Ìwé Kejì sí Tímótì
2 Nítorí náà, ìwọ ọmọ mi,+ túbọ̀ máa gba agbára nípasẹ̀ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí tó wà nínú Kristi Jésù; 2 àwọn nǹkan tí o sì gbọ́ lọ́dọ̀ mi, tí ọ̀pọ̀ èèyàn jẹ́rìí sí,+ àwọn nǹkan yìí ni kí o fi síkàáwọ́ àwọn olóòótọ́, tí àwọn náà á sì wá kúnjú ìwọ̀n dáadáa láti kọ́ àwọn ẹlòmíì. 3 Kí ìwọ náà múra tán láti jìyà+ nítorí ọmọ ogun rere+ fún Kristi Jésù ni ọ́. 4 Ọmọ ogun tó bá fẹ́ múnú ẹni tó gbà á sí iṣẹ́ ológun dùn, kò ní tara bọ* òwò* ṣíṣe. 5 Kódà nínú àwọn eré ìdíje, wọn kì í dé ẹni tó bá kópa ládé, àfi tó bá tẹ̀ lé àwọn òfin ìdíje náà.+ 6 Àgbẹ̀ tó ń ṣiṣẹ́ kára ló gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ jẹ nínú àwọn èso oko. 7 Máa ronú nígbà gbogbo lórí àwọn ohun tí mò ń sọ; Olúwa máa fún ọ ní òye* nínú ohun gbogbo.
8 Rántí pé a jí Jésù Kristi dìde,+ ọmọ Dáfídì* sì ni,+ bó ṣe wà nínú ìhìn rere tí mò ń wàásù,+ 9 èyí tí mò ń torí rẹ̀ jìyà, tí wọ́n sì fi mí sẹ́wọ̀n bí ọ̀daràn.+ Àmọ́, ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ò ṣeé dè.+ 10 Nítorí èyí ni mo ṣe ń fara da ohun gbogbo torí àwọn àyànfẹ́,+ kí àwọn náà lè rí ìgbàlà tó wá nípasẹ̀ Kristi Jésù pẹ̀lú ògo àìnípẹ̀kun. 11 Ọ̀rọ̀ yìí ṣeé gbára lé: Ó dájú pé tí a bá jọ kú, a tún jọ máa wà láàyè;+ 12 tí a bá ń fara dà á nìṣó, a tún jọ máa jọba;+ tí a bá sẹ́ ẹ, òun náà máa sẹ́ wa;+ 13 tí a bá jẹ́ aláìṣòótọ́, ó ṣì máa jẹ́ olóòótọ́, torí kò lè sẹ́ ara rẹ̀.
14 Máa rán wọn létí àwọn nǹkan yìí, kí o máa fún wọn ní ìtọ́ni* níwájú Ọlọ́run pé kí wọ́n má ṣe jà nítorí ọ̀rọ̀, torí kò wúlò rárá, ó máa ń ṣàkóbá fún àwọn tó ń fetí sílẹ̀.* 15 Sa gbogbo ipá rẹ kí o lè rí ìtẹ́wọ́gbà Ọlọ́run, kí o jẹ́ òṣìṣẹ́ tí kò ní ohunkóhun tó máa tì í lójú, tó ń lo ọ̀rọ̀ òtítọ́ bó ṣe yẹ.+ 16 Àmọ́ yẹra fún àwọn ọ̀rọ̀ asán tó ń ba ohun mímọ́ jẹ́,+ torí ṣe ló máa ń mú kí èèyàn túbọ̀ jìnnà sí Ọlọ́run, 17 ọ̀rọ̀ wọn sì máa tàn kálẹ̀ bí egbò tó kẹ̀. Híméníọ́sì àti Fílétọ́sì wà lára wọn.+ 18 Àwọn ọkùnrin yìí ti yà kúrò nínú òtítọ́, wọ́n ń sọ pé àjíǹde ti ṣẹlẹ̀,+ wọ́n sì ń dojú ìgbàgbọ́ àwọn kan dé. 19 Síbẹ̀, ìpìlẹ̀ Ọlọ́run lágbára, ó dúró digbí, ó ní èdìdì yìí, “Jèhófà* mọ àwọn tó jẹ́ tirẹ̀,”+ àti pé, “Kí gbogbo àwọn tó ń pe orúkọ Jèhófà*+ kọ àìṣòdodo sílẹ̀ pátápátá.”
20 Àwọn ohun èlò wúrà àti fàdákà nìkan kọ́ ló wà nínú ilé ńlá, àmọ́ ohun èlò ti igi àti ti amọ̀ pẹ̀lú, wọ́n máa ń fi àwọn kan ṣe àwọn ohun tó ní ọlá, wọ́n sì ń fi àwọn míì ṣe ohun tí kò ní ọlá. 21 Torí náà, tí ẹnikẹ́ni bá yẹra fún àwọn tó kẹ́yìn yìí, wọ́n máa lò ó láti fi ṣe ohun tó ní ọlá,* tí a sọ di mímọ́, tó wúlò fún ẹni tó ni ín, tó sì múra tán láti ṣe gbogbo iṣẹ́ rere. 22 Torí náà, sá fún àwọn ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ìgbà ọ̀dọ́, àmọ́ máa wá òdodo, ìgbàgbọ́, ìfẹ́, àlàáfíà, pẹ̀lú àwọn tó ń fi ọkàn tó mọ́ ké pe Olúwa.
23 Bákan náà, má ṣe dá sí àwọn ìjiyàn tí kò bọ́gbọ́n mu àti ti àìmọ̀kan,+ o mọ̀ pé wọ́n máa ń fa ìjà. 24 Torí pé kò yẹ kí ẹrú Olúwa máa jà, àmọ́ ó yẹ kó máa hùwà jẹ́jẹ́* sí gbogbo èèyàn,+ kí ó kúnjú ìwọ̀n láti kọ́ni, kó máa kó ara rẹ̀ níjàánu tí wọ́n bá ṣe ohun tí kò dáa sí i,+ 25 kó máa fi ìwà tútù tọ́ àwọn tó ń ṣàtakò sọ́nà.+ Bóyá Ọlọ́run lè mú kí wọ́n ronú pìwà dà,* kí wọ́n sì wá ní ìmọ̀ tó péye nípa òtítọ́,+ 26 ká lè pe orí wọn wálé, kí wọ́n sì bọ́ lọ́wọ́ ìdẹkùn Èṣù, torí ó ti mú wọn láàyè kí wọ́n lè ṣe ìfẹ́ rẹ̀.+