Ìtàn Ìgbésí Ayé
Jèhófà Ti Mẹ́sẹ̀ Mi Dúró ní Gbogbo Ọjọ́ Ayé Mi
GẸ́GẸ́ BÍ FORREST LEE ṢE SỌ Ọ́
Àwọn ọlọ́pàá ṣẹ̀ṣẹ̀ gba giramọfóònù wa àtàwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa ni. Ogun Àgbáyé Kejì làwọn alátakò fi kẹ́wọ́, tí wọ́n ń rọ alákòóso tuntun ní Kánádà pé kó kéde pé iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lòdì sófin. Ìkéde yìí wáyé ní July 4, 1940.
OHUN tó ṣẹlẹ̀ yìí kò mú wa rẹ̀wẹ̀sì rárá. Ńṣe la tún lọ kó ìwé níbi táa kó o pa mọ́ sí, táa sì ń bá iṣẹ́ ìwàásù wa lọ. Mi ò jẹ́ gbàgbé ohun tí bàbá mi sọ nígbà tí ọ̀ràn yẹn ṣẹlẹ̀, ó ní: “A ò lè jáwọ́ wẹ́rẹ́ báyẹn. Jèhófà ló pàṣẹ pé ká máa wàásù.” Nígbà yẹn, ọmọ ọdún mẹ́wàá tí ń tọ pọ́n-ún pọ́n-ún ni mí. Àmọ́ títí dòní, ìgbà gbogbo ṣì ni ìpinnu bàbá mi àti ìtara rẹ̀ fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ ń rán mi létí bí Jèhófà, Ọlọ́run wa, ṣe ń mẹ́sẹ̀ àwọn tó ṣe olóòótọ́ sí i dúró.
Ẹlẹ́ẹ̀kejì táwọn ọlọ́pàá dá wa dúró, wọn ò fi mọ sórí gbígba àwọn ìwé wa nìkan, wọ́n tún fi bàbá mi sí àtìmọ́lé, ó wá ku màmá mi nìkan àtọmọ mẹ́rin. Ìyẹn ṣẹlẹ̀ ní September 1940 ní Ìpínlẹ̀ Saskatchewan. Àìpẹ́ lẹ́yìn náà ni wọ́n lé mi kúrò ní iléèwé nítorí pé mo ṣègbọràn sí ẹ̀rí ọkàn mi tí mo fi Bíbélì kọ́, tí mo kọ̀ láti kí àsíá àti láti kọ orin orílẹ̀-èdè. Bíbá ẹ̀kọ́ mi lọ nípasẹ̀ iléèwé àgbélékà jẹ́ kí n lè ṣètò àkókò mi bó ṣe wù mí, mo sì túbọ̀ kópa ní kíkún nínú iṣẹ́ ìwàásù.
Ní 1948, ìpè kan dún pé a ń fẹ́ kí àwọn aṣáájú ọ̀nà, ìyẹn àwọn òjíṣẹ́ alákòókò kíkún ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ṣí lọ sí etíkun ìlà oòrùn Kánádà. Bí mo ṣe gbéra nìyẹn, tí mo lọ ṣe aṣáájú ọ̀nà nílùú Halifax, ní Ìpínlẹ̀ Nova Scotia, àti ní Cape Wolfe, tó wà ní Erékùṣù Prince Edward. Lọ́dún tó tẹ̀ lé e, mo tẹ́wọ́ gba ìkésíni láti wá ṣiṣẹ́ fún ọ̀sẹ̀ méjì ní ẹ̀ka iléeṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Toronto. Ọ̀sẹ̀ méjì yẹn wá di ohun tó lé ní ọdún mẹ́fà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn tó lérè nínú. Ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, mo pàdé Myrna, tóun náà ní irú ìfẹ́ tí mo ní fún Jèhófà, a sì ṣe ìgbéyàwó ní December 1955. Ìlú Milton, ní Ìpínlẹ̀ Ontario, la fìdí kalẹ̀ sí, kò sì pẹ́ táa fi dá ìjọ tuntun sílẹ̀ níbẹ̀. Yàrá ìsàlẹ̀ ilé wa ló wá di Gbọ̀ngàn Ìjọba.
