Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn
Ó Ń Ṣọ́nà, Ó sì Ní Sùúrù
ÓWU wòlíì Èlíjà pé kó dá wà níbì kan tó ti lè gbàdúrà sí Bàbá rẹ̀ ọ̀run. Àmọ́, ó dájú pé ojú rere wòlíì Èlíjà ni èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn èrò tó yí i ká wọ̀nyẹn ń wá, nítorí pé wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ rí i tí wòlíì tòótọ́ yìí pé iná sọ̀kalẹ̀ látọ̀run ni. Èlíjà fẹ́ lọ sórí Òkè Ńlá Kámẹ́lì tí ẹ̀fúùfù ti gbá gbogbo nǹkan tó wà níbẹ̀ lọ, láti lọ gbàdúrà sí Jèhófà Ọlọ́run ní ìdákọ́ńkọ́. Àmọ́ kó tó lọ, ó ní iṣẹ́ kan láti ṣe, iṣẹ́ náà kò sì rọrùn rárá. Ó ní láti lọ bá Áhábù Ọba sọ̀rọ̀.
Ìyàtọ̀ gbọ̀ọ̀rọ̀gbọọrọ ló wà láàárín Áhábù àti Èlíjà. Oníwọra àti apẹ̀yìndà tí kò lè dápinnu ṣe ni Áhábù tó gúnwà lórí ìtẹ́ rẹ̀. Àmọ́ aṣọ wòlíì tí kì í ṣe olówó ńlá ni Èlíjà wọ. Ó tiẹ̀ ṣeé ṣe kó jẹ́ pé awọ ẹranko ni wọ́n fi ṣe é tàbí kó jẹ́ irun ràkúnmí tàbí ti ewúrẹ́. Onígboyà èèyàn ni, ó jẹ́ adúróṣinṣin, ó sì nígbàgbọ́. Àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ látàárọ̀ títí dìrọ̀lẹ́ ọjọ́ yẹn ti jẹ́ ká rí ọ̀pọ̀ nǹkan nípa irú èèyàn táwọn méjèèjì jẹ́.a
Ọjọ́ burúkú lọ́jọ́ tá à ń wí yìí jẹ́ fún Áhábù àtàwọn olùjọsìn Báálì yòókù. Àṣírí ìjọsìn èké tí Áhábù àti Ayaba Jésíbẹ́lì ìyàwó rẹ̀ ń gbé lárugẹ níjọba ẹ̀yà Ísírẹ́lì mẹ́wàá ti tú. Gbogbo ayé ti rí i pé ọlọ́run èké ni Báálì tí wọ́n ń jọ́sìn. Òrìṣà tí kò lẹ́mìí yìí ò lè pe iná lásán wá sórí pẹpẹ, pẹ̀lú bí àwọn tó ń sìn ín ṣe ké pè é tó àti gbogbo ìyà tí wọ́n fi jẹ ara wọn níbi tí wọ́n ti ń jó, tí wọ́n sì ń fọ̀bẹ ya ara wọn, tí ẹ̀jẹ̀ sì ń dà ṣùrùṣùrù. Nígbà tí Èlíjà ní kí wọ́n pa àwọn àádọ́ta-lé-nírínwó [450] ọkùnrin gẹ́gẹ́ bí èrè ẹ̀ṣẹ̀ wọn, Báálì ò lè dáàbò bò wọ́n. Àmọ́ òrìṣà yìí tún kùnà láti ṣe nǹkan míì, ìyẹn ló sì wá tẹ́ ẹ pátápátá. Ó ju ọdún mẹ́ta lọ táwọn wòlíì Báálì fi ń ké pè é kó fòpin sí ọ̀dá òjò tó wà nílẹ̀ Ísírẹ́lì, síbẹ̀ Báálì ò mà lè rọ̀jo o. Àmọ́ Jèhófà máa fàjùlọ han Báálì nípa fífòpin sí ọ̀dá náà.—1 Àwọn Ọba 16:30–17:1; 18:1-40.
