Ẹ Jẹ́ Onítara Fún Ìjọsìn Tòótọ́
“Ìkórè pọ̀, ṣùgbọ́n díẹ̀ ni àwọn òṣìṣẹ́.”—MÁT. 9:37.
1. Kí ni ìjẹ́kánjúkánjú túmọ̀ sí?
O NÍ ìwé kan tó o fẹ́ kí ẹnì kan bá ẹ ṣiṣẹ́ lé lórí kí iṣẹ́ ọjọ́ náà tó parí. Kí lo máa ṣe? Wàá sọ fún onítọ̀hùn pé kó “ṢE É KÍÁKÍÁ!” Ò ń wọkọ̀ lọ síbi tó o ti fẹ́ lọ bójú tó ohun pàtàkì kan, o sì ti pẹ́. Kí lo máa ṣe? Wàá sọ fún awakọ̀ pé, “Rìn ńlẹ̀; OJÚ Ń KÁN MI!” Kò sí àní-àní pé tó o bá ní ohun kan láti bójú tó, tí àkókò sì ti ń lọ, ara rẹ kò ní balẹ̀, wàá sì máa kánjú. Ọkàn rẹ á bẹ̀rẹ̀ sí í lù kìkì, wàá sì máa yára ṣe é. Ohun tí ìjẹ́kánjúkánjú túmọ̀ sí nìyẹn!
2. Iṣẹ́ wo ló jẹ́ kánjúkánjú jù lọ fún àwọn Kristẹni tòótọ́ lóde òní?
2 Kò sí iṣẹ́ tó jẹ́ kánjúkánjú fún àwọn Kristẹni tòótọ́ lóde òní tó kọjá iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run àti sísọ àwọn èèyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn. (Mát. 24:14; 28:19, 20) Nígbà tí Máàkù tó jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn ń tọ́ka sí ọ̀rọ̀ Jésù, ó kọ̀wé pé iṣẹ́ yìí la gbọ́dọ̀ “kọ́kọ́” ṣe, ìyẹn ni pé ṣáájú kí òpin tó dé. (Máàkù 13:10) Bó sì ṣe yẹ kó rí gan-an nìyẹn. Jésù sọ pé: “Ìkórè pọ̀, ṣùgbọ́n díẹ̀ ni àwọn òṣìṣẹ́.” Ìkórè kò ṣeé sọ di ìgbà míì; àfi kéèyàn kórè kí àkókò ìkórè tó kọjá lọ.—Mát. 9:37.
3. Kí ni ọ̀pọ̀ èèyàn ń ṣe kí wọ́n lè lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù tó jẹ́ kánjúkánjú?
3 Tá a bá ro ti bí iṣẹ́ ìwàásù náà ti ṣe pàtàkì sí wa tó, a ó máa ṣe gbogbo ohun tá a bá lè ṣe nípa rẹ̀, a ó sì máa lo àkókò àti okun wa lẹ́nu iṣẹ́ náà débi tí agbára wa bá gbé e dé. A gbóríyìn fún ọ̀pọ̀ àwọn ará tó jẹ́ pé ohun tí wọ́n ń ṣe gan-an nìyẹn. Àwọn kan ti jẹ́ kí ohun díẹ̀ tẹ́ wọn lọ́rùn kí wọ́n lè bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò-kíkún, bí aṣáájú-ọ̀nà tàbí míṣọ́nnárì tàbí kí wọ́n lọ sìn ní ọ̀kan lára àwọn Bẹ́tẹ́lì tá a ní káàkiri ayé. Wọ́n máa ń ní ohun púpọ̀ láti ṣe nígbà gbogbo. Ó ṣeé ṣe kí wọ́n ti yááfì ọ̀pọ̀ nǹkan, kí wọ́n sì máa dojú kọ ọ̀pọ̀ ìṣòro. Síbẹ̀, Jèhófà ń bù kún wọn lọ́pọ̀ yanturu. A bá wọn yọ̀! (Ka Lúùkù 18:28-30.) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò ṣeé ṣe fún àwọn míì láti di ọ̀kan lára àwọn òjíṣẹ́ alákòókò-kíkún, síbẹ̀ wọ́n ń lo àkókò wọn débi tí agbára wọn bá gbé e dé lẹ́nu iṣẹ́ ìgbẹ̀mílà náà, èyí sì tún kan ríran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ kí wọ́n lè rí ìgbàlà.—Diu. 6:6, 7.
