Ìjẹ́wọ́ Tí Ń Yọrí sí Ìwòsàn
“NÍGBÀ tí mo dákẹ́, egungun mi ti di gbígbó nítorí ìkérora mi láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀. Nítorí pé tọ̀sán-tòru ni ọwọ́ rẹ wúwo lára mi. Ọ̀rinrin ìgbésí ayé mi ni a ti yí padà bí ti àkókò ooru gbígbẹ ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn.” (Sáàmù 32:3, 4) Àwọn ọ̀rọ̀ tí ń ró kìì lọ́kàn ẹni wọ̀nyẹn lè jẹ́ ká mọ ìrònú tó dorí Dáfídì Ọba Ísírẹ́lì ìgbàanì kodò, àròdùn tó fọwọ́ ara rẹ̀ fà nípa bíbo ẹ̀ṣẹ̀ wíwúwo mọ́lẹ̀, kàkà tí ì bá fi jẹ́wọ́.
Dáfídì ta yọ lẹ́dàá. Akíkanjú ni lójú ogun, ògbóǹkangí òṣèlú ni, akéwì ni, olórin sì tún ni. Síbẹ̀, kò gbára lé ọgbọ́n orí rẹ̀, bí kò ṣe Ọlọ́run rẹ̀. (1 Sámúẹ́lì 17:45, 46) A pè é ní ọkùnrin tí ọkàn rẹ̀ “pé pérépéré pẹ̀lú Jèhófà.” (1 Àwọn Ọba 11:4) Ṣùgbọ́n ó dá ẹ̀ṣẹ̀ kan tó burú jáì, bóyá ni kì í ṣe ẹ̀ṣẹ̀ yìí ló ń tọ́ka sí nínú Sáàmù 32. A lè rí ohun púpọ̀ kọ́ nínú ṣíṣàyẹ̀wò ohun tó sún un dá ẹ̀ṣẹ̀ náà. A óò rí ọ̀f ìn tó yẹ ká yẹra fún, a ó sì rí ìdí tó fi yẹ ká jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wa, kí a lè mú àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run bọ̀ sípò.
Ọba Olóòótọ́ Kó Wọnú Ẹ̀ṣẹ̀
Orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ń bá àwọn ọmọ Ámónì jagun lọ́wọ́, ṣùgbọ́n Dáfídì wà ní Jerúsálẹ́mù. Nírọ̀lẹ́ ọjọ́ kan, bó ti ń gbatẹ́gùn lórí òrùlé ààfin rẹ̀, ó tajú kán rí obìnrin arẹwà kan tó ń wẹ̀ nílé kan tí ń bẹ nítòsí. Dípò kí ó kó ara rẹ̀ níjàánu, ó jẹ́ kí ìfẹ́ obìnrin náà kó sí òun lórí. Nígbà tí wọ́n sọ fún un pé Bátí-ṣébà, aya Ùráyà, tí í ṣe ọ̀kan lára ọmọ ogun rẹ̀ lobìnrin náà, Dáfídì ní kí wọ́n lọ pè é wá, ó sì bá a ṣe panṣágà. Nígbà tó ṣe, Bátí-ṣébà ránṣẹ́ sí Dáfídì pé òun ti lóyún o.—2 Sámúẹ́lì 11:1-5.
Dáfídì ti wọ gàù. Bí àṣírí bá tú, àwọn méjèèjì ló máa kú ikú ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n dá yìí. (Léfítíkù 20:10) Nítorí náà, ó ta ọgbọ́n kan. Ó ní kí Ùráyà, ọkọ Bátí-ṣébà, padà wálé lójú ogun. Lẹ́yìn tí Dáfídì bi Ùráyà lóríṣiríṣi ìbéèrè nípa ogun náà, ó ní kó máa lọ sílé. Dáfídì retí pé èyí á mú kó dà bíi pé Ùráyà ló ni oyún inú Bátí-ṣébà.—2 Sámúẹ́lì 11:6-9.
