“Ẹ Mọ́kànle! Mo Ti Ṣẹ́gun Ayé”
ỌJỌ́ tí Jésù kú—ìyẹn ọjọ́ kẹrìnlá oṣù Nísàn ti àwọn Júù—bẹ̀rẹ̀ lẹ́yìn tí oòrùn wọ̀ lọ́jọ́ Thursday, March 31, ọdún 33 Sànmánì Tiwa. Lálẹ́ ọjọ́ yẹn, Jésù àtàwọn àpọ́sítélì rẹ̀ kóra jọ sínú iyàrá òkè kan ní Jerúsálẹ́mù láti ṣayẹyẹ àjọ̀dún Ìrékọjá. Bí Jésù ṣe ń múra “láti lọ kúrò ní ayé yìí sọ́dọ̀ Baba,” ó fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ àwọn àpọ́sítélì òun títí dé òpin. (Jòhánù 13:1) Lọ́nà wo? Nípa kíkọ́ tó kọ́ wọn láwọn ẹ̀kọ́ tó ṣe kókó, tó sì tipa bẹ́ẹ̀ mú wọn gbára dì fún àwọn nǹkan tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀.
Bí alẹ́ ṣe ń lẹ́ lọ, Jésù sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ mọ́kànle! Mo ti ṣẹ́gun ayé.” (Jòhánù 16:33) Kí ló ní lọ́kàn pẹ̀lú gbólóhùn ìgboyà yìí? Lọ́nà kan, ohun tó ń sọ ni pé: ‘Gbogbo láabi tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ayé kò mú mi bínú bẹ́ẹ̀ ni kò sì mú kí n máa gbẹ̀san. Mi ò jẹ́ kí ayé yìí bẹ̀rẹ̀ sí darí mi láti máa ṣe ohun tó wù ú. Ẹ̀yin náà sì lè ṣe bẹ́ẹ̀.’ Ohun tí Jésù kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ olóòótọ́ láwọn wákàtí tó gbẹ̀yìn ìwàláàyè rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé á tún ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ṣẹ́gun ayé.
Ǹjẹ́ a rẹ́ni tó lè sọ pé ìwà ibi ò gbayé kan lónìí? Báwo ni ìwà ìrẹ́jẹ àti ìwà ipá rírorò táwọn èèyàn ń hù ṣe máa ń rí lára wa? Ǹjẹ́ ó máa ń mú ká bẹ̀rẹ̀ sí ro ibi sáwọn èèyàn tàbí kó máa ṣe wá bíi pé ká gbẹ̀san? Báwo ni ìwàkiwà táwọn èèyàn ń hù láyìíká wa ṣe ń nípa lórí wa? Àìpé ẹ̀dá tó ń bá wa jà àti èrò tó máa ń wá sọ́kàn wa láti dẹ́ṣẹ̀ ló tún ń mú kí ọ̀ràn náà burú sí i. Ogun alápá méjì la gbọ́dọ̀ máa jà lẹ́ẹ̀kan náà: a óò gbógun ti ayé búburú tó ń bẹ lóde àtàwọn èròkerò tó wà nínú wa. Ǹjẹ́ a lè ja ogun yìí ká sì borí láìsí ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run? Báwo la ṣe lè rí ìrànlọ́wọ́ rẹ̀ gbà? Àwọn ànímọ́ wo ló yẹ ká ní ká tó lè kojú àwọn ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara? Láti rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè wọ̀nyí, ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò ohun tí Jésù kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ọ̀wọ́n ní ọjọ́ tó gbẹ̀yìn ìwàláàyè rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé.
