“Ẹ Sún Mọ́ Ọlọ́run, Yóò Sì Sún Mọ́ Yín”
Nígbà kan Rí àti Nísinsìnyí—Ìgbésí Ayé Rẹ̀ Yí Padà Pátápátá
ÌGBÉSÍ ayé Matsepang ti dìdàkudà, kò sì ní ìtumọ̀! Ọ̀dọ́mọbìnrin kan ni lórílẹ̀-èdè Lesotho, tó wà láàárín gbùngbùn Gúúsù Áfíríkà. Inú ẹ̀sìn Kátólíìkì ni wọ́n ti tọ́ Matsepang dàgbà. Àmọ́ dípò tí wọ́n á fi ràn án lọ́wọ́ láti sún mọ́ Ọlọ́run, ọ̀pọ̀ ọdún làwọn obìnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé tó ń kówó fún un láti fajú ẹ̀ mọ́ra fi bá a ṣèṣekúṣe.
Èyí ló mú kí ọ̀ràn ẹ̀sìn tojú sú Matsepang, ó sì ṣòro fún un láti gbà gbọ́ pé Ẹlẹ́dàá onífẹ̀ẹ́ kan wà tí kì í fọ̀rọ̀ àwọn èèyàn tó dá ṣeré rárá. Báwọn èèyàn ò ṣe ka Matsepang sí àti bíbá tí wọ́n ti bá a ṣèṣekúṣe yìí fa ìbànújẹ́ ńláǹlà fún un, ó sì wá ka ara rẹ̀ sẹ́ni tí ò já mọ́ ohunkóhun. Ó wá di aríjàgbá àti oníjàgídíjàgan kalẹ̀. Èyí mú kó bẹ̀rẹ̀ sí hùwà ọ̀daràn káàkiri.
Nígbà tó yá, Matsepang di ara ẹgbẹ́ ọmọ ìta tó máa ń lọ ja àwọn èrò inú ọkọ̀ ojú irin lólè. Àwọn ọlọ́pàá gbá a mú wọ́n sì ní kó lọ fẹ̀wọ̀n jura ní Gúúsù Áfíríkà. Nígbà tó ṣe, wọ́n dá a padà sí orílẹ̀-èdè rẹ̀, ìyẹn Lesotho níbi tó ti ń bá ìwà ọ̀daràn, ọtí àmuyíràá, ìwà ipá àti ìṣekúṣe nìṣó.
Nígbà tí ilé ayé tojú sú Matsepang, ó gbàdúrà tọkàntọkàn pé kí Ọlọ́run dákun ran òun lọ́wọ́. Ó tiẹ̀ ṣèlérí pé: “Ìwọ Ọlọ́run, bí ìgbésí ayé mi bá lè lójú, gbogbo ipá mi ni màá sà láti sìn ọ́.”
Kò pẹ́ sígbà yìí làwọn míṣọ́nnárì Ẹlẹ́rìí Jèhófà dé ọ̀dọ̀ Matsepang. Wọ́n sọ pé àwọn fẹ́ kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ ló ti wá rí i pé Ọlọ́run kì í ṣe ẹni tí ò bìkítà tàbí tí ò nífẹ̀ẹ́ èèyàn. Àní ó wá rí i pé Sátánì, tó jẹ́ “baba irọ́” máa ń lo ọgbọ́n àyínìke àti ẹ̀tàn láti mú káwọn kan ronú pé wọn ò já mọ́ ohunkóhun kí wọ́n sì gbà pé Jèhófà ò lè nífẹ̀ẹ́ àwọn láé.—Jòhánù 8:44; Éfésù 6:11.
Àmọ́ ìtùnú ńlá gbáà ló jẹ́ fún Matsepang nígbà tó kẹ́kọ̀ọ́ pé a lè padà ní ọ̀wọ̀ ara ẹni tá a bá ronú pìwà dà ẹ̀ṣẹ̀ tá a ti ṣẹ̀ sẹ́yìn, tá a bẹ̀bẹ̀ pé kí Ọlọ́run dárí jì wá, tá a sì wá ń sapá láti ṣe ohun tó fẹ́! Wọ́n jẹ́ kó mọ̀ pé “Ọlọ́run tóbi ju ọkàn-àyà wa lọ,” pé ọ̀nà tó gbà ń wò wá sì lè yàtọ̀ pátápátá sí ọ̀nà tá a gbà ń wo ara wa.—1 Jòhánù 3:19, 20.
