Ẹ Jẹ́ Kí Ọwọ́ Yín Le
“Ẹ jẹ́ kí ọwọ́ yín le, ẹ̀yin tí ẹ ń gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ní àwọn ọjọ́ wọ̀nyí láti ẹnu àwọn wòlíì.”—SEKARÁYÀ 8:9.
1, 2. Kí nìdí tó fi yẹ ká gbé ohun tó wà nínú ìwé Hágáì àti Sekaráyà yẹ̀ wò?
Ó LÉ ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀tàlá [2,500] ọdún sẹ́yìn tí Hágáì àti Sekaráyà ti kọ àsọtẹ́lẹ̀ wọn sílẹ̀, síbẹ̀ ó kàn ọ́ lóde òní. Ọ̀rọ̀ tó wà nínú ìwé méjèèjì yìí kì í ṣe ìtàn lásán. Wọ́n jẹ́ ara “gbogbo ohun tí a ti kọ ní ìgbà ìṣáájú [tí] a kọ fún ìtọ́ni wa.” (Róòmù 15:4) Ọ̀pọ̀ ohun tá a kà nínú wọn ń jẹ́ ká rántí àwọn ohun tó ti ń ṣẹlẹ̀ látìgbà tí Ìjọba Ọlọ́run ti bẹ̀rẹ̀ lọ́run lọ́dún 1914.
2 Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sáwọn èèyàn Ọlọ́run tipẹ́tipẹ́ ṣáájú ìgbà ayé rẹ̀, ó ní: “Wàyí o, nǹkan wọ̀nyí ń bá a lọ ní ṣíṣẹlẹ̀ sí wọn gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ, a sì kọ̀wé wọn kí ó lè jẹ́ ìkìlọ̀ fún àwa tí òpin àwọn ètò àwọn nǹkan dé bá.” (1 Kọ́ríńtì 10:11) Ṣùgbọ́n o lè máa rò ó pé, ‘Báwo ni ìwé Hágáì àti ti Sekaráyà ṣe lè ṣe wá láǹfààní lóde òní?’
3. Ọ̀rọ̀ nípa kí ni Hágáì àti Sekaráyà tẹnu mọ́?
3 Gẹ́gẹ́ bá a ṣe sọ nínú àpilẹ̀kọ́ tó ṣáájú èyí, ìgbà táwọn Júù kúrò nígbèkùn Bábílónì padà wá sí ilẹ̀ tí Ọlọ́run fún wọn ni Hágáì àti Sekaráyà sọ àsọtẹ́lẹ̀ yìí. Ọ̀rọ̀ nípa àtúnkọ́ tẹ́ńpìlì làwọn wòlíì méjèèjì sì tẹnu mọ́. Ọdún 536 ṣáájú Sànmánì Kristẹni làwọn Júù fi ìpìlẹ̀ tẹ́ńpìlì yìí lélẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé nígbà yẹn, àwọn àgbà Júù kan ń ronú nípa tẹ́ńpìlì tàtijọ́, ńṣe ni ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn ń ké “igbe ìdùnnú.” Àmọ́ ṣá o, ohun tó tún ṣe pàtàkì jùyẹn lọ ti ṣẹlẹ̀ nígbà tiwa yìí. Báwo ló ṣe ṣẹlẹ̀?—Ẹ́sírà 3:3-13.
