Wàá Ní Ìbàlẹ̀ Ọkàn Tó O Bá Ń Fi Ìlànà Bíbélì Sílò
KÒ SÍ àní-àní pé wàá ti rí ológbò kan tó rọra ká gulutu rí, tó rọra ń ké mín-án-un, mín-án-un. Àmì pé ọkàn rẹ̀ balẹ̀ gan-an nìyẹn. Báwo ni ì bá ti dára tó ká láwa náà lè wà nírú ipò yẹn ká sì ní ìbàlẹ̀ ọkàn bíi tirẹ̀! Àmọ́, ó ṣòro fún ọ̀pọ̀ èèyàn láti ní ìbàlẹ̀ ọkàn, tí wọ́n bá sì ní in, kì í pẹ́ lọ. Kí ló fà á?
Nítorí pé a jẹ́ aláìpé, a máa ń ṣàṣìṣe lọ́pọ̀ ìgbà, bẹ́ẹ̀ la sì tún ní láti fara da àṣìṣe àwọn ẹlòmíràn. Síwájú sí i, àkókò tí Bíbélì pè ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” la wà yìí, ó sì jẹ́ “àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò.” (2 Tímótì 3:1-5) Ká tiẹ̀ ní inú wa máa ń dùn nígbà tá a bá rántí ìgbà tá a wà lọ́mọdé tá a ní ìbàlẹ̀ ọkàn, síbẹ̀ ọ̀pọ̀ jù lọ wa ló ń mọ̀ ọ́n lára nísinsìnyí pé “àwọn àkókò lílekoko” yìí kò rọrùn rárá. Ǹjẹ́ ó tiẹ̀ ṣeé ṣe láti ní ìbàlẹ̀ ọkàn lákòókò tá a wà yìí?
Kíyè sí i pé ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ ni pé àwọn àkókò lílekoko yìí á nira láti fara dà, kò sọ pé kò ní ṣeé fara dà. Tá a bá ń fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò, á ṣeé ṣe fún wa láti fara dà á. A lè má lè yanjú àwọn ìṣòro wa ní gbogbo ìgbà, àmọ́ a óò ní ìbàlẹ̀ ọkàn díẹ̀. Ẹ jẹ́ ká gbé mẹ́ta yẹ̀ wò lára irú àwọn ìlànà bẹ́ẹ̀.
Máa Rántí Pé Ó Níbi Tágbára Rẹ Mọ
Tá a bá fẹ́ ní ìbàlẹ̀ ọkàn, a gbọ́dọ̀ máa rántí pé ó níbi tágbára wa mọ ká sì tún mọ̀ pé bó ṣe rí fáwọn mìíràn náà nìyẹn. Nínú lẹ́tà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn ará Róòmù, ó jẹ́ ká mọ̀ pé: “Gbogbo ènìyàn ti ṣẹ̀, wọ́n sì ti kùnà láti kúnjú ìwọ̀n ògo Ọlọ́run.” (Róòmù 3:23) Ọ̀pọ̀ lára àwọn iṣẹ́ àrà tí Jèhófà ṣe ló kọjá ohun táwa ẹ̀dá lè lóye rẹ̀. Àpẹẹrẹ kan ni òtítọ́ pọ́ńbélé tó wà nínú Jẹ́nẹ́sísì 1:31, èyí tó sọ ní ṣókí pé: “Ọlọ́run rí ohun gbogbo tí ó ti ṣe, sì wò ó! ó dára gan-an ni.” Kò sígbà tí Jèhófà wo àwọn ohun tó ti ṣe sẹ́yìn tí kò ní sọ pé “ó dára gan-an.” Àmọ́ kò sí ẹ̀dá èèyàn kankan tó lè sọ pé gbogbo ohun tóun ti ṣe sẹ́yìn ló dára gan-an. Ohun àkọ́kọ́ tó máa jẹ́ ká ní ìbàlẹ̀ ọkàn ni ká gbà pé ó níbi tágbára wa mọ. Àmọ́ kò parí síbẹ̀ yẹn. A tún gbọ́dọ̀ mọ èrò Jèhófà lórí kókó yìí ká sì fara mọ́ èrò náà.
Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n tú sí “ẹ̀ṣẹ̀” wá látinú ọ̀rọ̀ ìpilẹ̀ṣẹ̀ kan tó túmọ̀ sí “kíkùnà láti dójú àmì.” Àpèjúwe kan tá a lè lò fún un rèé: Fojú inú wo ẹnì kan tó ń retí àtigba ẹ̀bùn bó bá lè ta ọfà kan kí ọfà náà sì ba ọ̀gangan ibi tó fẹ́ kó bà. Ọfà mẹ́ta ló wà lọ́wọ́ rẹ̀. Ó ta ọfà àkọ́kọ́, àmọ́ ó ku nǹkan bí ẹsẹ̀ bàtà mẹ́ta kí ọ̀fà náà dé ibi tó fẹ́ kó bà gangan. Kó tó ta ọfà kejì, ó wo ibi tó fẹ́ kó bà náà dáadáa, síbẹ̀ ó tún ku nǹkan bí ẹsẹ̀ bàtà kan kó bọ́ sójú ibi tó fẹ́ kó bà náà. Ó wá fara balẹ̀ dáadáa kó tó ta ọfà kẹta, ṣùgbọ́n ó tún kù díẹ̀ kín-ún kó bọ́ sójú ibi tó fẹ́ kó bà náà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọfà náà sún mọ́ ibẹ̀ gan-an, síbẹ̀ kò bọ́ sójú ibi tó fẹ́ kó bà yẹn gangan.
Bíi tafàtafà tí ọfà rẹ̀ kò bọ́ sójú ibi tó fẹ́ kó bà gangan yẹn ni gbogbo wa rí. Nígbà míì, á dà bíi pé a ‘ò dé ojú àmì’ náà rárá. Ìgbà míì sì rèé á dà bíi pé díẹ̀ kíún ló kù ká dójú àmì náà, ṣùgbọ́n síbẹ̀ a ò tíì débẹ̀. Èyí máa ń dùn wá gan-an, nítorí pé a gbìyànjú gan-an síbẹ̀ a ò ṣe dáadáa tó. Ẹ jẹ́ ká tún padà sọ́dọ̀ tafàtafà yẹn.
Ó yẹ́yìn padà ó sì rọra ń lọ. Inú rẹ̀ bà jẹ́ gidigidi nítorí pé ó wù ú gan-an láti gba ẹ̀bùn yẹn. Lójijì lẹni tó ń bójú tó ìdíje náà pè é padà ó sì fún un lẹ́bùn náà. Ó wá sọ fún un pé: “Ìdí tí mo fi fún ẹ lẹ́bùn yìí ni pé mo nífẹ̀ẹ́ rẹ, mo sì rí i pé o gbìyànjú lọ́pọ̀lọpọ̀.” Inú tafàtafà yìí dùn gan-an!
Bí inú tafàtafà yìí ṣe dùn gan-an ni inú gbogbo ẹni tó bá gba “ẹ̀bùn” tí Ọlọ́run fẹ́ fúnni ṣe máa dùn, ìyẹn ẹ̀bùn ìyè àìnípẹ̀kun nínú Párádísè níbi táwọn èèyàn á ti jẹ́ ẹni pípé. (Róòmù 6:23) Látìgbà náà lọ, gbogbo ohun tí wọ́n bá ń ṣe ni yóò dára, wọn ò tún ní ṣàìdé ojú àmì náà mọ́ láé. Wọ́n á ní ojúlówó ìbàlẹ̀ ọkàn. Kí àkókò yẹn tó dé, tá a bá ń wo àwọn nǹkan lọ́nà yìí, a ò ní máa bọkàn jẹ́ jù nítorí ìkùdíẹ̀–káàtó wa àti tàwọn ẹlòmíràn.
Máa Rántí Pé Gbogbo Nǹkan Ló Ní Àsìkò Tirẹ̀
Kò sírọ́ níbẹ̀ pé gbogbo nǹkan ló ní àsìkò tirẹ̀. Àmọ́, ǹjẹ́ o ti ṣàkíyèsí pé ó máa ń ṣòro gan-an láti ní ìbàlẹ̀ ọkàn tó bá dà bíi pé ohun kan tí ò ń retí kò tètè tẹ̀ ọ́ lọ́wọ́ bó o ṣe lérò tẹ́lẹ̀ tàbí tí ìṣòro kan tó o ní kò bá yanjú bọ̀rọ̀ bó o ṣe rò pé ó máa tètè yanjú? Síbẹ̀, àwọn kan ti wà nírú ipò yìí tí wọ́n sì ní ìbàlẹ̀ ọkàn. Wo àpẹẹrẹ ti Jésù.