Ẹ Fi Ìwà Ìrẹ̀lẹ̀ Borí Ìgbéraga
Bí àpẹẹrẹ, ẹ wo ìṣòro ìgbéraga tàbí ìṣòro kí ẹni tí ò tó gèlètè máa mí fìn-ìn. Ohun tí Bíbélì sọ nípa rẹ̀ ni pé: “Ìgbéraga ní í ṣáájú ìfọ́yángá, ẹ̀mí ìrera sì ní í ṣáájú ìkọsẹ̀.” (Òwe 16:18) Ìwé Mímọ́ tún gbà wá nímọ̀ràn pé: “Bí ẹnikẹ́ni bá rò pé òun jẹ́ nǹkan kan nígbà tí kò jẹ́ nǹkan kan, ó ń tan èrò inú ara rẹ̀ jẹ.” (Gálátíà 6:3) Òdodo ọ̀rọ̀, ìwà ìgbéraga ń bani láyé jẹ́ ó sì ń tanni jẹ. Ohun tó dára ni pé ká kórìíra “ìgbéra-ẹni-ga àti ìyangàn.”—Òwe 8:13.
Ǹjẹ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ní ìṣòro gbígbé ara ẹni ga àti yíyangàn? Ó kéré tán, ìgbà kan wà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí jiyàn láàárín ara wọn nípa ẹni tó tóbi jù. (Máàkù 9:33-37) Lákòókò mìíràn, Jákọ́bù àti Jòhánù béèrè fún ipò ọlá nínú Ìjọba náà. (Máàkù 10:35-45) Jésù fẹ́ láti mú àwọn èrò tó kù díẹ̀ káàtó yìí kúrò lọ́kàn àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. Nígbà tí wọ́n ń jẹ oúnjẹ àjọ̀dún Ìrékọjá lọ́wọ́, ó dìde, ó mú aṣọ ìnura, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fọ ẹsẹ̀ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. Ó dájú pé ẹ̀kọ́ tó fẹ́ kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ níhìn-ín kò fara sin rárá. Jésù sọ pé: “Bí èmi, tí ó tilẹ̀ jẹ́ Olúwa àti Olùkọ́, bá wẹ ẹsẹ̀ yín, ó yẹ kí ẹ̀yin pẹ̀lú máa wẹ ẹsẹ̀ ara yín lẹ́nì kìíní-kejì.” (Jòhánù 13:14) Wọ́n gbọ́dọ̀ fi ìwà ìrẹ̀lẹ̀ tí í ṣe òdìkejì ìgbéraga rọ́pò rẹ̀.
Àmọ́ ṣá, kò rọrùn láti borí ìwà ìgbéraga o. Nígbà tó ṣe lálẹ́ ọjọ́ kan náà, lẹ́yìn tí Jésù ti lé Júdásì Ísíkáríótù, ẹni tó máa dà á jáde, àríyànjiyàn ńlá kan tún bẹ́ sílẹ̀ láàárín àwọn ọmọ ẹ̀yìn mọ́kànlá yòókù. Kí ló fa awuyewuye náà? Ńṣe ni wọ́n ń jiyàn kùrà lórí ẹni tó máa jẹ́ ọ̀gá láàárín wọn! Àmọ́ dípò tí Jésù ì bá fi fìbínú bá wọn wí, ńṣe ló tún fi sùúrù tẹ̀ ẹ́ mọ́ wọn lọ́kàn pé ó ṣe pàtàkì láti máa ṣèránṣẹ́ fáwọn ẹlòmíràn. Ó sọ pé: “Àwọn ọba àwọn orílẹ̀-èdè a máa jẹ olúwa lé wọn lórí, àwọn tí wọ́n sì ní ọlá àṣẹ lórí wọn ni à ń pè ní àwọn Olóore. Àmọ́ ṣá o, ẹ̀yin kò ní jẹ́ bẹ́ẹ̀. Ṣùgbọ́n kí ẹni tí ó tóbi jù lọ láàárín yín dà bí ẹni tí ó kéré jù lọ, kí ẹni tí ó sì ń ṣe gẹ́gẹ́ bí olórí dà bí ẹni tí ń ṣe ìránṣẹ́.” Ó wá rán wọn létí àpẹẹrẹ tiẹ̀ fúnra rẹ̀, ó sọ pé: “Èmi wà láàárín yín gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ń ṣe ìránṣẹ́.”—Lúùkù 22:24-27.