Ìgbà wo wá ni Jèhófà máa ṣe bẹ́ẹ̀? Kí ni Èlíjà á máa ṣe títí dìgbà yẹn? Kí la sì lè kọ́ lára ọkùnrin tó nígbàgbọ́ yìí? Ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò ìtàn tó wà nínú 1 Àwọn Ọba 18:41-46.
Kì Í Fàdúrà Ṣeré
Èlíjà tọ Áhábù lọ ó sì sọ fún un pé: “Gòkè lọ, kí o jẹ, kí o sì mu; nítorí ìró ìkùrìrì eji wọwọ ń bẹ.” (1 Àwọn Ọba 18:41) Ǹjẹ́ ọba burúkú yìí kẹ́kọ̀ọ́ látinú ohun tó ti ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ yẹn? Ìtàn yẹn ò sọ nǹkan kan nípa èyí ní tààràtà, a ò sì rohun tó fi hàn pé ó ronú pìwà dà, kò ní kí Èlíjà bóun tọrọ àforíjì lọ́wọ́ Jèhófà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni Áhábù “bẹ̀rẹ̀ sí gòkè lọ láti jẹ àti láti mu.” (1 Àwọn Ọba 18:42) Kí ni Èlíjà ṣe ní tiẹ̀?
“Ní ti Èlíjà, ó gòkè lọ sí orí Kámẹ́lì, ó sì . . . bẹ̀rẹ̀ mọ́lẹ̀, ó sì ń gbé ojú sáàárín eékún rẹ̀.” Nígbà tí Áhábù lọ jẹun, ńṣe ni Èlíjà lo àǹfààní yẹn láti lọ gbàdúrà sí Jèhófà, Bàbá rẹ̀. Kíyè sí ipò ìrẹ̀lẹ̀ tí ibí yìí sọ pé Èlíjà wà. Ó wà nílẹ̀ẹ́lẹ̀, ó tẹ orí rẹ̀ ba débí tí ojú rẹ̀ fẹ́rẹ̀ẹ́ máa kan eékún rẹ̀. Kí ni Èlíjà ń ṣe? Kò sóhun míì tó ń ṣe ju pé ó ń gbàdúrà lọ. Nínú Jákọ́bù 5:18, Bíbélì sọ fún wa pé Èlíjà gbàdúrà pé kí ọ̀dá náà dópin. Kò sí àní-àní pé orí òkè Kámẹ́lì ló ti gba àdúrà yẹn.
Ṣáájú ìgbà yẹn, Jèhófà ti sọ pé: “Mo ti pinnu láti rọ òjò sórí ilẹ̀.” (1 Àwọn Ọba 18:1) Torí náà ṣe ni Èlíjà ń gbàdúrà pé kí ìfẹ́ Ọlọ́run òun ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí Jésù ṣe kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa gbàdúrà ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ọdún lẹ́yìn ìgbà yẹn.—Mátíù 6:9, 10.
Àpẹẹrẹ Èlíjà kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ tó pọ̀ nípa ọ̀ràn àdúrà. Ohun tó gba Èlíjà lọ́kàn jù lọ ni bí ìfẹ́ Jèhófà, Bàbá rẹ̀ á ṣe di ṣíṣe. Nígbà táwa náà bá ń gbàdúrà, ó yẹ ká máa rántí pé: “Ohun yòówù tí ì báà jẹ́ tí a bá béèrè ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ [Ọlọ́run,] ó ń gbọ́ tiwa.” (1 Jòhánù 5:14) Ó ṣe kedere nígbà náà pé ó yẹ ká mọ ohun tí ìfẹ́ Ọlọ́run jẹ́ kó bàa lè máa gbọ́ àdúrà wa. Ìdí pàtàkì kan sì nìyẹn tó fi yẹ ká jẹ́ kí Bíbélì kíkà ojoojúmọ́ mọ́ wa lára. Ó dájú pé Èlíjà fẹ́ kí òpin dé bá ọ̀dá yẹn torí pé ọ̀dá náà ti ń fìyà jẹ àwọn ọmọ ìlú rẹ̀. Ó ti ní láti dúpẹ́ gidigidi nítorí iṣẹ́ ìyanu tó rí tí Jèhófà ṣe lọ́jọ́ yẹn. Ó yẹ kí àdúrà tiwa náà kún fún ọpẹ́ ká sì máa jẹ́ kí ọ̀rọ̀ àwọn ẹlòmíì jẹ wá lógún.—2 Kọ́ríńtì 1:11; Fílípì 4:6.
