“Mo Ké Gbàjarè sí Késárì!”
ÀWỌN jàǹdùkú ṣùrù bo ọ̀gbẹ́ni kan tí kò lólùgbèjà. Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí lù ú. Lílù ni wọ́n fẹ́ lù ú pa bámúbámú. Díẹ̀ ṣín-ún ló kù kí ẹ̀mí rẹ̀ bọ́, nígbà táwọn sójà rọ́ dé, tí wọ́n sì fipá já ẹni ẹlẹ́ni gbà lọ́wọ́ àwọn kàràǹbààní ẹ̀dá náà. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ni ọkùnrin náà. Àwọn Júù ló fẹ́ lù ú pa. Wọ́n ní ìwàásù Pọ́ọ̀lù ń run àwọn nínú. Wọ́n tún ní ó ń ṣe ohun tó jẹ́ èèwọ̀ ní tẹ́ńpìlì. Àwọn ará Róòmù ló wá gbà á sílẹ̀. Orúkọ ọ̀gágun tó kó àwọn sójà wá ni Kilaudiu Lísíà. Gbogbo rìgbòrìyẹ̀ yẹn ló sáà jẹ́ kí wọ́n mú Pọ́ọ̀lù nímùú ọ̀daràn.
Àkọsílẹ̀ ẹjọ́ tí wọ́n ṣe lẹ́yìn tí wọ́n mú un yìí wà nínú orí ìwé méje tó gbẹ̀yìn ìwé Ìṣe. Mímọ ibi tí Pọ́ọ̀lù lóye ọ̀ràn òfin dé, mímọ àwọn ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án, mímọ bó ṣe gbèjà ara rẹ̀ àti mímọ ìlànà táwọn ará Róòmù ń tẹ̀ lé nínú ọ̀ràn ìgbẹ́jọ́, á jẹ́ ká túbọ̀ lóye àwọn orí ìwé wọ̀nyí.
Nígbà Tó Wà ní Àtìmọ́lé Kilaudiu Lísíà
Ara ojúṣe Kilaudiu Lísíà ni láti rí sí i pé ìgboro Jerúsálẹ́mù kò dà rú. Ìlú Kesaréà ni ọ̀gá rẹ̀, ìyẹn ará Róòmù tí í ṣe gómìnà Jùdíà, ń gbé. Ìgbésẹ̀ tí Lísíà gbé nínú ọ̀ràn Pọ́ọ̀lù lè jẹ́ nítorí àtigbà á lọ́wọ́ àwọn jàǹdùkú. Ó tún lè jẹ́ nítorí pé ó fẹ́ fi ẹni tó kà sí ọ̀dàlúrú sí àtìmọ́lé. Ìhùwàpadà àwọn Júù ló jẹ́ kí Lísíà gbé ọkùnrin tó mú yìí lọ sí ibùdó ológun tó wà ní Ilé Gogoro Antonia.—Ìṣe 21:27–22:24.
Ó wá ku bí Lísíà ṣe máa mọ ohun tí Pọ́ọ̀lù ṣe. Rìgbòrìyẹ̀ yẹn kò jẹ́ kó mọ ohun tí àwọn èèyàn náà rí lọ́bẹ̀ tí wọ́n fi wa irú sọ́wọ́. Nítorí náà, láìsí lọ kábọ̀, ó pàṣẹ pé kí ‘wọ́n na Pọ́ọ̀lù lọ́rẹ́ láti fi wádìí ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu rẹ̀, kí òun lè mọ ìdí tí wọ́n fi ń kígbe lòdì sí Pọ́ọ̀lù.’ (Ìṣe 22:24) Ohun tí wọ́n kúkú ń ṣe nìyẹn láti lè mú kí àwọn ọ̀daràn, àwọn ẹrú àtàwọn gbáàtúù èèyàn jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Ọrẹ́ (flagrum) tí wọ́n ń lò sì ń ṣe iṣẹ́ yẹn dáadáa. Ó kàn jẹ́ pé oró tó ń dáni ti pọ̀ jù ni. Àwọn kan lára ọrẹ́ wọ̀nyẹn ní àwọn irin ródóródó lára. Àwọn míì jẹ́ kòbókò tó ní egungun ṣóróṣóró àti irin lára. Wọ́n ń dá ọgbẹ́ yánnayànna síni lára. Wọ́n sì ń fa ẹran ara ya.