Àwọn ọ̀rọ̀ tí onísáàmù náà Dáfídì kọ pé: “Jèhófà sún mọ́ àwọn oníròbìnújẹ́ ní ọkàn-àyà; ó sì ń gba àwọn tí a wó ẹ̀mí wọn palẹ̀ là,” tí Matsepang kà wú u lórí gan-an. (Sáàmù 34:18) Gẹ́gẹ́ bó ṣe jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tí a “wó ẹ̀mí wọn palẹ̀,” ó wá rí i pé Jèhófà kì í fi àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sílẹ̀, kódà bí wọ́n bá tiẹ̀ ń ronú pé ó ti bọ́ lọ́wọ́ àwọn tàbí pé àwọn ò já mọ́ ohunkóhun pàápàá. Inú rẹ̀ dùn nígbà tó kẹ́kọ̀ọ́ pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ gbogbo àwọn àgùntàn rẹ̀ pátá àti pé ó máa ń dúró tì wọ́n gbágbáágbá nígbà ìṣòro. (Sáàmù 55:22; 1 Pétérù 5:6, 7) Àwọn ọ̀rọ̀ tó kanlẹ̀ múnú rẹ̀ dùn lèyí tó sọ pé: “Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run, yóò sì sún mọ́ yín.”—Jákọ́bù 4:8.
Kò pẹ́ rárá tí agbára tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní fi bẹ̀rẹ̀ sí fara hàn nínú ìgbésí ayé Matsepang. Ó bẹ̀rẹ̀ sí wá sáwọn ìpàdé Kristẹni déédéé ó sì jáwọ́ nínú àwọn ìwà tí ò bá Ìwé Mímọ́ mu tó ń hù tẹ́lẹ̀. Kí ni àbájáde rẹ̀? Èrò náà pé Ọlọ́run ò lè nífẹ̀ẹ́ òun pé kò sì lè ṣojú rere sóun kúrò lọ́kàn rẹ̀. Látìgbà tó sì ti ṣèrìbọmi gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó ti lo ẹgbẹẹgbẹ̀rún wákàtí nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni gẹ́gẹ́ olùpòkìkí ìhìn rere Ìjọba náà. Ní báyìí, Matsepang ń gbé ìgbésí ayé tó lóyin tó sì nítumọ̀ láìfi àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn tó ń bà á nínú jẹ́ pè. Ẹ ò rí i pé ẹ̀rí lèyí jẹ́ nípa bí Bíbélì ṣe lágbára tó láti tún ìgbésí ayé èèyàn ṣe!—Hébérù 4:12.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 9]
“Ìwọ Ọlọ́run, bí ìgbésí ayé mi bá lè lójú, gbogbo ipá mi ni màá sà láti sìn ọ́.”
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 9]
Àwọn Ìlànà Bíbélì Tó Ṣe É Mú Lò
Lára àwọn ìlànà Bíbélì tó ti tu àwọn tí wọ́n bá ṣèṣekúṣe nínú rèé:
“Nígbà tí ìrònú tí ń gbé mi lọ́kàn sókè di púpọ̀ nínú mi, ìtùnú tìrẹ [ti Ọlọ́run] ni ó bẹ̀rẹ̀ sí ṣìkẹ́ ọkàn mi.” (Sáàmù 94:19) “Ìtùnú” Jèhófà tó wà nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ máa ń tuni nínú gan-an ni. Ríronú lórí wọn nígbà tá a bá ń ṣàṣàrò tá a sì ń gbàdúrà máa ń pẹ̀rọ̀ sáwọn ìrònú tó ń gbé wa lọ́kàn sókè ó sì ń jẹ́ ká ní ìgbọ́kànlé nínú Ọlọ́run pé Ọ̀rẹ́ tó mọ irú ipò tá a wà ni.
“Ó [Jèhófà] ń mú àwọn oníròbìnújẹ́-ọkàn lára dá, ó sì ń di àwọn ojú ibi tí ń ro wọ́n.” (Sáàmù 147:3) Tá a bá mọrírì ojú àánú Jèhófà àti ìpèsè tó ṣe nípasẹ̀ ẹbọ ìràpadà Jésù láti bo àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa mọ́lẹ̀, àá lè fi tọkàntọkàn tọ Ọlọ́run lọ láìsí pé ọkàn wa tún ń nà wá ní pàṣán. Èyí lè fúnni ní ìtùnú tí ò láfiwé àti ìbàlẹ̀ ọkàn.
“Kò sí ènìyàn kankan tí ó lè wá sọ́dọ̀ mi [Jésù Kristi] láìjẹ́ pé Baba, tí ó rán mi, fà á; dájúdájú, èmi yóò sì jí i dìde ní ọjọ́ ìkẹyìn.” (Jòhánù 6:44) Nípa ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ àti nípa iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà, Jèhófà fúnra rẹ̀ ń fà wá sọ́dọ̀ Ọmọ rẹ̀ ó sì ń fún wa ní ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun.