Kí Ni Párádísè Tẹ̀mí?
ÌLÚ kékeré kan ní Brazil ni wọ́n ti tọ́ Gustavo dàgbà.a Àtìgbà tó ti wà lọ́mọdé ni wọ́n ti kọ́ ọ pé àwọn èèyàn rere máa ń lọ sọ́run nígbà tí wọ́n bá kú. Kò mọ ohunkóhun nípa ète Ọlọ́run pé ọjọ́ kan ń bọ̀ táwọn olóòótọ́ èèyàn yóò gbádùn ìwàláàyè pípé nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé. (Ìṣípayá 21:3, 4) Ohun mìíràn tún wà tí kò mọ̀. Kò mọ̀ pé nísinsìnyí pàápàá, òun lè wà nínú párádísè tẹ̀mí.
Ǹjẹ́ o ti gbọ́ nípa párádísè tẹ̀mí yẹn rí? Ǹjẹ́ o mọ ohun tó jẹ́ àti ohun tóo gbọ́dọ̀ ṣe tóo bá fẹ́ jẹ́ apá kan rẹ̀? Ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ ní ayọ̀ tòótọ́ gbọ́dọ̀ mọ̀ nípa párádísè yẹn.
Wíwá Párádísè Tẹ̀mí Náà Rí
Sísọ pé èèyàn lè wà nínú párádísè kan lóde òní pàápàá lè dún bí àlá tí kò lè ṣẹ. Ayé yìí kò jọ Párádísè rárá. Àwọn èèyàn tó pọ̀ gan-an ló ń fojú winá ohun tí ọba Hébérù ìgbàanì kan ṣàpèjúwe pé: “Wò ó! omijé àwọn tí a ń ni lára, ṣùgbọ́n wọn kò ní olùtùnú; ọ̀dọ̀ àwọn tí ń ni wọ́n lára sì ni agbára wà, tí ó fi jẹ́ pé wọn kò ní olùtùnú.” (Oníwàásù 4:1) Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ lọ́nà ọgọ́rọ̀ọ̀rún èèyàn ló ń jìyà lábẹ́ ètò tó ti díbàjẹ́ ní ti ọ̀ràn òṣèlú, ti ìsìn, àti ti ìṣúnná owó, tí wọn kò sì ní ìtura, tí kò sí “olùtùnú.” Ọ̀pọ̀ àwọn mìíràn ń làkàkà láti san gbèsè tó wà lọ́rùn wọn, láti tọ́ àwọn ọmọ wọn, kí wọ́n sì ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan mìíràn tó pọndandan láti ṣe kí nǹkan lè máa lọ déédéé. Ó ṣeé ṣe kí àwọn wọ̀nyí náà máa wá olùtùnú, ìyẹn ẹni tí yóò mú ẹrù ìnira wọn fúyẹ́ díẹ̀. Fún gbogbo wọn, ìgbésí ayé jìnnà pátápátá sí ipò tó rí bíi párádísè.
Ibo wá ni párádísè tẹ̀mí wà? Tóò, gbogbo ọ̀rọ̀ Gíríìkì àti ti Hébérù táa tú sí “Párádísè” ló ní èrò nípa ọgbà ìtura tàbí ọgbà, ìyẹn ibì kan tó lálàáfíà, téèyàn ti lè najú kí agbára rẹ̀ sì dọ̀tun. Bíbélì ṣèlérí pé ìgbà kan ń bọ̀ tí ayé yìí yóò di Párádísè táa lè fojú rí, ìyẹn ibùgbé tó dà bí ọgbà ìtura fún ìran ènìyàn aláìlẹ́ṣẹ̀. (Sáàmù 37:10, 11) Pẹ̀lú ìyẹn lọ́kàn, a rí i pé párádísè tẹ̀mí jẹ́ àyíká kan tó ń fini lọ́kàn balẹ̀, tó sì ń tuni lára, tó ń fúnni láǹfààní láti gbádùn àlàáfíà pẹ̀lú ènìyàn ẹlẹgbẹ́ ẹni àti pẹ̀lú Ọlọ́run. Gẹ́gẹ́ bí Gustavo ṣe wá rí i, irú párádísè bẹ́ẹ̀ wà lóde òní, àwọn èèyàn sì ń rọ́ lọ síbẹ̀.