4. Kí ló lè fà á tí àwọn kan kò fi fi ìjẹ́kánjúkánjú ṣe iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé lé wa lọ́wọ́ mọ́?
4 Ó ti wá ṣe kedere báyìí pé bí ohun kan bá jẹ́ kánjúkánjú, a gbọ́dọ̀ mọ bí àkókò tó máa gbà ṣe pọ̀ tó àti ìgbà tó máa dópin. Àkókò òpin là ń gbé yìí, ọ̀pọ̀ ẹ̀rí ló sì wà nínú Ìwé Mímọ́ àtàwọn ohun tí ìtàn sọ, tó jẹ́ ká mọ̀ bẹ́ẹ̀. (Mát. 24:3, 33; 2 Tím. 3:1-5) Síbẹ̀, kò sí èèyàn kankan tó mọ àkókò pàtó tí òpin máa dé. Nígbà tí Jésù ń sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa “àmì” tó máa fi hàn pé a ti wà ní “ìparí ètò àwọn nǹkan,” ó jẹ́ kó ṣe kedere pé: “Ní ti ọjọ́ àti wákàtí yẹn, kò sí ẹnì kankan tí ó mọ̀ ọ́n, àwọn áńgẹ́lì ọ̀run tàbí Ọmọ pàápàá kò mọ̀ ọ́n, bí kò ṣe Baba nìkan.” (Mát. 24:36) Bí ọ̀rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, bí ọdún ti ń gorí ọdún, ó lè ṣòro fún àwọn kan láti máa fi ìjẹ́kánjúkánjú ṣe iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé lé wa lọ́wọ́, àgàgà tó bá jẹ́ pé wọ́n ti ń bá a bọ̀ fún ọ̀pọ̀ ọdún. (Òwe 13:12) Ǹjẹ́ ó máa ń ṣe ìwọ náà bẹ́ẹ̀ nígbà míì? Kí ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti máa fi ìjẹ́kánjúkánjú ṣe iṣẹ́ tí Jèhófà Ọlọ́run àti Jésù Kristi fẹ́ ká máa ṣe lóde òní tàbí tí kò ní jẹ́ ká dẹ́kun láti máa ṣe é?
Gbé Àpẹẹrẹ Jésù Tó Jẹ́ Àwòfiṣàpẹẹrẹ Wa Yẹ̀ Wò
5. Àwọn ọ̀nà wo ni Jésù gbà fi ìjẹ́kánjúkánjú ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀?
5 Kò sí àní-àní pé àpẹẹrẹ tó ta yọ jù lọ ni Jésù Kristi jẹ́ lára gbogbo àwọn tó fi ìjẹ́kánjúkánjú ṣe iṣẹ́ ìsìn wọn sí Ọlọ́run. Ọ̀kan lára ìdí tó fi fi ìjẹ́kánjúkánjú ṣe iṣẹ́ náà ni pé ó ní ohun púpọ̀ láti gbé ṣe láàárín ọdún mẹ́ta àtààbọ̀ péré. Síbẹ̀, kò tíì sí ẹnikẹ́ni tó ṣe ohun tó pọ̀ tó ohun tí Jésù gbé ṣe tó bá dọ̀ràn ìjọsìn tòótọ́. Ó sọ orúkọ Bàbá rẹ̀ àti ohun tó fẹ́ ṣe di mímọ̀, ó wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, ó túdìí àṣírí àgàbàgebè àti ẹ̀kọ́ èké àwọn aṣáájú ẹ̀sìn, ó sì fi hàn pé ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ ayé àtọ̀run lòun fara mọ́, kódà títí dójú ikú. Ó ṣe gudugudu méje lẹ́nu iṣẹ́ kíkọ́ àwọn èèyàn, ríràn wọ́n lọ́wọ́ àti wíwò wọ́n sàn, jákèjádò ilẹ̀ náà. (Mát. 9:35) Kò sẹ́ni tó ṣiṣẹ́ ribiribi tó tó èyí tí Jésù ṣe yìí láàárín àkókò kúkúrú. Ó ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ náà.—Jòh. 18:37.
