé tàbí ká wá pe ìpàdé àkànṣe nítorí rẹ̀. A lè rí ìlànà tó tọ́ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Wo ohun tí wọ́n lè ṣe tó bá jẹ́ Ísírẹ́lì ìgbàanì lẹ́nì kan ti hùwà ọ̀tẹ̀, tàbí tó jẹ́ alájẹkì, tàbí ọ̀mùtí: “Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ọkùnrin kan wá ní ọmọ kan tí ó jẹ́ alágídí àti ọlọ̀tẹ̀, tí kì í fetí sí ohùn baba rẹ̀ tàbí ohùn ìyá rẹ̀, tí wọ́n sì ti tọ́ ọ sọ́nà ṣùgbọ́n tí kò jẹ́ fetí sí wọn, kí baba rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ dì í mú, kí wọ́n sì mú un jáde lọ bá àwọn àgbà ọkùnrin ìlú ńlá rẹ̀ àti sí ẹnubodè ibi tí ó ń gbé, kí wọ́n sì wí fún àwọn àgbà ọkùnrin ìlú ńlá rẹ̀ pé, ‘Ọmọ wa yìí jẹ́ alágídí àti ọlọ̀tẹ̀; kì í fetí sí ohùn wa, alájẹkì àti ọ̀mùtípara ni.’ Nígbà náà, kí gbogbo ọkùnrin ìlú ńlá rẹ̀ sọ ọ́ ní òkúta.”—Diutarónómì 21:18-21.
18 Kì í ṣe gbogbo orílẹ̀-èdè tàbí gbogbo àwọn tí wọ́n jẹ́ ẹ̀yà ẹni tó dẹ́ṣẹ̀ náà ló gbọ́ sí i, kì í sì í ṣe gbogbo wọn ló dá a lẹ́jọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, “àwọn àgbà ọkùnrin” táa yàn ló bójú tó ọ̀ràn náà gẹ́gẹ́ bí aṣojú ìjọ. (Fi wé Diutarónómì 19:16, 17 níbi tí a ti kà nípa ẹjọ́ tí ‘àwọn àlùfáà àti àwọn onídàájọ́ tí wọ́n ń gbéṣẹ́ ṣe ní ọjọ́ wọnnì dá.’) Bákan náà lónìí, nígbà tó bá pọndandan láti gbé ìgbésẹ̀ kẹta, àwọn alàgbà, tí wọ́n ń ṣojú fún ìjọ, ni yóò yanjú ọ̀ràn náà. Góńgó tí ẹni táa ṣẹ̀ ní lọ́kàn làwọn náà ní, ìyẹn ni pé bó bá ṣeé ṣe, àwọn fẹ́ jèrè Kristẹni arákùnrin àwọn padà. Wọn yóò fi èyí hàn nípa pé wọn ò ní gbè sẹ́yìn ẹnì kan, wọn ò ní gbọ́ ẹjọ́ ẹnì kan dájọ́, wọn ò sì ní ṣojúsàájú.
19. Kí ni àwọn alàgbà táa yàn láti gbọ́ ọ̀rọ̀ náà gbọ́dọ̀ sapá láti ṣe?
19 Wọn yóò sapá láti yẹ ọ̀rọ̀ náà wò fínnífínní, kí wọ́n sì gbọ́ tẹnu àwọn ẹlẹ́rìí, kí wọ́n lè fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé onítọ̀hún dẹ́ṣẹ̀ náà tàbí kò dá a (tàbí pé kò tíì jáwọ́ nínú ẹ̀ṣẹ̀ náà). Wọ́n fẹ́ dáàbò bo ìjọ, kó má bàa di pé ìwà ìbàjẹ́ yọ́ wọlé, wọ́n sì fẹ́ lé ẹ̀mí ayé jìnnà. (1 Kọ́ríńtì 2:12; 5:7) Láti fi hàn pé wọ́n tóótun lójú ìwòye Ìwé Mímọ́, wọn yóò sapá láti “gbani níyànjú pẹ̀lú ẹ̀kọ́ afúnni-nílera àti láti fi ìbáwí tọ́ àwọn tí ń ṣàtakò sọ́nà.” (Títù 1:9) Ó dájú pé, oníwà àìtọ́ náà kò ní fìwà jọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àwọn tí wòlíì Jèhófà sọ nípa wọn pé: “Mo pè, ṣùgbọ́n ẹ kò dáhùn; mo sọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n ẹ kò fetí sílẹ̀; ẹ sì ń ṣe ohun tí ó burú ṣáá ní ojú mi, ohun tí èmi kò sì ní inú dídùn sí ni ẹ yàn.”—Aísáyà 65:12.