Nígbà tí Gustavo wà lọ́mọ ọdún méjìlá, ó pinnu pé òun fẹ́ di àlùfáà Roman Kátólíìkì. Nítorí pé inú àwọn òbí rẹ̀ dùn sí i, ó lọ sí ilé ẹ̀kọ́ṣẹ́ àlùfáà. Ibẹ̀ ló ti bẹ̀rẹ̀ sí kópa nínú orin kíkọ, eré orí ìtàgé, àti ìṣèlú, èyí tí àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì náà ń ṣe láti fa àwọn ọ̀dọ́ mọ́ra. Ó mọ̀ pé ohun tó yẹ kí àlùfáà ṣe ni pé kó fi ara rẹ̀ jin àwọn èèyàn, kí ó má sì gbéyàwó. Síbẹ̀ àwọn kan lára àwọn àlùfáà àtàwọn tí ń kọ́ṣẹ́ àlùfáà tí Gustavo mọ̀ máa ń lọ́wọ́ nínú ìwà pálapàla. Ìgbà tí Gustavo bá ara rẹ̀ nínú àyíká yẹn lòun náà bá bẹ̀rẹ̀ sí mutí yó kẹ́ri. Ó ṣe kedere pé kò tíì rí párádísè tẹ̀mí síbẹ̀.
Lọ́jọ́ kan, Gustavo ka ìwé àṣàrò kúkúrú Bíbélì kan tó sọ̀rọ̀ nípa Párádísè orí ilẹ̀ ayé. Ó jẹ́ kó ronú nípa ète ìgbésí ayé. Ó sọ pé: “Mo wá bẹ̀rẹ̀ sí ka Bíbélì ní gbogbo ìgbà, ṣùgbọ́n kò yé mi. Mi ò tiẹ̀ rí i pé Ọlọ́run ní orúkọ kan pàápàá.” Bó ṣe fi ilé ẹ̀kọ́ṣẹ́ àlùfáà náà sílẹ̀ nìyẹn, tó wá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kàn, pé kí wọ́n ran òun lọ́wọ́ láti lóye Bíbélì. Lẹ́yìn ìyẹn, kíá ló tẹ̀ síwájú, kò sì pẹ́ tó ya ìgbésí ayé rẹ̀ sí mímọ́ fún Ọlọ́run. Bí Gustavo ṣe bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ nípa párádísè tẹ̀mí nìyẹn.
Àwọn Èèyàn Kan fún Orúkọ Ọlọ́run
Gustavo kẹ́kọ̀ọ́ pé Jèhófà, orúkọ Ọlọ́run, kì í kàn-án ṣe ìsọfúnni àkọsẹ̀bá fún akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. (Ẹ́kísódù 6:3) Ó jẹ́ apá pàtàkì nínú ìjọsìn tòótọ́. Jésù kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti gbàdúrà pé: “Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, kí orúkọ rẹ di sísọ di mímọ́.” (Mátíù 6:9) Nígbà ti ọmọ ẹ̀yìn nì, Jákọ́bù ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn Kèfèrí tó di Kristẹni, ó sọ pé: “Ọlọ́run ti yí àfiyèsí rẹ̀ sí àwọn orílẹ̀-èdè . . . láti mú àwọn ènìyàn kan fún orúkọ rẹ̀ jáde láti inú wọn.” (Ìṣe 15:14) Ní ọ̀rúndún kìíní, “àwọn ènìyàn kan fún orúkọ rẹ̀” ni ìjọ Kristẹni. Ǹjẹ́ àwọn èèyàn kan wà fún orúkọ Ọlọ́run lónìí? Bẹ́ẹ̀ ni o, Gustavo wá mọ̀ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà làwọn èèyàn náà.
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe iṣẹ́ àṣekára ní àwọn ilẹ̀ àti ìpínlẹ̀ igba ó lé márùnlélọ́gbọ̀n [235]. Iye wọn kọjá mílíọ̀nù mẹ́fà àwọn òjíṣẹ́, àwọn mílíọ̀nù mẹ́jọ mìíràn tí wọ́n jẹ́ olùfìfẹ́hàn sì ti wá sí àwọn ìpàdé wọn. A mọ̀ wọ́n dunjú mọ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn fún gbogbo ènìyàn, wọ́n sì ń mú ọ̀rọ̀ Jésù ṣẹ pé: “A ó sì wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè.” (Mátíù 24:14) Àmọ́, èé ṣe tí Gustavo fi gbà pé òun ti rí párádísè tẹ̀mí nígbà tó dara pọ̀ mọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà? Ó sọ pé: “Mo fi ohun tí mo ti rí nínú ayé àti pàápàá nínú ilé ẹ̀kọ́ṣẹ́ àlùfáà wé ohun tí mo rí láàárín àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ìyàtọ̀ gíga tí mo rí níbẹ̀ ni ìfẹ́ tó wà láàárín àwọn Ẹlẹ́rìí.”
Àwọn ẹlòmíràn ti sọ ohun kan náà nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Miriam, ọ̀dọ́mọbìnrin ará Brazil kan sọ pé: “Mi ò mọ̀ béèyàn ṣe ń láyọ̀, kódà nínú ìdílé mi pàápàá. Àárín àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni mo ti kọ́kọ́ rí bí ìfẹ́ ṣe ń ṣiṣẹ́.” Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Christian sọ pé: “Mo máa ń bẹ́mìí lò lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àmọ́ ìsìn kò jẹ́ nǹkan kan lójú mi. Ohun tó ká mi lára ni ipò tí mo wà láwùjọ àti iṣẹ́ mi gẹ́gẹ́ bí onímọ̀ ẹ̀rọ. Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí bá ìyàwó mi ṣèkẹ́kọ̀ọ́, mo rí ìyàtọ̀ nínú ìwà rẹ̀. Ayọ̀ àti ìtara tí àwọn obìnrin Kristẹni tó máa ń bẹ̀ ẹ́ wò ní tún wú mi lórí gan-an.” Kí ló ń mú káwọn èèyàn sọ irú nǹkan bẹ́ẹ̀ nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà?
Kí Ni Párádísè Tẹ̀mí?
Ohun kan tó mú kí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yàtọ̀ ni bí wọ́n ṣe mọyì ìmọ̀ Bíbélì. Wọ́n gbà gbọ́ pé Bíbélì jẹ́ òótọ́ àti pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni. Ìdí nìyẹn tí wọn kì í sọ pé táwọn bá sáà ti mọ àwọn ìpìlẹ̀ ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn wọn, ọ̀rọ̀ ti bùṣe. Wọ́n ní àwọn ìtòlẹ́sẹẹsẹ tí wọ́n máa ń lò fún ìdákẹ́kọ̀ọ́ àti Bíbélì kíkà ní gbogbo ìgbà. Béèyàn bá ṣe dara pọ̀ mọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pẹ́ tó ni yóò túbọ̀ kọ́ nípa Ọlọ́run àti ìfẹ́ Rẹ̀ táa ṣí payá nínú Bíbélì.
Irú ìmọ̀ bẹ́ẹ̀ ló sọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà dòmìnira kúrò lọ́wọ́ àwọn nǹkan tí kì í mú káwọn èèyàn láyọ̀, ìyẹn àwọn nǹkan bí ìgbàgbọ́ nínú ohun asán àti àwọn èrò tí ń pani lára. Jésù sọ pé: “Òtítọ́ yóò sì dá yín sílẹ̀ lómìnira,” àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sì rí i pé bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ ló rí. (Jòhánù 8:32) Fernando tó ń fìgbà kan bẹ́mìí lò sọ pé: “Kíkẹ́kọ̀ọ́ nípa ìyè àìnípẹ̀kun jẹ́ ìtura ńlá. Mo máa ń bẹ̀rù pé yálà èmi tàbí àwọn òbí mi lè kú.” Òtítọ́ sọ Fernando dòmìnira kúrò lọ́wọ́ ìbẹ̀rù àwọn ẹ̀mí àìrí àti ohun tí wọ́n ń pè ní ìwàláàyè lẹ́yìn ikú.
Nínú Bíbélì, ìmọ̀ nípa Ọlọ́run ní í ṣe pẹ̀lú Párádísè. Wòlíì Aísáyà sọ pé: “Wọn kì yóò ṣe ìpalára èyíkéyìí, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò fa ìparun èyíkéyìí ní gbogbo òkè ńlá mímọ́ mi; nítorí pé, ṣe ni ilẹ̀ ayé yóò kún fún ìmọ̀ Jèhófà bí omi ti bo òkun.”—Aísáyà 11:9.
