Ọlọ́run Dámọ̀ràn Ìfẹ́ Rẹ̀ Fún Wa
“Inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí [yóò] ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba nípasẹ̀ òdodo pẹ̀lú ìyè àìnípẹ̀kun níwájú.”—RÓÒMÙ 5:21.
1, 2. Ohun méjì wo làwọn èèyàn kà sí ẹ̀bùn tó ṣeyebíye, èwo ló sì ṣeyebíye jù lọ nínú ẹ̀bùn méjèèjì?
Ọ̀MỌ̀WÉ David J. Williams, tó jẹ́ atúmọ̀ èdè àti ọ̀jọ̀gbọ́n ní yunifásítì ìlú Melbourne, ní orílẹ̀-èdè Ọsirélíà, sọ pé ‘òfin Ilẹ̀ Ọba Róòmù jẹ́ ẹ̀bùn kan tó ṣeyebíye fún ìdàgbàsókè ọ̀làjú.’ Àmọ́, Bíbélì kọ́ wa pé Ọlọ́run fi ẹ̀bùn tó ṣeyebíye jù bẹ́ẹ̀ lọ jíǹkí àwa èèyàn. Ẹ̀bùn tí Ọlọ́run fún wa yìí lè mú ká rí ojú rere rẹ̀, kó kà wá sí olódodo, kó gbà wá là, ká sì ní àǹfààní láti wà láàyè títí láé.
2 Ọ̀nà tó bá òfin mu ni Ọlọ́run gbà fún wa ní ẹ̀bùn yìí. Nínú Róòmù orí 5, nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń ṣàlàyé bí ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà pèsè ẹ̀bùn náà ṣe bá òfin mu, kò ṣàlàyé rẹ̀ lọ́nà tó díjú tí kò sì fani mọ́ra. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ́nà tó fi hàn pé ohun tó ń sọ dá a lójú. Ó ní: “A ti polongo wa ní olódodo nítorí ìgbàgbọ́, [torí náà] ẹ jẹ́ kí a máa gbádùn àlàáfíà pẹ̀lú Ọlọ́run nípasẹ̀ Olúwa wa Jésù Kristi.” Àwọn tó rí ẹ̀bùn Ọlọ́run gbà máa ń nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run. Pọ́ọ̀lù náà wà lára àwọn tó rí ẹ̀bùn Ọlọ́run gbà. Torí náà, ó kọ̀wé pé: “A ti tú ìfẹ́ Ọlọ́run jáde sínú ọkàn-àyà wa nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́.”—Róòmù 5:1, 5.
3. Àwọn ìbéèrè wo ló bọ́gbọ́n mu pé ká bi ara wa?
3 Àmọ́, kí nìdí tí ẹ̀bùn tí Ọlọ́run fìfẹ́ pèsè yìí fi ṣe pàtàkì? Báwo ni Ọlọ́run á ṣe pèsè ẹ̀bùn náà lọ́nà tó bá òfin mu tó sì ṣàǹfààní? Kí ni Ọlọ́run sì fẹ́ kí ẹnì kan ṣe kó bàa lè rí ẹ̀bùn náà gbà? Ẹ jẹ́ ká wá ìdáhùn tó yẹ sí àwọn ìbéèrè yìí ká sì rí bí àwọn ìdáhùn náà ṣe fi ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní hàn.
Bí Ìfẹ́ Ọlọ́run Ṣe Borí Ẹ̀ṣẹ̀
4, 5. (a) Ọ̀nà àrà ọ̀tọ̀ wo ni Jèhófà gbà fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn? (b) Kí ló yẹ ká mọ̀ ká bàa lè lóye ohun tó wà nínú ìwé Róòmù 5:12?
4 Nítorí pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa lọ́pọ̀lọpọ̀, ó rán Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo láti wá ran aráyé lọ́wọ́. Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ nípa ìfẹ́ yìí pé: “Ọlọ́run dámọ̀ràn ìfẹ́ tirẹ̀ fún wa ní ti pé, nígbà tí àwa ṣì jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, Kristi kú fún wa.” (Róòmù 5:8) Ronú nípa gbólóhùn náà: “Àwa ṣì jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀.” Ó yẹ kí gbogbo wá mọ bí a ṣe di ẹlẹ́ṣẹ̀.
5 Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé ohun tó fà á. Ó bẹ̀rẹ̀ àlàyé rẹ̀ báyìí pé: “Ẹ̀ṣẹ̀ . . . tipasẹ̀ ènìyàn kan wọ ayé àti ikú nípasẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀, ikú sì tipa báyìí tàn dé ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn nítorí pé gbogbo wọn ti dẹ́ṣẹ̀.” (Róòmù 5:12) Èyí kò lè ṣàjèjì sí wa torí pé Ọlọ́run mú kí àwọn tó kọ Bíbélì ṣàlàyé bí ìwàláàyè ẹ̀dá èèyàn ṣe bẹ̀rẹ̀. Wọ́n sọ pé Jèhófà dá Ádámù àti Éfà. Ẹni pípé ni Ẹlẹ́dàá tó dá àwọn òbí wa àkọ́kọ́ yìí, ó sì dá àwọn náà ní pípé. Ó sọ ohun kan ṣoṣo tí wọn kò gbọ́dọ̀ ṣe fún wọn, ó sì jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé bí wọ́n bá ṣàìgbọràn, wọ́n máa kú. (Jẹ́n. 2:17) Àmọ́, wọ́n yàn láti ṣe ohun tó máa yọrí sí ìparun fún wọn, wọ́n ṣàìgbọràn sí àṣẹ tó mọ́gbọ́n dání tó sì ṣe kedere èyí tí Ọlọ́run pa fún wọn, wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé àwọn kò gba Jèhófà gẹ́gẹ́ bí Ọba Aláṣẹ ayé àtọ̀run àti ẹni tó yẹ kó máa fún àwọn lófin.—Diu. 32:4, 5.
6. (a) Kí ló fà á tí àwọn àtọmọdọ́mọ Ádámù fi ń kú, ṣé Òfin Mósè sì yí èyí pa dà? (b) Kí la lè fi àrùn tí kì í jẹ́ kí ẹ̀jẹ̀ tètè dá wé?
6 Ádámù ti dẹ́ṣẹ̀ kó tó bí àwọn ọmọ rẹ̀, àwọn ọmọ rẹ̀ jogún ẹ̀ṣẹ̀ yìí látọ̀dọ̀ rẹ̀, wọ́n sì ń kú. Àmọ́ torí pé àwọn ọmọ Ádámù kò rú òfin kan náà tí Ádámù rú, Ọlọ́run kò fi ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù bi wọ́n; àti pé kò tíì sí àkójọ òfin kankan nígbà yẹn. (Jẹ́n. 2:17) Síbẹ̀, àwọn àtọmọdọ́mọ Ádámù jogún ẹ̀ṣẹ̀. Ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú sì ń tipa bẹ́ẹ̀ jọba títí di àkókò tí Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní àkójọ òfin, èyí tó mú kó ṣe kedere pé wọ́n jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀. (Ka Róòmù 5:13, 14.) A lè fi bí ẹ̀ṣẹ̀ tá a jogún ṣe ń fa ikú wé àwọn àìsàn tàbí àìlera kan tí wọ́n máa ń bí mọ́ni, irú bí àìtó ẹ̀jẹ̀ tàbí àrùn tí kì í jẹ́ kí ẹ̀jẹ̀ tètè dá. O lè ti kà á rí pé wọ́n bí àrùn kan tí kì í jẹ́ kí ẹ̀jẹ̀ tètè dá mọ́ Alexis, tó jẹ́ ọmọ olú ọba ilẹ̀ Rọ́ṣíà, ìyẹn Czar Nicholas Kejì àti Alexandra. Síbẹ̀, àwọn ọmọ kan wà nínú ìdílé tí wọ́n ti ní irú àrùn yìí tí wọ́n lè ní àrùn náà lára ṣùgbọ́n tí kò ní ṣe wọ́n ní nǹkan kan. Ti ẹ̀ṣẹ̀ kò rí bẹ́ẹ̀. Àìpé tí ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù fà kò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀. Gbogbo wa là ń jìyà rẹ̀. Ikú ló sì máa ń yọrí sí. Gbogbo ọmọ ló máa ń jogún rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn òbí wọn. Ṣé a tiẹ̀ lè bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ tó ń fa ikú yìí?
Ohun Tí Ọlọ́run Pèsè Nípasẹ̀ Jésù Kristi
7, 8. Báwo ni ọ̀nà tí àwọn ọkùnrin pípé méjì gbà gbé ìgbé ayé wọn ṣe já sí ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀?
7 Ìfẹ́ tí Jèhófà ní sí àwa èèyàn mú kó ṣe ohun tó lè mú ká borí ẹ̀ṣẹ̀ tá a jogún. Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé ńṣe ni Ọlọ́run lo ọkùnrin míì, tó jẹ́ ẹni pípé bíi ti Ádámù àkọ́kọ́. (1 Kọ́r. 15:45) Àmọ́, ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni ọ̀nà tí àwọn ọkùnrin pípé méjì yìí gbà gbé ìgbé ayé wọn já sí. Báwo ló ṣe jẹ́ bẹ́ẹ̀?—Ka Róòmù 5:15, 16.
8 Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí ó ti rí pẹ̀lú ẹ̀bùn náà ni ó rí pẹ̀lú àṣemáṣe.” Ádámù jẹ̀bi àṣemáṣe, ó sì gba ìdájọ́ tó tọ́ sí i, èyí tí í ṣe ikú. Àmọ́, ikú náà kò mọ sórí òun nìkan. Bíbélì sọ pé: “Ọ̀pọ̀lọpọ̀ . . . kú nípasẹ̀ àṣemáṣe ọkùnrin kan.” Ìdájọ́ òdodo Jèhófà gba pé kó dẹ́bi ikú fún ẹni tó bá dẹ́ṣẹ̀. Nípa bẹ́ẹ̀, ọ̀ràn ikú Ádámù kan àwa ọmọ wọn náà torí pé àìpé tá a jogún látọ̀dọ̀ wọn ti sọ wá di ẹlẹ́ṣẹ̀. Síbẹ̀, ó tù wá nínú láti mọ̀ pé ohun tí Jésù, ọkùnrin pípé náà, ṣe máa yọrí sí ohun tó yàtọ̀ sí ìyẹn. Kí ló yọrí sí? A rí ìdáhùn sí ìbéèrè yìí nínú ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ pé Ọlọ́run máa ‘polongo onírúurú èèyàn ní olódodo fún ìyè.’—Róòmù 5:18.
9. Ìwé Róòmù 5:16, 18 sọ pé Ọlọ́run polongo àwọn èèyàn ní olódodo, kí ni ìyẹn túmọ̀ sí?
9 Kí ni ìtumọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a túmọ̀ lédè Yorùbá sí “ìpolongo òdodo” àti “pípolongo wọn ní olódodo”? Ọ̀mọ̀wé Williams tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí sọ pé: “Àfiwé ni. Wọ́n máa ń lò ó láti ṣàlàyé ọ̀rọ̀ tó bá jẹ mọ́ òfin. Gbólóhùn náà ṣàlàyé ìyípadà tí Ọlọ́run mú kó wáyé nínú ìgbésí ayé ẹnì kan, kì í wulẹ̀ ṣe bí èèyàn ṣe yí ọ̀nà tó gbà ń hùwà pa dà . . . Àfiwé náà fi Ọlọ́run sípò adájọ́ tó ti ṣe tán láti dá ẹni tí wọ́n gbé wá sí kóòtù rẹ̀ láre lẹ́yìn tí wọ́n ti fi ẹ̀sùn kan onítọ̀hún pé ó hùwà àìṣòdodo. Àmọ́, Ọlọ́run dá ẹni tí wọ́n fẹ̀sùn kàn náà sílẹ̀ pátápátá.”
10. Kí ni Jésù ṣe tó mú kí Ọlọ́run polongo aráyé ní olódodo?
10 Kí ló lè mú kí “Onídàájọ́ gbogbo ilẹ̀ ayé” dá aláìṣòdodo sílẹ̀ pátápátá? (Jẹ́n. 18:25) A lè rí ìdáhùn sí ìbéèrè yìí nínu ohun tí Ọlọ́run ṣe. Ìfẹ́ tó ní sí aráyé mú kó rán Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo wá sáyé. Láìka ìdẹwò, ìfiniṣẹ̀sín àti èébú sí, Jésù ṣe ìfẹ́ Baba rẹ̀ lọ́nà pípé pérépéré. Ó pa ìwà títọ́ rẹ̀ mọ́ débi tó fi kú lórí òpó igi oró. (Héb. 2:10) Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá èèyàn pípé, Jésù fi ìwàláàyè rẹ̀ rúbọ, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ pèsè ìràpadà tó lè tú àwọn ọmọ Ádámù sílẹ̀ tàbí kó rà wọ́n pa dà kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú.—Mát. 20:28; Róòmù 5:6-8.