6. Kí ni Jésù fi sípò àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé rẹ̀?
6 Kí nìdí tí Jésù kò fi káàárẹ̀ títí tó fi parí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀? Látinú àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì, ó ṣeé ṣe kí Jésù ti mọ ìgbà tí Jèhófà fẹ́ kí òun parí iṣẹ́ náà. (Dán. 9:27) Bí àsọtẹ́lẹ̀ náà ṣe sọ, ó yẹ kí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé parí “ní ìdajì ọ̀sẹ̀ náà” tàbí ní ẹ̀yìn ọdún mẹ́ta àtààbọ̀. Kété lẹ́yìn tí Jésù wọ Jerúsálẹ́mù gẹ́gẹ́ bí aṣẹ́gun nígbà ìrúwé ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, ó sọ pé: “Wákàtí náà ti dé tí a ó ṣe Ọmọ ènìyàn lógo.” (Jòhánù 12:23) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù mọ̀ pé ikú òun ti sún mọ́lé, kò jẹ́ kí ìyẹn gba òun lọ́kàn, kó wá jẹ́ torí ìyẹn ló fi ń ṣiṣẹ́ kára. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó gbájú mọ́ lílo gbogbo àǹfààní tó ṣí sílẹ̀ láti ṣe ìfẹ́ Bàbá rẹ̀ àti láti fi ìfẹ́ hàn sí àwọn èèyàn. Ìfẹ́ yìí ló mú kó kó àwọn ọmọ ẹ̀yìn jọ, tó dá wọn lẹ́kọ̀ọ́, tó sì rán wọn jáde láti lọ wàásù. Ó ṣe èyí kó lè ṣeé ṣe fún wọn láti máa bá iṣẹ́ tó bẹ̀rẹ̀ náà lọ, kí wọ́n sì lè ṣe iṣẹ́ tó pọ̀ ju tirẹ̀ lọ.—Ka Jòhánù 14:12.
7, 8. Kí ló wá sí àwọn ọmọ ẹ̀yìn lọ́kàn nígbà tí Jésù fọ tẹ́ńpìlì mọ́, kí sì nìdí tí Jésù fi hùwà lọ́nà yẹn?
7 Ohun kan tó ṣẹlẹ̀ nínú ìgbésí ayé Jésù fi bí ìtara tó ní ṣe pọ̀ tó hàn kedere. Kò pẹ́ tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ ni ìṣẹ̀lẹ̀ yìí wáyé, nígbà Ìrékọjá ọdún 33 Sànmánì Kristẹni. Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ wá sí Jerúsálẹ́mù, nígbà tí wọ́n sì dé tẹ́ńpìlì wọ́n rí “àwọn tí ń ta màlúù àti àgùntàn àti àdàbà àti àwọn onípàṣípààrọ̀ owó lórí ìjókòó wọn.” Kí wá ni Jésù ṣe, ipa wo ló sì ní lórí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀?—Ka Jòhánù 2:13-17.