Àmọ́ ṣá o, ìmọ̀ nìkan kò tó láti mú àlàáfíà tí Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ wá. Èèyàn gbọ́dọ̀ fi ohun tó ń kọ́ sílò. Ohun tí Fernando sọ nìyí: “Nígbà tẹ́nì kan bá mú àwọn èso tẹ̀mí dàgbà, ó ń fi kún párádísè tẹ̀mí nìyẹn.” Fernando ń tọ́ka sí àwọn ọ̀rọ̀ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, ẹni tó pe àwọn ànímọ́ rere tí Kristẹni gbọ́dọ̀ ní ní “èso ti ẹ̀mí.” Ó tò wọ́n lẹ́sẹẹsẹ, ó pè wọ́n ní “ìfẹ́, ìdùnnú, àlàáfíà, ìpamọ́ra, inú rere, ìwà rere, ìgbàgbọ́, ìwà tútù, ìkóra-ẹni-níjàánu.”—Gálátíà 5:22, 23.
Ṣé o wá rídìí tí dídarapọ̀ mọ́ àwùjọ àwọn èèyàn tó ń tiraka láti mú irú àwọn ànímọ́ bẹ́ẹ̀ dàgbà yóò fi rí bíi pé èèyàn wà nínú párádísè ní tòótọ́? Párádísè tẹ̀mí tí wòlíì Sefanáyà sọ tẹ́lẹ̀ yóò wà láàárín irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀. Ó sọ pé: “Wọn kì yóò ṣe àìṣòdodo, tàbí kí wọ́n pa irọ́, bẹ́ẹ̀ ni a kì yóò rí ahọ́n àgálámàṣà ní ẹnu wọn; nítorí àwọn fúnra wọn yóò jẹun, wọn yóò sì nà gbalaja ní ti tòótọ́, kò sì sí ẹnì kankan tí yóò máa mú wọn wárìrì.”—Sefanáyà 3:13.
Ipa Pàtàkì Tí Ìfẹ́ Kó
O ti lè ṣàkíyèsí pé èkíní nínú àwọn èso tẹ̀mí tí Pọ́ọ̀lù mẹ́nu kàn ni ìfẹ́. Èyí jẹ́ ànímọ́ tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ gan-an. Jésù sọ pé: “Nípa èyí ni gbogbo ènìyàn yóò fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, bí ẹ bá ní ìfẹ́ láàárín ara yín.” (Jòhánù 13:35) Lóòótọ́, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í ṣẹni pípé o. Wọ́n ń ní èdèkòyédè láàárín ara wọn lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, bíi tàwọn àpọ́sítélì Jésù. Àmọ́, wọ́n nífẹ̀ẹ́ ara wọn ní ti tòótọ́, wọ́n sì máa ń gbàdúrà fún ìtìlẹ́yìn ẹ̀mí mímọ́ bí wọ́n ṣe ń mú ànímọ́ yìí dàgbà.
Ìdí nìyẹn tí ìfararora àárín wọn fi jẹ́ àrà ọ̀tọ̀. Kò sóhun tó ń jẹ́ ẹlẹ́yàmẹ̀yà tàbí ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni láàárín wọn. Àní sẹ́, ọ̀pọ̀ Ẹlẹ́rìí tó bá ara wọn láàárín àwọn ẹ̀yà àti ìran kan tó fẹ́ pa ara wọn run láàárín àwọn ọdún tó kẹ́yìn nínú ọ̀rúndún ogún dáàbò bo ara wọn lẹ́nì kìíní kejì, kódà nígbà tí ẹ̀mí tiwọn alára lè lọ sí i. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n jáde wá “láti inú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ènìyàn àti ahọ́n,” wọ́n ń gbádùn ìṣọ̀kan tó ṣòro láti lóye àyàfi tóo bá tọ́ ọ wò.—Ìṣípayá 7:9.