Ìgbà yẹn gan-an ni Pọ́ọ̀lù wá sọ pé ará Róòmù lòun. Kò sẹ́ni tó tóó ná ará Róòmù láìtíì dá a lẹ́bi. Kíá ni ọwọ́ wọn rọ nígbà tí Pọ́ọ̀lù mẹ́nu kan ẹ̀tọ́ ọmọ ìbílẹ̀. Iṣẹ́ lè bọ́ lọ́wọ́ ọ̀gá ará Róòmù tó bá hùwà àìtọ́ sí ọmọ ìbílẹ̀ Róòmù tàbí tó fìyà jẹ ẹ́. Abájọ tí àtìmọ́lé tí wọ́n fi Pọ́ọ̀lù sí látìgbà yẹn wá yàtọ̀. Wọ́n tiẹ̀ yọ̀ǹda fún un láti gbàlejò pàápàá.—Ìṣe 22:25-29; 23:16, 17.
Nígbà tí Lísíà ò mọ ẹ̀sùn tí ì bá fi kan Pọ́ọ̀lù, ló bá ní kó nìṣó níwájú Sànhẹ́dírìn kóun lè mọ̀dí tí ìlú fi dàrú. Ṣùgbọ́n Pọ́ọ̀lù da àárín àwọn aráabí yẹn rú nígbà tó sọ pé ọ̀ràn àjíǹde ni wọ́n tìtorí ẹ̀ ń bá òun ṣẹjọ́. Awuyewuye náà wá le débi pé àyà Lísíà pàápàá bẹ̀rẹ̀ sí já pé wọ́n lè fa Pọ́ọ̀lù ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ. Kò sí ṣíṣe kò sáìṣe, ńṣe ni Lísíà tún já a gbà lọ́wọ́ àwọn Júù onínú fùfù yìí.—Ìṣe 22:30–23:10.
Lísíà kò fẹ́ kí wọ́n pa ará Róòmù sí òun lọ́rùn. Nígbà tó gbọ́ pé wọ́n ti dẹ pàkúté ikú dè é, lórí eré ló ṣètò pé kí wọ́n gbé e lọ sí Kesaréà. Òfin béèrè pé kí gbogbo ìsọfúnni nípa ẹjọ́ náà bá ẹlẹ́jọ́ wá nígbà tí wọ́n bá fi í ránṣẹ́ sí ilé ẹjọ́ gíga. Ara ìsọfúnni tí wọn yóò fi ránṣẹ́ ni àbájáde ìwádìí tí wọ́n kọ́ ṣe, ìdí tí wọ́n fi gbé ìgbésẹ̀ tí wọ́n gbé àti èrò olùwádìí nípa ẹjọ́ náà. Ìsọfúnni tí Lísíà fi ránṣẹ́ ni pé wọ́n ‘fẹ̀sùn kan Pọ́ọ̀lù nípa àwọn ọ̀ràn tó jẹ mọ́ Òfin àwọn Júù, ó ní kì í ṣe nítorí ohunkóhun tí ó yẹ fún ikú tàbí ìdè.’ Ó sì pàṣẹ pé kí àwọn tó fẹ̀sùn kan Pọ́ọ̀lù lọ wí tẹnu wọn níwájú Fẹ́líìsì tí í ṣe ajẹ́lẹ̀.—Ìṣe 23:29, 30.