Ǹjẹ́ ẹ̀kọ́ inú ọ̀rọ̀ yìí yé àwọn àpọ́sítélì náà? Ẹ̀rí fi hàn pé ó yé wọn dáadáa. Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà ni àpọ́sítélì Pétérù kọ̀wé pé: “Gbogbo yín ẹ jẹ́ onínú kan náà, kí ẹ máa fi ìmọ̀lára fún ọmọnìkejì hàn, kí ẹ máa ní ìfẹ́ni ará, kí ẹ máa fi ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ hàn, kí ẹ jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ ní èrò inú.” (1 Pétérù 3:8) Ẹ ò wá rí i pé ó ṣe pàtàkì gan-an pé kí àwa náà fi ìwà ìrẹ̀lẹ̀ borí ìwà ìgbéraga! Ohun tó bọ́gbọ́n mu ni pé ká má ṣe máa du òkìkí, agbára tàbí ipò. Bíbélì sọ pé: “Ọlọ́run kọ ojú ìjà sí àwọn onírera, ṣùgbọ́n ó fi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí fún àwọn onírẹ̀lẹ̀.” (Jákọ́bù 4:6) Bákan náà, òwe ọlọ́gbọ́n kan láyé àtijọ́ sọ pé: “Ìyọrísí ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ àti ìbẹ̀rù Jèhófà ni ọrọ̀ àti ògo àti ìyè.”—Òwe 22:4.
Bíborí Ìkórìíra—Lọ́nà Wo?
Gbé ìwà mìíràn kan tó tún gbòde yẹ̀ wò—ìyẹn ìwà ìkórìíra. Ìwà ìkórìíra yìí wà káàkiri ibi gbogbo, ohun yòówù tí ì báà fà á, yálà ìbẹ̀rù tàbí àìmọ̀kan, ẹ̀tanú, ìnilára, ìwà ìrẹ́nijẹ, ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni, ìwà kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà tàbí ìwà ẹ̀yà tèmi lọ̀gá. (2 Tímótì 3:1-4) Bẹ́ẹ̀ náà ni ìwà ìkórìíra gbòde kan lákòókò Jésù. Ńṣe ni àwùjọ àwọn Júù kórìíra àwọn agbowó òde bí ìgbẹ́. Àwọn Júù kì í dá sí àwọn ará Samáríà rárá. (Jòhánù 4:9) Bákan náà làwọn Júù tún kórìíra àwọn Kèfèrí. Àmọ́ nígbà tó tó àkókò kan, ọ̀nà ìjọsìn tí Jésù dá sílẹ̀ di èyí tó gba onírúurú èèyàn láti ibi gbogbo mọ́ra. (Ìṣe 10:34, 35; Gálátíà 3:28) Nítorí náà, ó fi ìfẹ́ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ní ohun kan tó jẹ́ àkọ̀tun.
Jésù polongo pé: “Èmi ń fún yín ní àṣẹ tuntun kan, pé kí ẹ nífẹ̀ẹ́ ara yín lẹ́nì kìíní-kejì; gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti nífẹ̀ẹ́ yín, pé kí ẹ̀yin pẹ̀lú nífẹ̀ẹ́ ara yín lẹ́nì kìíní-kejì.” Ó di dandan kí wọ́n kọ́ bí wọ́n á ṣe máa fi ìfẹ́ yìí hàn, nítorí ó sọ ọ́ síwájú pé: “Nípa èyí ni gbogbo ènìyàn yóò fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, bí ẹ bá ní ìfẹ́ láàárín ara yín.” (Jòhánù 13:34, 35) Àṣẹ tuntun làṣẹ náà nítorí pé kò mọ sórí kìkì nínífẹ̀ẹ́ “ọmọnìkejì rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.” (Léfítíkù 19:18) Lọ́nà wo? Jésù ṣàlàyé ọ̀rọ̀ náà kúnnákúnná nígbà tó sọ pé: “Èyí ni àṣẹ mi, pé kí ẹ nífẹ̀ẹ́ ara yín lẹ́nì kìíní-kejì gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti nífẹ̀ẹ́ yín. Kò sí ẹni tí ó ní ìfẹ́ tí ó tóbi ju èyí lọ, pé kí ẹnì kan fi ọkàn rẹ̀ lélẹ̀ nítorí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀.” (Jòhánù 15:12, 13) Wọ́n gbọ́dọ̀ múra tán láti fi ẹ̀mí wọn rúbọ nítorí àwọn ará wọn tàbí àwọn èèyàn mìíràn.
Báwo ni ẹ̀dá èèyàn aláìpé ṣe lè mú ìkórìíra kúrò nínú ìgbésí ayé wọn? Wọ́n lè ṣe bẹ́ẹ̀ nípa fífi ìfẹ́ ìfara-ẹni-rúbọ rọ́pò rẹ̀. Ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn olóòótọ́ ọkàn tí wọ́n wá látinú onírúurú ẹ̀yà, àṣà ìbílẹ̀, ẹ̀sìn àti ètò òṣèlú ló ń ṣe bẹ́ẹ̀. A ń sọ wọ́n di ọ̀kan báyìí nínú àwùjọ tó ṣọ̀kan, tí ìkórìíra kò sí—ìyẹn ẹgbẹ́ ará àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé. Wọ́n ń fi ọ̀rọ̀ onímìísí àpọ́sítélì Jòhánù sọ́kàn, èyí tó sọ pé: “Olúkúlùkù ẹni tí ó bá kórìíra arákùnrin rẹ̀ jẹ́ apànìyàn, ẹ̀yin sì mọ̀ pé kò sí apànìyàn kankan tí ìyè àìnípẹ̀kun dúró nínú rẹ̀.” (1 Jòhánù 3:15) Kì í ṣe pé àwọn Kristẹni tòótọ́ kì í lọ́wọ́ nínú ogun jíjà nìkan ni, àmọ́ wọ́n tún ń sapá gidigidi láti fi ìfẹ́ hàn láàárín ara wọn.
Nígbà náà, irú èrò wo ló yẹ ká ní sáwọn tí kì í ṣe onígbàgbọ́ bíi tiwa tó sì ṣeé ṣe kí wọ́n kórìíra wa? Nígbà tí wọ́n fi Jésù kọ́ sórí òpó igi, ó gbàdúrà fún àwọn tó fẹ́ pa á pé: “Baba, dárí jì wọ́n, nítorí wọn kò mọ ohun tí wọ́n ń ṣe.” (Lúùkù 23:34) Nígbà táwọn èèyàn tí ìkórìíra ti jọba lọ́kàn wọn ń sọ ọmọ ẹ̀yìn náà Sítéfánù lókùúta láti gbẹ̀mí rẹ̀, ọ̀rọ̀ tó jáde lẹ́nu rẹ̀ gbẹ̀yìn ni pé: “Jèhófà, má ka ẹ̀ṣẹ̀ yìí sí wọn lọ́rùn.” (Ìṣe 7:60) Jésù àti Sítéfánù kò ro ibi sáwọn tó tiẹ̀ kórìíra wọn pàápàá. Èrò búburú ò sí lọ́kàn wọn rárá. Bíbélì gbà wá níyànjú pé: “Ẹ jẹ́ kí a máa ṣe ohun rere sí gbogbo ènìyàn.”—Gálátíà 6:10.
‘Olùrànlọ́wọ́ Títí Láé’
Bí ìpàdé láàárín Jésù àtàwọn àpọ́sítélì rẹ̀ mọ́kànlá tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ ṣe ń lọ lọ́wọ́, ó sọ fún wọn pé láìpẹ́ òun ò ní sí lọ́dọ̀ wọn mọ́. (Jòhánù 14:28; 16:28) Àmọ́ ó fi dá wọn lójú pé: “Èmi yóò sì béèrè lọ́wọ́ Baba, yóò sì fún yín ní olùrànlọ́wọ́ mìíràn láti wà pẹ̀lú yín títí láé.” (Jòhánù 14:16) Ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run ni olùrànlọ́wọ́ tó ṣèlérí náà. Òun ló máa kọ́ wọn láwọn ohùn ìjìnlẹ̀ tó wà nínú Ìwé Mímọ́ táá tún jẹ́ kí wọ́n rántí àwọn nǹkan tí Jésù ti kọ́ wọn nígbà iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ orí ilẹ̀ ayé.—Jòhánù 14:26.