Ìfẹ́ Wa Láti Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Wa Gbòòrò sí I
Ní àwọn ọdún tó tẹ̀ lé e, a di òbí ọmọ mẹ́fà ní wàràwàrà. Miriam ọmọbìnrin wa ni àkọ́bí. Lẹ́yìn rẹ̀ la bí Charmaine, Mark, Annette, Grant, àti níkẹyìn Glen. Nígbà tí mo bá ń tibi iṣẹ́ bọ̀, mo sábà máa ń bá àwọn ọmọ kéékèèké wọ̀nyí tí wọ́n jókòó sórí ilẹ̀ pẹ̀pẹ̀ yí iná ká, bí Myrna ti ń ka Bíbélì sí wọn létí, tó ń ṣàlàyé àwọn ìtàn inú Bíbélì fún wọn, tó sì ń gbin ojúlówó ìfẹ́ fún Jèhófà sí wọn lọ́kàn. Ọpẹ́lọpẹ́ ìtìlẹyìn onífẹ̀ẹ́ rẹ̀, ìyẹn ló jẹ́ kí gbogbo àwọn ọmọ wa ní òye tó jinlẹ̀ nípa Bíbélì nígbà tí wọ́n ṣì kéré lọ́jọ́ orí.
Ìtara tí bàbá mi ní fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà ti wọ̀ mí lọ́kàn ṣinṣin. (Òwe 22:6) Ìyẹn ló fi jẹ́ pé nígbà tí wọ́n ní kí àwọn ìdílé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣí lọ sáwọn orílẹ̀-èdè kan ní Àárín Gbùngbùn àti Gúúsù Amẹ́ríkà láti lọ kọ́wọ́ ti iṣẹ́ ìwàásù lẹ́yìn níbẹ̀, ìdílé wa fẹ́ láti dáhùn sí ìkésíni náà. Nígbà yẹn, ọjọ́ orí àwọn ọmọ wa jẹ́ láti ọdún márùn-ún sí mẹ́tàlá, kò sì sẹ́nì kankan nínú wa tó gbọ́ á-á nínú èdè Spanish. Gẹ́gẹ́ bí ìtọ́ni táa rí gbà, mo lọ yẹ àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyẹn wò, láti lè mọ bí ipò nǹkan ti rí níbẹ̀. Lẹ́yìn tí mo padà dé, gẹ́gẹ́ bí ìdílé, a gbé ibi tí a óò ṣí lọ yẹ̀ wò tàdúrà-tàdúrà, a sì pinnu láti lọ sí Nicaragua.
Sísìn ní Nicaragua
Nígbà tó fi máa di October 1970, a ti wà nílé wa tuntun. Láàárín ọ̀sẹ̀ mẹ́ta, wọ́n ti yan iṣẹ́ kékeré kan fún mi nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìpàdé ìjọ. Mo sáà ń sọ ìwọ̀nba táátààtá tí mo gbọ́ nínú èdè Spanish nínú iṣẹ́ yẹn, mo sì kádìí rẹ̀ nípa sísọ pé kí gbogbo ìjọ wá sílé wa fún cerveza lọ́jọ́ Sátidé ní agogo mẹ́sàn-án ààbọ̀ òwúrọ̀. Ohun tí mo fẹ́ sọ ni servicio, ìyẹn ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń lò fún iṣẹ́ ìsìn pápá, àmọ́ ńṣe ni mo ní kí gbogbo èèyàn máa bọ̀ wá mu bíà. Kí n sòótọ́, èdè yẹn ṣòroó gbọ́ o!