Párádísè Láàárín Àwọn Tó Ṣe Ìfẹ́ Ọlọ́run
Kò sáyè fún ìwọra, ìwà pálapàla, àti ìmọtara-ẹni-nìkan nínú párádísè tẹ̀mí. A sọ fún àwọn Kristẹni pé: “Ẹ jáwọ́ nínú dídáṣà ní àfarawé ètò àwọn nǹkan yìí, ṣùgbọ́n ẹ para dà nípa yíyí èrò inú yín padà, kí ẹ lè ṣàwárí fúnra yín ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó dára, tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà, tí ó sì pé.” (Róòmù 12:2) Nígbà táa bá ń gbé ìgbésí ayé tó mọ́ tónítóní, tó jẹ́ ti ìwà rere, táa sì ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run láwọn ọ̀nà mìíràn, a ń ṣèrànwọ́ láti kọ́ párádísè tẹ̀mí nìyẹn, a sì ń fi kún ayọ̀ tiwa fúnra wa. Carla rí i pé òótọ́ pọ́ńbélé nìyí. Ó sọ pé: “Bàbá mi kọ́ mi pé kí n ṣe iṣẹ́ àṣekára kí n lè gbọ́ bùkátà ara mi. Àmọ́, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀kọ́ tí mo kọ́ ní yunifásítì jẹ́ kí n mọ̀ pé ẹ̀mí mi dè, síbẹ̀ mo pàdánù ìṣọ̀kan ìdílé àti ààbò tí kìkì ìmọ̀ látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lè fún wa.”
Ní ti tòótọ́, gbígbádùn párádísè tẹ̀mí kò mú àwọn ìṣòro inú ìgbésí ayé kúrò. Àwọn Kristẹni ṣì máa ń ṣàìsàn. Ogun abẹ́lé lè máa jà lórílẹ̀-èdè tí wọ́n ń gbé. Ọ̀pọ̀ ló ń fara da ipò òṣì. Síbẹ̀síbẹ̀, níní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run—èyí tó jẹ́ apá pàtàkì jù lọ nínú párádísè tẹ̀mí—túmọ̀ sí pé a lè yíjú sí i fún ìtìlẹ́yìn. Àní sẹ́, ó ké sí wa pé kí a ‘ju ẹrù ìnira wa sọ́dọ̀ òun,’ ọ̀pọ̀ ló sì lè jẹ́rìí sí ọ̀nà àgbàyanu tó gbà tì wọ́n lẹ́yìn nígbà tí wọ́n wà nínú ipò tó le koko. (Sáàmù 55:22; 86:16, 17) Ọlọ́run ṣèlérí láti wà pẹ̀lú àwọn olùjọsìn rẹ̀, kódà nínú “àfonífojì ibú òjìji.” (Sáàmù 23:4) Níní ìdánilójú pé Ọlọ́run ṣe tán láti tì wá lẹ́yìn ń ràn wá lọ́wọ́ láti ní “àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ,” èyí tó mú kí párádísè tẹ̀mí ṣeé ṣe.—Fílípì 4:7.
Kíkọ́wọ́ti Párádísè Tẹ̀mí
Ọ̀pọ̀ jù lọ ló máa ń fẹ́ ṣèbẹ̀wò sí ọgbà ìtura tàbí ọgbà ọ̀gbìn. Wọ́n máa ń fẹ́ káwọn máa rìn káàkiri ibẹ̀ tàbí kí wọ́n jókòó sórí bẹ́ǹṣì kí wọ́n sì gbádùn àyíká náà. Lọ́nà kan náà, ọ̀pọ̀ ló máa ń gbádùn bíbá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kẹ́gbẹ́. Wọ́n rí i pé ìbákẹ́gbẹ́ náà ń tuni lára, ó ń fúnni ní àlàáfíà, ó sì ń sọ agbára ẹni dọ̀tun. Àmọ́, a gbọ́dọ̀ máa tọ́jú ọgbà rírẹwà kan bí a bá fẹ́ kó máa rí bíi párádísè lọ. Bákan náà, párádísè tẹ̀mí wà nínú ayé tó yàtọ̀ pátápátá sí Párádísè yìí kìkì nítorí pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń mú un dàgbà, Ọlọ́run sì ń bù kún ìsapá wọn. Báwo ni ẹnì kan ṣe lè kó ipa pàtàkì nínú kíkọ́wọ́ti párádísè yẹn?