Ó Gbékẹ̀ Lé Jèhófà Ó sì Ń Ṣọ́nà
Ó dá Èlíjà lójú pé Jèhófà máa fòpin sí ọ̀dá tó wà nílẹ̀ yìí, àmọ́ ìgbà tí Jèhófà máa fòpin sí i gan–an ni kò mọ̀. Kí wá ni Èlíjà ń ṣe títí dìgbà tí Jèhófà á fi ṣohun tó fẹ́ ṣe? Kíyè sí ohun tí Àwọn Ọba Kìíní orí kejìdínlógún ẹsẹ kẹtàlélógójì sọ, ó ní: “Ó sọ fún ẹmẹ̀wà rẹ̀ pé: ‘Jọ̀wọ́, gòkè lọ. Wo ìhà òkun.’ Nítorí náà, ó gòkè lọ, ó sì wò ó, ó sì wá sọ pé: ‘Kò sí nǹkan kan rárá.’ Ó sì ń bá a lọ láti sọ pé, ‘Padà lọ,’ fún ìgbà méje.” Ó kéré tán a rí ohun méjì kọ́ látinú ohun tí Èlíjà ṣe. Àkọ́kọ́ ni pé ọkàn rẹ̀ balẹ̀ pé Jèhófà yóò dá sí ọ̀rọ̀ náà, ekèjì sì ni pé ó ń ṣọ́nà.
Èlíjà ń wá ẹ̀rí láti mọ̀ ìgbà tí Jèhófà fẹ́ rọ òjò, ìyẹn ló fi ran ẹmẹ̀wà rẹ̀ láti lọ sí téńté orí òkè, níbi tá á ti lè rí ojú sánmà dáadáa, láti lọ wò ó bóyá ó máa rí àmì kan táá jẹ́ kí wọ́n rí i pé òjò ti fẹ́ rọ̀. Àmọ́ nígbà tí ẹmẹ̀wà rẹ̀ padà wá, ìròyìn tó mú wá lè mú kéèyàn rẹ̀wẹ̀sì, ó ní: “Kò sí nǹkan kan rárá.” Ńṣe lojú sánmà mọ́ fo, òjò ò sì ṣú rárá. Àmọ́ ǹjẹ́ o kíyè sí ohun kan tó gbàfiyèsí? Rántí pé àìpẹ́ yìí ni Èlíjà ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ fún Áhábù Ọba pé: “Ìró ìkùrìrì eji wọwọ ń bẹ.” Kí ló mú kí wòlíì náà sọ ọ̀rọ̀ yìí nígbà tó jẹ́ pé òjò ò ṣú sójú sánmà rárá?
Èlíjà mọ̀ pé Jèhófà ti ṣèlérí. Nítorí pé wòlìí àti aṣojú Jèhófà ni Èlíjà, ó dá a lójú pé Ọlọ́run máa mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ. Ọkàn Èlíjà balẹ̀ débi tó fi lè sọ̀rọ̀ bíi pé ó ti ń gbúròó òjò tó ń kù rìrì. Èyí lè rán wa létí ohun tí Bíbélì sọ nípa Mósè pé: “Ó ń bá a lọ ní fífẹsẹ̀múlẹ̀ ṣinṣin bí ẹni tí ń rí Ẹni tí a kò lè rí.” Ṣé ìwọ náà ń rí Ọlọ́run lọ́nà bẹ́ẹ̀? Ọlọ́run fún wa ní ọ̀pọ̀ ìdí tó lè mú ká ní irú ìgbàgbọ́ bẹ́ẹ̀ nínú òun àtàwọn ìlérí rẹ̀.—Hébérù 11:1, 27.