Báwo ni ẹ̀mí mímọ́ ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ lónìí? Ó dára, Bíbélì jẹ́ Ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí. Àwọn ọkùnrin tó lò láti sọ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ àti láti kọ Bíbélì jẹ́ àwọn ‘tí ẹ̀mí mímọ́ darí wọn.’ (2 Pétérù 1:20, 21; 2 Tímótì 3:16) Bá a ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́ tá a sì ń fi àwọn ohun tá à ń kọ́ sílò ń fún wa ní ìmọ̀, ọgbọ́n, òye, ìfòyemọ̀, ó ń jẹ́ ká lè ṣe ìpinnu tó tọ́ ká sì lè ronú jinlẹ̀. Gbogbo nǹkan wọ̀nyí ti mú wa gbára dì láti kojú àwọn wàhálà inú ayé búburú yìí, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?
Ẹ̀mí mímọ́ tún jẹ́ olùrànlọ́wọ́ lọ́nà mìíràn. Ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run máa ń sún èèyàn ṣe ohun tó dáa, ó sì máa ń jẹ́ káwọn tó bá ní in máa ní àwọn ànímọ́ tí Ọlọ́run fẹ́. Bíbélì sọ pé: “Èso ti ẹ̀mí ni ìfẹ́, ìdùnnú, àlàáfíà, ìpamọ́ra, inú rere, ìwà rere, ìgbàgbọ́, ìwà tútù, ìkóra-ẹni-níjàánu.” Ǹjẹ́ kì í ṣe àwọn ànímọ́ wọ̀nyí la nílò láti borí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ẹran ara tó ń súnni sí ìṣekúṣe, gbọ́nmi-si omi-ò-tó, owú, ìbínú àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ?—Gálátíà 5:19-23.
Tá a bá gbára lé ẹ̀mí Ọlọ́run, àá tún lè rí “agbára tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá” gbà láti kojú wàhálà tàbí ohunkóhun tó lè máa gbé wa lẹ́mìí sókè. (2 Kọ́ríńtì 4:7) Òótọ́ ni pé ẹ̀mí mímọ́ lè máà mú àwọn ìdánwò àti ìdẹwò kúrò, àmọ́ ó lè ràn wá lọ́wọ́ láti fara dà wọ́n. (1 Kọ́ríńtì 10:13) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Mo ní okun fún ohun gbogbo nípasẹ̀ agbára ìtóye ẹni tí ń fi agbára fún mi.” (Fílípì 4:13) Ọlọ́run ń fúnni nírú agbára bẹ́ẹ̀ nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀. Ẹ ò rí i pé ó yẹ ká dúpẹ́ ká sì tún ọpẹ́ dá fún ẹ̀mí mímọ́ náà! A ti ṣèlérí pé a máa fún àwọn tó “bá nífẹ̀ẹ́ Jésù tí wọ́n sì ń pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́.’—Jòhánù 14:15.
“Ẹ Dúró Nínú Ìfẹ́ Mi”
Ní òru ọjọ́ tó gbẹ̀yìn ìgbésí ayé Jésù gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá èèyàn, ó sọ fáwọn àpọ́sítélì rẹ̀ pé: “Ẹni tí ó bá ní àwọn àṣẹ mi, tí ó sì ń pa wọ́n mọ́, ẹni yẹn ni ó nífẹ̀ẹ́ mi. Ẹ̀wẹ̀, ẹni tí ó nífẹ̀ẹ́ mi ni Baba mi yóò nífẹ̀ẹ́.” (Jòhánù 14:21) Ó rọ̀ wọ́n pé: “Ẹ dúró nínú ìfẹ́ mi.” (Jòhánù 15:9) Báwo ni dídúró nínú ìfẹ́ Baba àti Ọmọ ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ nínú ìjàkadì tá à ń bá èròkérò tó ń wá sí wa lọ́kàn láti dẹ́sẹ̀ àti ayé búburú tó yí wa ká jà?
Ó dára, ǹjẹ́ a lè kápá àwọn èròkerò láti dẹ́ṣẹ̀ yìí tí kò bá sí ohun kan tó dìídì ń sún wa láti ṣe bẹ́ẹ̀? Ohun wo ló tún lè dìídì sún wa láti ṣe bẹ́ẹ̀ tó ṣẹ̀yìn fífẹ́ tá a fẹ́ ní àjọṣe tó dán mọ́rán pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run àti Ọmọ rẹ̀? Ọ̀dọ́mọkùnrin kan tó ń jẹ́ Ernesto,a tó ti sapá títí láti jáwọ́ nínú ìwà ìṣekúṣe tó ti jàrábà rẹ̀ látìgbà tó ṣẹ̀ṣẹ̀ lé lọ́mọ ọdún mẹ́wàá, ṣàlàyé pé: “Mo fẹ́ múnú Ọlọ́run dùn, mo sì kẹ́kọ̀ọ́ látinú Bíbélì pé bí mo ṣe ń gbé ìgbésí ayé mi ò dùn mọ́ ọn nínú. Ni mo bá pinnu láti pa ìwà dà, kí n sì máa pa àwọn ìlànà Ọlọ́run mọ́. Ojoojúmọ́ ni mo máa ń jìjàkadì pẹ̀lú àwọn èròkerò, èrò játijàti tó ṣì máa ń rọ́ wá sí mi lọ́kàn. Àmọ́ mo pinnu pé gbogbo ohun tó bá gbà ni màá fún un, mo sì gbàdúrà lójú méjèèjì pé kí Ọlọ́run ràn mí lọ́wọ́. Lẹ́yìn odidi ọdún méjì, mo borí, bó tiẹ̀ jẹ́ pé mi ò gba gbẹ̀rẹ́ fún ara mi.”
Ní ti ìjàkadì tá à ń bá ayé tó yí wa ká jà, gbé àdúrà tí Jésù gbà gbẹ̀yìn kí wọ́n tó kúrò nínú iyàrá òkè yẹn ní Jerúsálẹ́mù yẹ̀ wò. Ó gbàdúrà sí Baba rẹ̀ nítorí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, ó sì sọ pé: “Èmi kò béèrè pé kí o mú wọn kúrò ní ayé, bí kò ṣe láti máa ṣọ́ wọn nítorí ẹni burúkú náà. Wọn kì í ṣe apá kan ayé, gan-an gẹ́gẹ́ bí èmi kì í ti í ṣe apá kan ayé.” (Jòhánù 17:15, 16) Èyí mà ń fini lọ́kàn balẹ̀ púpọ̀ o! Jèhófà ń ṣọ́ àwọn tó nífẹ̀ẹ́ sí ó sì ń fún wọn lókun bí wọ́n ṣe ń ya ara wọn sọ́tọ̀ nínú ayé.
“Lo Ìgbàgbọ́”
Pípa àṣẹ Jésù mọ́ lè ràn wá lọ́wọ́ gan-an láti borí nínú ìjàkadì wa pẹ̀lú ayé búburú yìí àti èrò tó máa ń wá sí wa lọ́kàn láti dẹ́ṣẹ̀. Òótọ́ ló ṣe pàtàkì pé ká borí nínú ìjàkadì náà, àmọ́ bíborí yìí kò lè mú ayé yìí tàbí ẹ̀ṣẹ̀ tá a ti jogún kúrò. Àmọ́ ká má ṣe ronú pé a ò lè rọ́nà gbé e gbà o.
Bíbélì là á mọ́lẹ̀ pé: “Ayé ń kọjá lọ, bẹ́ẹ̀ sì ni ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ni yóò dúró títí láé.” (1 Jòhánù 2:17) Jésù fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ láti gba “olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀” lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. (Jòhánù 3:16) Nítorí náà, bí ìmọ̀ wa nípa àwọn ète Ọlọ́run ṣe ń pọ̀ sí i, ẹ jẹ́ ká fi ìmọ̀ràn Jésù sílò, èyí tó sọ pé: “Ẹ lo ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run, ẹ lo ìgbàgbọ́ nínú mi pẹ̀lú.”—Jòhánù 14:1.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A ti yí orúkọ onítọ̀hún padà.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6, 7]
Jésù rọ àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ pé: “Ẹ dúró nínú ìfẹ́ mi”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Òmìnira kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àtàwọn àbájáde rẹ̀ máa wáyé láìpẹ́