20. Kí ni Jésù sọ pé ó gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀ bí ẹlẹ́ṣẹ̀ náà bá kọ̀ láti fetí sí ìmọ̀ràn, kó sì ronú pìwà dà?
20 Àmọ́ ṣá o, àwọn ọ̀ràn díẹ̀ mà ti wáyé, tó jẹ́ pé ẹlẹ́ṣẹ̀ náà fìwà jọ wọ́n. Bọ́ràn bá wá rí bẹ́ẹ̀, àṣẹ Jésù ṣe kedere, ó ní: “Jẹ́ kí ó rí sí ọ gan-an gẹ́gẹ́ bí ènìyàn àwọn orílẹ̀-èdè àti gẹ́gẹ́ bí agbowó orí.” Olúwa kò fojúure wo jíjẹ́ òǹrorò tàbí ẹni tó ń mọ̀ọ́mọ̀ ṣe ohun tó máa dun ọmọnìkejì ẹ̀. Àmọ́ ṣá o, àṣẹ tí Pọ́ọ̀lù pa láti yọ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tí kò ronú pìwà dà kúrò nínú ìjọ ṣe tààrà, ó sì yéni yéké. (1 Kọ́ríńtì 5:11-13) Èyí pàápàá ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, lè yọrí sí jíjèrè ẹlẹ́ṣẹ̀ náà.
21. Kí ló ṣeé ṣe kó ṣẹlẹ̀ sí ẹni táa ti yọ kúrò nínú ìjọ?
21 A lè rí i pé èyí ṣeé ṣe, táa bá ronú lórí àkàwé Jésù nípa ọmọ onínàákúnàá. Gẹ́gẹ́ bí a ti ṣàkàwé rẹ̀, lẹ́yìn àkókò díẹ̀ tí ẹlẹ́ṣẹ̀ náà kò fi láǹfààní gbígbé nínú ilé baba rẹ̀, níbi tí wọ́n ti ń kẹ́ ẹ, tí wọ́n ti ń gẹ̀ ẹ́, “orí rẹ̀ wálé.” (Lúùkù 15:11-18) Pọ́ọ̀lù sọ fún Tímótì pé àwọn oníwà àìtọ́ yóò ronú pìwà dà bó bá yá, wọn yóò sì “padà wá sí agbára ìmòye wọn tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu kúrò nínú ìdẹkùn Èṣù.” (2 Tímótì 2:24-26) Ìrètí wa ni pé àwọn tó bá dẹ́sẹ̀, tí wọn kò sì ronú pìwà dà, tó wá di pé a ní láti yọ wọ́n lẹ́gbẹ́, yóò pàdá wá mọ̀ pé àwọn ti gbé àǹfààní ńlá sọnù—wọn ò rojú rere Ọlọ́run mọ́, wọ́n sì ti pàdánù ìfararora onífẹ̀ẹ́ àti àjọṣe ti ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà tí wọ́n máa ń ní pẹ̀lú àwọn Kristẹni adúróṣinṣin—orí wọn yóò sì wá wálé.