Tún kíyè sí pé Èlíjà jẹ́ ẹni tó ń ṣọ́nà. Ó ń rán ẹmẹ̀wà rẹ̀ lọ léraléra pé kó lọ wo ojú òfuurufú, kì í ṣe ẹ̀ẹ̀kan kì í ṣe ẹ̀ẹ̀mejì, àmọ́ ẹ̀ẹ̀méje ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló rán an lọ! Ẹ wo bí máa-lọ máa-bọ̀ yẹn á ti dá ẹmẹ̀wà Èlíjà lágara tó, àmọ́ Èlíjà ṣì ń retí àmì kò sì sọ̀rètí nù. Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, nígbà tó di ẹ̀kéje tí ẹmẹ̀wà Èlíjà máa lọ wo ibi tó ti ń wo àmì, ó sọ fún Èlíjà pé: “Wò ó! Àwọsánmà kékeré kan bí àtẹ́lẹwọ́ ènìyàn ń gòkè bọ̀ láti inú òkun.” (1 Àwọn Ọba 18:44) Tiẹ̀ fojú inú wo bí ìránṣẹ́ Èlíjà á ṣe na apá láti fi àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀ júwe bí àwọsánmà tó yọ lójú ọ̀run lórí Òkun Ńláb yẹn ṣe kéré tó! Ohun tí ẹmẹ̀wà Èlíjà rí yẹn lè má jọ ọ́ lójú. Àmọ́ lójú Èlíjà, ohun pàtàkì ni. Ó wá rán ẹmẹ̀wà yẹn níṣẹ́ kánjúkánjú kan, ó sọ pé: “Gòkè lọ, sọ fún Áhábù pé, ‘Di kẹ̀kẹ́! Kí o sì sọ̀ kalẹ̀ lọ kí eji wọwọ má bàa dá ọ dúró!’”
Èlíjà tún fi àpẹẹrẹ kan tó lágbára lélẹ̀ fún wa. Àkókò táwa náà ń gbé yìí jẹ́ àkókò tí Ọlọ́run ò ní pẹ́ mú kí ohun tó ní lọ́kàn ṣẹ. Èlíjà ní sùúrú títí dìgbà tí òpin fi dé bá ọ̀dá òjò náà; ó yẹ káwa ìránṣẹ́ Ọlọ́run náà máa fi sùúrù dúró de òpin ètò nǹkan ìsinsìnyí tó ti díbàjẹ́ yìí. (1 Jòhánù 2:17) Títí dìgbà tí Jèhófà Ọlọ́run máa dá sí ọ̀rọ̀ ayé yìí, ẹ jẹ́ káwa náà máa ṣọ́nà nìṣó, gẹ́gẹ́ bíi ti Èlíjà. Jésù Ọmọ Ọlọ́run fúnra rẹ̀ gba àwa ọmọlẹ́yìn rẹ̀ níyànjú pé: “Nítorí náà, ẹ máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà, nítorí pé ẹ kò mọ ọjọ́ tí Olúwa yín ń bọ̀.” (Mátíù 24:42) Ṣóhun tí Jésù ń sọ ni pé àwọn ọmọlẹ́yìn òun ò ní rí òye kankan nípa ìgbà tí òpin máa dé ni? Rárá o, torí pé ó ṣe ọ̀pọ̀ àlàyé nípa báyé ṣe máa rí tó bá kù díẹ̀ kí òpin dé. Gbogbo wa la lè mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ àmí tí Jésù fún wa nípa “ìparí ètò àwọn nǹkan.”—Mátíù 24:3-7.c
Gbogbo àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó wà nínú àmì náà ló jẹ́ ẹ̀rí tó yẹ kó mú wa gbà gbọ́ pé òpin ò ní pẹ́ dé. Ǹjẹ́ àwọn ẹ̀rí tá à ń rí yìí kò tó láti mú ká bẹ̀rẹ̀ sí í gbé àwọn ìgbésẹ̀ tó ṣe pàtàkì ní kíákíá? Gbogbo ohun tó mú kó dá Èlíjà lójú pé Jèhofà máa tó gbégbèésẹ̀ kò ju àwọsánmà tó ṣú díẹ̀. Ǹjẹ́ ìrètí wòlíì yìí já sásán?