Kí Jésù tó wá sáyé, àpẹẹrẹ gidi ló jẹ́ nínú ṣíṣègbọràn ní ọ̀run. Àmọ́ o, orí ilẹ̀ ayé ńbí ló ti wá “kọ́ ìgbọràn.” Lọ́nà wo? “Láti inú àwọn ohun tí ó jìyà rẹ̀” ni. Kó tó wá sáyé, ó ti rí i bí ìyà ṣe ń jẹ àwọn èèyàn àmọ́ òun fúnra rẹ̀ kò mọ bó ṣe ń rí lára. Nígbà tó wá dé orí ilẹ̀ ayé, ó dojú kọ ọ̀pọ̀ ìṣòro, àgàgà látìgbà tó ti ṣèrìbọmi lódò Jọ́dánì títí tó fi kú níbi tí wọ́n ń pè ní Gọ́gọ́tà. A ò mọ gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀ bí Jésù ṣe di ẹni tá a sọ “di pípé” lórí ọ̀ràn yìí, ṣùgbọ́n a mọ̀ pé kíkọ́ ìgbọràn yẹn gba àkókò.—Hébérù 5:8, 9.
Ohun tó mú kí Jésù lè ṣàṣeyọrí ni pé ó ṣàṣàrò lórí “ìdùnnú tí a gbé ka iwájú rẹ̀,” ìyẹn èrè ìṣòtítọ́ rẹ̀. (Hébérù 12:2) Síbẹ̀, àwọn ìgbà míì wà tó “ṣe ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ àti ìtọrọ . . . pẹ̀lú igbe ẹkún kíkankíkan àti omijé.” (Hébérù 5:7) Nígbà míì, àwa náà lè bára wa nípò tó máa mú ká gba irú àdúrà yẹn. Ojú wo ni Jèhófà fi ń wo irú àdúrà yìí? Ẹsẹ yẹn fi hàn pé Jèhófà gbọ́ àdúrà Jésù “pẹ̀lú ojú rere.” Ọlọ́run yóò gbọ́ tiwa náà. Kí nìdí?
Ìdí ni pé Jèhófà mọ ibi tí agbára wa mọ ó sì máa ń ràn wá lọ́wọ́. Gbogbo wa ló níbi tá a lè fara da nǹkan mọ. Àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè Benin nílẹ̀ Áfíríkà máa ń sọ gbólóhùn kan pé: “Bí omi bá pàpọ̀jù, àkèré pàápàá á bómi lọ.” Jèhófà mọ̀ ju bí àwa fúnra wa ṣe mọ̀ lọ tó bá di pé agbára wa kò fẹ́ gbé e mọ́. Tìfẹ́tìfẹ́ ló fi máa ń pèsè ‘àánú àti inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí fún ìrànlọ́wọ́ ní àkókò tí ó tọ́.’ (Hébérù 4:16) Ó ṣe bẹ́ẹ̀ fún Jésù, ó sì ti ṣe bẹ́ẹ̀ fún àìmọye àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ mìíràn. Wo bí arábìnrin kan tó ń jẹ́ Monika ṣe rí ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run gbà.
Nígbà tí Monika ń dàgbà, kò fi bẹ́ẹ̀ níṣòro tàbí wàhálà, gágá lara rẹ̀ máa ń yá, ọlọ́yàyà èèyàn sì ni. Àmọ́ lọ́dún 1968, nígbà tó ṣẹ̀ṣẹ̀ lé díẹ̀ lọ́mọ ogún ọdún, jìnnìjìnnì bò ó nígbà tó gbọ́ pé òun ní àrùn tó ń mú kí iṣan ara le gbagidi tó sì sábà máa ń yọrí sí kí apá kan ara rọ pátápátá. Èyí yí ìgbésí ayé rẹ̀ padà pátápátá ó sì di dandan kó ṣe àwọn ìyípadà ńlá nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò-kíkún tó ń ṣe. Monika rí i pé àìsàn tó kọ lu òun kì í ṣe àìsàn tó máa lọ bọ̀rọ̀. Ọdún mẹ́rìndínlógún lẹ́yìn náà, ó sọ pé: “Kò tíì sí oògùn tó lè wo àìsàn tó ń ṣe mí yìí sàn, ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé bó ṣe máa wà nìyẹn títí ètò àwọn nǹkan tuntun tí Ọlọ́run ń mú bọ̀ á fi sọ ohun gbogbo dọ̀tun.” Monika gbà pé nǹkan kò rọrùn fóun rárá. Ó ní: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọ̀rẹ́ mi máa ń sọ pé jíjẹ́ tí mo jẹ́ ọlọ́yàyà èèyàn tí mo sì máa ń láyọ̀ nígbà gbogbo kò yí padà, . . . síbẹ̀ àwọn ọ̀rẹ́ mi tó sún mọ́ mi gan-an mọ̀ pé àwọn ìgbà míì wà tó jẹ́ pé ńṣe lomi máa ń dà lójú mi pẹ̀rẹ̀pẹ̀rẹ̀ tí kò sì ní dáwọ́ dúró.”
