Ọ̀rọ̀ Jèhófà Yè
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Aísáyà—Apá Kìíní
“TA NI èmi yóò rán, ta sì ni yóò lọ fún wa?” Aísáyà ọmọ Émọ́sì dáhùn ìpè tó wá látọ̀dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run yìí, ó ní: “Èmi nìyí! Rán mi.” (Aísáyà 1:1; 6:8) Bó ṣe gba iṣẹ́ wòlíì nìyẹn. Gbogbo àsọtẹ́lẹ̀ tí wòlíì Aísáyà sọ wà nínú ìwé tí wọ́n fi orúkọ rẹ̀ pè nínú Bíbélì.
Wòlíì Aísáyà ló kọ ìwé yìí fúnra rẹ̀, ó sì gbà á ní ọdún mẹ́rìndínláàádọ́ta gbáko, ìyẹn láti nǹkan bí ọdún 778 ṣáájú Sànmánì Kristẹni sí ẹ̀yìn ọdún 732 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìdájọ́ tí Ọlọ́run fẹ́ mú wá sórí orílẹ̀-èdè Júdà, Ísírẹ́lì, àtàwọn orílẹ̀-èdè mìíràn wà nínú ìwé náà, kì í ṣe ìdájọ́ ni ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ dá lé lórí. Kàkà bẹ́ẹ̀, ‘ìgbàlà láti ọ̀dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run’ ló dá lé lórí. (Aísáyà 25:9) Kódà, ohun tí orúkọ Aísáyà túmọ̀ sí ni, “Ìgbàlà Jèhófà.” Àpilẹ̀kọ yìí yóò jẹ́ ká rí àwọn kókó pàtàkì inú ìwé Aísáyà orí kìíní ẹsẹ kìíní sí orí karùndínlógójì ẹsẹ kẹwàá.
“ÀṢẸ́KÙ LÁSÁN NI YÓÒ PADÀ”
Yálà kí Ọlọ́run tó yan Aísáyà gẹ́gẹ́ bíi wòlíì tàbí lẹ́yìn tí Ọlọ́run yàn án tán ló kéde àwọn ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ tó wà ní orí kìíní sí orí karùn-ún ìwé yìí, Bíbélì kò sọ. (Aísáyà 6:6-9) Àmọ́ ohun tó ṣe kedere ni pé, Júdà àti Jerúsálẹ́mù ń ṣàìsàn tẹ̀mí “láti àtẹ́lẹsẹ̀ àní dé orí.” (Aísáyà 1:6) Ìbọ̀rìṣà pọ̀ rẹpẹtẹ. Àwọn aṣáájú ń hùwà ìbàjẹ́. Àwọn obìnrin sì ti di agbéraga. Àwọn èèyàn kò sin Ọlọ́run lọ́nà tí Ọlọ́run fọwọ́ sí. Ọlọ́run wá rán Aísáyà sí àwọn èèyàn tí kò lóye tí wọn ò sí nífẹ̀ẹ́ sí ìmọ̀ kankan, ó sì ní kó lọ bá wọn sọ̀rọ̀ léraléra.
Àpapọ̀ àwọn ọmọ ogun ilẹ̀ Ísírẹ́lì àti ti Síríà ń gbìmọ̀ pọ̀ láti gbógun ja ilẹ̀ Júdà. Ṣùgbọ́n Jèhófà lo Aísáyà àtàwọn ọmọ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí “àmì àti bí iṣẹ́ ìyanu” láti fi dá ilẹ̀ Júdà lójú pé àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun Síríà àti Ísírẹ́lì tí wọ́n para pọ̀ náà kò ní ṣàṣeyọrí. (Aísáyà 8:18) Àmọ́ o, nípasẹ̀ ìṣàkóso “Ọmọ Aládé Àlàáfíà” nìkan ni àlááfíà tí kò lópin fi máa wà. (Aísáyà 9:6, 7) Jèhófà yóò tún dá Asíríà lẹ́jọ́, ìyẹn orílẹ̀-èdè tó lò gẹ́gẹ́ bí “ọ̀pá tí ó wà fún ìbínú [rẹ̀].” Bópẹ́bóyá, Júdà yóò lọ sí ìgbèkùn, àmọ́ “àṣẹ́kù lásán ni yóò padà.” (Aísáyà 10:5, 21, 22) Ìdájọ́ òdodo yóò wà lábẹ́ ìṣàkóso “ẹ̀ka igi kan” tó jẹ́ ìṣàpẹẹrẹ tí yóò “yọ láti ara kùkùté Jésè.”—Aísáyà 11:1.
Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Tó Jẹ Yọ:
1:8, 9—Ọ̀nà wo la ó gbà fi ọmọbìnrin Síónì “sílẹ̀ bí àtíbàbà inú ọgbà àjàrà, bí ahéré alóre inú àwọn pápá apálá”? Ohun tí èyí túmọ̀ sí ni pé, nígbà tí Asíríà bá gbógun wá, ńṣe ló máa dà bíi pé Jerúsálẹ́mù kò lè bọ́ lọ́wọ́ wọn rárá, á dà bí àtíbàbà inú ọgbà àjàrà kan tàbí bí ahéré kan tó lè tètè wó lulẹ̀, tó wà nínú oko apálá. Àmọ́ Jèhófà ran Jerúsálẹ́mù lọ́wọ́, kò jẹ́ kó dà bíi Sódómù àti Gòmórà.
1:18—Kí ni ìtumọ̀ gbólóhùn náà: “Ẹ wá, nísinsìnyí, ẹ sì jẹ́ kí a mú àwọn ọ̀ràn tọ́ láàárín wa”? Èyí kì í ṣe pé Ọlọ́run ń pe orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì pé káwọn jọ sọ̀rọ̀ káwọn sì jọ fẹnu kò síbì kan nípa jíjùmọ̀ yanjú ọ̀ràn kan ní ìtùnbí-ìnùbí. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí ń tọ́ka sí ni pípè tí Jèhófà onídàájọ́ òdodo ń pe orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì láti fún wọn láǹfààní láti yí padà, kí wọ́n sì wẹ ara wọn mọ́.
6:8a—Kí nìdí tá a fi lo àwọn ọ̀rọ̀ arọ́pò orúkọ náà, “èmi” àti “wa” nínú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí? Ọ̀rọ̀ náà “èmi,” dúró fún Jèhófà. Ọ̀rọ̀ ẹlẹ́ni púpọ̀ náà “wa,” sì fi hàn pé ẹnì kan wà pẹ̀lú Jèhófà. Dájúdájú, ‘ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo’ ni ẹni yìí.—Jòhánù 1:14; 3:16.
6:11—Kí ni Aísáyà ní lọ́kàn nígbà tó béèrè pé: “Yóò ti pẹ́ tó, Jèhófà?” Kì í ṣe pé Aísáyà ń béèrè bí àkókò tóun fi máa kéde ọ̀rọ̀ Jèhófà fáwọn èèyàn tó jẹ́ aláìgbọràn náà ṣe máa gùn tó. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó fẹ́ mọ̀ ni bí àìsàn tẹ̀mí tó ń ṣe àwọn èèyàn náà tó sì ń mú ẹ̀gàn bá orúkọ Ọlọ́run yóò ṣe pẹ́ tó.
7:3, 4—Kí nìdí tí Jèhófà fi dáàbò bo Áhásì Ọba tó jẹ́ ẹni burúkú? Àwọn Ọba ilẹ̀ Síríà àti ilẹ̀ Ísírẹ́lì ti gbìmọ̀ pọ̀ láti mú Áhásì Ọba kúrò lórí oyè kí wọ́n sì fi ẹni tí wọ́n á lè máa darí bó ṣe wù wọ́n rọ́pò rẹ̀, ìyẹn ọmọkùnrin Tábéélì, tí kì í ṣe àtọmọdọ́mọ Dáfídì. Ètekéte Èṣù yìí yóò ṣèdíwọ́ fún májẹ̀mú Ìjọba tí Ọlọ́run bá Dáfídì dá. Kí ohunkóhun má bàa ṣẹlẹ̀ sí ìran tí “Ọmọ Aládé Àlàáfíà” yóò ti wá ni Jèhófà ṣe dáàbò bo Áhásì.—Aísáyà 9:6.