Jèhófà Mú Ìtura àti Ìbùkún Wá
Àkọsílẹ̀ yẹn ń tẹ̀ síwájú pé: “Ó sì ṣẹlẹ̀ láàárín àkókò náà pé àwọsánmà àti ẹ̀fúùfù mú ojú ọ̀run ṣókùnkùn, eji wọwọ ńláǹlà sì bẹ̀rẹ̀. Áhábù sì ń gun kẹ̀kẹ́ lọ, ó sì wá sí Jésíréélì.” (1 Àwọn Ọba 18:45) Kíákíá làwọn nǹkan bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹlẹ̀ tẹ̀ léra wọn. Bí ẹmẹ̀wà Èlíjà ṣe ń jíṣẹ́ Èlíjà fún Áhábù lọ́wọ́, àwọsánmà kékeré tó ṣú yẹn bẹ̀rẹ̀ sí í pọ̀ sí i tó fi di pé ó kún gbogbo ojú ọ̀run, tí gbogbo ojú sánmà sì ṣú. Ìjì líle bẹ̀rẹ̀ sí í jà. Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, òjó rọ̀ nílẹ̀ Ísírẹ́lì lẹ́yìn ọ̀dá ọdún mẹ́ta àtààbọ̀.d Ilẹ̀ tó ti gbẹ táútáú tẹ́lẹ̀ wá rin gbingbin. Bí òjò yẹn ṣe ń ya lulẹ̀ wììwìì, odò Kíṣónì kún àkúnya, ó sì dájú pé yóò ti fọ ẹ̀jẹ̀ àwọn wòlíì Báàlì tí Èlíjà ní kí wọ́n pa kúrò nílẹ̀. Òjò yẹn tún fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó ti di alágídí náà láǹfààní láti fọ ẹ̀gbìn tí ìjọsìn Báálì ti kó bá wọn dà nù.
Ó dájú pé Èlíjà á nírètí pé ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí yóò mú ìyípadà wá! Ṣé Áhábù á ronú pìwàdà tá a sì pa ìjọsìn Báàlì tó ti sọ ọ́ dẹ́lẹ́gbin tì? Àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ yẹn ti tó láti mú kó ronú pìwà dà. Àwa ò mọ ohun tó wà lọ́kàn Áhábù lákòókò yẹn o. Ohun tí ìtàn yẹn kàn sọ fún wa ni pé ọba yẹn “ń gun kẹ̀kẹ́ lọ, ó sì wá sí Jésíréélì.” Ǹjẹ́ ó ti rí ẹ̀kọ́ kankan kọ́? Ṣó ti pinnu pé òun á yí padà? Àwọn ohun tó wá ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà fi hàn pé kò fẹ́ yí padà. Síbẹ̀, Áhábù àti Èlíjà ṣì láwọn nǹkan kan láti ṣe lọ́jọ́ yẹn.
Wòlíì Èlíjà bẹ̀rẹ̀ sí í rìnrìn àjò gba ojú ọ̀nà tí Áhábù gbà. Ibi tí Èlíjà ń lọ yìí ṣì jìnnà gan-an, ilẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣú, gbogbo ilẹ̀ sì ti tutù. Àmọ́ ohun àrà ọ̀tọ̀ kan wá ṣẹlẹ̀.