Ṣùgbọ́n ọwọ́ pálábá Dáfídì ségi nígbà tí Ùráyà kọ̀ láti lọ bá ìyàwó rẹ̀. Ùráyà sọ pé kí á má ri pé òun gbọ̀nà ilé òun lọ nígbà tí àwọn ọmọ ogun ń fìjà pẹẹ́ta lójú ogun. Nígbà tí ẹgbẹ́ ogun Ísírẹ́lì bá wà lójú ogun, wọn ò gbọ́dọ̀ ní ìbálòpọ̀ takọtabo, kódà pẹ̀lú aya tiwọn pàápàá. Wọ́n gbọ́dọ̀ wà ní mímọ́ lọ́nà ayẹyẹ. (1 Sámúẹ́lì 21:5) Dáfídì wá se àsè fún Ùráyà, ó sì fi ọtí rọ ọ́ yó, síbẹ̀síbẹ̀ ó kọ̀, kò lọ sílé lọ bá ìyàwó ẹ̀. Ìṣòtítọ́ Ùráyà dẹ́bi fún ẹ̀ṣẹ̀ búburú jáì tí Dáfídì dá.—2 Sámúẹ́lì 11:10-13.
Ẹ̀ṣẹ̀ Dáfídì wá fẹ́ kó ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ sí i lọ́wọ́ báyìí. Nígbà tó sì wá di pé gbangba fẹ́ dẹkùn, ló bá pinnu láti gba ọ̀nà àbáyọ kan ṣoṣo tó kù. Ó ní kí Ùráyà padà sójú ogun, pẹ̀lú ìwé kan tó fi rán an sí Jóábù olórí ogun. Iṣẹ́ tó rán nínú ọ̀rọ̀ ṣókí tó kọ sínú ìwé yẹn ṣe kedere, ó ní: “Ẹ fi Ùráyà sí iwájú ibi tí ìjà ogun ti gbóná jù lọ, kí ẹ sì sá padà lẹ́yìn rẹ̀, kí a sì ṣá a balẹ̀, kí ó sì kú.” Ọba alágbára yìí rò pé òun ti fi gègé parí gbogbo ọ̀ràn náà, ó kúkú ti rán Ùráyà lọ síbi tó ti máa kú.—2 Sámúẹ́lì 11:14-17.
Gbàrà tí Bátí-ṣébà parí sáà ọ̀fọ̀ ọkọ rẹ̀ tó kú ni Dáfídì sọ ọ́ daya. Ọjọ́ ò tọ́jọ́, oṣù ò tóṣù, wọ́n bímọ ọ̀hún. Nígbà tí gbogbo eléyìí ń ṣẹlẹ̀, ṣe ni Dáfídì fi ẹnu mọ́ ẹnu, tó fi ètè mọ́ ètè, kò jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. Ó kúkú lè jẹ́ pé ńṣe ló ń gbìyànjú àtidá ohun tó ṣe láre. Ikú akíkanjú sáà ni Ùráyà kú, àbí ikú ogun kọ́ ní í pa akíkanjú ni? Yàtọ̀ síyẹn, kò ha kọ ọ̀rọ̀ sí ọba ìlú rẹ̀ lẹ́nu nígbà tó kọ̀ láti lọ bá ìyàwó rẹ̀? Gbogbo irú èròkérò wọ̀nyí ni ‘ọkàn-àyà tó kún fún àdàkàdekè’ máa ń rò láti fi dá ẹ̀ṣẹ̀ láre.—Jeremáyà 17:9; 2 Sámúẹ́lì 11:25.
Àwọn Àṣìṣe Tó Yọrí sí Ẹ̀ṣẹ̀
Báwo ni Dáfídì, tó fẹ́ràn òdodo, ṣe lè wá fi ọmọlúwàbí rẹ̀ wọ́lẹ̀, débi pé ó lọ ṣe panṣágà, tó tún pànìyàn? Ó jọ pé díẹ̀díẹ̀ ni ẹ̀ṣẹ̀ náà ń ta gbòǹgbò nínú rẹ̀. A lè máa ṣe kàyéfì pé kí ló dé tí Dáfídì ò bá àwọn èèyàn rẹ̀ lọ, kó lọ bá wọn jagun tí wọ́n ń bá àwọn ọ̀tá Jèhófà jà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni Dáfídì fẹ̀ sí ààfin, tó ń ṣe fàájì, àfi bí ẹni pé ogun náà ò kàn án rárá. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ká ní ọ̀ràn ogun náà jẹ ẹ́ lọ́kàn ni, bóyá ìyẹn ì bá ti paná ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ tó ní sí aya ọmọ ogun rẹ̀ olóòótọ́. Lónìí, ààbò ló jẹ́, bí àwọn Kristẹni tòótọ́ bá ń forí-fọrùn kópa nínú ìgbòkègbodò tẹ̀mí pẹ̀lú ìjọ wọn, tí wọ́n sì ń ṣe iṣẹ́ ìjíhìnrere náà déédéé.—1 Tímótì 6:12.