Àmọ́ ó fi kún un pé: “Mo ti kọ́ béèyàn ṣe ń ní sùúrù, mo sì ti kọ́ láti máa láyọ̀ nígbàkigbà tára mi ba le díẹ̀, ì báà tiẹ̀ jẹ́ pé ìwọ̀nba ìyàtọ̀ díẹ̀ ni mo rí. Mímọ̀ tí mo mọ̀ pé òtúbáńtẹ́ ni gbogbo ìsapá èèyàn láti mú àìsàn kúrò ti mú kí àjọṣe mi pẹ̀lú Jèhófà lágbára sí i. Jèhófà nìkan ṣoṣo ló lè woni sàn pátápátá.” Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, ó ṣeé ṣe fún Monika láti máa ní ìbàlẹ̀ ọkàn nìṣó, ó sì ti lo ohun tó lé lógójì ọdún lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alákòókò-kíkún.
Ká sòótọ́, kò rọrùn láti fara da irú ìṣòro tí Monika ní yìí. Àmọ́ ohun kan tó dájú ni pé, mímọ̀ pé àwọn nǹkan kan lè gba àkókò ju bó o ṣe rò lọ á jẹ́ kó o lè túbọ̀ ní ìbàlẹ̀ ọkàn. Bíi ti Monika, jẹ́ kó dá ọ lójú pé “ìrànlọ́wọ́ ní àkókò tí ó tọ́” yóò ti ọ̀dọ̀ Jèhófà wá.
Má Ṣe Fara Rẹ Wé Ẹlòmíràn—Ohun Tó O Mọ̀ Pọ́wọ́ Rẹ Lè Tẹ̀ Ni Kó O Máa Lé
Gbogbo ọ̀nà ni o fi yàtọ̀ sí ẹlòmíràn. Kò sì sí ẹlòmíràn tó dà bíìrẹ gangan. Òwe Yorùbá kan sọ kókó yìí lọ́nà rírọrùn. Ó ní: “Ìka kò dọ́gba.” Ìwà òmùgọ̀ ni kéèyàn máa fi ìka kan wé òmíràn. O ò ní fẹ́ kí Jèhófà fi ọ́ wé ẹlòmíràn, kò sì ní ṣe bẹ́ẹ̀ láéláé. Àmọ́ láàárín èèyàn, fífira ẹni wé ẹlòmíràn wọ́pọ̀ gan-an, kò sì ń jẹ́ kéèyàn lè ní ìbàlẹ̀ ọkàn. Wo àkàwé kan tí Jésù ṣe tó gbé kókó yìí jáde lọ́nà tó fakíki bí a ó ti kà á nínú Mátíù 20:1-16.
Jésù sọ̀rọ̀ nípa “ọ̀gá” kan tó nílò àwọn òṣìṣẹ́ nínú ọgbà àjàrà rẹ̀. Ní “òwúrọ̀ kùtùkùtù,” tó ṣeé ṣe kó jẹ́ aago mẹ́fà òwúrọ̀, ó rí àwọn ọkùnrin kan tí wọn ò níṣẹ́ lọ́wọ́ ó sì háyà wọn. Iye tí òṣìṣẹ́ sábà máa ń gbà lóòjọ́ láyé ìgbà yẹn ni wọ́n jọ ṣàdéhùn lé lórí, ìyẹn dínárì kan fún iṣẹ́ ọjọ́ kan tó jẹ́ wákátì méjìlá. Ó dájú pé inú àwọn ọkùnrin wọ̀nyẹn á dùn pé àwọn tiẹ̀ ríṣẹ́ àti pé iye tí òṣìṣẹ́ ń gbà náà làwọn máa gbà. Nígbà tó yá, ọ̀gá náà tún rí àwọn ọkùnrin mìíràn tí wọn ò ríṣẹ́ ṣe. Ó gba àwọn kan láago mẹ́sàn-án òwúrọ̀, àwọn kan láago méjìlá ọ̀sán, àwọn kan láago mẹ́ta, kódà ó gba àwọn kan láago márùn-ún ìrọ̀lẹ́ tọ́jọ́ ti lọ tán. Kò sí èyíkéyìí nínú àwọn tó dé kẹ́yìn yìí tó ṣiṣẹ́ odindi ọjọ́ kan pé. Ní ti owó iṣẹ́, ọ̀gá náà ṣèlérí pé “ohun yòówù tí ó bá tọ́” lòun máa fún wọn, wọ́n sì gbà.