“Ọwọ́ Jèhófà sì wà lára Èlíjà, bẹ́ẹ̀ ni ó sì di ìgbáròkó rẹ̀ lámùrè, ó sì ń sáré lọ níwájú Áhábù dé iyàn-níyàn Jésíréélì.” (1 Àwọn Ọba 18:46) Ó ṣe kedere pé “ọwọ́ Jèhófà” ló ń ṣiṣẹ́ ìyanu lára Èlíjà. Jésíréélì tí Èlíjà forí lé jìnnà tó bí ọgbọ̀n kìlómítà, ara Èlíjà sì ti ń dara àgbà.e Tiẹ̀ fojú inú wo bó ṣe máa rí ná: Èlíjà di àmùrè rẹ̀ sórí aṣọ gígùn tó wọ̀, ó dì í mọ́ ìgbáròkó rẹ̀ kí ẹsẹ̀ rẹ̀ méjèèjì lè ṣeé gbé pẹ̀lú ìrọ̀rùn, èyí ló sì jẹ́ kó lè ráyè sáré dáadáa lórí ilẹ̀ tó ti rin gbingbin yẹn, débi tó fi lè bá kẹ̀kẹ́ ẹṣin ọba tó sì yà á sílẹ̀!
Ìbùkún ńlá mà nìyẹn jẹ́ fún Èlíjà o! Ó ní láti dùn mọ́ ọn nínú bó ṣe ń wo ara rẹ̀ tó tún ta kébékébé ju ti ìgbà tó wà lọ́dọ̀ pàápàá. Ìyẹn lè rán wa létí pé àsọtẹ́lẹ̀ nípa báwọn olóòtọ́ èèyàn tó máa wà nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé yóò ṣe ní ìléra tó pé máa nímùúṣẹ. (Aísáyà 35:6; Lúùkù 23:43) Bí Èlíjà ṣe ń sáré gba ọ̀nà tó rin gbingbin yẹn kọjá, ó mọ̀ dájú pé inú Bàbá òun, Jèhófà Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà ń dùn sí òun!
Ó máa ń wu Jèhófà kó máa bù kún wa. Ìsapá èyíkéyìí tá a bá ṣe láti rí ìbùkún Jèhófà tó bẹ́ẹ̀, ó jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ó yẹ káwa náà ṣe bí Èlíjà, ká máa ṣọ́nà ká sì máa ṣàgbéyẹ̀wò àwọn ẹ̀rí tá à ń rí, pé Jèhófà máa tó dá sí ọ̀ràn ayé eléwu yìí, òpin ò sì ní pẹ́ dé mọ́. Bíi ti Èlíjà, a ní ọ̀pọ̀ ìdí láti ní ìgbẹ́kẹ̀lé kíkún nínú àwọn ìlérí Jèhófà, “Ọlọ́run òtítọ́.”—Sáàmù 31:5.
[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Tó o bá fẹ́ àlàyé tó kún rẹ́rẹ́ nípa èyí, wo àpilẹ̀kọ náà, “Ó Gbèjà Ìjọsìn Mímọ́,” tá a gbé jáde nínú Ilé Ìṣọ́ January 1, 2008.
b Òkun Ńlá yìí la wá mọ̀ sí Òkun Mẹditaréníà lónìí.
c Àlàyé síwájú sí i pé ọ̀rọ̀ Jésù yẹn ti bẹ̀rẹ̀ sí í nímùúṣẹ lónìí wà ní orí kẹsàn-án ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? èyí tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde.
d Èrò àwọn kan ni pé Bíbélì ta ko ara rẹ̀ lórí ohun tó sọ nípa bí ọ̀dá yẹn ṣe gùn tó. Wo àpótí tó wà lójú ìwé 19.
e Kò pẹ́ sígbà tá à ń sọ yìí ni Jèhófà ní kí Èlíjà bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ Èlíṣà níṣẹ́. Èlíṣà yìí ló wá dẹni tá a mọ̀ sí “ẹni tí ń bu omi sí ọwọ́ Èlíjà.” (2 Àwọn Ọba 3:11) Èlíṣà di ẹmẹ̀wà Èlíjà, ó tiẹ̀ ṣeé ṣe kó bá a ṣàwọn iṣẹ́ kan tó yẹ ní ṣíṣe fún àgbàlagbà.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]
Báwo Ni Ọ̀dá Ìgbà Ayé Èlíjà Ṣe Gùn Tó?