Ìtọ́ni táa fún ọba Ísírẹ́lì ni pé kó ṣe àdàkọ Òfin náà, kó sì máa kà á lójoojúmọ́. Bíbélì sọ ìdí tí ọba fi gbọ́dọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀, ó ní: “Kí ó bàa lè kọ́ láti máa bẹ̀rù Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀, kí ó lè máa pa gbogbo ọ̀rọ̀ òfin yìí àti ìlànà wọ̀nyí mọ́ nípa títẹ̀lé wọn; kí ọkàn-àyà rẹ̀ má bàa gbé ara rẹ̀ ga lórí àwọn arákùnrin rẹ̀ àti kí ó má bàa yà kúrò lórí àṣẹ náà sí ọ̀tún tàbí sí òsì.” (Diutarónómì 17:18-20) Ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ pé Dáfídì kò tẹ̀ lé ìtọ́ni yìí nígbà tó dá ẹ̀ṣẹ̀ burúkú wọ̀nyí. Ó dájú pé ìkẹ́kọ̀ọ́ déédéé àti àṣàrò lórí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yóò dáàbò bò wá kúrò nínú ìwà àìtọ́ láwọn àkókò líle koko wọ̀nyí.—Òwe 2:10-12.
Síwájú sí i, èyí tó gbẹ̀yìn nínú Àṣẹ Mẹ́wàá sọ ní pàtó pé: “Ojú rẹ kò gbọ́dọ̀ wọ aya ọmọnìkejì rẹ.” (Ẹ́kísódù 20:17) Kí ẹ sì máa wò ó, àwọn aya àti wáhàrì kún ọ̀dẹ̀dẹ̀ Dáfídì ní àkókò táà ń sọ yìí o. (2 Sámúẹ́lì 3:2-5) Pẹ̀lú gbogbo ìyẹn náà ńkọ́, ojú ẹ̀ ò gbébì kan, arẹwà obìnrin míì ló tún ń fojú sí lára. Ìtàn yìí rán wa létí bí ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ ṣe wúwo tó, pé: “Olúkúlùkù ẹni tí ń bá a nìṣó ní wíwo obìnrin kan láti ní ìfẹ́ onígbòónára sí i, ti ṣe panṣágà pẹ̀lú rẹ̀ ná nínú ọkàn-àyà rẹ̀.” (Mátíù 5:28) Dípò fífàyègba irú ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ ká mú un kúrò nínú ọkàn àti èrò wa kíákíá.
Ìrònúpìwàdà àti Àánú
Ó dájú pé a kò kọ ìtàn tòótọ́ tí Bíbélì sọ nípa ẹ̀ṣẹ̀ Dáfídì yìí láti fi tẹ́ ìfẹ́ ìbálòpọ̀ tí ẹnì kan ní lọ́rùn. Àkọsílẹ̀ yìí jẹ́ kí ó ṣeé ṣe fún wa láti rí ọ̀kan lára àwọn ànímọ́ títayọ Jèhófà, ànímọ́ tí ń runi sókè, tó sì wúni lórí, tí í ṣe àánú.—Ẹ́kísódù 34:6, 7.