22. Báwo la ṣe lè rí arákùnrin wa jèrè padà?
22 Jésù kò gbà pé àwọn ènìyàn orílẹ̀-èdè àti àwọn agbowó orí ò lè ṣàtúnṣe mọ́. Mátíù ọmọ Léfì, tóun pẹ̀lú jẹ́ agbowó orí, ṣáà ronú pìwà dà, tó sì fi tọkàntọkàn ‘tẹ̀ lé Jésù,’ tí Jésù sì yàn án gẹ́gẹ́ bí àpọ́sítélì. (Máàkù 2:15; Lúùkù 15:1) Bákan náà, lóde òní, bí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan kò bá “fetí sí ìjọ,” tí a sì yọ ọ́ lẹ́gbẹ́, a ṣì lè mú sùúrù ná, ká máa wò ó bóyá, láìpẹ́, ó lè ronú pìwà dà, kó sì mú ọ̀nà rẹ̀ tọ́. Tó bá ṣe bẹ́ẹ̀, tó sì padà di mẹ́ńbà ìjọ, ìgbà náà ni inú wa yóò dùn pé a ti jèrè arákùnrin wa padà sínú agbo ìjọsìn tòótọ́.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà, McClintock and Strong’s Cyclopedia, sọ pé: “Ọ̀dalẹ̀ àti apẹ̀yìndà ni wọ́n ka àwọn agbowó òde [àwọn agbowó orí] sí nínú Májẹ̀mú Tuntun, àwọn èèyàn gbà pé wọ́n ti di aláìmọ́ nípa ṣíṣe wọléwọ̀de pẹ̀lú àwọn abọgibọ̀pẹ̀, àwọn tí àwọn aninilára ń lò. Wọ́n kà wọ́n kún àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ . . . Nítorí tí wọ́n ti di ẹni ìtanù, àwọn ọmọlúwàbí èèyàn kò jẹ́ bá wọn rìn, àwọn tó dà bíi tiwọn, àwọn ẹni àpatì bí aṣọ tó gbó nìkan lọ̀rẹ́ àti alábàákẹ́gbẹ́ wọn.”
b Ọ̀rọ̀ ìṣòwò tàbí ọ̀ràn owó tó bá ti ní ẹ̀tàn, jìbìtì, tàbí gbájú-ẹ̀ nínú lè wà lára ẹ̀ṣẹ̀ tí Jésù ní lọ́kàn. Báa ṣe mọ èyí ni pé, lẹ́yìn tí Jésù sọ ìlànà táa kọ sínú Mátíù 18:15-17, ó fúnni ní àkàwé àwọn ẹrú (àwọn òṣìṣẹ́) tí wọ́n jẹ gbèsè, tí wọ́n kọ̀, tí wọn ò san án.
c Ọ̀mọ̀wé kan tó kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jinlẹ̀ ṣàlàyé pé: “Ó sábà máa ń ṣẹlẹ̀ pé ẹni tó hùwà àìtọ́ yóò tẹ́tí sí ẹni méjì tàbí mẹ́ta ju ẹnì kan ṣoṣo lọ (pàápàá jù lọ bí wọ́n bá jẹ̀ àwọn tó yẹ kó bọ̀wọ̀ fún), yóò ṣòro fún un láti tẹ́tí sí ẹnì kan, pàápàá jù lọ bí onítọ̀hún bá lọ jẹ́ ẹni tí èrò wọn kò bára mu.”
Ṣé O Rántí?
◻ Ní ti gidi, irú ẹ̀ṣẹ̀ wo la lè lo Mátíù 18:15-17 fún?
◻ Kí ló yẹ ká rántí báa bá fẹ́ gbé ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́?
◻ Àwọn wo ló lè ṣèrànwọ́ báa bá fẹ̀ gbé ìgbésẹ̀ kejì?
◻ Àwọn wo ni gbígbé ìgbésẹ̀ kẹta kàn, báwo la sì ṣe lè rí arákùnrin wa jèrè padà?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Àwọn Júù yẹra fún àwọn agbowó orí. Mátíù yí padà ó sì tẹ̀ lé Jésù
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
Lọ́pọ̀ ìgbà a lè yanjú ọ̀ràn kan “lábẹ́ ojú mẹ́rin”