Lákọ̀ọ́kọ́, o gbọ́dọ̀ dara pọ̀ mọ́ ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, kí o kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ wọn, kí o sì gba ìmọ̀ Bíbélì tó jẹ́ ìpìlẹ̀ fún párádísè tẹ̀mí. Carla sọ pé: “Kò lè sí párádísè tẹ̀mí bí kò bá sí oúnjẹ tẹ̀mí.” Èyí ní kíka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé nínú, àti ríronú lórí ohun tóo kà. Ìmọ̀ tóo bá gbà yóò mú ọ túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà Ọlọ́run, wàá sì wá nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Wàá tún kọ́ bóo ṣe máa bá a sọ̀rọ̀ nínú àdúrà, tí wàá sì máa béèrè pé kó tọ́ ọ sọ́nà, kí ó sì fún ọ ní ẹ̀mí rẹ̀ tí yóò máa tì ọ́ lẹ́yìn bóo ṣe ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Jésù sọ pé ká máa tẹra mọ́ àdúrà gbígbà. (Lúùkù 11:9-13) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ẹ máa gbàdúrà láìdabọ̀.” (1 Tẹsalóníkà 5:17) Àǹfààní bíbá Ọlọ́run sọ̀rọ̀ nínú àdúrà pẹ̀lú ìdánilójú pé ó ń gbọ́ àdúrà rẹ jẹ́ apá pàtàkì nínú párádísè tẹ̀mí.
Bí àkókò ti ń lọ, ohun tóo ń kọ́ yóò tún ìgbésí ayé rẹ ṣe, ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, wàá fẹ́ bá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Ìgbà yẹn ló máa lè ṣègbọràn sí àṣẹ Jésù pé: “Kí ìmọ́lẹ̀ yín máa tàn níwájú àwọn ènìyàn, kí wọ́n lè rí àwọn iṣẹ́ àtàtà yín, kí wọ́n sì lè fi ògo fún Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run.” (Mátíù 5:16) Bíbá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀ nípa ìmọ̀ Jèhófà Ọlọ́run àti ti Jésù Kristi, kí o sì máa kókìkí ìfẹ́ gíga tí wọ́n ti fi hàn sí aráyé ń mú ayọ̀ púpọ̀ wá.
Àkókò ń bọ̀ tí gbogbo ayé yóò jẹ́ Párádísè táa lè fojú rí—ìyẹn ibì kan tó dà bí ọgbà ìtura, tí kò ti ní sí ìbàyíkájẹ́, tó sì máa jẹ́ ilé tó dára fún ìran ènìyàn olóòótọ́. Wíwà tí párádísè tẹ̀mí wà ní “àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò” wọ̀nyí jẹ́ ẹ̀rí agbára Ọlọ́run àti àpẹẹrẹ ohun tó máa ṣe lọ́jọ́ iwájú.—2 Tímótì 3:1.
Nísinsìnyí pàápàá, àwọn tó ń gbádùn párádísè tẹ̀mí ń rí ìmúṣẹ nípa tẹ̀mí tó wà nínú ìwé Aísáyà 49:10, tó kà pé: “Ebi kì yóò pa wọ́n, bẹ́ẹ̀ ni òùngbẹ kì yóò gbẹ wọ́n, tàbí kí ooru amóhungbẹ hán-ún hán-ún mú wọn tàbí kí oòrùn pa wọ́n. Nítorí pé Ẹni tí ń ṣe ojú àánú sí wọn yóò ṣamọ̀nà wọn, ẹ̀bá àwọn ìsun omi sì ni yóò darí wọn lọ.” José á jẹ́rìí sí i pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yẹn. Ó ń lépa àtidi gbajúgbajà olórin, ṣùgbọ́n ó rí ìtẹ́lọ́rùn tó ju ìyẹn lọ nínú sísin Ọlọ́run pẹ̀lú ìjọ Kristẹni. Ó sọ pé: “Nísinsìnyí, mò ń gbé ìgbésí ayé tó nítumọ̀. Ọkàn mi balẹ̀ láàárín ẹgbẹ́ àwọn ará Kristẹni, mo sì mọ Jèhófà gẹ́gẹ́ bí Baba onífẹ̀ẹ́ táa lè gbẹ́kẹ̀ lé. Ayọ̀ tí José ní—àti èyí tí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ mìíràn ní nínú párádísè tẹ̀mí náà—la ṣàpèjúwe rẹ̀ dáadáa nínú Sáàmù 64:10 pé: “Olódodo yóò sì máa yọ̀ nínú Jèhófà, yóò sì sá di í ní tòótọ́.” Àpèjúwe yìí mà bá párádísè tẹ̀mí mu o!
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwọn èèyàn táa mẹ́nu kàn níhìn-ín kì í ṣe àròsọ, àmọ́ a ti yí àwọn orúkọ kan padà.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Bóo ṣe ń gbádùn párádísè tẹ̀mí náà, ṣèrànwọ́ láti mú un gbòòrò sí i!