Níbẹ̀rẹ̀, ńṣe ni màá kọ ohun tí mo fẹ́ sọ sínú ìwé, tí màá sì máa fi dánra wò bí mo ti ń sún mọ́ ẹnu ọ̀nà. Màá sọ pé: “Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́fẹ̀ẹ́ wà fún ẹnikẹ́ni tó bá gba ìwé yìí.” Ẹnì kan tó tẹ́wọ́ gba ìfilọni yìí sọ lẹ́yìn náà pé, àfi tóun bá wá sípàdé wa nìkan lòun fi lè mọ ohun tí mo ń gbìyànjú láti sọ. Ọkùnrin yìí di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ẹ wo bó ti ṣe kedere tó pé Ọlọ́run ló ń mú kí irúgbìn òtítọ́ hù nínú ọkàn-àyà àwọn onírẹ̀lẹ̀, gan-an gẹ́gẹ́ bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe sọ!—1 Kọ́ríńtì 3:7.
Lẹ́yìn nǹkan bí ọdún méjì ní Managua tí í ṣe olú ìlú, wọ́n ní ká ṣí lọ síhà gúúsù Nicaragua. Ibẹ̀ la ti bá ìjọ tí ń bẹ ní Rivas àti àwùjọ àwọn olùfìfẹ́hàn tó wà ní àdádó ṣiṣẹ́. Pedro Peña, Ẹlẹ́rìí olóòótọ́ kan tó jẹ́ àgbàlagbà, máa ń bá mi lọ nígbà tí mo lọ ń bẹ àwùjọ wọ̀nyí wò. Ọ̀kan wà ní erékùṣù ayọnáyèéfín tí ń bẹ ni Adágún Nicaragua, níbi tó jẹ́ pé ìdílé Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan ṣoṣo ló wà níbẹ̀.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìdílé yìí kò fi bẹ́ẹ̀ ní lọ́wọ́ nípa tara, wọ́n máa ń sapá gidigidi láti fi ìmọrírì hàn fún ìbẹ̀wò wa. Lálẹ́ ọjọ́ táa débẹ̀, oúnjẹ ti ń dúró dè wá. Ọ̀sẹ̀ kan la fi wà níbẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn ọmọlúwàbí tó fẹ́ràn Bíbélì níbẹ̀ sì ń fi oúnjẹ wọn bọ́ wa. Inú wa dùn gan-an nígbà téèyàn mọ́kànlélọ́gọ́rùn-ún [101] wá síbi àsọyé Bíbélì táa sọ fún gbogbo èèyàn lọ́jọ́ Sunday.
Mo gbà pé agbára Jèhófà ló mẹ́sẹ̀ mi dúró nígbà kan tó yẹ ká bẹ àwùjọ àwọn olùfìfẹ́hàn kan wò ní àwọn àgbègbè olókè tó wà lẹ́bàá ààlà orílẹ̀-èdè Costa Rica. Lọ́jọ́ tó yẹ ká lọ, Pedro wá bá mi ká jọ máa lọ, ṣùgbọ́n ibà dá mi wó sórí bẹ́ẹ̀dì. Mo sọ pé: “Pedro, mi ò ní lè lọ o.” Ó fọwọ́ kan iwájú orí mi, ó sì fèsì pé: “Akọ ibà ló ń ṣe ọ́ yìí, àmọ́ ó di dandan kóo lọ! Àwọn ará ń retí wa.” Ó wá gba àdúrà àtọkànwá kan, tí n kò gbọ́ irú rẹ̀ rí.