Lópin ọjọ́ náà, ọ̀gá náà pàṣẹ pé kí ẹni tó ń mójú tó iṣẹ́ náà sanwó fáwọn òṣìṣẹ́. Ó ní kó pe àwọn òṣìṣẹ́ náà kó sì kọ́kọ́ sanwó fáwọn tóun háyà kẹ́yìn. Iṣẹ́ wákàtí kan péré làwọn wọ̀nyí ṣe, àmọ́ ìyàlẹ́nu ló jẹ́ pé owó iṣẹ́ odindi ọjọ́ kan ni wọ́n gbà. A lè fojú inú wo irú ìjíròrò tí yóò máa lọ láàárín àwọn òṣìṣẹ́ náà. Èyí mú káwọn tó ṣiṣẹ́ wákàtí méjìlá rò pé owó tàwọn náà yóò lé sí i. Àmọ́, iye kan náà ni wọ́n gbà.
Kí ni wọ́n ṣe? “Nígbà tí wọ́n gbà á, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí kùn sí baálé ilé náà, wọ́n sì wí pé, ‘Àwọn ẹni ìkẹyìn wọ̀nyí ṣe iṣẹ́ wákàtí kan; síbẹ̀ ìwọ mú wọn bá wa dọ́gba, àwa tí a fàyà rán iṣẹ́ ìnira òní àti ooru tí ń jóni!’”
Àmọ́ ọ̀nà tí ọ̀gá yìí gbà wò ó yàtọ̀. Ó jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé iye tí wọ́n jọ ṣàdéhùn lé lórí ni wọ́n gbà, kò dín síye yẹn. Àmọ́ ní ti àwọn òṣìṣẹ́ yòókù yẹn, ó pinnu láti san owó iṣẹ́ odindi ọjọ́ kan fún wọn, kò sì sí àní-àní pé ìyẹn ju iye tí wọ́n fọkàn sí lọ. Ká sòótọ́, kò sẹ́ni tó gbà dín síye tí wọ́n jọ ṣàdéhùn rẹ̀, kódà ọ̀pọ̀ tiẹ̀ gbà ju iye tí wọ́n fọkàn sí lọ. Ọ̀gá náà wá fi ìbéèrè kan kádìí ọ̀rọ̀ náà pé: “Kò ha bófin mu fún mi láti fi àwọn nǹkan tí ó jẹ́ tèmi ṣe ohun tí mo fẹ́?”
Ìwọ rò ó ná, ká láwọn tí ọ̀gá náà kọ́kọ́ háyà yẹn ni alámòójútó náà kọ́kọ́ sanwó fún tí wọ́n sì ti lọ, iye tí wọ́n gbà yẹn ì bá ti tẹ́ wọn lọ́rùn. Ìgbà tí wọ́n rí i pé iye kan náà làwọn yòókù tí kò ṣiṣẹ́ tó àwọn gbà ni wọ́n di aláìnítẹ̀ẹ́lọ́rùn. Èyí sì bí wọn nínú débi pé wọ́n tiẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í kùn sí ọ̀gá yẹn, ẹni tó yẹ kí wọ́n máa dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ gan-an pé ó tiẹ̀ gba àwọn síṣẹ́.
Àkàwé yìí jẹ́ ká rí ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ ní kedere nígbà tá a bá bẹ̀rẹ̀ sí í fi ara wa wé àwọn mìíràn. Bó o bá ń ṣàṣàrò lórí àjọṣe rẹ pẹ̀lú Jèhófà tó o sì tún mọyì bó ṣe ń bù kún ọ, ó dájú pé wàá nítẹ̀ẹ́lọ́rùn. Má ṣe máa fi ipò rẹ wé ti àwọn ẹlòmíràn. Bó bá dà bíi pé Jèhófà ṣe nǹkan kan fáwọn mìíràn láfikún, ńṣe ni kó o bá wọn yọ̀ kó o sì jẹ́ kínú rẹ dùn sí wọn.