4. Kí ló ṣẹlẹ̀ láìpẹ́ sígbà tí Ogun Àgbáyé Kìíní parí?
4 Láìpẹ́ sígbà tí Ogun Àgbáyé Kìíní parí, Jèhófà dá àwọn ẹni àmì òróró nídè kúrò nígbèkùn Bábílónì Ńlá. Ìdáǹdè yìí jẹ́ ọ̀nà pàtàkì kan tí Jèhófà gbà fi hàn pé òun wà lẹ́yìn wọn. Ṣáájú ìgbà náà, ńṣe ló dà bíi pé àwọn aṣáájú ìsìn àtàwọn aláṣẹ tí wọ́n jọ lẹ̀dí àpò pọ̀ ti fòpin sí iṣẹ́ wíwàásù àti kíkọ́ni táwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ń ṣe káàkiri ayé. (Ẹ́sírà 4:8, 13, 21-24) Ṣùgbọ́n Jèhófà Ọlọ́run mú gbogbo ohun tó jẹ́ ìdènà fún iṣẹ́ ìwàásù àti ìkọ́ni yìí kúrò. Iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run sì ti ń gbilẹ̀ láti ọdún 1919 láìsí nǹkan kan tó lè dá a dúró.
5, 6. Ohun ńlá wo ni Sekaráyà 4:7 fi hàn pé Ọlọ́run máa ṣe?
5 Ó dájú pé kò sóhun tó máa dá iṣẹ́ wíwàásù àti kíkọ́ni táwọn ìránṣẹ́ Jèhófà onígbọràn ń ṣe nígbà tiwa yìí dúró láé nítorí pé Jèhófà ló ń tì wọ́n lẹ́yìn. Sekaráyà 4:7 sọ pé: “Dájúdájú, òun yóò . . . mú olórí òkúta ìpìlẹ̀ jáde wá. Kíkígbe sí i yóò wà, pé: ‘Ó mà lóòfà ẹwà o! Ó mà lóòfà ẹwà o!’” Kí ni ohun ńlá tí ọ̀rọ̀ yìí ń fi hàn pé Jèhófà máa ṣe lóde òní?
6 Ọ̀rọ̀ inú Sekaráyà 4:7 yìí ń sọ nípa ìgbà táwọn èèyàn yóò máa ṣe ìjọsìn tòótọ́, ìyẹn ìjọsìn Olúwa Ọba Aláṣẹ, lọ́nà pípé nínú àgbàlá tẹ́ńpìlì tẹ̀mí rẹ̀ ti orí ilẹ̀ ayé. Tẹ́ńpìlì tẹ̀mí yìí ni ètò tí Jèhófà ṣe nípa bí a ó ṣe máa jọ́sìn òun lọ́lá ẹbọ ìpẹ̀tù Kristi Jésù. Lóòótọ́, ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Kristẹni ni tẹ́ńpìlì ńlá nípa tẹ̀mí yìí ti wà. Ṣùgbọ́n ìjọsìn tòótọ́ kò tíì dé ipò pípé tó yẹ kó wà lórí ilẹ̀ ayé. Lónìí, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ olùjọsìn ló ń sin Ọlọ́run lọ́nà pípé nínú àgbàlá tẹ́ńpìlì tẹ̀mí rẹ̀ ti orí ilẹ̀ ayé. Ìgbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìjọba Jésù Kristi làwọn olùjọsìn yìí àti ọ̀kẹ́ àìmọye tó máa jíǹde yóò di ẹni pípé. Lópin ẹgbẹ̀rún ọdún yìí, àwọn tó ń sin Ọlọ́run lọ́nà tòótọ́ nìkan ṣoṣo ni yóò kù lórí ilẹ̀ ayé tí Ọlọ́run ti fọ̀ mọ́ tónítóní.
7. Ipa wo ni Jésù ń kó nígbà tiwa yìí kí ìjọsìn tòótọ́ lè dé ipò pípé, kí sì nìdí tó fi yẹ kí èyí jẹ́ ìṣírí fún wa?
7 Ojú Serubábélì tó jẹ́ gómìnà àti Jóṣúà Àlùfáà Àgbà ni wọ́n ṣe kọ́ tẹ́ńpìlì náà parí lọ́dún 515 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Àsọtẹ́lẹ̀ inú Sekaráyà 6:12, 13 sì fi hàn pé bẹ́ẹ̀ náà ni Jésù ṣe máa rí sí i pé ìjọsìn tòótọ́ dé ipò pípé. Ó kà pé: “Èyí ni ohun tí Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí: ‘Ọkùnrin náà rèé tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ìrújáde. Láti ipò rẹ̀ ni yóò sì ti rú jáde, dájúdájú, òun yóò sì kọ́ tẹ́ńpìlì Jèhófà. Òun . . . ní tirẹ̀, yóò ru iyì; yóò sì jókòó, yóò sì ṣàkóso lórí ìtẹ́ rẹ̀, òun yóò sì di àlùfáà lórí ìtẹ́ rẹ̀.’” Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Jésù tó wà lọ́run, tó mú kí ìdílé àwọn ọba látọ̀dọ̀ Dáfídì rú jáde, ló wà lẹ́yìn iṣẹ́ Ìjọba Ọlọ́run tó ń lọ lọ́wọ́ nínú tẹ́ńpìlì tẹ̀mí, ǹjẹ́ o rò pé ẹnikẹ́ni lè dí iṣẹ́ yẹn lọ́wọ́ kó má lè tẹ̀ síwájú? Rárá o! Ǹjẹ́ kò yẹ kí èyí mú ká túbọ̀ tẹra mọ́ iṣẹ́ ìsìn wa, ká má ṣe jẹ́ kí àníyàn ayé yìí gbà wá lọ́kàn?
Ohun Tó Yẹ Ká Fi Ṣáájú
8. Kí nìdí tá a fi gbọ́dọ̀ fi iṣẹ́ inú tẹ́ńpìlì nípa tẹ̀mí ṣáájú ohun gbogbo?
8 Tá a bá fẹ́ rí ojú rere Jèhófà àti ìtìlẹyìn rẹ̀, a ní láti fi iṣẹ́ inú tẹ́ńpìlì nípa tẹ̀mí ṣáájú ohun gbogbo. A kò gbọ́dọ̀ dà bí àwọn Júù tó sọ pé, “Àkókò kò tíì tó,” kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló yẹ ká máa rántí pé “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” la wà yìí. (Hágáì 1:2; 2 Tímótì 3:1) Ohun tí Jésù sọ tẹ́lẹ̀ ni pé àwọn olóòótọ́ ọmọlẹ́yìn òun yóò máa wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run wọn yóò sì máa sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn. Nítorí náà, a gbọ́dọ̀ rí i pé a ò fi iṣẹ́ pàtàkì yìí ṣeré rárá. Nígbà kan, àtakò ayé Sátánì mú kí iṣẹ́ yìí dáwọ́ dúró díẹ̀, ṣùgbọ́n ó tún bẹ̀rẹ̀ padà lọ́dún 1919, kò sì tíì parí. Ó dájú pé iṣẹ́ yẹn yóò parí!
9, 10. Kí la ní láti ṣe ká tó lè rí ẹ̀san ire gbà lọ́dọ̀ Jèhófà, ẹ̀kọ́ wo ni ìyẹn sì kọ́ wa?
9 Bí a bá ṣe ṣiṣẹ́ yẹn tọkàntọkàn tó lẹ́nì kọ̀ọ̀kan àti lápapọ̀ ni Jèhófà yóò ṣe san wá lẹ́san ire tó. Wo ìlérí tí Jèhófà ṣe tó lè mú kí èyí dá wa lójú. Jèhófà sọ ohun tí òun yóò ṣe bí àwọn Júù bá lè tún bẹ̀rẹ̀ sí í jọ́sìn òun tọkàntọkàn, tí wọ́n sì padà sídìí iṣẹ́ ìpìlẹ̀ tẹ́ńpìlì tí wọ́n ń ṣe, ó ní: “Láti òní lọ, èmi yóò máa súre.” (Hágáì 2:19) Èyí túmọ̀ sí pé wọ́n á rí ojú rere Jèhófà lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́. Àwọn ìbùkún tí Ọlọ́run sì ṣèlérí fún wọn ni pé: “Irú-ọmọ àlàáfíà yóò wà; àní àjàrà yóò mú èso rẹ̀ wá, ilẹ̀ pàápàá yóò sì mú èso rẹ̀ jáde, ọ̀run pàápàá yóò sì fúnni ní ìrì rẹ̀; dájúdájú, èmi yóò sì mú kí àwọn tí ó ṣẹ́ kù lára àwọn ènìyàn yìí jogún gbogbo nǹkan wọ̀nyí.”—Sekaráyà 8:9-13.
10 Bí Jèhófà ṣe san àwọn Júù yẹn lẹ́san nípa tẹ̀mí àti nípa tara, bẹ́ẹ̀ ni yóò ṣe san àwa náà lẹ́san tá a bá fi tìdùnnú-tìdùnnú tẹra mọ́ iṣẹ́ tó gbé lé wa lọ́wọ́. Lára ohun tó máa fi jíǹkí wa ni àlàáfíà tó máa jọba láàárín wa, ààbò, aásìkí àti ìtẹ̀síwájú nínú ìjọsìn wa. Àmọ́ ká má gbàgbé o, pé a ní láti ṣe iṣẹ́ inú tẹ́ńpìlì tẹ̀mí bí Jèhófà ṣe ní ká ṣe é ká tó lè máa rí ojú rere rẹ̀ nìṣó.
11. Báwo la ṣe lè yẹ ara wa wò?
11 Àkókò gan-an nìyí tá a ní láti ‘fi ọkàn-àyà wa sí àwọn ọ̀nà wa.’ (Hágáì 1:5, 7) Ó yẹ ká fara balẹ̀ yẹ ara wa wò nípa àwọn ohun tá a fi ṣáájú nígbèésí ayé. Bí a bá ṣe gbé orúkọ Jèhófà ga tó àti bí a bá ṣe tẹ̀ síwájú tó nínú iṣẹ́ tẹ́ńpìlì rẹ̀ nípa tẹ̀mí ni Jèhófà yóò ṣe bù kún wa tó lóde òní. Nítorí náà, o lè bi ara rẹ pé: ‘Ṣé mi ò ti máa fi àwọn nǹkan míì ṣáájú ìjọsìn mi? Ǹjẹ́ mo ṣì nítara fún Jèhófà, fún ẹ̀kọ́ òtítọ́ àti fún iṣẹ́ Ọlọ́run bí mo ṣe ní in nígbà tí mo ṣe ìrìbọmi? Ǹjẹ́ ìlépa ìgbé ayé ìdẹ̀ra kò máa nípa lórí ọwọ́ tí mo fi ń mú ìjọsìn Jèhófà àti iṣẹ́ Ìjọba rẹ̀? Ǹjẹ́ ìbẹ̀rù èèyàn, ìyẹn ìbẹ̀rù ohun táwọn èèyàn máa wí, kò ti mú kí n fà sẹ́yìn bákan ṣáá lẹ́nu iṣẹ́ Ọlọ́run?’—Ìṣípayá 2:2-4.
12. Kí ni Hágáì 1:6, 9 sọ pé ó ṣẹlẹ̀ sáwọn Júù?
12 A kò ní fẹ́ kí Ọlọ́run fawọ́ ìbùkún jìngbìnnì rẹ̀ sẹ́yìn torí pé a kò gbé orúkọ rẹ̀ ga. Rántí pé àwọn Júù tó padà wálé láti ìgbèkùn kọ́kọ́ káràmáásìkí iṣẹ́ àtúnkọ́ tẹ́ńpìlì kó tó di pé wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í “sá kiri, olúkúlùkù nítorí ilé tirẹ̀” gẹ́gẹ́ bí Hágáì 1:9 ṣe wí. Wọ́n jẹ́ kí ìlépa nǹkan tara wọn gbà wọ́n lọ́kàn. Àbáyọrí èyí ni pé nǹkan ‘díẹ̀ ni wọ́n ń mú wọlé,’ ní ti pé wọn ò róúnjẹ jẹ tó, wọn ò fi bẹ́ẹ̀ rí ọtí mu, wọn ò sì fi bẹ́ẹ̀ rí aṣọ tó lè mú ara móoru wọ̀. (Hágáì 1:6) Ìdí ni pé Jèhófà ti fawọ́ ìbùkún rẹ̀ sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ wọn. Ǹjẹ́ a rí ẹ̀kọ́ kọ́ nínú èyí?
13, 14. Báwo la ṣe lè lo ẹ̀kọ́ tá a rí kọ́ nínú Hágáì 1:6, 9, kí sì nìdí tí èyí fi ṣe pàtàkì?
13 Ǹjẹ́ o ò gbà pé tá a bá fẹ́ máa rí ìbùkún Ọlọ́run gbà, a ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ìlépa nǹkan tara wa dí ìjọsìn wa sí Jèhófà lọ́wọ́? A ní láti rí i pé a kò gba ohun yòówù tó bá lè fa ìpínyà ọkàn fún wa nínú ìjọsìn láyè, ì báà jẹ́ ìlépa ọrọ̀, okòwò tó lè sọni dolówó òjijì, ìlépa ẹ̀kọ́ nílé ìwé gíga láti lè dépò ńlá nínú ayé, tàbí ìlépa ètò ẹ̀kọ́ mìíràn tó lè gbé wa dépò tá a fẹ́.
14 Nǹkan wọ̀nyẹn lè má burú lóòótọ́ o. Àmọ́ tá a bá ń sọ̀rọ̀ nípa ohun tó lè múni ní ìyè ayérayé, ǹjẹ́ o kò rí i pé “òkú iṣẹ́” ni wọ́n jẹ́? (Hébérù 9:14) Báwo ni wọ́n ṣe jẹ́ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé òkú iṣẹ́, ohun àìníláárí tàbí ohun asán gbáà ni wọ́n jẹ́ lágbo àwọn ohun tó lè múni tẹ̀ síwájú nínú ìjọsìn àti àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run. Téèyàn ò bá jáwọ́ nínú irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀, wọ́n lè ba àjọṣe ẹni pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́. Irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ṣẹlẹ̀ sáwọn Kristẹni ẹni àmì òróró kan nígbà ayé àwọn àpọ́sítélì. (Fílípì 3:17-19) Ó sì tún ṣẹlẹ̀ sáwọn kan lóde òní pẹ̀lú. Ó ṣeé ṣe kó o mọ àwọn kan tó jẹ́ pé díẹ̀díẹ̀ làwọn nǹkan míì tí wọ́n ń lépa gbà wọ́n lọ́kàn tí wọn ò fi kópa mọ́ nínú ìgbòkègbodò Kristẹni tí wọn ò sì wá sípàdé mọ́. Tó sì jẹ́ pé títí di báyìí ọkàn wọn ò tiẹ̀ sí nínú pé kí wọ́n padà wá máa sin Jèhófà. Ìrètí wa ni pé irú àwọn bẹ́ẹ̀ yóò padà sọ́dọ̀ Jèhófà lọ́jọ́ kan. Àmọ́ ohun kan tó dájú ni pé, téèyàn bá ń lépa “òkú iṣẹ́,” Jèhófà ò ní bù kún onítọ̀hún, kò sì ní fojú rere wò ó. Ìyẹn yóò sì burú jáì, nítorí ńṣe lonítọ̀hún máa pàdánù ayọ̀ àti àlàáfíà tí ẹ̀mí Ọlọ́run máa ń jẹ́ kéèyàn ní. Ẹ ò rí i pé àdánù ńlá ló máa jẹ́ fẹ́ni tó bá pàdánù ìfararora aláyọ̀ tó wà láàárín àwọn ará!—Gálátíà 1:6; 5:7, 13, 22-24.