Gómìnà Fẹ́líìsì Kọ̀, Kò Dá Ẹjọ́ Náà
Ọ̀pá àṣẹ láti dá ẹjọ́ náà ń bẹ lọ́wọ́ Fẹ́líìsì. Tó bá fẹ́, ó lè lo òfin ìbílẹ̀ tàbí kí ó lo òfin ti ìjọba—èyí tí wọ́n ń lò fún àwọn ọ̀tọ̀kùlú àtàwọn òṣìṣẹ́ ìjọba. Òfin ti ìjọba yìí ni wọ́n ń pè ní ordo, tó túmọ̀ sí àkọsílẹ̀ lẹ́sẹẹsẹ. Ó tún lè lo òfin tí wọ́n ń pè ní extra ordinem, tó ṣeé fi dá ẹjọ́ èyíkéyìí. Ohun tá a retí pé kí gómìnà ṣe ni pé ‘kó gbé ohun tó yẹ láti ṣe lápapọ̀ yẹ̀ wò, kì í wulẹ̀ ṣe ohun tí wọ́n ń ṣe ní Róòmù nìkan.’ Fún ìdí yìí, ọwọ́ rẹ̀ ni ọ̀pá àṣẹ wà.
A ò mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ òfin Róòmù ìgbàanì. Àmọ́ ẹjọ́ Pọ́ọ̀lù jẹ́ “àpẹẹrẹ àwọn ẹjọ́ tó ṣeé dá ní ẹkùn ilẹ̀ náà lábẹ́ òfin extra ordinem.” Gómìnà, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn agbaninímọ̀ràn, yóò jókòó gbọ́ ẹjọ́ táwọn èèyàn mú wá. Wọ́n á wá pe olùjẹ́jọ́ pé kí ó wá ko olùfisùn rẹ̀ lójú, kí ó sì gbèjà ara rẹ̀. Àmọ́ ojúṣe olùpẹ̀jọ́ ni láti fẹ̀rí tí kò ṣeé já ní koro gbe ẹjọ́ rẹ̀ lẹ́sẹ̀. Ìyà tó bá wu adájọ́ ló lè fi jẹ ọ̀daràn. Ó lè dájọ́ lójú ẹsẹ̀ tàbí kó sún un síwájú, kí ó sì ní kí wọ́n fi olùjẹ́jọ́ sí àtìmọ́lé. Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ nì, Henry Cadbury, sọ pé: “Láìsí àní-àní, pẹ̀lú irú agbára ńlá tí ń bẹ lọ́wọ́ ajẹ́lẹ̀ yẹn, ó lè ‘pohùn dà,’ kí ó gba rìbá—yálà láti dá olùjẹ́jọ́ sílẹ̀ pátápátá, tàbí kí ó dá a lẹ́bi, tàbí kí ó sún ẹjọ́ náà síwájú.”
Ananíà Àlùfáà Àgbà àtàwọn àgbààgbà Júù àti Tẹ́túlọ́sì kóra wọn wá síwájú Fẹ́líìsì láti wá fẹ̀sùn kan Pọ́ọ̀lù. Wọ́n ní ‘alákòóbá ni. Wọ́n ló ń ru ìdìtẹ̀ sí ìjọba sókè láàárín àwọn Júù.’ Wọ́n lóun ni baba ìsàlẹ̀ “ẹ̀ya ìsìn àwọn ará Násárétì.” Wọ́n tún ní ó fẹ́ ṣe ohun tó jẹ́ èèwọ̀ ní tẹ́ńpìlì.—Ìṣe 24:1-6.
Àwọn tó dọwọ́ bo Pọ́ọ̀lù níbẹ̀rẹ̀ yẹn rò pé òun ló mú Kèfèrí kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Tírófímù wọ àgbàlá tó wà fáwọn Júù nìkan.a (Ìṣe 21:28, 29) Tá a bá ní ká sọ̀rọ̀ síbi tọ́rọ̀ wà, Tírófímù gan-an ló rúfin. Àmọ́ tó bá jẹ́ ojú ṣíṣe agbódegbà arúfin làwọn Júù fi wo ohun tí wọ́n rò pé Pọ́ọ̀lù ṣe yìí, ẹ̀sùn tó la ikú lọ ni. Ó sì jọ pé Róòmù ti gbà pé wọ́n lè dájọ́ ikú fẹ́ni tó bá hu ìwà ọ̀daràn yìí. Nítorí náà, ká ṣe pé àwọn Júù tó jẹ́ ọlọ́pàá tẹ́ńpìlì ló mú Pọ́ọ̀lù, tí kì í ṣe Lísíà ni, Sànhẹ́dírìn ni ì bá gbọ́ ẹjọ́ rẹ̀, wọ́n á sì dá ẹjọ́ náà láìsí ẹni tó máa yẹ̀ wọ́n lọ́wọ́ wò.
Àwọn Júù sọ pé ohun tí Pọ́ọ̀lù ń kọ́ni kì í ṣe ti ẹ̀sìn Júù, tàbí ẹ̀sìn tó bófin mu (religio licita). Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n ní ẹ̀sìn tí kò bófin mu, tó lè dá họ́wùhọ́wù sílẹ̀ ni.
Wọ́n tún sọ pé Pọ́ọ̀lù “ń ru ìdìtẹ̀ sí ìjọba sókè láàárín gbogbo àwọn Júù jákèjádò ilẹ̀ ayé tí a ń gbé.” (Ìṣe 24:5) Ẹnu àìpẹ́ sígbà yẹn ni Kíláúdíù Olú Ọba fẹ̀sùn kan àwọn Júù tí ń bẹ nílùú Alẹkisáńdíríà pé “wọ́n ń dá họ́wùhọ́wù sílẹ̀ jákèjádò ayé.” Ẹ ò rí i pé kò sí ohun tó fi yàtọ̀ síra. Òpìtàn nì, A. N. Sherwin-White sọ pé: “Irú ẹ̀sùn yẹn dùn-ún fi kan Júù nígbà Ìṣàkóso Kíláúdíù tàbí láwọn ọdún tí Nérò ṣẹ̀ṣẹ̀ gorí ìtẹ́. Àwọn Júù ń wá ọ̀nà láti mú kí gómìnà gbà pé iṣẹ́ ìwàásù Pọ́ọ̀lù ń dá rúgúdù sílẹ̀ láàárín gbogbo àwọn Júù tí ń bẹ ní Ilẹ̀ Ọba náà. Wọ́n mọ̀ pé àwọn gómìnà kì í fẹ́ dá ẹnikẹ́ni lẹ́jọ́ nítorí ọ̀ràn ẹ̀sìn lásán, ìyẹn ni wọ́n fi fẹ́ wé ọ̀ràn òṣèlú mọ́ ọn.”
Gbogbo ẹ̀sùn náà ni Pọ́ọ̀lù bì wó lọ́kọ̀ọ̀kan. ‘Èmi ò dá rúkèrúdò kankan sílẹ̀. Òótọ́ ni pé mo jẹ́ mẹ́ńbà ohun tí wọ́n ń pè ní “ẹ̀ya ìsìn,” ṣùgbọ́n àwọn ìlànà Júù là ń tẹ̀ lé. Àwọn Júù kan tó wá láti Éṣíà ni eku ẹdá tó dá rògbòdìyàn sílẹ̀. Bí wọ́n bá ní ẹ̀sùn tí wọ́n fẹ́ fi sùn, kí wọ́n wá fi sùn níbí.’ Pọ́ọ̀lù wá sojú abẹ níkòó pé ìjà ẹ̀sìn láàárín àwọn Júù ni gbogbo ọ̀ràn tó wà nílẹ̀ yìí o. Ìwọ̀nba sì ni Róòmù mọ̀ nípa irú ọ̀ràn bẹ́ẹ̀. Nígbà tí Fẹ́líìsì rí i pé àwọn Júù kìígbọ́-kìígbà yìí lè fárígá, ló bá lóun sún ẹjọ́ náà síwájú, kí kálukú lọ sinmi agbaja o jàre. Kò tìtorí pé àwọn Júù sọ pé àwọn làwọn mọ ẹjọ́ yìí dá, kó wá fa Pọ́ọ̀lù lé wọn lọ́wọ́. Bẹ́ẹ̀ ni kò fi òfin Róòmù dá a lẹ́jọ́. Bẹ́ẹ̀ náà ni kò tú u sílẹ̀. Kò kúkú sẹ́ni tó lè fipá mú Fẹ́líìsì láti ṣe ìdájọ́. Yàtọ̀ sí pé ó ń wá ojú rere àwọn Júù, ìdí míì tún wà tó jẹ́ kó fi ẹjọ́ náà falẹ̀—ó ń retí pé kí Pọ́ọ̀lù wá fún òun ní rìbá.—Ìṣe 24:10-19, 26.b
Ọ̀ràn Náà Dójú Ẹ̀ Nígbà Tí Pọ́kíọ́sì Fẹ́sítọ́ọ̀sì Gorí Àlééfà
Lọ́dún méjì lẹ́yìn náà ní Jerúsálẹ́mù, àwọn Júù tún gbé ẹjọ́ náà wá lákọ̀tun, nígbà tí Pọ́kíọ́sì Fẹ́sítọ́ọ̀sì, ìyẹn gómìnà tuntun dé. Wọ́n ní kí ó fa Pọ́ọ̀lù lé àwọn lọ́wọ́. Ṣùgbọ́n Fẹ́sítọ́ọ̀sì kọ̀ jálẹ̀, ó ní: “Kì í ṣe ọ̀nà-ìgbàṣe-nǹkan àwọn ara Róòmù láti fi ènìyàn èyíkéyìí léni lọ́wọ́ láti fi wá ojú rere kí ẹni tí a fẹ̀sùn kàn tó fojú-kojú pẹ̀lú àwọn olùfisùn rẹ̀, kí ó sì rí àyè sọ̀rọ̀ ní ìgbèjà ara rẹ̀ nípa ẹ̀sùn náà.” Òpìtàn nì, Harry W. Tajra sọ pé: “Ó hàn gbangba sí Fẹ́sítọ́ọ̀sì pé ńṣe làwọn aráabí fẹ́ ta jàǹbá fún ọmọ ìbílẹ̀ Róòmù kan.” Ìyẹn ló jẹ́ kó sọ fáwọn Júù pé kí wọ́n kó ẹjọ́ náà lọ sí Kesaréà.—Ìṣe 25:1-6, 16.
Nígbà tí wọ́n dé ọ̀hún, àwọn Júù tún bẹ̀rẹ̀ sí pariwo pé Pọ́ọ̀lù “kò yẹ láti wà láàyè mọ́.” Àmọ́ ariwo ẹnu lásán ni wọ́n ń pa. Wọn ò ní ẹ̀rí kankan. Fẹ́sítọ́ọ̀sì sì róye pé Pọ́ọ̀lù kò ṣe nǹkan kan tó tọ́ sí ikú. Fẹ́sítọ́ọ̀sì ṣàlàyé fún aláṣẹ kan pé: “Àwọn awuyewuye kan ni wọ́n kàn ní pẹ̀lú rẹ̀ nípa ìjọsìn tiwọn fún ọlọ́run àjúbàfún àti nípa Jésù kan tí ó kú ṣùgbọ́n tí Pọ́ọ̀lù ń tẹnu mọ́ ọn ṣáá pé ó wà láàyè.”—Ìṣe 25:7, 18, 19, 24, 25.
Ó dájú pé Pọ́ọ̀lù kò rú òfin kankan tó jẹ́ ti ìṣèlú. Àmọ́ ní ti awuyewuye lórí ọ̀ràn ẹ̀sìn, ó jọ pé àwọn Júù fi yé àwọn aláṣẹ pé kóòtù àwọn nìkan ló lè gbọ́ ẹjọ́ yìí. Ṣé Pọ́ọ̀lù á fẹ́ lọ sí Jerúsálẹ́mù kí wọ́n lọ dá ẹjọ́ yìí níbẹ̀? Fẹ́sítọ́ọ̀sì béèrè bóyá Pọ́ọ̀lù fẹ́ bẹ́ẹ̀. Ṣùgbọ́n ìyẹn ò tiẹ̀ bọ́ sí i rárá ni. Pípadà sí Jerúsálẹ́mù níbi táwọn olùfisùn rẹ̀ á ti di onídàájọ́, kò yàtọ̀ sí fífi Pọ́ọ̀lù lé àwọn Júù lọ́wọ́. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Mo dúró níwájú ìjókòó ìdájọ́ Késárì, níbi tí ó yẹ kí a ti ṣèdájọ́ mi. Èmi kò ṣe àìtọ́ kankan sí àwọn Júù . . . Ènìyàn kankan kò lè fi mí lé wọn lọ́wọ́ láti fi wá ojú rere. Mo ké gbàjarè sí Késárì!”—Ìṣe 25:10, 11, 20.
Sísọ tí ará Róòmù kan sọ irú ọ̀rọ̀ yìí jáde fi hàn pé ẹjọ́ ọ̀hún ti kọjá agbára ẹkùn ilẹ̀ yẹn. Ẹ̀tọ́ tó ní láti pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn (provocatio) “kò ṣeé sẹ́, kò láàlà, ó sì gbéṣẹ́.” Ìyẹn ló fi jẹ́ pé lẹ́yìn tí Fẹ́sítọ́ọ̀sì àtàwọn agbaninímọ̀ràn rẹ̀ foríkorí láti fojú ṣùnnùkùn wo ọ̀ràn náà, ó kéde pé: “Késárì ni ìwọ ké gbàjarè sí; ọ̀dọ̀ Késárì ni ìwọ yóò lọ.”—Ìṣe 25:12.
Inú Fẹ́sítọ́ọ̀sì dùn pé òun bọ́ nínú ọ̀ràn Pọ́ọ̀lù. Àní ó jẹ́wọ́ fún Hẹ́rọ́dù Àgírípà Kejì ní ọjọ́ mélòó kan lẹ́yìn náà pé ọ̀ràn náà rú òun lójú. Ó wá di dandan báyìí pé kí Fẹ́sítọ́ọ̀sì kọ ọ̀rọ̀ nípa ẹjọ́ náà ránṣẹ́ sí olú ọba. Ṣùgbọ́n lójú Fẹ́sítọ́ọ̀sì, àwọn ohun tó ta kókó nínú òfin àwọn Júù ni ẹ̀sùn wọ̀nyí dá lé. Àmọ́ ọ̀jáfáfá ni Àgírípà nínú irú ọ̀ràn bẹ́ẹ̀. Nígbà tí Àgírípà sì lòun fẹ́ gbọ́ nípa ẹjọ́ náà, ojú ẹsẹ̀ ló sọ fún un pé kó jọ̀ọ́ bá òun kọ lẹ́tà náà. Nígbà tí ẹjọ́ tí Pọ́ọ̀lù rò níwájú Àgírípà kò yé Fẹ́sítọ́ọ̀sì, ló bá kígbe pé: “Orí rẹ ti ń dà rú, Pọ́ọ̀lù! Ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ ti ń dà ọ́ lórí rú!” Ṣùgbọ́n yékéyéké ni gbogbo rẹ̀ yé Àgírípà. Ìyẹn ló jẹ́ kó sọ pé: “Ní àkókò kúkúrú, ìwọ yóò yí mi lérò padà di Kristẹni.” Ohun yòówù kó jẹ́ èrò Fẹ́sítọ́ọ̀sì àti Àgírípà nípa ẹjọ́ tí Pọ́ọ̀lù rò kalẹ̀, wọ́n fohùn ṣọ̀kan pé kò rúfin rárá, àwọn ì bá sì tú u sílẹ̀ bí kì í báá ṣe pé ó ti ké gbàjarè sí Késárì.—Ìṣe 25:13-27; 26:24-32.
Ibi Tí Ẹjọ́ Náà Wá Parí Sí
Nígbà tí Pọ́ọ̀lù dé Róòmù, ó pe àwọn sàràkí-sàràkí Júù. Kì í ṣe láti wàásù fún wọn nìkan, ṣùgbọ́n láti tún fìyẹn mọ ohun tí wọ́n ti gbọ́ nípa òun. Èyí lè jẹ́ kó mọ ohun tó wà lọ́kàn àwọn tó pè é lẹ́jọ́. Ó máa ń ṣẹlẹ̀ dáadáa pé kí àwọn aláṣẹ ní Jerúsálẹ́mù ké sí àwọn Júù tó wà ní Róòmù pé kí wọ́n bá àwọn mójú tó ẹjọ́ kan. Ṣùgbọ́n wọ́n sọ fún Pọ́ọ̀lù pé àwọn ò gbọ́ nǹkan kan nípa rẹ̀. Bí Pọ́ọ̀lù ti ń retí ìgbẹ́jọ́, wọ́n gbà á láyè láti wá ilé gbé àti láti máa wàásù ní fàlàlà. Irú ojú àánú yẹn fi hàn pé lójú Róòmù, Pọ́ọ̀lù kì í ṣe arúfin.—Ìṣe 28:17-31.
