Àìsáyà
28 Adé* ìgbéraga* àwọn ọ̀mùtípara Éfúrémù+ gbé
Àti ìtànná ẹwà ológo rẹ̀ tó ti ń rọ,
Tó wà ní orí àfonífojì ọlọ́ràá tó jẹ́ ti àwọn tí wáìnì ti kápá wọn!
2 Wò ó! Jèhófà ní ẹnì kan tó lókun tó sì lágbára.
Bí ìjì yìnyín tó ń sán ààrá, ìjì apanirun,
Bí ìjì tó ń sán ààrá tó ń fa àkúnya omi tó bùáyà,
Ó máa fipá jù ú sílẹ̀.
4 Òdòdó ẹwà ológo rẹ̀ tó ti ń rọ,
Èyí tó wà ní orí àfonífojì ọlọ́ràá,
Máa dà bí àkọ́pọ́n èso ọ̀pọ̀tọ́ ṣáájú ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn.
Tí ẹnì kan bá rí i, ṣe ló máa gbé e mì ní gbàrà tó bá ti wà lọ́wọ́ rẹ̀.
5 Ní ọjọ́ yẹn, Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun máa di adé ológo àti òdòdó ẹ̀yẹ fún àwọn èèyàn rẹ̀ tó ṣẹ́ kù.+ 6 Ó máa di ẹ̀mí ìdájọ́ òdodo fún ẹni tó jókòó láti ṣe ìdájọ́, ó sì máa jẹ́ orísun agbára fún àwọn tó ń lé ogun sẹ́yìn ní ẹnubodè.+
7 Àwọn yìí náà ṣìnà torí wáìnì;
Ohun mímu wọn tó ní ọtí ń mú kí wọ́n ta gọ̀ọ́gọ̀ọ́,
Àlùfáà àti wòlíì ti ṣìnà torí ọtí;
Wáìnì ò jẹ́ kí wọ́n mọ nǹkan tí wọ́n ń ṣe,
Ọtí wọn sì ń jẹ́ kí wọ́n ta gọ̀ọ́gọ̀ọ́;
Ìran wọn ń mú kí wọ́n ṣìnà,
Wọ́n sì ń kọsẹ̀ nínú ìdájọ́.+
8 Torí pé èébì ẹlẹ́gbin kún àwọn tábìlì wọn,
Kò sí ibi tí kò sí.
9 Ta ni èèyàn máa fún ní ìmọ̀,
Ta sì ni èèyàn máa ṣàlàyé ọ̀rọ̀ fún?
Ṣé àwọn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ gba wàrà lẹ́nu wọn ni,
Àwọn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ já lẹ́nu ọmú?
10 Torí ó jẹ́ “àṣẹ kan tẹ̀ lé òmíràn, àṣẹ kan tẹ̀ lé òmíràn,
Okùn tẹ̀ lé okùn, okùn tẹ̀ lé okùn,*+
Díẹ̀ níbí, díẹ̀ lọ́hùn-ún.”
11 Torí náà, ó máa bá àwọn èèyàn yìí sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ àwọn tó ń kólòlò* tí wọ́n sì ń sọ èdè àjèjì.+ 12 Ó ti sọ fún wọn rí pé: “Ibi ìsinmi nìyí. Ẹ jẹ́ kí ẹni tó ti rẹ̀ sinmi; ibi ìtura nìyí,” àmọ́ wọn ò fetí sílẹ̀.+ 13 Torí náà, ohun tí ọ̀rọ̀ Jèhófà máa jẹ́ fún wọn ni pé:
“Àṣẹ kan tẹ̀ lé òmíràn, àṣẹ kan tẹ̀ lé òmíràn,
Okùn tẹ̀ lé okùn, okùn tẹ̀ lé okùn,*+
Díẹ̀ níbí, díẹ̀ lọ́hùn-ún,”
Kí wọ́n lè kọsẹ̀, kí wọ́n sì ṣubú sẹ́yìn
Tí wọ́n bá ń rìn,
Kí wọ́n lè ṣèṣe, kí wọ́n lè dẹkùn mú wọn, kí ọwọ́ sì tẹ̀ wọ́n.+
14 Torí náà, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà, ẹ̀yin afọ́nnu,
Ẹ̀yin alákòóso àwọn èèyàn yìí ní Jerúsálẹ́mù,
15 Nítorí ẹ sọ pé:
Tí omi tó ń ru gùdù bá ya kọjá lójijì,
Kò ní dé ọ̀dọ̀ wa,
Torí a ti fi irọ́ ṣe ibi ààbò wa,
A sì ti fi ara wa pa mọ́ sínú èké.”+
16 Torí náà, ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí:
“Wò ó, màá fi òkúta+ tí a ti dán wò ṣe ìpìlẹ̀ ní Síónì,
Ẹnikẹ́ni tó bá ní ìgbàgbọ́ kò ní bẹ̀rù.+
Yìnyín máa gbá ibi ààbò irọ́ lọ,
Omi sì máa kún bo ibi ìfarapamọ́.
Tí omi tó ń ru gùdù bá ya kọjá lójijì,
Ó máa pa yín rẹ́.
Ní ọ̀sán àti ní òru.
Ìbẹ̀rù nìkan ló máa jẹ́ kí ohun tí wọ́n gbọ́ yé wọn.”*
20 Torí pé ibùsùn ti kéré jù láti na ara,
Aṣọ tí wọ́n hun sì ti tẹ́ẹ́rẹ́ jù láti fi bora.
21 Torí Jèhófà máa dìde bó ṣe ṣe ní Òkè Pérásímù;
Ó máa gbéra sọ bó ṣe ṣe ní àfonífojì* tó wà nítòsí Gíbíónì,+
Kó lè ṣe ìṣe rẹ̀, ìṣe rẹ̀ tó ṣàjèjì,
Kó sì lè ṣe iṣẹ́ rẹ̀, iṣẹ́ rẹ̀ tó ṣàrà ọ̀tọ̀.+
22 Ní báyìí, ẹ má fini ṣe yẹ̀yẹ́,+
Ká má bàa tún mú kí àwọn ìdè yín le sí i,
Torí mo ti gbọ́ látọ̀dọ̀ Olúwa Ọba Aláṣẹ, Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun
23 Ẹ gbọ́, kí ẹ sì fetí sí ohùn mi;
Ẹ fiyè sílẹ̀, kí ẹ sì fetí sí ọ̀rọ̀ mi.
24 Ṣé ẹni tó ń túlẹ̀ máa ń fi gbogbo ọjọ́ túlẹ̀ kó tó fúnrúgbìn ni?
Ṣé á máa túlẹ̀, tí á sì máa fọ́ ilẹ̀ rẹ̀ sí wẹ́wẹ́ láìdáwọ́ dúró ni?+
25 Tó bá ti mú kí ilẹ̀ náà tẹ́jú,
Ṣebí ó máa fọ́n kúmínì dúdú, kó sì gbin kúmínì,
Ṣebí ó sì máa gbin àlìkámà,* jéró àti ọkà bálì sí àyè wọn
Àti ọkà sípẹ́ẹ̀tì+ sí eteetí ilẹ̀?
Kàkà bẹ́ẹ̀, ọ̀pá la fi ń lu kúmínì dúdú,
Igi la sì fi ń lu kúmínì.
28 Ṣé èèyàn máa ń fọ́ ọkà kó lè fi ṣe búrẹ́dì ni?