Kí Gbogbo Ènìyàn Máa Kéde Ògo Jèhófà
“Ẹ gbé ògo àti okun fún Jèhófà. Ẹ gbé ògo tí ó jẹ́ ti orúkọ Jèhófà fún un.”—SÁÀMÙ 96:7, 8.
1, 2. Àwọn nǹkan wo ló ń gbé ògo fún Jèhófà, àwọn wo la sì gbà níyànjú láti dara pọ̀ mọ́ wọn nínú ṣíṣe bẹ́ẹ̀?
AGBÈGBÈ Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ni Dáfídì ọmọ Jésè gbé, ìdí iṣẹ́ olùṣọ́ àgùntàn ló sì dàgbà sí. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ni yóò ti gbójú sókè láti wo ìràwọ̀ ojú ọ̀run tó pọ̀ lọ súà ní ààjìn òru nígbà tó ń ṣọ́ agbo ẹran bàbá rẹ̀ ní pápá ìjẹko tó dákẹ́ rọ́rọ́! Láìsí àní-àní, àwọn ohun àrà wọ̀nyí ló rántí nígbà tí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run dárí rẹ̀ láti sọ àwọn ọ̀rọ̀ dáradára tó kọ lórin sínú Sáàmù ìkọkàndínlógún pé: “Àwọn ọ̀run ń polongo ògo Ọlọ́run; òfuurufú sì ń sọ̀rọ̀ nípa iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀. Okùn ìdiwọ̀n wọn ti jáde lọ sí gbogbo ilẹ̀ ayé, àsọjáde wọn sì ti jáde lọ sí ìkángun ilẹ̀ eléso.”—Sáàmù 19:1, 4.
2 Wọn kò fọhùn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sì sọ̀rọ̀; láti ọjọ́ dé ọjọ́ a kò gbọ́ ohùn wọn. Láti òru dé òru làwọn ọ̀run àgbàyanu tí Jèhófà dá ń polongo ògo rẹ̀. Ìṣẹ̀dá ò dákẹ́ kíkéde ògo Ọlọ́run. Tá a bá ronú jinlẹ̀ lórí àwọn ẹ̀rí àgbàyanu tó fara han ní “gbogbo ilẹ̀ ayé” fún àwọn olùgbé ayé láti rí, a ó wá mọ̀ pé à kò já mọ́ nǹkan kan. Ṣùgbọ́n ẹ̀rí àwọn ìṣẹ̀dá yìí kò tó. A tún rọ àwọn olóòótọ́ èèyàn pé kí wọ́n pa ohùn tiwọn náà pọ̀ mọ́ ti àwọn ìṣẹ̀dá wọ̀nyí láti yin Ọlọ́run. Onísáàmù kan tá ò dárúkọ fi ọ̀rọ̀ onímìísí tó tẹ̀ lé e yìí rọ àwọn olóòótọ́ olùjọ́sìn pé: “Ẹ gbé ògo àti okun fún Jèhófà. Ẹ gbé ògo tí ó jẹ́ ti orúkọ Jèhófà fún un.” (Sáàmù 96:7, 8) Gbogbo àwọn tó ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà ni inú wọn dùn láti ṣe gẹ́gẹ́ bí a ṣe gbà wọ́n níyànjú yìí. Ṣùgbọ́n kí ló túmọ̀ sí láti gbé ògo fún Ọlọ́run?
3. Kí ni ìdí tí àwọn èèyàn fi ń gbé ògo fún Ọlọ́run?
3 Gbígbé ògo fún Ọlọ́run ju ọ̀rọ̀ ẹnu lásán lọ. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ọjọ́ Aísáyà fi ètè wọn yin Ọlọ́run lógo, ṣùgbọ́n kò dénú wọn. Jèhófà gbẹnu Aísáyà sọ pé: “Àwọn ènìyàn yìí ti fi ẹnu wọn sún mọ́ mi, tí wọ́n sì ti fi kìkì ètè wọn yìn mí lógo, tí wọ́n sì ti mú ọkàn-àyà wọn pàápàá lọ jìnnà réré kúrò lọ́dọ̀ mi.” (Aísáyà 29:13) Ìyìn tí irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ fún Ọlọ́run kò wúlò rárá. Kí irú ìyìn bẹ́ẹ̀ lè wúlò, ó gbọ́dọ̀ wá látinú ọkàn tó kún fún ìfẹ́ fún Jèhófà àti látinú ọkàn tó mọ̀ pé lóòótọ́ ni Ọlọ́run yẹ fún ògo tó ga jù lọ. Jèhófà nìkan ni Ẹlẹ́dàá. Òun ni Olódùmarè, Ẹni tí kò le ṣèké, àní Òun gan-an ni ọba ìfẹ́. Òun ni orísun ìgbàlà wa àti ẹni tó lẹ́tọ̀ọ́ láti jẹ́ Ọba Aláṣẹ láyé àti lọ́run, ẹni tí olúkúlùkù tó ń gbé láyé àtọ̀run gbọ́dọ̀ tẹrí ba fún. (Ìṣípayá 4:11; 19:1) Tá a bá gba gbogbo nǹkan wọ̀nyí gbọ́ lóòótọ́, ẹ jẹ́ ká fi gbogbo ọkàn wa yin Ọlọ́run lógo.
4. Ìtọ́ni wo ni Jésù fún wa nípa bó ṣe yẹ ká máa yin Ọlọ́run lógo, báwo là ṣe lè pa ìtọ́ni yẹn mọ́?
4 Jésù Kristi sọ fún wa nípa bó ṣe yẹ ká máa yin Ọlọ́run lógo. Ó sọ pé: “A yin Baba mi lógo nínú èyí, pé ẹ ń bá a nìṣó ní síso èso púpọ̀, tí ẹ sì fi ara yín hàn ní ọmọ ẹ̀yìn mi.” (Jòhánù 15:8) Báwo la ṣe ń so èso púpọ̀? Lákọ̀ọ́kọ́, nípa fífi gbogbo ọkàn kópa nínú “wíwàásù ìhìn rere ìjọba” náà, kí á sì tipa bẹ́ẹ̀ dara pọ̀ mọ́ gbogbo ìṣẹ̀dá ní “sísọ” nípa ‘àwọn ànímọ́ Ọlọ́run tí a kò lè rí.’ (Mátíù 24:14; Róòmù 1:20) Ní àfikún sí i, ọ̀nà yìí ń mú ká kópa ní tààràtà tàbí láìṣe tààràtà nínú sísọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn tuntun, tí wọ́n sì ń gbé ohùn wọn sókè láti yin Jèhófà Ọlọ́run lógo. Ìkejì, à ń báa lọ láti máa fi èso tí ẹ̀mí mímọ́ ń so nínú wa ṣèwà hù, a sì ń làkàkà láti máa fara wé àwọn ànímọ́ títayọ tí Jèhófà Ọlọ́run ní. (Gálátíà 5:22, 23; Éfésù 5:1; Kólósè 3:10) Ìyẹn ló ń jẹ́ kí ìwà wa ojoojúmọ́ máa yin Ọlọ́run lógo.
“Sí Gbogbo Ilẹ̀ Ayé”
5. Ṣàlàyé bí Pọ́ọ̀lù ṣe tẹnu mọ́ ojúṣe Kristẹni láti máa yin Ọlọ́run lógo nípa sísọ ohun tí wọ́n gbà gbọ́ fún àwọn ẹlòmíràn.
5 Nínú lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn ará Róòmù, ó tẹnu mọ́ ojúṣe Kristẹni láti máa yin Ọlọ́run lógo nípa sísọ ohun tí wọ́n gbà gbọ́ fún àwọn ẹlòmíràn. Ẹṣin ọ̀rọ̀ pàtàkì inú ìwé Róòmù ni pé, kìkì àwọn tó bá ní ìgbàgbọ́ nínú Jésù Kristi ló lè rí ìgbàlà. Nínú Róòmù, orí kẹwàá, Pọ́ọ̀lù fi hàn pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nípa tara ṣì ń gbìyànjú láti jẹ́ olóòótọ́ nípa títẹ̀ lé Òfin Mósè, nígbà tó jẹ́ pé “Kristi ni òpin Òfin.” Nítorí náà, Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Bí ìwọ bá polongo ‘ọ̀rọ̀ yẹn tí ń bẹ ni ẹnu ìwọ alára’ ní gbangba, pé Jésù ni Olúwa, tí o sì ń lo ìgbàgbọ́ nínú ọkàn-àyà rẹ pé Ọlọ́run gbé e dìde kúrò nínú òkú, a ó gbà ọ́ là.” Láti ìgbà yẹn wá ni “kò [ti] sí ìyàtọ̀ láàárín Júù àti Gíríìkì, nítorí Olúwa kan náà ní ń bẹ lórí gbogbo wọn, ẹni tí ó jẹ́ ọlọ́rọ̀ sí gbogbo àwọn tí ń ké pè é. Nítorí ‘olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń ké pe orúkọ Jèhófà ni a ó gbà là.’”—Róòmù 10:4, 9-13.
6. Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe lo Sáàmù 19:4?
6 Lẹ́yìn náà, Pọ́ọ̀lù fọgbọ́n béèrè pé: “Báwo ni wọn yóò ṣe ké pe ẹni tí wọn kò ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀? Báwo, ẹ̀wẹ̀, ni wọn yóò ṣe ní ìgbàgbọ́ nínú ẹni tí wọn kò gbọ́ nípa rẹ̀? Báwo, ẹ̀wẹ̀, ni wọn yóò ṣe gbọ́ láìsí ẹnì kan láti wàásù?” (Róòmù 10:14) Pọ́ọ̀lù sọ nípa Ísírẹ́lì pé: ‘Gbogbo wọn kọ́ ló ṣègbọràn sí ìhìn rere.’ Kí ló fà á tí Ísírẹ́lì kò fi ṣègbọràn? Ìdí ni pé wọn kò ní ìgbàgbọ́, kì í ṣe nítorí pé wọn kò láǹfààní láti ṣègbọràn. Pọ́ọ̀lù fi èyí hàn nípa fífa ọ̀rọ̀ tó wà nínú Sáàmù 19:4 yọ tó sì lò ó fún iṣẹ́ ìwàásù Kristẹni dípò kó lò ó fún ẹ̀rí ìṣẹ̀dá. Ó sọ pé: “Họ́wù, ní ti tòótọ́, ‘ìró wọ́n jáde lọ sí gbogbo ilẹ̀ ayé, àsọjáde wọn sì jáde lọ sí àwọn ìkángun ilẹ̀ ayé tí a ń gbé.’” (Róòmù 10:16, 18) Bẹ́ẹ̀ ni o, gẹ́gẹ́ bí àwọn ìṣẹ̀dá tí kò lẹ́mìí ṣe ń yin Jèhófà, làwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní náà ṣe ń wàásù ìhìn rere ìgbàlà níbi gbogbo, wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ yin Ọlọ́run lógo ní “gbogbo ilẹ̀ ayé.” Nínú lẹ́tà Pọ́ọ̀lù sáwọn ará Kólósè, ó sọ̀rọ̀ nípa ibi tí ìhìn rere náà ti gbilẹ̀ dé. Ó sọ pé ìhìn rere náà ni a ti wàásù “nínú gbogbo ìṣẹ̀dá tí ń bẹ lábẹ́ ọ̀run.”—Kólósè 1:23.
Àwọn Ẹlẹ́rìí Tó Nítara
7. Iṣẹ́ wo ni Jésù sọ pé kí àwọn Kristẹni ṣe?
7 Ó ṣe é ṣe kó jẹ́ pé nǹkan bí ọdún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n lẹ́yìn ikú Jésù Kristi ni Pọ́ọ̀lù kọ lẹ́tà rẹ̀ sáwọn ará Kólósè. Báwo ni iṣẹ́ ìwàásù ṣe yára gbilẹ̀ dé Kólósè láàárín àkókò kúkúrú yẹn? Ìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀ ni pé àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní jẹ́ onítara, Jèhófà sì bù kún ìtara wọn. Jésù ti sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn ọmọlẹ́yìn òun yóò jẹ́ oníwàásù tó ń ṣiṣẹ́ kára nígbà tó sọ pé: “A ní láti kọ́kọ́ wàásù ìhìn rere náà ní gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè.” (Máàkù 13:10) Jésù fi àṣẹ tó wà ní àwọn ẹsẹ tó gbẹ̀yìn ìwé Ìhìn Rere Mátíù kún àsọtẹ́lẹ̀ yẹn pé: “Nítorí náà, ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn, ẹ máa batisí wọn ní orúkọ Baba àti ti Ọmọ àti ti ẹ̀mí mímọ́, ẹ máa kọ́ wọn láti máa pa gbogbo ohun tí mo ti pa láṣẹ fún yín mọ́.” (Mátíù 28:19, 20) Kété lẹ́yìn ìgbà tí Jésù gòkè re ọ̀run, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí mú àṣẹ yẹn ṣẹ.
8, 9. Gẹ́gẹ́ bí ohun tó wà nínú ìwé Ìṣe, kí làwọn Kristẹni ṣe sí àṣẹ Jésù?
8 Lẹ́yìn tá a tú ẹ̀mí mímọ́ dà sórí àwọn ọmọ ẹ̀yìn ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa, ohun tí àwọn adúróṣinṣin ọmọ ẹ̀yìn kọ́kọ́ ṣe ni pé wọ́n jáde láti lọ wàásù, wọ́n ń sọ nípa “àwọn ohun ọlá ńlá Ọlọ́run” fáwọn èèyàn ní Jerúsálẹ́mù. Iṣẹ́ ìwàásù wọn méso jáde gan-an ni, nítorí pé “nǹkan bí ẹgbẹ̀ẹ́dógún ọkàn” ló ṣe ìrìbọmi. Àwọn ọmọ ẹ̀yin ń bá a lọ láti máa fi ìyìn fún Ọlọ́run ní gbangba, wọ́n sì n fi ìtara ṣe bẹ́ẹ̀, èyí sì méso jáde lọ́pọ̀ yanturu.—Ìṣe 2:4, 11, 41, 46, 47.
9 Kò pẹ́ táwọn aṣáájú ìsìn fi mọ̀ nípa ìgbòkègbodò àwọn Kristẹni. Nítorí pé inú wọn kò dùn sí bí Pétérù àti Jòhánù ṣe ń fi ìgboyà sọ̀rọ̀, wọ́n pàṣẹ fún àwọn àpọ́sítélì méjì yìí pé wọn kò gbọ́dọ̀ wàásù mọ́. Àwọn àpọ́sítélì fèsì pé: “Àwa kò lè dẹ́kun sísọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tí a ti rí tí a sì ti gbọ́.” Lẹ́yìn tí wọ́n halẹ̀ mọ́ wọn tí wọ́n sì dá wọn sílẹ̀, Pétérù àti Jòhánù padà sọ́dọ̀ àwọn ara wọn, gbogbo wọn sì dara pọ̀ láti gbàdúrà sí Jèhófà. Wọ́n fi ìgboyà bẹ Jèhófà pé: “Kí o sì yọ̀ǹda fún àwọn ẹrú rẹ láti máa bá a nìṣó ní fífi àìṣojo rárá sọ ọ̀rọ̀ rẹ.”—Ìṣe 4:13, 20, 29.
10. Inúnibíni wo ló yọjú, kí sì ní àwọn Kristẹni tòótọ́ ṣe?
10 Àdúrà yẹn bá ìfẹ́ Jèhófà mu gẹ́gẹ́ bó ṣe hàn kedere ní àkókò tí kò jìnnà sí ìgbà yẹn. Wọ́n fi àṣẹ mú àwọn àpọ́sítélì, áńgẹ́lì kan sì tú wọn sílẹ̀ lọ́nà ìyanu. Áńgẹ́lì yẹn sọ fún wọn pé: “Ẹ mú ọ̀nà yín pọ̀n, àti pé, nígbà tí ẹ bá ti dúró nínú tẹ́ńpìlì, ẹ máa bá a nìṣó ní sísọ gbogbo àsọjáde nípa ìyè yìí fún àwọn ènìyàn.” (Ìṣe 5:18-20) Nítorí pé àwọn àpọ́sítélì ṣègbọràn, Jèhófà ń báa lọ láti bù kún wọn. Nítorí náà, “ní ojoojúmọ́ nínú tẹ́ńpìlì àti láti ilé dé ilé ni wọ́n sì ń bá a lọ láìdábọ̀ ní kíkọ́ni àti pípolongo ìhìn rere nípa Kristi náà, Jésù.” (Ìṣe 5:42) Ó ṣe kedere pé inúnibíni gbígbóná janjan kò dá àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù dúró láti máa fi ògo fún Ọlọ́run ní gbangba.
11. Irú ẹ̀mí wo làwọn Kristẹni ìjímìjí fi hàn sí iṣẹ́ ìwàásù?
11 Láìpẹ́ wọ́n fàṣẹ mú Sítéfánù, wọ́n sì sọ ọ́ lókùúta pa. Ikú rẹ̀ yìí ló tanná ran inúnibíni ní Jerúsálẹ́mù, ó sì di dandan fún gbogbo àwọn ọmọlẹ́yìn láti tú ká lọ sí ilẹ̀ òkèèrè, àyàfi àwọn àpọ́sítélì nìkan ló kù ní Jerúsálẹ́mù. Ṣé inúnibíni yẹn mú kí wọ́n rẹ̀wẹ̀sì ni? Rárá o, kò rí bẹ́ẹ̀. A kà pé: “Àwọn tí a tú ká la ilẹ̀ náà já, wọ́n [sì] ń polongo ìhìn rere ọ̀rọ̀ náà.” (Ìṣe 8:1, 4) Ńṣe ni ìtara láti máa kéde ògo Ọlọ́run kàn ń pọ̀ sí i ṣáá. Nínú ìwé Ìṣe orí kẹsàn-án, a kà nípa Farisí náà, Sọ́ọ̀lù ará Tásù pé ó rí ìran kan níbi tó tí ń rin ìrìn àjò lọ sí Damásíkù láti lọ ṣe inúnibíni sáwọn ọmọlẹ́yìn Jésù, a sì bù ìfọ́jú lù ú. Ní Damásíkù, Ananíà la ojú Sọ́ọ̀lù lọ́nà ìyanu. Kí ni ohun ti Sọ́ọ̀lù ta a wá mọ̀ sí Pọ́ọ̀lù nígbà tó yá kọ́kọ́ ṣe? Àkọsílẹ̀ yẹn sọ pé: “Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ni ó bẹ̀rẹ̀ sí wàásù Jésù nínú àwọn sínágọ́gù, pé Ẹni yìí ni Ọmọ Ọlọ́run.”—Ìṣe 9:20.
Gbogbo Wọn Ló Wàásù
12, 13. (a) Gẹ́gẹ́ bí ohun táwọn òpìtàn sọ, kí ni ohun tó gbàfiyèsí nípa ìjọ Kristẹni ìjímìjí? (b) Báwo ni ìwé Ìṣe àti ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù ṣe bá ohun táwọn òpìtàn sọ mu?
12 Gbogbo èèyàn ló mọ̀ pé gbogbo àwọn tó wà nínú ìjọ Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ ló ṣe iṣẹ́ ìwàásù. Philip Schaff kọ̀wé nípa àwọn Kristẹni ìgbà yẹn pé: “Iṣẹ́ òjíṣẹ́ ló wà lórí ẹ̀mí gbogbo ìjọ, gbogbo Kristẹni onígbàgbọ́ ló sì jẹ́ míṣọ́nnárì.” (History of the Christian Church) Ọ̀gbẹ́ni W. S. Williams náà sọ pé: “Gbogbo èèyàn ló jẹ́rìí nípa àwọn Kristẹni tó wà nínú Ṣọ́ọ̀ṣì àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ pé, wọ́n wàásù ìhìn rere náà, pàápàá àwọn tó lẹ́bùn ẹ̀mí.” (The Glorious Ministry of the Laity ) Ó tẹnu mọ́ ọn pé: “Jésù Kristi kò ní in lọ́kàn rí pé kí ìwàásù jẹ́ àǹfààní àkànṣe fún ẹgbẹ́ kan pàtó lára àwọn tó wà nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́.” Kódà, Celsus tó jẹ́ ọ̀tá ìsìn Kristẹni látijọ́ kọ̀wé pé: “Àwọn tó ń rànwú, àwọn tó ń ṣe bàtà, àwọn oníṣẹ́ awọ, àwọn tó ya púrúǹtù jù lọ àtàwọn gbáàtúù nínú ìràn ènìyàn ló fi ìtara wàásù ìhìnrere.”
13 Àkọsílẹ̀ ìtàn tó wà nínú ìwé Ìṣe fi hàn pé bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ làwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn rí. Lẹ́yìn tí a tú ẹ̀mí mímọ́ jáde ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa, gbogbo àwọn ọmọlẹ́yìn, àtọkùnrin àtobìnrin ló ń kéde àwọn ohun àgbàyanu Ọlọ́run ní gbangba. Lẹ́yìn inúnibíni tó tẹ̀lé pípa tí wọ́n pa Sítéfánù, ńṣe ni gbogbo àwọn Kristẹni tó ti tú ká lọ́ sí ilẹ̀ òkèèrè ń tan ìhìn rere náà kálẹ̀. Ní nǹkan bí ọdún méjìdínlọ́gbọ̀n lẹ́yìn náà, Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí gbogbo àwọn Kristẹni tó jẹ́ Hébérù, kì í ṣe sí ẹgbẹ́ àlùfáà kékeré kan, nígbà tó sọ pé: “Nípasẹ̀ rẹ̀, ẹ jẹ́ kí a máa rú ẹbọ ìyìn sí Ọlọ́run nígbà gbogbo, èyíinì ni, èso ètè tí ń ṣe ìpolongo ní gbangba sí orúkọ rẹ̀.” (Hébérù 13:15) Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń ṣàlàyé èrò tiẹ̀ nípa iṣẹ́ ìwàásù náà, ó sọ pé: “Wàyí o, bí mo bá ń polongo ìhìn rere, kì í ṣe ìdí kankan fún mi láti ṣògo, nítorí àìgbọ́dọ̀máṣe wà lórí mi. Ní ti gidi, mo gbé bí èmi kò bá polongo ìhìn rere!” (1 Kọ́ríńtì 9:16) Ó dájú pé èrò tí gbogbo àwọn Kristẹni tó jẹ́ adúróṣinṣin ní ọ̀rúndún kìíní náà ní nìyẹn.
14. Báwo ni ìgbàgbọ́ ṣe tán mọ́ iṣẹ́ ìwàásù?
14 Láìṣe àní-àní, ojúlówó Kristẹni kan gbọ́dọ̀ máa wàásù nítorí pé iṣẹ́ ìwàásù àti ìgbàgbọ́ kò ṣe é pín níyà. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ọkàn-àyà ni a fi ń lo ìgbàgbọ́ fún òdodo, ṣùgbọ́n ẹnu ni a fi ń ṣe ìpolongo ní gbangba fún ìgbàlà.” (Róòmù 10:10) Ṣé àwùjọ kékeré kan láàárín ìjọ, bóyá ẹgbẹ́ àlùfáà kéréje kan tó bá lo ìgbàgbọ́ ló yẹ kó máa ṣe iṣẹ́ ìwàásù ni? Rára o! Gbogbo Kristẹni tó bá ní ìgbàgbọ́ tó lágbára nínú Jésù Kristi Olúwa là ń sún láti máa polongo irú ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀ fún àwọn ẹlòmíràn ní gbangba. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, a jẹ́ pé òkú ni ìgbàgbọ́ wọn nìyẹn. (Jákọ́bù 2:26) Nítorí pé àwọn Kristẹni tó jẹ́ adúróṣinṣin ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa lo ìgbàgbọ́ wọn lọ́nà yẹn, a yin orúkọ Jèhófà lógo lọ́nà gíga lọ́lá.