Pọ́ọ̀lù wà lábẹ́ àwọn ẹ̀ṣọ́ fún ọdún méjì sí i. Kí nìdí? Bíbélì kò ṣàlàyé. Ńṣe ló yẹ kí ẹni tó pẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn wà ní àtìmọ́lé títí àwọn olùpẹ̀jọ́ yóò fi dé láti wá ṣẹjọ́ náà. Ṣùgbọ́n bóyá ńṣe ni àwọn Júù tó wà ní Jerúsálẹ́mù kò yọjú rárá, nígbà tí wọ́n ti rí i pé kò sí báwọn ṣe lè rojọ́ yẹn kí àwọn sì jàre. Bóyá wọ́n rò pé ọ̀nà tó dáa jù lọ táwọn lè gbà pa Pọ́ọ̀lù lẹ́nu mọ́ ni káwọn má yọjú rárá. Láìfọ̀rọ̀ gùn, ó jọ pé Pọ́ọ̀lù déwájú Nérò, ó jọ pé ó dá a láre, ó sì jọ pé ó tú u sílẹ̀ nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín pé kí ó máa bá iṣẹ́ míṣọ́nnárì rẹ̀ nìṣó—ìyẹn lẹ́yìn ọdún márùn-ún gbáko tí wọ́n mú un.—Ìṣe 27:24.
Kì í ṣòní, kì í ṣàná, làwọn ọ̀tá òtítọ́ “ti nfi ofin dimọ ìwa-ika” kí wọ́n lè dá iṣẹ́ ìwàásù àwọn Kristẹni dúró. Kò yẹ kí èyí yà wá lẹ́nu. Jésù sáà sọ pé: “Bí wọ́n bá ti ṣe inúnibíni sí mi, wọn yóò ṣe inúnibíni sí yín pẹ̀lú.” (Sáàmù 94:20, Bibeli Mimọ; Jòhánù 15:20) Síbẹ̀, Jésù tún mú un dá wa lójú pé a óò ní òmìnira láti sọ ìhìn rere náà fún gbogbo ayé. (Mátíù 24:14) Ìyẹn ló fi jẹ́ pé bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe dúró gbọn-in lójú inúnibíni àti àtakò, bẹ́ẹ̀ náà làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lóde òní ‘ń gbèjà, tí a sì ń fìdí ìhìn rere múlẹ̀ lọ́nà òfin.’—Fílípì 1:7.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wọ́n fi òkúta mọ odi ìdènà kan, tó ga ní ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ta, tó pààlà sáàárín Àgbàlá Kèfèrí àti àgbàlá inú lọ́hùn-ún. Wọ́n sì fi èdè Gíríìkì àti èdè Látìn kọ ìkìlọ̀ sí ibi púpọ̀ lára odi yìí pé: “Kí ọmọ ilẹ̀ òkèèrè kankan má kọjá ohun ìdènà àti ọgbà yìí tó yí ibùjọsìn ká. Ẹnikẹ́ni tọ́wọ́ bá tẹ̀, òun ló ṣekú pa ara rẹ̀ o.”
b Dájúdájú, èyí lòdì sófin. Ìwé kan ṣàlàyé pé: “Lábẹ́ òfin ìlọ́nilọ́wọ́gbà, ìyẹn Lex Repetundarum, ẹnikẹ́ni tó bá wà nípò àṣẹ tàbí ipò agbára kò gbọ́dọ̀ béèrè fún rìbá tàbí kí ó gbà á, yálà láti de ẹnì kan tàbí láti tú u, láti ṣe ìdájọ́ òdodo tàbí láti yí ìdájọ́ po tàbí láti tú ẹlẹ́wọ̀n kan sílẹ̀.”