15. Báwo ni Hágáì 2:14 ṣe jẹ́ ká rí i pé ọ̀rọ̀ ìjọsìn wa kì í ṣe nǹkan kékeré?
15 Nǹkan kékeré kọ́ lọ̀rọ̀ yìí o. Wo bí Hágáì 2:14 ṣe sọ irú ojú tí Jèhófà fi wo àwọn Júù tó pa ilé ìjọsìn Ọlọ́run tì tí wọ́n wá lọ ń figi dárà sí ilé tara wọn, yálà wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀ ní ti gidi ni o tàbí wọ́n kàn ń ṣe ohun tó máa mú ilé wọn lẹ́wà sí i bákan ṣáá. Ó ní: “‘Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ènìyàn yìí rí, bẹ́ẹ̀ sì ni orílẹ̀-èdè yìí rí níwájú mi,’ ni àsọjáde Jèhófà, ‘bẹ́ẹ̀ sì ni gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ wọn rí, àti ohun yòówù tí wọ́n bá mú wá síbẹ̀. Ó jẹ́ aláìmọ́.’” Táwọn Júù tí ò fi gbogbo ọkàn wọn sin Jèhófà yìí kò bá kọ́kọ́ kọbi ara sí ìjọsìn tòótọ́, inú Ọlọ́run ò lè dùn sí ẹbọ yòówù kí wọ́n máa rú lórí pẹpẹ tí wọ́n ṣì mọ sí Jerúsálẹ́mù nígbà yẹn.—Ẹ́sírà 3:3.
Ọlọ́run Fi Dá Àwọn Ìránṣẹ́ Rẹ̀ Lójú Pé Òun Wà Lẹ́yìn Wọn
16. Kí ni àwọn ìran tí Sekaráyà rí jẹ́ kó dá àwọn Júù lójú pé yóò ṣẹlẹ̀?
16 Ọlọ́run tipa ìran mẹ́jọ tí Sekaráyà rí fi dá àwọn Júù onígbọràn tó ń ṣiṣẹ́ àtúnkọ́ tẹ́ńpìlì lójú pé òun wà lẹ́yìn wọn. Ìran àkọ́kọ́ fi dá àwọn Júù lójú pé iṣẹ́ àtúnkọ́ tẹ́ńpìlì máa parí dandan àti pé nǹkan yóò rọ̀ṣọ̀mù ní Jerúsálẹ́mù àti ilẹ̀ Júdà bí àwọn Júù bá ti lè parí iṣẹ́ tí Ọlọ́run ní kí wọ́n ṣe. (Sekaráyà 1:8-17) Ìran kejì fi yé wọn pé gbogbo ìjọba tó ta ko ìsìn tòótọ́ yóò pa run dájúdájú. (Sekaráyà 1:18-21) Àwọn ìran yòókù jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ààbò Ọlọ́run máa wà lórí iṣẹ́ ìkọ́lé tí wọ́n ń ṣe, pé àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè púpọ̀ yóò rọ́ wá sínú ilé ìjọsìn Jèhófà tí wọ́n bá kọ́ ọ parí, pé àlàáfíà àti ààbò yóò wà, pé gbogbo ohun tó dà bí òkè ìṣòro tó ń dí iṣẹ́ Ọlọ́run lọ́wọ́ yóò di pẹ̀tẹ́lẹ̀, pé Ọlọ́run yóò mú ìwà ibi kúrò àti pé àwọn áńgẹ́lì yóò bójú tó wọn, yóò sì dáàbò bò wọ́n. (Sekaráyà 2:5, 11; 3:10; 4:7; 5:6-11; 6:1-8) O lè wá rí ìdí táwọn Júù onígbọràn fi yí ọ̀nà tí wọ́n gbà ń gbé ìgbé ayé wọn padà nígbà tó dá wọn lójú pé Ọlọ́run wà lẹ́yìn wọn, tí wọ́n sì gbájú mọ́ iṣẹ́ tí Ọlọ́run tìtorí ẹ̀ dá wọn nídè.
17. Níwọ̀n bí Ọlọ́run ti jẹ́ kó dá wa lójú pé ìjọsìn tòótọ́ yóò borí, àwọn ìbéèrè wo ló yẹ ká bi ara wa?
17 Lónìí bákan náà, níwọ̀n bó ti dá wa lójú pé ìjọsìn tòótọ́ yóò borí, ó yẹ kí ìyẹn mú wa ronú jinlẹ̀ nípa ilé ìjọsìn Jèhófà ká sì káràmáásìkí iṣẹ́ Ọlọ́run. Á dára kó o bi ara rẹ láwọn ìbéèrè yìí: ‘Bí mo bá gbà pé ìsinsìnyí ló yẹ ká máa wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run lójú méjèèjì ká sì máa sọni di ọmọ ẹ̀yìn, ǹjẹ́ àwọn ohun tí mò ń lépa àti ọ̀nà tí mo gbà ń gbé ìgbé ayé mi fi hàn pé mo gbà bẹ́ẹ̀ lóòótọ́? Ǹjẹ́ mò ń lo àkókò tó pọ̀ tó láti fi kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó kún fún àsọtẹ́lẹ̀, kí n máa ṣàṣàrò lé e lórí kí n sì máa bá àwọn Kristẹni bíi tèmi àtàwọn ẹlòmíì jíròrò nípa rẹ̀?’
18. Kí ló ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú, gẹ́gẹ́ bí Sekaráyà orí kẹrìnlá ṣe fi hàn?
18 Sekaráyà sọ̀rọ̀ nípa ìparun Bábílónì Ńlá tí ogun Amágẹ́dọ́nì yóò tẹ̀ lé. Ó sọ pé: “Yóò sì di ọjọ́ kan tí a mọ̀ pé ó jẹ́ ti Jèhófà. Kì yóò jẹ́ ọ̀sán, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò jẹ́ òru; yóò sì ṣẹlẹ̀ pé ní ìrọ̀lẹ́ yóò di ìmọ́lẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ ni o, ọjọ́ tó ṣókùnkùn tó sì burú jáì ni ọjọ́ Jèhófà yóò jẹ́ fáwọn ọ̀tá rẹ̀ tó wà lórí ilẹ̀ ayé! Àmọ́ yóò jẹ́ àkókò ìmọ́lẹ̀ tí kò ní yéé tàn àti àkókò ojú rere tí kò ní lópin fún àwọn olùjọsìn Jèhófà tí wọ́n jẹ́ onígbọràn. Sekaráyà tún ṣàpèjúwe bí ohun gbogbo yóò ṣe máa kókìkí ìjẹ́mímọ́ Jèhófà nínú ayé tuntun. Kìkì ìjọsìn tòótọ́ tá à ń ṣe sí Ọlọ́run nínú tẹ́ńpìlì ńlá nípa tẹ̀mí ló máa ṣẹ́ kù láyé. (Sekaráyà 14:7, 16-19) Ohun ńlá gbáà ni Ọlọ́run fi dá wa lójú yìí o! Àwọn ohun tí àsọtẹ́lẹ̀ yìí wí máa ṣẹ níṣojú wa, a ó sì tún rí bí ìdáláre Jèhófà gẹ́gẹ́ bí Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run yóò ṣe wáyé. Áà, ọjọ́ Jèhófà, ọjọ́ lọjọ́ náà yóò jẹ́!
Ìbùkún Ayérayé
19, 20. Kí nìdí tí ọ̀rọ̀ inú Sekaráyà 14:8, 9 fi jẹ́ ìṣírí fún ọ?