7:8—Báwo làwọn ọ̀tá ṣe “fọ́ [Éfúráímù] túútúú” láàárín ọdún márùnlélọ́gọ́ta? Kíkó tí wọ́n ń kó àwọn èèyàn ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá ilẹ̀ Ísírẹ́lì kúrò ní ilẹ̀ wọn, tí wọ́n sì ń kó àwọn àjèjì wá síbẹ̀ bẹ̀rẹ̀ “ní àwọn ọjọ́ Pékà ọba Ísírẹ́lì,” ìyẹn kété lẹ́yìn tí Aísáyà sọ àsọtẹ́lẹ̀ yìí. (2 Àwọn Ọba 15:29) Èyí ń bá a lọ fún àkókò gígùn, títí lọ di àkókò Esari-hádónì, ọba ilẹ̀ Asíríà, tó jẹ́ ọmọ Senakéríbù tó sì tún di ọba lẹ́yìn bàbá rẹ̀. (2 Àwọn Ọba 17:6; Ẹ́sírà 4:1, 2; Aísáyà 37:37, 38) Kíkó táwọn ará Asíríà ń kó àwọn èèyàn lọ sí Samáríà tí wọ́n sì ń kó àwọn èèyàn kúrò níbẹ̀ yìí mú kí ọdún márùn-dín-láàádọ́rin inú ìwé Aísáyà 7:8 nímùúṣẹ.
11:1, 10—Báwo ni Jésù Kristi ṣe lè jẹ́ ‘ẹ̀ka igi kan tó yọ láti ara kùkùté Jésè’ síbẹ̀ kó tún jẹ́ “gbòǹgbò Jésè”? (Róòmù 15:12) “Láti ara kùkùté Jésè” ni Jésù ti wá. Ó jẹ́ àtọmọdọ́mọ Jésè nípasẹ̀ Dáfídì tó jẹ́ ọmọ Jésè. (Mátíù 1:1-6; Lúùkù 3:23-32) Àmọ́ o, lẹ́yìn tí Jésù di ọba, ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àtọmọdọ́mọ yí padà. Nítorí pé Ọlọ́run ti fún Jésù ní agbára àti àṣẹ láti fún àwọn tó bá ṣègbọràn ní ìyè ayérayé lórí ilẹ̀ ayé, ó wá tipa bẹ́ẹ̀ di “Baba Ayérayé” fún wọn. (Aísáyà 9:6) Nítorí náà, òun tún ni “gbòǹgbò” àwọn baba ńlá rẹ̀, títí kan Jésè.
Ẹ̀kọ́ Tá A Rí Kọ́:
1:3. Tá a bá kọ̀ láti ṣe ohun tí Ẹlẹ́dàá wa sọ pé ká ṣe, a jẹ́ pé ọgbọ́n wa kò tó ti akọ màlúù tàbí ti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ nìyẹn. Àmọ́ o, tá a bá jẹ́ ẹni tó mọrírì gbogbo ohun tí Jèhófà ti ṣe fún wa, èyí kò ní jẹ́ ká máa hùwà bí aláìloye, a ò sì ní fi Ọlọ́run sílẹ̀.
1:11-13. Àwọn àjọ̀dún ìsìn tó ní àgàbàgebè nínú àtàwọn àdúrà tí kò tinú ọkàn wá máa ń sú Jèhófà. Gbogbo ohun tá à ń ṣe àtàwọn àdúrà tá à ń gbà, gbọ́dọ̀ wá látinú ọkàn tó dára.
1:25-27; 2:2; 4:2, 3. Kíkó tí wọ́n kó àwọn èèyàn Júdà lẹ́rú tí wọ́n sì tún pa ilẹ̀ náà run dópin nígbà tí àṣẹ́kù tó ronú pìwà dà padà sí Jerúsálẹ́mù tí wọ́n sì mú kí ìjọsìn tòótọ́ padà bọ̀ sípò rẹ̀. Jèhófà máa ń fi àánú hàn sáwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tó bá ronú pìwà dà.
2:2-4. Bá a ṣe ń fìtara kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run àti iṣẹ́ sísọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn máa ń jẹ́ káwọn èèyàn látinú ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè kẹ́kọ̀ọ́ ọ̀nà tí àlàáfíà fi máa wà, ó sì ń jẹ́ kí wọ́n lè máa wá àlàáfíà láàárín ara wọn.
4:4. Jèhófà yóò fọ gbogbo ìwà ìbàjẹ́ àti ìtàjẹ̀sílẹ̀ mọ́ kúrò, ìyẹn ni pé yóò mú wọn kúrò.