Lẹ́yìn tí Bátí-ṣébà bí ọmọ inú rẹ̀, Jèhófà rán wòlíì Nátánì pé kí ó lọ bá Dáfídì. Ojú àánú ni èyí jẹ́. Ká ní kò sẹ́ni tó ko Dáfídì lójú ni, tó sì dákẹ́ síbẹ̀ láìsọ̀rọ̀, ó ṣeé ṣe kí ó jingíri sínú ẹ̀ṣẹ̀ dídá. (Hébérù 3:13) Ó dùn mọ́ni nínú pé Dáfídì tẹ́wọ́ gba àánú Ọlọ́run. Ọ̀rọ̀ olóye tó sọjú abẹ níkòó tí Nátánì sọ gbún ẹ̀rí ọkàn Dáfídì ní kẹ́sẹ́, ó sì fi tìrẹ̀lẹ̀-tìrẹ̀lẹ̀ gbà pé òun ti ṣẹ̀ sí Ọlọ́run. Ní ti tòótọ́, ẹ̀yìn tí Dáfídì ronú pìwà dà, tó sì jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wíwúwo rẹ̀, ló kọ Sáàmù 51, tó sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀ṣẹ̀ tó dá pẹ̀lú Bátí-ṣébà. Ǹjẹ́ kí a má ṣe jẹ́ kí ọkàn wa yigbì bí ẹ̀ṣẹ̀ wíwúwo bá lé wa bá.—2 Sámúẹ́lì 12:1-13.
A dárí ji Dáfídì, àmọ́ kò lọ láìjìyà, bẹ́ẹ̀ ni kò bọ́ lọ́wọ́ ìyọrísí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. (Òwe 6:27) Báwo ló ṣe lè lọ láìjìyà? Bí Ọlọ́run bá kàn gbójú fo gbogbo rẹ̀ dá, á jẹ́ pé ó fi ìlànà rẹ̀ báni dọ́rẹ̀ẹ́ nìyẹn. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ò ní tà mọ́, bíi ti Élì Àlùfáà Àgbà, tó gbàgbàkugbà láyè fáwọn ọmọkọ́mọ rẹ̀, tó sì jẹ́ kí wọ́n máa bá iṣẹ́ burúkú wọn nìṣó. (1 Sámúẹ́lì 2:22-25) Àmọ́ síbẹ̀ náà, Jèhófà kì í tilẹ̀kùn àánú Rẹ̀ mọ́ oníròbìnújẹ́ ọkàn. Àánú rẹ̀, bí omi tútù tí ń tuni lára, yóò jẹ́ kí ẹlẹ́ṣẹ̀ lè fàyà rán àbájáde ẹ̀ṣẹ̀. Ìdáríjì Ọlọ́run tí ń múni lọ́kàn yá gágá, àti ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ tí ń gbéni ró pẹ̀lú àwọn olùjọsìn ẹlẹgbẹ́ ẹni, lè múni bọ̀ sípò. Bẹ́ẹ̀ ni o, lórí ìpìlẹ̀ ìràpadà Kristi, ẹni tó ronú pìwà dà lè wá rí “ọrọ̀ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run.”—Éfésù 1:7.
“Ọkàn-Àyà Mímọ́ Gaara” àti “Ẹ̀mí Tuntun”
Nínú Sáàmù 51, lẹ́yìn tí Dáfídì jẹ́wọ́, kò wá bẹ̀rẹ̀ sí ronú pé òun ò wúlò fún nǹkan kan mọ́. Àwọn ọ̀rọ̀ tó wà nínú àwọn sáàmù tó kọ nípa ìjẹ́wọ́ rẹ̀ fi hàn pé ara tù ú àti pé ó pinnu láti máa fi ìṣòtítọ́ sin Ọlọ́run. Fún àpẹẹrẹ, wo Sáàmù 32. Ní ẹsẹ kìíní, a kà pé: “Aláyọ̀ ni ẹni tí a dárí ìdìtẹ̀ rẹ̀ jì, tí a bo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ mọ́lẹ̀.” Bó ti wù kí ẹ̀ṣẹ̀ náà wúwo tó, ó bà ni, kò tíì bà jẹ́, bí onítọ̀hún bá fi tọkàntọkàn ronú pìwà dà. Ọ̀nà kan téèyàn lè gbà fi hàn pé tọkàntọkàn lòun fi ronú pìwà dà ni pé kí ó gbà, bí Dáfídì ti gbà, pé ẹ̀bi òun ni gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀. (2 Sámúẹ́lì 12:13) Dáfídì kò bẹ̀rẹ̀ sí wá àwáwí níwájú Jèhófà tàbí kí ó gbìyànjú láti di ẹ̀bi ru àwọn ẹlòmíì. Ẹsẹ karùn-ún sọ pé: “Ẹ̀ṣẹ̀ mi ni mo jẹ́wọ́ fún ọ nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, ìṣìnà mi ni èmi kò sì bò mọ́lẹ̀. Mo wí pé: ‘Èmi yóò jẹ́wọ́ àwọn ìrélànàkọjá mi fún Jèhófà.’ Ìwọ fúnra rẹ sì dárí ìṣìnà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ mi jì.” Ìjẹ́wọ́ àtọkànwá ń mú ìtura wá, kò sì ní jẹ́ kí ẹ̀rí ọkàn máa na onítọ̀hún ní pàṣán mọ́ nítorí àwọn ìwà àìtọ́ tó hù sẹ́yìn.