Àmọ́ o, ohun kan wà tí Jèhófà retí pé kó o máa ṣe. Kí lohun náà? Gálátíà 6:4 sọ pé: “Kí olúkúlùkù máa wádìí ohun tí iṣẹ́ tirẹ̀ jẹ́, nígbà náà ni yóò ní ìdí fún ayọ̀ ńláǹlà ní ti ara rẹ̀ nìkan.” Lédè mìíràn, ohun tó o mọ̀ pé ọwọ́ rẹ lè tẹ̀ ni kó o máa lé. Wéwèé àwọn ohun tó o mọ̀ pé o lè ṣe, kó o sì rí i pé o múra sí nǹkan náà kọwọ́ rẹ lè tẹ̀ ẹ́. Bó bá jẹ́ pé ohun tó bójú mu ni ohun tí ò ń lé tí ọwọ́ rẹ sì tẹ ohun náà, wàá “ní ìdí fún ayọ̀ ńláǹlà.” Wàá sì ní ìbàlẹ̀ ọkàn.
Èrè Ń Bọ̀ O
Àwọn ìlànà mẹ́ta tá a ti gbé yẹ̀ wò yìí fi hàn pé tá a bá ń fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò, ó dájú pé a óò ní ìbàlẹ̀ ọkàn bó tilẹ̀ jẹ́ pé àkókò òpin la wà tá a sì jẹ́ aláìpé. Lákòókò tó o máa ń ka Bíbélì lójoojúmọ́, o ò ṣe máa wá irú àwọn ìlànà bẹ́ẹ̀, yálà àwọn tí Bíbélì dìídì sọ tàbí àwọn tó o lè rí nínú àwọn ìtàn tàbí àwọn àkàwé tí Bíbélì sọ?
Bó bá dà bíi pé oò fi bẹ́ẹ̀ ní ìbàlẹ̀ ọkàn mọ́, gbìyànjú láti mọ ohun tó fà á gan-an. Lẹ́yìn náà, wá àwọn ìlànà tó o lè lò láti ṣàtúnṣe ipò náà. Bí àpẹẹrẹ, o lè wo ojú ìwé 110 sí 111 nínú ìwé “All Scripture Is Inspired of God and Beneficial.”a Láwọn ojú ìwé náà, wàá rí ìjíròrò lórí ìwé Òwe, wàá sì rí onírúurú ìlànà àti ìmọ̀ràn lábẹ́ ìsọ̀rí méjìlá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Ìwé atọ́ka The Watch Tower Publications Index,b àti Watchtower Library (CD-ROM) [Àkójọ Ìwé Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Tá A Ṣe Sínú Àwo Pẹlẹbẹ Tá À Ń Fi Kọ̀ǹpútà Lò]c yóò tún ràn ọ́ lọ́wọ́ láti rí onírúurú ìsọfúnni tó dára gan-an. Bó o bá ń lo àwọn irinṣẹ́ wọ̀nyí déédéé, wàá dọ̀gá nínú mímọ bó o ṣe lè rí àwọn ìlànà tó o lè máa lò.
Àkókò ń bọ̀ tí Jèhófà yóò fún gbogbo ẹni tí ẹ̀bùn ìyè àìnípẹ̀kun bá tọ́ sí ní ẹ̀bùn yìí wọ́n á sì di ẹni pípé nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé. Wọ́n á ní ìbàlẹ̀ ọkàn gan-an nígbèésí ayé wọn.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ wọ́n jáde.
b Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ wọ́n jáde.
c Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ wọ́n jáde.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 12]
“Gbogbo ènìyàn ti ṣẹ̀, wọ́n sì ti kùnà láti kúnjú ìwọ̀n ògo Ọlọ́run.”—Róòmù 3:23
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 13]
Jésù “kọ́ ìgbọràn láti inú ohun tí ó jìyà rẹ̀.”—Hébérù 5:8, 9
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 15]
“Yóò ní ìdí fún ayọ̀ ńláǹlà ní ti ara rẹ̀ nìkan, kì í sì í ṣe ní ìfiwéra pẹ̀lú ẹlòmíràn.”—Gálátíà 6:4