Ṣé O Mọyì Àwọn Ìbùkún Tó O Ní Lóòótọ́?
LẸ́YÌN tí Ọlọ́run dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nídè kúrò lóko ẹrú ní Íjíbítì, inú wọ́n kọ́kọ́ dùn pé àwọn lómìnira láti máa sin Jèhófà. (Ẹ́kís. 14:29–15:1, 20, 21) Àmọ́, kò pẹ́ lẹ́yìn náà tí èrò wọ́n fi yí pa dà. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ráhùn nípa ipò tí wọ́n wà. Kí nìdí? Ìdí ni pé wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ronú nípa bó ṣe nira fún wọn láti máa gbé nínú aginjù, wọ́n sì gbàgbé ohun tí Jèhófà ti ṣe fún wọn. Wọ́n sọ fún Mósè pé: “Èé ṣe tí ẹ fi mú wa gòkè wá láti Íjíbítì láti kú ní aginjù? Nítorí kò sí oúnjẹ, kò sì sí omi, ọkàn wa sì ti fi tẹ̀gàntẹ̀gàn kórìíra oúnjẹ játijàti [mánà] yìí.”—Núm. 21:5.
Ní ọ̀pọ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún lẹ́yìn náà, Dáfídì Ọba orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ìgbàanì kọ ọ́ lórin pé: “Ní tèmi, inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́ ni mo gbẹ́kẹ̀ lé; jẹ́ kí ọkàn-àyà mi kún fún ìdùnnú nínú ìgbàlà rẹ. Ṣe ni èmi yóò máa kọrin sí Jèhófà, nítorí ó ti bá mi lò lọ́nà tí ń mú èrè wá.” (Sm. 13:5, 6) Dáfídì kò gbàgbé inú-rere-onífẹ̀ẹ́ tí Jèhófà ti fi hàn sí òun. Dípò kó gbàgbé, ńṣe ló ń ronú lé wọn lórí ní gbogbo ìgbà. (Sm. 103:2) Jèhófà ti bá àwa náà lò lọ́nà tí ń mú èrè wá, ohun tó sì bọ́gbọ́n mu ni pé ká má ṣe fọwọ́ kékeré mú ohun tí Jèhófà ti ṣe nítorí wa. Ẹ jẹ́ ká gbé díẹ̀ yẹ̀ wò lára àwọn ìbùkún tá à ń gbádùn lónìí.
“Ìbárẹ́ Tímọ́tímọ́ Pẹ̀lú Jèhófà”
Onísáàmù náà kọrin pé: “Ìbárẹ́ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà jẹ́ ti àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀.” (Sm. 25:14) Àǹfààní ńlá mà ni fún àwa ẹ̀dá èèyàn aláìpé láti ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà o! Àmọ́, bá a bá wá jẹ́ káwọn ìgbòkègbodò ojoojúmọ́ gbà wá lọ́kàn débi tí a kò fi ní àkókò tó pọ̀ tó láti máa gbàdúrà ńkọ́? Ronú nípa bí ìyẹn ṣe máa nípa lórí àjọṣe rere tá a ní pẹ̀lú Jèhófà. Torí pé Jèhófà jẹ́ Ọ̀rẹ́ wa, ó fẹ́ ká ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú òun, ká máa sọ ohun tó wà lọ́kàn wa fún òun, ká sì máa sọ ohun tó ń da ọkàn wa láàmú, ìfẹ́ ọkàn wa àti àwọn àníyàn wa fún òun bá a bá ń gbàdúrà. (Òwe 3:5, 6; Fílí. 4:6, 7) Bọ́ràn bá rí bẹ́ẹ̀, ṣé kò wá yẹ ká mú kí àdúrà wa sunwọ̀n sí i?
Nígbà tí ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí kan tó ń jẹ́ Paul ronú nípa àdúrà rẹ̀, ó rí i pé ó yẹ kóun mú un sunwọ̀n sí i.a Ó sọ pé: “Bí mo bá ń gbàdúrà sí Jèhófà, ó ti mọ́ mi lára láti máa sọ ọ̀rọ̀ kan náà lásọtúnsọ.” Nígbà tí Paul ṣe ìwádìí lórí àdúrà nínú ìwé atọ́ka Watch Tower Publications Index, ó rí i pé ó tó ọgọ́sàn-án [180] àdúrà tó wà lákọọ́lẹ̀ nínú Bíbélì. Nínú àwọn àdúrà yìí, àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ní ìgbà àtijọ́ sọ ohun tó wà lọ́kàn wọn fún Ọlọ́run. Paul sọ pé: “Bí mo ṣe ń ronú lórí àwọn àpẹẹrẹ inú Ìwé Mímọ́ yìí, ó wá yé mi pé ó yẹ kí n máa sọ̀rọ̀ tó ṣe pàtó bí mo bá ń gbàdúrà. Èyí ti ràn mí lọ́wọ́ láti máa ṣí ọkàn mi payá fún Jèhófà. Ní báyìí, ó máa ń dùn mọ́ mi láti túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà nípasẹ̀ àdúrà.”
‘Oúnjẹ Ní Àkókò Tí Ó Bẹ́tọ̀ọ́ Mu’
Ìbùkún míì tá à ń gbádùn lónìí ni ọ̀pọ̀ òtítọ́ inú Ìwé Mímọ́ tí Jèhófà fi jíǹkí wa. Bá a ti ń jẹ ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ oúnjẹ tẹ̀mí dídọ́ṣọ̀ tí Ọlọ́run fún wa, ìdí wà tó fi yẹ ká máa “fi ìdùnnú ké jáde nítorí ipò rere ọkàn-àyà.” (Aísá. 65:13, 14) Àmọ́, a gbọ́dọ̀ wà lójúfò ká má bàa jẹ́ kí àwọn ohun tó lè nípa búburú lórí ẹni mú kí ìtara tá a ní fún òtítọ́ jó rẹ̀yìn. Bí àpẹẹrẹ, bá a bá ń tẹ́tí sí èrò òdì àwọn apẹ̀yìndà, ó lè nípa lórí èrò wa kó má sì jẹ́ ká mọyì àwọn oúnjẹ tẹ̀mí tí Jèhófà ń pèsè fún wa “ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu” nípasẹ̀ “ẹrú olóòótọ́ àti olóye.”—Mát. 24:45-47.
Èrò àwọn apẹ̀yìndà ṣi André tó ti sin Jèhófà fún ọ̀pọ̀ ọdún lọ́nà. Ó lérò pé kò léwu bí òun bá wọ ìkànnì tó jẹ́ tàwọn apẹ̀yìndà bí òun kò bá ṣáà ti pẹ́ níbẹ̀. Ó rántí ohun tó ṣẹlẹ̀, ó ní: “Ohun táwọn apẹ̀yìndà náà gbé kalẹ̀ bí òtítọ́ lórí ìkànnì náà ló kọ́kọ́ fà mí mọ́ra. Bí mo ṣe túbọ̀ ń ṣàyẹ̀wò ohun tí wọ́n sọ, bẹ́ẹ̀ ni mò ń ronú pé kò burú bí mo ṣe fi ètò Jèhófà sílẹ̀. Àmọ́, nígbà tó yá, mo ṣe àwọn ìwádìí kan lórí awuyewuye táwọn apẹ̀yìndà náà ń ṣe nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, mo sì wá rí bí àwọn olùkọ́ èké náà ṣe jẹ́ elétekéte tó. Ohun tí wọ́n pè ní ẹ̀rí tí kò ṣeé já ní koro tí wọ́n ní lòdì sí wa, kò fi ibì kan jẹ́ òótọ́. Torí náà, mo tún bẹ̀rẹ̀ sí í ka àwọn ìtẹ̀jáde wa mo sì ń lọ sí àwọn ìpàdé. Láìpẹ́, ó wá yé mi pé ọ̀pọ̀ nǹkan ni mo ti pàdánù.” Ó múni láyọ̀ láti rí i pé André pa dà sínú ètò Ọlọ́run.
“Gbogbo Ẹgbẹ́ Àwọn Ará”
Ẹgbẹ́ àwọn ará wa tó jẹ́ onífẹ̀ẹ́ jẹ́ ìbùkún látọ̀dọ̀ Jèhófà. (Sm. 133:1) Abájọ tí àpọ́sítélì Pétérù fi sọ pé: “Ẹ máa ní ìfẹ́ fún gbogbo ẹgbẹ́ àwọn ará.” (1 Pét. 2:17) Torí pé a wà láàárín àwọn Kristẹni tá a jọ jẹ́ ará, à ń gbádùn wíwà nínú òtítọ́ pẹ̀lú àwọn bàbá, ìyá, arákùnrin àti arábìnrin nípa tẹ̀mí tí wọ́n ń kóni mọ́ra, tí wọ́n sì ń dúró tini.—Máàkù 10:29, 30.
Síbẹ̀, lábẹ́ onírúurú ipò, ọ̀pọ̀ nǹkan ló lè mú kí àjọṣe àárín àwa àti àwọn ará wa máà dán mọ́rán mọ́. Bí àpẹẹrẹ, ó rọrùn láti jẹ́ kí àìpé ẹnì kan múni bínú, kéèyàn sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àríwísí onítọ̀hún. Bí ọ̀rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, ǹjẹ́ kò ní sàn kéèyàn rántí pé Jèhófà fẹ́ràn àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ bí wọ́n tilẹ̀ jẹ́ aláìpé? Síwájú sí i, “bí a bá sọ gbólóhùn náà pé: ‘Àwa kò ní ẹ̀ṣẹ̀ kankan,’ a ń ṣi ara wa lọ́nà ni, òtítọ́ kò sì sí nínú wa.” (1 Jòh. 1:8) Ṣé kò wá yẹ ká sapá láti ‘máa bá a lọ ní fífaradà á fún ara wa lẹ́nì kìíní-kejì, ká sì máa dárí ji ara wa fàlàlà lẹ́nì kìíní-kejì?’—Kól. 3:13.
Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Ann kẹ́kọ̀ọ́ lọ́nà tó le koko nípa bí pípéjọ pẹ̀lú àwọn ará ti ṣe pàtàkì tó. Òun náà ṣe bí ọmọ onínàákúnàá inú àkàwé Jésù, ó sú lọ kúrò nínú ìjọ Kristẹni. Lẹ́yìn náà, ó pe orí ara rẹ̀ wálé ó sì pa dà sínú òtítọ́. (Lúùkù 15:11-24) Kí ni Ann rí kọ́ látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i? Ó sọ pé: “Ní báyìí tí mo ti pa dà sínú ètò Jèhófà mo mọyì gbogbo àwọn ará mi lọ́kùnrin àti lóbìnrin láìka àìpé wọn sí. Tẹ́lẹ̀, kì í pẹ́ kí n tó ṣe àríwísí wọn. Àmọ́ ní báyìí mo ti pinnu pé n kò ní jẹ́ kí ohunkóhun gba àwọn ìbùkún tí mò ń gbádùn láàárín àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́ mọ́ mi lọ́wọ́. Kò sí ohun tó wà nínú ayé tó yẹ ká torí rẹ̀ fi Párádísè tẹ̀mí wa sílẹ̀.”
Máa Fi Hàn Pé O Mọyì Àwọn Ìbùkún Tó O Ní
Ńṣe ni ìrètí tá a ní pé Ìjọba Ọlọ́run ló máa yanjú gbogbo ìṣòro aráyé dà bí ìṣúra iyebíye. Ẹ wo bí ọkàn wa ti kún fún ìmọrírì tó nígbà tí á kọ́kọ́ ní ìrètí yìí! A mọrírì rẹ̀ gan-an bíi ti olówò inú àkàwé Jésù tó “ta gbogbo ohun tí ó ní” kó lè ra “péálì kan tí ìníyelórí rẹ̀ ga.” (Mát. 13:45, 46) Jésù kò sọ pé olówò náà fìgbà kan rí pàdánù ìmọrírì tó ní fún péálì náà. Bákan náà, ẹ má ṣe jẹ́ ká pàdánù ìmọrírì tá a ní fún ìrètí àgbàyanu yìí.—1 Tẹs. 5:8; Héb. 6:19.
Ṣàgbéyẹ̀wò àpẹẹrẹ Arábìnrin Jean, tó ti ń sin Jèhófà fún ohun tó ju ọgọ́ta [60] ọdún lọ. Ó sọ pé: “Ohun tí kì í jẹ́ kí ọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run kúrò lọ́kàn mi ni pé mo máa ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ fáwọn ẹlòmíì. Nígbà tí mo bá rí bí wọ́n ṣe láyọ̀ tó torí pé wọ́n lóye ohun tí Ìjọba Ọlọ́run jẹ́, ó máa ń ní ipa tó dáa lórí èmi náà. Bí mo bá sì rí ọ̀nà tí òtítọ́ Ìjọba Ọlọ́run gbà yí ìgbésí ayé ẹnì kan tí mò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pa dà, ó máa ń mú ki n ronú pé, ‘Òtítọ́ àgbàyanu mà ni mò ń wàásù rẹ̀ fáwọn ẹlòmíì yìí o!’”
A ní ìdí rere láti kún fún ọpẹ́ torí ọ̀pọ̀ ìbùkún tẹ̀mí tá à ń gbádùn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìṣòro bí àtakò, àìsàn, ọjọ́ ogbó, àárẹ̀ ọkàn, ìbànújẹ́ àti ìṣòro àtijẹ àtimu lè dojú kọ wá, a mọ̀ pé fúngbà díẹ̀ ni. Nínú Ìjọba Ọlọ́run, a máa gbádùn àwọn ìbùkún tara ní àfikún sí àwọn ìbùkún tẹ̀mí tá à ń gbádùn báyìí. Ìyà èyíkéyìí tá a bá ń fara dà ní báyìí kò ní sí mọ́ nínú ètò àwọn nǹkan tuntun.—Ìṣí. 21:4.
Kó tó dìgbà náà, ẹ jẹ́ ká máa ṣọpẹ́ torí àwọn ìbùkún tẹ̀mí tá à ń gbádùn ká sì máa fi ìmọrírì hàn bíi ti onísáàmù tó kọ ọ́ lórin pé: “Ọ̀pọ̀ nǹkan ni ìwọ fúnra rẹ ti ṣe, ìwọ Jèhófà Ọlọ́run mi, àní àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ àti ìrònú rẹ sí wa; kò sí ẹnì kankan tí a lè fi ọ́ wé. Ká ní mo fẹ́ máa wí, kí n sì máa sọ nípa wọn ni, wọ́n pọ̀ níye ju èyí tí mo lè máa ròyìn lẹ́sẹẹsẹ.”—Sm. 40:5.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A ti yí àwọn orúkọ pa dà.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
A máa ń rí ìbùkún tẹ̀mí gbà nígbà àdánwò