Èlíjà, wòlíì Jèhófà sọ fún Áhábù pé ọ̀dá ọlọ́jọ́ gbọọrọ yẹn ò ní pẹ́ dópin. Ní “ọdún kẹta” ni Èlíjà lọ sọ ọ̀rọ̀ yẹn fún ọba, ìyẹn tá a bá kà á látìgbà tí Èlíjà kọ́kọ́ kéde ọ̀dá yẹn. (1 Àwọn Ọba 18:1) Kò pẹ́ sígbà tí Èlíjà sọ pé Jèhófà á rọ òjò ni Jèhófà mú kí òjò bẹ̀rẹ̀ sí í rọ̀. Èyí lè mú káwọn kan sọ pé ọdún kẹta tí ọ̀dá yẹn bẹ̀rẹ̀ ló parí, torí náà kò tó ọdún mẹ́ta tí ọ̀dá náà fi wà. Síbẹ̀, Jésù àti Jákọ́bù sọ pé “ọdún mẹ́ta àti oṣù mẹ́fà” ni ọ̀dá yẹn fi wà. (Lúùkù 4:25; Jákọ́bù 5:17) Ṣé kì í ṣe pé Bíbélì ta ko ara rẹ̀ lórí kókó yìí?
Kò rí bẹ́ẹ̀ rárá. Ohun tó ṣẹlẹ̀ ni pé, nílẹ̀ Ísírẹ́lì láyé àtijọ́, ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn máa ń gùn gan-an, ó máa ń tó oṣù mẹ́fà. Kò sí àní-àní pé àsìkò tí ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn ti ń pẹ́ ju bó ṣe yẹ lọ tó sì ti le gan-an ni Èlíjà wá kéde ọ̀dá náà fún Áhábù. Ìyẹn la fi lè sọ pé ọ̀dá náà ti bẹ̀rẹ̀ láti bí oṣù mẹ́fà ṣáájú ìgbà tí Èlíjà kéde rẹ̀. Èyí wá fi hàn pé nígbà tí Èlíjà fi máa kéde òpin ọ̀dá náà ní “ọdún kẹta” sígbà tó kéde pé ó ti bẹ̀rẹ̀, ó ti tó nǹkan bí ọdún mẹ́ta àtààbọ̀ tí ọ̀dá náà ti bẹ̀rẹ̀. “Ọdún mẹ́ta àti oṣù mẹ́fà” ti kọjá nígbà tí gbogbo èèyàn fi pé jọ láti wá wo ìdánwò tó pabanbarì yẹn ní orí Òkè Ńlá Kámẹ́lì.
Tún ronú nípa bí nǹkan ṣe rí lákòókò tí Èlíjà kọ́kọ́ lọ bá Áhábù lórí ọ̀rọ̀ ọ̀dá yìí. Àwọn èèyàn gbà gbọ́ pé Báálì ni “ẹni tó ń darí àwọsánmà,” ìyẹn ni pé òun ni òrìṣà tó máa rọ̀jò láti fòpin sí ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn náà. Tó bá jẹ́ pé ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn yẹn ti ń gùn ju bó ṣe yẹ lọ, ó ṣeé ṣe káwọn èèyàn ti máa béèrè pé: ‘Báálì dà? Ìgbà wo ló máa rọ̀jò?’ Ó dájú pé ó ti ní láti dun àwọn olùjọ́sìn Báálì yẹn gan-an bí wọ́n ṣe gbọ́ tí Èlíjà sọ pé kò ní sí òjò tàbí ìrí títí òun á fi sọ pé kí òjò rọ̀.—1 Àwọn Ọba 17:1.
[Credit Line]
Pictorial Archive (Near Eastern History) Est.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Àdúrà tí Èlíjà gbà fi hàn pé ó ń wù ú pé kí ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