8 Ohun tí Jésù ṣe àtohun tó sọ ní àkókò yẹn mú kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ rántí ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ kan tí onísáàmù náà Dáfídì sọ, pé: “Ògédé ìtara fún ilé rẹ ti jẹ mí run.” (Sm. 69:9) Kí nìdí? Ìdí ni pé ọ̀pọ̀ ewu ló rọ̀ mọ́ ohun tí Jésù ṣe yẹn. Ó ṣe tán, àwọn aláṣẹ tẹ́ńpìlì, àwọn àlùfáà, àwọn akọ̀wé àtàwọn míì ló jẹ́ babaàsàlẹ̀ fún àwọn tó ń ṣe òwò tí wọ́n fi ń kó àwọn èèyàn nífà èyí tó ń wáyé níbẹ̀. Torí náà bí Jésù ṣe ń túdìí àṣírí ìwà àrékérekè wọn tó sì ń sọ èròǹgbà wọn dòfo yìí, ńṣe ló ń forí gbárí pẹ̀lú ẹ̀sìn tó ti fìdí múlẹ̀ nígbà ayé rẹ̀. Bí àwọn ọmọ ẹ̀yìn ṣe kíyè sí i gẹ́lẹ́ lọ̀rọ̀ náà rí, ó hàn gbangba pé Jésù ní ‘ìtara fún ilé Ọlọ́run’ tàbí ìtara fún ìjọsìn tòótọ́. Bó bá rí bẹ́ẹ̀, kí ni ìtara túmọ̀ sí? Ǹjẹ́ ó yàtọ̀ sí ìjẹ́kánjúkánjú?
Bí Ìjẹ́kánjúkánjú àti Ìtara Ṣe Jọra
9. Kí ni ìtara túmọ̀ sí?
9 Ìwé atúmọ̀ èdè kan fi hàn pé “ìtara” túmọ̀ sí fífi “ìháragàgà àti ìfẹ́ ọkàn mímúná lépa ohun kan” àti kéèyàn ní “ìgbóná-ọkàn nípa ohun kan” bíi pé iná ń jó nínú ọkàn ẹni. Ó dájú pé a lè lo àwọn ọ̀rọ̀ yìí láti ṣàpèjúwe ọ̀nà tí Jésù gbà ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀. Torí náà, Bíbélì Today’s English Version túmọ̀ ẹsẹ yẹn báyìí pé: “Ìfọkànsìn mi fún ilé rẹ, Ọlọ́run, ó ń jó bí iná nínú mi.” Abájọ nígbà náà tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn fi rántí ọ̀rọ̀ Dáfídì nígbà tí wọ́n rí ohun tí Jésù ṣe nínú tẹ́ńpìlì. Àmọ́, kí ni ohun tó mú kí iná ìtara máa jó nínú ọkàn Jésù, tí ìyẹn sì sún un láti ṣe ohun tó ṣe?
10. Kí ni “ìtara” túmọ̀ sí nínú Bíbélì?
10 Ọ̀rọ̀ náà “ìtara” tó wà nínú sáàmù tí Dáfídì kọ wá látinú ọ̀rọ̀ Hébérù kan tí wọ́n sábà máa ń túmọ̀ sí “jowú” tàbí “owú” ní àwọn apá ibòmíì nínú Bíbélì. Nígbà míì Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun máa ń túmọ̀ rẹ̀ sí “tí ń béèrè ìfọkànsìn tí a yà sọ́tọ̀ gedegbe.” (Ka Ẹ́kísódù 20:5; 34:14; Jóṣúà 24:19.) Nígbà tí ìwé kan tó ń túmọ̀ ọ̀rọ̀ inú Bíbélì ń ṣàlàyé ọ̀rọ̀ yìí, ó sọ pé: “Wọ́n sábà máa ń lò ó nínú àjọṣe àárín tọkọtaya . . . Bí owú tó dára, èyí tí tọkọtaya ní síra wọn, ṣe máa ń mú kí wọ́n gbà pé àwọn jọ wà fúnra àwọn ni, bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ni Ọlọ́run máa ń fi hàn pé Òun nìkan lòun lẹ́tọ̀ọ́ sí ìjọsìn àwọn tó ń sin òun, ó sì ṣe tàn láti gbèjà ẹ̀tọ́ náà.” Torí náà, bí Bíbélì ṣe lo ọ̀rọ̀ náà ìtara kọjá kéèyàn kàn ní ìtara ọkàn fún ohun kan, bí ọ̀pọ̀ olùfẹ́ eré ìdárayá ṣe máa ń ṣe nípa eré ìdárayá tí wọ́n yàn láàyò. Ìtara tí Dáfídì ní jẹ́ owú tó dára tí kò fàyè gba ìdíje tàbí ìkẹ́gàn, tó sì máa ń súnni láti ṣe ohun tí kò ní ba orúkọ rere jẹ́ tàbí láti ṣàtúnṣe ohun tó ti bà jẹ́.
11. Kí ló mú kí Jésù lo ara rẹ̀ tokuntokun?
11 Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù fi ohun tí wọ́n rí tí Jésù ṣe nínú tẹ́ńpìlì wé ọ̀rọ̀ tí Dáfídì sọ, bó sì ṣe rí gan-an nìyẹn. Kì í ṣe torí pé àkókò kan ti wà fún Jésù láti parí iṣẹ́ náà ló ṣe lo ara rẹ̀ tokuntokun, bí kò ṣe torí pé ó ní ìtara, tàbí pé ó ń jowú, nítorí orúkọ Bàbá rẹ̀ àti nítorí ìjọsìn tòótọ́. Nígbà tó rí ẹ̀gàn tí wọ́n ti kó bá orúkọ Ọlọ́run àti ọ̀rọ̀ òdì tí wọ́n ń sọ nípa rẹ̀, ó lo ìtara tàbí pé ó jowú lọ́nà tó tọ́, ó sì ṣe nǹkan kan láti ṣàtúnṣe ọ̀ràn náà. Nígbà tí Jésù rí i tí àwọn aṣáájú ẹ̀sìn ń ni àwọn èèyàn tí wọ́n jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ lára tí wọ́n sì ń kó wọn nífà, ìtara rẹ̀ mú kó pèsè ìtura fún wọn, ó sì tún mú kó ké ègbé lé àwọn aṣáájú ẹ̀sìn tí wọ́n jẹ́ aninilára náà lórí.—Mát. 9:36; 23:2, 4, 27, 28, 33.
Jẹ́ Onítara fún Ìjọsìn Tòótọ́
12, 13. Kí ni àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì lákòókò tá a wà yìí ti ṣe nípa (a) Orúkọ Ọlọ́run? (b) Ìjọba Ọlọ́run?
12 Ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lágbo àwọn onísìn lóde òní jọ ti ìgbà ayé Jésù, bí kò bá tiẹ̀ burú ju ti ìgbà yẹn lọ. Bí àpẹẹrẹ, rántí pé ohun tó ní í ṣe pẹ̀lú orúkọ Ọlọ́run ni Jésù kọ́kọ́ kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa gbàdúrà fún, ó ní: “Kí orúkọ rẹ di sísọ di mímọ́.” (Mát. 6:9) Ǹjẹ́ a rí i kí àwọn aṣáájú ẹ̀sìn, pàápàá jù lọ àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì máa fi orúkọ Ọlọ́run kọ́ àwọn èèyàn kí wọ́n sì máa sọ orúkọ rẹ̀ dí mímọ́ tàbí pé kí wọ́n máa bọ̀wọ̀ fún orúkọ náà? Rárá o, kàkà bẹ́ẹ̀ wọ́n ti lo àwọn ẹ̀kọ́ èké bíi Mẹ́talọ́kan, àìleèkú ọkàn àti iná ọ̀run àpáàdì láti fi sọ ohun tí kò jẹ́ òtítọ́ nípa Ọlọ́run, wọ́n sì ń tipa bẹ́ẹ̀ mú kí Ọlọ́run dà bí ìkà, òkú òǹrorò àti ẹni tí kò ṣeé lóye. Wọ́n tún ti kó ẹ̀gàn bá Ọlọ́run nípasẹ̀ àwọn ìwà máà-jẹ́-á-gbọ́ àti àgàbàgebè wọn. (Ka Róòmù 2:21-24.) Síwájú sí i, kò sí ohun tí wọn ò ṣe tán nítorí àtifi orúkọ Ọlọ́run pa mọ́, kódà wọ́n yọ ọ́ kúrò nínú ìtumọ̀ Bíbélì wọn. Wọ́n tipa bẹ́ẹ̀ ṣèdíwọ́ fún àwọn èèyàn láti sún mọ́ Ọlọ́run, kí wọ́n sì ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú rẹ̀.—Ják. 4:7, 8.
13 Jésù tún kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti máa gbàdúrà pé kí Ìjọba Ọlọ́run dé, ó ní: “Kí ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.” (Mát. 6:10) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì máa ń tún àdúrà yẹn kà léraléra, ètò ìṣèlú àtàwọn àjọ míì táwọn èèyàn gbé kalẹ̀ ni wọ́n ń rọ àwọn èèyàn pé kí wọ́n máa kọ́wọ́ tì. Síwájú sí i, wọ́n ń tẹ́ńbẹ́lú àwọn tó ń sapá láti wàásù, tí wọ́n sì ń jẹ́rìí nípa Ìjọba Ọlọ́run yìí. Nítorí èyí, ọ̀pọ̀ èèyàn tó sọ pé àwọn jẹ́ Kristẹni kì í sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run mọ́, wọn kò sì ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀.
14. Ọ̀nà wo ni àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì ti gbà bomi la Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?
14 Nínú àdúrà tí Jésù gbà sí Ọlọ́run, ó sọ kedere pé: “Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ rẹ.” (Jòh. 17:17) Bákan náà, kí Jésù tó kúrò lórí ilẹ̀ ayé, ó sọ pé òun máa yan “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” láti máa pèsè oúnjẹ tẹ̀mí fún àwọn èèyàn òun. (Mát. 24:45) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó máa ń yá àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì lára láti sọ pé àwọn ń kọ́ni ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ǹjẹ́ ẹ̀rí fi hàn pé wọ́n ń ṣe iṣẹ́ tí Ọ̀gá náà gbé lé àwọn tó bá jẹ́ ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lọ́wọ́? Rárá o. Ìtàn àròsọ ni wọ́n ka ohun tí Bíbélì sọ sí. Dípò kí àwọn àlùfáà máa fi oúnjẹ tẹ̀mí bọ́ agbo wọn, kí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ pèsè ìtùnú àti ìlàlóye fún wọn, ìmọ̀ ọgbọ́n orí, ìyẹn ẹ̀kọ́ tó dá lórí èrò àwọn èèyàn lásán, ni wọ́n fi ń kọ́ wọn. Láfikún sí i, wọ́n ti bomi la ìlànà Ọlọ́run nípa ìwà tó yẹ ká máa hù kí wọ́n lè fàyè gba ohun tí wọ́n pè ní ọ̀nà ìwà rere tuntun.—2 Tím. 4:3, 4.
15. Báwo ni gbogbo ohun táwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì ti ṣe lórúkọ Ọlọ́run ṣe rí lára rẹ?
15 Nítorí gbogbo ohun tí àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì ti ṣe lórúkọ Ọlọ́run tó ni Bíbélì, ọ̀pọ̀ àwọn olóòótọ́ ọkàn ni ìjákulẹ̀ ti bá tàbí tí wọn kò ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run àti nínú Bíbélì mọ́. Wọ́n sì ti kó sínú akóló Sátánì àti ètò àwọn nǹkan búburú rẹ̀. Bó o ṣe ń rí i tírú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ ń ṣẹlẹ̀ lójoojúmọ́ tó o sì ń gbọ́ nípa rẹ̀, báwo ló ṣe rí lára rẹ? Gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Jèhófà, tó o bá rí ẹ̀gàn tí wọ́n ti kó bá orúkọ Ọlọ́run àti ọ̀rọ̀ òdì tí wọ́n ń sọ nípa rẹ̀, ǹjẹ́ kì í ṣe ẹ́ bíi pé kó o wá nǹkan ṣe sí i? Tó o bá rí i tí wọ́n ń tan àwọn olóòótọ́ ọkàn jẹ tí wọ́n sì ń kó wọn nífà, ṣé kì í wù ẹ́ láti tu irú àwọn èèyàn tí à ń ni lára bẹ́ẹ̀ nínú? Nígbà tí Jésù rí àwọn èèyàn ìgbà ayé rẹ̀ pé “a bó wọn láwọ, a sì fọ́n wọn ká bí àwọn àgùntàn tí kò ní olùṣọ́ àgùntàn,” àánú wọn ṣe é. Èyí ló mú kó “bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ wọn ní ohun púpọ̀.” (Mát. 9:36; Máàkù 6:34) Àwa náà ní ọ̀pọ̀ ìdí láti jẹ́ onítara fún ìjọsìn tòótọ́, bí Jésù ti ṣe.