5:11-13. Téèyàn ò bá ní ìkóra-ẹni-níjàánu nínú eré ìnàjú tàbí téèyàn ò bá ṣe é níwọ̀ntúnwọ̀nsì, a jẹ́ pé èèyàn ń hùwà bí òmùgọ̀ nìyẹn.—Róòmù 13:13.
5:21-23. Àwọn Kristẹni tó jẹ́ alàgbà tàbí àwọn alábòójútó gbọ́dọ̀ yẹra fún jíjẹ́ ọlọ́gbọ́n “ní ojú ara wọn.” Wọn ò tún gbọ́dọ̀ jẹ́ aláṣejù nínú “mímu wáìnì,” bẹ́ẹ̀ ni wọn ò sì gbọ́dọ̀ máa ṣe ojúsàájú.
11:3a. Àpẹẹrẹ Jésù àtàwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀ fi hàn pé ìbẹ̀rù Jèhófà ń fúnni láyọ̀.
“JÈHÓFÀ YÓÒ FI ÀÁNÚ HÀN SÍ JÉKỌ́BÙ”
Àwọn ìdájọ́ tó máa wá sórí àwọn orílẹ̀-èdè ló wà nínú orí kẹtàlá sí orí kẹtàlélógún. Àmọ́ “Jèhófà yóò fi àánú hàn sí Jékọ́bù,” ìyẹn ni pé yóò mú kó ṣeé ṣe fún gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì láti padà sílé. (Aísáyà 14:1) Àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìsọdahoro Júdà tó wà nínú orí kẹrìnlélógún sí orí kẹtàdínlọ́gbọ̀n tún ní ìlérí kan nínú pé a óò mú Júdà padà bọ̀ sípò. Jèhófà bínú sí “àwọn ọ̀mùtípara Éfúráímù [Ísírẹ́lì]” nítorí pé wọ́n lọ lẹ̀dí àpò pọ̀ pẹ̀lú ilẹ̀ Síríà, ó sì bínú sí “àlùfáà àti wòlíì” Júdà nítorí pé wọ́n wá ọ̀nà láti lẹ̀dí àpò pọ̀ pẹ̀lú ilẹ̀ Ásíríà. (Aísáyà 28:1, 7) Ọlọ́run kéde ègbé sórí “Áríélì [Jerúsálẹ́mù]” nítorí pé wọ́n “mú ọ̀nà wọn pọ̀n láti sọ̀ kalẹ̀ lọ sí Íjíbítì” láti wá ààbò. (Aísáyà 29:1; Aísáyà 30:1, 2) Síbẹ̀, Aísáyà sàsọtẹ́lẹ̀ pé àwọn tó bá fẹ̀rí hàn pé àwọn nígbàgbọ́ nínú Jèhófà yóò rí ìgbàlà.
Gẹ́gẹ́ bí ‘ẹgbọrọ kìnnìún onígọ̀gọ̀ ti ń kùn hùn-ùn lórí ẹran ọdẹ rẹ̀,’ ni Jèhófà yóò ṣe pa “Òkè Ńlá Síónì” mọ́. (Aísáyà 31:4) Ìlérí kan tún wà o, ìlérí náà ni pé: “Wò ó! Ọba kan yóò jẹ fún òdodo.” (Aísáyà 32:1) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé híhalẹ̀ tí Asíríà ń halẹ̀ mọ́ ilẹ̀ Júdà mú kí “àwọn ońṣẹ́ àlàáfíà” pàápàá sunkún kíkorò, Jèhófà ṣèlérí pé òun yóò mú àwọn èèyàn òun lára dá, ìyẹn ni pé òun yóò “dárí ìṣìnà wọn jì wọ́n.” (Aísáyà 33:7, 22-24) “Jèhófà ní ìkannú sí gbogbo orílẹ̀-èdè, àti ìhónú sí gbogbo ẹgbẹ́ ọmọ ogun wọn.” (Aísáyà 34:2) Júdà kò ní wà ní ahoro títí lọ. “Aginjù àti ẹkùn ilẹ̀ aláìlómi yóò yọ ayọ̀ ńláǹlà, pẹ̀tẹ́lẹ̀ aṣálẹ̀ yóò sì kún fún ìdùnnú, yóò sì yọ ìtànná gẹ́gẹ́ bí sáfúrónì.”—Aísáyà 35:1.
Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Tó Jẹ Yọ:
13:17—Ọ̀nà wo làwọn ará Mídíà kò fi ka fàdákà sí ohunkóhun tí wọ́n kò sì ní inú dídùn sí wúrà? Ògo táwọn ará Mídíà àtàwọn ará Páṣíà máa ń rí nígbà tí wọ́n bá ṣẹ́gun ṣe pàtàkì lójú wọn ju ẹrù tí wọ́n ń rí kó lójú ogun lọ. Ohun tí Kírúsì ṣe nígbà táwọn ìgbèkùn Júdà ń padà sí ilẹ̀ wọn fi hàn pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí. Ó dá àwọn ohun èlò wúrà àti ti fàdákà tí Nebukadinésárì kó nínú tẹ́ńpìlì Jèhófà padà fún wọn.
14:1, 2—Ọ̀nà wo làwọn èèyàn Jèhófà gbà di “amúnilóǹdè àwọn tí ó mú wọn ní òǹdè” tí wọ́n sì “jọba lórí àwọn tí ń kó wọn ṣiṣẹ́ tẹ́lẹ̀ rí”? Èyí ṣẹlẹ̀ sáwọn èèyàn bíi Dáníẹ́lì tó di ipò ńlá mú nílẹ̀ Bábílónì nígbà ìṣàkóso àwọn Mídíà àti Páṣíà. Bákan náà ni Ẹ́sítérì tó di ayaba nílẹ̀ Páṣíà; àti Módékáì, tí wọ́n yàn gẹ́gẹ́ bí igbá kejì Ọba gbogbo àgbègbè tí Ilẹ̀ Páṣíà ń ṣàkóso lé lórí.
20:2-5—Ṣé òótọ́ ni pé Aísáyà rìn kiri níhòòhò fún ọdún mẹ́ta? Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ẹ̀wù àwọ̀lékè nìkan ni Aísáyà bọ́ sílẹ̀ tó sì ń rìn kiri pẹ̀lú aṣọ jáńpé.
21:1—Àgbègbè wo ni Bíbélì pè ní “aginjù òkun”? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ilẹ̀ Bábílónì kò sí lẹ́gbẹ̀ẹ́ òkun rárá, Bíbélì pè é ní “aginjù òkun.” Ìdí ni pé ọdọọdún ni omi odò Yúfírétì àti Tígírísì máa ń kún bo àgbègbè náà, èyí sì máa ń fa àbàtà tó lọ salalu bí òkun.
24:13-16—Ọ̀nà wo làwọn Júù á gbà dà bíi ‘lílu igi ólífì, bí èéṣẹ́ nígbà tí kíkó èso àjàrà jọ bá ti wá sí òpin, láàárín àwọn ènìyàn’? Bí èso díẹ̀ ṣe máa ń ṣẹ́ kù sórí igi tàbí sórí àjàrà lẹ́yìn ìkórè, ìwọ̀nba díẹ̀ péré làwọn tí yóò la ìparun Jerúsálẹ́mù àti Júdà já. Ibikíbi tí wọn ì báà kó àwọn tó là á já lọ, ì báà jẹ́ sí “ẹkùn ilẹ̀ ìmọ́lẹ̀ [ìyẹn Bábílónì ní Ìlà Oòrùn]” tàbí sí “àwọn erékùṣù òkun [ìyẹn Mẹditaréníà],” wọn yóò máa yin Jèhófà.
24:21—Àwọn wo ni “ẹgbẹ́ ọmọ ogun ibi gíga” àti “àwọn ọba ilẹ̀”? “Ẹgbẹ́ ọmọ ogun ibi gíga” ni àwọn agbo ọmọ ogun ẹ̀mí burúkú. “Àwọn ọba ilẹ̀” sì ni àwọn alákòóso ilẹ̀ ayé tí àwọn ẹ̀mí èṣù ń darí wọn lójú méjèèjì.—1 Jòhánù 5:19.
25:7—Kí ni “ìràgàbò . . . tí ó ràgà bo gbogbo ènìyàn, àti ohun híhun tí a hun pọ̀ sórí gbogbo orílẹ̀-èdè”? Àfiwé yìí mú ọkàn wa lọ sórí àwọn ọ̀tá ńlá méjì tí ọmọ aráyé ní, ìyẹn ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú.