Lẹ́yìn náà, mo sọ pé: “Dìde lọ wá fresco (ohun mímu eléso) tí wàá mu. Màá ṣe tán láàárín nǹkan bí ìṣẹ́jú mẹ́wàá.” Àwọn ìdílé Ẹlẹ́rìí méjì ló wà ní àgbègbè táa lọ bẹ̀ wò, wọ́n sì tọ́jú wa dáadáa. Ní ọjọ́ tó tẹ̀ lé e, àwa àtàwọn jọ lọ wàásù, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ibà yẹn ṣì ń gbò mí. Ẹ wo bó ti ń fúnni lókun tó láti rí àwọn tó lé ní ọgọ́rùn-ún tó wá sípàdé wa ọjọ́ Sunday!
A Tún Gbéra
Ọdún 1975 la bí Vaughn, ọmọ wa keje. Lọ́dún tó tẹ̀ lé e, ó di dandan láti padà sí Kánádà nítorí ìṣúnná owó. Kò rọrùn láti fi Nicaragua sílẹ̀ nítorí a ti rí i bí agbára Jèhófà ti mẹ́sẹ̀ wa dúró lóòótọ́. Nígbà táa fẹ́ kúrò, ó ti lé ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500] tó ń wá sípàdé ní ìpínlẹ̀ ìjọ wa.
Kó tó dìgbà yẹn, nígbà tí wọ́n yan èmi àti Miriam ọmọbìnrin wa gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà àkànṣe ní Nicaragua, Miriam bi mí pé: “Dádì, bó bá di dandan pé kí ẹ padà sí Kánádà lọ́jọ́ kan, ṣé ẹ máa jẹ́ kí n dúró síhìn-ín?” Níwọ̀n bí mi ò ti gbèrò àtipadà rárá, mo dá a lóhùn pé: “Dájúdájú, màá jẹ́ kóo dúró!” Ìyẹn ló fi jẹ́ pé nígbà táa kúrò níbẹ̀, Miriam ń bá iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún rẹ̀ nìṣó níbẹ̀. Nígbà tó yá, ó fẹ́ Andrew Reed. Ní 1984, wọ́n lọ sí kíláàsì kẹtàdínlọ́gọ́rin ti ilé ẹ̀kọ́ Gílíádì, ìyẹn ilé ẹ̀kọ́ fáwọn míṣọ́nnárì Ẹlẹ́rìí Jèhófà, èyí tó wà ní Brooklyn, New York nígbà yẹn. Miriam àti ọkọ rẹ̀ ń sìn báyìí ní Dominican Republic, ó ń mú ìfẹ́ táwọn míṣọ́nnárì àtàtà tó wà ní Nicaragua gbìn sí i lọ́kàn ṣẹ.
Ní gbogbo àkókò yìí, ọ̀rọ̀ bàbá mi pé, “a ò lè jáwọ́ wẹ́rẹ́ báyẹn,” ṣì ń gbún ọkàn mi ní kẹ́ṣẹ́. Nítorí náà, nígbà tó di 1981, táa ti ní owó tó pọ̀ tó láti padà sí Àárín Gbùngbùn Amẹ́ríkà, a tún gbéra, lọ́tẹ̀ yìí, ó di Costa Rica. Nígbà táa ń sìn níbẹ̀ ni wọ́n ní ká wá bá àwọn kọ́wọ́ ti iṣẹ́ kíkọ́ ẹ̀ka iléeṣẹ́ tuntun. Àmọ́ ní 1985, ọ̀ràn ìlera Grant ọmọkùnrin wa ń fẹ́ àbójútó, fún ìdí yìí, a padà sí Kánádà. Glen dúró sí Costa Rica láti bá wọn kọ́ ẹ̀ka iléeṣẹ́ náà, nígbà tí Annette àti Charmaine ń sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà àkànṣe. Àwa táa fi Costa Rica sílẹ̀ kò mọ̀ láé pé a ò ní padà síbẹ̀.