11. Kí ni ìràpadà náà bá ṣe rẹ́gí?
11 Nínú 1 Tímótì 2:6, Pọ́ọ̀lù pe ẹbọ yìí ní “ìràpadà tí ó ṣe rẹ́gí.” Kí ni ìràpadà náà bá ṣe rẹ́gí? Ádámù mú àìpé àti ikú wá sórí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn tí wọ́n jẹ́ àtọmọdọ́mọ rẹ̀. Òótọ́ ni pé Jésù tó jẹ́ ẹni pípé lè bí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àtọmọdọ́mọ tí wọ́n jẹ́ ẹni pípé.a Torí náà, ó yé wa pé ìwàláàyè Jésù àti ti gbogbo àwọn àtọmọdọ́mọ pípé tó lè bí ló fi rúbọ gẹ́gẹ́ bí ìràpadà tó ṣe rẹ́gí pẹ̀lú ìwàláàyè Ádámù àti tí àwọn ọmọ rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ aláìpé. Àmọ́, Bíbélì kò sọ pé ọmọ èyíkéyìí tí Jésù lè bí jẹ́ apá kan ìràpadà náà. Ìwé Róòmù 5:15-19 sọ pé nípasẹ̀ ikú “ọkùnrin kan” ṣoṣo la fi lè rí ìtúsílẹ̀. Torí náà, ìwàláàyè pípé ti Jésù ló ṣe rẹ́gí pẹ̀lú ìwàláàyè pípé ti Ádámù. Jésù Kristi nìkan ṣoṣo ló pèsè ìràpadà náà. Ó ṣeé ṣe fún gbogbo onírúurú èèyàn láti gba ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ àti ìyè torí “ìṣe ìdáláre kan” ti Jésù, ìyẹn bó ṣe ṣègbọràn tó sì pa ìwà títọ́ mọ́ dójú ikú. (2 Kọ́r. 5:14, 15; 1 Pét. 3:18) Báwo la ṣe lè rí ìtúsílẹ̀ nípasẹ̀ ìràpadà?
Ìràpadà Mú Kí Ìtúsílẹ̀ Pátápátá Kúrò Lọ́wọ́ Ẹ̀ṣẹ̀ Ṣeé Ṣe
12, 13. Kí nìdí tó fi jẹ́ pé ìfẹ́ àti àánú Ọlọ́run ló mú kó polongo àwọn kan ní olódodo?
12 Jèhófà Ọlọ́run gba ẹbọ tí Ọmọ rẹ̀ fi ra aráyé pa dà. (Héb. 9:24; 10:10, 12) Síbẹ̀, aláìpé ṣì ni àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù, tó fi mọ́ àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ olóòótọ́, nígbà tí wọ́n wà lórí ilẹ̀ ayé. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n máa ń sapá láti ṣe ohun tó tọ́ nígbà gbogbo, ìgbà míì wà tí wọ́n máa ń ṣe ohun tí kò tọ́. Kí nìdí? Ìdí ni pé wọ́n ti jogún ẹ̀ṣẹ̀. (Róòmù 7:18-20) Àmọ́ Ọlọ́run lè wá nǹkan ṣe sí i, ohun tó sì ṣe nìyẹn. Ó gba “ìràpadà tí ó ṣe rẹ́gí” náà, ó sì fẹ́ láti dárí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ jì wọ́n lọ́lá ẹbọ ìràpadà náà.
13 Kì í ṣe pé àwọn àpọ́sítélì àti àwọn míì ti ṣe àwọn iṣẹ́ rere kan tó mú kó pọn dandan fún Ọlọ́run láti dárí ẹ̀ṣẹ̀ jì wọ́n lọ́lá ẹbọ ìràpadà náà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìfẹ́ àti àánú tí Ọlọ́run ní sí wọn ló mú kó dárí jì wọ́n. Lọ́lá ẹbọ ìràpadà Kristi, ó yàn láti má ṣe dá àwọn àpọ́sítélì àtàwọn mìíràn lẹ́bi ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n jogún látọ̀dọ̀ Ádámù, ó kà á sí pé wọ́n ti bọ́ pátápátá lọ́wọ́ ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ náà. Pọ́ọ̀lù mú kí èyí ṣe kedere nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Nípa inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí yìí, a ti gbà yín là nípasẹ̀ ìgbàgbọ́; èyí kì í sì í ṣe ní tìtorí tiyín, ẹ̀bùn Ọlọ́run ni.”—Éfé. 2:8.
14, 15. Èrè wo ló ń dúró de àwọn tí Ọlọ́run polongo ní olódodo, àmọ́ kí ni wọ́n ṣì ní láti ṣe?
14 Rò ó wò ná: Olódùmarè ṣe tán láti dárí ẹ̀ṣẹ̀ tí ẹnì kan jogún àti àwọn àṣìṣe rẹ̀ jì í. Ẹ̀bùn ńlá mà nìyẹn o! Ó ṣòro láti ka iye ẹ̀ṣẹ̀ tí ẹnì kan ti dá kó tó di Kristẹni; síbẹ̀, Ọlọ́run lè dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ náà jì í lọ́lá ẹbọ ìràpadà náà. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ẹ̀bùn náà yọrí láti inú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àṣemáṣe sí ìpolongo òdodo.” (Róòmù 5:16) Àwọn àpọ́sítélì àti àwọn míì tí wọ́n rí ẹ̀bùn tí Ọlọ́run fìfẹ́ pèsè yìí gbà (bó ṣe polongo wọn ní olódodo) ní láti máa bá a nìṣó láti máa fi ìgbàgbọ́ sin Ọlọ́run tòótọ́. Èrè wo ló ń dúró dè wọ́n? Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Àwọn tí ń gba ọ̀pọ̀ yanturu inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí àti ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ òdodo yóò ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba nínú ìyè nípasẹ̀ ènìyàn kan, Jésù Kristi.” Dájúdájú, ẹ̀bùn òdodo ń ṣiṣẹ́ lọ́nà kan tó yàtọ̀. Ìyè ló máa yọrí sí fún àwọn tó bá gba ẹ̀bùn náà.—Róòmù 5:17; ka Lúùkù 22:28-30.
15 Torí pé Ọlọ́run ti polongo àwọn tó rí ẹ̀bùn náà gbà ní olódodo, wọ́n di ọmọ Ọlọ́run nípa tẹ̀mí. Wọ́n tún jẹ́ ajùmọ̀jogún pẹ̀lú Kristi. Èyí sì máa mú kí Ọlọ́run jí wọn dìde sí òkè ọ̀run gẹ́gẹ́ bí ẹni ẹ̀mí, kí wọ́n lè “ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba” pẹ̀lú Jésù Kristi.—Ka Róòmù 8:15-17, 23.
Ọlọ́run Fìfẹ́ Hàn sí Àwọn Mìíràn
16. Ǹjẹ́ àwọn tó ń retí láti gbé lórí ilẹ̀ ayé lè rí ẹ̀bùn kan gbà látọ̀dọ̀ Ọlọ́run?
16 Kì í ṣe gbogbo àwọn Kristẹni tó ń lo ìgbàgbọ́ nínú Jésù tí wọ́n sì ń sin Ọlọ́run láìyẹsẹ̀ ni wọ́n máa “ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba” pẹ̀lú Kristi lókè ọ̀run. Kí ẹ̀sìn Kristẹni tó bẹ̀rẹ̀, àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ní ìrètí tó bá Bíbélì mu. Irú ìrètí bẹ́ẹ̀ ni ọ̀pọ̀ èèyàn ní lónìí. Wọ́n ń fojú sọ́nà fún gbígbé títí láé nínú Párádísè ilẹ̀ ayé. Àmọ́, ṣé wọ́n tiẹ̀ lè rí ẹ̀bùn tí Ọlọ́run fìfẹ́ pèsè gbà lákòókò tá a wà yìí, kó sì tipa bẹ́ẹ̀ kà wọ́n sí olódodo tó máa láǹfààní láti gbé lórí ilẹ̀ ayé? Bẹ́ẹ̀ ni. Ní ìbámu pẹ̀lú lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ sí àwọn ará Róòmù, èyí jẹ́ ìdáhùn tó fini lọ́kàn balẹ̀!