Ẹ̀kọ́ Tá A Rí Kọ́:
13:20-22;14:22, 23; 21:1-9. Gbogbo àsọtẹ́lẹ̀ Jèhófà ló máa ń nímùúṣẹ gẹ́gẹ́ bí àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ nípa orílẹ̀-èdè Bábílónì ti nímùúṣẹ.
17:7, 8. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn èèyàn ilẹ̀ Ísírẹ́lì ni kò fetí sílẹ̀, síbẹ̀ àwọn kan yíjú sí Jèhófà. Bákan náà lónìí, àwọn kan láàárín àwọn Kristẹni aláfẹnujẹ́ ń tẹ́tí sí ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, wọ́n sì wá ń sin Jèhófà.
28:1-6. Orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì yóò ṣubú sọ́wọ́ àwọn ará Asíríà, àmọ́ Ọlọ́run yóò rí sí i pé àwọn tó jẹ́ olóòótọ́ là á já. Ìrètí wà fáwọn olódodo nígbà tí ìdájọ́ Jèhófà bá dé.
28:23-29. Jèhófà máa ń tọ́ àwọn tó fẹ́ mọ òtítọ́ sọ́nà, gẹ́gẹ́ bí ipò kálukú wọn bá ṣe rí.
30:15. Ká tó lè rí ìgbàlà Jèhófà, a gbọ́dọ̀ fi ìgbàgbọ́ hàn nípa “sísinmi,” ìyẹn ni pé ká jáwọ́ nínú wíwá ìgbàlà nípasẹ̀ àwọn ètò tí ẹ̀dá èèyàn gbé kalẹ̀. Bákan náà, nípa ‘ṣíṣàì ní ìyọlẹ́nu’ èyí tó túmọ̀ sí ṣíṣàì bẹ̀rù, à ń fi hàn pé a gbọ́kàn lé Jèhófà pé ó lè dáàbò bò wá.
30:20, 21. À ń “rí” Jèhófà a sì ń “gbọ́” ohùn rẹ̀ tí ń fúnni ní ìgbàlà, nípa ṣíṣe àwọn ohun tó ń sọ fún wa nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó mí sí, ìyẹn Bíbélì àti nípasẹ̀ “ẹrú olóòótọ́ àti olóye.”—Mátíù 24:45.
Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà Jẹ́ Ká Túbọ̀ Nígbẹ̀ẹ́kẹ̀lé Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
Ọpẹ́ wa pọ̀ gan-an fún ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run sọ nínú ìwé Aísáyà! Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó ti nímùúṣẹ túbọ̀ fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé ‘ọ̀rọ̀ tí ó ti ẹnu Jèhófà jáde kì yóò padà sọ́dọ̀ rẹ̀ láìní ìyọrísí.’—Aísáyà 55:11.
Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa Mèsáyà ńkọ́, irú bí àwọn tó wà nínú Aísáyà 9:7 àti Aísáyà 11:1-5, 10? Ǹjẹ́ wọn ò mú kí ìgbàgbọ́ wa túbọ̀ lágbára sí i nínú ètò tí Jèhófà ṣe ká lè rí ìgbàlà? Ìwé Aísáyà tún ní àwọn àsọtẹ́lẹ̀ mìíràn nínú, tí èyí tó pọ̀ jù lára wọn ń nímùúṣẹ lọ́wọ́lọ́wọ́ tàbí tí wọn yóò nímùúṣẹ lọ́jọ́ iwájú. (Aísáyà 2:2-4; 11:6-9; 25:6-8; 32:1, 2) Ká sòótọ́, ìwé Aísáyà túbọ̀ fi kún ẹ̀rí náà pé, “ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yè”!—Hébérù 4:12.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]
Aísáyà àtàwọn ọmọ rẹ̀ “dà bí àmì àti bí iṣẹ́ ìyanu ní Ísírẹ́lì”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8, 9]
Jerúsálẹ́mù yóò dà bí “àtíbàbà inú ọgbà àjàrà”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Báwo la ṣe ń ran àwọn èèyàn látinú onírúurú orílẹ̀-èdè lọ́wọ́ kí wọ́n lè fi “idà wọn rọ abẹ ohun ìtúlẹ̀”?