Lẹ́yìn tí Dáfídì tọrọ àforíjì lọ́dọ̀ Jèhófà, ó wá bẹ̀bẹ̀ pé: “Àní kí o dá ọkàn-àyà mímọ́ gaara sínú mi, Ọlọ́run, kí o sì fi ẹ̀mí tuntun sínú mi, ọ̀kan tí ó fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin.” (Sáàmù 51:10) Bíbéèrè “ọkàn-àyà mímọ́ gaara” àti “ẹ̀mí tuntun” fi hàn pé Dáfídì gbà pé ẹ̀dá ẹlẹ́ṣẹ̀ lòun, òun sì nílò ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run láti wẹ ọkàn-àyà òun mọ́, kí òun sì wá bẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé tuntun. Dípò kí ó wá bẹ̀rẹ̀ sí káàánú ara rẹ̀, ó pinnu láti máa bá iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ sí Ọlọ́run nìṣó. Ó gbàdúrà pé: “Jèhófà, kí o ṣí ètè tèmi yìí, kí ẹnu mi lè máa sọ ìyìn rẹ jáde.”—Sáàmù 51:15.
Kí ni Jèhófà ṣe sí ìrònúpìwàdà àtọkànwá Dáfídì àti akitiyan rẹ̀ láti sìn ín? Ó sọ ọ̀rọ̀ ìfinilọ́kànbalẹ̀ yìí fún Dáfídì pé: “Èmi yóò mú kí o ní ìjìnlẹ̀ òye, èmi yóò sì fún ọ ní ìtọ́ni nípa ọ̀nà tí ìwọ yóò máa tọ̀. Dájúdájú, èmi yóò fún ọ ní ìmọ̀ràn pẹ̀lú ojú mi lára rẹ.” (Sáàmù 32:8) Èyí fini lọ́kàn balẹ̀ pé Jèhófà yóò kọbi ara sí ìmọ̀lára àti àìní ẹni tó ronú pìwà dà. Jèhófà gbé ìgbésẹ̀ láti fún Dáfídì ní ìjìnlẹ̀ òye púpọ̀ sí i, èyíinì ni agbára láti ríran ré kọjá ohun tó wà lóréfèé. Bí ó bá dojú kọ àdánwò lọ́jọ́ iwájú, yóò fojú inú wo ohun tí ìgbésẹ̀ rẹ̀ yóò yọrí sí àti ipa tí yóò ní lórí àwọn ẹlòmíì, yóò sì lè gbégbèésẹ̀ lọ́nà ọgbọ́n.
Ohun tó ṣẹlẹ̀ nínú ìgbésí ayé Dáfídì yìí jẹ́ ìṣírí fún gbogbo àwọn tó bá dá ẹ̀ṣẹ̀ wíwúwo. Nípa jíjẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wa àti nípa fífi tọkàntọkàn ronú pìwà dà, a lè jèrè ohun tó ṣe iyebíye jù lọ fún wa, ìyẹn ni àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run. Àròdùn àti ìtìjú tó lè di dandan fún wa láti fara dà fúngbà díẹ̀ sàn ju másùnmáwo tí yóò dé bá wa nítorí dídákẹ́, tàbí ìyọrísí búburú jíjingíri sínú ìwà ọ̀tẹ̀. (Sáàmù 32:9) Kàkà bẹ́ẹ̀, a lè rí ìdáríjì amúnilọ́kànyọ̀ ti Ọlọ́run onífẹ̀ẹ́ àti aláàánú, ẹni tí í ṣe “Baba àánú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ àti Ọlọ́run ìtùnú gbogbo.”—2 Kọ́ríńtì 1:3.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
Dáfídì rò pé òun ti bọ́ lọ́wọ́ àbájáde ẹ̀ṣẹ̀ òun nígbà tó rán Ùráyà lọ síbi tó ti kú