15, 16. Fúnni ní àpẹẹrẹ tó fi hàn pé ìṣẹ́ ìwàásù náà kò dúró bí ọ̀pọ̀ ìṣòro tiẹ̀ wà.
15 Ní ọ̀rúndún kìíní, Jèhófà bù kún àwọn èèyàn rẹ̀ nípa mímú kí wọ́n gbèrú láìka ọ̀pọ̀ ìṣòro nínú tàbí lóde ìjọ sí. Bí àpẹẹrẹ, ìwé Ìṣe orí kẹfà ṣàkọsílẹ̀ nípa awuyewuye tó wáyé láàárín àwọn tó yí padà lára àwọn tó ń sọ èdè Hébérù àtàwọn tó ń sọ èdè Gíríìkì. Àwọn àpọ́sítélì ló yanjú awuyewuye náà. A kà nípa àbájáde rẹ̀ pé: “Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ń bá a lọ ní gbígbilẹ̀, iye àwọn ọmọ ẹ̀yìn sì ń di púpọ̀ sí i ṣáá ní Jerúsálẹ́mù; ogunlọ́gọ̀ ńlá àwọn àlùfáà sì bẹ̀rẹ̀ sí di onígbọràn sí ìgbàgbọ́ náà.”—Ìṣe 6:7.
16 Nígbà tó yá, wàhálà lórí ọ̀ràn òṣèlú bẹ́ sílẹ̀ láàárín Ọba Hẹ́rọ́dù Àgírípà ti Jùdíà àtàwọn èèyàn Tírè àti Sídónì. Àwọn olùgbé àwọn ìlú wọ̀nyẹn ṣe àdéhùn àlàáfíà arúmọjẹ, Hẹ́rọ́dù wá ṣe ìkéde ìtagbangba láti fèsì padà. Ogunlọ́gọ̀ tó pé jọ náà bẹ̀rẹ̀ sí kígbe pé: “Ohùn ọlọ́run kan ni, kì í sì í ṣe ti ènìyàn!” Lójú ẹsẹ̀, áńgẹ́lì Jèhófà kọ lù Hẹ́rọ́dù Àgírípà, ó sì kú “nítorí pé kò fi ògo fún Ọlọ́run.” (Ìṣe 12:20-23) Ẹ ò ri pé ìjákulẹ̀ ńlá gbáà ló jẹ́ fáwọn tó gbẹ́kẹ̀ lé àwọn alákòóso ẹ̀dá ènìyàn! (Sáàmù 146:3, 4) Àmọ́ ṣá o, ńṣe làwọn Kristẹni ń báa lọ láti máa yìn Jèhófà lógo. Ní àbárèbábọ̀, “ọ̀rọ̀ Jèhófà ń bá a lọ ní gbígbilẹ̀ àti ní títànkálẹ” láìfi gbogbo rògbòdìyàn tó ń ṣẹlẹ̀ nípa òṣèlú pè.—Ìṣe 12:24.