17, 18. (a) Kí ni Ọlọ́run ka Ábúráhámù sí nítorí ìgbàgbọ́ rẹ̀? (b) Kí ló mú kí Jèhófà ka Ábúráhámù sí olódodo?
17 Àpẹẹrẹ pàtàkì kan tí Pọ́ọ̀lù jíròrò nínú lẹ́tà rẹ̀ ni ti Ábúráhámù, ọkùnrin tó ní ìgbàgbọ́, tó gbé ayé kí Jèhófà tó fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní àkójọ òfin àti ní ọ̀pọ̀ ọdún ṣáájú kí Kristi tó ṣí àǹfààní láti jogún ìyè ti ọ̀run sílẹ̀. (Héb. 10:19, 20) Bíbélì sọ pé: “Kì í ṣe nípasẹ̀ òfin ni Ábúráhámù tàbí irú-ọmọ rẹ̀ gba ìlérí pé òun yóò jẹ́ ajogún ayé kan, ṣùgbọ́n ó jẹ́ láti inú òdodo nípasẹ̀ ìgbàgbọ́.” (Róòmù 4:13; Ják. 2:23, 24) Ábúráhámù sin Ọlọrun láìyẹsẹ̀, torí náà Ọlọ́run kà á sí olódodo.—Ka Róòmù 4:20-22.
18 Ìyẹn ò túmọ̀ sí pé Ábúráhámù kò dẹ́ṣẹ̀ kankan rárá jálẹ̀ ọ̀pọ̀ ọdún tó fi sin Ọlọ́run. Rárá, kì í ṣe ọ̀nà tó gbà jẹ́ olódodo nìyẹn. (Róòmù 3:10, 23) Àmọ́, ọgbọ́n Jèhófà tí kò ṣeé díwọ̀n mú kó ro ti ìgbàgbọ́ àrà ọ̀tọ̀ tí Ábúráhámù ní àti àwọn iṣẹ́ tí ìgbàgbọ́ náà mú kó ṣe. Pàtàkì jù lọ ibẹ̀ ni pé Ábúráhámù lo ìgbàgbọ́ nínú “irú-ọmọ” tí Ọlọ́run ṣèlérí pé ó máa ti ìlà ìdílé rẹ̀ wá. Irú-ọmọ náà sì ni Mèsáyà, tàbí Kristi. (Jẹ́n. 15:6; 22:15-18) Nípa báyìí, ó ṣeé ṣe fún Ọlọ́run tó jẹ́ Onídàájọ́ láti dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tó wáyé ní ìgbà tí ó ti kọjá jì lọ́lá “ìràpadà tí Kristi Jésù san.” Nípa báyìí, ó máa ṣeé ṣe fún Ábúráhámù àti àwọn ẹni ìgbàgbọ́ mìíràn tí wọ́n gbáyé kí ẹ̀sìn Kristẹni tó bẹ̀rẹ̀ láti jíǹde.—Ka Róòmù 3:24, 25; Sm. 32:1, 2.
Jèhófà Lè Ka Ìwọ Náà sí Olódodo
19. Kí nìdí tó fi yẹ kí ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí máa láyọ̀ nítorí ojú tí Ọlọ́run fi wo Ábúráhámù?
19 Ó yẹ kí àwa tá a jẹ́ Kristẹni lónìí máa láyọ̀ nítorí bí Ọlọ́run ìfẹ́ ṣe ka Ábúráhámù sí olódodo. Ọ̀nà tí Jèhófà gbà kà á sí olódodo yàtọ̀ sí ti àwọn tó fi ẹ̀mí rẹ̀ yàn láti jẹ́ “ajùmọ̀jogún pẹ̀lú Kristi.” Àwùjọ èèyàn kéréje yìí ni a “pè láti jẹ́ ẹni mímọ́” a sì gbà wọ́n gẹ́gẹ́ bí “ọmọ Ọlọ́run.” (Róòmù 1:7; 8:14, 17, 33) Àmọ́, ní ti Ábúráhámù, ó di “ọ̀rẹ́ Jèhófà” kó tiẹ̀ tó di pé Jésù rú ẹbọ tó fi ra aráyé pa dà. (Ják. 2:23; Aísá. 41:8) Àwọn Kristẹni tòótọ́ tí wọ́n ní ìrètí láti máa gbé lórí ilẹ̀ ayé nínú Párádísè tí Ọlọ́run ń mú pa dà bọ̀ wá ńkọ́?
20. Ní àkókò tá a wà yìí, kí ni Ọlọ́run fẹ́ kí àwọn tó kà sí olódodo bíi ti Ábúráhámù ṣe?
20 Ọlọ́run kò fún àwọn wọ̀nyí ní “ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ òdodo” kí wọ́n bàa lè jogún ìyè ti ọ̀run “nípasẹ̀ ìtúsílẹ̀ nípa ìràpadà tí Kristi Jésù san.” (Róòmù 3:24; 5:15, 17) Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n ní ìgbàgbọ́ tó lágbára nínú Ọlọ́run àti ìràpadà tó pèsè, ìgbàgbọ́ yẹn sì ń mú kí wọ́n ṣe àwọn iṣẹ́ rere. Ọ̀kan lára irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ ni “wíwàásù ìjọba Ọlọ́run . . . àti kíkọ́ni ní àwọn nǹkan nípa Jésù Kristi Olúwa.” (Ìṣe 28:31) Nípa báyìí, Jèhófà á lè kà wọ́n sí olódodo bíi ti Ábúráhámù. Ẹ̀bùn tí wọ́n rí gbà, ìyẹn ni bí wọ́n ṣe di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run, yàtọ̀ sí “ẹ̀bùn ọ̀fẹ́” tí àwọn ẹni àmì òróró rí gbà. Síbẹ̀, ó dájú pé wọ́n tẹ́wọ́ gba ẹ̀bùn náà, wọ́n sì mọrírì rẹ̀.
21. Àwọn àǹfààní wo la lè rí látinú ìfẹ́ tí Jèhófà fi hàn sí wa àti bí ète rẹ̀ ṣe bá ìdájọ́ òdodo mu?
21 Bó o bá fẹ́ máa gbé títí láé lórí ilẹ̀ ayé, o gbọ́dọ̀ mọ̀ pé kì í ṣe àwọn alákòóso tí kò ṣeé gbára lé ló fi àǹfààní yìí jíǹkí rẹ o. Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run ló mú kí ìyẹn ṣeé ṣe. Èyí sì jẹ́ ká rí bí ète Ọlọ́run fún aráyé ṣe bọ́gbọ́n mu tó. Kí ète yìí lè ní ìmúṣẹ, Jèhófà ti mú kí àwọn nǹkan ṣẹlẹ̀ ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé. Àwọn nǹkan wọ̀nyí sì bá ìdájọ́ òdodo rẹ̀ mu. Pabanbarì rẹ̀ wá ni pé, wọ́n fi ìfẹ́ tó jinlẹ̀ tí Ọlọ́run ní sí wa hàn. Ìyẹn sì ṣe wẹ́kú pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù pé: “Ọlọ́run dámọ̀ràn ìfẹ́ tirẹ̀ fún wa ní ti pé, nígbà tí àwa ṣì jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, Kristi kú fún wa.”—Róòmù 5:8.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Bí àpẹẹrẹ, àlàyé tá a ṣe lórí àwọn àtọmọdọ́mọ yìí wà nínú ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà, Insight on the Scriptures, Ìdìpọ̀ 2, ojú ìwé 736, ìpínrọ̀ 4 àti 5; Ilé Ìṣọ́, March 15, 2000, ojú ìwé 4, ìpínrọ̀ 4.
Ǹjẹ́ O Rántí?
• Kí ni àwọn ọmọ Ádámù jogún, kí ló sì jẹ́ àbájáde rẹ̀?
• Báwo ni Jésù ṣe pèsè ìràpadà tó ṣe rẹ́gí, kí ló sì bá ṣe rẹ́gí?
• Ìrètí wo ni ẹ̀bùn tó lè mú kí Ọlọ́run kà wá sí olódodo mú kó o ní?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
Ádámù, ọkùnrin pípé, dẹ́ṣẹ̀. Jésù, ọkùnrin pípé, pèsè “ìràpadà tí ó ṣe rẹ́gí”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Ìhìn rere ló jẹ́ pé a lè polongo wa ní olódodo nípasẹ̀ Jésù!