Kíkojú Àgbákò
Nígbà tí ojúmọ́ September 17, 1993 mọ́, oòrùn yọ, ojú ọjọ́ sì dára. Èmi àti Mark, àkọ́bí wa ọkùnrin, jọ ń tún òrùlé ṣe. A ń ṣiṣẹ́ lẹ́gbẹ̀ẹ́ ara wa ni, a sì ń jíròrò àwọn nǹkan tẹ̀mí, bí ìṣe wa. Lọ́nà kan ṣá, ẹsẹ̀ mi yẹ̀ gẹ̀rẹ̀, mo sì já bọ́ látorí òrùlé. Ìgbà tí mo jí, gbogbo ohun tí mo rí ni àwọn iná tó tàn yòò, àtàwọn èèyàn tó wọ aṣọ funfun. Yàrá ìtọ́jú pàjáwìrì nílé ìwòsàn ni mo wà.
Nítorí ohun tí Bíbélì sọ, ohun tó kọ́kọ́ tẹnu mi jáde ni pé: “Mi ò gbẹ̀jẹ̀ o, mi ò gbẹ̀jẹ̀ o!” (Ìṣe 15:28, 29) Ẹ wo bí ọkàn mi ti balẹ̀ tó nígbà tí mo gbóhùn Charmaine tó sọ pé: “Dádì, kò síṣòro. Gbogbo wa wà ńbí.” Wọ́n sọ fún mi lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn pé àwọn dókítà rí ìwé àkọsílẹ̀ ìṣègùn mi, wọn ò sì fa wàhálà lórí ọ̀ràn ẹ̀jẹ̀. Ọrùn mi ti ṣẹ́, gbogbo ara mi sì ti rọ, mi ò tilẹ̀ lè dá mí mọ́.
Nísinsìnyí tí mi ò lè gbápá gbẹ́sẹ̀, Jèhófà nìkan ló lè mẹ́sẹ̀ mi dúró ju ti ìgbàkígbà rí lọ. Wọ́n ṣe iṣẹ́ abẹ kan ní ọ̀nà ọ̀fun mi láti fi ẹ̀rọ tí màá fi máa mí síbẹ̀, èyí wá dí ọ̀nà tí afẹ́fẹ́ ń gbà wọ àpò ohùn. Mi ò lè sọ̀rọ̀. Ńṣe làwọn èèyàn ní láti máa wo bí ètè mi ṣe ń mì, kí wọ́n tó lè mọ ohun tí mo fẹ́ sọ.
Kíá, ìnáwó ti wọ̀ wá lọ́rùn. Níwọ̀n bí èmi àti ìyàwó mi àti èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àwọn ọmọ mi ti wà nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún, mo bẹ̀rẹ̀ sí ronú pé àfàìmọ̀ ni wọn ò ní fi iṣẹ́ ìsìn yìí sílẹ̀ kí wọ́n lè bójú tó ẹrù ìnáwó yìí. Ṣùgbọ́n, Mark rí iṣẹ́ kan tó jẹ́ pé, láàárín oṣù mẹ́ta péré, owó iṣẹ́ rẹ̀ ti san èyí tó pọ̀ jù lọ nínú gbèsè náà. Fún ìdí yìí, gbogbo wọn ń bá iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún wọn nìṣó, àfi èmi àti ìyàwó mi.
Ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn káàdì ìkíni kára-ó-le àtàwọn lẹ́tà láti orílẹ̀-èdè mẹ́fà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni a tò sára ògiri yàrá mi ní ọsibítù. Jèhófà ló mẹ́sẹ̀ mi dúró lóòótọ́. Ìjọ pẹ̀lú ran ìdílé mi lọ́wọ́ nípa pípèsè oúnjẹ fún wọn láàárín oṣù márùn-ún ààbọ̀ tí mo fi wà ní wọ́ọ̀dù ìtọ́jú àkànṣe. Ojoojúmọ́ ni Kristẹni alàgbà kan máa ń wà pẹ̀lú mi lọ́sàn-án, tí á máa ka Bíbélì àtàwọn ìtẹ̀jáde Bíbélì sí mi létí, a tún máa sọ àwọn ìrírí tí ń fúnni níṣìírí. Méjì lára àwọn mẹ́ńbà ìdílé mi máa ń múra gbogbo ìpàdé ìjọ pẹ̀lú mi, fún ìdí yìí mi ò pàdánù oúnjẹ tẹ̀mí tó ṣe kókó.
Nígbà tí mo ṣì wà ní ọsibítù, wọ́n ṣètò pé kí n lọ sí àpéjọ àkànṣe. Àwọn òṣìṣẹ́ ọsibítù ṣètò pé kí nọ́ọ̀sì kan àti ẹnì kan tó mọ̀ nípa ẹ̀rọ tí mo fi ń mí, wà pẹ̀lú mi ṣúlẹ̀ ọjọ́ náà. Ẹ wo bí inú mi ti dùn tó láti tún wà pẹ̀lú àwọn Kristẹni arákùnrin àti arábìnrin mi! Láéláé mi ò lè gbàgbé rírí ọgọ́rọ̀ọ̀rún tí wọ́n tò sórí ìlà, tí wọ́n ń dúró láti kí mi.
Bíbójútó Ipò Tẹ̀mí Mi
Ní nǹkan bí ọdún kan lẹ́yìn jàǹbá náà, wọ́n gbé mi wálé, sọ́dọ̀ ìdílé mi, bó tiẹ̀ jẹ́ pé mo ṣì nílò ìtọ́jú ní gbogbo wákàtí ọjọ́. Ọkọ̀ kan tó jẹ́ àkànṣe ló ń gbé mi lọ sáwọn ìpàdé, nítorí náà n kì í sábàá pa ìpàdé jẹ. Àmọ́ kí n sòótọ́, ó gba ìpinnu. Gbogbo àpéjọpọ̀ àgbègbè ni mo ti ń lọ látìgbà tí mo ti padà wálé.
Ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, ní February 1997, ohùn mi là díẹ̀. Àwọn kan lára àwọn nọ́ọ̀sì mi fetí sílẹ̀ tọkàntara bí mo ṣe ń sọ fún wọn nípa ìrètí tí mo ní, èyí táa gbé ka Bíbélì. Nọ́ọ̀sì kan ti ka ìwé náà, Jehovah’s Witnesses—Proclaimers of God’s Kingdom sí mi létí látìbẹ̀rẹ̀ dópin, àtàwọn ìtẹ̀jáde Watch Tower mìíràn. Mo ń kọ̀wé sáwọn èèyàn nípa lílo ọ̀pá kékeré kan láti fi tẹ kọ̀ǹpútà. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé títẹ̀wé lọ́nà yìí nira gan-an, àǹfààní púpọ̀ wà nínú lílọ́wọ́ sí iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà.
Gbogbo iṣan ara ló máa ń ro mí gógó. Àmọ́ ó dà bíi pé ara máa ń tù mí nígbà tí mo bá ń jíròrò àwọn òtítọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwọn ẹlòmíì tàbí nígbà tí wọ́n bá ń ka òtítọ́ wọ̀nyí sí mi létí. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, mo máa ń ṣe ìjẹ́rìí òpópónà pẹ̀lú ìtìlẹyìn aya mi, tó máa ń gbẹnu sọ fún mi nígbà tí mo bá nílò ìrànlọ́wọ́. Mo ti sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ nígbà mélòó kan. Sísìn gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni alàgbà ń fún mi láyọ̀, àgàgà nígbà táwọn ará bá wá bá mi nípàdé tàbí tí wọ́n bá wá bẹ̀ mí wò nínú ilé mi, tí mo sì lè ràn wọ́n lọ́wọ́, kí n sì fún wọn níṣìírí.