19 Lẹ́yìn tí gbogbo ìyẹn bá ṣẹlẹ̀ tán, Jésù yóò sọ Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ dèrò ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ níbi tí wọn ò ti ní lè ta pútú. (Ìṣípayá 20:1-3, 7) Ìbùkún yabuga-yabuga yóò wá máa tú jáde nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìjọba Kristi. Sekaráyà 14:8, 9 sọ pé: “Yóò sì ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ yẹn pé omi ààyè yóò jáde lọ láti Jerúsálẹ́mù, ìdajì rẹ̀ sí òkun ìhà ìlà-oòrùn àti ìdajì rẹ̀ sí òkun ìhà ìwọ̀-oòrùn. Ní ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn àti ní ìgbà òtútù ni yóò ṣẹlẹ̀. Jèhófà yóò sì di ọba lórí gbogbo ilẹ̀ ayé. Ní ọjọ́ yẹn, Jèhófà yóò jẹ́ ọ̀kan, orúkọ rẹ̀ yóò sì jẹ́ ọ̀kan.”
20 “Omi ààyè” tàbí “odò omi ìyè,” tó dúró fún àwọn ètò tí Jèhófà ṣe láti fi gbé ìwàláàyè wa ró, yóò máa ṣàn gbùúgbùú jáde láti ibi ìtẹ́ Ìjọba Mèsáyà. (Ìṣípayá 22:1, 2) Ogunlọ́gọ̀ ńlá àwọn olùjọsìn Jèhófà tó la Amágẹ́dọ́nì já yóò bọ́ lọ́wọ́ ikú tí ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù fà. Kódà àwọn tó ti kú yóò jàǹfààní ní ti pé wọn yóò jíǹde. Bí Jèhófà yóò ṣe tún bẹ̀rẹ̀ ìṣàkóso rẹ̀ lórí ayé lákọ̀tun nìyẹn. Gbogbo èèyàn jákèjádò ayé ni yóò sì gbà pé Jèhófà ni Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run, àti pé òun lẹ́nì kan ṣoṣo tó yẹ láti máa sìn.
21. Kí ló yẹ ká pinnu pé a ó máa ṣe?
21 Pẹ̀lú gbogbo àsọtẹ́lẹ̀ inú ìwé Hágáì àti Sekaráyà yìí àti gbogbo àwọn tó ti ṣẹ lára wọn, kò sí àní-àní pé ńṣe ló yẹ ká máa bá iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé lé wa lọ́wọ́ lọ ní pẹrẹu nínú àgbàlá tẹ́ńpìlì tẹ̀mí rẹ̀ ti orí ilẹ̀ ayé. Ó sì yẹ ká máa sa gbogbo ipá wa láti fi iṣẹ́ Ọlọ́run ṣáájú ohun gbogbo títí Jésù yóò fi mú ìjọsìn tòótọ́ dé ipò pípé. Sekaráyà 8:9 rọ̀ wá pé: “Ẹ jẹ́ kí ọwọ́ yín le, ẹ̀yin tí ẹ ń gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ní àwọn ọjọ́ wọ̀nyí láti ẹnu àwọn wòlíì.”
Ǹjẹ́ O Rántí?
• Àwọn nǹkan wo ló ń ṣẹlẹ̀ lónìí tó fi hàn pé àsọtẹ́lẹ̀ inú ìwé Hágáì àti Sekaráyà kàn wá?
• Ẹ̀kọ́ wo ni ìwé Hágáì àti Sekaráyà kọ́ wa nípa ohun tó yẹ ká fi sípò iwájú?
• Kí nìdí tí àyẹ̀wò ìwé Hágáì àti Sekaráyà tá a ṣe fi mú ká ní ìdánilójú nípa ọjọ́ ọ̀la?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Hágáì àti Sekaráyà gba àwọn Júù níyànjú pé kí wọ́n ṣe iṣẹ́ Ọlọ́run tọkàntọkàn kí wọ́n lè rí ìbùkún gbà
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]
Ṣé ìwọ ò ‘máa sá kiri nítorí ilé tìrẹ’?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
Jèhófà ṣèlérí ìbùkún, ó sì ti pèsè ìbùkún ọ̀hún