Nígbà Yẹn Lọ́hùn-ún àti Lóde Òní
17. Ní ọ̀rúndún kìíní, kí ni àwọn èèyàn púpọ̀ dara pọ̀ láti ṣe?
17 Bẹ́ẹ̀ ni o, kìkì àwọn tó jẹ́ onítara, tó ń fi gbogbo ọkàn yin Jèhófà Ọlọ́run lógo ló wà nínú ìjọ Kristẹni kárí ayé ní ọ̀rúndún kìíní. Gbogbo àwọn Kristẹni tó jẹ́ adúróṣinṣin ló kópa nínú títan ìhìn rere náà kálẹ̀. Àwọn díẹ̀ bá àwọn tó fẹ́ gbọ́ pàdé, wọ́n sì ṣe gẹ́gẹ́ bí Jésù ṣe sọ, pé kí wọ́n kọ́ irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ láti máa pa gbogbo ohun tí ó ti pa láṣẹ fún wọn mọ́. (Mátíù 28:19, 20) Àbájáde rẹ̀ ni pé, ńṣe ni ìjọ bẹ̀rẹ̀ sí kún sí i, tí àwọn èèyàn púpọ̀ sì dara pọ̀ mọ́ Ọba Dáfídì ayé ìgbàanì láti máa fi ògo fún Jèhófà. Gbogbo wọn ló fara mọ́ ọ̀rọ̀ onímìísí náà pé: “Èmi yóò fi gbogbo ọkàn-àyà mi gbé ọ lárugẹ, ìwọ Jèhófà Ọlọ́run mi, ṣe ni èmi yóò sì máa yin orúkọ rẹ lógo fún àkókò tí ó lọ kánrin, nítorí pé títóbi ni inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́ sí mi.”—Sáàmù 86:12, 13.
18. (a) Kí ni ìyàtọ̀ tó wà láàárín ìjọ Kristẹni ọ̀rúndún kìíní àti Kirisẹ́ńdọ̀mù òde òní? (b) Kí ni a ó gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀lé é?
18 Látàrí bọ́rọ̀ ṣe ri yìí, ọ̀rọ̀ tí ọ̀jọ̀gbọ́n ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn náà Allison A. Trites sọ múni ronú jinlẹ̀. Nígbà tí ọkùnrin yìí ń fi ìsìn Kirisẹ́ńdọ̀mù òde òní wé ìsìn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní, ó sọ pé: “Ọmọ bíbí ló ń mú káwọn Ṣọ́ọ̀ṣì kún sí i lónìí, ìyẹn ni gbígbà táwọn ọmọ àwọn tó ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì ń gbà láti ṣe ìsìn tí ìdílé wọn ǹ ṣe tàbí gbígbèrú nítorí ìṣíkiri, ìyẹn nígbà tẹ́nì kan bá ṣí kúrò nínú ìjọ kan lọ́ sínú irú ìjọ́ kan náà tó wà ní ibòmíràn. Ṣùgbọ́n nínú ìwé Ìṣe, gbígbèrú jẹ́ nípasẹ̀ ìyíniléròpadà, nítorí pé ìjọ yẹn ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ni.” Ṣé ìyẹn wá fi hàn pé ìsìn Kristẹni tòótọ́ kò gbèrú mọ́ lọ́nà tí Jésù sọ pé yóò máa gbà gbèrú ní? Rárá o. Gbogbo ọ̀nà làwọn Kristẹni tòótọ́ lónìí fi jẹ́ onítara nínú fífi ògo fún Ọlọ́run ní gbangba gẹ́gẹ́ báwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní ti ṣe. A óò rí èyí nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀lé é.
Ǹjẹ́ O Lè Ṣàlàyé?
• Àwọn ọ̀nà wo la gbà ń yin Ọlọ́run lógo?
• Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe lo Sáàmù 19:4?
• Báwo ni ìgbàgbọ́ ṣe tán mọ́ iṣẹ́ ìwàásù?
• Kí ló gbàfiyèsí nípa ìjọ Kristẹni ọ̀rúndún kìíní?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8, 9]
Gbogbo ìgbà làwọn ọ̀run ń jẹ́rìí sí ògo Jèhófà
[Credit Line]
Nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda Anglo-Australian Observatory, fọ́tò látọwọ́ David Malin
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Ìṣẹ́ ìwàásù àti àdúrà tan mọ́ra wọn gan-an