Kí n sòótọ́, ó rọrùn gan-an láti sorí kọ. Nítorí náà, nígbàkigbà tí ìrẹ̀wẹ̀sì bá dé, kíá ni mo máa ń gbàdúrà kí n lè láyọ̀. Tọ̀sántòru ni mo ń gbàdúrà pé kí Jèhófà mẹ́sẹ̀ mi dúró. Ara mi máa ń yá gágá nígbà tí mo bá gba lẹ́tà tàbí tẹ́nì kan bá wá bẹ̀ mí wò. Kíka ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ tàbí Jí! tún máa ń fi àwọn ohun tí ń gbéni ró kún èrò inú mi. Nígbà míì, nọ́ọ̀sì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló máa ń ka ìwé ìròyìn wọ̀nyí sí mi létí. Látìgbà tí jàǹbá yẹn ti ṣẹlẹ̀ sí mi, ẹ̀ẹ̀meje ni mo ti gbọ́ kásẹ́ẹ̀tì Bíbélì látìbẹ̀rẹ̀ dópin. Ìwọ̀nyí wà lára onírúurú ọ̀nà tí Jèhófà ti gbà mẹ́sẹ̀ mi dúró.—Sáàmù 41:3.
Ìyípadà tó dé bá mi ti jẹ́ kí n ní àkókò púpọ̀ láti ṣàṣàrò lórí bí Jèhófà, Olùkọ́ wa Atóbilọ́lá, ṣe ń kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́. Ó fún wa ní ìmọ̀ pípéye nípa ìfẹ́ àti ète rẹ̀, ó fún wa ní iṣẹ́ òjíṣẹ́ tó gbámúṣé, ó ń fún wa nímọ̀ràn nípa àṣírí ayọ̀ ìdílé, ó sì ń fún wa ní òye láti mọ ohun tó yẹ ní ṣíṣe nígbà tí àgbákò bá dé. Jèhófà ti fi aya olóòótọ́, aya rere jíǹkí mi. Àwọn ọmọ mi pẹ̀lú ti dúró tì mí gbágbáágbá, inú mi sì dùn pé gbogbo wọn ló ti kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún. Àní, ní March 11, 2000, Mark ọmọ wa àti Allyson ìyàwó rẹ̀, kẹ́kọ̀ọ́ yege ní kíláàsì kejìdínláàádọ́fà ti Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì, wọ́n sì rán wọn lọ sí Nicaragua. Èmi àti ìyàwó mi lọ síbi ayẹyẹ ìkẹ́kọ̀ọ́yege náà. Mo lè sọ tòótọ́tòótọ́ pé àgbákò ti yí ìgbésí ayé mi padà, àmọ́ kò yí ọkàn mi padà.—Sáàmù 127:3, 4.
Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà nítorí ọgbọ́n tó fún mi, tó jẹ́ kó ṣeé ṣe fún mi láti fi ogún tẹ̀mí tí mo rí gbà ṣọwọ́ sí ìdílé mi. Ó ń fún mi lókun, ó sì ń fún mi níṣìírí bí mo ti ń rí i pé àwọn ọmọ mi ń sin Ẹlẹ́dàá wọn pẹ̀lú irú ẹ̀mí tí bàbá mi ní, ẹni tó sọ pé, “A ò lè jáwọ́ wẹ́rẹ́ báyẹn. Jèhófà ló pàṣẹ pé ká máa wàásù.” Àní sẹ́, Jèhófà ti mẹ́sẹ̀ èmi àti gbogbo ìdílé mi dúró ní gbogbo ọjọ́ ayé wa.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Èmi àti bàbá mi, ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin àti ẹ̀gbọ́n mi obìnrin, lẹ́bàá ọkọ̀ àfiṣelé wa, táa ń lò nígbà táa ń ṣe aṣáájú ọ̀nà. Èmi nìyẹn lápá ọ̀tún
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Èmi àti Myrna aya mi
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Fọ́tò kan tí ìdílé wa yà láìpẹ́ yìí
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]
Mo ṣì ń jẹ́rìí nípa kíkọ lẹ́tà