16, 17. (a) Kí ló yẹ kó sún wa láti máa lo ara wa tokuntokun lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù? (b) Kí la máa gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?
16 Bá a bá wo iṣẹ́ ìwàásù wa bí ohun tó yẹ ká máa fi ìtara ṣe, ọ̀rọ̀ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tó wà nínú 1 Tímótì 2:3, 4 á túbọ̀ yé wa. (Kà á.) À ń ṣiṣẹ́ kára lóde ẹ̀rí torí a mọ̀ pé ọjọ́ ìkẹyìn là ń gbé yìí, àmọ́ kì í ṣèyẹn nìkan, a tún mọ̀ pé ohun tí Ọlọ́run fẹ́ nìyẹn. Ó fẹ́ kí àwọn èèyàn ní ìmọ̀ òtítọ́, kí wọ́n bàa lè kọ́ láti jọ́sìn rẹ̀, kí wọ́n sì rí ìbùkún rẹ̀ gbà. Kì í wulẹ̀ ṣe torí pé àkókò ń lọ la ṣe ń lo ara wa tokuntokun lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, bí kò ṣe nítorí pé a fẹ́ láti máa bọlá fún orúkọ Ọlọ́run, ká sì máa ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀. A jẹ́ onítara fún ìjọsìn tòótọ́.—1 Tím. 4:16.
17 Jèhófà ti jẹ́ kí àwa èèyàn rẹ̀ ní ìmọ̀ òtítọ́ nípa ohun tó ní lọ́kàn láti ṣe fún aráyé àti ilẹ̀ ayé. A ní ohun táá jẹ́ ká lè ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti rí ayọ̀ kí wọ́n sì ní ìrètí tó dájú nípa ọjọ́ ọ̀la. A lè darí wọn sí ibi tí wọ́n ti máa rí ààbò nígbà tí ìparun bá dé sórí ètò àwọn nǹkan Sátánì. (2 Tẹs. 1:7-9) Dípò tí a ó fi jẹ́ kó sú wa tàbí tí a ó fi rẹ̀wẹ̀sì bó bá ń ṣe wá bíi pé Jèhófà kò tètè mú ìparun wá, ńṣe ló yẹ ká máa yọ̀ pé àkókò ṣì wà fún wa láti jẹ́ onítara fún ìjọsìn tòótọ́. (Míkà 7:7; Háb. 2:3) Báwo la ṣe lè ní irú ìtara bẹ́ẹ̀? Èyí ni ohun tá a máa gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.
Ǹjẹ́ O Lè Ṣàlàyé?
• Kí nìdí tí Jésù kò fi káàárẹ̀ títí tó fi parí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀?
• Kí ni “ìtara” túmọ̀ sí nínú Bíbélì?
• Kí là ń rí lóde òní tó gbọ́dọ̀ mú ká jẹ́ onítara fún ìjọsìn tòótọ́?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]
Jésù gbájú mọ́ ṣíṣe ìfẹ́ Bàbá rẹ̀ àti fífi ìfẹ́ hàn sí àwọn èèyàn
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Kò sídìí tí kò fi yẹ ká jẹ́ onítara fún ìjọsìn tòótọ́